#Article 1: Abẹ́òkúta (2279 words)


Abeokuta je ilu ni ti o gbajumo nile Yoruba, lapa iwo-oorun orile-ede Naijiria.. O je olu-ilu ipinle Ogun ti o tedo si agbegbe ti o kun fun Apata nla nla. Idi niyi ti won fi n pee ni Abeokuta. Ibe ni Oke Olumo (Olumo Rock) fikale si.

Ó se pàtàkì láti mọ díẹ̀ nípa ìtàn ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti irú ènìyàn tí ń gbé ìlú Ẹ̀gbá. Ìdí èyí ni pé yóò jẹ́ ohun ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó yẹ ní mímọ̀ nínú orin ògódò. Fún ìdí pàtàkì yìí, n ó ò pín àkòrí yìí si ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ló ti sọ nípa bí a ti se tẹ ilẹ̀ Ẹ̀gbá dó, tí wọn sí tì gbé àbọ̀ ìwádìí wọn fún aráyé rí. Ara irú àwọn báyìí ni Samuel Johnson, Sàbírì Bíòbákú, Ajísafẹ́, Délànà àti àwọn mìíràn tó jẹ́ òpìtàn àtẹnudẹ́nu.

Johnson gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn Ẹ̀gbá ti wá. O ní àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá tòótọ́ lé ti orírun wọn de Ọ̀yọ́. ó tún tẹ̀ síwájú síi pé ọmọ àlè tàbí ẹrú ni Ẹ̀gbá tí kò bá ní orírun láti Ọ̀yọ́. Àwọn olóyè wọn  wà lára àwọn Ẹ̀sọ́ Aláàfin láyé àtijọ́, àtipé àwọn olóyè yìí ló sá wá sí Abẹ́òkúta lábẹ́ olórí wọn tó jẹ́ àbúrò ọba Ọ̀yọ́ nígbà náà.

Délànà ní tirẹ̀ ní etí ilé-ifẹ̀ ni àwọn Ẹ̀gbá tó kọ́kọ́ dé tẹ̀ dó sí. Àwọn ni ó pè ní Ẹ̀gbá Gbàgùrà. Wọ́n dúró  súú sùù súú káàkiri. Olú ìlú wọn sì ni “ÌDDÓ” tí ó wà níbi tí Ọ̀yọ́ wà báyìí. Àwọn ìsí kejì sun mọ ìsàlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n kọjá odò ọnà. Àwọn ni Ẹ̀gbá òkè-ọnà. Òsilẹ̀ ni ọba wọn. Òkó ni olú ìlú wọn .Ẹ̀gbá Aké ló dé gbẹ̀yìn.

Ajísafẹ́ ní ọ̀tẹ̀ ló lé àwọn Ẹ̀gbá kúrò ni ilé- ifẹ̀ wá Kétu. Láti Kétu ni wọn ti wá sí Igbó- Ẹ̀gbá kí wọn to de Abẹ́òkúta ní 1830. Sàbúrí Bíòbákú náà faramọ́ èyí.
Lọ́rọ̀ kan sá, àwọn Ẹ̀gbá ti ilé- ifẹ̀ wá, wọ́n ni ohun i se pẹ̀lú oko Àdágbá, Kétu, àti igbó-Ẹ̀gbá.
Ìtàn tún fi yé ni síwájú sii pé ìlú Ẹ̀gbá pọ̀ ní orílẹ̀ olúkúlùkù ló sì ń ní ọba tirẹ̀, fífọ́ tí orílẹ́ Ẹ̀gbá fọ́ lò gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìtàn ti sọ, 1821 ni Ìjà tó fọ́ gbogbo Ìlú Ẹ̀gbá ti sẹlẹ̀. Ohun kékeré ló dá Ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn òwu àti àwọn Ìjẹ̀bú ni ọjà Apòmù, Ogun Ọ̀yọ́ àti tí ifẹ̀ dà pọ̀ mọ́ ogun Ìjẹ̀bú láti bá Òwu jà. Àgbáríjọ ogun yìí dé ìlú àwọn Òwu ní tọ̀ọ̀ọ́tọ́ sùgbọ́n àwọn Òwu lé wọn padà títí wọ́n fi dé àárín àwọn Gbágùrá to wa ni Ìbàdàn. Inú àwọn Gbágùrá kò dùn sí è́yí wọ́n ti lérò pé ogun yóò kó àwọn Òwu. Èyí náà ló sì mú àwọn Gbágùrá tún gbárajọ láti pẹ̀lú ogun Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀bú àti ifẹ̀ kí wọn le borí ogun Òwu. Wọ́n sẹ́gun lóòótọ́ sùgbọ́n lánlẹ́yìn, àkàrà Ríyìíkẹ́ ni ọ̀rọ̀ náà dà nígbẹ̀yìn. Òjò ń podídẹrẹ́ ni, àwòko ń yọ̀. Kò pẹ́ ẹ̀ ni ogun Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀sà, Ọ̀yọ́ àti ifẹ̀ rí i mọ́ pé àsé àwọn Ẹ̀gbá kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ǹbẹ̀ lẹ̀kun sí àwọn Ẹ̀gbá. Wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Ìlú wọn tán lọ́kọ̀ọ̀kan. 

Èyí tí ó wá burú jù níbẹ̀ ni ti IKÚ Ẹ́GẸ́ tó jẹ olóyè ifẹ̀ kan. Lámọ́di asíwájú Ẹ̀gbá kan ló páa nígbà tí ǹ dìtẹ̀ mọ ọn. Sùgbọ́n àwọn ọ̀tá kò sàì pa òun náà sán.
Ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun tí wọn ń dí mọ́ àwọn Ẹ̀gbá yìí ló mú wọn pinnu láti kúrò ní ibùjókòó wọ́n.
Àwọn babaláwo wọn gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, wọn rí odù òfúnsàá. Wọ́n kifá lọ wọ́n kifá bọ̀, wọ́n ní wọn yóò dé Abẹ́òkúta, àwọn aláwọ̀ funfun yóò sì wá láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn babaláwo wọn náà ni Tẹ́jú osó láti Ìkìjà Òjo (a ń-là-lejì- ogbè) ara Ìlúgùn àti Awóbíyìí ará irò.

Nígbà tí wọn kọ́kọ́ dé, wọ́n do sí itòsí Olúmọ, olúkúlùkù ìlú sa ara wọn jọ, wọn do kiri Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá òkè-ọnà àti Ẹ̀gbá Gbágùrá ló kọ́kọ́ dé sí Abẹ́òkúta. Ni 1831 ni àwọn Òwu sẹ̀sẹ̀ wá bá wọn tí àwọn Ẹ̀gbá sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn Ẹ̀gbádò tí wọ́n bá ní Ìbarà ló sọ wọ́n ni Ẹ̀gbá, nínú ọ̀rọ̀ “Ẹ̀GBÁLUGBÓ” ni wọ́n sì tí fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Àwọn òpìtàn ní àwọn Ẹ̀gbádò ni ń gbé ìpadò nígbà tí àwọn Ẹ̀gbá ní gbé ni òkè ilẹ̀. Òpìtàn míìràn tún ní ìtumọ̀ Ẹ̀gbá ni “Ẹ GBÀ Á “ lálejò nítorí pé wọ́n gba àwọn Òwu àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá abẹ́ ààbò sá sí mọ́ra.

Ẹ̀yà orísìírísìí tó wà nílẹ̀ Ẹ̀gbá ló jẹ́ kí ó di ìlú ń lá, pẹ̀lú ìjọba àkóso tó lágbára ogun ló sọ ọ́ di kékéré bó ti wàyìÍ. Ní apá Àríwá, ó fẹ̀ dé odò ọbà, ní gúúsù ó gba ilẹ̀ dé Èbúté mẹ́ta, lápá Ìlà Ìwọ̀ oòrùn (Ẹ̀gbádò)
Johnson ní ìlú mẹ́tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta (503) ló parapọ̀ dé Abẹ́òkúta lonìí yìí.
Orísìí mẹ́rin ni àwọn Ẹ̀gbá tó wà ní Abẹ́òkúta lónìí. Kò parí síbẹ̀ àwọn miiran tún wà tí wọn ti di Ẹ̀gbá lónìí. Sé tí ewé bá pẹ́ lára ọsẹ, kò ní sàì di ọsẹ. 
Èkíní nínú àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbà yìí ni Ẹ̀gbá Aké. Orísìírísìí ìlú ló tẹ̀ ẹ́ dó, ìdí nìyí tí àwọn Ẹ̀gbá tó kù se ń sọ pé “Ẹ̀GBÁ KẸ́GBÁ PỌ̀ LÁKÉ”. Aké ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá Aké ni Ìjokò, Ìjẹùn, Ọ̀bà, Ìgbẹ̀Ìn, Ìjẹmọ̀, Ìtọ̀kú, imọ̀, Emẹ̀rẹ̀, Kéesì, Kéǹta, Ìrò, Erunwọ̀n, Ìtórí, Ìtẹsi, Ìkọpa, Ìpóró ati Ìjákọ.

Ẹ̀gbá òkè-ọnà ló tẹ lẹ́ Ẹ̀gbá Aláké. Osìlè ni ọba wọn, oun ni igbákejì Aláké. Òkò ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá òkè -ọnà ni Ejígbo, Ìkìjà, Ìjẹjà, odo, Ìkèrèkú, Ẹ̀runbẹ̀, Ìfọ́tẹ̀, Erinjà, ilogbo àti Ìkànna.
Ẹ̀gbá Gbágùrá ni orísìí kẹta. Ìdó ni olórí ìlú wọn. Àgùrá si ni ọba wọn. Àwọn Ìlú to kù ni ọ̀wẹ̀, Ìbàdàn, Ìláwọ̀, Ìwéré, òjé ati àwọn ìlú mọ́kàndínlógoji (39) mìírán.Nígbà tí ogun bẹ sílẹ̀ ni mẹ́sàn-án lara ìlú Gbágùrá sá lọ fi orí balẹ̀ fún Ọlọ́yọ̀ọ́ títí di òní yìí. Àwọn ìlú naa ni Aáwẹ́, Kòjòkú Agéníge, Aràn, Fìdítì, Abẹnà, Akínmọ̀ọ́rìn, Ìlọràá àti Ìròkò.
Ẹ̀gbá Òwu ni orísìí kẹrin, Àgó-Òwu ni olú ìlú wọn, Olówu ni ọba wọn, ìlú tó kù lábẹ́ Òwu ni Erùnmu, Òkòlò, Mowó, Àgọ́ ọbà, àti Apòmù.
Yàtọ̀ sí àwọn tí a sọ̀rọ̀ rẹ lókè yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà míìràn náà ló pọ̀ ní Ẹ̀gbá tí wọ́n ti di ọmọ onílẹ̀ tipẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn báyìí ni a kó lásìkò ogun tàbí kí wọn wá fúnra wọn nígbà tí wọn ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, tí wọn sì ǹ wá ibi isádi. Irú àwọn báyìí ni Ègùn tí wọn wá ni Àgọ́- Ègùn, Ìjàyè- ni Àgọ́- Ìjàyè, àti àwọn Ìbàràpá ni Ìbẹ̀rẹ̀kòdó àti ni Arínlẹ́sẹ̀. Bákannáà ni àwọn Ẹ̀gbádò wà ní Ìbàrà iléwó, onídà àti oníkólóbó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí sáájú Ẹ̀gbá dó síbẹ̀.

Láti ìgbà tí àwọn Ẹ̀gbá ti dó sí Abẹ́òkúta ni ètò ìsèlú wọn ti bẹ̀rẹ̀ si yàtọ̀. Ó di pè wọn ń yan ọba kan gẹ́gẹ́ bí olórí gbogbo gbò. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, kọ́lọ́mú dọ́mú Ìyá rẹ gbé ni. Èyí náà ló sì fìyà jẹ wọ́n. ÀÌrìnpọ̀ ejò ló sá ǹ jẹ ejò níyà.Sé bọ́ká bá síwájú, tí pamọ́lẹ̀ tẹ le e, tí baba wọn òjòlá wá ń wọ́ ruru bọ̀ lẹ́yìn, kò sí baba ẹni tó jẹ dúró. Ọ̀rọ̀ “èmi –ò-gbà ìwọ -ò -gbà” yìí ló jẹ́ kí àwọn alábàágbé Ẹ̀gbá maa pòwe mọ́ wọn pe “Ẹ̀gbá kò lólú, gbogbo wọn ló ń se bí ọba” Ọba wá di púpọ̀.

Ìjọba ìlú pín sí ọ̀nà bíi mẹ́rin nígbà tí ọ̀kan wọn balẹ̀ tán ni ibùdó titun yìí. Àkọ́kọ́ nínú wọn ni àwọn Ológbòóni. Ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ẹgbẹ́ yìí fún ra rẹ̀. Lóòtọ́, ọba ló nilẹ̀, òun ló sì ń gbọ́ ẹjọ́ tó bá tóbi jù. Sị́bẹ̀ síbẹ̀, àwọn Ògbóni lágbára ju ọba lọ. Àwọn ni òsèlú gan-an. Àwọn ló ń pàsẹ ìlú. Wọn lágbára láti yọ ọba lóyè. Delanọ ní láti ilé-ifẹ̀ ni Ẹ̀gbá tí mú ètò Ògbóni wá. Wọn tún un se, wọn sì jẹ́ kí o wúlò tóbẹ́ẹ̀ tí ilé-ifẹ̀ pàápàá ń gáárùn wo ògbóni Ẹ̀gbá.
Orò ni wọn ń lò láti da sẹ̀ríà fún arúfin ti ẹ̀sẹ̀ rẹ tòbi. Bí orò bá ti ń ké ní oru yóò máa bọ̀ lákọlákọ. Olúwo ni olórí àwọn ògbóni. Àwọn oyè tó kù tó sì se pàtàkì ní Apèènà, Akẹ́rẹ̀, Baàjíkí, Baàlá, Baàjítò, Ọ̀dọ̀fín àti Lísa.
Àwọn olórógun tún ní àwọn ẹgbẹ́ kejì tó ń tún ìlú tò. Láti inú ẹgbẹ́ àáró tí ọkùnrin kan ti n jẹ Lísàbí dá sẹ́lẹ̀, ní ẹgbẹ́ olórógun ti yọ jáde. Ọjọ́ kẹtàdínlógún kẹtàdínlógún ni wọ́n ń se àpèjọ wọn. Àwọn náà ló gba Ẹ̀gbá kalẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tí Ọlọ́yọ̀ọ́ àti àwọn Ìlàrí rẹ fi ń jẹ wọn. Ara àwọn oyè tí wọn ń jẹ ni jagùnà (ajagun lójú ọ̀nà) olúkọ̀tún (olú tí Í ko ogun òtún lójú), Akíngbógun, Òsíẹ̀lẹ̀ àti Akílẹ́gun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni wọn si ti sẹ.

Àwọn pàràkòyí náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ọrọ ba di ti ọrọ̀ ajé àti ìsèlú. Àwọn ni n parí ìjà lọ́jà, àwọn ló n gbowó ìsọ ̀. Asíwájú àwọn pàràkòyí ni olórí pàràkòyí.
Àwọn ọdẹ pàápàá tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn atúnlùútò. Wọ́n ń dá ogun jà nígbà mìíràn. Àwọn ni wọn n sọ ọjà àti gbogbo ìlú lóru.
Àwọn olóyè ọdẹ jàǹjàǹkàn naa a maa ba àwọn tó wà ní ìgbìmọ̀ ìlú pésẹ̀ fún àpérò pàtàkì. Díẹ̀ lára oyè tí wọn n jẹ ni Asípa, olúọ́dẹ àti Àró ọdẹ.
Bí ọ̀rọ̀ kan ba n di èyí ti apá lé ko ka, o di ọdọ olórí àdúgbò nì yẹn. Bí kò bá tún ni ojútùú níbẹ̀, a jẹ́ pé ó di tìlùú nì yẹn ọba lo maa n dájọ́ irú èyí nígbà náà.
Tí a bá ka a ni ẹní , èjì ó di ọba mẹsan an to ti jẹ láti ìgbà ti wọn ti de sí Abẹ́òkúta. Àwọn náà nìwọ̀n yii:

Yàtọ̀ sí ọba Aláké tí a to orúkọ wọn sókè yìí, ọba mẹ́rin míìrán tún sì wà ní Abẹ́òkúta tí wọn ń se olórí ìlú wọn. Sùgbọ́n, gbogbo wọn tún sì wà lábẹ́ aláké gẹ́gẹ́ bii ọba gbogbo gbò ni. Àwọn ọba náà ni, Àgùrà Olówu, Òsilẹ̀ àti olúbarà. Ọba aládé sì ni gbogbo wọn. Ní ti oyè tó kù nílùú, o ní agbára tí wọn fún ìlú kọ̀ọ̀kan láti fi olóyè sílẹ̀. Ẹ̀gbá òkè- ọnà ló ń yan ọ̀tún ọba.  Ẹ̀gbá Gbágùrá lo n fi òsì àti Òdọ̀fin sílẹ̀. Ẹ̀gbá Òwu lo si n yan Ẹ̀kẹrin ìlú.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jàǹkànjàǹkàn tó ti fi ẹ̀mí wọn wu ewu fún Ẹ̀gbá ni wọ́n máa ń ráńtí nínú gbogbo orin wọn. Wọn a sì máa fi orúkọ wọn búra pàápàá. Irú àwọn báyìí ni Sódẹkẹ́, Lísàbí, Ẹfúnróyè, Tinúubú ati Ògúndìpẹ̀ Alátise. Àwọn Ẹ̀gbá kò kó iyán wọn kéré wọn kò sì yé bu ọlá fún wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú.
Orísìí ètò ìjọba mẹ́rin ọtọ̀ọ̀ọ̀tọ̀ ni ó ti kọjá ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá kí á tó bọ sí èyí tí a wà lóde òní. 

Ètò ìbílẹ̀ lábẹ́ àsẹ Ògbóni àti Pàràkòyí 1830-1865

Ẹ̀gbá United Board of Management 1865-1898

Ẹ̀gbá United Government (Ìjọba Ẹ̀gbá) 1898 – 1914

Ẹ̀gbá Native Administration (Ìjọba Ìbílẹ̀) 1914 – 1960

Orísìírìsìí isé ajé ni àwọn Ẹ̀gbá n mú se nínú ìlú. Yàtọ̀ sí isẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ tajá tẹran ló ń seé wọ́n fẹràn láti máa da aró, wọ́n mọ̀ nípa àdìrẹ ẹlẹ́kọ dáadáa. Wọ́n tún nífẹ̀ẹ́ si òwò síse. Àwọn àbọ̀ ilẹ̀ sàró ni ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òwò síse yìí túbọ̀ gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kò sí ìlú kan tí kò ní ọjà tirẹ̀, sùgbọ́n àwọn ọjà ń lá kan wà tó ti di ti gbogbo gbo. Irú àwọn ọjà báyìí ni Ìtọ̀kú, Ìta Ẹlẹ́gà, ọjà ọba àti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó. Paríparí rẹ̀ àwọn Ẹ̀gbá fẹ́ràn láti máa kọrin lásán.yálà kíkọ tà gẹ́gẹ́ bí alágbe tàbí ìfẹ́ láti máa kọrin lásán. Gbogbo ohun tó sì ti sẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wọn ni wọ́n máa ń mú lò nínú orin wọn pàápàá.

A ti sọ pé kálukú ẹ̀yà Ẹ̀gbá ló ń da ọmú ìyá rẹ̀ gbé, sị́bẹ̀, kò sàìsí ìbásepọ̀ díẹ̀ láàárín wọn.
Lọ́nà kìnní, gbogbo Ẹ̀gbá ló gbà Abẹ́òkúta sí ìlú wọn.Wọn ni ilẹ̀ níbẹ̀, sùgbọ́n wọn a máa lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti lọ múlẹ̀ oko. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń wálé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oko ẹ̀yìn odi ìlú báyìí lo ti di ìlú fún wọn. Abúlé ni wọn n pe àwọn ìletò wọ̀nyí. Kò sí ọmọ Ẹ̀gbá kan tí kò ní abúlé . Ètò abúlé wọ́ pọ̀, ó sì gún régé, Baálẹ̀ tàbí olóróko (olórí oko) ni o wà ní ipò ọ̀wọ̀ jùlọ.
Bákan náà ló jẹ́ pé gbogbo wọn lo jọ ń bú ọlá fún àwọn ẹni ńlá wọn. Kò sí pé apá kan kò ka àwọn ẹni àná yìí wọ̀nyìí́ kún.
Orò tún jẹ́ ẹ̀sìn kan tó so wọ́n pọ̀. Nílélóko ni wọn ti ń sọdún orò lọ́dọọdún. Àwọn olórò ìlú kan lè mú orò wọn dé ìlú mìíràn láìsí ìjà láìsí ìta. Lóòótọ́, ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní òrìsà tirẹ̀ tó se pàtàkì, fún àpẹẹrẹ, àwọn Òwu ló ni Òtòǹpòrò àti Ẹlúkú. Àwọn Odò ọnà ló ni Agẹmọ, àwọn ìbarà lo ni Gẹ̀lẹ̀dẹ́. Òrìsà Àdáátán, ọ̀tọ̀ ni. O máa ń sẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé tí ìlú kan bá parí ọdún tiwọn lónìí, tí àdúgbò míìràn le bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ keje ẹ̀. Èyí kò sí yi padà láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

Ọjà kan náà ni wọn jọ́ ń ná, oúnjẹ ti wọn ń jẹ ní Aké ni wọn ń jẹ ní Òkò. Wọn fẹ́ràn àmàlà láfún púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń jẹ Sapala kòkò, ewé, awújẹ àti èsúrú.




#Article 2: Ogun (254 words)


Ogun Ẹkú dédé àsìkò yìí ẹ̀yin ọmọ ogun. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́kí á tún bọ̀ sọwọ́pọ̀ láti gbé ògo ilẹ̀ Yorùbá ga.Inù mi dùn púpọ̀ sí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀ẹ̀tí kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá yálà nílẹ̀ Yorùbá tàbí ní òkè òkun bá lè bẹ̀rẹ̀ láti máa kọ́ ọ̀pọlọ̀pọ̀ nínú àwọn àròkọ wọn ní èdè abínibí wà nítorí òní kọ́ àmọ́ nítorí ọjọ́ ọ̀la kí àwọn ọmọ tí wọn kò ì tíì bí lè rí nnkan kà nípa gbogbo ohun mère mère tí ó n sẹlẹ̀ jákè jádò àgbáyé.

Tí a bá wo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sì ní máa gbérí níwọ̀n ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn a ri wí pé púpọ̀ nínú wọn ni wọn fi èdè abínibí kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́n, kòsí iṣẹ́ìwádìí kan tí wọ́n se tí wọ́n kò kọ ní èdè wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé èdè gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n gbà fi se ìwádìí náà.
Ó seni láànu láti máa pàdé àwọn ara ilé nílu òyìnbó kí wọ́n máa fara pamọ́ ki a máà ba pè wọ́n ní ọmọ Yorùbá.Ogún lọ́gọ̀ àwọn olùkọ́ni nílu òyìnbó ni wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yorùbá sùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo akitiyan wọn kò sí ọ̀kan soso nínú isẹ́ ìwádìí wọ́n pẹ̀lú aroko tí ó wà ní èdè Yorùbá-
Kí ló dé?

Ọ̀rọ́ tán lẹ́nu sùgbọ́n ó pọ̀ níkùn,

Títí di ọjọ́ mìíràn ọjọ́ ire,
Emi ni tiyín ní tòótọ́,
Ọmọba Onanusi Olusegun.
Onanusi_olusegun@hotmail.comó

Àkíyèsí pàtàkì - Ti ẹ bá ní ohun láti sọ nípa àròkọ yìí, ẹ̀yin náà lè bọ́sí gbàgede WIKIPEDIA.




#Article 3: Orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan àwọn Ìpínlẹ̀ Amẹ́ríkà (990 words)


Orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan àwọn Ìpínlẹ̀ Amẹ́ríkà tabi Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (USA tabi US ní sọ́kí ní gẹ̀ẹ́sì), tàbí Amerika ni soki, jẹ́ orílé-èdè ijoba àpapò olominira pèlú iwe-ofin ibagbepo tí ó ni adota ipinle, agbegbe ijoba-apapo kan ati agbegbe merinla, ti o wa ni Ariwa Amerika. Ilẹ̀ re fe lati Òkun Pasifiki ni apa iwoorun de Òkun Atlántíkì ni apa ilaorun. O ni bode pelu ile Kanada ni apa ariwa ati pelu Meksiko ni apa guusu. Ipinle Alaska wa ni ariwaiwoorun, pelu Kanada ni ilaorun re ati Rosia ni iwoorun niwaju Bering Strait. Ipinle Hawaii je agbajo erekusu ni arin Pasifiki. Orile-ede awon Ipinle Aparapo tun ni opolopo agbegbe ni Karibeani ati Pasifiki.

Pelu 3.79 egbegberun ilopomeji maili (9.83 million km2) ati iye to ju 309 egbegberun eniyan lo, awon Ipinle Aparapo je orile-ede totobijulo keta tabi kerin bii apapo iye aala, ati iketa totobijulo bii aala ile ati bi awon olugbe. O je kan ninu awon orile-ede agbaye to ni opolopo eya eniyan ati asapupo, eyi je nitori ikoreokere lati opo awon orile-ede. Okowo awon Ipinle Aparapo ni okowo orile-ede to tobijulo lagbaye, pelu idiye GIO 2009 to je $14.3 egbegberunketa (idamerin GIO oloruko lagbaye ati idamarun GIO agbaye fun ipin agbara iraja).

Awon eniyan abinibi ti won wa lati Asia ti budo si ori ibi ti orile-ede awon Ipinle Aparapo wa loni fun egberun lopo odun. Awon olugbe Abinibi ara Amerika din niye gidigidi nitori arun ati igbogunti leyin ibapade awon ara Europe. Orile-ede awon Ipinle Aparapo je didasile latowo awon ileamusin metala ti Britani to budo si egbe Okun Atlantiki. Ni ojo 4 Osu Keje, 1776, won se Ifilole Ilominira, eyi kede eto won fun iko araeni ati idasile isokan alafowosowopo won. Awon ipinle asagun yi bori Ileobaluaye Britani ninu Ogun Ijidide Amerika, eyi ni ogun alamusin fun ilominira akoko to yori si rere. Ilana-ibagbepo ile awon Ipinle Aparapo lowolowo je gbigba bi ofin ni ojo 17 Osu Kesan, 1787; itowobosi ni odun to tele so awon ipinle di apa orile-ede olominira kan na pelu ijoba apapo to lagbara. Awon Isofin awon Eto, to ni atunse mewa si ilana-ibagbepo ti won semudaju awon eto ati ainidekun araalu, je titowobosi ni 1791. 

Ni orundun 19th, awon Ipinle Aparapo gba ile lowo France, Spain, Ileoba Aparapo, Mexico, ati Rosia, o si sefamora Ile Olominira Teksas ati Ile Olominira Hawaii. Ijiyan larin awon ipinle ni Guusu ati awon ipinle ni Ariwa lori awon eto awon ipinle ati igbegun oko eru lo fa Ogun Abele Amerika ti awon odun 1860. Isegun ti Ariwa dena ipinya, o si fa opin oko eru ni Amerika. Nigba ti yio fi to awon odun 1870, okowo orile-ede awon Ipinle Aparapo ile Amerika ni eyi ti o tobijulo lagbaye. Ogun Spein ati Amerika ati Ogun Agbaye Akoko so Amerika di orile-ede alagbara ologun. Leyin Ogun Agbaye Keji o di orile-ede akoko to ni ifija inuatomu, o si tun di omo egbe tikoye ni Ileigbimo Abo Agbajo awon Orile-ede Aparapo. Opin Ogun Koro ati Isokan Sofieti mu ki awon Ipinle Aparapo o di orile-ede alagbara nikan to ku. Amerika siro fun idameji ninu marun inawo ologun lagbaye be sini o tun je akopa asiwaju ninu okowo, oloselu ati asa lagbaye.

Ni 1507, Martin Waldseemüller ayamaapu ara Jemani pese maapu lori ibi to ti pe oruko awon ile ti won wa ni Ibiilaji Apaiwoorun bi Amerika lati inu oruko oluwakiriri ati ayamaapu ara Italia Amerigo Vespucci. Awon ibiamusin Britani tele metala koko lo oruko orile-ede yi ninu Ifilole Ilominira, bi Ifilole alafenuko awon Ipinle aparapo ile Amerika (unanimous Declaration of the thirteen united States of America) to je gbigba mu latowo Awon Asoju awon Ipinle aparapo ile Amerika (Representatives of the united States of America) ni ojo 4 Osu Keje, 1776. Ni ojo 15 Osu Kokanla, 1777, Ipejo Olorile Keji gba awon Ese-oro Ikorapapo, to so pe, Oruko Ijekorapapo yi yio je 'Awon Ipinle Aparapo ile Amerika' (The Stile of this Confederacy shall be 'The United States of America.') Awon iwe adehun lari Fransi ati Amerika odun 1778 lo Awon Ipinle Aparapo ile Ariwa Amerika (United States of North America), sugbon lati ojo 11 Osu Keje, 1778, Awon Ipinle Aparapo ile Amerika (United States of America) lo je lilo lori awon owo fun pasiparo, latigbana eyi lo ti je oruko onibise re.

Ni ede Yoruba Orile-ede Amerika tabi Amerika lasan loruko to wopo. A tun le lo lo U.S. tabi USA.

Awon araalu awon Ipinle Aparapo ile Amerika la mo bi awon ara Amerika.

Amerika ni bode po mo Kanada, to gun lapapo to 8895 km (pelu bode larin Kanada ati Alaska to to 2477 km), o tun ni bode mo Meksico, to gun to 3326 km. Iye apapo igun bode Amerika je 12,221 km. Bakanna etiodo mo Atlantiki, Pasifiki ati Ikun-omi Meksiko na tun ni iye apapo to to 19,924 km.

Aala ori ile Amerika je 9,161,924 km2 pelu aala ori omi to to 664,706 km2, gbogbo aala ile Amerika je 9.82663 egbegberun km2.

Ifagun ariwa-guusu re lati bode mo Kanada ati bode mo Meksiko je 2,500 km, ifagun ilaorun-iwoorun lati eti Okun Atlantiki de Psifiki je 4,500. Orile-ede Amerika dubule si arin ilagbolojo apaariwa 24 ati 49 ati larin ilaninaro apaiwoorun 68th ati 125, be sini o pin si akókò ilẹ̀àmùrè merin.

Aala orile-ede Amerika ni ilafiwo to yato pato. Awon oke ileru bi Cascade Range, ati oke alokoro bi Rocky Mountains ati Appalachian Mountains wa lati Ariwa de Guusu. O ni odo bi Odo Misissipi ati Missouri. O ni opo ile gbigbe ati ile koriko.

Ojuojo duro lori ibudo. Lati ileolooru ni Florida titi de tundra ni Alaska. Opo ibi ni won ni ooru ni igba eerun ati otutu ni igba oye. Awon ibomiran tun wa bi California ti won ni ojuojo Mediteraneani. Ojuojo oloro ko wopo. Awon ipinle ti won bode mo Ikun-omi Meksiko ni iji are prone to hurricanes, and most of the world's tornadoes occur within the country, mainly in the Midwest's Tornado Alley.




#Article 4: Ìjọ Jéésù Lótìítọ́ (145 words)


Ìjọ Jéésù Lótìítọ́ ti a dá s’ílẹ̀ ní ìlú Beijing, Shaina ní ọdún 1917, jẹ́ ìjọ t’ó dá dúró nínú àwọn oní-pẹ́ntíkọ́stì. Ìjọ yìí faramọ́ ìkọ́ni “ọ̀kan soso l’Ọlọ́run”. Wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀kan l’Ọlọ́run àti pé Jésu jẹ́ Ọlọ́run. Ìjọ yìí kọ ìkọ́ni “mẹ́tal’ọ́kan” pé kò tọ́, kò sì dọ́gba láti s’àpèjúwe Ọlọ́run. Ìjọ gbà pé ìkọ́ni “mẹ́tal’ọ́kan” kò wá láti inú Bíbélì nìkan sùgbọ́n láti inú àwọn orísirísi àfikún lẹ́yin àkojo Bíbélì, èyí tí àwọn olùtèlé “ọ̀kan soso l’Ọlọ́run” kà sí èrò èniyàn lásán, tí kò ní àsẹ ìmísi Ọlọ́run bíi ti Bíbélì.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kà á sí ìjọ àwọn ará Sháínà, “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” lóde òní tí ó n tàn kálẹ̀ àgbáye bí a ti n wàásù ìhìnrere Jéésù kárí ayé. Iye àwọn olùtèlé “Ìjọ Jéésù Lótìítọ́” jẹ́ ẹgbèrún lọ́nà ẹgbàá mẹ́jọ èniyàn ní orílẹ̀ kọ́ntínẹ́ntì mẹ́fà ní àgbáyé.




#Article 5: Orílẹ̀-edeé Yorùbá (3820 words)


Ìtumọ̀ àwọn Orúkọ Àdúgbò

ADÚGBÒ 	[Ìkénné] 

[Sònyìndo]

[Ajíno]

[Ìmóbìdo]

[Ìdótun]

[Ìdómolè]

[Ìròlù] 

[Sáàpàdé]

Ìsarà – láti ibi ni wón ti yo ‘sá’ 
Ìparà – láti ibi ni wón ti yo oá’
Odè – láti ibi ni wón ti yo dé’
Àpaofò sá- pà-dé ni ó wá di sápadè.

[Ìsarà] 

[Ògèrè] 

[Ajítaádùn]

ADÚGBÒ
[Ìlúgùn]
Ìtunmò:  Ni ìgbà láéláé, ìtàn so fún wa pé omo kan sonù tí kiri títí, léyìn tí wón ti wáa kiri títí ni wón ríini ìlú ken tí ó jìnà. Nítorí pé ibi tí wón ti rí omo náà jìnà, ni wón se ń pè ní ìlúgùn. 

[Àgó Òkò]:	Òkúta ni wón ń pè ní òkò nì èka èdè ègbá. Ní ìgbà ogun, awon ará àdúgbò yìí ko ni ohun elo ìjà kankan ayàfi òkúta. Òkò ni wón má a ń so fún àwon ota won. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wòn ní Àgó Òkò

Ojà Àgbò: 	Eran àgbò ni wón ń tà níbè kí ó tó di ìbi tí awon ènìyàn ń gbé 

Ìtokò: 		Adágbà je omo ìrówò ìbàràpá òun ní ó kókó dé Abéòkúta, Ogun lé won dé orí dímo (Àwon ìbàràpá) wón bá Adágbà tí ó ń se isé ode ní orí olúmo. Adágbà fi àwon ìbàràpá tí ogun lé dé ori olúmo yìí sí ìdi igi ìto kan. Àwon náà bèrè sí í se ode. Ní ojó kan wón ro oko yí ìdi igi ìto yìí ká, wón gbá pàǹtí sí abé igí ìto yìí, wón fi iná sí i. Nígbà tí Adágbà rí i, ó pariwo lé won lórì pé: Ah! Èyin ènìyàn yìí ìto le kò (Kò túmò sí kí á pa igi). Bí a se rí ìtokò nì yí.
Ìjemò: 		Ìjemò túmò sí Àjumò. Ohun tí a fìjo mò nípa rè 

Kémta: 	 Kémta tumo sì kèeta, Àsòjóró, òtè. Wón máa ń se keèta ara won ìdí èyí ni wón fi ń pe wòn ni kémta.

Ìjeùn: 		Ìtumo re ni “èjì ohùn” áwon olórò méjì héun 

Àgó òwu: 	Àwon ará àdúgbò yìí jé àwon tí ó ń jowú, owú jíje won ló mú won sokún gba adé àwon omo ìkijà. Ìdí nìyí tí wón se ń ki won pé “Ara òwu, omo asunkún gbadé 

Arégbà: 	Àdúgbò tí àwon ìbàràpá tèdó sí. Nígbà tí wón dífá pé kí wón mú Ègbá wá. Wón ní ati-re-gbà ó. Bí ó se dí arégbà nìyí. 

Kúgbà: 	Ikú-gba-èyí. Odò ńlá kan tí ó gbé omo lo ní Arégbà ní àwon ènìyàn ìgbà náà fi ń so pé íkú gba èyí lówó wa. Kúgbà. 

Òkè Èfòn:  	Àwon ará Efòn Alàyè láti ìpínlè Òǹdó ni wón ń gbé àdúgbò yìí. ìdí nìyí tí a fi ń pè àdúgbò náà ní òkè èfòn. 

Àdátán: 	Ogun àti oko ríro, léyìn tí wón tí ja ogun tán, wón fé roko àyíká àdúgbò náà ní a so fún òkunrìn kan pé kí ó lo mú Àdá láti fi sisé wá. Òle ènìyàn nì okùnrin yìí, ó dáhún, ó ní Àdá ti tán. Bayìí ni a se ń pe ibè ní Àdátá. 

Sábó: 		Sábó wá láti inú Sábánímó. Àdúgbò tí àwon Hausa tèdó si ni. Òrò yìí kì í se òrò Yorùbá tàbí ti Ègbá. 

Odédá: 	Àdúgbò tí àwon ode má a ń fàbò sí lèyìn tí wón bá ti sode lo tán ni ibè ní won yóò péjo sí tí won yóò sì dá àwon eran tí wón bá pa jo sí ibè. 

Òkè Agbède: 	Àdúgbò yìí ni àwon ìbàdàn tí wón wá sí Abéòkúta tèdó sí ní igbà tí wón wòlú Egbá. Won kò gba ará ìlú mìíràn móra níbè àfi omo ìbàdàn. 

Àgó Ìjèsà: 	Àdúgbò àti ìbìdó àwon ará ilésà nínú ìlú ègbá 

Ìsàle Jagun: 	Ìsàlè (AJAGUN) – Àdúgbò tí wón ti ń ja ogun ní ìlú Ègbá ní ìgbà àtijo. Kòtò wà ní ibè nì wón fi ń pè é ní ìsàlè jagun. 

Àgó Tápà: 	Ibùdó àwon Tápà nígbà tí wón dé sí Ègbá 

Eléwéran: 	Ewé iran tí a fi ń pón èbà tàbí àmàlà ní o hù àyíká yìí ni ìgbà tó tip é láé. Ibè nì àgó olópàá wà ní Abéòkúta.

Àdúgbò:  	Panséké 
Ìtumò: 		Igì ken wa ti èso rè máa ń dún bì ìgbà ti ènìyàn bá ń mi beere. Ibì tì igi yìí wà gan-an ní gbogbo ènìyàn si máa n lo lati mú u fún lìlò ni awón ara ìlú fún ni orúko ti ó jò mo dídún tie so inu rè màa ń dun. – Pasiséké
Adúgbò:	Mókóla
Ìtùmò:		Àwon ará Òkè-Ìdó ni Abéòkúta nìkan ni ó mo awo ti ó wà nínú àgbùdo gbíngbìn. Odò won sì ni gbogbo awon ènìyàn ti máa ǹ ra àgbàdo. Nítorí ìyànje yìí nì Oba Aláké se fun Olórí àdúgbò yìí ni Omobìnrin re kan lati fi se aya. Obinrin yìí ni o ridìí àsiri ìkòkò yìí tì ó sì sàlàyé fún awon ènìyàn rè. Ibì ti arabinrin yìí wà pàdà nì Oko si ni a fùn ni orunko yìí. Mókólà – Omo ko olá wá sílé. 

Adúgbò:	Fàjé 
Ìtùmò:             Iyá ken ni ò ń dààmú awon ara àdùgbò ìbi ti ó n gbé. Nìgba ti idààmú yìí wá pòju tí awon ènìyàn si mú ejo rè to Oba lo ni ìyá yìí wá sàlàyé wì pé lóòótò ni òún jé àjé ati wì pé ení ti ó bat ó òun ni òún ń da sèrìyà oún. Kábiyèbi bà so pé àsàjemátèe ni obìnrin yìí o. Bi wòn se ń fi ìyá yìí fúwe àdùgbò tì ó ń gbé nìyèn. Won a ní àwón ń lo sí sàje: 

Adúgbò:	Quarry 
Ìtùmò:              Àdugbò yìí ni awon òyìnbó tédò sí làtí máa fo òkútà si wéwé oún ilé kíko tàbi òná sise. Awon Òyìnbó yìí ni wón n pè ni Òyìnbó Quarry nítori Orúko òyìnbo ti ó koko gbé àdùgbò yen. Won ní àwon ń lo sí agbègbè Qùarry. 

Adúgbò:      Àgo Òwu 		
Ìtùmò:        Ní àsìkò Ogun nígbà ti ogun tú awon ènìyàn Owu ti onìkàlùkù won sì fónká. Awon ti ó tédó sí àdúgbò yìí ni o kúkú fé se ìdámò ara won si awon Ègbà yookù. Ìdí nìyìí ti won fí so Ibùdó won nì Àgó Òwù Àgò ti a tì ilè rí awon ara Owù 

Adúgbò:    Ita-eko 		
Ìtùmò:       Ní àtijó àdúgbò kookan ni ó ní ise ìdamo won. ‘Sùgbón nì tí awon ara àdúgbò yìí eko nì gbogbo awaon obìnrin won màá ń tà. Bí ó bà sì dì ale gbogbo won a pate eko won sì ojú kan. Bì a bá wà rí ení ti o bá fe lo sí ojúde yìí onítòhùn yòó sò pé òun lo si Ìtà-eko. Orúko yìí nì ò sì mo àdúgbò náà lòrí dì onì yìí ni pàtàkí fún ìdamò ìta-eko ojóun. 

Adúgbò:    Ita Ìyálòde. 		
Ìtùmò:       Akínkanjú obinrin kan wa ni Ègbá ni ayé ojóun. Efúnróyè Tínubú nì orúko rè. ‘Nítorí ibe ìdàgbàsòkè re sù ìlú Ègbá ni oba Àláké se fí jè Ìjatóde ìlù. Oún ni ìyálódè Ègbá àkòkó. Ibì ti Ìyá yìí wá kólé sí ní àdúgbò rè ni won so di ‘Ita ìyálódè. 

Adúgbò:	Kútò 
Ìtùmò:              Nì àyé àtíjó àbikú ń da bàbá kan láàmu. Nigbà ti ó dáfá, won ni ki ó fe síwáju bì ó bà ń fé kì àbìkú dúró. Bàbá yìí wá dó sí ìbi ti a mo sí Kútò lónìí. Sùgbon léyìn odún díè omo ti ó bà tún kú nì o bá bérè ariwo pé ikú tun to òun léyìn dé ibí yìí. Báyìí ni awon elégbe rè se ge orúko kéré di`kútò tí ó sì wà dòní yìí 

Adúgbò:	Ìdí àbà 
Ìtùmò:            Nígbà tì kò tíì sí ònà móto bí àwon ti a ní lònìí yìí àwon ènìyàn ti wón jè yálà ode tàbí àgbè a máa fi adúgbò Ìdí Àbà se ìpàdé won. Igi àbà po ni àdúgbò yìí nìgbà náà. Awon ènìyàn wonyi a sì maa sinmi ni àbe àwon Ìgi yìí yàlà ní àlo tabì ní àbò. Báyìí nì won se kúkú so agbégbè yìí ni Idí àbà. Bì ó file jè pé olàjú ti dé báyìí èyí kò yí oruko adugbo náà páde dì báyìí. 

Àdúgbò:	Ajítaádùn
Itùmò:		Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn. Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn).   

Ilé-Àwòrò-òsé: 	ìtàn ti a gbo nipa adugbo tabi agbo-ile yì so fun wa pe ilé. Àwòrò-òsé je ibi pàtàkì ti won ti ma n se orò, ò sì tun je ile-Olorisa. 

Ìlé-Olúóde:                    A gbó pe ode ni ìran àwon wònyí n se láti ìgbà ìwásà. Ibe sì nì Olórí àwon ode n gbe. 

Ile-Olutojokun: 	   Àwon ìdílé yi ni o ma ń joba ni ìlú-ìlá-òràngún. 

Ile-Olorirawo: 	Adugbo ati Agbo-ile ni eyi je. Ìtan ti a si gbo nipa won núpé ìbè ni Olori awon awo tedo sì. 

Ìjímògòdò:  	 	Akoni èdá kan ni o je, jagunjagun sin i pelu, oun lo te àdúgbò yì dó. 

Ìgbonnìbí:	jé òkan nínú àwon oba akíkanjú ti o wolè ni ìlá. Níbi ti o wolè sin i a n pe ni Ìgbonnìbí loni yìí. 

Ajagúnlá: 	Ode ni ajagunle nigba aye re, o si je jagunjagun O si bínú wolè lo ni. 

Ògbún Ìperin: 	 Nibi ti a pa Erin sin i a n pe ni ìperin

Òkè-Èdè: 	túmò si ibi ti a pa elédè si 

Ògbún ìsèdó: 	Eyi tumò si ibi ti isé sodo si. Agbègbè yin i ìlú ma n lo gégé bi ojúbo isé. 

Ilé- Olóòsà! 	A gbo pe wón ma n ko òrìsà pamó sì adugbó yií.

Òkè-Alóyin: 	Odò kan ti o n san ni àdúgbò yì, wón ma n lo omi yì láti fi se ìmúláradá àwon omo wéwé. 

Ilé-Agbérùkóó:  A gbó pe ìdílé yì ma n gbe èrúkó tà, ni won fi ma n pé wón ni agbérùkóó. 

Ilé-Alápìnni:       Ìtàn so pe idile Oloje tabi eleegun ni won je. Àwon sin i Olórí gbogbo àwon eégún. 

Ilé-Ìyálóde: 	Obìnrin ni o te idile yi do, O gbé fáàrí O sit un je akikanju obinrin láàrin ìlú. 

Ilé-Akogun: 	Jagunjagun naa ni o te adugbo yi do Akogun sit un je Oloye pàtàkì ni ìlú 

Ilé-Òjá-bèbè:   Isé abèbè ni wón yàn láàyò ni àdúgbò yì. 

Ìlé-Agbèdègbede: 	Àwon ìdílé Alágbède ni àwon wonyi n se. 

Ilé-Òdú: 	Èfó òdú ni won ma ngbin ni akoko ti won so orúko ile yii. 

Ilé-Ajengbe: Isé Ìsègùn ni won ma n se ni ìdílé yi. Won sit un je akoni èdá kan.

Ilé-Obajisun: 	Ìdílé oba ni won jé won sì tun je Olóyè ìlú. Èfó òsùn pò púpò nì àdúgbò yìí 

Ilé-Onílù: 	Àwon àyàn ni o te ile yìí do, ìdílé onilu ni àwon wonyi je 

Ilé-Awúgbo: 	àwon ìdílé yi saba ma n gbìn erè kan ti a n pen i awúje, èyítí o ti gbilè ti won fi n pe won lórúko loni. 

Ile-Èelemukan : Èkan po ni àdúgbò yìí 

Ìle-Obajoko: 	    Idile yin i won ti ma n sábà fi Oba je, eyìti a mo si kingmaker. 

Òkè-Ògbún:        Nígbàtí ìlú ko ti làjú àdúgbò yin i wón ma sábà ko gbogbo àwon òhun ìdòtí pamó si, o si je ògbun eyìti wòn so di oke-ògbún lòni yì. 

Ilé-Àtèéré

Ilé-Àbálágemo:	 

Ilé-Asóyòò:

Ilé-odogun: 	Ìdílé àwon jagunjagun ni won.

Òkè-Àgó: 	Gégé bí ìwádìí tí mo se, àdúgbò yìí ni àwon tí ó kókó tèdó sí ìlú yìí dé sí. Láyé ìgbà náà, kò ì tí ì  sí ilé-búlókù, àgó ni wón ma ń pa, ibi tí wón rook pàgó sí ni wón wó ń pè ní òkè-àgó ní oorí pé, ó bó sí ibi tí òké wà. 

Ilé-Ita: 	      Gégé bí ìtàn se so, ní orí ilè yí nì àwon ará ìlú pàápàá jùlo àwon àgbàgbà lókìnrin  ti ma ń ta ayò bí wón bá ti took dé láyé ìgbà náà. Ilè-ìtayò nì wón ń kókó pè é kó tó di wí pé, wón kó ilé síbè gan-gan. Ilè-ìtayò ni ó wá yí padà sí ilé-ìtayò, ìgbà tí ó yá, wón so ó di ilé-ita. Eyí ni, ibi tí a ti ń ta ayò.

Ilé-Okógbà: 	Àdúgbò yìí gba orúko rè nípa sè Baba kan tí ó fé ràn isé oko púpò. wón ní Bàbá yìí ma ń fi àyíká ilé e rè gbin orisirisi nǹkan lódodún sùgbón wón wí pé, àwon eran òsìn bíi ewúré ma ń yo ó lénu púpò. Nígbà tí ó yá, ó wá bèrè sí ní pa àwon erúré tó bá ti won ú ogbà a rè. Eléyìí ló wá fà á tí ìjà fi wà láàárín òun àti àwon ènìyàn, ni wón bá fim ni orúko wí pé, Baba ológbà. Léhùn tí bàbá yìí kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò ibè ní ilé-Ológbà. 

Ìdí-Isin :	Gégé bí ìwádìí, won ni igi ńlá kan wa níbè nígbà náà tí a ń pè ní igi-isin. wón wí pé, lábé rè ni wón ti ma ń gba aféfé nítorí pé igi-ńlá ni, wón sì tún ma ń je èso ara rè. Bí ó tilè jé pé, èyìn ìlú ni igi-isin yìí wà, sùgbón ní gbà tí wón kó ilé de ibè, ni wón bá ń pè é ní ìdí-isin

Ilé-Lódò: 	wón ní àdúgbò yìí jé ibi ilè àkèrò nígbà náà. Odò kékeré kan sì wà níbè nígbà náà tí wón ń pon mu. Orúko Odò yìí ni a ń pè ní Odò-àwéré, Ibí yìí ni àdúgbò yìí tí gba orúko rè.

Ilé- ńlá:	Wón wí pé láàti àdúgbò kan tí a ń pè ní ilé-ńlá nilu ilé-ifè ni àwon àdúgbò yìí ti sè wá nípa sè ogun Ìdí nìyìí tí wón fi ń pè é ni ilé-ńlá.

Òkè-Ganmo	Àdúgbò yìí gba oríko jè láà ti ìlú kan tí ó wà ní tòsí ìlorin tí a ń pè ní Gunmo. Lati ìlú yìí ni wón ní àwon ènìyàn tó kókó tèdó sí sórí ilè náà o wá. Ìdí nìyìí tí wón fi ń pè é ní àdúgbò ara ganmo títí ó fid i wí pé, wón ń pè rí òkè-Ganmo. 

Òkè-Abà 	Àdúgbò yìí náà jé òkan lára àwon àdúgbò tó tí pé jù nilu yìí. wón wí pé, nígbà tí ìlú kò ì tíì pò rárá, bí ènìyàn dúrói ní àdúgbò yìí, yóó máa wo gbogbo ìlú tókù ketekete, ìdí nìyìí tí wón kúkú fi ń pe ibè ní òkè-abà. 

Ilé- alágbè 	Àdúgbò yìí gba orúko nípasè igi-tòròmogbè tí wón ma ń gbìn sí àyíká ilé ní agbègbè náà. Wón ní àdúgbò á wón ti ń kókó gbin igi yìí ní ìlú yìí náà ni wón so di ilé-alágbè títí di òní yìí. 

Ìsàlè-ojà	Àdúgbò yìí ni àdúgbò tí ó wa ní ojúde-ojà gan-an tí wón ti ń ná jà di òní-olónú. Àdúgbò yìí kò jìnnà sí ilé-Oba. 

Oníbàtá	Láyé ojóun, wón ní, Olórí àdúgbò yìí ni wón fi je olórí àwon alubàbá àti igangan ní ìlú yìí. Láàti ìgbà tí wón ti fi je é, ni wón ti ń pè é ní baba-oníbàbá, tí wón sì ń pe ilé e jè ní ilé Baba-oníbàtá. Lati ibí yìí ni wón ti so àdúgbò ibè ní àdúgbò oníbàtá èyí ni àdúgbò ilé Baba oníbàtá. 

Olú-ìpo 	Orúko oyè kan pàtàkì ni orúko àdúgbò yìí. Ìwádìí fihàn wí pé, eni tí ó je oyè yìí nígbà ìkéjì jé akíkanjú ènìyàn tí ó lágbára tí ó sì tún jé ode. Oyè yìí ti di àsómodómo. 

Ìlálè	Wón wí pé, nígbà kan tí àwon ará ìlú-òbà wá sígun bá àwon ìlú pàmò wón wí pé nígbà tí wón dé lojiji, ni enìkan nínú àwon asájú tàbí olóyè ìlú pàmò bá fowó fa ìlà tàbí fowó la ilè wí pé àwon ará ìlú-òbà kò gbodò kojá ilà yen kí won tó pa dà séhìn sùgbón wón dá ilà náà kojá tí ó sì fa ìjà ńlá. Ibi tí wón ti ja ìjà tí ó wá di ìlálè lónìí. 

Aráròmí 	Ìtàn fi yé wa wí pé, ogun ló lé àwon tí ó tèdó sí àdúgbò yí wá. Nígbà tí wón dé, ìlú pàmò gbà wón láàyè láàti dúró tì wón. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe ibè ní aráròmí. 

Tèmíoire	Gégé bí ìtàn ti so, eni tí ó kókó tèdó sí àdúgbò yìí wá láàti se àtìpó fún ìgbà díè ni sùgbón nígbà tí ó di wí pé ìwà sè dára, tí ó sì kó àwon ènìyàn móra, ni ó bá kúkú fi ibè se lé. Isé àgbè ni a gbó wí pé ó ma ń se, ó ń gbé ní òdò okùnnn kan kí ó tó di wí pé òun náà kó ilé ara rè. Ibi tí ó wá lo kó ilé ara rè sí ni ó pè ní tí èmí di ise ní ìlú pàmò. 

Ilé-tààrà 	Àdúgbò yìí ni wón ti kókó kó ilé pèlú búlókù ní ìlú yìí, ilé koríko ni ó pòjù láyé àtijó. Bí àwon ènìyàn bá ti wá ń sòrò, won yóò máa wí pé àwon ń lo sí ilé tààrà, èyí ni ilé-gidi, tí a kù fi koríko kó. Bí àdúgbò yìí se gba orúko nìyí. 

Ìsawo	Ìtàn fi yé wa wí pé, inú igbó ni àdúgbò yí télè kí ilé tí dé ibè. Igbó yìí ni wón ti ń se awo tàbí ńbo. Wón ma ń pe igbó yìí ni igbó-ìsawo sùgbón nígbà tí wón kó ilé ibè, wón wá ń pe ibè ní àdúgbò ìsawo. 

Bàkókò 	Emi tí ó te àdígbò yìí dú ni wón wí pé, ó wá láàti ilu won tí a ń pè ní òkù lébgbè é òmù-àran. Ìtàn wí pé, àdúgbò yìí ni bàbá yìí pé sí tí ó sì dàgbà kí ó tó kú. Nígbà tí, ó wà láyé, Baboko ni wón ma ń pè é, Léhìn tí ó kú tán, ni wón bá ń pe àdúgbò yìí ní Babuko. 

Ìsàlè-Òbà	Ìdí tí wón fi ń pe àdúgbò yìí béè ni pé, àdúgbò yìí jé ibi tí kòtò wà, ó sì tún jé wí pé, ó tèdó sí ibi àbáwo ìlú. 

Iwó-road: 	Àdúgbò yìí tèdó sí òpópó-ònà tí ó lo sí ìlú iwó-ìsin. Ìdí nì yìí tèdó sí òpópó-ònà tí ó lo sí ìlú iwó-ìsin. Ìdí nì yìí tí wón fi ń pe àdúgbò yí ní Iwó-road. 

Imojì 	Gégé bí ìwádìí tí mo se, orí-ilè àdúgbò yí ni wón ma ń sin òkú sí láyé àtijo. Orí-ilè yìí kò jìnnà púpò sí àárín ìlú kí ó tó di wí pé, ìlú fè dé ibè, ni wón bá kúkú ń pè é ní àdúgbò imojì. 

Odò-ilé	Ìdí tí àdúgbò yí fi ń jé béè ni pé, ó wà nítòsí Odò kan tí àwon ará ìlú fi ń foso. Odò yìí kò tóbi púpò, kódà, ó ma ń yaw o àdúgbò yìí ní ìgbà òjò. Ilé-Odò ni wón ma ń pè é télè kí won tó so ó di odò-ilé báyìí. 

Òkè-Àgbàá: 	Àdúgbò yìí wà láàárín gùn-gùn ìlú. Ìtàn wí pé, bí òjù bá ti ń rò, àgbàré òjò yíò kó ìdòtín láàti òkè yìí lo sí ìsàlè-òbà, àwon ará ìsàlè-òbà yóò wá a wí pé, àgbàrá òrè ló kó ìdòtí wá sí àdúgbò àwon. Kò pé púpò, ni wón bá ń pe àwon ará òkè yìí ní awon onílé ìdòtí àgbàrá-òkè. Àgbàrá-òkè yìí ni wón wá fi ń pe àdúgbò yìí kí ó tú di wí pé, ó ń jé òkè-àgbàrá tàbí òkè-àgbàá. 

Gbádéyan 	Kì í se orúko yìí ni àdúgbò yí ń jé télè. Ayédùn ni orúko jè télè sùgbón nígbà tí ó di wí pé, enì kan tí ó tip é lénu isé-oba ní ìpínlè Èkó tí ó jé omo ìlú yìí kú, ni wón bá ń fi orúko rè pe àdúgbò yí nítorí pé, ó jé omo bíbí àdúgbò yí bákan náà. Wón sì gba ìwé-àse rè láàti òdò ìjoba ìbílè won. 

Òkè-Òbà:	Àdúgbò yí wà ní òpópó-ònà tí ó lo sí ilu owó-kájolà. Ìwádìí kò fi ìdí rè mule. Ìdí tí wón fi ń pè é béè. 

Elékùú:	Àwon ènìyàn àdúgbò yí wí pé, ní ìgbà kan, tí àwon ènìyàn ma ń sepo, orí ni wón fi ma ń ru eyìn lo sí ìlú pàmò sùgbón nígbà tí ó yá, ìjá wà láàárín àwon ará ìlú méjèjì, ni àwon ará-òbà bá sòfin wípé enikéni nínú àwon Obìnrin kò gbódù lo se epo ní ìlú-pàmò mó. Àwon ará ìlú Òbà gba àwon Ègbìrà láàti bá won gbé ekùú ti won náà. Wón wá ilè sí èhìn odi ìlú, wón sì ń pe ibè ní ilè-ekùú. Sùgbón ní báyìí, wón ti kó ilé yí ni wón wá ń pè ní elékùú sùgbón èyí kò túmò sí wí pé, àwon àdúgbò yí ló ni èkùú náà. Àwon ekùú tí wón gbé nígbà náà wà níbè di ìsisìyí. 

Òfé-Àrán	Ìwádìí kù fi ìdírè mule pàtó bí àdúgbò yí se jé sùgbón àrí-gbámú ìtàn kan ni wí pé, àwon àdúgbò yí jé Ìbátan kan ni wí pé, àwon àdúgbò yí jé ìbátan kan ní ìlú òmù-Àrán nitorí pé, àdúgbò ń jé òfé-àrán. 

Eésabà:	Gégé bí ìtàn, oye ti won n je ní àdúgbò yí ni a ń pè ní eésabà. Ìdí nì yí tí wón fi ń pe ibè ní àdúgbò Eésabà . 

Agbo ilé-Òbà:	       Gégé bí ìtàn, agbo ilé kan soso ni ó ma ń je oba ní ìlú yìí. Orúko tí àdúgbò yìí ń jé télè ni òkè-ìsolà, ìran won lú ma ń joba ni ìlú yìí kí ó tó di wí pé, ó di agbo ilé-jagboolé báyìí sùgbón nítorí pé àwon ìran òkè-ìsolà ti je é fún òpòlopò odún séhìn, ní àkókò tí wón ń je é yìí, ni wón ti ń pè wón ní agbo ilé-oba. Orúko yìí kò sì yí padà títí di òní yìí bí ó tilè jé wí pé, kì í se àwon nìkan ló ń joba báyìí. 

Òkè-Ìdèra:	Gégé bí ìtàn ìsèdálè àdúgbò yìí, àdúgbò imojì ni àwon wònyí ti wá. Wón wí pé, enì kan tí ó so wí pé, òun kò le kó ilé sí ibi tí wón ń sin òkú sí ni ó sí kúrò ní àdúgbò imojì lo sí ibòmíràn tí ó sì pe ibè ní ibè ní ibi-ìdèra fún òun. Láàti ibi-ìdèra ni wón ti so ibè di òkè-ìdèra. Omo àdúgbò imojì ni àwon ará òkè-Ìdèra jé.

Àdúgbò: 	Òkè Àgbìgbò – Òkè Àgbò 
Ìtumò:		Ní ayé atijo, àdúgbò yìí wà nínú igbó kìjikìji, àwon eye àgbìgbò ni o sì pò si ibè. Àwon eye wònyí a máa fò káàkiri orí igi t’osan t’òru, bákan náà ni òkè pò sí àdúgbò ti a ń so nipa rè yìí. Ní ìgbà tì o se, àwon ènìyàn bèrè sì tèdó sí àdúgbò yìí, wón ń kó ilé mole síbè àwon eye wònyí kò fi àdúgbò náà sílè. Obinrin kan lára àwon ti ó kókó te ìlú náà dó ti orúko rè ń jé “Bèje” akíkanjú obìnrin ni, òun ni ó pa àwon eye àgbìgbò náà run. Wón sì so àdúgbò náà di oke àgbìgbò, ti wón wá ń pè ni “Òkè Àgbò” ni òde òní. Won sì máa ń ki àwon omo àdúgbò náà báyìí; 
	“Omo òkè àgbò Bèje” ìdí ni wí pé Òun (Bèje) ni o pa gbogbo àwon eye àgbìgbò náà run




#Article 6: Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ (452 words)


 
Mathew Àrẹ̀mú Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ GCFR
(;   (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹta ọdún 1937) jẹ́ gbajúmọ̀ àgbà olóṣèlú, ajagun-fẹ̀yíntí àti Ààrẹ àná orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Amos Àdìgún Ọbalúayésanjọ́ Obasanjo Bánkọ́lé, ìyá rẹ̀ sìn ń jẹ́ Àṣàbí.Ọbásanjọ́ jẹ́ ọmọ bíbí Òwu ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún 1958, bàbá rẹ̀ sìn kú bákan náà ní ọdún 1959. 

Wọn bi Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ni Ojo Kaarun, Oṣù Kẹta, ọdun mẹtadinlojilẹdẹgbẹwa (1937) fún Amos Obaluayesanjo Bankole ati Asabi lilu Ìbògùn Ọláogun. O jẹ akọbi awọ̀n obi re, wọn bi ọmọ mẹjọ tẹle, ṣugbon arabirin kan loni ti ò kù. O di omo orukan nigba ti o pe omodun mejilelogun. Ile iwe Saint David Ebenezer School ni  Ibogun ni  oloye obasanjo ti ka iwa alakobere( primary school education),ni odun 1948. Oloye Obasanjo  jé ògágun tó tifèyìntì  kúrò nínú iṣẹ́ Ológun ilè Nàìjíríà ati olóṣèlú  ọmọ ilè Naijiria. Oun ni Ààre ilè Naijiria lati odún 1999 títí dé ọdún 2007. Èyí ni ìgbà iketa tí Obasanjo yíò jé  Ààre orílè-èdè Nàìjírìa. O ti koko je Aare laye Igba ijoba ologun laarin odun 1976 sí 1979.

Lẹ́yìn tí ó fẹ̀yìntì, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àdáṣe tirẹ̀, ìyẹn ní iṣẹ́ àgbẹ̀. Ilé-iṣẹ́ àgbẹ̀ rẹ̀, (Obasanjo Farms) gbòòrò; tó fẹ́rẹ ma sí abala iṣé àgbẹ̀ tí kò sí níbẹ̀. Láàrín ọdún 1976 sí 1999, Obasanjo di ẹni mímọ̀ ní gbogbo àgbáyé. Akinkanju ni ninu eto oselu agbaye. O wa ninu awon Igbimo to n petu si aawo ni awon orile-ede to n jagun, paapaa ni ile adulawo. O je ogunna gbongbo ninu egbe kan to koriira iwa ibaje, iyen ni Transparency International. Ni odun 1999, Obasanjo tun di Aare alagbada fun orile-ede Naijiria, labe asia egbe PDP. A tun fi ibo yan an pada gege bi Aare lekeji ni 2003.. Okan pataki ninu awon afojusun ijoba Obasanjo ni igbogun ti iwa jegudujera (Anti-Corruption). Obasanjo gbiyanju dida ogo Naijiria pada laarin awon akegbe re ni agbaye (Committee of nations). O tun iyi owo naira to ti di aburunmu bi omi gaari se, gbigbowo-lori-oja (inflation) si dinku jojo. Iye owo afipamo-soke-okun (external reserves) Naijiria ti ga gan-an ni, o to $40 billion bayii. Obasanjo tun fidi awon banki wa mule gbogbo, pipo ti won po yanturu tele ti dinku, won o ju meeedogbon lo mo bayii. Eyi mu ki awon eniyan ni igbekele ninu fifi owo pamo si banki, won si tun le ya owo fun idagbasoke okowo won gbogbo. Lara awon eto ti ijoba Obasanjo n se ni tita awon ogun ijoba fun awon aladani (privatisation policy). Eto yii ku die kaato. Idi ni pe awon olowo lo le ra awon ogun bee, talika kankan ko le ra won.




#Article 7: Orúkọ Àdúgbò ní Ìjẹ̀bú-Rémo, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà (714 words)


Adugbò: 	Ìkénné 
Itumò:		Kòríkó ìkólé ti a ń pè ní ìken nì èdè Rémo ni ó wópò púpò ní agbegbe kan nì ayé ojoún. Nìgbà ti ó wà dì wí pé awoòn ènìyàn ń gbé abbègbè yìí bí ìlú ni won bá n so wí pé a tun ni ni ikèn néè o. èyí ti a wa se ìsúnkì gbólohùn náà sí ìkènné. 

Adugbò: 	Sònyìndo 
Itumo: 		Òkunrìn jagunjagun kan ni àdúgbò yìí ni ó ka ení rè kan mo ibi ti ó tí n kínrin aya re ken leyin nigbati aránbìnrin náà ń wè ní ile iwe. Inu bi okunrin yìí pàápàá nitori pe erúbinrin náà kò sá nìgbà ti é rí ì. Èyí mu kì ó bínu pa ìyàwó rè àti erúbìnrin náà Nìgbà ti won sì bì í ìdí ti ó fi se béè o sàlàyé pé ń se ni erú yìí sànyín-dó. Lati ìgbà náà ni a ti ń pe adugbo ohun ní sànyìndó. 

Àdúgbò: 	Ajíno 
Itumò:		Nì ayé àtijó, òwúrò kùtùkùtù ni won máa ń ná ojà agbègbè kan báyìí ni ìlè Remo. Kèrèkèrè, awon ènìyàn bèrè sí ìlé ní í ko sí ibi ofà yii, wón sì ń gbé ibe. Bayìí ni won se so ojà náà ní Ajino ti àwon ènìyàn sì so adugbo náà nì Ajìwo titi di ìsìnsìnyí. 

Adúgbo:	Ìmóbìdo 
Itumò:		Agbègbè ti a fi igi Obì pààlà tàbí sàmì sí. Àwon méjì ti ó ń jà du ààlà ilè ni o fa orúko yìí jáde nítorí awon tì ó nì ìlè salàyé wí pé ìgi obì ni àwon fì dó: ìlè àwon láti fi se idámo sí ilè elòmìíràn. 

Adúgbò:	Ìdótun 
Itumò:		Ní asìko ogun ti awon Yorùbá ń ti ibi kan dé ibì kan ni àwon kan ko ara won jò láti te ìlú tìtun dó. Léyin ti awon ènìyàn ti n pò níbe ni wòn wa so ìbùdó won yìí ní ‘Ìdótùn’ èyí ti ó túmò sí ibùdó tìtun. 

Àdùgbò:	Ìdómolè 
Itumò:		Nítorí àgbára àti ìwa ìpàǹle tàbí ìwà jàgídíjàgan okunrin kan báyìí ti a pe orùko rè ní Ìdó ni àsìkò Ojoun ni a se so oruko adugbo yìí ní Ìdómolè léyìn ikù okunrin yìí ni awon ènìyàn bérè sì fi okunrin yìí júwè adúgbò ré. Won a ní awon n lo sí Ìdó akínkayú  nì tàbí okùnrin imolè nì. Báyìí ni a kuku so adúgbà di Ìdómolè. 

Àdùgbó:	Ìròlù 
Ìtumò:		Léyìn ìgbà ti awon Yorùbá ken ti gbà latí parapò máa gbe pèlu ìrépò ni agbègbè kémo, yìí ni won kùkú wá pè è ní Ìrolù. Èyí túmo sì pé awon jo kò ó lù ni kí àwón tó ‘péjo síbè. 

Àdugbò:	Sáàpàdé
Itumò:		Àwon ìlu méta ni ó parapò sí ojú kan. Nígbà tí ó wà di wì pé okan kò yòǹda oruko tirè oún èkèjì ni wón wà yo nínú oruko awon meteeta;  làti yo sàaàpàde 
Ìsarà – láti ibi ni wón ti yo ‘sá’ 
Ìparà – láti ibi ni wón ti yo oá’
Odè – láti ibi ni wón ti yo dé’
Àpaofò sá- pà-dé ni ó wá di sápadè.

Àdúgbò:	Ìsarà 
Itúmò:		Òde nì awon tí ó parapò te ìlú ìsara dó. Kaluku awon ènìyàn wònyi ni won sì wá láti agbègbè òtòòtó. Nígbà ti ó wá dì wí pè ènìkan fé so ara re di olorí ‘àpàpàndodo ni won bá làá yée pe n se nì awon sa ara awon jo sibe! Ti won sì ‘sun orúkò náà kì di Isarà. 

Àdugbò: 	Ògèrè 
Ìtumò: 		Áwon tí ó ń gbé òkèèrè ni won ti kèrèkèrè só dì ògèrè. Láyé àtijó bì ó bà ti dì wí pé awon ènìyàn Remo bà fé lo sí ibi ti awon are ‘Ògèrè wá won a so wí pè awon fe ló sí agbègbè awon ara òkèèrè. Awon ènìyàn wònyí búrú púpò jù, won sì taari won sìwaju. Won á ni Okeere ni ó ye won. Nígbà ti ójú ń là nì wón bà so oruko ìlú yìí di Ògèrè. 

Àdúgbò:	Ajítaádùn
Itùmò:		Ìyá kan wà tí ó ń gbe àdúgbò yìí ni ayé ojoun. Kó sì ìgbà ti àwon ènìyàn dé òdò rè tí kìí ni oúnje àdi`dùn. Nìgbà ti ò dì wí pe gbogbo ènìyàn bere si fi ounje ìyà yìí júwè adúgbò naa ni wòn kúkú wa n pe adugbo yìí ní Ajítáádùn (Ají-ta-dídùn). 

(see Yoruba Place Names)




#Article 8: Orúkọ Àdúgbò ní Ila, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Nàìjíríà (477 words)


Ilé-Àwòrò-òsé: 	ìtàn ti a gbo nipa adugbo tabi agbo-ile yì so fun wa pe ilé. Àwòrò-òsé je ibi pàtàkì ti won ti ma n se orò, ò sì tun je ile-Olorisa. 

Ìlé-Olúóde:                    A gbó pe ode ni ìran àwon wònyí n se láti ìgbà ìwásà. Ibe sì nì Olórí àwon ode n gbe. 

Ile-Olutojokun: 	   Àwon ìdílé yi ni o ma ń joba ni ìlú-ìlá-òràngún. 

Ile-Olorirawo: 	Adugbo ati Agbo-ile ni eyi je. Ìtan ti a si gbo nipa won núpé ìbè ni Olori awon awo tedo sì. 

Ìjímògòdò:  	 	Akoni èdá kan ni o je, jagunjagun sin i pelu, oun lo te àdúgbò yì dó. 

Ìgbonnìbí:	jé òkan nínú àwon oba akíkanjú ti o wolè ni ìlá. Níbi ti o wolè sin i a n pe ni Ìgbonnìbí loni yìí. 

Ajagúnlá: 	Ode ni ajagunle nigba aye re, o si je jagunjagun O si bínú wolè lo ni. 

Ògbún Ìperin: 	 Nibi ti a pa Erin sin i a n pe ni ìperin

Òkè-Èdè: 	túmò si ibi ti a pa elédè si 

Ògbún ìsèdó: 	Eyi tumò si ibi ti isé sodo si. Agbègbè yin i ìlú ma n lo gégé bi ojúbo isé. 

Ilé- Olóòsà! 	A gbo pe wón ma n ko òrìsà pamó sì adugbó yií.

Òkè-Alóyin: 	Odò kan ti o n san ni àdúgbò yì, wón ma n lo omi yì láti fi se ìmúláradá àwon omo wéwé. 

Ilé-Agbérùkóó:  A gbó pe ìdílé yì ma n gbe èrúkó tà, ni won fi ma n pé wón ni agbérùkóó. 

Ilé-Alápìnni:       Ìtàn so pe idile Oloje tabi eleegun ni won je. Àwon sin i Olórí gbogbo àwon eégún. 

Ilé-Ìyálóde: 	Obìnrin ni o te idile yi do, O gbé fáàrí O sit un je akikanju obinrin láàrin ìlú. 

Ilé-Akogun: 	Jagunjagun naa ni o te adugbo yi do Akogun sit un je Oloye pàtàkì ni ìlú 

Ilé-Òjá-bèbè:   Isé abèbè ni wón yàn láàyò ni àdúgbò yì. 

Ìlé-Agbèdègbede: 	Àwon ìdílé Alágbède ni àwon wonyi n se. 

Ilé-Òdú: 	Èfó òdú ni won ma ngbin ni akoko ti won so orúko ile yii. 

Ilé-Ajengbe: Isé Ìsègùn ni won ma n se ni ìdílé yi. Won sit un je akoni èdá kan.

Ilé-Obajisun: 	Ìdílé oba ni won jé won sì tun je Olóyè ìlú. Èfó òsùn pò púpò nì àdúgbò yìí 

Ilé-Onílù: 	Àwon àyàn ni o te ile yìí do, ìdílé onilu ni àwon wonyi je 

Ilé-Awúgbo: 	àwon ìdílé yi saba ma n gbìn erè kan ti a n pen i awúje, èyítí o ti gbilè ti won fi n pe won lórúko loni. 

Ile-Èelemukan : Èkan po ni àdúgbò yìí 

Ìle-Obajoko: 	    Idile yin i won ti ma n sábà fi Oba je, eyìti a mo si kugmaker. 

Òkè-Ògbún:        Nígbàtí ìlú ko ti làjú àdúgbò yin i wón ma sábà ko gbogbo àwon òhun ìdòtí pamó si, o si je ògbun eyìti wòn so di oke-ògbún lòni yì. 

Ilé-Àtèéré

Ilé-Àbálágemo:	 

Ilé-Asóyòò:

Ilé-odogun: 	Ìdílé àwon jagunjagun ni won.




#Article 9: Orúkọ Àdúgbò ní Ìjẹ̀bú-Igbó, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà (2975 words)


Àdúgbò: 	Òkè Àgbìgbò – Òkè Àgbò 
Ìtumò:		Ní ayé atijo, àdúgbò yìí wà nínú igbó kìjikìji, àwon eye àgbìgbò ni o sì pò si ibè. Àwon eye wònyí a máa fò káàkiri orí igi t’osan t’òru, bákan náà ni òkè pò sí àdúgbò ti a ń so nipa rè yìí. Ní ìgbà tì o se, àwon ènìyàn bèrè sì tèdó sí àdúgbò yìí, wón ń kó ilé mole síbè àwon eye wònyí kò fi àdúgbò náà sílè. Obinrin kan lára àwon ti ó kókó te ìlú náà dó ti orúko rè ń jé “Bèje” akíkanjú obìnrin ni, òun ni ó pa àwon eye àgbìgbò náà run. Wón sì so àdúgbò náà di oke àgbìgbò, ti wón wá ń pè ni “Òkè Àgbò” ni òde òní. Won sì máa ń ki àwon omo àdúgbò náà báyìí; 
	“Omo òkè àgbò Bèje” ìdí ni wí pé Òun (Bèje) ni o pa gbogbo àwon eye àgbìgbò náà run.

	Ìtumò: 		Ní ìgbà láyéláyé ni ìlú Ìjèbú Igbó, ti wón bá ń jagun, ìbi ti ogun ti má a ń le ni won ń pè ni Jàpara, nitorí wí pé ni ibè ni wòn ti máa ń lérí mó ara won pé a o pa ara wa lónìí ni, won a sì jà titi won ó fi férè pa ara won tán. Ní gbà ti won wa bèrè sì te ibè dó, àwon àgbà wá so orúko àdúgbò ni “Jàpara” oríkì “Jàpara a kó obì se esà, a kérógbó bo ojú ogun. Ìjà ìpara – Jàpara”. 

	Ìtumò:	    Àwon Yorùbá máa ń pe àdúgbò ní “itún nígbà míràn, àdúgbò ti won ń pè ni itún yìí wà ni Ìjèbú Igbo, se ni àwon ara àdúgbò dédé jí ni ojo kan, won rí i ti omi ti di odò nla sí apá kan itún won. Káwí káfò, àwon ara itún bèrè sì ni pa eja nínú odò náà. Báyìí ni wón so àdúgbò náà di “Itúndòsà”. Won a sì máa pe àwon ti won wá lati àdúgbò yìí ni “Omo Ìdósà maye”. 

	Ìtumò:	      Àdúgbò yìí jé ibi ti igi igbá ti máa ń so, igi igbá pò sí àdúgbò yìí tó béè gee, ti awon eniyan sì máa ń seré lábé rè. Bí enikan báni àlejò ti ó wá a wá, won a ni kì won lo wòó ni abé igi igbá àìré- Ìgba ti won kò tii ré kúrò lórí Igi. Won wá so àdúgbò náà di Igbáìre. 

	Ìtumò:	     Ibi ti ojó máa ń wò si ni won ń pè ni Ojó wò ti o wa di Òjóò loni yìí. 

	Ìtumò:	       Itún ni èdè Ìjèbú je “Agbo ilé”. Ó sì jé ibi ti àwon alágbẹ̀dẹ pò sì, bí àwon enìyàn bá sì fé júwe àdúgbò lati agbo ilé yìí, won a ni e lo sí itún alágbède, tí ò sì di itúnlágbède di oni yìí. 

	Ìtumò:	        Ní ayé àtijú won máa ń mo sìgìdì nú ni àdúgbò yìí, àwon ènìyàn ati àwon Ode, Babaláwo ati lébo lóògùn a máa be sìgìdì lówè fún isé ibi, a sì je isé náà fún won. Tí sìgìdì bá padà dé, won a sì se ètùtù, won a fún-un ni epo mu. Nítori ìdí èyí ni won se ń pe àwon ti won tèdó sí àdúgbò yìí ni 

Omo Asìgìdì mode,
Omo Mode ráàtà
Omo atà je epo má pòn ón.

	Ìtumò:	  	Ibi ti ìgi àgbon pò sí ni àdúgbò yìí, igi àgbon yìí pò to béè ti o fi je wí pe kò si ílé ti e kò tin i ríi. Béè sì ni imò wà lórí rè lópòlopò. Àwon eniyan Ìgbà náà sì ń pe ibè ni Imò àgbon, ti awon enìyan ode òní sì so ó di “Imàgbon”

	Ìtumò:	 	Àdúgbò yìí je ibi ti ìgi òro pò sí. Àwon ènìyàn a sì máa je òro yìí, Imó ni agbègbè ibi ti òro yìí ń so sí jìngbìnni. Àwon ènìyàn wá so àdúgbò náà di imó òro ìmòro ni won ń pe ibè lónì yìí. 
Oríki! “Imòro àláà, a rérun (enu) gé òrò bí òbe”

	Ìtumò:		Ní ìgbà Ìwásè, Efòn ńlá kan wa ni Àdúgbò yìí ti o máa ń dààmú àwon ènìyàn ti won bá fe bojá lo sí oko. Odò nlá kan sì wà ni orí òkè ibì ti Efòn yìí máa ń lúgo sí. Bí àwon eniyàn ba ń darí bò lati oko won máa ń bu omi mu ninu odò yìí. Tí enikeni bá se ohun míràn yàtó sí mímu nínú omi náà, Efòn yóò fi imú onitòhún fon fèèrè. Sùgbón ti Efòn wáà bá ti rí wí pé won ń mu omi ni, kì yóò se ohunkóhun fun irú eni béè, won yóò sì la omu náà  dúpé lówó Olódùmarè wí pé àwon gun òkè Efòn, ati wí pé omi ti àwon mu ninu odò ti re Efòn té lati má se ìjàmbá titi àwon fi gun òkè. Won wa so àdúgbò náà di òkè Odò re’fòn teti àgékúrú rè wá di “Òkè-erèfon”

	Ìtumò:		Ládugbó ni èdè Ìjèbú túmò sí ìkokò ni Yorùbá àjùmòlò. Ìtàn sò wí pé Odò ńlá kan wà ni àdúgbò yìí ti ìkòkò (ládugbó) àbáláyé kan wà  nínú rè. Tí àwon enìyàn bá fé pon omi múmu, nínú Ládugbó yìí ni won ti máa ń pon-ón. Sùgbon bi o ba je ki a fo aso, ìwè ati ohun miran ni won a lo omi tí ó yí Ládigbó náà kà á. Nígbà ti o se won se àdúgbò náà di “Odò-o-Ládugbó” ti àgékúrú rè wá di Lágugbó. 

	Ìtumò:		Ní ìgbà láyéláyé, Bàbá kan wà ti wón ń pè ni Òsígbadé Olómo òdo-nitori kò mo iye omo ti  o bi, sùgbón ó jé onísòwò eran Màlúù. Ó ní àgbàlá ńlá ti ó máa ń da eran sí lati je pápá, kò si ohun òsìn míràn ti ó ń ba àwon màlúù náà gbé ni àgbàlá náà. Àgbàlá ńlá yìí ni àwon Ìjèbú máa ń pè ni Ugà eran ti o wa di “Igbà Eran’ lónìí	

	Ìtumò:		Ní ayé àtijú won a máa sa ìgò jo sí àdúgbò yìí fún fífo lati tà á. Ìtán so wí pé èyìn odi ìlú ni ibè jé, wón tún máa ń da àwon àkúfó ìgò jo síbè, àwon tí ó bá jé odùndùn, won a fó won sí wéwé. Ìgbà tí ó se, àwon ènìyàn bèrè sí tèdó sì àdúgbò yìí. won wa ń pe ibè ní “Abúle Ìdágòlu” ti o wa di “idágòlu”lónìí 

	Ìtumò:		Inú Igbó ni àdúgbò yìí jé nígbà àtijó, Igi ti o máa ń so èso isin ni ó pò nínú igbó yìí jù. Àwon eniyàn a máa sinmi labe àwon igi náà bí won bá ń ti ònà oko tàbí odò bò. Ìgbà tí ó se, ìgbó náà bèrè sí súnmó abúlé, nìtori àwon ènìyàn ń tèdó sí etí bè. Tí àwon àgbàlagbà ní abúlé pàápàá àwon Okùnrin bá jeun tan won a “tàtaré”sí abé igi yìí lati lo gba atégùn, ìbi ti wón bá ti ń tayò, tí won ń “tàkúrò so” won a wà níbè fún ìgbà pípé. Enikéni ti ò ba ni àlejò, won a ni kí ó lo wo eni ní ó ń bèèrè ni ìdí igi isin tí ó wa di “Ìdí Isin” lónìí. 

	Ìtumò:		Ní àdúgbò yìí, ìwòn tì àwon alágbède ro ni wón ń lò lati máa fi se òsù wòn kòkó. Gbogbo àwon onísòwò kòkó pátápátá ni won máa ń pàdé ni àdúgbò ti a ń so yìí lati wa rà ati ta kòkó won níbè. Ní ìdí èyí, won so ibè dí ìdí scale ti wón ti ń won kòkó, ti àgékúrú rè sì di “Ìdí scale” lónìí

	Ìtumò:		Ní ìgbà atijo, àwon osó ati Àjé kò fi ìse won bò rárá, isé ibi won kò ni àfìwé, sùgbón àwon Àgbààgbà pinnu lati da sèríà fún enikeni ti owó won bá tè. Tí won bá mú enikeni ti o ni osó tabi Àjé ibi tì wón ti yàn sótò, ti won ti ń so òkò pa wón ni wón ń pè ní òkè ti osó pari emir è sí, tabí òkè tie mi osó pin sí. Èdè àdúgbò Ìjèbú ni “pen” – Yorùbá àjùmòlò ni “Pin” Nígbà ti ojú ńlà ti àwon enìyàn ń kólé sí bè won wa so àdúgbò náà dí “Orí òkè osópen”ti àgékúrú rè wá di “ÒKE SÓPEN”

	Ìtumò:		Ìtàn so fún wa wí pé àdúgbò kan wà ti ogun máa ń jà wón lópòlopò, bí ogun bá sì ti wolé tò wón, won máa kó won lérú ni. Ní ìgbà ti o se àwon àgbaàgbà ti won kù ni ìlú náà fi orí kan orí won sì to “ifá” lo lati bèèrè ohun ti won tè se ti agbègbè àwon kò fin i parun lowo àwon ti o ń ko won lérú. Ifá ni kì won bo Odò ti o nà ni ìlú won, kì won sì máa pon omi Odò náà sí ilé, gbàrà tì won bá gbó wí pé ogun wòlú, ki oníkálukú bu omi náà mu. Láìpé Ogun miran wolé tò wón, wón se bi ifá ti wí, wón jagun won sì ségun. Wón wá ni odò ni awon fí ségun, ti ó wá di “Odò-rámúùségun”

	Ìtumò:		Itún ni èdè ìjèbú túmò sí “Agbólé”.  Àwon jagunjagun ìlú ni ibi ti wón ti máa ń pàdé dira ogun ti won ba fe lo sí ojú ogun. Àkókò ti won bá fe lo jagun nikan ni won máa ń pàdé ni ibè. Tí àwon ènìyàn tì kò mo ohun ti o ń selè télè bá ti ń ri àwon jagunjagun  ti won ń dé sí itún yìí, won a ni àwon Ológun ti dé sí itún won. Won wa so ibè di “itún Ológun” ti àgékúrú rè wa di “itún Lógun”. 

	Ìtumò:		Odò kan wà ni àdúgbò kan, ti èso Òyìn máa ń so repete ní bèbè rè. Àwon àgbàgbà a máa jókòó ta ayò ni abé àwon igi yìí, won a si máa fi èso òyìn panu bí ayò bá ń lo lówó. Báyìí ni wón so ibè di “Odò ti o ń so èso Òyìn”  tí ó wá di “Odò asoyìn”. 

	Ìtumò:		Ní Ìgbà Ìwásè orúko àdúgbò ńlá kan ni ìjèbú Igbó ni “Orímolúsì”. Sùgbón, gégé bi a ti mò wí pé àwon Yorùbá máa ń ye ìpún tabi Àyàmó wò (ori). Àwon ènìyàn àdúgbò náà a da Obì won a wí pé “Orí ìwo lo mo Olùsìn, Olùserere, je kí ìgbésí ayé mi dára o. Báyìí ni eni ti  o kókó je Oba ìlú náà wí pé òun ni Olórí ìlú, òun ni orí fún àwon ènìyàn ti o wà ni ìlú gbogbo ènìyàn yóò sì ma pe sin òun ni. Ní ìdí ènìyàn, won so Oba náà di “Orí-mo-Olùsìn” ti ó di “orímolúsì” lónìí.

	Ìtumò:		Ní ayé atijo okùnrin kan wà ti o kúrò ni àárin ìlú lati máa lo gbé inú Igbo nitori wí pé o ti ya wèrè, wèrè yìí pe lára rè to béè gè é ti o gbé òpòlopò odún nínú igbó náà. Ní ìgbà míràn ti kinní òhún bá wò ó lára tán, a bèrè sí yà èèpo igi a máa rún-un wòmùwòmù; Àwon èrò ti ó ń lo, tó ń bò lónà oko máa ń wòó tàánú-tàánú; nígbà tì o yá kò jo wón lójú mo. Wón wá ń pè é ni wèrè ti ó ń bó igi je, òun a sì máa le won bí wón bá ti pè é béè. Sùgbón nígbà tì àwon ènìyàn bèrè sí ko ilé ibè, won wa so ibè di àdúgbò wèrè tò ń bó igi je, àgékúrú rè wá di “bógije”

	Ìtumò:		Àwon eléégún ati àwon abòrìsà ìlú máa ń se ayeye Odún won ni Odoodún ni ayé atiju. Orí Òkè ńlá kan ni won sì ti máa ń pa Idán Orísirísi fún àwon ara ìlú. Nígbà tì o se àwon ènìyàn kólé sí Orí Òkè yìí, won sí so àdúgbò náà di “Orí Òkè Idán pípa” tó wa di Òkè Idán” lónìí. 

	Ìtumò:		Ní ìgbà ti àwon ènìyàn bá je Oyè tan ní ìlú, àwon Ìjòyè a sì wá sí Iwájú ìta àafin Oba pèlú àwon ebí, ara ati òré won-lati wa jó, lati se àjoyò pèlú Olóyè tuntun. Nígbà ti ó so àwon ènìyàn féràn lati máa se ayeye orísirìsì ni iwájú ìta àafin Oba nitori pé enikeni ti o ba fe se ayeye ti Oba bat i gbó nipa rè ni yóò ri èbùn gbà lówó Oba. Báyìí ni won bèrè sì lo ìtà Oba fun ayeye, bí won ba sì fé se àpèjúwe ìbì ti won yóò ti se ayeye fun àwon ará, òré, ati ojúlùmò, won a ni kí wón wá bá won se ayeye ni iwájú ìta Oba. Níbo ni e o ti se ayeye? “iwáta Oba ni” kèrèkèrè wón so àdúgbò náà di “Iwátá”. 

	Ìtumò:		Kí o tó dì wí pé a gba òmìnira, àdúgbò yìí ni wón ti máa ń ta erú, tì àwon ènìyàn sì ti máa ń ra àwon erú lo sí “Àgbádárìgì”. Nígbà ti ó se Ojà erú títà sá féré ni orí òkè yìí, àwon Olùtajà a sì wá so ibè di Òkè-Ererú 

	Ìtumò:		Ní ìgbà àtijó, ti wón ba fe fi Oba je ni ìlú, àdígbò yìí ni won ti máa ń gbìmò eni ti Oba kan, lati ìdílé ti Oba kan. Tí ètò fífi Oba je yìí bá takókó ti o díjú tan pátá, àwon àgbààgbà afobaje á kó ara won lo si Ori Òkè kan lati lo tú gbogbo ohun ti o bá dìju palè. Ní orí òkè yìí won a dìbò, won a dá ifá, ohun gbogbo yóò sì ni ojútùú kì won tó padà sí ilé. Nitorí ìdí èyí ni wón se so òkè náà di “Òkè Tákò” Òkè ti a ti ń tú ohun lèrò ti ó ta kókó. 

	Ìtumò:		Léyìn Ìgbà ti àwon afobaje bá ti ri ojùtùú enì ti yóò joba, Okan won a balè, won a wá gun orí òkè kan lo lati lo gba atégùn sára, nìbe wón a mu emu, won a sì máa wí  pé àlàáfíà ti dé bá ìlú. Orí òkè yìí ni o di àdúgbò ńlá lónì, ti won so di “Òkè àlààfíà”. 

	Ìtumò:		Orí òkè kan wà ti àwon àlejò ti wón ba sèsè wo inú ìlú ti máa ń lo búra wí pé àwon kò ni se búburú sí Oba ati àwon omo onílùú Orisìrìsi àwon èyà enìyàn ni won máa ń pàdé ni orí oke yìí ni asìko ìbúra náà, Ègbá, ìbàdàn Òyó. Hausa, Ìgbò, abbl. Orò ajé ni ó gbe  won wá sí ìlú náà (Ìjèbú Igbó). Ní gbà tí ó se Oba se akiyesi wí pé gbogbo àwon àlejò wònyí ń se bí omo ìyá kan náà, a fi bi eni pe ile kan ni gbogbo won ti wá. Láì fa òrò gùn, àwon àlejò yìí ń pò sí, won ń bí sí i, won ń rè sí, ìlú sì kún to béè géè tì onílé kò mo àlejò mó. Ní ojo kan, Ob ape gbogbo àwon àlejò ìlú jo tèbí tàráawon, Ó sì so fún won wí pé òun ríi pé won ni ìfé ara won, lati òní lo, òun (Oba) yàn-ǹ-da orí òkè tì wón tì bura ni ojósí fún won, ki won ko àwon enìyàn won ki wón lo tèdó sí ibè. 
	Gbogbo àwon àlejò wònyí sì dupe lówó oba. Won sì se bi Oba ti wí. Lati Igba náà ni won ti so àdúgbò náà di orí òkè ìfé ti o di “Òkè Ìfé” loni yìí. 

	Ìtumò:		Ní ayé atijo, ìko tìí wón fi ń hun eni ni ó pò ni àdúgbò yìí. Bàbá kan wà ti o je ògbóǹtagí onísègùn; ìko ni o máa ń fi ríran sí àwon ènìyàn. ohun kohun ti ènìyàn bá bá lo si òdò rè ìko yìí ni ó máa kó kalè ti yóò sì máa ba sòrò bí ènìyàn; sùgbón ohun nìkan ni o máa ń gbo èdè tì ìko náà ń so, òun yóò wa túmò fún eni tí ó wa se àyèwò. Ní ìdí èyí, won so “Baba’yìí ni “Ati ìko ri ohun ti o ń sele si ènìyàn” ti o di “Atìkorí nigba ti awon ènìyàn tèdó si àdúgbò náà. Lónìí Atìkòrì ni àwon ènìyàn ń pè é. 

	Ìtumò:		Ní aye atijo, Okùnrin ken wà ni ìlú ó je alágbára atì alákíkanjú ènìyàn. Orúko rè ń jé “omódóríoyè” Ó se isé takun-takun fún ìlú Baba rè, ò sì jè omo Oba”. Ní ìgbà tì Oba tó wà lórí Oyè wàjà, Ìdílé rè ni Oba kàn òun sì ni o ye ki wón mú, nínú ìdílé náà. pàápàá tì o tún jé alágbára ènìyàn. 
	Àwon afobaje gba àbètétè lowo elòmíràn won sì kojú “Omódoríòyè” sóòrù alé. Kàkà ki ilè kú, ilè á sá ni Omódérìoyè fi òrò náà se ati bi a se mò wí pé àwon alágbára kò kò Ikú Omodorioye se Okunrin, ò sì pinnu wí pé bí won kò tilè fi òun joba won kò ni gbàgbé òun láyéláyé. Báyìí ni “omódóríoyè tí àwon ènìyàn ti se àgékúrú orúko rè sí “Dóróyè” télè, di odò ńla kan sí odì ìlú náà, ó sì fi ohùn sílè wí pè, Oba tí ó ba je ti kò bá mu nínú omi náà kì ni pe lori oyè tí wón fi je, atì wí pé eníkéni tí ó bá ń mu omi náà yóò di alágbára. Bíí àwon ènìyàn se bèrè sí ni tèdó si eti odò náà ni yìí, ti won sí so àdúgbò náà ti “Odòdóoróyè” iyan nip e “Odò Omódórí oyè”. 

	Ìtumò:		Léyìn Ìgbà ti awon Gèésì dé, ti Okò ayókélé ati irúfé okò mìran bèrè si won orile èdè wa, àwon Okò akérò tì o ba wo ìlú ìjèbú Igbó ni ibikan ti won ti gbódò ja awon èrò won sile, ti won yóò sì kó àwon èrò miran. Ibè ni won ń pè ni station, Ibikiri ti ènìyàn bá ń lo lati ìjèbú Igbó, Ibe nikan ni e ti lè ri oko wò. 




#Article 10: Orúkọ Àdúgbò ní Àkùngbá-Àkókó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà (673 words)


Awon itumo awon oruko awon adugbo ilu Akungba-Akoko, ni Ipinle Ondo, Naijiria.

ÀKÚNMI :	ìsèlè tí o mu ìpayà wa sele ní àdúgbò yi ti o mu ki ìpàdé pàjáwìrì wáyé nílé Oba. Nígbà tí onísé yoo jísé fún oba ohun tí o kó so ni pé àkún mi eyi tí o túmò sip e Àkùn ni àdápè Àkùngbá sugbon nígbà tí ìsèlè yi mi gbogbo Àkìngbá ni won fi n so pe Akun mi ti won si waa so adugbo naa ní Akunmi lati ìgbà naa ni won ti n je olóyè ti a n pè ni Alákúnmù. 
ÒKELÈ :	Àwon jà-ǹ-dù-kú ènìyàn ni won fe àdúgbò yìí dó; Awon alo-kólóhun-kígbe, olè ati ìgára. Ibi ti won si tèdó si je ibi ti o ga sókè. Bi enikeni ba fee lo sí àdúgbò yi won a ni o lo òkè olè. Òkè olè ni won so di òkelè di òní-olónìí. 

AKÙWÀ:	Ìgbàgbó awon ènìyàn nip é awon to wa ni àdúgbò yi je òdàlè, atan-ni-je Àgàbàgebè ènìyàn ni won. Èdè Akungba ni Akuwa eyi ti o túmò sí pe ìwà nikan ni o kù won kù. 

ÙBÈRÈ:	Eni ti o kókó kó ilé ni ilú Àkùngbá Ùbèrè ni o ko o sí. Ibè ni àwon ènìyàn sì gbàgbó pe Àkùngbá ti se wá Ibè ni olóyè àkókó ti je. Idi niyi tí wón fi ń pè é ni Ubere-ibi ti nǹkan ti bèrè tàbí sè. 

OKÙSÀ:	Orúko eni tí o kókó kó ilé ni àdúgbò yí ni a fi n pèé. Òhun ni won n pè ni Okusa. Ìdílé re ni won ti n je oye olókùsà. 

ÌBÀKÁ:	Òbe ìrelé ti bàbá àgbà kan lo lati ségun àwon òtá ni àwon omo-omo rè ri ni òkè àjà ti won n pe ni ìká ni àkùngba. Lati igba yen ni won ti n pe àdúgbò náà ni ìbàká. 

ÒDODÒ:	Àgbàrá san gba èhìnkùlé àdúgbò yi kojá. Gbogbo Ilé ti o wa ní àdúgbò yi ni won si n pè ni òdodò eyí tí o túmò si ode (ile)-odo Òde-ode tasí Ododo. 

ÒLÁLÈ:	Oloye ti o koko je ni àdúgbò yi ni o létòó lati máa pín ilè fún àwon ènìyàn. Ilè ni Akungba n pè  ni alè. Ìdí nìyí tí won fi n pea won to leto lati tai le tabi latí pín ìlè ni alale ti adugbo won sì n jé Olale. Ni adugbo bi ni won sit i n je oba titi ji oni-Oloni eyi wá wà ni ìbámu pèla òrò Yorùba tó so pé Oba ló nile. 

AROKUNPANLE :	Oke pupo wa ni adugbo yi to béè gee bi ènìyàn ko ba jeun kánú dáadáa yoo maa fidi wo kó tó wolé míràn ni. Itumo arokunpanle ni afìdímólè. 

APOLE:	Eni ti o koko te àdúgbò yi do maa n mo ògiri yi àwon ilé ibè po. Awon ilé tí a bá sì mo ògiri yip o ni a n pè ní apolé lati ìgbà náà ni wón ti ń pe àdúgbò yìí ní apolé.

ÀLÙJÙ:	Ni àràárò ni baba arúgbò kan máa n fi ìlù ji awon ara adugbo yòókù. Nigba ti won bi baba yi léèrè èrèdí to fi n lu ilu o ni o n mu oun larada ni. Lati igba naa ni won ti n pe àdúgbò yìí ni àlùjù. 

OKOGBO:	Inú igbó ni bàbá àgbàlagbà ti o te àdúgbò yi do ń gbé kí àwon ènìyàn to de ba a nibe ìdí nìyí ti awon ènìyàn fi n pe àdúgbò náà ni okogbó.

ODÈÈGBÒ:	Àwon to kókó te àdúgbò yí dó máa n da agbàdo sise sinu omi to n sàn to wà níbè. Àgbàdo yìí ni won n pè ni ègbo tì won sì ń pe odò yìí ní odo-egbo ti wón sì so àdúgbò yin i odèègbo. 

ÒNÀKÈ:	Ile pupa àti òpòlopò òkìtì-ògán wa ni adugbo yìí. Òpòlopo ona ni o sì já si ìlú yìí. Ona ti o wà ni ese òkè yi ni eni ti o te e dó ń gbé ìdí nìyí ti won fi n pe àdúgbò yí ní ònàkè. 




#Article 11: Àwọn àdúgbò ìlú Ìjẹ̀bú-Òde (2517 words)


 1.	Àdúgbò:  Itaolówájodá 
	Ìtùmò: 	   Àdúgbò yìí ni àwon ìjòyè Oba ìlú yìí tí a ń pè ni olówá tè dí, ti won si ń se ìjoba lórí àwon ènìyàn tó wà ládùgbó yìí 

	Ìtùmò: 		 Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà alá wà tétètélè, Àwon àwòrò òrìsà yìí ni ó te àdúgbò yìí dó. 

	Ìtùmò: 		Igi obì púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí bá nígbà ti wón fé te ìbè dó.

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà òsù wa. ni tori pe ibí yìí ni wón ti ń bo òrìsà yìí ni wón se ń pe e ni ìta òsù. 

	Ìtùmò: 		Igi òpe púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí ban i ibi yìí nígbà tí wón fé te ibè dó

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni òkan lára àwon akoni ode to máa ń ye ojó ogun ti awon olóde yòókù bá ti dá síwájú tè dó ìdí niyìí tí won fi ń pe àdúgbò yìí ni Ayegun. 

	Ìtùmò: 		Awon ounje orisirisi tí a dì sínú àpò bii àgbàdo, ìyo, ni àwon ara àgbègbè máà ń gbé wá si àdúgbò yìí wá lati tà kí ó tó di àdúgbò. Wón si máà ń na ojà ni àdúgbò yìí títí di òní yìí . 

	Ìtùmò: 		Isé ìkokò mímo ni isé àwon to té àdúgbò yìí dó. Díè lára àwon omo omo won si ń se ìsé yìí 

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni àwon Olósùgbó ti máà ń se ìpàdé. Níbè ni ilé ìpàdé wón wa, kí ó tó di pé won te ibè dó. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni ójúbo osi esi wà télètélè kí o to di pé won te ibè do tí o si dí àdúgbò ojúbo osi yìí si wa níbè títí dònìí. 

	Ìtùmò: 		Àwon Opó ni won máà ń na ojà yìí ni alaalé. Òríta ti wón ń náà yìí ni o di adúgbò, ti wón si ń pe ni ìtà opó. Wón si máà ń ná ojà alé ni àdúgbò yìí títí dònìí 

	Ìtùmò: 		Okunrin kan tó mú opà dání ló te apá ibí yìí dó. Ìtàn so fún wa pé àpá ase Oba ìlú ibòmíìràn ló mu dàni nígbà tí o ń bo, àwon kan tilè so pé Àremo oba ìlú náà ni. Nígbà tí o, fé te àdúgbò náà do ó mú òpá yìí dá ni, Ìdí niyìí tó fi je pé won ń je oba ni àdúgbò náà títí di òní yìí 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé omi nigbogbo àdúgbò yìí teletélè kí ó to dí pe wón te ibè do. Okunrin akoni ti a ń pè ni òró ni o pé ofò tí ó sì le omi náà lo. Ìdí nìyìí ti a fi ń pé àdúgbò náà ni Ìtóòró. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni òkan lára àwon akoni tó te ìlú yii dó kokó dúró si kó tó dip é ó wo àárin ìlú lo. Nígbà ti ijà dé láàrin òun àti àwon tí wón fo wo ìlú yìí, o bínú pàdà si ibi yìí o si wolè. Ìdí niyìí tí wón fi ń pe àdúgbò naa ni Olóde. Oórì okùnrin yìí si wà níbè títí dòníì. 

	Ìtùmò: 		Eégún kan ti won ń pè ni obrinrin ojòwú ní o te ibí yìí dó. Èégún Odoodún ni eégún máà ń jáde ni àdúgbò yìí títí donii. Ìdí igi ìrókò ni won fi se ojúbo eégún yìí Igi ìrókò yii wà níbè títí dónì yìí. 

	Ìtùmò:     	Isé epo ni àwon to te àdúgbò yìí yàn láàyò léyìn tí wón ti dó síbè. Bí o tilè jé pé won kò se ise epó níbè mó, won si ń ná ojà epo níbè titi dò níí. 

	Ìtùmò: 		Lára àwon ìjòyè oba Gbélébùwà àkókó tí won kò fara mo on pé kí wón pa Oba náà ni won wa te àdúgbò yìí dó léyìn ti wón kúrò ni ààfún. 

	Ìtùmò: 		Oríta yìí ni àwon ìjoyè Oba Gbétebùwá àkókó péjo sí láti bi ara won ohun ti o ye kí àwon se fún oba náà. 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so gún wa pé nígbà tí wín fe te ibí yìí dó, wón bá òrìsà kan níbè tó dé adé sórí tó sì fi èwòn onírin se ileke owó àti tí esè. Ìdí ni yìí ti à fi máà ń yan Oba láti ìdílé enití ó te àdúgbò náà dó. Ìdílè yìí náà tílè ni ààfún tí a ń pè ni ààfin Òba ìdéwon. 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé bí ó tilè jé pé èrúktí o té àdúgbò yìí do kii se àfín, sùgbón gbogbo àwon omo tí won bi láti ìdílè enití o te àdúgbò náà do je àfín. Nígbà ti won lo bi ifá wo, Ifá ni ki won máà bo Obàtálá ni ìdílé náà, láti ìgbà náà lo ni won ti ń bo Obàtálá ni ìdílè yìí. Ti o bad i àsìkò odún òrìsà yìí, àríyá ni fún gbogbo àwon omo àdúgbò yìí àti fún ìlú pàápàá. 
(see Yoruba Place Names)

C.O. Onanuga

Ijebu-Ode

Ilu Ijebu-Ode

C.O. Ọnanuga (1981), ‘Ìlú Ìjẹ̀bú-Òde’, láti inú ‘Ọdún Òrìṣà Agẹmọ ní Agbègbè Ìjẹ̀bú-Òde.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL. OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwé 3-6

ITAN IJEBU-ODE
	
Oríṣìíríṣìí ni ìtàn tí à ń gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá ìjẹ̀bú Òdẹ. Ṣùgbọ́n èyí tí ó wọ́ pọ̀ jù nínú àwọn ìtàn náà ni mo mẹ́nu bà yìí; 
	
Aládùígbò ni Odùduwà àti Alárẹ̀ jẹ́ ni apá ilẹ̀ Lárúbáwá. Odùduwà ni a gbọ́ pé ó kọ́kọ́ ṣí kúrò ní agbègbè náà wá sí Ilẹ́-Ifẹ̀. Lẹ́hìn rẹ̀ ni Alárẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ Wàdáì; tí ó gba aṣálẹ̀ Núbíà dẹ́ Ilé-Ifẹ̀, tí ó sì ṣe “ẹ-ǹlẹ́-ń bẹ̀un o” fún Odùdùwà. Alárẹ̀ fi ọmọbìnrin rẹ̀ kan Gbórowó, fún Odùduwà láti fi ṣe aya. Lẹ́hìn èyí, ó gba ọ̀nà Ìṣẹri dé Ìbẹsẹ̀, títí ó fi dúró ní Ìjẹ̀bú-Òde. Ajẹ̀bú àti Olóde jẹ́ lára àwọn àtẹ̀lé Alárẹ̀. Fún iṣẹ́ ribiribi wọn fún ìlú ni a ṣe sọ Ibùdó náà lórúkọ wọn - Ajẹ̀bú-Olóde. Àpèjá orúkọ yìí ni ó di Ìjẹ̀bú-Òde lónìí yìí. 
	
Lẹ́hìn Alárẹ̀ ni Lúwà (OLÙ-ÌWÀ) náà dé láti aṣálẹ̀ Núbíà. Òun náà gba ọ̀nà Ilé-Ifẹ̀, ó sì yà kí Odùduwà. Lúwà àti Àlárẹ̀ bí ọmọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Osi ni ọmọ Lúwà; Eginrin sì ni ọmọ Alárẹ̀. Ní àsìkò yìí. Ọṣìn tàbí Ọlọ́jà ni à ń pe Olórí Ìjẹ̀bú-Òde. 
	
Èdè àìyédè bẹ́ sílẹ̀ láàárín Alárẹ̀ àti Lúwà lórí, i ẹni tí yóò jẹ ọlọ́jà. Nígbà tí wọ́n tọ Ìfá lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó fí yé wọn pé ẹni tí yóò jẹ olórí  kòì tíì dè!. 
	
Kò pẹ́ kò jìnnà, lẹ́hìn ikú Alárẹ̀ àti Lúwà, ni àjèjì kan tí o múrá pàpà-rẹrẹ wọ̀lú. Ọ̀nà Oǹdó ni àjèji yíí gbà wọ ìlú. Kò pẹ́, ìròhìn ti tàn ká pé àjìji kán fẹ́ gbọ́gun wọ̀lú. Èyí ni ó mú Apèbí (Olóyè pàtàkì kan ní ibùdó yìí) lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì ju pé “Ìjà dà?. láti fi hàn pé òun kò bá ogun wá. Àjèjì náà fi yé wọ́n pé Ògbòrògánńdá-Ajogun ni orúkọ òun. Ó jẹ́ ọmọ Gbórówó tí í ṣe ọmọbìnrin Alárẹ̀ tí ó fún Odùduwà fẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀, Ipasẹ̀ àwọn ẹbí ìyáa rẹ̀ ni Ògbòrògánńdà tọ̀ wá, lẹ́hìn ikú bàbá rẹ̀. Títí di òní, àdúgbò tí Apèbí tí pàdé Ògbòrògánńdà ni à ń pè ní ÌJÀDÀ. 
	
Àpàbí lọ fi tó olóyè àgbà Jaginrìn tí ó rán an níṣẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀rọ̀ ni àjèjì náà mú wá. Nígbà tí Jaginrìn bi Apèbí ibi tí àjèjì náà wà, Apèbí dáhùn pé “Ọba-ńníta” (Ọba wà ní ìta) nítorí ipò Ọ́ba ni ó rí i pé ó yẹ ẹni pàtàkì bí i tí Ògbòrògbánnńdà-Ajogun. Láti ìgbà yìí ni a tí mọ Ògbòrògánńdà ní Ọbańníta, tí àjápè rẹ̀ di Ọbańta di òní. Agbègbè tí Ọníṣeémù ti lẹ́ ọ̀sà lọ tí a fún Ògbòrògánńdà láti máa gbé ni ó júwe pé” ó tóó ró”- (Ibí yìí) tó láti dúró sí) ni à ń pè ní Ìtóòró di òní. Àdúgbò yìí ni a ṣe ọ̀wọ́n kan sí ní ìrántí Ọbańta, nítorí a kò mọ bí ó ṣe kú. Inú igbó kan ni tòsí Orù-Àwà ni a gbọ́ pé ó rá sí. 
	
Ògbórògbánńdá Ajogun (Ọbańta) gbé Winniadé, ọmọ Osi níyàwó. Ósi yìí, bí a ti mọ̀ ṣáájú jẹ́ ọmọ Lúwà. Ọbáńta sì jẹ́ ọmọ-ọmọ Alárẹ̀. Wọ́n bí ọmọkùnrin kan tí ó ń jẹ Mọnigbùwà. Síbẹ̀ aáwọ́ tí ó wà láàárín Lúwà àti Alárẹ̀ nípa óyè jíjẹ kò í tán láàárín àwọ́n ẹbí méjèèjì. 
	
Láti fi òpin sí aáwọ̀ yìí, àwọn ará ìlú ní kí Monigbùwà, ọmọ Ọbańta, jáde rẹ̀ ti ṣe ní ọjọ́ kìíní. ‘Mọnigbùwà gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lọ sí ìletò kan tí a mọ̀ sí Òdo, láti ibẹ̀ ní ó sì ti padà wọ ìlú pẹ̀lú ìfọn àti orin. Ọjọ́ yìí ni a gbé adé fún Mọnígbùwà. Oùn ni ó jẹ́ ẹni àkókó ti ó jẹ oyè Awùjalẹ̀ - ‘A-mu-ìjà-ilẹ̀’-èyí ni ẹni tí ó parí ìjá tí ó bá nílẹ̀. Àpápè oyè yìí ni ó di Awùjalẹ̀ dòní yìí. Títí di òní yìí ni ẹnikẹ́ni tí a bá yàn gẹ́gẹ́ bí ọba tuntun gbọ́dọ̀ jáde ní ìlú lọ sí Òdo, kí ó sì wọ ìlú padà gẹ́gẹ́ bí i Mọnigbùwà àti Ọbańta kí ó tó ó gbadé. 
	
Lára àwọn olóyè pàtàkì-pàtàkì ní Ìjẹ̀bú-Òde ni Olísà Ẹgbọ̀, Àgbọ̀n, Kakaǹfò, Jaginrìn àti Lápòẹkùn, tí wọ́n jẹ́ óyè ìdílé. Àwọn oyè bí i Ọ̀gbẹ́ni Ọjà kìí ṣe oyè ìdílé. 
	Àwùjalẹ̀ kọkànléláàádọ́ta ni a gbọ́ pé ó wà lórí oyè báyìí. 

Àwọn Ìjẹ̀bú fẹ́ràn láti máa jẹ kókò àti ọ̀jọ̀jọ̀. Wọ́n tún fẹ́ràn lati máa fi ògìrì sí obẹ̀ àti oúnjẹ wọn mìíràn bíi ikọ́kọrẹ́ láti fún un ní adùn àjẹpọ́nmulá. 

 							Ẹ̀SIN
 Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ni àwọn ènìyàn Ijẹ̀bú Òde ní ìgbà láíláí. Wọ́n máa ń bọ oríṣìíriṣìí òrìṣà tí a ń bọ ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bí i Ògún, Ifá, Èsù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òrìṣà ìbílẹ̀ bíi Agẹmọ, Òrò, àti Obìnrin-Òjòwú wà pẹ̀lú. 
	Lọ́de oní àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ̀nyí kò ranlẹ̀ bíi ti àtijọ́, síbẹ̀ a ṣì ń bọ wọ́n lójú méjèèjì. Ẹ̀sìn Mùsùlùnì ni ọ̀pọ̀ àwọn ará Ìjẹ̀bú-Òde ń ṣe báyìí. Mọṣáláṣí kan  wà ní àdúgbò Òyìngbò tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú mọ́ṣáláṣí tí ó tóbi jù ni apá ìwọ́ oòrùn Afríka. 
	
Àwọn ẹlẹ́sìn àtẹ̀lé Krístì Lóríṣìíríṣìí kò gbẹ́hìn. Àwọn náà pọ̀ ní iba tiwọn. Àwọn ìjọ Àgùdà tilẹ̀ fi Ìjẹ̀bú Òde ṣe ibùjúkóó fún dáyósíìsì ti ẹkùn Ìjẹ̀bú.

 1.	Àdúgbò:  Itaolówájodá 
	Ìtùmò: 	   Àdúgbò yìí ni àwon ìjòyè Oba ìlú yìí tí a ń pè ni olówá tè dí, ti won si ń se ìjoba lórí àwon ènìyàn tó wà ládùgbó yìí 

	Ìtùmò: 		 Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà alá wà tétètélè, Àwon àwòrò òrìsà yìí ni ó te àdúgbò yìí dó. 

	Ìtùmò: 		Igi obì púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí bá nígbà ti wón fé te ìbè dó.

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà òsù wa. ni tori pe ibí yìí ni wón ti ń bo òrìsà yìí ni wón se ń pe e ni ìta òsù. 

	Ìtùmò: 		Igi òpe púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí ban i ibi yìí nígbà tí wón fé te ibè dó

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni òkan lára àwon akoni ode to máa ń ye ojó ogun ti awon olóde yòókù bá ti dá síwájú tè dó ìdí niyìí tí won fi ń pe àdúgbò yìí ni Ayegun. 

	Ìtùmò: 		Awon ounje orisirisi tí a dì sínú àpò bii àgbàdo, ìyo, ni àwon ara àgbègbè máà ń gbé wá si àdúgbò yìí wá lati tà kí ó tó di àdúgbò. Wón si máà ń na ojà ni àdúgbò yìí títí di òní yìí . 

	Ìtùmò: 		Isé ìkokò mímo ni isé àwon to té àdúgbò yìí dó. Díè lára àwon omo omo won si ń se ìsé yìí 

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni àwon Olósùgbó ti máà ń se ìpàdé. Níbè ni ilé ìpàdé wón wa, kí ó tó di pé won te ibè dó. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni ójúbo osi esi wà télètélè kí o to di pé won te ibè do tí o si dí àdúgbò ojúbo osi yìí si wa níbè títí dònìí. 

	Ìtùmò: 		Àwon Opó ni won máà ń na ojà yìí ni alaalé. Òríta ti wón ń náà yìí ni o di adúgbò, ti wón si ń pe ni ìtà opó. Wón si máà ń ná ojà alé ni àdúgbò yìí títí dònìí 

	Ìtùmò: 		Okunrin kan tó mú opà dání ló te apá ibí yìí dó. Ìtàn so fún wa pé àpá ase Oba ìlú ibòmíìràn ló mu dàni nígbà tí o ń bo, àwon kan tilè so pé Àremo oba ìlú náà ni. Nígbà tí o, fé te àdúgbò náà do ó mú òpá yìí dá ni, Ìdí niyìí tó fi je pé won ń je oba ni àdúgbò náà títí di òní yìí 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé omi nigbogbo àdúgbò yìí teletélè kí ó to dí pe wón te ibè do. Okunrin akoni ti a ń pè ni òró ni o pé ofò tí ó sì le omi náà lo. Ìdí nìyìí ti a fi ń pé àdúgbò náà ni Ìtóòró. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni òkan lára àwon akoni tó te ìlú yii dó kokó dúró si kó tó dip é ó wo àárin ìlú lo. Nígbà ti ijà dé láàrin òun àti àwon tí wón fo wo ìlú yìí, o bínú pàdà si ibi yìí o si wolè. Ìdí niyìí tí wón fi ń pe àdúgbò naa ni Olóde. Oórì okùnrin yìí si wà níbè títí dòníì. 

	Ìtùmò: 		Eégún kan ti won ń pè ni obrinrin ojòwú ní o te ibí yìí dó. Èégún Odoodún ni eégún máà ń jáde ni àdúgbò yìí títí donii. Ìdí igi ìrókò ni won fi se ojúbo eégún yìí Igi ìrókò yii wà níbè títí dónì yìí. 

	Ìtùmò:     	Isé epo ni àwon to te àdúgbò yìí yàn láàyò léyìn tí wón ti dó síbè. Bí o tilè jé pé won kò se ise epó níbè mó, won si ń ná ojà epo níbè titi dò níí. 

	Ìtùmò: 		Lára àwon ìjòyè oba Gbélébùwà àkókó tí won kò fara mo on pé kí wón pa Oba náà ni won wa te àdúgbò yìí dó léyìn ti wón kúrò ni ààfún. 

	Ìtùmò: 		Oríta yìí ni àwon ìjoyè Oba Gbétebùwá àkókó péjo sí láti bi ara won ohun ti o ye kí àwon se fún oba náà. 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so gún wa pé nígbà tí wín fe te ibí yìí dó, wón bá òrìsà kan níbè tó dé adé sórí tó sì fi èwòn onírin se ileke owó àti tí esè. Ìdí ni yìí ti à fi máà ń yan Oba láti ìdílé enití ó te àdúgbò náà dó. Ìdílè yìí náà tílè ni ààfún tí a ń pè ni ààfin Òba ìdéwon. 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé bí ó tilè jé pé èrúktí o té àdúgbò yìí do kii se àfín, sùgbón gbogbo àwon omo tí won bi láti ìdílè enití o te àdúgbò náà do je àfín. Nígbà ti won lo bi ifá wo, Ifá ni ki won máà bo Obàtálá ni ìdílé náà, láti ìgbà náà lo ni won ti ń bo Obàtálá ni ìdílè yìí. Ti o bad i àsìkò odún òrìsà yìí, àríyá ni fún gbogbo àwon omo àdúgbò yìí àti fún ìlú pàápàá. 




#Article 12: Àwọn àdúgbò ìlú Ìbàdàn (3424 words)


	Ìtumò: 		Ilé ńlá kan tí ìjoba kó sí ìbàdàn ló ń je mòpó. Mapo Hill  gangan ni orúko ibi yìí sùgbón ìgbà tó yá àwon ènìyàn bèrè sí ní pè nì òkè mòpó

	Ìtumò: 		orúko ojà kan ní ìbàdàn ni. Sùgbón orúko èèyàn kan ló ń jé béè. 

	Ìtumò: 		Ìbùdókoo kan ni èyí ní ìbàdàn; orúko èèyàn kan ni wón fi so. orúko eni náà ni Alhaji Múfútàù Oláníhùn. Ìbùdókò yìí wà ní ònà Gate. 

	Ìtumò: 		Èbá-Òdàn ni wón kókó ń jé télè nítorí pé ní èbá-òdàn ni àwon ògúnmólá tó té Ìbàdàn dó kókó de si kí wón tó ó bó sí àárín ìlú nígbà tí ojú ń là ni wón yí orúko náà padà sí Ìbàdàn. 

	Ìtumò: 		Ìyàwó méjì ni won jo wà lóòdò Oko gbogbo ìgbà ni ìjà ma ń wáyé láàrin àwon méjéèjì èyìn ìyàwó si ni oko ma ń gbèè sí Ìyàálé ka èyí sí àrínfín ló fi bínú dodo èyí ni wón fi ń pe odò yìí ní Orógún orúko yìí náà ni wón fi ń pe àdúgbò yen. 

	Ìtumò: 		Orúko ode kan ni wón fi ń pe ibí yìí kò sí ìgbà tí ènìyàn lè kojá níbè ti kò ní í bá odè náà níbè ìdí nìyí tí wón fi ń pe òdúgbò náà ni Ajíbóde. 

	Ìtumò: 		Adé ti àwon omo Osòrun gbé wá láti òyó ni wón kó sí ìlé kan ní àdúgbó yìí ni wón bá so ibè ní Adéòyó. 

	Ìtumò: 		Ìrísí bàbà kan tí ń jé Yusuff ni wón fi so agboolé yìí ilé bàbá yìí ni ó wà ní àkókó kàn ní àdúgbò náà. Bí ó sé tééré ló mú won so àdúgbò náà béè 

	Ìtumò: 		ìdílé elégún ni ìdílé yìí. Eégún ilé won tí ń jé alágbàáà ni wón fi so àdúgbò náà 

	Ìtumò: 		enìkan tí ń jé Dáúdá ni wón so orúko rè di Dàádàá tí wón fi ń pe àdúgbò yìí. 

	Ìtumò: 		Odò àgbàrá tó ma ń dégún sí àdúgbò yìí tí ó ma ń dún gbodagbùdù ni wón fi so àdúgbò yìí ní agbedàgbùdù. 

	Ìtumò: 		Ode ni Okùnrin yìí ni àsìkò ogun ti àwon èèyàn bá ń sá sógùn ún sósì ó wá pe àwon ènìyàn pé tí àwon dijo dúró síbí ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ní àgbolé Bánjo ibi tí àwon ènìyàn jo sí. 

	Ìtumò: 		Àrèmo Obo kan ló yòó ti orúko rè ń jé Lándànì ló wá te ibí yìí dó nítorí ti ibè jé orí-òkè ni wón fi só di òkè-Àrèmo. 

	Ìtumò: 		Ìdílé Osòrun òyó ló wá te àdúgbò yìí dó ni wón fi so orúko oyè ti ìdílé won ń je lóyòó so àdúgbò náà. 

	Ìtumò: 		Nínú àwon tí wón ma ń mo ilé-pàálábàrá láyé ìgbà yen bàbá kan wà ládùgbó yìí tó jé ìlú mò-ón-ká nínú ìsé òmòlé ló jé kí wón so àdúgbò náà ní ilé-olómo. 

	Ìtumò: 		Igi ló ń jo osè yìí àwon ènìyàn ma ń dúró sídìí rè láti won okò nígbà tí ó wá dip é àwon ènìyàn ń kí ilé sí agbègbè yìí ni wón wá á fi igi yìí so àdúgbò náà. 

	Ìtumò: 		Egúngún ló ń jé Adábaálé láti ìlú òyó ni wón ti gbé eégún yen wá síbè, orúko eégún yìí ni wón fi ń pe àdúgbò yìí 

	Ìtumò: 		Ìyá kan wà lágbègbè yìí tó ń ta etu, ti àwon ènìyàn bá ń lo sódò ìyá yìí won á so pé àwon ń lo sílè yèyé metu, èyí ni wón súnki di Ìyemetu. 

	Ìtumò: 		Odò kan ló ń jé onà àwon ìyá kan ma ń ta ewé lápákan ibi tí odò wáà ti sàn kojá idí nìyí ti wón fi ń lo ewé láti yán an kí ènìyàn lè mo ibi tí à ń tóka sí lápá odò náà. 

	Ìtumò: 		Wón ń bo òrìsà Oya ládùgbó náà ni orúko òrìsà yìí ni wón fi so àdúgbò yìí. 

	Ìtumò: 		enu òpin  ìlú ni bode wón tún wá á dé ojà síbè ni wón fi ń pè é ní bode-ojà. 

	Ìtumò: 		Okùnrin kan tó jé àáfà mùsùlùmí ló ma ń kínrun níbi yìí yóò wàá lé téńté èyin ló jé kí wón máa wi pé ìmòle lé téńté èyí ni wón se àsúnkì rè sí mòlété.

	Ìtumò: 		Òde ni bàbá yìí ìlú Abéòkúta ló ti sode wá sí Ìbàdàn ibi tí ó wá tèdó sí tó ń gbé ni wón ń pé lábè ògúntulà.

	Ìtumò: 		ìdílé yìí jé ti àwon alágbède Òjé.

	Ìtumò: 		Òkè yìí ga ò wé rí gánrangánran bi òkè yúse rí ni wón fi ń pe àdúgbò yìí. 

	Ìtumò: 		Odò kan ló sàn kojá ládùgbó yìí ti orúko rè ń jé àgbèré èyí ni wón so di orúko fun àdúgbò náà.

	Ìtumò: 		ní àdúgbò yìí kò sí omi kankan ní be tó jé pé tí wón bá gbé kànga kò lè kan omi èyí ló mú won so àdúgbò yìí ní kosódò. 

	Ìtumò: 		gbogbo àwon tí wón kókó wá láti ilú ìbòmíran sí Ìbàdàn agbègbè yìí ni wón kókó dúró sí kí wón tó ó fónká ló sí ìgboro orísìírìsìí àwon èyà ní ilè-Yorùbá la lè bá pàde nib í ìdí nìyí tó fi ń jé Ayékalè. 

	Ìtumò: 		Igi Obì kan ràpàtà ló wà ládùgbóò yìí òhun ni wón ń to láti fi pè 
é. 

Ìtumò: 		Orúko ìnagije tí wón fún jagunjagun kán tí àwón ènìyàn rè rò pé ó ti kú sójú ogún nítorí won kò gbúròó rè fún ìgbà pípé. Ojó tó dé ó ua àwon ènìyàn lénu ni wón ba so pé omólàde tó di orúko àdúgbò yìí 
	

	Ìtumò: 		Ní ayé àtijó, a maa n ní odi ìlú, bákan náà ni a máa n ní bode ìlú. Nígbà tó di ojó kun, àwon omodé tó ń dègbé bá seesi finá sí oko. Báyì ni odi ìlú se bèrè sii jóná. Enìkan sáré wádè sáàrín ìlú láti so fún wón pé odí ìlú ti ń jóná. Báyi ni gbogbo ènìyàn se ń pari wop e Odíńjo odíńjó tí `dúgbò náà sì dí odíńjó loni 

	Ìtumò:		Ojúbo òrìsà yemoja wà ni àdúgbò náà, ti kò sì sí onà míràn láti gbà dé ibè yàtò sí ojú ònà kan soso. Nítorí ìdí èyí ni won se ń pe ojú ònà yìí ní òpópó yemoja

	Ìtumò:		Ibi tí ojà Bodè wà lónì yìí ní enu odì ìlú nígbà náà. Ibè ni àwon  omibodè maa ń dúró sí láti máa só ìlú náà. 

	Ìtumò:		Ènìyàn ni ó n jè òrániyàn yìí, tí ó di odò pèlú ìbínú ńlà. Ojúbo odò náà ni wón fi so àdúgbò ibè ní orúko tó ń jé láti máa fi se ìránti rè. 

	Ìtumò:		Akínkanju Ológun kan ni ó di odò láyé àtijó. Ìdí nìyí tí wón fi ń pe odò náà ní orúko re Ògùnpa, ti oruko náà sì di orúko àdúgbò náà. 

	Ìtumò:		Ojúbo èsù ńlá kan wa ni ibi tí wón ń pè ni èsù àwèlé lorni. Ìdí sì nìyí tí wón fi ń pé àdúgbò náà ni orúko yìí. 

	Ìtumò:		Orí òkè ti ààre Látóòsà kole sí ni wón ń pè ni òkè àrelónì

	Ìtumò:		Ibi tí a ń pè ní ilé-tuntun lónì jé igbó ń lá télètélè ti kò sì sí àwon ilé oní bíríkì kankan níbè. Àdúgbò yìí ni wón kókó kó ilé oní bíríki sí ní ìlú Ibadàn. Ìdí nìyí tí a fi ń pé é ní Ilé-tuntun. 

	Ìtumò:		Ilé eléégún tí ó ń jé afìdi èlégèé ni ó wà ní àdúgbò náà, tí ó sì ní orúko ńlá ní ìlú Ìbàdàn. Àti pé ibè ni wón ti máa ń se àseye fún eni tó bá kú tí kìí se elésìn mùsùlùmí tàbí ìgbàgbó. 

	Ìtumò:		Àgbègbè tí bale kan tó n jé Olúgbòde ni ìlú Ìbàdàn láyé àtìjó kólé sí ni a ń pè ni Ìta-baálè lónì yìí. 

	Ìtumò:		Akinkanjú ológun kan un ó di Odò láye àfìjó nígbà tí àwon òdá rè fé mu. Ó wòó pé kàkà kí ilè kú ilè á sá. Ìdí nìyí tí wón fi so Odò náà ni kúde tì láti máa fi se ìrántí akoni náà, tí gbogbo agbègbè náà sì di kúdetì bákan náà. 

	Ìtumò:		Ìbi yìí gan an ni ògangan agbègbè tí àwon Ìjèbú tèdó si nígbà ti wón de Ìbàdàn. 

	Ìtumò:		Agbègbè kan tí àwon ènìyàn tí ogun lé kùró ní ìbùgbé won tèdó sí, tí wón sì fin í ìsinmi ni a ń pè ni Ináléndé lónì yìí. 

	Ìtumò:		Egúngún ni lá olókìkí kan wà ilú Ìbàdàn tí kìí pojú kan Obìnrin. Agbègbè tí ilé eni tí maa ń gbé eégún náa wà ni a ń pè ní Òde-ajé Olóòlù sì ni orúko egúngún náà ní Òde-ajé-Olóòtù. 

	Ìtumò:		Okùnrin kan wà láyè àtíjó tó ní n àsìn bíi adìye ati eyele, okùnrin yìí sì fún je eni tó burú púpò. Bákan náà, okùnrin yìí féràn àgbàdo púpò. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń fun àwon ń nkan òsìn rè lóńje, ni oùn náà máà ń je àgbàdo ti rè. Nítorí ìwà yìí, àwon ènìyàn máa ń júwe ìlé rè gégé bíi bàbá-a-bá-eye-rún-oka bàbà. Báyìí ni wón se só ó di Béyerúnkà.

	Ìtumò:		Agbègbè yìí jé ibi ti òwò èkùr’’o pípa wópò sí. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní elékùró. 

	Ìtumò:   	Agbègbè yìí ni bàbá tí ó máa ń bo òrìsà òkè-Ìbàdàn ń gbé. Ìdí nìyí tí won fi ń pe àdúgbò náà ni ìlé abòkè. 

Ìtumò:		Agbegbe tí àwon ènìyàn, tí ogun lé kúrò níbì kan, tí gbogbo wón sì ro gìlàgìlà dé sí ni a ń pè ní Dùgbè

	Ìtumò:		Ìtàn fi yé wa pé Òkan léhìn àwon omo Ogun Bashorun Ìbíkúnlé tí ó jé jagun-jagun pàtàkì ní ìlú Ìbàdàn ní ó ńgbé àdúgbò yìí. Nítorí àkíkanjú rè lójú ogun tú won fi ńpè ni amúló ju ogun. Ìnagije yìí sì ni won so di Amunigun 

	Ìtumò:		Ibí jé àgó àwon abìrun kan, àwon odi ni wón máa ńkó síbè fún ìtójú, ní ayé àtijó ilé-ìtóju odi ní ibè jé. 

	Ìtumò:		Ní àyé àtijó oko obì ní wón fi adúgbò yìí dá àwon àgbè alóko osì ní ó ńgbé ìbè tí o fí jé wípé tí ènìyàn bá ńlo abé obì ni yío màà tò lo. 

	Ìtumò:		Okùnrin kán wà ní àdúgbò tí féràn láti máa je àgbàdo, ni ìgbà yen àwon àgbe ka àgbàdo kún oúnje ye nítori, ìdí èyí ní wón se ńjè Okùnrin náà ní eni tí ó ń bá èye rú Okà.

Ìtumò:		Ibí yìí jé Ibi tí iwón máa ń pa koríko kan tí ó ń jé beere lo fún Aláàfin láyé àtijó.

	Ìtumò:		Ìnagije alàgbà tí ó jé baákì àdúgbò yìí rí, tí ò si je oloro pèlu oun ti eni àkoko láti dé àdúgbò yìí.

	Ìtumò:		Ní àárò ojó àwon onísòwò ni àwon tí ó tèdó sí ibí yìí. Ìtumò orúkoyìí ni agbeni bí owó. 

	Ìtumò:		Àwon àgbà fí yé wá pé awuye wuye kún tí ó wáyé láàrín àwon elegbé ode lórí ode tí ó tédòó láti de igbó yìí. Orúko àdúgbò yìí gan ni “Igbódìjà”

	Ìtumò:		Ìtàn yíì dá lórí okùnrin kan tí ó yá owó sùgbón tí kò lè singbà nípasè àíró wó san, ó dá ìgbà àti dá owó yìí padà sùgbón kò ri san. 

	Ìtumò:		Nítorí Ìwà òlàjú, òmòwé àti aláfé ti gbayì ní àdúgbò yìí ni wón fi so lórú ko yìí. 

	Ìtumò:		Igbó ni àdúgbò yí jé ní ayé Ìgbà yen, àwon ará àdúgbò yìí ni wón béèrè sì nà ojà alé ní bè Ìdí nà yí tí orúko àdúgbò yìí fi wáyé. 

	Ìtumò:		Igi kúnwá nì àdúgbò ewé aréré ni ó maa ń wù lórí rè, ewé yìí máa ńtàn tí o fi sé wípé Ibòji ré pò púpò, ìwon ènìyàn máa ńjoko láti gba ategùn níbè won sì máà ń se fàájì níbì pèlú. 

	Ìtumò:		Alàgbà ken tí orúko rè ńké máyabìkan ni wón gé kúru ti wòn sí ńpè ní ìta máyà. 

	Ìtumò:		Òkin lára àwon olóyè olúbàbàn kan tí ó ńjé òsì máyè ni ó tèdó sí ibí yìí láyé àtijó 

	Ìtumò:		Nkan ti o mu oriko adugbo yii wa nipe adapo yangi ati ile erofo ni olorun da ibe, o sit un je oke, Ibe maa n nira lati gba. 

	Ìtumò:		Ibi yíi ni awon oyinbo ajele gbe aremo Alaafin Oya sa pamo si ki o maa ba ku lehin Iku baba re gere bi asa awon Oyo.

	Ìtumò:		Ibí yii ni awon ara ilu Egba fi se Ibí isadi won ni igba aye ogun nigabi. 

	Ìtumò:		Igi ayanre kun ni o ti wa ni adugbo yìí kí ó ti wa dí wipe awon ènìyàn la ile loju de ibe. 

	Ìtumò:		Àdúgbò yìí jé ibi tí won ní orúkí asiwájú kan ni akoko kan ni Ibadan tí orúko rè ń jé Ológbéńlá. Ológbéńlá yìí ni wón wá so di “Gbenla”èka-èdè ló fà á 

	Ìtumò:		A gbó pé ni àsìkò ogun Ìbàdàn àti ìjàyè, owó àwon ìjàyè ló kókó dun àwon Ìbàdàn ti won sì mu olórí ogun Ìbàdàn ìgbà náà sí ìgbèkùn won. Àwon omo-Ogun Ìbàdàn padà sí ilé láti lo tún ara mu, won sì padà ìjàyè ni àkókó yìí ni Ibàdàn ségun Ìjàyè pátápatá tí wón mú lérú Okàn àwon Ìbàdàn kò bale nígbà tí wón dé ilé nítorí èèyàn líle ni awon ìjàyè ìdí nìyí tí wón fi wá yan àwon òpò omo-ogun won sí ojú ònà tí àwon ìjàyè mó ó ń rìn wo Ìbàdàn, lásìkò ìgbà náà láti máa só won. A gbó pé àwon omo-ogun wònyí lò to osù méta dáádáá kíwon tó kúrò níbè, ni wón fi so ògangan ibè ni Alékúsó (ibi tí a gbé uan eeyan kó máa so won). 

	Ìtumò:		Ojà kan ló wà nì adúgbò yìí tó jé wí pé kìkì àlùbósà nì wón máa ń tà, ní bè gégé bí isé ajé won. Ibikíbi ní àwon ìlú tó wà léti Ìbàdàn sin i won ti máa ń wá ra àtùbósà tó bá ti je enì tó fé ra òpò. 

	Ìtumò:		Àbúrò ni eni tó/te/ Ode-Ajé olóòlù yìí jé sí eni tó te àdúgbò òde-Ajé alálùbósà dó ó, kó tó di ojà. A gbó pé jagunjagun ni wón àti wí pé eégún Olóòlù yìí òkan lára erù ti wón ko bò láti ojú-ogun ni. Ègbón ló ní kí àbúlò òun sún sí ìsàlè díè kí ó tó dúró, èyí ló fà á tí àdúgbò mejeeji yìí kò fi jìnnà si ara won. 

	Ìtumò:		Àdúgbò yìí ń be láàrin òjé sí yemétu Ìdí tí wón fi ń pè é ni Òkè-Àpón ni pé òke-kere ni àdúgbò òhún wà tó sì takété sí títì lákòókò kan àwon tí kò tíì ni Ìyàwó nílé nì wón máa ń sáábà gba tàbí réǹtì ilé sí àdúgbò yìí, pàápàá àwon omo ile-ìwé èkósé Nóòsì ti na ìwe èkóse noosí tiko jinna sibe àti àwon òsìsé sekiteríàtì. Nítorí pé àwon òdó wá po níbè tíwon kò sì tíì ni ìyàwó tàbí oko ni won fi so àdúgbò yìí ní òkè-Àpón. Tí àwon olóńje bíi èbà, iyán fùfú èwà àti béèbéè/ lo bá ti apé ońje lé omo won lórí fún kíkiri, won á wà so fún-un pé kó tètè mó o gbé ojà rè lo oke-Àpón nítorí ojà, pàápàá ońje, a máa tà níbè púpò.

	Ìtumò:		Abénà ìmò mi so pé àwon ará Ìbàdàn gbèjà Ìbikúnle tó jé Balógun won ní àkókò ken pé wón wá ta òtúu rè lójì (ojì - gbèsè tàví fáìnì) wón wá so pé ibi ti baba won ìyen (ìbíkúnlé) gbé sanwo ojì náà ni won ń pè ni Agbeni ìdí nìyí tíwón fi máa ń ki àwon Ìbàdàn ní “Agbeniníjà omo òkè Ìbàdán 

	Ìtumò:		Àdúgbò yìí jé bí oríta tó ya ìlú ìjàyè àti Òyó sótò ní Ìbàdàn. Ìdí nip é ni Móníyá nì èèyàn tó ń lo sí ìlú ìjàyè yóò ti yà. Ní ojó ti àwon ará Ìbàdàn/wá ń lo sógun ìjàyè nígbà tí won dé móníyá wón pín ara won àwon kan yà sí ona tó gba ìjàyè lo tààrà, àwon kan gba ojú ònà òyó lo láti lè gba fìdítì wo ìjàyè Ògúnmólá ni wón so pé, ó sájú Ogun lódún náà, wón ní Ìbíkúnlé ò lo “Ibi ti gbogbo wa ti yà là ń pè ní Móníyà”

	Ìtumò:		Lójó tí àwon Ìbàdàn ń lo Ogun Èkìtì parapò ti àwon omo ogun tó jé akoni wa kó ara won jo sójú kan tí won ró gégé kí won ó tó wa ránsé re ilé Balógun Ìbíkúnlé pé kó máa bò pé àwon ti se tán ni “Gégé” “Won ró gégé-tan won ranse re ilé Balógun won”.

	Ìtumò:		Nígbà tí wón ń lo ogun Èkìtì parapò yìí wón ní ó pé won díè ki wón ó tó fi ìlú Ìbàdàn sí ilè nítorí won kò múra fún ogun yìí, òjíjì ni won rónísé Alaafin kí omo ogun tó ye kó lo, ó tó múra tán ó pe díè. Ibì tó wà gbé ló won jáí púpò kí won ó tó fi odi ìlú sílè ni wón so nì “òde-òóló”.

	Ìtumò:		Láyé ìgbà kan, Okùnrin ìjèsà kan wà nì ìlú. Ìbàdàn tó jé pé ó máa ń sòsómàáló. Okùnrin yìí gbajúmò púpò aso-òkè ló máa ń tà. Ní ojó kan owó rè wá bó sonù, ó wa owó yìí títí, kò ri, bàbá yìí wá bèrè sì í ké nitori owo yìí ká a lára, owó tó ti ń pa á bò láti àárò ni ‘Òwó bó, Olá bó, ìbòòsí àrè” Ibi tówó bàbá ìjèsà gbé bó sonù là ń pè nì “Lábó”

	Ìtumò:		Àdúgbò yìí ni won ti máa ń pín àgbá ota fún àwon omo-ogun Ìbàdàn tí wón bá ń lo ogun. Ibi ti won ti rí yíta Ogun fún wa ni “Eléta”

	Ìtumò:		Abénà-ìmó mi so fun mi pé ibi ti won ti yé àwon eni àkókó sí ni ayéyé. Òkan lára àwon tí wón yé sí nígbà náà lóhùn-ún nì “Agbájé Ayéyé “Ibi tí a gbé yéni sí là ń pè láyéyé”. 

	Ìtumò:		Láyé ijóun, tí wón bá fe lo sí ogun ní ìlú Ìbàdàn, Balógun yóò se ìkéde láti pé àwon ode, olóògùn ológun tó bá dára rè lójú tó fé bá won lo sójú ogun. Nígbà tí gbogbo àwon èèyàn wòn yí ba péjú sìbà, ni Balógun àti àwon ìjòyè rè yòókù yóò tó wá á sa àwon to pójú-òsùwòn láti lo léhìn òpò Ìdánrawò. Òpóyéosà ni gbangba ibi tí wón ti máa ń se èyí Níbàdàn wà nitori ko jinnà si ilé Balógun. Irú èyí náà selè nínú ìwé Ògbójú Ode nínú Igbó Irúnmolè tí D.O. Fágúnwà ko. Ibi tí a gbe n sa won lójó tá a bá n lo ogun là ń pè ni yéosà nijo-un. 

	Ìtumò:		Wón ní ìná ló lé àwon ènìyàn tówà ní àdúgbò yìí dé ibè láyé ijóun. Wón wá so pé ní àdúgbò odinjo ni iná ti sé lójó náà, èyí fíhàn pé àwon tó sá kúrò níbè tí won kò padà síbè mó ni won so ibè ni orúko ìtumò re nip é (Ní-hàà-ín ní iná lémi dé) 

	Ìtumò:		Lójó ti iyò wón ti gbogbo Ìbàdàn àti ìlú agbègbè rè kó rí iyò je tàbí se Obè. Ológbó tawón pé iyò pé iyò wà nì ìkòròdú lébàá Èkó ni gbogbo Ìbàdàn bá to jánà rere bí esú jáko. Ìyá baba mi máa ń pe odún náà ní “Odún gágá”. Nígbà tí wón wá n padà bò látìkòròdú, Ìdí Arere ni àwon èrò kókó gbé sò. Níjó èrò ìbàdàn n wayo o rekorodu tí gbogbo wón to jánà rere bi esú jáko, ìdí Arere lakokoso èrò” 

	Ìtumò:		Òòsà-oko nì won máa ń bon i àdúgbò yìí Níbàdàn. Àwon Oloosa oko ló wà ní bè  títí di òní. Awoni ènìyàn a sì máa lo toro omo níbè

	Ìtumò:		Àgó-odi-ìlú ló di Agodi nítorí èhìn odi ìlú ni àdúgbò yìí wà láyé àtijó Níbàdàn Ibè si ni ilé-isé Telifísòn àkókó wà nítorí ìbè máa ń dáké róró ni. 

	Ìtumò:		Àdúgbò yìí ni àwon ìjo Àgùdà fi Ìbùjokòó sí nígbà tí wón dé pèlú èsìn won páàdi ni wón máa ń pe àwon olórí èsìn yìí. 

	Ìtumò:		Bàbá kan ni ó máa ń dá oko sí èbá ìdí Ìrókò ní àtijó. Ìgbàkúùgbà tí wón bá ti ń wá bàbá yí tàbí wón fé gba nǹken lówó rè, wón á ní kí won lo wò ó ní Ìdí-Ìrókò. Bí bàbá yí se kó abúlé síbè nìyí àti ìgbà yìí ni wón ti ń pe ibè ní ìdí Ìrókò. 

	Ìtumò:		Òyìnbó kátólíìkì ni a gbó pé ó kó ilé rè si orí okè kàn ti àwon ènìyàn sì máa ń wo ilé náà lórí òkè téńté ríí wón bá wá béèrè pé níbo ni enìkan ń lo o le ni ibi tí sápátì kólé kólé si. Bí wón se so ibid i òkè sápátì nìyí 




#Article 13: Orúkọ Àdúgbò ní Ọ̀fà, Ìpínlẹ̀ Kwárà, Nàìjíríà (165 words)


	Ìtumò:		Agbègbè yìí ni àwon ìdílé Oba máa ń de ilè àti ìdòtí sí ni ayé atijo. Sùgbón ìgbà tí ó yá ni ilé bèrè sí ní dé àdúgbò yíí. Bí wón se ń pe àdúgbò yìí ní Atan Oba. 

	Ìtumò:		Ní àyé àtijó àwon ara àdúgbò yìí máa ń gun igi obì láti ká obì, nítorí wón gbà pé obì yìí máa ń mówó wólé. Èyí ni àwon ènìyàn rí tí wóm fi so àdúgbò yìí ní apónbì 

	Ìtumò:		Igi ń lá kán wà ni agbègbè yìí tí àwon eye lékeléke máa ń bà le. Gbogbo àwon ilé tí ó wà níbè ni àwon lékelékèé yìí máa ń yàgbé sí tí asogbo ara ilé náà á sì funfun. Sùgbón ìgbà tí olájú wá dí òfà ni wón kó àgó olópàá sí àdúgbò yíi. Tí wón bá ti wá fe júwe àgó olópàá yìí wón máa ń so wi pe àdúgbò funfun leye ń sun. Bí orúko yìí se mó won lára títí dóní nìyí. 




#Article 14: Àwọn àdúgbò ìlú Mọdákẹ́kẹ́ (2954 words)


Oruko ati itumo awon adugbo ilu Mọdákẹ́kẹ́, ni Ipinle Osun, Naijiria.

	Ìtumò:		Orúko Oyè ìlí, òun ni olóórí àwon afobaje 

	Ìtumò:		A ri èyin kágò eégún ijó níí jó. Òrìsà eégún ni won ń bo níbè 

	Ìtumò:		Onísòwò ni gbogbo won. nínú oríkì won lo ti jáde tói so pé. Kárí kárà kámó sanwó, ká sin owó kó dìjà 

	Ìtumò:		orisa oya ni won ń lo níbe, ojúbo oya wà nibe, won sì gbàgbó pé o máa ń fun won lómo 

	Ìtumò:		Gbajumò aláfé ènìyàn ni bale agbo ilé yìí. Ti o ba n rin lo lójúde ìrin oge pèlú fáàri ni. 

	Ìtumò:		kìkì òkúta ni agbo ilé náà. Àwon ènìyàn rip e ko si ohun to lè hù níbè. 

	Ìtumò:		Orúko Eégún to maa ń jáde ni agboile yìí ni. Nínú oríki rè ló ti jáde tó so pé. Elébiti sàgbá ko níjà.

	Ìtumò:		Onísègùn ni won. Kò si àrùn ti won gbé dé Ibè ti ko san 

	Ìtumò:		Ilé olósun òrìsà òsun máa ń fún won lómo. 

	Ìtumò:		Orúko òye Balógun. Òun lo je igbá kerin si Oba. 

	Ìtumò:		Aró dídá ni isé won níbi. Ko si aso ti won ko le se òsó sí lára. 

	Ìtumò:		Ifá gúnwá síbì. Onífá niwón ni agbo ilé yìí wón ni ojúbo Ifá níbè. 

	Ìtumò:		Orò ni won ń bò. Àwon ara agbo ilé yìí máa ń dásà pe bi obìnrin bá fojú di orò,  orò yóò gbe e. 

	Ìtumò:		Ogo bu olá fún won nínú ilé yìí. Ibi ti olóórí àwon onísàngó ń gbé. Ojúbo sàngó wà níbè

	Ìtumò:		Orúko oyè ìlú ní, onílù ni wón níbè

	Ìtumò:		Agbón ni wón ń hun ta. pàtàkì isé owó won ni àgbòn híhùn.

	Ìtumò:		Oti títà ni isé owó won. Eléyìí hàn nínú oríkì won tó sap é: Játi jákà bí àdèbà Oti sèkètè ni won máa ń se 

	Ìtumò:		Omi inú orù won máa ń mu. Won máa n re omì nínú ape. 

	Ìtumò:		Ewúro gbigbo ni ise won, àwon ènìyàn kìí wá ewúro ti níbè 

	Ìtumò:		Orúko eni tó te agbo ilé yìí dó. Won gba pe oruko ajemoyè ni èrè nínú 

	Ìtumò:		òun lo kókó je oba ògúnsùà. O ni ìfé àwon ènìyàn re

	Ìtumò:		Àgbàdo títà ni ise won. Àwon ni kò jékí ebi pa èlú . 

	Ìtumò:		Àlùbàtá ni won. Bàtá ni won máa ń lù fún Eégún won 

	Ìtumò:		Onísowò epo ni won. Epo kìí won nílé yìí 

	Ìtumò:		Ibi ti olóórí àwon onísàgó ń gbé, Ojúbo sàngó wà níbè. 

	Ìtumò:		Ní àtijo òrìsà kan wà ni ibi tí à ń pè ni ìráyè yìí orúko òrìsà náà ni ìrá láti ipólé òwu ni wón ti gbé òrìsà yìí wá léyìn ogun húkù húkù, obaláayè ni orúko àwòro rè. Bí wón bat i n bo òrìsà yìí tí won da Obì tí Obì si yàn àwon Olùsìn rè yóòmáa pariwo ayò pé ìra ti yè, Ìráyè, ìráyè láti ibi yìí ni a ti mu orúko àdúgbò yìí 

	Ìtumò:		Ìrísí ìyá ken tí ó jé gbajúmò ni agbo ilé yìí ni won fi n pè é ìyá náà lówó lówó béè ni ó sì pupa wèè ó sì tún sígbonlè pípupa tí ìyà yìí pupo ni won fi n fi àwò rè júwe rè tí wón si fi so agbo ilé yìí 

	Ìtumò:		Àwon ìran oníkòyí ni wón te agbo ilé yìí dó, jagunjagun sin i wón àwon ni won máa n jagun fun ìlú. 

	Ìtumò:		Ilé Alésinlóyè ni won máa n pè é télè kí won fi n pe béè ni pé okùnrin ken wa níbè nígbà náà tí ó máa n gun esin ni àsìkò ilé odún tí wón bá wa sí ilé láti oko àsìkò yìí sì ni oyé máa n mu ni agbègbè wa; èyí ni won fi máa n pè é ni Alésin nígbà oyé. 

	Ìtumò:		Ní Ìdílé yìí oyè Èkerin ni wón máa ń je níbè èyí ni won fi máa n pè won ni ilé èkerin 

	Ìtumò:		Orí òkè ni ìbí yìí ó sì kún fun kìkì òkuta èyí ni a fi n pè é ni òkè ìpàhò 

	Ìtumò:		Aji bá esin lórí òòró ni wón sún kid i ajíbésinró. Ní àtijó àwon ìdílé yìí ni won máa n fie sin rin ìrìn àjò béè wón sì ni esin yìí to pò gan-an débi pe won máa n so won mólè ní iwájú ìta nit í eni tí ó ń lo tí o ń bò yóò máa ba won níbè. 

	Ìtumò:		Àwon ènìyàn tí ogun lé kúrò ni ìpólé òwu nígbà ogun húkùhúkù ni wón tèdó si ibí, orúko ìlú won ni won si fib o agbolé won 

	Ìtumò:		Níbí yìí ni ilè ìjósìn àkókó ni ilú Modákéké kókó wa àwon ìjo sítifáánù mimó ni wón kó ilé ìjósìn yìí bákan náà légbèé rè ni ilé ìjósìn àwon mùsùlùmí wà èyí ni won fi so Ibè ni ita ìsìn èyí tí ó wa di itaàsìn 

	Ìtumò:		Ní agboole yìí òrìsà oya ni won n sìn níbí orúko òrìsà yìí ni a fi n pe agbo ilé yìí. 

	Ìtumò:		Orúko odò kan  ni olúgbo ògàn yìí orúko odò yìí ni a fi n pe agbo ilé yìí. 

	Ìtumò:		Orí òkè kan ń be ni àdúgbò yìí àwon ènìyàn ń dá àníyàn pé kí òkè náà ó jé òkè olá fún àwon 

	Ìtumò:		Ìnágije babaláwo kan ni ń jé báyìí  ìdí ti wón fi n pè é béè ni pé babaláwo náà máa n tu eni ti àwon àjé bá dè mólè béè ni ó sì máa n gbogbo kùrukùn ti bá n be ní ìgbésí ayé omo èdá. Babalawo náà gbónà ìlú mo ká sì nib í àwon ènìyàn ba ti n lo si ilé rè won a ni àwon ènìyàn ba ti n lo si ilé rè won a ni àwon n lo si ilé arídìíèké èyí ni won fi n pe agbe ilé yìí di òní olónìí

	Ìtumò:		Ní ìdílé yìí aso àrán ni won máa n tà níbè ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ni onílé àrán 

	Ìtumò:		Ìdì ti wón fi ń pe agbo ilé yìí ni ilé eréta ni pé níògangan agbo ilè yìí ni àwon ará ijóhun ti máa n wa ota tí àwon alágbède máa n yó sínú ìgbá kí won ó tó so ó di Irin ti won fi n rokó ròdá.

	Ìtumò:		Ìsé ìlù lílù ni wón n se níbí ìlù bàtá ni won sì máa n lù àwon onílù ìdílè yìí ni wón máa n lu bàtà fun àwon tí won ń bo òrìsà sàngó àti àwon eléégún ibé owó won yìí ni won fi so agbo ilé won loruko. 

Ìtumò:		Orúko enìkàn tí ó jé gbajúmò ní ìlù Modákéké ni ó ń jé Amólà ní àgbègbè Ibi tí ó kó ilé sí òkè yí. Ibè po ni béè ni orí òkè yìí ni ó kó ilé sí tente èyì ni won fi n pe agbo ilé yìí ni òkè Amolà 

	Ìtumò:		Látijo isé aró dídà ni àwon idílè yìí máa n se isé yìí ni àwon ènìyàn sì mo wón mó bí enìkàn bá ti fe lo si ilé won, won á ni àwon ń lo sí ilé aláró, orúko yìí ni wón tè mo agbo ilé yìí lára dòní olónìí. 

	Ìtumò:		Níbí ni igbódù àwon baba awo kí ilù ó to máa fè si nígbà tí ìlú wá kúrò ni inú igbó ni àwon babalawo wá fenu kò pé ibè ni àwon yòó ti máa se ìpàdé owo àwon yóò lo se igbódù mìíràn ni wón bá n se ìpàdé awo ni òkè awo. Èyí ni won fi  ń pe ibè ní òkè awo di òní. 

	Ìtumò:		Ní agbo ilé yìí ni won ti máa n ta àgbàdo ju ní àsìkò òjò èyí rí béè torí pé àwon kíì sábà gbin oúnje mìíràn àfi àgbàdo ìdí nìyí ti won fi n pè won ni ilé àtàgbàdo òjò. 

	Ìtumò:		Odò ti ó ń sun láti ilè tí won wa gbé ape le lórí láti inú àpe yìí ni won ti máa n pon omi yìí idí nìyí ti wón fi so ni agbo ilé olomi ape.

	Ìtumò:		Àwon egbé ni wón parapò tí wón dá àdùgbò yìí sílè èyí ni wón fi so agbo ilé yìí ní orúko. 

	Ìtumò:		Àwon ìdílé Obá ìkirè ni won te agboolé yìí dó ìdí nìyí ti won fi só lórúko mo orúko ìlú won 

	Ìtumò:		Orita ni àdúgbò yi jé títì mérin ni wón sì pàdé níbè èyí ló fà á tí wón fi n pè é ni ìtamérin.

	Ìtumò:		Ní agbe ilé yìí – isé gbegilére ni isé won àwon ìdílé Ajibógun ni won sì máa n gbénà ni wón ba kúkú so ìdílé náà ní ilé gbénàgbénà sùgbón akekúrú rènì àwon ènìyàn ń pè dòní 

	Ìtumò:		Ìtàn ìgbà ìwásè so fun wa pe tokotaya kan wà níbí agbo ilé yìí tí won n bí àbìkú omo bí won bat i bi omo yìí ni yóòkú ni won wá pinnu láti kó omo tí wón bi ni àsìkò kan jade kí won ó si se ináwó rè kí ayé gbó kórun mò. Nìgbà tí wón se báyìn ni omo bá dúró ni kò bá kú mó èyí ni ó fà á ti won fi so ibè ni kóìíwò èyí tí àpajá rè ń jé kó èyí wò ná bóyá a jé dúró. 

	Ìtumò:		Ìtàn so pé Ibè ni (District officer) ń gbé orí òkè sì ni ibè ilé àwon tí ó ti di ipò D.O. yìí mu ti wón jé òyìnbó sì wà níbè pèlú. Léyìn ìgbà tí a gba òmìníra àwon òyìnbo ti ń gbé ibè kí Obásanjó ó tó sòfin kí àlejò m;aa lo ní (1978)

	Ìtumò:		A rí orúko agbo ilé yìí nipa sè pé ibè ni enu odi ìlú. 

	Ìtumò:		Àwon ìdílè yìí jé ìdílé tí wón wa láti ede wá tèdó sí Modákéké. Ilá ni wón sì máa ń gbìn. Wón ni wón máa n sòrò pé ilá odun yìí o àkálà ni o ohun tí wón máa n wí yìí ni won fi so agbo ilé won ni ilé àkálà. 

	Ìtumò:		Télètélè rí, àwon eléégún ni àwon ti wón ń jé alágbàáà yìí ibè sì ni àwon olórí òjè won wa. lénu kan kìkìdá àwon eléégún ni wón dá àdúgbò yìí sílè. 

	Ìtumò:		Ní ayé àtijó, ode niwón nínú agboolé yìí Akíkanjú ènìyàn sì ni wón nínú ode sisé nígbà náà, tí wón bá degbó lo títí tí wón bá pa erankéran àwon ni wón máa ń gbé orí rè fún. Ìdi rè nìyí tí wón fi ń pè wón ní agbóríitú. 

	Ìtumò:		Gégé bí wón ti so, wón ní láti Ilésà ni àwon tí ó da àdúgbò yìí sílè ti wá. Nítorí pá àwon ìjèsà ni a máa ń kì ni “Omo owá, obokun rémi”. 

	Ìtumò:		Gbogbo àwon tí wón kólé ládúgbò yìí ni wón femu kò láti so àdúgbò won ni Ìrépòlérè. A lè so pé pèlú ìsòkan tí wón ní ni orúko àdúgbò yìí se di 

	Ìtumò:		Ìtàn so fún wa pé, àwon tó wà ni àdúgbò yìí láyé àtijó jé ologbón gidigidi, tó fi jé pe tí òrò bá rújú tan níbò míràn àwon ni wón máa ń báwon dá eyó pèlú. Èyí ló mú kí àwon aládùúgbò won panupò so àdúgbò yìí dó títí di òní olónìí yìí. 

	Ìtumò:		Àwon tí wón wá láti òmù àrán la gbó pé àwon ló té àdúgbò yìí dó títí di òní yìí. 

	Ìtumò:		Ní ayé àtijó àwon babaláwo ni wón wa ní àdúgbò yìí. Ní ìgbà náà gbogbo wa mò pé ipa pàtàkì ni Ifá ń kó láwùjò àwon Yorùbá, èyí ló mú kí àwon ènìyàn máa so pé, àwon ń lo sílé baba awo títí wón fi so ó di ilé Awótóbi. 

	Ìtumò:		Ìdí tí wón fi ń pe àdúgbò yìí ni Amókèegùn nip é, kí èègùn tó débè yóò gun òkè bíi mélòó kan, lénu kan òkè ni a máa gùn débè ni wón se so àdúgbò ni Amókèegùn. 

	Ìtumò:		Ìsé àwon àdúgbò yìí ni wón se so wón lórúko. Ní ayé àtijó làálì tí àwon Hausa máa ń lé sórí èékánná ni àwon fi ń sisé se ní ti won. Idí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé Onílàálì. 

	Ìtumò:		Ní ayé àtijó ìtàn kan so fún wa pé àwon tí wón wa nínú agbo ilé yìí gbáfínjú dáadáa, kò sí ibi tí wón lè dé nígbà náà tí wònkò ní mò pé inú àdúgbò yìí ni wónm ti jáde wá, ni àwon ènìyàn se pa emu pò láti so wón ni ilé Ogérojú. 

	Ìtumò:		Wón ni ní ìgbà ken Igbó tí ouni máa wa lára rè ni ènìyàn máa wà dé àdúgbò yìí, àárò kùtù hàn ni omi yìí máa ń wà ní ara igbó yìí tó fi jé pé kò sí bí ènìyàn se lè jí lo sì àdúgbò yìí ki aso irú eni béè ma tutu wálé. Idí nìyí tí wón fi so àdúgbò yìí ni agbón-an-ni. 

	Ìtumò:		Ní ilé yìí, àwon jagunjagun má fit i ìbon se ni wón, tí ogun bale tán won ki í lo ìbon láti fi jà rárá bí kò se kùmò àti ada pèlú ida. Ko sì sí bí ogun náà se lè le tó ti wón lè pa wón lójú ogun, fóniladìe toko èèmó bò nit ì won. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón ní ilé Atólógun. 

	Ìtumò:		Ìtàn so fún wa pé àwon tó wà ni ilé Àgbójà máa ń bínú púpò tó fi jé pet í enìkan bá yan ènìyàn je lójú won, wón lè so ìjà náà di ti won pátápátá, kò sì sí ibi tí wón ti lè gbá pé wón ń jà ní àdúgbò tó tì wón, tí won kò ní débè láti loo jà. Òpèbé aríjà sorò ló mú won di ìlé àgbójà. 

	Ìtumò:		Isé owó tí wón ń se ló mú ki wón máa pe àdúgbò won ni òsúnaró. Isé aró rife ni wón fi sísé òjó won, bí ó tilè jé pé isé aró ríre yìí kò wópò láàrin won mó 

	Ìtumò:		Nínú agbo ilé yìí láyé àtijó, wón ní àwon omo agbo ilé yìí máa ń wéré nígbà náà, èyí ló mú kí won máa pe agbo ilé won ní ilé léwèéré. 

	Ìtumò:		Wón ni inú àwon tí ń gbé àdúgbò yìí té púpò, won kì í ba èèyàn jà rárá, wón sì máa n ba èèyàn dámòràn púpò tàbí gba ènìyàn nímòràn nípa ohunkóhùn tí ba se ènìyàn. Idí nìyí tí wón fi ń pé wón ní ilé ìbágbé. 

	Ìtumò:		Wón ní ní ayé àtijó bàbá kan wà tí ó máa n sòrò tí yó sì yo kòmóòkun òrò tó bá so pèlú, àwon aládùúgbò tí ò tí won máa ń wá kó ìlànà tí ènìyàn fi máa ń ba ènìyàn sòrò tírú eni béè yó sì gbó òrò náà ni àgbóyé. Idi nìyí tí wón fi so ilé máa ní ilé agbédè. 

	Ìtumò:		Wón ní ìdí ti wón fi ń pe àwon ní òkódò ni pé ilé àwon ti omi pé omi yìí gan-an ló sì yí àwon ka pèlú. 

	Ìtumò:		Ìtàn so fún wa pé, nítorí pé àwon tó wà ní agbo ilé yìí féràn láti máa yin olúwa logo ni wón se so wón di agbo ilé ògo. 

	Ìtumò:		Sàngó ni wón so pé àwon tí wón wà nínú ilé yìí máa ń bo láyé àtijó, ibè gan-an ni a lè so pé ojúbo sàngó gan-an wà nígbà náà láti ìgbà tí à ń wí yìí ni wón ti ń pè wón ni agbo ilé baálè Sàngó. 

	Ìtumò:		Wón ní àwon omo tó wà ni agbo ilé yìí burú ju èpè ìdílé lo láyé àtijó tó fi jé pé òkò ni gbogbo àwon omo yìí máa ń lè kiri àdúgbò nígbà náà, èyí ló mú won so orúko agbo ilé won ní agbo ilé òkò. 

	Ìtumò:		Orúkò enìkàn tí ó kókó dé àdúgbò nì wón fi so àdúgbò náà ni orúko rè. Wón ní òun gan-an ni wón fi je alága àdúgbò náà. 

	Ìtumò:		Wón ní eni tí ó bá sè ni àwon ilé yìí máa ń gbé ni gídí gánún lo bá baálè láàfin rè láyé àtijó, won kì í jé kí esè irú enì béè kanlè títí tí won ó fi gbé e dé ibi tí wón bá gbé e lo. Ìdí nìyí tí wón fi ń pe ilé yìí ní agbo ilé ògìdìgànún

	Ìtumò:		Adúgbò yìí náà dàbí ti okè tí mo kókó menu bà télè, orúko eni tí ó kókó dé àdúgbò yìí ni wón fi so àdúgbò yìí lórúkò tí wón sì ń jé orúko náà di òní olómìí yìí. 

	Ìtumò:		Ìtàn so fún wa pé, wón le nílé béré yìí láyé àtìjó, Ìbèrù yìí ni wón gbìn sókàn àwon ènìyàn láti má jè é kí àwon omodé máa ta félefèle lo sí àdúgbò won láti se ohunkóhun. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè wón nílé bérí. 

	Ìtumò:		Ní ayé àtijó, wón ní kò sí irú ojà tí ènìyàn lè gbé dé agbolé yìí tí kò ní rí tà. Ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ni ilé òòtà. 

	Ìtumò:		Wón ní ní  ayé àtijó, wón ní ilé kan soso tó wà ni àdúgbò yìí pa amò ni wón fi kó ilé náà, fún ìdí èyí tí ènìyàn bá ti ńlo ibè won a ní ilé monde, ilé móńdé. Ìdí nìyí tí wón fi só dilé móńdé. 

	Ìtumò:		Gégé bí a se mò pé sàká gan-an jé Ìtore àánú fún àwon aláìní ènìyàn, èyí lò mú kí àwon ara ile ońsàká sora won ni orúko yìí nítorí pé wón ní bàbá kan wa ní agbolé yìí ni ayé àtijó to máa ń se ìtore àánú fún àwon ènìyàn lopolopo. Bí àwon alámùlégbè won se so won ní agbolé ońsàká nìyen. 




#Article 15: Àwọn àdúgbò ìlú Ilé-Ifẹ̀ (3104 words)


Ìtumò:		Agbolé yi jé ibi tí òsùpá ìjíó wà ìdí nìyí tí wón fi ńpè ni ìjíó 
	

Ìtumò:		Ìwádìí so fún wa wípé nígbà tí òrànmíyàn fé wolè ó so fún àwon àgbà ifè wípé tí won bá tí ní ìsòre kí wón má pé òuni kò pé ní àwon àláìgbàgbó kan bí lope láìsí ìsòrò bí óse fí ìbínú jáde sí wón tí ó sí ńbe wón lórí lo ibè ní àwon àgbègbè bá le pàdé rèní wón bá so fún wípé kó má bínú pé àwon omorè náà ní bí àwon àgbàgbà se so wípé Ìré-lórí-mo Iremo. 

	Ìtumò: 		Àgbolé yí jé ibi tí wón má ń sin àwon tó bá pokùnso sí idi ní tí wón fí máń pè ní lókòóré 

	Ìtumò: 		Nípa sè erú ní orúko yíi ti je jáde erú kan ti olówó kan ni agbègbè yíi ni óni ogún ni ojó kan wón níkí o gun orí àjà lo láti lo sisé ó gún orí àjà naa ó sì bímo sí ibè osì so wípé láti ojó naa ni aboyún àdúgbò naa yo tí má bímo sí orí àjà àwon tí kò sí tèlé ohun tí ó so omo yìí, omo won ń  bèrè sí ń ku. 

	Ìtumò: 		Ni àdúgbò yíi isu ti ó dára pò ni ibè, ìdí ni wípé wón ńbe ógbin isu ògbìn isu daradara íbè wón sí má ń di isu ní ìdì, bí ìdi ní, ìdi nìyí tí wón se ń pe ni Arùbidì 

	Ìtumò: 		Eku ní wón sábà má ń rú ní àdúgbò yí àti egúngún ìdí nìyí lí wón se ń pen í Kééku 

	Ìtumò: 		Orúko àdúgbò yìí je yo ni pa sè olóyè Akogun, ìta olóyè Akogun ni wón so di Itakogun. 

	Ìtumò: 		Ìtàn so wípé oya ni ó rò sí àdúgbó yìí 

	Ìtumò: 		Jé ibi ti wón má ń sin àwon tó bá kú pèlú oyún síi 

	Ìtumò: 		Ènìyàn kan tí ó tì Ibòmíràn wá ti ó sì wá di olówó àti olórò jù eni tó gba látì dúrò lo. 

	Ìtumò: 		Jé ibi tí wón má ń sin àwon tí ó bá fori sole kú síi 

	Ìtumò: 		Jé Ibì tí àgbon pò sí ni wón fi ń pè ní Ìtà àgbon. 

	Ìtumò: 		Ìtàn so wípé  àdúgbò yí jé bi tíó jé àlà nígbà tí ifè àti ilésà fé má jà sí ilè wón wá so wípé kí àwon mó jà pé tí ó bá din í òla kí á jí sí ònà kí á pàdé ara sùgbón àwon ilésà kò sùn sùgbón ifè tí sùn ìgbàtí wón má jí ilésà tí dé òdò won, wón wá wò pé Enu owá la ó ma pe àdúgbò yi Enuwa.

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé ibi tí wón ti má ń ro okó àti àdá àwon Àgèdè 

	Ìtumò: 		Orúko àdúgbò yíi wá nipa sè wípé ó jé Ogbà tí olórun fí Adámù àti Éfà sin i ìsèdálè ayé gégébí ase mò. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yi jé ibi tí odùduwà àti àwon omo rè ti jo se Àjorò kí wón tó pín yà. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé yo nípa sè lúwon gbágidá tí ó jé óbìnrin àkókó tí ó jé òòni 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé yo nípa sè oba Adékúnlé Abewéla

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo òrànmíyàn. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo ògún lákoko olójó. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Èsù-Obásan. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yì je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Òduduwà. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Obàlùfòn. 

	Ìtumò: 		Adúgbò yí je yo nípa sè olóyè tó má ń bo Orè. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí ní òrúnmìlà dé sí nígbà tí o de sí ilú ilé-Ifè.

	Ìtumò: 		ó jé ibi odò tí wón tí fí Èlà, tí ń se omo morèmi rúbo, òun ní wón sínpè ní, Mòkúrò. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé yo nípa sè ìyá Oba adésojí Adérèmí tó jé àfé kéhìn tí ó má gbá àwon imín àwon eran tí ó má ń wá níta ilé wón òun ní wón wá so dí ajígbáyín 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé yo nípa sè olóyè tó má ń bo Elésìje. 

	Ìtumò: 		Jé ibi tí won má ń sin àwon tí ó bá kú pèlú Oyún si. 

	Ìtumò: 		(Enuwa Square) Eni tí ó te agboolé náà dó ni orúko rè ń jé Jétawo, Ìdí nìyí tí wón fi so ilé náà ní jétawo. 

	Ìtumò: 		Nígbàtí kò sí ààyè mó láti kólè sí mó ní ilé-Jétewo (Enuwa) Àwon omo Àkàntìokè wá lo sí Adugbo Ìtà-Òsun. Ìdí nìyí tí wón fi máa ń so wípé Enuwa kò gbàà yè, lówá yalémo ó lo Ìta-òsun. 

	Ìtumò: 		(Ìlórò Square) àdúgbò morèmi jé Àdúgbò ibi tí ojúbo òrìsà morèmi wa. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí jé ibi tí omí-odò kan tí won ń pè ní Atan wa, ìdí nìyí tí won fi ń pe Àdúgbò náà ní Òkè-Àtan. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yí ni Oba Láfogído wolè sí, ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Láfigído.

	Ìtumò: 		(Enuwa Square) Oba Olófin pe sèru láti Ìta-ye mò ó wá sí agbègbè Enuwá láti wá tèdó. Ìdí nìyí tí wón fi so Àdúgbò náà ní Ilé-Sèru. 

	Ìtumò: 		Orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó ni Alákàá. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Ilé-Alákàá.

	Ìtumò: 		(Enuwa Square) Òkòrí ni orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó. 

	Ìtumò: 		(Enuwa Square) Orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó ni Àlútú. 

	Ìtumò: 		(Enuwa Square) Àká ni orúko eni tí ó te àdúgbò náà dó.

	Ìtumò: 		Orúko eni tí ó te àdúgbò yí dó ni Ogua Ògìdigbo, O yè ti o jé ni Obaloran, isé ré nip é ó ní àse láti gbésè lé èsè késè ti àwon ènìyàn tàbí ará ìlú bá dá. èyí túmò sí Oba-ló ni òràn. Ìdí tí won fi so àdúgbò yí ni Agboolé Obàloràn. 

	Ìtumò: 		(Ilódè-Oríyangí Square). Ní ayé àtijó, eni tí ó bá kó isé-Ifá, tí ó tó àkókò láti ní Odù-Ifá, ilé tàbí àdúgbò yí ni wón máa ń lo láti gba Odù-ifá náà. 

	Ìtumò: 		(Láàkáyè) Láakáyè ni oruko eni tí ó te àdúgbò yí dó. Àdúgbò yí tún jé ibi tí won ti máa ń bo Oya. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ni Ògbón-Oya. 

	Ìtumò: 		(Oríyangí) Eni tí ó te agboolé yí dó jé Aláwo. Ìdí nìyí tí won fi so ilé tàbí àdúgbò yí ní Ilé-Obàsa o. 

	Ìtumò: 		(Èdènà) Orúko eni tí ó te àdúgbò láà dó ni Òpá, Ìdí nìyí tí won fi so agboolé náà ní ilé-Òpá.

	Ìtumò: 		Orúko ìyàwò Obalòràn ni ó ń jé omìtótó, òun ni eni tí ó te àdúgbò náà dó. 

	Ìtumò: 		Orúko eni tí ó te agboolé náà dó ni Déboóyè. 

	Ìtumò: 		Orúko eni tí ó te agboolé náà dó ni won Ìdú-Oládère. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní Ilé-Ìdú. 

	Ìtumò: 		(Ojà-Ifè) Orúko eni tí ó te agboolé náà dó nì ó ń jé Olákòró. 

	Ìtumò: 		(Mòòrè Square) Oba òjájá ni ó te Àdúgbò náà dó. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò ibi yí jé ibi tí Ojúbo Obàtálá wà. Òpá tí won máa ń ta tabi ní gbàtí wón bá ń se odún Obàtálá. Ìdí nìyí tí won fi ń pe àdúgbò náà ní Igbó-Ìtàpá. 

	Ìtumò: 		Obalásè jé orúko eni tí o máa ń bo Olúorogbo, òun sin i eni tí te àdúgbò Obalásè dó. 

	Ìtumò: 		Ilé yìí jé ilé tí won ti máa ń bo Odùduwà. 

Ìtumò:		Oníjà-kìí-sá ni Orúko eni tí ó te àdúgbò yí dó. Ìdí nìyí tí wón fi so àdúgbò náà ní Njasa.

	Ìtumò: 		Ilé yìí jé agbo ilé tí won ti máa ń je oyè ní ayé àtijó, sùgbón nígbà tí ó yá won kò rí omo okùnrin tí yóò je oyè mó, nígbà tí ó pé òkan lára àwon ìyàwó agbo ilé náà bí omo Okùnrin kan, èyí tí won fi je oyè náà, tí won sì ń pe orúko rè ní Oláyodé orúko olóyè yìí ni wón fi so agbo ilé náà tí won fi ń pèé ní Oláyodé. 

	Ìtumò: 		Ilé Olókó jé ilé tí a mò sí ilé àgbède tí ó jé pé isé okó ní isé tí won. Kò wá sí orúko tí àwon ènìyàn lè fi pè wón, wón bá so ilé won ní ilé Olókó. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí jé agbo ilé Eléégún, eni tí ó jé olórí àwon eléégún yìí ni a ń pè ní Ààre-òjè. Orúko rè ni àwon ènìyàn fi so agbo ilé yìí. 

	Ìtumò: 		Ilé Jagun ni ilé tí àwon ènìyàn mò gégé bíi ilé Olóógun, nígbà tí ayé sì wà láìsí omo ogun rárá. Eni tí ó je olórí Ogun nígbà náà ni Jagun. Wón wá so agbo ilé rè di ilé Jagun nínú ìlu. 

	Ìtumò: 		Bàbá kan ní agbo ilé yìí tí orúko rè ń jé òjó tí ó féràn láti máa jó ijó bàtá ni à ń pè ní Òjóbàtá tí a fi so agbo ilé yìí ní Òjóbàtá. 

	Ìtumò: 		Asé ni wón máa ń hun nínú ilé yìí bíi isé e won ìdí nìyí tí a fi so agbo ilé náà ní ilé Baba Alásé 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni a ti máa ń je oyè Badà. Ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Badà. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni wón ti máa ń je Oyè Baálè-Àgbè ìdí nìyí tí won fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Bálè-Àgbè 

	Ìtumò: 		Ní ìgbà àtijó Okùnrin kán wà tí ó jé elégun tí àwon ènìyàn máa ń pè ní Baba-Elégun, nínú ilé náà ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fi ń pe agbo ilé náà ni ilé Baba-Elégún. 

	Ìtumò: 		Orúko Oyè won ní agbo ilé yìí ní Máyè, ìdí nì yí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Máyè. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni wón ti máa ń je Oyè Àgòrò, ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Àgòrò. 

	Ìtumò: 		Orúko Oyè tí won ń je bákannáà ní agbo ilé yìí, ni wón fi ń pe ilé náà ní ilé Baálè

	Ìtumò: 		Eyelé ni wón ń sìn gégé bí ohun òsìn nínú ilé yìí, ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní agbo ilé Eléyelé. 

	Ìtumò: 		Ìlé yìí jé ilé tí won ti máa ń lu sèkèrè, ìdí nìyí tí wón fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Alusèkèrè. 

	Ìtumò: 		Ní agbo ilé yìí ni wón ti ń sin òni, ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Olóní. 

	Ìtumò: 		Orúko oyè won ní agbo ilé yìí ni Basòrun, òun náà ni a sì fi ń pe agbo ilé yìí. 

	Ìtumò: 		Okùnrin kan ní agbo ilé yìí ni à ń pè ní Ààre ìlù tí ó jé olórí àwon onílù, Orúko rè ni a fi so agbo ilé yìí. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ní ayé àtijó ni àkóbí oba tí à ń pè ní Dáódù kó ilé sí, ìdí nìyí tí wón fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Dáódù. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni ilé tí agbápò sango ń gbé, agbápò sàngó yìí ni à ń pè ní ìkólàbà, ìdí nìyí tí a fi n pe agbo ilé náà ní ilé Ìkólàbà. 

	Ìtumò: 		Ní ayé àtijó eni tí ó jé baálé ilé náà onífá ni, sùgbón nígbà tí ó kú tán, gbogbo àwon omo ìlé náà àti ègbón àti àbúrò ni won ń se èsìn ifá yìí, ìdí nìyí tí wón fi so agbo ilé náà ní agbo ilé Arífájogún. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni àwon tí won máa ń ko ilà fún àwon ènìyàn wa. ìdí nìyí tí a fi ń pe ilé náà ní ilé Olóólà 

	Ìtumò: 		Ní ayé àtijó ní agbo ilé yìí àwon egbé kan fi baba àgbàlagbà kan je baba ìsàlè inú egbé e won, ilé tí baba yìí ń gbé ní àwon ènìyàn so di agbo ilé Baba-ìsàlè. 

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí ni eni tí ó jé Olórí àwon alápatà tí à ń pè ni Séríkí ìnú ìlú náà wà, agbo ilé tí ó ń gbé ni à ń pè ní agbo ilé Séríkí. 

	Ìtumò: 		Orúko agbo ìlé yìí ń tóka sí ilé tí wón ti ń dá oko ju, tí won sì ní oko jù ní inú ìlú, ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé Alókońgbó. 

	Ìtumò: 		Láti ayébáyé ni onílé yìí ti ń sin adìe, kí ó tó kú, núgbà tí ó sì túnkú àwon omo rè náà tun ń sin adìe náà. ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fi so agbo ilé náà ní ilé Aládìe

	Ìtumò: 		Agbo ilé yìí jé agbo ilé tí ó súnmó Odò, tí awon ènìyàn si so di agbo ilé Asúmádódò. 

	Ìtumò: 		Láti ayábáyé ní agbo ilé yìí ni a ti rí àwon àgbè tí ó jé pé isu kìí wón ní orí àjà won, títí tí àgbodò fi máa ń dé, ìdí nìyí tí won fi so agbo ilé náaà ní agbo ilé Anísulájà. 

	Ìtumò: 		Ilé yìí ni ilé tí wón ti máa ń sin ajá lópòlopò fún títà, tí àwon ènìyàn sì ń pe agbo ilé náà ní ilé Alájá. 

	Ìtumò: 		Ilé yìí ni ilé tí eni tí ó máa ń lu aro wà tí ó ń gbé, tí àwon ènìyàn sì ń pe agbo  ilé rè ní ilé Alaro 

	Ìtumò: 		Ìlé yìí jé ilé tí baba kan àti ìyàwó re wá tèdó sí láti ìlú Tedé tí wón sì bímo sí ibè tí won sì di púpò ní agbo ilé náà. ìdí nìyí tí a fi ń pe agbo ilé náà ní ilé baba-Tedé.

	Ìtumò: 		Nípa sè Èrédùmí tí ó jé Olusìn Òrànmíyàn tí ó sì ma ń fún oòni tí ó bájé ní idà. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí ni Odùduwà wolè sí. Wón sì ń pe àdúgbò yìí ni odùduwà fún ìrántí. 

	Ìtumò: 		Wón ń fi orúko yìí rántí Gómìnà ìpínlè òyó àná fún isé ribiribi tí ó gbé se. 

	Ìtumò: 		Bàbá tí a ti ipasè rè n pe Òpa ni Akíngbolá. Agbo ilé yìí wà ní ègbé àfin Oba. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí ni wón fi ń se ìrántí pédrò gan-an fún rarè tí ó gbé ìgbé-ayé tí o burú jojo.

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí ni a fí ń se ìrántí Oba àná tí ó wà jà 

	Ìtumò: 		Bàbá ològùn ni ó te ibè dó, Orúko yi wá jásí aláki ajámopó, Bàbá olóógùn yi ma ń já omo nínú apó ni wón so di ajámopó. 

	Ìtumò: 		Òsun kan wà tí orúko re ń jé òjìyàn ibè ni okúka kán wá tóní ojú ihò méje gégé bi poón ayò tí enikéni kò mò enití ó gbe ìdí èyí ni wón fi sodi ìta òsun. 

	Ìtumò: 		Okùnrin kan lo ma ń gba ibè lo sí inú oko rè nígbà tí ń kan rè dàgbà tan olè ma ń wo inú oko rè lo, ìgbà yen ni bale la ojú ònà ibè ìdí èyí ni wón fi ń pe nì òkèsòdà. 

	Ìtumò: 		Ibití oòni Ilé Ifè bòǹsè rè sí nígbà tí wón bá ń se odún òrìsà kan tí a ń pè ní jùgbè ìta ni wón sì ti ma ń se odún náà ni wón so di ìtasìn

	Ìtumò: 		Ìdí tí wón fi ń pen í òkèrèwè nip é ògbón ni ojó, nígbà tí enití ó te ibè dó fi so pé òun á kó ilé òun sí orí òkè níbí ibè ni wón so di òkèrèwè. 

	Ìtumò: 		Ògbón nì o náà ń jé ifájuyì ni wón ń pe ttélè nígbà tí enìkan kú tí wón sì dá Ifá  níbè pé kí wón ma gbé òkúrè àfi tí wón bá sin sì ibè, bíwón se bèrè sip è ní fájuyì nìyàn. 

	Ìtumò: 		Omo aládé ni wón ń jé télè, nígbà tí wón dá Ifá tí ifá mú enití adé tósí ni wón sí bèrè sí pe ibè ni lúgbadé 

	Ìtumò: 		Ògbón ni ibè ń jé ògbón Oya yen wón ti ibì kan ya wá ni wón wá te ibè dó ni wón fi kó ilé síbè bíwón se bèrè sí pè wón ni ògbón-oya. 

	Ìtumò: 		Àwon ará ilé òpá ni wón, níbè ni wón tí so pé àwon ń lo si oko àwon ni olórò ni wón fi ń pé gbogbo ibè ni ìlórò. 

	Ìtumò: 		Àwon ìdílé Obaláyè ni wón ní ibè sùgbón òkè kúta ni wón n pe ibè òkè kúta pò níbè ni wón fí so ibè di wánísánì òkè kúta 

	Ìtumò: 		Omi tí ó wà níbè láyé ni wóni sì ti ma ń pon omi náà bíwón se so ibè di odo Yàrá. 

	Ìtumò: 		Obu ìjéta ni ó je oba níbè ibi tí agbo ilé náà wa ni wón ń pe nì ìta-òtutù bí wón se so ibe di otutu niyen. 

	Ìtumò: 		Ìdí tí wón fi ń pe ibè ni látalè ni pé ilè ni wón ń tà níbè ni ayé àtijó, bí wón se so ibè di látalè (compound) 

	Ìtumò: 		Ìdí tí wón fi ń pé ni yèèkéré ni pé nígbà tí enití ó te ibè dó bèrè si pin ilé fún won ní won bèrè sí so pé yèèkéré ìdí èyí ni won fi ń pen i ìyékéré. 

	Ìtumò: 		Ní ayé àtijó ènítí ó te igbó òyà dó ni okùnrin. Òyà ni ó sì ma ń pa nítorí pé kò sí isé nígbà náà ju isé ode lo bíwón se bèrè síí pe ibè ni ìgboyà. 

	Ìtumò: 		wón ń pe ibè ní aroko nítorí pé oko ni wón ma ń jù ní gbogbo ojó ayé wón ìdí nìyen ti wón fi ń pen i aroko. 

	Ìtumò: 		ó jé sírítí tí wón ma ń gbà lo sí òndó bí wón se bèrè sip é ni òndó Road ojú ònà, òndó. 

	Ìtumò: 		Ìdí tí ó fi á jé orúko náà ní pé wón ma ń jòró opó ni àdúgbò náà ìdí nìyen ti ó fi ń je ìtáolopo

	Ìtumò: 		Ìdí pàtàkì ti o fi á jé òrunobadó nip é ni ayé àtijó tí oba bá fé wàjà tí ó bá ti wo odò tàbí kànga náà á lo sí òrun bí wón se bèrè sip é ni òrunobado nìye 

	Ìtumò: 		Ní àdúgbò jàrán yi àrán ni wón ń jàn nibe láyé àtijó bíwón se bèrè sí pen i jàrán nìyan. 

	Ìtumò: 		Ní ayé àtijó bàbá kan wá  tí ó má ń gun esin yówá sí àdúgbò náà láti ìgbà yen ní wón ti bèrè sip e ibè ní agesinyówá. 

	Ìtumò: 		àdúgbò ògbón àgbàrá yìí àgbàrá ma ń sàn níbè gan ti wón sì ma ń fi igbá gbón omi náà kúrò lónà, bí wón se so ibè di ògbón àgbàrá. 

	Ìtumò: 		Ìgbódò jé ìdílé tí wón ti ma ń gbé odó ìgbà tí enití ó ń gbé odó náà kú ni wón bèrè sí so ibè di igbódò. 




#Article 16: Àwọn àdúgbò ìlú Iléṣà (1708 words)


	Ìtumò: 		Ìbí yìí ni àwon omo ogun Ìjèsà gbà lé àwon òtá won ni ìgbà ogun ni èyí, èka ède ló fà á tí ó fi jé Ìkótì. 

	Ìtumò: 		Orúko owá ketàlá tó jè ni Ilésà ni Bíládù Arère, ìrántí rè ni won fi so àdúgbò yìí ni orúko rè. Nìgbà tí ò ti dé orí oyè, ó wá gbajúmò débi pé fí àwon èèyàn ba n lo si àdúgbò yen, dígbò ki won so pe àwon n lo si ògbón wón á ni àwon n lo sí ilé Bíládù bí wón se so ó àdúgbò yìí di Bíládù nìyí 

	Ìtumò: 		ibi tí àwon jagunjagun Ìjèsà pelu àwon omo Ogun Èkìtì ti pàdé ní ìgbà Ogun ni àdúgbò yìí torí pé ota ìbón pò ni ilè ibi yìí léyìn Ogun yìí ni won se so o ní ota pèté. 

	Ìtumò: 		Omi kan wà ni àdúgbò yìí tí won ń pè ni asorò tori omi yìí ni won se so àdúgbò yìí ni omi-asorò.

	Ìtumò: 		Àwon ènìyàn gbà pé igbó tí ó wà ni àdúgbò yìí ni ìgbà àtijó ni àwon abàmì lópòlópò eni tó sì mú ki won gbà pé òràn ni yóò ri, Orìn-ken-òràn (èdè Ìjèsà) O rìn kan òràn. 

	Ìtumò: 		Igi ààyàn kan wà ní agbègbè yìí tele èyí ló fàá tí won fi so àdúgbò yìí ní ìdí àyàn. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí ni ilé Obalógun Ilesa wà ní àkókò ti won so orúko àdúgbò yìí (Ìta-Obalogun).

	Ìtumò: 		Ibi yìí kojá ibi tí ìrókò kan wà díè, èyí ló fà á ti won fi so pe o-mu-iroko (èdè Ìjèsà) ìtumò-mu-iroko nip é ó kojá ìrókò mùrókò. 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon Haúsá ń gbé tí won sí ti n ta ojà, àlejò ni arè ní èdè Ìjèsà 

	Ìtumò: 		Àwon tí won ón dá ara won sà sí ònà kan ni ìtumò ìdásà, àwon kan kúrò ni àárín ìgboro, wón sì lo da àdúgbò yìí sílè ni won ba so o ni Ìdásà. 

	Ìtumò: 		(Páàdì) Ibi yìí ni àwon Òyìnbó ìjo Rátólíkì tí a gbà pé won mu ìgbàgbó wá ń gbé nígbà yen ni òkè-Páàdì. 

	Ìtumò: 		Eni tí ó kókó dá àdúgbò yìí sílè bínú kúrò láàrin àwon ènìyàn lo dá dúró síbè ni, èyí ni awon ènìyàn fì so ibè ní arágan torí pé, wón gbà pé ìwà eni tí ó kókó dé àdúgbò yìí kò jot i ènìyàn tó kù lò fàá to fi wá dá àdúgbò tirè sílè.

	Ìtumò: 		Òtè ló gbé àwon tó kókó de adugbo yìí dé ibè torí pé wón ń gbèrò láti yan olóyè láàrin ara won, Owá gbó èyí ló bá lé won kúrò ni ibi tí won ti wá télè. 

	Ìtumò: 		Àwon tí ó kókó dé adúgbò yìí jè ólòwó pàápàá àwon tí ó kókó jáde to se awo ni èyìn odi tí won fi wá n kólé sí ilé. 

	Ìtumò: 		àdúgbò yìí ni won ti máa n ta aso àwon oyinbo nigba tí àwon kòráà kókó gbé aso títà dé Ilesa, ìdí niyi ti won fi n pè é ni Òkè-eso. 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon tó ma n se isé onà pò jù sí láyé àtijó, ìtàn so fún wa pé ibè ni won ti máa n hun òpá àse àti ìlèkè owá, tí àwon ìyàwó rè àti àwon olóyè. 

	Ìtumò: 		Ìgi ìgandò kan náà ló wà ní àdúgbò yìí láyé àtijó. 

	Ìtumò: 		Àwon désìn kinyó ló so àdúgbò yìí ni òkè ayò nígb`atí won kó ilé ìjósìn ati ibi ìsojí àti lé isun won síbè. 

	Ìtumò: 		Ìtàn so pé àdúgbò yìí àwon omo ogun ti níláti gbéra lati sigun lo sibi ti won ti fé jagun. Béè náà ni won sì gbódò wá jábò ti won si pin enìati erú tí wón kó bò lójú ogun. 

	Ìtumò: 		ìbi tí ará ìgboro ti má a ń wá pàdé àwon ará oko láti ra ojà lówó won èyí ló fà á tí wón fi so àdúgbò yìí ní Ìlájé. 

	Ìtumò: 		Orúko igi kan tó wà ládùgbóò yìí télè ni wón fi so àdúgbò yìí 

	Ìtumò: 		Ibi tí ó bó sí aopá ìsàlè ní adúgbò òkè ìrò ni odò ìrò

	Ìtumò: 		ibí yìí ni wón ti máa n aso ofì nígbà tí ó kókó dé Ilésà.

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí jè ìbi titun tí òpòlopò àwon tí ó fi jáde nílùú tipé tipé ń gbé òpòlopò won lo ti Èkó wá kólé síle, ojú tì wòn fi wo ìkòyí Estate l’Ekoo ni won fi mu àdúgbò náà. 

	Ìtumò: 		Ibí yìí ni ìlú parí si látijó sùgbón ìlú ti fe séyìn si i ju ibí yìí lo 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon Ìbòkun dúró dí nígbà tí ogún parí ti won wá láti dúpé lówó Owá ti o ràn wón lówó láti segun òtá wòn (A-de-eti-owá) À dé tòsí ilé Owá Adètí Owá. 

	Ìtumò: 		Àwon ará Òwò ló so adúgbò yìí lórúko yìí, àgbàdo ni won máa n tà níbè télè bóyá àgbàdo tí won máa n dàpè ní okà ló fa orúko yìí. 

	Ìtumò: 		Ní ìgbà àtijó àwon ìyá àgbà má a n se àdín níbí yìí (Ùmàdín) 

	Ìtumò: 		àdúgbò titun tó jáde lara Ìmàdín nìyí 

	Ìtumò: 		Òríkì èèyàn tí ó kókó kólé sí àdúgbò yìí ni won fi pe ibí yìí. 

	Ìtumò: 		Ìkòkò ni àwonìjèsà máa ń dà á pè ní ìsà. Àdúgbò yìí sì ni wón ti máa ń ná oyà ìkòkò saájú kí ilésà tó di ilé-ìsà. 

	Ìtumò: 		Ìsò okùn ló di ìsokùn yìí, ibè ni àwon àgbè àti elému ti máa ń wá okùn láti fid i erù tàbí òpe-emu won ní ìgbà láéláé. 

	Ìtumò: 		Igi osè ńlá kan ló wà ní ìbí yìí ni ìgbà láéláé tí àwon ènìyàn máa ń dúró ta ojà mí abé rè. 

	Ìtumò: 		Ìbí yìí ni wón ti máa ń bo ògún owá ní ìgbà àtijó, wón sì máa ń pa ajá ògún sí ibé yìí títí di oní. 

	Ìtumò: 		Ibí yìí ni àwon ológun máa ń dúró sí de àwon òtá ní ìgbà láéláé, ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ní ìta akogun. 

	Ìtumò: 		Àgékúrín fún “A dé etí owá” mí èyí, ibè ni àwon ará ìbòkun dúró sé nígbà tí ogun parí tí wón fé wá dúpé lówó owá-omo-Ajíbógun tó ràn wón lówó láti ségun àwon Ìlàré. 

	Ìtumò: 		Òrúko akoni kan tó wá láti ìbòkun sùgbón tó wolè láàrin ìlésà àti ìbòkun nígbà tí ó gbó pé ogun ti pa ìyàwó àti omo òun mi ìbòkun. 

	Ìtumò: 		Orí egúrù ló di Erégúrù, ìlè tó le ló wà ní ibí yìí télè àwon omodé sì máa ń seré níbè. 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon tó má a ń se isé onà pò jù sí láyé àtijó ìtàn so fún wa pé ibè ni wón ti máa ń hun òpá ńlèkè owá, tí àwon Olóyè rè àti ti àwon ìyàwó rè. 

	Ìtumò: 		Orúko ìgbàlódé ní èyí, Arágan ni orúko àdúgbò yìí télè wón sèsè yíi padà sé Aráròmí ni 

	Ìtumò: 		Ìgi Isis ńlá kan ló wà ní ibí yìí télè tí àwon ènìyàn máa ń ta ayò ní idi rè èyí ló di ìtà-isin lónìí (Ìhnsin). 

	Ìtumò: 		Orúko tuntun ni orúko àdúgbò yìí nítorí pé àwon tó kókó dé ibè kò tètè kólé kan ara won, wón gbà pé àwon bá olórun dúrò. 

	Ìtumò: 		Ní ìgbà ogun, Ibí yìí ni àwon Ológun ìjèsà gbà láti sá àsálà fún èmí won. “Ibi tí a gbà tí a fi yè”ni àpèjá rè. 

	Ìtumò: 		Orí ojà ni wón gé kúrú sí Eréjà, ibí yìí ló jé bíi oríta fún gbogbo àwon ìlú kékèèké ibè sì ni wón ti máa ń pàdé láti ta ojà won. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò tuntun ni èyí, àwon tó sì fún un ní orúko yìí yá a lò láti ìlú Èkó ni. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò tí omi tí àwon ènìyàn máa ń pon ní ayé àtijó, omo yìí wà ní ìtòsí ibi tí wón máa ń dá oko sí, èyí ni wón fi máa ń pè é ní omi-oko. 

	Ìtumò: 		Ibí yìí ni ilésà dé ní àkókò yìí, èyí ló fà á tí wón fi ń pe ibí yìí ní Enu-Odi. 

	Ìtumò: 		Ìróyè yìí kò jìnà sí ìgbàyè, ibè ni àwon tó sá fún èmí won ní ìgbà ogun ti kókó dúró. 

	Ìtumò: 		Àwon tí ó kókó dó àdúgbò yìí jé olówó, pàápàá wón jé òkan lára àwon tó kókó jáde lo sòwò ní òkè oya tí wón wá ń kólé sílé. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí kò jìnà sí omi kan tí àwon ènìyàn máa ń mu, èyí ló jé kí àwon ènìyàn máa pe àwon tó ń gbé àdúgbò yìí ní òlómilágbàlá. 

	Ìtumò: 		Àgbède kan wà ní àdúgbò yìí ní àkókò tí wón fún un ní orúko yìí, omo Èfòn alààyè ni àgbède yìí.

	Ìtumò: 		Òrúko Babaláwo kan ni Jìgbà, àdúgbò yìí ló sì máa ń gbé tí ó ti ń se isé owo rè. ìdí nìyí tí wón fi ń pe àdúgbò náà ní òkè-jìgbà. 

	Ìtumò: 		Òmi kan wà ní ibí yìí tí wón ti máa ń fo irú ní ayé àtijó, ìgbà tí àwon ènìyàn téèrè sin í kólé omi irú. 

	Ìtumò: 		Oko kan wà ní ibí yìí ní ìgbà àtijó tí wón ti máa ń sin adie (poultry) omi kan sì wà ní ìtòsí oko yìí, èyí ló mú kí won máa pe omi yìí ní omi aládìe èyí tó di o’ruko àdúgbò náà lónìí. 

	Ìtumò: 		Àdúgbò yìí ti wà láti ìgbà láéláé sùgbón àwon ènìyàn kò tètè wá ko ilé sí ibè, nígbà tí ó sì yá ààrin ìgbà díè ni àwon ènìyàn kó òpòlopò ilé sí ibè, èyí ló mú kí won pè é ní Olórunsògo. 

	Ìtumò: 		Ibí yìí ni àwon àgbè tó bá ń bò láti oko ti máa ń já imò òpe láti di erù won ibè ló di Ìjámò nígbà tí ilé bèrè si ní de ibè. 

	Ìtumò: 		Orúko akíkanjú kan ni ìgbà ogun ògèdèǹgbé ni èyí, ní ìrántí rè ni wón se so àdúgbò yìí ní ògúdù. 

	Ìtumò: 		Òmi kan wà ní àdúgbò yìí télè tí àwon ènìyàn ti máa ń do nǹkan, torí omi yìí ni wón se so àdúgbò yìí ní Ìfofín. 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon alápatà ti máa ń pa eran won fún títà ni wón so di omi-eran. 

	Ìtumò: 		Ibi tí àwon ìyá àgbà ti máa ń se àdín ní ìgbà àtijó ni wón ń pè ní Umàdín ní èka èdè ìjèsà, èyí ló sì di Imàdín lónìí




#Article 17: Ìbàdàn (258 words)


 

Ìbàdàn jẹ́ ilú Nàìjíríà tí ó tó bí jùlo ni apá ìwọ̀òrùn Afríkà, bé ni ó sí jé olúìlú ìjoba ìpínlè Oyo. Ìbàdàn jé ilú àwon jagunjagun. Ìtumọ̀ orúkọ Ibàdàn ni ẹ̀bá ọ̀dàn (Near Savannah).

Ìbàdàn bùdó sí apa gùùsu-ìwòorùn Nàìjíríà, 128 km sínú láti aríwáìlàorùǹ ìlú Èkó àti 530 km láti gúúsùìwọ̀orùn Abuja, olú-ìlú àpapò, bẹ́ẹ̀ sìni ó jé ibi ìgúnlẹ̀ pàtàkì láàrín agbèègbè ẹ̀bá òkun àti àwọn ibi tí wọ́n wà ní àríwá Nàìjíríà. Ibadan ti je gbongan ijoba fun Agbegbe Apaiwoorun atijo lati igba ijoba amusin Britani, be sini apa die ogiri bode to da abo bo ilu na si wa titi doni. Awon alabugbe to poju ni be ni awon omo Yoruba ati opo eniyan lati apa Naijiria yioku.

Ibadan je didasile ni odun 1829 nitori awon rogbodiyan to unsele ni Ilẹ̀ Yorùbá nigba na. Asiko yi ni awon ilu ti won se pataki ni ile Yoruba nigba na bi Ọ̀yọ́ ilé, Ìjàyè ati Òwu je piparun, ti awon ilu tuntun bi Abeokuta, Oyo atiba ati Ibadan dide lati dipo won. Gege bi awon onitan se so Lagelu, nigba na to je Jagun ilu Ife lo da Ibadan sile gege bi àgọ́ fun awon jagunjagun ti won unbo lati Oyo, Ife ati Ijebu.

O tun jẹ ilu abinibi ti Bobby Ologon ti n ṣiṣẹ lọwọ Japan.

Ibadan je pipin si agbegbe ijoba ibile 11. Ninu won 5 wa ni arin igboro Ibadan ati 6 wa ni awon ayika etile Ibadan.

Awon agbegbe ijoba ibile arin ilu Ibadan

Awon agbegbe ijoba ibile ayika etile Ibadan




#Article 18: T.M. Ilésanmí (289 words)


Ojogbon Thomas Makanjuola Ilesanmi ni eni ti o koko gba oye B.A. ni eka-eko ede ati litireso Aafirika ni Obafemi Awolowo University. O sese fi eyin ti ni aipe yii ni leyin igba ti o ti sise ni eka-eko yii kan naa lati odun 1975 si 2005. Opolopo ise ni ojogbon yii gbe se lori ede Yoruba. Die ninu won ni a ko ni ede Geesi ni isale yii.

Ojogbon T. M Ilesanmi gba ise oluko in Yunifasiti ti Ife(Yunifasiti Obafemi Awolowo, nisinsinyi), Ile-Ife, Naijiria, gegebi Graduate Assistant ni Eka-eko Ede Aafirika ati Litireso ni November 25, odun 1975 leyin igba to ti gboye akeko-jade meji lati Yunifasiti Pontifical, ilu Roomu ati Yunifasiti  ti Ife. O gba igbega lenu ise to fi de ipo ojogbon ni osu October, ni odun 1997. Ipo yi ni o wa titi digba ti won fi fi ise sile ni ibamu pelu gbedeke ifisesile ni omo-odun arundilaadorin ni odun 2005.

Bi a ba n wo akojopo ati akosile imo-iwe ojogbon yii, a o rii pe o ni ifokantan ati iteramose. O ti sese di araba ni idi ifi-imo-soro, paapaa, ni eka eko asa Yoruba. Awon iwadii Ojogbon Ilesanmi lori awon ayeye irubọ ati itan ibile se gboogi, won si je itokasi ninu imo isewadii lori Yoruba. Akonimora ati onirele, Ojogbon Ilesanmi ti se agbekale opolopo akosile to je alariyanjiyan, alarojinle ati alakiyesi lori ipede ati ewi Yoruba.

Laaarin akegbe re, Ojogbo Ilesan okan lara awon agba alabojuto fun opo ti o ti se akekoo gboye keji ati oye omowe pelupelu ninu ise -akosile won lori ede ati litireso Yoruba. Awon iwadii ti o jeyo ninu ise-akosile wonyi ni o gba iyi pe won si ferese si ona titun lati ronu ninu eko lori Yoruba.




#Article 19: Orúkọ Àdúgbò ní Òndó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà (1034 words)


Òndó

Ìtumọ̀:Ibi ti olóyè Ọ̀túnba kọ́ ilé sí tí ó n gbé ni à n pè ní òkè ọ̀túnba 

Ìtumọ̀:	Ibi ti àwọn òyìnbó tó mú èsìn ìgbàgḅó wá, ilé ibi tí wón ń gbé tí ó wà lórú òkè tú wọ́n ń pè ni yádì ni àwọn so di òke àyàdí tí àdúgbò náà ń jé dòní. 

Ìtumọ̀:Ìsàlè òndó tí olóyè Ọjọmù kọ́lé sí ni wọn ń pè ni Odòjọ̀mù.

Ìtumọ̀:	Òrìsà kan tí wọ́n ń pè ní odòlúà ní ó tè àdúgbò yí dò, Ibìtí o wọlẹ̀ si ni à ń pè ni odòlúà.

Ìtumọ̀:	Òkè ibi ti ó kọ́lé sí tí ó ń gbé ti peka sí tí wọ́n ń pè ni íÒkèlísà. Lísà ni o wa ní àdúgbò ti a ń pè ni Òkèlísà. 

Ìtumọ̀:Ìdi igi kan ti ẹyẹ oge máa ń pọ̀sí ni wọ́n sọ di Ìdímògé ní ìlú Òndó. 

Ìtumọ̀:	Igi kan wa ti wọ́n ń pè ní igi sin. Abẹ́ igi yíì fẹjú, ó tutu, ó sì gbòòrò tó bẹ́ẹ̀ tí o lè gba èèyàn púpọ̀ láti seré bíì ìjàkadì ayò ọpọ́n abbl. Béì tití ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sí àyíká igi yi ti ó wá di ibi tí à ń pè ni idi isin di òní.

Ìtumọ̀:	ni àdúgbò ti àwọn onísòwò tí ó jẹ́ ìsòbò pọ̀ si wọn a sì máa se kárà kátà wọn ní àdúgbò náà idi nìyí tí Òndó ń fi ń pe àdúgbò náà ni Òkè ìsòwò ni wọ́n igbati ó jẹ́ wí pé òkè ni ó wà. Òkè ìsòwò yíì ni àwọn ìsòbò yíì se àsìse ni pípé rè tí wọ́n fi ń pè ní òkè ìròwò ti ó di òkèrówó títí di òní.

Ìtumọ̀:Ó jẹ́ ibi ti Ògbóni ti bẹ̀rẹ̀ ti wọn n ko ìlédi wọn si, ti wọn bà si ń lọ wọn a mú Ogbó dani gẹ́gẹ́ bí àmìn ẹgbẹ́ wọn. Wọn á ma so wí pé à kìí wòó Àdúgbò yí ni wọn sọ di Ogbo-ti-a-kii-wò tì ò fi di Ògbònkowo lónìí

Ìtumọ̀:	Ọjọ́ ti Òndó ìbá dàrú tí Òndó ìbá túká nítorí awo nlá kan to sẹlẹ̀, ojú ibi tí wọn joko si pètù sọ́rọ̀ òhún. 

Ìtumọ̀:	ìdí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ni ọ̀kà ni pé àwọn ará Ọ̀kà Àkókó lo fi agbègbè yí se ibùgbé. Àwọn ará òkà yii si ti pẹ̀ ni Òndó to bee je ti won ti gbo èdè Òndó yinrinyirin se téwé bá pe lára ose a dose ìdí nì yen tí won ń fi pé won ní òkà Ondo ti o doruko àdúgbò won ti a mo si oka

Ìtumọ̀:	Ijoye nla kan lo nje yege, ibi to tedo di to n gbe bo si owo isale Òndó ìdí niyi ti won fi n pe won ni òdò yègè.

Ìtumọ̀:	Ojà ni won n pen i igele ni èdè Òndó. Tomodé tàgbà won ni o ma fi aro wọn lo oko ni agbèègbè ti a n soro bayii nigba ti  o ba di owo, ale won a pate oja won si ita ile won, titi  ti o fid i ojà ti won náà ni alale. 

Ìtumọ̀:	Ó jé agbègbè ti okuta pos i agbegbe yin i àwon molé molé ti n ma wa ko okuta àwon ni o si so agbegbe naa di ibi-a-n-gbo-òkútà oun lo wa di ìgbònkúta lóní

Ìtumọ̀:Ibi tí Ondo ati Bágbè ti pinya ni a npe ni ìtapín 

Ìtumọ̀:	lósìnlá-là gbalá ni àpètán lósùlá ibè ni won ti kókó ń se osùn tí won ńrà osìn, tí won ńtà osìn ní Ondo.

Ìtumọ̀:	àwon òlàjú ti o kókó lo sí Èkó  ti won tàjò dé ni won so agbegbe yin i sùrúlérè nigba ti won tàjò de lati ma fí rántí agbègbè tí won gbé ni Èkó 

Ìtumọ̀:	Àwon òlàjú ti o koko lo sí Èkó ti won tajo dé ni won so agbègbè yin í Yaba nígbà tí won tàjò dé láti le ma fi rántí àgbègbè ti won gbé ní Èkó. 

Ìtumọ̀:	O je akínkanjú okùnrin kan tí ó lòkíkí ti a wa fi orúko re so agbègbè tí ó ńgbé.

Ìtumọ̀:Olóyè ló ń jé sokoti àdúgbò rè ni won wá so di idim-sòkòtí. 

Ìtumọ̀:Jé ìtà oba tí won ti ń ma pa olè àti òdaràn idà ni a fi ń pa won ibi tí a n tójú idà náà sí ni Ìsídà níwòn ìgbà tí ó si jé pé apá ìsàlè Ondo ló bó sí ni a fi ń pè ní Odòsíndà.

Ìtumọ̀:Ibi tí àwon ará Ondó tí máa ń  jo ibi tí ó téjú tí ó gba èrò púpò ni, ó sì bó sí àrín ìlú a sì ma ń se ìpàdé níbè náà pèlú agbègbè yíì ni won ń pè ní òde Ondó. 

Ìtumọ̀:Ibè ní agbèbbè tí a ma ńkò àwon omobìnrin tí kò tí mo Okunrin si fun Idabobo lowo isekuse ki won tó ní oko ní ayé àtijó agbègbè náà sì ni eré obìtun ti bèrè.

Ìtumọ̀:	O je agbègbè tí òkà ti ń pò ti àwon èèyàn ń rà tí won si ń tà. Ìdí nìyí ti won fi ń pè ní ibi-ìje-okà ti ó di ìjòkà lónìí.

Ìtumọ̀:	O je àdúgbò ti èèyàn kan tédó ni pe bayìí ti o so àdúgbò náà ni orúko Tèmídire: Tèmi-di-ire. 

Ìtumọ̀:	Ó jé agbègbè tí babaláwo kan tí ó gbójú wa ni àtijó a sì máagbà èmí eniyan la pupo lowo iku. Igbàgbó sì ni wipe eni ti o bat i mikanlè lówó Iku lódò rè ko le rí ajínde mo idi niyi ti won fi ń pè ni odò-ìmí-kanlè tí àgékúrú rè wa di odòmíkàn.

Ìtumọ̀:	Eni tó ní ilé ni a ń pè ni ‘nuli’ ni èdè Òndó. Agbègbè yi si wa je agbègbè ti àwon oní ilé ń gbé idi niyi ti won fi n pe ni odò-núlí ti ó wá di odòlÍlí 

Ìtumọ̀:	Orúko ìlagije akíkanjú kan ló ń jé béè. Agbègbè tí ó n gbe ni a fi orúko re so lati se aponle fún un.

Ìtumọ̀:	Baba kan wa ti o ni, irúfé, irúgbìn kan ti a mo si pakala ni ede Oǹdó.

Ìtumọ̀:	Àgbègbè tí àwon elésìn Kiriyó ti máa se ìsìn won fún ìgbalà okàn ni won pè ní òkè-ìgbàlà ti o wa di okegbala lónìí yíì.




#Article 20: Àdúgbò Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà (807 words)


Ìtumò:	Agbègbè yí jé ibi tí àwon ará ìlú orísirísi latí orílè èdè káàkiri gbé ní gbà a ayeye yí ní 1977 (Festival of Arts and culture). 

Ìtumò:	Ibí yí jé agbègbè tí àown Ìbàrì bà ńgbé, nítorínáà ni wón fi pèé ní Ìyànà-Ibà.

Ìtumò:	Abúlé –Ìjèsà ni apá ibi tí àwon ìjèsà kókó pò sí ní èkó, èyí ni ìdí tí ó fi ńjé Abúlé-Ìjàshà. 

Ìtumò:	Ìdí tí a fí só ní mile 2 nìípé máìlì méjì ni ókù láti ibè sí ìbi tó ńjé Tincan-Island.

Ìtumò:	Ibí ni ówà nínú Èkó, orúko yí ni orúko Oba Èkó níìgbà tó tipé, sùgbó orúko rè ni wón fi so agbègbè yí tí ó ńjé kòsókó road.

Ìtumò:	Orúko ènìyàn Tàfá Bàléwà, eni náà jé lára àwon tí ó ti jé ààre orílè wa, lé yìn ikú rè ni wón fi so ibè ní Tàfá Bàléwà “Square”. 

Ìtumò:	Technology Road, ìdí tí wón fi só ní oruko yi nípé, Yaba Technology kò jìnà sí ibè rárá, ìdí náà ni wón fi soóní Technology Road.

Ìtumò:	Ní agbègbè yí enìkan péré ni óní kéké sùgbón nítorí èyí ni won fi so ibè ní kèké, sùgbón ní ìgbà tí àwon òyìnbó fid é ní wón só di kéké.

Ìtumò:	Orúko èyàn ni óún jé Herbert macanlay, eni yì jé okan lára àwon òyìbó tí wón wá sí orílè èdè yí, nítorí èyí ni wón fi só ní Herbert macaulay way.  

Ìtumò:	Ní ìlú Èkó ìdí tí wón fi só ní Maryland  nipé, orúko aya oba ìlú òyinbó ni Mary, ìdí èyí ni a fi só ní Maryland.

Ìtumò:	Èdè yí ni èdè àwon haúsá, ìtumò rè sì ni kíá-kíá, àwon Haúsá ni wón pò sí ibí yìí jù, ní-ìgbà tí wón tèdó tí bè wón kò mò bí wón áse bá àwon èèyàn sòrò, sùgbón nínú ìwònba ìgbà tí wón ń tajà èdè won ni másámásá, ìdí ètí ni wón fi só ní másámásá-kíá-kíá.

Ìtumò:	Ìdí tí wón fi só ní “coconut village” niípé omi pò ní ibè gan, àti cocoanut (àgbon). O wa ni agbègbè Ajégúnlè.

Ìtumò:	Ajégúnlè jé ibi tí wón ti ń ra jà àti ta jà ní Èkó, àti wípé ibè jé lára ibi tìí àwon èèyàn pòsí ní ìlú Èkó, ojà títà sì ń lo déédéé tí aje ati owó dè tińwolé nígbà náà, ìdí náà ni ófinjé Ajégúnlè.

Ìtumò:	Èyí jé orúko agbègbè kan ní ìlú Agége cinema ńlá kan ní ó wà ní ibè, tí wón pè ní PEN-CINEMA.  

Ìtumò:	Ibí ni won sin àwon Ológun tí wón ti won ti kú, wón sìn o àre ńlá kan sí bè tí ó je sójà ológun. 

Ìtumò:	Ilú yíì wà ní agbègbè Àpápá ní Èkó, ìlú ńkí jé ibi tí àwon èèyàn pò si, tí àwon sì gbèrò sí gan. 

Ìtumò:	Ibì jé agbègbè tí àwon custom pò sí, ibè sì ni ibi tí àwon erù sì pò sí àti àwon kòntánà idí èyí ni wón fi pèéní Tincay-Island.

Ìtumò:	Agbègbè èyí ní Èkó ni ilé-isé ibi tí wón ti ń se àwon Okò Volkswagen.

Ìtumò:	Agbègbè yí ni ówà ní Dòpèmú ní ìlú Èkó, ibè ni àwon ohun ìkólé yìí pò sí (aluminum) ìdí náà ni wón fi ń pèé ní aluminum

Ìtumò:	Agbègbè yí ni wón ti má n já erù tí óún bò láti òkè-ògun àti èyí tí wón bá fé gbé jáde, ìdí èyí ni a fi ń pèé ní “port’

Ìtumò:	Lékki jé ibi tí wón kó àwon eléwòn sí ìdí yìí ni wón fi ń pèéní Lékkí.

Ìtumò:	Abúlé òsun jé lára ibi tí àwon abò-òrìsà òsun pó sí ní ìlú Èkó èyí ni wón fi só ní Abúlé-òsu, àti pé omí pò ní bè lópòlópò. 

Ìtumò:	Kiríkirì ni ibi tí àwon eléwòn má n gbéé kiríkirì sì jé lára, ilé èwèn tí ó tóbí jù, nítorí è ni wón fi ń péè agbègbè náà ní kiríkirì.

Ìtumò:	Abílé-Àdó jé lara ibi ti awon àlàdó pos i ni aiye atijo ni ilu Eko opolopo ni ko mo ibe nitori ise ti won nse ni ibe.

Ìtumò:	Eyi je ibi ti nkan alaworan yip o sin i ilu Eko, nkan ti ounje “satellite” nitori náà ni won fi pee ni “Satellite Town”.

Ìtumò:	saw mill jé lára àwon agbègbè tí ó tóbi jù tí wón ti máa n se ìtójú igi tí a fin kólé ìdí náà ni ó finjé saw-mill.

Ìtumò:	Ibi agbègbè ni ibi tí a ti má n rí àwon Haúsá tí wón pò sí jù ní agbègbè tàbí ìlú.

Ìtumò:	“Salvation Avenue” je ibi ti awon elesin Christi posi “choistians”, ibi ti awon elesin bas i posi igbala ni won ma n pariwo (salvation) idi ti won fi n pe ni “salvation Avenue”

Ìtumò:	Idi-Ararba yi je ibi ti idi araba po si lopolopo, agbegbe náà ko jina si mushin ni ìlu Eko.
adugb bariga




#Article 21: Gbólóhùn Yorùbá (915 words)


Síńtáàsì ni èka kan nínú gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Síntáàsì ní òfin ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yí yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn làákàyè elédè sá féré bóyá látaàrí òhún jíje tàbí mįmu ti ó le máa mú elédè so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti opolo red bá padà sípò, yóò so òrò ti ó mógbón lówó. 

Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó èdè Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, 
	
(1)	(a) 	Mo lo sí oko 

		(b)	Sí lo oko mo 

Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò tí yóò first di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu.
O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin bíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé ítéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé ìtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. 

	(2)	(a)	Àwon  ti ó  lo kò pò 
		
(b)	 Àwon  ti wón lo kò pò 

Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé ìtéwógbà, èkejì kò jé ìtéwógbà. Èyí kò ni ǹ kan se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófin mu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú jùlo. 

Ó ye kí á mò wípé òhún àdámó ni èdè jé. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó bí Wón tí ń so Èdè abínibí rè. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àdámó ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè abínibí, ó ti wà lára rè. Kò sí èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. 
(2)	Òrò àti Àpólà: 	Òrò ti a ba tòó pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). 

	(3)	(a)	Olú gíga  lo 
		
(b)	Olú  lo

Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 

	Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: 
	
(4)	GB ---		APOR APIS

Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun  tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). 

(5)	GB ---		APOR AF APIS

Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: 

(6)	AF ---			AS, IB, M, IBM

Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS




#Article 22: Adebáyò Faleti (156 words)


Adébáyọ̀ Àkàndé Fálétí (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Akéwì , Olùkọ̀tàn, àti eléré orí-Ìtàgé, bákan náà ni ó tún jẹ́ oǹgbufọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá, ó sìn tún jẹ́ Omíròyìn orí Ẹ̀rọ asoro-ma-gbesi Radio, Olóòtú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n TV, àti Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ Afíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Western Nigeria Television (WNTV).

Adébáyọ̀ Fálétí náà ló ṣe ògbufọ̀ orin àmúyẹ orílẹ̀-èdè Naigerian National Anthem láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè abínibí Yorùbá. Bákan náà ni ó tún ṣe oǹgbufọ̀ fún ohun tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí lásìkò Ológun, ìyẹn Ibrahim Babangida sọ, pẹ̀lú tí Ààrẹ-fìdíhẹ nígbà ayé Ológun kan rí Chief Ernest Shoneka, nípa lílo èdè Yorùbá tó gbámúṣé. Fálétí ti tẹ Ìwé-Atúmọ èdè Dictionary Yorùbá ní èyí tí ó ní àbùdá ògidì Yorùbá nínú.   Adébáyọ̀ Fálétí ti gba onírúurú àmì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá oríṣiríṣi nílẹ̀ yìí àti lókè Òkun pẹ̀lú. 




#Article 23: Kọ́lá Akínlàdé (3085 words)


Kola Akinlade

	
A bí Kọ́lá Akínlàdé ní ọdún 1924, ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ni Michel Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù mímọ́ ní Ayétòrò. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí ni ó kọjá sí Ìlaròó tí ó sì dá iṣẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé sílẹ̀ ńbẹ̀ fúnrarẹ̀ ni ó ka ìwé gba ìwé-èrí G.C. E. ní ilé. 
	Lẹ́yìn tí Kọ́lá Akínlàdé gba ìwé-ẹ̀rí yìí ni ó dá ìwé ìròyàn kan sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper: Lẹ́yìn èyí ni ó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ìjọba. Ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba ìpínlè ìwọ̀-oòrùn àtijọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. 
	Kị́lá Akínlàdé lọ kàwé ní Yunifásítì Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ó sì tún padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ní ọdún 1976 ni Kọ́lá Akínlàdé fẹ̀yìn tì. Ní ọdún 1980, ó tún gba iṣẹ́ olùkọ́ sí ìbàdàn Boys High School, Ìbàdàn, Nàìjíríà. Ó wá fi ẹ̀yìn tì ní ọdún 1984. Kọ́lá Akínlàdé ní ìyàwó ó sì bí ọmọ. 
	Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni Kọ́lá Akínlàdé ti kọ. 
Lára wọn ni Ajá to ń Lépa Ẹkùn,  Ọ̣wọ̣̣́ Tẹ Amòokùnṣìkà, Àgbákò nílé Tẹ́tẹ́, Baṣọ̀run Olúyọ̀lé,  Ajayi, the Bishop,  Chaka, the Zulu, Esther, the Queen, Abraham, The…..Friend of God, Sheu Usman Dan fodio, Òwe àti Ìtumọ̀ rẹ̀, Sàǹgbá fọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún kópa nínú kíkọ Àsàyàn Ìtàn. 

	Àṣàkẹ́: Òun ni ó jẹ́rìí sí owó kòkó ti Àkàngbé gbà. Ohun tí ó yani lẹ́nu ni pé Ogóje náírà (N140.00) péré ni wọ́n bá ní abẹ́ ìrọ̀rí Àkàngbé nígbà tí ó kú. 
	Àdùnní: Òun ni ìyá Dúró Orímóògùnjé. Àdùnní ti di olóògbé, ìyẹn nip é ó ti kú. 
Ọ̀gbẹ́ni Túndé Atọ̀pinpin: Òun ló ní kí Dúró fi ọ̀rọ̀ owó tí ó sọnù lo Olófìn-íntótó. 

	Ní ọjà, Olófìn-íntótó bá obìnrin kan pàdé. Ó ra ọtí fún un. Obìnrin yìí sì mu ìgò otí kan tán ó sì mu ìkejì dé ìdajì. Ó yẹ kí a sẹ àkíyèsí obìnrin yìí dáadáa nítorí pé òun nì a wá fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jí owó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ jí ní iwájú. 
	Nígbà ti Olófìn-íntótó àti Ilésanmí dé Ilé-Ifè tí wọn ń lọ, ọ̀dọ̀ Àlàó ni wọ́n dé sí. Ilé-Ifẹ̀ ni Àlàó ti ń ta ojà. Àlàó ra obì àti ọtí fún Olófìn-íntótó Olófìn-íntótó mu bíà mẹ́ta. Àlàó ń mu ẹmu lẹ́yìn tí ó jẹun tán Ilésanmú sì ń mu ògógóró. Ọlọ́fìn-íntótó gbádùn láti máà fi ọwọ́ pa túbọ̀mu rẹ̀. Irun tí ó hù sí orí ètè òkè ní ìsàlẹ̀ ibi tí imú wà ni ó ń jẹ́ túbọ̀mu. Àsàkẹ́: Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Gbajímọ̀ ènìyàn ni. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ṣùgbọ́n ó dàbí ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọ̀mọ̀wé ni. 
	Yéwándé: Ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé ni òun náà. Kò kàwe ṣùgbọ́n o ní ọ̀yàyà ó sì máa ń ṣe àyẹ́sí ènìyàn. 
	Àlàó: Òun ni Olófin-íntótó àti Ilésanmí dé sí ọdọ rẹ̀. Onígbàgbọ́n ni. Jọ̀ọ́nú ni orúkọ rẹ̀ mìíràn. Ó máa ń gbàdúrà ni alaalé kí ó tó sùn. Ọmọ mẹ́ta ni ó bí. Ní ọjọ́ tí àwọn Olófin-íntótó kọ́kọ́ dé ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbàdúrà ó ní kí gbgbo wọn kọ orin wá bá mì gbé olúwa. Àwọn ọmọ Àlàó kò bá wọn kọ ẹsẹ kejì tí ó sọ wí pé ‘Ọjọ́ ayéè mi ń sáré lọ sópin’. Àsàmú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Àlàó ni ó ṣe àlàyé fún bàbá rẹ̀ ìdí tí wọn kò ṣe kọ ẹsẹ kejì orin náà. Ó ní orin àgbàlagbà ni. 

Dúró – Òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Orímóògùnjẹ́. 
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni 
Fólúkẹ́ - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni. Ó ṣẹṣẹ̀ wo kọ́lẹ́jì ni. 
Ọmọ́wùmí- Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni. Ilé-ẹ̀kọ́ kékeré ni ó wà. 
Ọládúpọ̀ -  - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjé ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni. Ilé-ẹ̀kọ kékeré ni ó wà. Fólúkẹ́, Omówùmí àti Oládípọ̀ jẹ́ ọmọ Yẹ́wándé. Bándélé jẹ́ ọmọ odún méje. Àṣakẹ́ ni ó bíí Yàtọ̀ sí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, Yéwándé nìkan ni ó tún máa ń mu owó nínú séèfù. Àìsàn Orímóògùnjẹ́ kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ tí ó fi kú. 
Ilé Orímóògùnjẹ́ kò ju ilé kẹ́rin lọ sí ilé Àlàó. Nígbà tí àwọn Olófìn-íntótó dé ilé Orímóògùnjẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí. Yéwándé ni ó mú wọn wọlé Kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù yìí kìí ya Orímóògùnjẹ́. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni ó wà nígbà tí ó ń ṣàìsàn. Kì í yọ kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù. 
	Àṣàkẹ́ wọlé bá wọn níbi tí wọn ti ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nílé Orímóògùnjẹ́. Wọ́n máa ń há ìlẹ̀kùn yàrá Orímóògùnjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi kọ́kọ́rọ ibẹ̀ há orí ìtérígbà. Ẹnikẹ́ni ní inú ilé ni ó lè mú un ní ibẹ̀ kí ó sì fi sí ilẹ̀kùn 
	Yéwándé ni ó máa ń tọ́jú Orímóògùnjẹ́ lóru nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Àṣàkẹ́ máa ń ràn án lọ́wọ́. yéwándé àti àwọn ọmọ náà máa ń wá tọ́jú Orímóògùnjẹ́ nígbà ti ó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí àìsàn rẹ̀ bá ń yọnu. 
	Adékẹ́yẹ ni orúkọ bàbá yéwándé. 
	Ọjà Ajégbémilékè ni Yéwándé fẹ́ lọ ní ọjọ́ tí ọkọ rẹ̀ kú. 
	Àlàó ni ó kó ogóje náírà (N140.00) tí wọ́n bá níbi ìgbèré Orímóògùnjẹ́ fún Yéwándé láti tójú. Orúkọ mìíràn tí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ tún ń jẹ́ ni Bándélé. Ẹ rántí pé eléyìí yàtọ̀ sí Bándélé orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ. 
	Ọ̀sanyìnnínbí ni orúkọ oníṣèègùn Orímóògùnjẹ́. Ó ra páànù ìgàn méjìlá ní ọ̀dọ̀ kékeréowó. Èyí sì fẹ́ mí ìfura dání nítorí owó tí ó sonù. Àwọn kan rò pé bóyá òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ tí ó sọnù. 
	Nílé Orímóògùnjẹ́ níbití wọ́n ti ń ṣe ìwádìí, Ọlọ́fìn-íntótó rí ẹ̀já òwú kan tí ó wà  lára ọ̀kan nínú àwọn ojú kéékèèkéé inú séèfù ó sì mú un. Gbòngán ni fọláṣadé ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn Orímóògùnjẹ́ ń gbé. Ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún tàbí ọ̀sẹ̀ kan ní ifẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ kí ó tó padà sí Gbọ̀ngán. Kò bímọ kankan fún Orímóògùnjé. Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí fọláṣadé dáadáa nítorí pé òun ni Olófìn-íntótó ra otí fún ní ọjà tíó mu ìgò ọtí kan àbò. Òun ni a sì rí ní òpin ìwé pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé. 

Lóòótọ́, oníṣèègùn ni Ọ̀sanyìnnínbí síbẹ̀, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn Oníṣèègùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹgbẹ́ ìlera loògùn Ọrọ̀. 
	Awóyẹmí ni orúkọ ẹni tí ó bá àwọn Ọlọ́fìn-íntótó níbi tí wọ́n ti ń gbádùn lọ́dọ̀ Ọmọtóṣọ̀ọ́. 
	Ilésanmí àti Ọlọ́fin-íntótó sọ nípa ara wọn pé àwọn mọ ilẹ̀ tẹ̀ múyẹ́ (Ẹ rántí pé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀lmúyẹ́ ni wọ́n ń ṣe). Ajúṣefínní, ọ̀rẹ́ orímóògùnjẹ́ ni ó bá Orímóògùnjẹ́ ra ilẹ̀ tí ó ń kọ́ ilé sí. A ó rántí pé kòkó ní Ajíṣefínní ń tà. 
	Ọwọ́ Òṣúnlékè ni wọ́n ti r ailẹ̀ tí Orímóògùnjẹ́ fi ń kólé náà. Ẹgbẹ̀ta náírà (N600.00) ni wọ́n ra ilẹ̀ náà. 
	Káyòdé akòwé Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ sùn ní ẹnu iṣẹ́ Ìgbà tí wọ́n bi í pé kí ló dé tí ó fi sùn ni ó dáhùn pé olè ajẹ́rangbe tí àwọn ń lé ní òru ni kò jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa. Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Oníṣèègùn Ọ̀sanyìnnínbí ni olórí àwọn olè ajẹ́rangbé yìí gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i kà ní iwájú. Ẹran tí ó ń jí gbé yìí wà lára ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fura sí Ọ̀sanyìnnínbí pé òun ló jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé níbi tí ó tí ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. 
	Ẹran mẹ́ta ni wọ́n bá ní ilé àwọn olè wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti jí méjì tẹ́lẹ̀. Nítorí pé Ọ̀sanyìnnínbí jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olè wọ̀nyí, wọ́n mú un lọ sí Àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Morèmi ní ilé-Ifè.

	Pópóọlá ni orúkọ ọ̀gá ọlọ́pàá yìí. Ọ̀rẹ́ Akin Olófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà ni. Àbéòkúta ni Pópóọlá wà tẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tí wá gbé e wá sí Morèmi ní Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́ta tí ó ti rí Akìn mọ. Pópóọlá bèèrè Túndé Atọ̀pinpin lọ́wọ́ Akin. 
	Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí wọ́n ti ṣè àlàyé pé ọ̀rọ́ Ọ̀sanyìnnínbí tí wọ́n mú ni ó gbé àwọn wa ni wọ́n ṣe àlàye pé tí ó bá jẹ́ pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́, yóò ti ná tó ẹgbẹ̀jọ náírà (N1,600.00) nínú owó náà. Ẹran ti Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé ni ó jẹ́ kí wọ́n ní àǹfààní láti yẹ ilé rẹ̀ wo. 
	Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí àwọn ènìyàn sọ ní orú yìí tí ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí. 
	Ilésanmí ni ó kọrin pé, ‘Iyán lóunjẹ.’
	Akin ni ó sọ pé, Ajímutí kìí tí’
	Akin náà ni ó sọ pé, ‘Ẹni fojú di Pópó á gba póńpó lórí…’. Orúko Pópíọlá ni ó fi ń ṣeré níbí yìí. 
	Pópóọlá sọ pé, ‘Ẹni tí ó pe tóró, Á ṣẹnu tọ́ńtọ́..’ Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Àlàó ni oríkì Pópóọlá. Eléyìí yàtò sí Àlàó tí ó tójú àwọn Olófìn-íntótó tí a ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ ṣáájú. 
	Nígbà tí wọ́n ló yẹ ilé Ọ̀sanyìnnínbí wò, owó tí wọ́n bá ní ibẹ̀ jẹ́ ọgọ́sàn-án náírà (N180.00) Níní orí yìí, a ó rí òwe, ‘Àfàgò kẹ́yin àparò…’ Ohun tí ó fa òwe yìí ni ẹran tí Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ní yóò lọ tí ìyàwó rẹ̀ yóò sì ti bímọ kí ó tó dé. Àpatán òwe yìí ni, ‘Afàgò kẹ́yin àparò, ohun ojú ń wá lojú ń rí. 

	Àlàó tí ó tọ́jú Akin àti Ilésanmí nígbà tí wọ́n dé Ifẹ̀ kò fẹ́ran oògùn ìbílẹ̀ 
	Ọ̀sanyìnnínbí sọ pé Orímóògùnjẹ́ kì í finú tan Àlàó yìí Àwọn ohun tí ó tún yẹ kí á ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: 
Awódélé wá kí Ọ̀sanyìnnínbí 
Àkànbí, àbúrò Aríyìíbí, tí Ọ̀sanyìnnínbí nígbà tí ó ń ṣàìṣàn ní ó dúró fún Ọ̀sanyìnnínbí ní àgọ́ ọlọ́pàá (Ìyẹn ni pé Àkàbí tí Ọ̀sanyìnnínbí wòsàn ni ó dúró fún òun náà)
	Ní ọjọ́ tí àwọn Ọ̀fíntótó wá sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí, nǹkan bí agogo mókànlá ni ó wọlé àwọn Òfíntótó sì dé ilé rẹ̀ ní aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá.
	Nígbà tí Akin Olúṣínà àti Ilésanmí dé ọ̀dọ̀ Ọ̀sanyìnnínbí tí ó rò pé oògùn ni wọ́n wá ṣe ní ọ̀dọ̀ òun, àwọn ẹbọ tí ó kà fún wọn ni ìyá ewúrẹ́ kan, ẹgbẹ̀rún náírà ìgò epo kan, iṣu mẹ́ta àti ìgàn aṣọfunfun kan.
	Akin Olúsínà mu ẹmu ní ilé Ọ̀sanyìnnínbí Ajéwọlé ni ó ra kòkó lówọ́ Ọ̀sanyìnnínbí. Ẹgbẹ̀fà náírà (N200.00) ni ó gbà ní owó kòkó náà. 

	Láti lè mọ iye tí Ọ̀sanyìnnínbí gbà fún kòkó tí ó tà fún Ajéwọlé, ọgbọ́n ni wọ́n fi tan Ọ̀sanyìnnínbí. Wọ́n sọ fún un pé ẹnì kan ń rọbí àti pé yóò nílò oníṣèẹ̀gùn. 
	Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Oládiípọ̀. Òun sì ni àbíkẹ́yìn Yéwándé 
	Bándélé jẹ́ ọmọ odún mẹ́jọ. Ọmọ Àṣàkẹ́ ni Jayéjayé kan ni Àṣàkẹ́ máa ń wọ àdìrẹ tàbí borokéèdì ó sì máa ń wọ súwẹ́ta nígbà òtútù.

Fawọlé: Ó wà lára àwọn ẹni tí ó wá wo Orímóògùnjẹ́ nígbà tí ara rè kò yá. Nígbà tí Akin Olúsínà ṣe ìwádìí nípa rẹ̀, èsì tí ó rí gbọ́ ni ìwọ̀nyí: 
Wọ́n ní ìhà sáábó ni Fáwọlé máa ń gbe Tinúkẹ́ ni orúkọ ọmọ rẹ̀. 

Nípa aṣọ tí ó wọ̀ ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́, ẹni kan sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú aṣọ òfì ni ó wọ̀. Ẹni kan sọ pé sán-ányán ni aṣọ tí ó wọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ́dé kìí tètè gbàgbé nǹkan, Akin Olúṣínà ní kí awọ́n bèèrè ìbéèrè nípá Fáwọlé lọ́wọ̀ Fólúkẹ́ àti Bándélé. 

Fólúkẹ́ sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì ni ó wọ̀. Ó ní ó dé filà sán-ányán, ó wọ́ bàtà aláwọ̀ funfun ràkọ̀ràkọ̀
Bándélé ni ó bomi fún Fáwọlé ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́.
Folúkẹ́ ní ojoojúmọ́ ni Ọ̀sányìnnínbí máa ń wá sọ́dọ̀ Orímóògùnjẹ́ nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń sàìsàn ó sì máa ń dúró di ìgbà tí wọ́n bá ń pèrun alẹ́ kí ó tó kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Folúkẹ́ ní òun rí nǹkan kan bí ológbò ní àpò rẹ̀ ni ọjọ́ kan. 
Àlàó kò gbọ́ nípa ẹni tí ó ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò nítorí pé ó lọ sí ibì òkú ìyá Báyọ̀ ní ọjọ́ náà. 
Ìyá Bándélé ni ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dan séèfù wò náà Orímóògùnjẹ́ kò sọ ọ̀rọ̀ eni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò yìí fún Àlàó. Yéwándé náà kò sọ fún un. 

Lẹ́yìn ìwádìí ti ọjọ́ yìí, Akin Ọlọ́fìn-íntótó àti ilésanmí padà sí Ìbàdàn. Ní ibi tí Akin ti dá mọ́lò dúró nígbà tí o fẹ́ ẹran ìgbẹ́ ni bàbá alágbẹ̀dẹ kan ti sọ fún ọmọ kan pé kí ó wò ọkọ̀ náà. Kọ́lá ni orúkọ ọmọ yìí. Orí yìí ní wọ́n ti wá mọ orúkọ ọmọge tí Akin Olúṣínà ra ọtí fún nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ifẹ̀ tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú. Orúkọ ọmọge yìí ni fìlísíà Olówólàgbà. A ó rí i ní iwájú pé filísíà Olówólàgbà yìí ni orúkọ mìíràn fún ìyàwo Orímóògùnjẹ́ tí ó jí owó Orímóògùnjé gbé. 
Akin àti Ilésanmí wá filísíà yìí lọ sí pètéèsì aláwò pupa rúsúsúsú. Kọ́lá ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ilé yìí. Akin àti Ilésanmí sun ọ̀dọ Fìlísíà mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí Pópóọlá. Ó gbé wọn dé màpó. 

Ohun tí ó fa ìjà tí Ògúndélé àti Jinádù ń jà ni pé Ògúndélé tí ó jé alágbẹ̀dẹ rọ kọ́kọ́rọ́ kan fún jìnádù ní múrí mẹ́ta (#60), Jìnádù san Múrí kan (#20) níbẹ̀ ó ku múrí méjì (#40). Ògúndélé bínú nítorí pé Jìnádù kò tètè san múrí méjì tí ó kì. Jìnádù bínú nítorí pé ó sọ pé Ògúndélé sin òun ní owó ní àárí àwùjọ. Jìnádù sọ pé Ògúndélé fi òrùkọ ẹ̀rẹ na òun. Nígbà tí Kọ́là sọ̀ kalẹ̀ tí ó ń lọ, ó gbàgbé àpò rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n dá a padà fún un. 

Nígbà tí Ain àti Ilésanmí ti Ìbàdàn tí wọ́n ti ń bọ̀ dé Ilé-Ifẹ̀, wọ́n lọ sí ilé fáwọlé Nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí fọláṣadé 9tí àwa tún mọ̀ sí fìlísíà) wá sí Ifẹ̀, ó lò tó ọjọ́ mẹ́ta dípò méjì tí ó máa ń lò tẹ́lẹ̀. Ìpàdé ọmọlẹ́bí tí wọ́n fẹ́ ṣe gan-an ni ó tèlè mú un padà. Yàtọ̀ sí ìgbà tí ìnáwó pàjáwùrù bá wà ọjọ́ karùn-ún kànùn-ún ni Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ nígbà tí ó wà láyé. 
	Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Yéwándé máa ń bá Orímóògùnjẹ́ mú owó nínú séèfù rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tó oṣù kan sí ìgbà tí Orímóògùnjẹ́ tó kú tí ó ti rán an mú owó nínú rẹ̀ gbèyìn. Ọjọ́ ọjà ni ọjọ́ tí Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ máa ń bọ́ sí. Ọjọ́ kẹ́rin tí Orímóògùnjẹ́ mú owó kẹ́yìn nínú séèfù rẹ̀ ni ó kú. Ìyẹn ni pé ọjà dọ̀la ni ó kú Orímóògùnjẹ́ máa ń fún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní owó-ìná tí ó bá ti mówó. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwadìí yìí, Akin Olúṣínà ń fi ataare jobì. Túndé Atọ̀pinpin ní kí àwọn yẹ yàrá Fọláṣadé wò. 

Akin Olúṣínà:  Òun ni wọ́n máa ń pè ní Akin Ọlófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà. Òun ni ó ṣe ìwádìí owó tí ó sọnù. Àròsọ ni ó ti wọkọ̀ lọ sí Ifẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí owó náà. Fìlà rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀ nínú mọ́tò tí ó wọ̀. Dírẹ́bà ọkọ̀ yìí kò mọ ọkọ̀ wà dáadáa. Akin Olúṣíná fẹ́ràn ẹran ìgbẹ́. Ó máa ń mutí. Ó máa ń jobì tó fi ataa sínú rẹ̀. Ó ní túbọ̀mu ó sì máa ń fi ọwọ́ pa á. Ó ṣe wàhálà púpọ̀ kí ó tó mọ̀ pé Fọláṣadé tí ó tún ń jẹ́ filísíà nì ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. 

Foláṣádé:  Òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́. Ìdí nì yí tí ó fi jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní kí ti òun má bàa jẹ́ òfo nílé Orímóògùnjẹ́ ni ó jẹ́ kí òun jí owó rẹ̀ gbé. Fọláṣadé náà ni ó yí orúkọ padà sí fìlísíà Olówálàgbà. Orúkọ yìí ni ó si fi lọ fi owó pamọ́ sí báǹkì. Gbòngán ni ó ń gbé ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, ó ní ilé sí Ibadan.
	Gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, Ọ̀gá ni ó jẹ́ fún Kọ́lá Òwú ara súwẹ́tà rẹ̀ tí ó já bọ́ síbi séèfù wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́ láti rí i mú. Ìwé ìfowópamọ́ rẹ̀ tí Akin Olúṣínà rí lọ́wọ́ Kọ́lá náà tún wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́. 
	Fọláṣadé wà lára àwọn tí wọ́n bí séèfù lójú rẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ tí wọn kò bá nǹkan kan níbẹ̀. Kò sì jẹ́wọ́ pé òun ni òun kó owó tí ó wà níbẹ̀. Ó máa ń ti Gbọ̀ngán wá sí Ifẹ̀. Òun ni ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn foún Orímóògùnjẹ́. Tí ó bá wá láti Gbọ̀ngán, ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún ní Ifẹ̀ tàbí ọ̀sẹ̀ kan. Ilé oúnjẹ ni Akin àti Ilésanmí ti kọ́kọ́ pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó jiyán tán ní ilé olóúnjẹ yìí, ó mu ìgò otí kan àti àbọ̀ nínú ọtí tí Akin Olúṣínà rà. 

Àkàngbé Ọrímóògùnjẹ́:  Òun ni wọ́n jí owó rẹ̀ gbé tí Akin Olúṣínà wá ṣe ìwádìí rẹ̀. Àìsàn tí ó ṣe é tí ó fi kú kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù rẹ̀ máa ń wà. Inú séèfù yìí nì ó máa ń kó owó sí. Kìí yọ àwọn kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù yìí. Tí wọ́n bá ti ilèkùn yàrá rẹ̀, wọ́n máa ń fi kọ́kọrọ́ há orí àtérígbà níbi tí ẹnikẹ́ni ti lè mú un. Orúkọ múràn tí ó ń jẹ́ ni Bándélé. Ogóje náírà (#140), péré ni wọ́n bá nígbà tí ó kú tán. Kí ó tó kú ó ti ra ilẹ̀ tí yóò fi kọ́lè. Ajíṣafínní ni ó bá a dá sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí ó rà náà. Owó Òṣúnlékè ni ó ti rà á. Ẹgbàáta náírà (#6,000) ni ó ra ilẹ̀ náà. 

Dúró: Dúró ni àkọ́bí ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Ilé-ẹ̀kọ́ girama ni ó wà. Ọdún kan ni ó kù kí ó jáde. Òun ni ó kọ ìwé sí Akin Olúṣínà pé kí ó wá bá òun wádìí owó bàbá òun tí wọn kò rí mọ́. Àdùnní ni orúkọ ìyá rẹ̀ òun nìkan ni ó sì bí fún bàbá rẹ̀. Àdùnní yìí tí kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) nì Dúró. Àbúrò mẹ́rin ni ó ní. Àwọn náà ni Àdùkẹ́, Ọmọ́wùmí, Oládípò àti Bándélé. 

Àdùnní: Àdùnní ni ìyàwó tí Orímóògùnjẹ́ kọ́kọ́ fẹ́. Ó kú ní ọdún mẹ́ta sáájú ọkọ rẹ̀. Òun ni ó bí Dúró fún Orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún Ilésanmí. Ọmọ ìlú kan náà nì òun àti Akin Olúṣínà.




#Article 24: Ìṣẹ̀-Èkìtì (195 words)


 
Ise-Ekiti

Iṣẹ́ yìí dá lórí àyẹ̀wò fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka-èdè tí à ń sọ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì. Láti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ yìí, tíọ́rì onídàrọ́ ni a lò. 
Ìpín mẹ́rin ni a pín iṣẹ́ yìí sí. Ní orí kìn-ín-ní ni a ti sọ ìtàn orírun Ìṣẹ̀-Èkìtì. A sọ èrèdí iṣẹ́ yìí, ọgbọ́n ìwádìí tí a lò àti àyẹ̀wò iṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀. Bákan náà, a sọ tíọ́rì tí a lò fún iṣẹ́ yìí. 

Ní orí kejì ni a ti ṣe àlàyé lórí àwọn ìró inú ẹ̀ka-èdè ìṣẹ̀-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. Bíi ìró kónsónáǹtì, ìró fáwẹ́lì, ìró ohùn, iṣẹ́ ohùn, sílébù àti oríṣiríṣi. sílébù tí a lè rí nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. 
Ní orí kẹ́ta àpilẹ̀ko yìí ni a ti ṣàyẹ̀wo nípa ìgbésẹ̣̀ fonọ́lọ́jì tí ó wà nínú ẹ̀ka-èdè Ìṣẹ̀-Èkìtì. A wo ìpàrójẹ, àrànmọ́ àti àǹkóò fáwẹ́lì. 

Ní orí kẹ́rin iṣẹ́ yìí ni a ti gbìyànjú láti wo àwọn ìyàtọ̀ àti ìjọra tí ó wà láàrin fonọ́lọ́ji ẹ̀ka-èdè Ìsè-Èkìtì àti ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. 
Àgbálọgbábọ̀ iṣẹ́ yìí dá lé àwọn tuntun tí ó jáde nínú ìwádìí ti a ṣe a si tọ́ka sí àwọn ibi tí a lérò pé iṣẹ́ kù sí.




#Article 25: Àkúrẹ́ (1306 words)


 

Akure je ilu ni Naijiria ati oluilu ipinle Ondo ni apa iwo oorun. 

A kò le sọ pàtó ọdún tàbí àkókò tí wọn tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Arífálò (1991) ṣe wòye, ó ní Àkúrẹ́ fẹ́rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ó pẹ́ tí wọn ti tẹ̀dó ni ilẹ̀ Yorùbá 
			
Akurẹ is probably lone of the oldest towns in Yorubaland. 

						(Arífálò 1991; o,1.2)

Ìtàn sọ fún wa pé, Aga, ẹni tí a tún wá mọ orúkọ rọ̀ bí Alákùnrẹ́ ni ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Orúkọ̀ bàbá rẹ̀ ni ìyàngèdè. Ìtàn sọ fún wa pé, Ẹ̀pé, ní ẹ̀bá ìlú Òǹdó ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ibùgbé lẹ́yìn tí wọn kúrò ní Ilé-Ifẹ̀. Alákùnrẹ́ tẹ̀ síwójú láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní. Ní àsìkò yìí, ohun ọ̀ṣọ́ ọwọ́ rẹ̀ tí á ń pè ní ‘Àkún’ gé. Ó pe ibẹ̀ ní ‘Àkún rẹ́’ nítorí ìtumọ̀ ‘gé’ ni ‘rẹ́’ ní èdè Àkúrẹ́. Eléyìí ni ó wá di ‘Àkúrẹ́’ títí dòní yìí. Alákùnrẹ́ sì jókòó gẹ́gẹ́ bí olórí ìlú. A kì í pè é ní ọba ní àsìkò yẹn bí kò ṣe ‘Ọmọlójù’. Ó lo ipò rẹ̀ bí olórí ìlú àti ọmọ Odùduwà ní ìlú Àkúrẹ́. 
	
Ní àsìkò yìí ni àwọn ọmọ Odùduwà ń jẹ ọba káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. A gbọ́ pé, Àjàpadá Aṣọdẹ́bọ̀yèdé tí o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odùduwà kúrò ní ìlú Òṣú, ó sì dúró sí ìlú kan tí wọn ń pè ní ‘Òyè’nítòsí Ẹ̀fọ̀n-Alààyè. Rògbòdìyàn, Ìṣòro, ogun àti àìfọkànbalẹ̀ kọ lu ìgbé – ayé Àjàpadá pẹ̀lú ara ìlú ‘Òyè’ náà. Ó wá di dandan fún Àjàpadá láti kúrò ní ìlú ‘Òyè’fún ààbò. Òun àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ dórí kọ ilẹ̀ àìmọ̀rí fún ibùgbé. 
	
Àjàpadá gbáradì, ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí akíkanjú àti ògbójú ọdẹ. wọ́n rìn títí tí wọn fi dé igbó Àkúrẹ́, ibí ni wọ́n ti bá wọn pa erin. Erin tí Àjàpadá pa fún àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún àwọn aré ìlú ní ìwúrí àti ìbẹ̀rù, nítorí pé, ọdẹ tí ó bá pa erin jẹ́ ọdẹ abàmì àti akíkanjú ọdẹ. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ wá gba Àjàpadà gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọdẹ tí yóò lè ní agbára láti gba ará ìlú rẹ̀ ní ọjọ́ mìíràn tí ogun tàbí ọ̀tẹ̀ bá dé. Àwọn ará ìlú Àkúrẹ́ fún Àjàpadá ní orúkọ ‘Aṣọdẹbóyèdé’. 
	
Àjàpadá tí à ń pè ní Aṣọdẹbóyèdé wá ní iyì gidi tí àwọn ará ìlú sì fẹ́ràn rẹ gan-an. Àwọn ará ìlú wá gbé Àjàpadá ga ju Alákùnrẹ́ tí o kọ́kọ́ dé ìlú Àkúrẹ́ lọ. Alákùnrẹ́ náà ṣàkíyèsí pé, àwọn ará ìlú fẹ́ràn Àjàpadá ju òun lọ, ó wa dàbí ẹni pé wọ́n rí ‘ọkọ́ tuntun gbé àlòkù èṣí dànù’. Alákùnrẹ́ wá já ọwọ́ rẹ̀ nínú irọ́kẹ̀kẹ̀ àti akitiyan láti jẹ́ ọba fún ìlú Àkúrẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gan-an ni ẹni kìíní tí ó kọ́kọ́ tẹ ìlú Àkúrẹ́ dó. Itàn sọ fún wa pé Alákùnrẹ́ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kúrò fún Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé. 
	
Àjàpadá Aṣọdẹbóyèdé wá jẹ́ ọba ìlú Àkúrẹ́ kìíní, gbogbo ayé gbọ́, ọ̀run sì mọ̀. Iwádìí fi hàn wá pé, Àjàpadá yìí jẹ́ ọmọ Ẹkùn, Ẹkùn sì jẹ́ ọmọ Òdùduwà1. Òdùduwà tí ó jẹ́ bàba Ẹkùn ni ó tọ́jú Àjàpadá dàgbà nítorí Ẹkùn tètè kú. Àjàpadé jẹ́ ọmọ rere, ó sì fẹ́ràn láti máa ṣeré káàkiri ààfin Òdùduwà, àwọn ènìyàn a sì máa pè é ní ‘Àjàpadá Ọmọ Ẹkùn. A gbọ́ pé Odùduwà fún Àjàpadá ní ẹ̀wù oògùn kan tí wọn ń pè ní ‘Ẹ̀wù Ogele’ tí Òduduwà fúnra rẹ̀ fi ń ṣe ọdẹ, nígbà tí Àjàpadá pinnu láti dá ibùgbé tirẹ̀ ní. 

Wo: T. A. Ládélé a.y. Àkòjọpọ̀ Iwádìí Ìjìnlẹ̀ Àsà Yorùbá.  Ibadan’, Macmillan Nigeria Publishers Ltd. 1986, o.i. 1-2.
Ohun méjì ni ó mú kí Òdùduwà ṣe èyí, èkínní ni ìwà akíkanjú tí Àjàpadá fi hàn nígbà tí o fi ‘Àjà’1 kékeré pa eku ẹdá nínú ilé àìlujú nígbà èwè rẹ. Èkejì ni ìfẹ́ tí Òdùduwà ní sí Ẹkùn tí ó jẹ́ bàbá fún Àjàpadá. Ẹkùn sì tètè kú, ‘Ọmọ́rẹ̀mílẹ́kún’ ni Àjàpadá jẹ́ sí Odùduwà. 
	
Ẹ̀bùn ẹ̀wù yìí nìkan kò tẹ́ Àjàpadá lọ́rùn, ó bẹ Odùduwà fún àwọn ohun ọrọ̀ míràn, èyí wá jẹ́ kí Òdùduwà tún rob í baba Àjàpadá ti jẹ́, ó sì wọ ilé lọ, nígbà tí o máa jáde,  ó jáde pẹ̀lú ẹwà iwà mímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó gbé adé kan lọ́wọ́, ó súre fún Àjàpadá, ó sì sọ fún Àjàpadá pé, ‘mo fi adé yìí jì ọ́’ Mo fi adé jì ọ́, ni ó wá di ‘Déjì’tí o jẹ́ orúkọ oyè ọba ìlú Àkúrẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Òdùduwà fi adé jì2. Adé yìí jẹ ìtọ́kasí pé ọmọ ọba ni Àjàpadá. 

	Àjàpadá ọmọ Ẹkùn Aṣọdẹbóyèdé, Déjì kìíní ní ìlú Àkúrẹ́ jẹ́ akínkanjú ògbójú ọdẹ ni gbogbo ìgbésì ayé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Weir (1934)1 ogójì ọba ni ó ti jẹ ní ìlú Àkúrẹ́ láti ìgbà tí ìtàn ti bẹ̀rẹ̀. Ọba mẹrìn sì ti jẹ lẹ́yìn àkókò tí Weir ṣe ìwádìí tirẹ̀. Àpapọ̀ ọba tí ó ti jẹ ní Àkúrẹ́ jẹ́ mẹ́rìnlélógójì2. À rí igbọ́ pé obìnrin méjì ni ó wà nínú wọn.3 Obìnrin kìínì ni Èyé – Aró ti ó jẹ ọba ní ọdún 1393 títí di ọdún 1419 A.D. Ohun tí o fà á tí oyè fi kan obìnrin yìí nip é, òun nìkan ni ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún ifá rẹ fọ rere láàrin àwọn tí wọn dárúkọ fún Ifá. Àwọn Àkúrẹ́ sì fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí Ifá sọ nítorí pé wọn ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba jẹ tí wọn kò pẹ lórí oyè. Ifá sọ pé obìnrin yìí yóò pẹ́ lórí oyè àti pé àsìkò rẹ̀ yóò tuba tùṣẹ. Obìnrin kejì tí ó jẹ ọba ní Èyémọhin, ó wà lórí oyè ni ọdún 1705 títí di ọdún 1735. A gbọ́ pé nígbà tí wọn tún dá ifá ní àsìkò yìí, ifá kò mú ọmọkùnrin ọmọ-ọba kọọkan, bí kò ṣe ọmọ-ọba-bìnrin yìí. Eléyìí ni ó mú kí àwọn ará Àkúrẹ́ fi ọmọ-ọba-bìnrin yìí jẹ ọba. 

	Ọba Adéṣidá Afúnbíowó ni a gbọ́ pé, ó pẹ́ láyé jù gẹ́gẹ́ bí ọba ìlú Àkúrẹ́. Ó lo bí ọgọ́ta ọdún láyé (1897 -1957.) 
Àkíyèsí:  A ko iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́mè ti F.A Àjàkáyé

A.F Àjàkáyé (1998) ‘Ìlò Orin Láwùjọ Àkúrẹ́ Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria. 
Àṣamọ̀
	
Èròngbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe ìwádìí sí ohun tí àwọn ará Àkúrẹ́ máa ń lo orin fún ní àwùjọ wọn. Ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣẹ̀dámọ̀ àwọn orin àwùjọ Àkúrẹ́, láti ṣàlàyé ìṣẹ̀ṣe àwọn orin wọn àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó tí orin máa ń dá lé. 
	
Ìlò orin ní àwùjọ Àkúrẹ́ tí iṣẹ́ ìwádìí yìí dá lé ni èròngbà láti sí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún àtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ lọ́nà láti mú kí àwọn orin wọ̀nyí yé ni dáradára. Ó tún jẹ́ ọ̀nà láti ṣí ọ̀nà titun sílẹ̀ fún ìwádìí lórí lítíréṣọ̀ alohùn pàápàá ti àwùjọ Àkúrẹ́ tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ ìwádìí kò ì tí pọ̀ lórí rẹ̀. 
	
À ṣe àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò láti ọdọ̀ àwọn ọ̀kọrin. Apohùn ìṣẹ̀nbáyé àti àwọn abínà-ìmọ̀. A ṣe àdàkọ àwọn orin tí a gbà jọ, a sì ṣe àgbéyẹwò àwọn iṣẹ́ tí wọn ti wà nílẹ̀ lórí orin ní àwọn agbègbè mìíràn. A ka àwọn ìwá tí ọwọ́ wa tẹ̀ ní agbègbè náà, a sì rí ọ̀kọ́ tó wúlò fún wa lórí orí ọ̀rọ̀ tí iṣẹ́ wa yìí dá lé. 
	
Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé àkọ́jinlẹ̀ orin nípa síṣe àtúpalẹ̀ kókó ohun tí à ń lo orin fún pọn dandan kí a tó le ní òye iṣẹ́ ọnà àti Ìtumọ̀ orin ní àpapọ̀. 
	
Ìṣẹ́ yìí tún jẹ́ kí ń ní ìmọ̀ nípa ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀, ẹ̀sìn àti ètò ìṣèlú àwọn ará Àkúrẹ́. 
	
Iṣẹ́ yìí tún fi hàn pé ẹ̀sìn ní o máa ń bí àwọn orin ẹ̀sìn ní àwùjọ Àkúrẹ́ àti pé àṣà àti ìṣe àwùjọ ni ó máa ń ṣe okùnfà fún àwọn orin aláìjọmẹ́sìn. 

Ojú Ìwé: 	Oókàn-dín-láàádọ́ọ̀sàn-án 

Alámòjútó: 	Ọ̀mọ̀wé A. Akínyẹmí.




#Article 26: Eégún (2012 words)


Ìtàn tí n ó sọ nípa bí eégún ̣ṣe délé ayé yìí, mo gbọ́ ọ láti ẹnu baba babaà mi ni kí ó tó di pé wọ́n jẹ́ ìpè Olódùmarà ní  nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn. Ìdí pàtàkì tí ó jẹ́ kí n fi ara mọ́ ìtàn náà ni pé ó fi ara jọ ìtàn tí mo kà lórí nǹkan kan náà ìwé Òmọ̀wé J.A. Adédèjì1. Ìdí mìíràn tí ó jẹ́ kí n fi ara ḿọ́ ìtàn náà yàtọ̀ sí òmíràn nip é ẹnu àwọn tí mo ṣe ìwadìí lọ́wọ́ wọn kò kò lóŕi ọ̀rọ̀ náà. Ó dà bí ẹni pé olúkálukú ni ó fẹ́ fi bu iyi kún ìlú tirẹ̀ pé ní ìĺú tòun ni awo Iségún ti bẹ̀rẹ̀. Ògbẹ́ni Táyélolú Ṣáṣálọlá tí ó ń gbé ni ìlú Oǹd́ó tilẹ̀ sọ f́ún mi pé ní ìlú Ọ̀fà ni Eégun ti ṣẹ̀. Nígbà tí mo sì fi ọ̀rọ̀ wá a lénu wò, mo rí i pé ọmọ Ọ̀fà ni baba rẹ̀. Ọmọ Iwékọṣẹ́ tún sọ fún mí pé ó dá òun lójú pé ní ìlú Òkè-igbó lẹ́bàá Oǹd́ó ni Eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.
	
Nínú Ìdàrúdàpọ̀ yìí ni mo wá rò ó pé bí ènìyàn bá fẹ́ẹ́ mọ òtítọ́ tí ó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, àfi bí ènìyàn bá tọ Ifá lọ nítorí pé If́a kò ní í gbè sẹ́hìn ẹnìkẹ́ni. Orísìí ìtàn méjì ni mo sì wá rí ńinú Ifá. Ṣùgbọ́n ìtàn kéjì ni mo fi ara mọ́. Ìdí tí mo sì ṣe fi ara mọ́ ọn náà nip é ó jọ ìtàn tí mo ti gbọ́ lẹ́nu baba babaà mi. Èyí nìkan kọ́: mo fi ara mọ́ 

Ìtàn kejì yìí nítorí pé ó tún là wá lọ́yẹ lórí bí orúkọ náà, “Eégún”, ti ṣe bẹ̀rẹ̀. 
	
Ìtàn àkọ́kọ́ yìí wà nínú Odù Èjì ogbè, Ẹsẹ̀ Èkejì. Ìbéjì ni wọ́n fi Eẹgún bí. Ọ̀kán kú èkejì sì wà láàyè. Èyí tí ó wà láàyè si wá ́n sunkún ṣá. Wọ́n wá dọ́gbọ́n, wọ́n dáṣọ̣ Eégún. Wọ́n mú èyí tí ó wà ẹnìkan lórí. Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pe ẹni tí ó wà láàyè pé:	

Ìhín ò rọ̀ o ò.” 
	
Ẹsẹ Ifá náà lọ báyìí: 
		

		
Ìbejì ni wọ́n bí i. 
		
Ọ̀kan kú, ọ̀kan wà láàyè. 
		
Èyí tí ó wà láàyè wáá sunkún títí, 
		
Ni wọ́n bá dọ́gbọ́n, 
		
Wọ́n dáṣọ Eégún. 
		
Wọ́n mú èyí tí ó wà láàyè lọ sínú igbó. 
		
Wọ́n gbé aṣọ Eégún náà bọ ẹnìkan lórí. 
		
Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pé 
		
Èyí tí ó wà láàyè pé: 
		
Mọ tíì wá o, 
		
Ìh́in ò rọ̀ o ó. 
		
Èyí tí ó wà láàyè bẹ̀rẹ̀ síí sunkún, 

	
Eégún náà yára wọ inú igbó lọ. 
	
Aṣọ tí a dà bo alààyè lórí 
	
Ni à ń pè ní ẹ̀kú Eégún. 
	
Ẹ̀kú ayé o, 
	
Ẹ̀kú ọ̀run, 
	
N à ń pè ní èjìgbèdè ẹ̀kù.” 
	
Ìtàn ke jì wà nínú ìwé Ọ̀mọ́wé J.A. Adédèjì tí mo ti tọ́ka sí tẹ́lẹ̀. Ńińu Odù Ọ̀wọ́nrínsẹ̀ ni ó wà. Ìtàn náà lọ báyìí: 
Nígbà TÌ Ọ̀wọ́nrín tí ọ́ ń gbé ní Ìsányín dolóògbé, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta -  Arúkú, Arùḱu àti Aròḱu-rọja-má-tà kò ní owó lọ́wọ́ lati fi ṣe òkú bàbáa wọn. Ìrònú ọ̀ràn náà pọ̀ dé bi pé èyí Arúkú tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún gbogbo wọn fi ìlú sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èyí àtẹ̀lé rẹ̀, Arùkú, mú ìmọ̀ràn wá pé kí àwọn ó ta òkú náà1. Èyí àbúrò wọn, Aròkú-rọja-má-tà, bá kiri òkú náà lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ti kiri fún ìgbà díẹ̀ tí kò ti rí ẹni ra òkú náà ni ó ti sú u, ó sì wọ́ òkú náà jùnù sínú igbó; ó bá tirẹ̀ lọ. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, èyí ẹ̀gbọ́n di baálé ilé, ó sì gba ipò bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ológbìín. Gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ̀ òun ni ó sì wá di Ológbo2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abuké ni, Aláàfin fún un ní ìyàwó kan, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìyá Mòsè. Ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọd́un, Mòsè kò gbọ́ mokòó 

rárá; ó kàn ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ ni. Èyí ni ó mú kí ọkọ rẹ̀ Ológbìín tọ Ọ̀rúnmìlà lọ. Nígbà tí ó débà tí ó débẹ̀, ó ńi “emi ló dé tí ìyàwó òun fi rọ́mọ lẹ́hìn adìẹ tó bú púrú sẹ́kún?” Ọ̀rúnmìlà sì sọ fún un pé àfi tí ó bá lè ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba rẹ̀ tí ó ti kú kí ìyàwó rẹ̀ ó tó lè bímọ. 
	
Ní àkókò yìí, Ìyá Mòsè ti lọ́ sọ́dọ̀ Amúsan láti lọ ṣe ìwádìí ohun tí ó fa sábàbí. Bí Ìyá Mòsè ti ń bọ̀ láti odò Asà níjọ̀ kan ni elégbèdè kan jáde sí i láti inu igbó tí ó sì bá a lòpọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ìyá Mosè ṣe bẹ́ẹ̀ lóyún. Mòsè kò sì lè jẹ́wọ̀ bí ó ṣe lóyún fún ọkọ rẹ̀. Ó sì fọ̀n ọ́n ó di ọ̀dọ̀ Ọlọ́pọndà tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ìyá Mòsè. Níbẹ̀ ni ó ti bí ìjímèrè. Ìtìjú a máa pa gbajúmọ̀. Nígbà tíìtìjú pọ̀ fún Mòsè, ó tún fọn ọ́n, ó di ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Bí ó sì ti ń lọ lọ́nà ni ó ju ìjímèrè sínú igbó. Ṣé ọkọ rẹ̀ kò kúkú mọ nǹ̀̀kan tí ó bí. Nígbà tí ó dijọ̀ keje ni Ato tí ó jẹ́ ìyàwó Ògògó tí ó jẹ́ ọmọ Ìgbórí rí ìjímèrè igbó. Ní àkókò tí a ń wí yìí. Ológbìín ti gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Ó ti lọ sí ọ̀dọ̀ Ọ̀rúnmìlà, Ifá sì ti sọ fún un pé sùúrù lẹbọ. Ifá ní kí Ológbìín máa tọ́jú abàmì ọmọ náà, ṣùgbọ́n kí ó tún ṣe ẹ̀yẹ ìkọhìn fún baba rẹ̀ nìpa lílọ sí igbó níbi tí wọ́n ti rí abàmì ọmọ náà láti lọ ya eégún baba rẹ̀. Àwọn ohun tí Ifá pa láṣẹ ètùtù náà ni ẹgbẹ̀rin àkàrà, ẹgbẹ̀rin ẹ̀kọ, ẹgbẹ̀rin pàsán àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹmu. Igbó tí wọn ti ṣe ètùtù náà ni a mọ̀ sí igbó ìgbàlẹ̀ di òní olónìí. 
	
Aláràn-án òfí tí ó jẹ́ ìyekan Ológbìín ni ó gbé aṣọ òdòdó tí baba Ológbìín tí ó ti kú ń lò nígbà ayé rẹ̀ bora, tí ó sì tún gbé abàmì ọmọ náà pọ̀n sẹ́hìn, tí ó sì ń jó bọ̀ wá sí àárín ìlú láti inú igbó náà pẹ̀lú ìlù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́hìn rẹ̀. Ológbìín ti fi lọ̀ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba òun tí ó ti kú nítorí náà nígbà tí wọ́n rí Aláràn-án Òrí nínú aṣọ òdòdó, wọ́n ṣe bí Ológbìín tí ó ti kú ni, pàápàá tí abàmì ọmọ tí ó pọ̀n dà bí iké ẹ̀hìn rẹ̀. Àwọn ènìyàn ń sún mọ́ ọn láti wò ó dáadáa ṣùgbọ́n pàṣán tí wọ́n fi ń nà wọ́n kò jẹ́ kí wọn sì wọ ilé baba Ológbìín tí ó ti kú lọ. Bí àwọn ènìyàn ti ń wò ó ni wọ́n wí pé: 
		

		
Egungun náà gún lóòótọ́!
		
Egungún gún! Egungún gún!” 

Báyìí ni àrá ọ̀run náà ṣe ṣe káàkiri ìlú tí ó sì ń súre fún àwọn ènìyàn. Nígbà tí ó sì ṣe ó wọ káà lọ. Wọ́n sì pe Ato kí ó máa tọ́jú abàmì ọmọ náà. Wọ́n sì ń pe abàmì ọmọ náà níOlúgbẹ̀rẹ́ Àgan. Nínú káà yìí ni Ògògó tí ó jẹ́ ọkọ Ato, ti ń wo ọmọ náà nígbàkúùgbà. Àwọn ènìyàn inú ilé a sì máa pe Ògògó ní Alàgbọ̀ọ́-wá1. Alágbọ̀ọ́-wá yìí ni ó sì di Alágbàá (baba Maríwo) títí di òní olónìí. Odù Òwọ́nrínsẹ̀ náà nìyí: 
		

		
Arùkú, 
		
Aròkú-rọjà-má-tà. 
		
Òkú tá a gbé rọjà tí ò tà; 

		
La gbé sọ sígbó. 
		
Òun la tún gbé wálé, 
		
Tá a daṣọ bò, 
		
Tá a ń pè léégún.
		
A dÌfá fún Ọ̀wọ́nrín Ìsányín 
		
Tó kú tí àwọn ọmọ rẹ̀ 
		
Kò rówó sin ín.1
	
Bí a bá sì tún wo oríkì eégún, ọ̀rọ̀ nípa bí eégún ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ yóò túbọ̀ tún yé wa sí i. Gẹ́gẹ́  bí a ti mọ̀, oríkì ni ọ̀rọ̀ tí ó júwe ìwà, ìṣe2 àti Ìtàn ìbí àwọn òrìṣà, ènìyàn àti àwọn nǹkan mìíràn. Oríkì Egúngún náà lọ báyìí: 
		

		
Lùkùlùkù gbúù-gbúù!
		
A-rágọ̀ gbálẹ̀, 
		
Egúngún kìkì egungun 
		
T’Ògògó!
		
Òkú yìí gbérí! 
		
Ẹni ará kan 
		
Tí ń jí jó awo. 

	
Ọ̀ṣọ̀ràn lokùn ń dè lÁgburè. 
	
Ìgbà tí n kò ṣòràn okùn,
	
Kí lẹ mókùn so mí lápá sí? 
	
Ọmọ kẹ́kẹ́ mo ṣá, 
	
Mo mú ṣèwe lÁgburè. 
	
Gọ̀ǹbọ̀ ni mo wà,
	
Mo mú ṣèwe nIgbórí1 
	

	
Baba Arúkú, 
	
Baba Arùkú, 
	
Baba Aròkú-rọjà-ma-tà. 
	
Òkú tá a gbé rọjà 
	
Tá ò tà, 
	
Òun la dáṣọ fún 
	
Tá à ń pè léégún. 
	
Ikú ‘i lÓdò. 
	
Ọmọ atòkú jẹun,
	
Ọmọ atáyé solẹ̀ nÍgbàlẹ̀. 
	
Baba Ato kékeré 
	
A-bẹnu wẹ́jewẹ́jẹ.2 

Báyìí a ti mọ̀ bí eégún ṣe kọ́kọ́ dé inú ayé nígbà ìwáṣẹ̀. 

Theatrical Art from its Origin to the Present Times.) Ph.D. Thesis (University of Ibadan 1969). Pp. 60.88. 

Ṣùgbọ́n láyé òde òní ń kọ́? Báwo ni a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún? Ó ṣòroó sọ pàtó pé kò níí sí ìyàtọ̀ díẹ̀ láti ìlú dé ìlú lórí ọ̀rọ̀ bí a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún. Ṣùgbọ́n bí ìyàtọ̀ kàn tilẹ̀ wà náà, kò pọ̀ rárá. Mo léèrò wí pé àwọn obìnrin kò ní í mọ ìdí abájọ. Obìn in a sì máa mọ awo, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá tilẹ̀ mọ ọ́n, wọn kò gbọdọ̀ wí. Àgbàlagbà Ọ̀jẹ̀ nikan ni wọ́n ń ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ bí ó bá kú. Bí a bá ti fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún ẹni tí ó ti kù yìí, a ó wá pàsán1 mẹ́ta, a ó wá aṣọ fúnfún tí ó tóbi, a ó tún wá ẹni tí kò sé kò yẹ̀ gíga ẹni tí a fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún rẹ̀ náà. Ìtàn sọ fún mi pé láyé àtìjọ́, tí wọ́n bá pe òkú Òjẹ̀ nígbà tí wọn kò bá tíì sin ín, pé ó maa ń dáhùn tí yóò sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n eke ti dáyé, aáṣà ti dÁpòmù, nǹkan ò rí bí í ti í rí mọ́ nítorí pé a kò lè ṣe é bí a ti í ṣe é tẹ́lẹ̀. 
	
Bí àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí bá ti dé ọwọ́ àwọn àgbà Òjẹ̀, a ó mú ọkùnrin tí kò sé kò yẹ̀ gíga òkú Òjẹ̀ náà lọ sínú igbó ìgbàlẹ̀. Àwọn àgbà Ọ̀jẹ̀ nìkan ni wọ́n lè mọ ẹni náà. Lẹ́hìn èyí, àwọn Òjẹ̀ yókù àti àwọn ènìyàn yóò máa lu ìlù eégún ní ibi tí wọn ti pa pẹrẹu lẹ́bàá igbó ìgbàlẹ̀ náà. Ọ̀wẹ́wẹ́2 ni ìlù tí a ń wí yìí. Tí wọ́n bá ti ń lu ìlù báyìí, àgbà Ọ̀jẹ̀ kan yóò máa mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú pàṣán yẹn, yóò 

Sì máa fin a ilẹ̀ lẹ́ẹ́mẹ́ta mẹ́ta. Bí ó bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni yóò máa pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà tí a sì fẹ́ ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ yìí. Nígbà tí ó bá ti fi pàṣán kẹta na ilẹ̀ lẹ́ẹ́kẹ́ta tí ó sì tún pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà, ẹni tí ó ti wà nínú igbó ìgbàlẹ̀ yóò dáùn, yóò sì máa bọ̀ pẹ̀lú aṣọ fúnfún báláú lọ́rí rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò sì máa yọ̀ pé baba àwọn dáhùn, pé kò tilẹ̀ kú rárá. 
	
Bí babá bá ti jáde báyìí ni àwọn ènìyàn yóò máa béèrè oríṣìíríṣìí nǹkan  lọ́wọ́ rẹ̀, tí baba náà yóò sì máa dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó bá ti jó dáadáa fún ìgbà díẹ̀, yóò súre fún àwọn ènìyàn kí ó tó padà bá inú igbó ìgbàlẹ̀ lọ. Bí eégún ṣe ń jáde lóde òní nìyí ní ìlú Oǹdó.

BÍ EÉGÚN ÀTI ÒGBÉRÈ EÉGÚN ṢE DÉ ÌLÚ OǸDÓ
	
Gẹ́gẹ́ bí yóò ti hàn níwájú, kì í ṣe èdè tí àwọn ará Oǹdó ń fọ̀ lẹ́nu ni wọ́n fi ń kógbèérè: èdè Ọ̀yọ́ ni wọ́n ń lò. Èyí jẹ́ ìtọ́kasí kan láti fi hàn pé láti Ọ̀yọ́ ni eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ kí ó tó tàn ká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá. Ní ayé àtijọ́, nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ogún kó láti ìlú kan dé òmíràn. Àwọn mìíràn lè ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí wọn ó sì padà sílé nígbà tí wọn bá ti ra ara. Àwọn mìíràn a tilẹ̀ kúkú jókòó sí ìlú náà wọn a sì fẹ́ Ìyàwó níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ àṣà kò ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò gbàgbé ẹ̀sìn wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé e




#Article 27: Rárà (1020 words)


Rárà
I.	OHUN TÍ RÁRÀ JẸ́ 
	Rárà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ewì àbáláyè ni ilẹ́ ẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí mo tí ṣe ṣe àlàyé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, agbègbè Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́ ni irú ewì báyìí tí wọ́pọ̀. Òun ni ọ̀kan nínú àwọn ewì `tí a máa ń fi ń yin ẹnikẹ́ni tí a bá ń sun ún fún yálà ní ìgbà tí ó bá ń ṣe ìnáwó tàbí àríyá kan. Bí ó ti jẹ́ ohun tí a fí ń yin ènìyàn náà ni ó tún jẹ́ ohun tí a lè fi pe àkíyèsí ènìyàn sí ìwà àléébù tí ó ń hù. Bákan náà, rárà jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi máa ń ṣe àpọ́nlé ènìyàn ju bí ó tí yẹ lọ, nígbà tí a bá sọ pé ó ṣe ohun tí ó dà bí ẹni pé ó ju agbára rẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ ni a máa ń bá pàdé nínú un rárà ó sì dà bí ẹni pé àwọn orúkọ wọ̀nyí jẹ́ orúkọ àwọn ẹni àtijọ́ tí ó jẹ́ bí i baba ńlá ènìyàn tí ó ṣẹni sílẹ̀. 
	
Nítorí pé ọ̀rọ̀ iyìn àti ẹ̀pọ́n la máa ń bá pàdé nínú un rárà, èyí máa ń mú inú àwọn ènìyàn tí ó bá ń gbọ́ rárà náà dùn, orí a sì máa wu. Ní ààrin orí wíwú àti yíyá báyìí ni àwọn ènìyàn tí à ń sun rárà fún yíò tí máa fún àwọn asunrárà náà ní ẹ̀bùn tí wọn bá rò pé ó tọ́ sí wọn. 
	
Rárà sísun báyìí pé oriṣI méjì tàbí mẹ́ta ni agbègbè ibi tí wọn ti ń suún. OríṣI kan ni àwọn èyí tí obìnrin-ilé máa ń sun. tí àwọn obìnrin ilé wọ̀nyí kò ń ṣe gbogbo ìgbà. Ìgbà tí ọmọ-ilé kan ọkùnrin tàbí ọmọ-osu, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó ilé bá ń ṣe ìnáwó ni wọn tóó sun ti wọn. OríṣI kejì nit i àwọn ọkùnrin tí ó máa ń lu ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹni kẹta ni àwọn ọkùnrin tí kò ń lú sí tiwọn. 

II.	ÌGBÀ TÍ A MÁA Ǹ SUN RÁRÀ
	Jákèjádò ilẹ̀ ẹ Yorùbá, ó ní ìgbà tí a máa ń sába ń kéwì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ àti bí òwe àwọn Yorùbá tí ó sọ wí pé “Ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán”, bákan náà ni fún rárà, a kì í déédé sun rárà láìjẹ́ pé ó ni nǹkankan pàtàkì tí à ń ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i àti bí a ṣe gbọ́ láti ẹnu àwọn asunrárà tí a wádìí lọ́dọ̀ ọ wọ́n, àwọn àsìkò tí a máa ń sun rárà jẹ àsìkò ti a bá ń ṣe àríyá tàbí àjọyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn asunrárà Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ tí wo, ó jẹ́ ìwá àti ìṣe wọn láti máa lọ̀ ọ́ sun rárà fún Aláafìn ní àǹfin rẹ̀.  Lẹ́hìn ti ààfin sísun fún yìí, wọn a tún máa sún tẹ̀lé ọba yìí bí ó bá ńlọ sí ìdálẹ̀ kan. Wọ́n ń ṣe èyí kí àwọn ẹni tí ọba náà kọjá ni ìlú u wọn lè mọ́ ẹni tí ń kọjá lọ. 
	
Ní ìlú Ọ̀yọ́ àti Ìbàdàn, ó dà bí ẹni pé a ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún rárà sísun yìí. Ọjọ́ yìí ní à ń pè ní ọjọ́ ọ Jímọ́ọ̀ Ọlóyin. Ọjọ́ yìí máa ń pé ní ọjọ kọkàndílọ́gbọ̀n sí ara wọn. Ọjọ́ yìí ni á gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì nínú ìkà oṣù àwọn Yorùbá. Ọjọ́ yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wá sí ààrin ìlú láti oko tí wọ́n ń gbé yálà láti wá ṣo ìpàdé e mọ̀lẹ́bí tàbí láti wá ṣe ohun pàtàkì míràn. Ní ọjọ́ yìí, àwọn ènìyàn máa ń pọ̀ nínú ìlú jú bí ó ṣe máa ń wà tẹ́lẹ̀ lọ. 
	
Ní Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ Jímọ́ọ̀ Olóyin yìí, àwọn asunrárà náà yíò máa káàkiri ilé awọn Ọ̀yọ́ Mèsì àti àwọn ìjoyé ìlú yókù. Lẹ́hìn ti èyí wọn ó padà sí àafin láti wá jókòó sí ojú aganjú. Níhìín ni wọn yíò tí máa sun rárà kí gbogbo àwọn àlejò tí ó bá ń lọ kí Aláàfin. Wọ́n ń ṣe èyí láti lè rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ àwọn àlejò náà; àti láti lè jẹ́ kí Aláàfin mọ irú àlejò tí ń bò. 
	
Bákan náà a gbọ́ pé ní ayé àtijọ́ ní ìgbà tí ogun wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, àwọn jagunjagun máa ń ní asunrárà tí í máa sun rárà tẹ̀ lé wọn bí wọn bá ńlọ sí ogun1. Mo rò pé wọ́n ń ṣe èyí láti lé fún àwọn jagunjagun náà ní ìṣírí. Bákan náà wọ́n a tún máa sọ fún wọn bí ó ti ṣe yẹ kí wọ́n ṣe lójú ogun. 
	
Lẹ́hìn ti kí a sún rárà fún àwọn ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a tún ń sun rárà jẹ́ àwọn àsìkò ìnáwó tàbí àríyá. Ni ìgbà tí ènìyàn bá ń ṣe Ìgbéyàwó àwọn onírárà a máa sun rárà fún onínàwó náà. Fún àpẹẹrẹ ni ibi ìyàwó tí àwọn obìnrin bá ń sun rárà fún ẹni tí ń gbé Ìyàwó náà wọn ó máa wí báyìí: 
	
			
Ẹ mọ̀mọ̀ ṣeun mì o 
			
Torí ẹni tó ṣúpó 
			
Opó laá póṣú 
			
Èèyàn tó gbẹ̀gbà, 
			
Aá pé n bẹ́gbà ló gbà. 
			
Ògo dodo nìyàwó alẹ́ àná, 
			
Ọmọ ‘Bísí Adé. 
			
Ọmọ lójúu Lájùnmọ̀kẹ́,			

Ọmọ Gẹ́gẹ́ọlá, 

Abiamọ ọ̀ mi Àjàmú, 

Ẹní gbé ‘yàwó ṣògo dodo”, 
	
Ìgbà tí a tún máa ń sun rárà ni ibi ìnáwó ìsọmọ lórúkọ. Irú ìsọmọlórúkọ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ṣe tìlù tìfọn. Bákan náà bí a bá ń sin òkú àgbàlagbà ó lè jẹ́ ìyá, bàbá, tàbí ẹ̀gbọ́n ẹni. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ibi tí a bá gbé ń ṣe nǹkan tí ó lè mú ìdùnnú lọwọ, yálà ilé ṣíṣí ní tàbí ìwuyè ni a ti i máa ń rí àwọn asunrárà. 
	
Ní ayé ìsin yìí a tún máa ń rí àwọn asunrárà nì ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣe ọdún. Nínú ọdún iléyá ti àwọn mùsùlùmí tàbí ọdún un kérésìmesì tí àwọn onígbàgbọ́, àwọn onírárà a máa káàkiri ilé àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyi, láti kí wọn kú ọdún nípa rárà sisun. Àwọn ọlọ́dún wọǹyí yìò sì máa fún àwọn asunrárà náà lẹ́bùn. Àwọn asunrárà ọkùnrin tí ó máa ń fi rárà ṣe iṣẹ́ ṣe ni wọ́n máa ń ya ilé kiri láti sun rárà.




#Article 28: Apiiri (1061 words)


E.I. Oso

E.I. Ọ̀ṣọ́ (1979), ‘Àpíìrì’, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria. 
	
Eré àpíìrì jẹ́ ohun tí ó ní orin, ìlù àti ijó nínú. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, erée pelebe ni ó di àpíìrì níwọ̀n ìrínwó ọdún sẹ́hìn. Ìjerò-Èkìtì ni eré àpíìrì yìí ti bẹ̀rẹ̀. Ìtàn fi yé wa pé wọn mọ̀ ọ́n fúnra wọn ni, kì í ṣe wí pé wọ́n mú un wá láti Ilé-Ifẹ̀ tí ó jẹ́ orírun Yorùbá. Eré yìí bẹ̀rẹ̀ ní àkókó tí àwọn ará Ìjerò mú Alákeji jọba dípò ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ó jẹ́ ọba. Ìtàn fi yé wa pé nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ yí ìlú Ìjerò ká, ẹ̀gbọ́n Alákeji tí ó jẹ́ ọba wá gbéra láti lọ wá ọ̀nà tí wọn yíò fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn ká. Nígbà tí àwọn ará ìlú kò tètè rí i, wọ́n gbèrò láti fi àbúrò rẹ̀ Alákeji jọba. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n Alájeji wá padà, ó rí i pé wọ́n ti mú àbúrò òun jọba. Ó ka gbogbo ètùtù tí wọ́n ní kí ará ìlú ṣe láti lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí ó yí wọn káàkiri. Ìtàn yìí náà ni ó fi yé wa pé kò torí èyí bínú kúrò ní ìlú. Ó sọ fún àwọn ará ìlú pé kí wọn máa ṣe eégún fún òun lákòókò ọdún Ògún fún ìrántí òun, kí wọn sì máa ṣeré àpíìrì tí egúngún yìí bá jáde. Lẹ́hìn èyí ni eré àpíìrì ti bẹ́rẹ̀ ní ìlú Ìjerò-Èkìtì. 
	
Àwọn alápìíìrì tí ó ti dolóògbèé ni Ọ̀gbẹ́ni Àṣàkẹ́ Ìwénifá, Ajórùbú, Àjàlá, Olóyè Ọsọ́lọ̀ Òkunlọlá, Afọlábí Ọ̀jẹ̀gẹ̀lé. Àwọn eléré àpíìrì tí ó tì ń ṣeré ní Ìjerò báyìí ni Èyéọwá Ọmọyẹyè, S.O. Fómilúsì  tí ó sọ ìtàn bí eré àpíìrì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Ìjerò-Èkìtì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹnu bà á ní ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, ìbágbé pọ̀ àwọn èèyàn ni ó mú eré àpíìrì tàn kálẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì. 
	
Èèyàn méjọ sí mẹ́wàá ni ó sábà máa ń ṣeré àpíìrì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn mẹ́rin péré ni í máa ń lu ìlù. Ohùn méjì pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn pàtàkì ni a ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. Èkíní ni ohùn alámọ̀, tó sábà máa ń jáde lẹ́nu nígbà tí eléré àpíìrì bá fẹ́ salámọ̀. Èyìí fẹ́ jọ ohùn arò. Ohùn orin ni èkejì tí a máa ń bá pàdé nínú eré àpíìrì. 
	
Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè ni eré àpíìrì. Eré yìí sábà máa ń ní olórí tí yíò máa dá orin, tí àwọn yòókù yíò máa gbè ti ìlù bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹni tí ń lé orin yìí lè ṣe ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tàbí ènìyàn méjì lápapọ̀ láti lè fi ohùn dárà nínú orin lílé. Nígbà míràn, ó lè ṣe ẹni tí ń dá orin náà ni yíò máa salámọ̀ láàrin eré, ó sì tún lè jẹ́ ènìyàn méjì yàtọ̀ sí àwọn tí ń dárin. Kíkọ́ ni mímọ̀ ni ọ̀rọ̀ eré yìí. Ẹni tí kò kọ́ ìlù eré àpíìrì tàbí orin rẹ̀ kò lè mọ̀ ọ́n. Àwọn eléré àpíìrì máa ń ronú láti lè mú kí wọn mú oríṣìíríṣìí ìrírí wọn lò nínú orin wọn. Èyí fi ìdàgbàsókè ti ń dé bá eré àpìírì hàn. Ní àtijọ́ ọdún Ògún ni eré àpíìrì wà fún, ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé yíyí ni ayé ń yi, àwọn òṣèré náà wá ń báyé yí nípa pé kí wọn ṣẹ̀dá orin àpíìrì fún onírúurú àṣeyẹ tí a ó mẹ́nu bà níwáju. Eré àpíìrì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ àti òye tí ó fi ọgbọ́n, ìrònú, àkíyèsí, èrò, èèwò àti ìgbàgbọ́ àwa Yorùbá hàn. 
	
Àwọn ohun tí ó ya eré àpíìrì sọ́tọ̀ sí eré ìbílẹ̀ míràn ni, irúfẹ́ ìlù tí a ń lò fún eré yìí, ọ̀nà tí a ń gbà kọ orin àpíìrì àti bí ìlù tí a ń lò ṣe ń dún létí. Nǹkan mìíràn tí ó tún ya eré yìí sọ́tọ̀ sí òmíràn nip é agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì nìkan ni a ti ń ṣe irú eré yìí ní gbogbo ilẹ̀ káàárọ̀-oò-jíire. 
	
Àwọn ohun tí a ń lò bí ìlù nínú eré àpíìrì láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá ni agbè tí ajé wà lára rẹ̀. Agbè àti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ohun èlò ìlù lílù àti ijó jíjó tí a dá sílẹ̀ ní àkókò Ẹ́mpáyà Bìní. Àwọn Ẹ̀gùn àti Pópó ni ó dá a sílẹ̀ ní àkókò ọba Oníṣílè. Agogo náà tún jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò eré àpíìrì. Àwọn agbè tàbí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí máa ń tóbi jura wọn, kí dídún wọn bàá lè yàtọ̀ síra. Orúkọ tí a ń pe ajé tàbí agbè wọ̀nyí ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì ni, Èyé ajé tàbí Èyé ùlù, kugú, ọ̀pẹẹẹrẹ àti agogo. Bí àwọn agbè wọ̀nyí ṣe tóbi sí ni a ṣe fún wọn lórúkọ. Wọn máa ń lo ìrùkẹ̀rẹ̀ láti jó ijó àpíìrì. Ìdàgbàsókè tí ń dé bá ohun èlò eré àpíìrì. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn. Àwọn Yorùbá ló ń pà á lówe pé, ‘báyé bá ń yí ká báyé yí, bígbà bá ń yí ká bá ìgbà yí, ìgbà laṣọ, ìgbà lẹ̀wù, ìgbà sì ni òdèré ikókò nílè Ìlọrin.’ Nísìsíìyí, arábìnrin Adépèjì Afọlábí tí ó jẹ́ eléré àpíìrì ní Ìdó-Èkìtì ti mú ìlù Bẹ̀mbẹ́ àti àkúbà mọ́ agbè àti agogo tí a ń lò tẹ́lẹ̀ nínú eré àpíìrì. 
	
Àwọn olùgbọ́ kó ipa pàtàkì nínú eré àpíìrì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú Lítíréṣọ̀ aláfohùnpè. Àwọn olùgbọ́ máa ń gbe orin pẹ̀lú àwọn òṣèré. Wọn a máa jó, wọn a sì máa pa àtẹ́wọ́ tí erá bá ti wọ̀ wọ́n lára. Irú ìtẹ́wẹ́gbà báyìí sì máa ń mú kí ọ̀sèré túbọ̀ ṣe eré tí ó dára lójú agbo. 
	
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí mo ṣe ṣáájú, ọ̀nà tí àwọn alápíììrì ń gbà ṣe eré wọn ni kí olórí eré máa lé orin fún àwọn elégbè tí yíò máa gbe orin tí ó bá dá. Olórí lè kọ́kọ́ kọrin kí alámọ̀ tẹ̀lé e tàbí kí ó kọ́kọ́ salámọ̀ kí ó tó kọrin. Kò sí bátànì kan pàtó tí alápìíìrì gbọ́dọ̀ tẹ̀lé nínú eré nítorí pé bí ó bá ṣe wuni ni a ṣe ń ṣèmọ̀le ẹni Ní àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí, alámọ̀ ni eléré àpíìrì yìí fi bẹ̀rẹ̀ erée rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó. 
	
Lílé (Alámọ̀) – Ò rì polóó ùdín ria 
			
Ọ̀bà ǹ bá e mú, kán an síì 
			
Mú un titun barun ùn 
			
Láiún ùgbín rẹ̀ pẹgbẹ̀fà 
			
An máiun rẹ̀ pegbèje lúléè mi, 
			
Ọ karee o, 
			
Mè í múléè ni, 
			
Mẹ́ mọ̀ búyà kànkàn í rè




#Article 29: Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà (3359 words)


Ìjèbú-Jèṣà je ilu ni ile Naijiria ati oluilu agbegbe ijoba ibile Oriade ni Ipinle Osun.
	
Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín. 
	
Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé: Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kìíni, Agírgírì jẹ́ tẹ̀gbọ́n tábúrò. Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọomún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú Ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Nípa bẹ́ẹ̀ Ọwá Ajíbógun àti Agígírì jọ dàgbà pọ̀. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kí í sì í yara wọn bí ó ti wú kí ó rí. 
	
Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji-Agígírì àti ajíbogun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọn wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣa láti dó sí kí wọn lè ni àyè ijọba tiwọn. Ajíbogun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónìí yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírì rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbùrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọdọ̀ jìnná sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé aginjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pè ibi tí òun ti rìn ti nàsẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí. 
	
Kì wọn tó kùrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún un ní ọgbọn nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọn, òun lè dáàbò bo ara òun, ò sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé; 
		

		
Ijẹ̀bú ogún 
		
É sìí bó ṣe a rí 
		
Kógún a parẹ́ 
		
mọ́gbọ̀n lára” 
	
Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírì àti Ajíbógun ni Ilé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lè ríran padà ó lọ, Ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohun ìní bàbá wọn líifi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran.
	
Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀) bàbá rẹ̀. ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fun un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú irin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀. 
	
Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyà yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn sì wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn. 
	
Itán sọ pé Ibòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọna Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà sì gba Ilékéte lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ si Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró: Agóró yìí ló dúró sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan patàki nínú àwọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sì iwájú díẹ̀ kí ó lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ràn Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Igbà ti Agígírì kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fun ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lonìí yìí. Iyàlẹnu ńlánlà lọ́ jẹ́ fún Agígírì láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lù àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí ti ibẹ̀ dùn mọ́ on fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọdẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì a sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n isàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkònísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayó”. 
	
Agbo ilée Bajimọn ní Òkè -Ọjà ni Agígírì sọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́jìn èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gbà òtẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè Agígírì kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ilédè náà ní ibi tí Aàfin Ọba Ijẹ̀bú-jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí wọ́n múra láti ibé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Nikẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. “Ojú iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu tí ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ́ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n. 
	
Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ijẹ̀bù-Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bí-Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbà tí wón dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n pẹ̀rẹ̀sì í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mù ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n Igbà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ láti máa tọ́jú ogbà náà, wọ́n sì dúró pẹ́ dìẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wọ́n fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ìbẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilé. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn –Agígírì sọ ibẹ̀ ni IJẸLÚ nítorí pe ÌJẸ̀ ni Ìjẹ̀sà máa ń pe Ẹ̀JẸ̀. Nigbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ̀bú tí wọ́n ti ń pè tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní. 
	
Ṣùgbọ́n Ijẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́. Ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa. 
	
A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bu ti Ìjẹ̀bù –Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè má sí láàárin wọn nígbà kan ti rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu Ògbóni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú-Òde lọ. Ibẹ̀ ló gi mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó. 
	
Nínú àwọn ìtàn òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ijẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfẹ́ èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ijẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mi díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ògbóni. Itán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀. 
	
Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, Ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ ọ̀ọ́tó jù lọ nínú wọn. 
	
Nipa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ojọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a sẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì kan náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti ajá tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárìn wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ìlẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkán kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn. 
	
Tí Ọwá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. 
	
Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilẹ̀ṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bu-Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Ilẹ́ṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Ilẹ́ṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọ̀n ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀. Idí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé; 
			

			
Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀ 
			
Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú 
			
Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀” 
	
Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sì n jẹ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà a rí Ògbóni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara Ìwàrẹ̀fà mẹfà ni ògbóní méjèejì yí a ni Iléṣà ṣùgbọ́n ògbóni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. A rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà. 
	
Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí ti orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún apẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní ìléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú jèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ́lù. 
	
Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, àdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ. 
	
Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán. 
	
Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, ón ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù.
	
Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀nà tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. 
	
Nígbà tí ilẹ̀ Ilèṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́ún, àrìmọ-kùnrin Ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bù-Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójù ráyè, kí ó tó tùbà tùṣẹ. 
	
Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọbà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá àti Ògbóni Ìjẹ̀bù -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”

Alaye sọ́kí lórí ìlú àti àwọn ènìyàn ìjẹ̀bù-jẹ̀ṣà

Ìlù Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ ìlú kan pàtàkì ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà. Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yị́ ní Nàìjéríà. Apá ìwọ́ oòrùn ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà wà ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí káàárọ́ - oò- jíire. Ìlú Ilẹ́ṣà ti ó jẹ́ olú ìlú fun gbogbo ilẹ̀ jẹ̀ṣà jẹ́ nǹkan ibùsọ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin sí ìlú Ìbàdàn tí jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlú Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì tó nǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́fà sí Iléṣà ní apá àríwá ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà.

Ní títóbi, ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ó pọwọ́lé ìlú Iléṣà ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, òun si ni olú ìlú fún ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun ọ́un kí wọn tó tún un pín sí ọ̀nà mẹ́rin; síbẹ̀ náà òun ni olú ìlú fún ìjọba ìbìlẹ́ ààrin gùngùn obòkun.

Àdúgbò márùnún pàtàkì ni wọ́n pín ìlú yìí sí kí bà lè rọrùn fún ètò ìjọ̀ba síṣe àti fúniṣẹ́ Ìlọ́rọ̀, Ọ̀kènísà àti Òdògo. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdúgbò yí ló ní Olórí ọmọ tàbí lóógun kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ aṣáájú fún ọmọ àdúgbò rẹ̀ òun ní aṣáájú fún iṣẹ́kíṣẹ́ àti tí ó bá délẹ̀ láti ṣe ni àdúgbó, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì tún jẹ́ aṣojú ọba fún àwọn ọmọ àdúgbò rẹ̀. Òdògo nìkan ni kò fi ara mọ́ èlò yí tó bẹ́ẹ̀ nítorí ìtàn tó bí i fi hàn pé ìlú ọ̀tọ̀ gédégédé ni òun. Àwọn ènìyàn ọ̀gbọ́n náà ń fẹ́ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbà ìwásẹ̀ ti fi hàn wí pé wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Lòde òní, nǹkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nítorí pé àjọṣẹ tí ó péye ti ń wàyé láàárín ọ̀gbọ́n náà àti àwọn ọ̀gbọ́n yòókù.

Ẹ̀rí tí ó fi hàn gbegbe pé àwọn Ìjẹ̀ṣà gba ìlù Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bi ìlú ti ó tẹ̀ lé Iléṣà ni ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni pé ìjókòó àwọn lọ́balọ́ba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá ìlẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń yàn àn lé. Síwájú sí i, nípa ti ìlànà oyè jíjẹ, ó ní iye ọjọ́ tí Ọwá tuntun gbọ́dọ̀ lò ní Ijẹ̀bù - Jẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni ó máa ń gbé Ọwá lésẹ̀ tí ó sì máa ń ṣúre fún un kí wọn tó gbà á gẹ́gẹ́ bí ọwá àti olóri gbogbo ọba ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà.

Láti túnbọ̀ fi pàtàkì ìlú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú ìtàn ìwásẹ̀, ti Ọwá bá fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ọ̀daràn apànìyàn kan, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbódọ̀ wà níjòkó, bí èyí kò bà rí bẹ́ẹ̀, Ọwá gbódọ̀ sùn irú igbẹ́jọ́ tábi ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sí ọjọ́ iwájú. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe máa ń sọ pé

K Ìjẹ̀bu -Jẹ̀ṣà mọ mọ̀n

Kọ́wá bá a pani

Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà á gbọ́”

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí àwọn ènìyàn ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ń ṣe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ, bẹ́ẹ̀ ni a tún rí àwọn tó mú àgbẹ̀ àrojẹ mọ́ àgbẹ̀ agbinrúgbìn tó ń mówó wọlé lọ́dọ́ọdún àti láti ìgbàdégbà. Àwọn irúgbìn tí wọ́n ń gbìn fún àrojẹ ni, iṣu, ẹ̀gẹ́ (gbáàgúdá) ikókó, ìrẹsì, àgbàdo, kọfí, òwù àti obì sì jẹ́ àwọn irù-gbìn tó ń mówó wálé fún wọn.

A rí àwọn oniṣẹ-ọwọ́ bíi, alágbẹ̀dẹ, onílù. agbẹ́gilére, àwọn mọlémọlé àti àwọn kanlékanlé. Àwọn obìnrin wọn náà a máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́-ọwọ́, lára wọn ni aró dídá, apẹ ati ìkòkò mímọ àti aṣọ híhun pẹ̀lú.

Bákan náà, wọ́n tún jẹ́ oníṣowò gidi. Ọmọ ìyá ni ẹlẹ́dẹ̀ àti ìmọ̀dò, bẹ́ẹ̀ náà sì ni inàki àti ọ̀bọ, gbogbo ibi tí a bá ti dárúkọ Ìjẹ̀ṣà ni a á ti máa fi ojú oníṣòwo gidi wò wọ́n. Elèyìí ni a fi ń pè wọ́n ní “Òṣómàáló” nítorí kò sí ibi tí a kó ti lè rí Ìjẹ̀ṣà ti ọ̀rọ̀ ìṣòwò bá délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí irúfẹ́ owo tí wọn kò lè ṣe, ohun tí ó kó wọn ni irìnra ni olé àti ọ̀lẹ. “Alápà má ṣiṣẹ́” ni àwọn Ìjẹ̀ṣà máa ń pe àwọn ti kò bá lè ṣiṣẹ́ gidi. Wọn ko sì fẹ́ràn irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ràrá. Ìjẹ̀ṣà kò kọ̀ láti kọ ọmọ wọn lọ́mọ tí ó bá jalè tàbí tí kò níṣẹ́ kan pàtàkì lọ́wọ́. Wọ̀n á sí máa fi ọmọ wọn tí ó bá jẹ́ akíkanjú tàbí alágbára yangàn láwùjọ. “Òkóbò nìkan ni kìí bímọ sí tòsí, a ní ọmọ òun wà ní òkè-òkun” Bákan náà ni pé “arúgbó nìkan ni ó lè parọ́ ti a kò lè já a nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ti kú tán” Purọ́ n níyì, ẹ̀tẹ́ ní ń mú wá, bi irọ́ ni, bí òótọ́ ni pé àwọn Ìjèṣà jẹ́ akíkanjú, ẹ wo jagunjagun Ògèdèngbé “Agbógungbórò” Ọ̀gbóni Agúnsóyè, “Ologun abèyìngọgọú, ó pẹ̀fọ̀n tán, ó wojú ìdó kọ̀rọ̀, Ọ̀dọ̀fin Arówóbùsóyè, Ọ̀gbọ́kọ̀ọ́ǹdọ̀ lérí odi kípàyẹ́ bì yẹ̀ẹ̀yẹ̀ẹ̀ séyìn” Ológun Arímọrọ̀ àti àwọn Olórúkọ ńláńlá ni ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà láyé ọjọ́un. Tí a bá tún wo àwọn oníṣòwò ńláńlá lóde òní nílẹ̀ Yorùbá jákèjádò, “Ọkan ni ṣànpọ̀nná kó láwùjọ èpè” ni ọ̀rọ̀ ti Ìjẹ̀ṣà. Nínú wọn ni a ti rí Àjànàkú, Erinmi lókun, Ọmọ́le Àmúùgbàǹgba bíu ẹkùn, S.B. Bákàrè Olóye méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti Onìbọnòjé àtàri àjànàkù tí kì í ṣẹrù ọmọdé. Mé loòó la ó kà lẹ́hín Adépèlé ni ọ̀rọ̀ wọn.

Àwọn ọmọ Ìjèbú -Jẹ̀ṣà jẹ́ aláfẹ́ púpọ̀ pàápàá nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àwọn ènìyàn ti o fẹ́ràn àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ láàárin onílé àti àlejò sì ni wọ́n pẹ̀lú. Wọn máa ń pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìlú láti jọ kẹ́gbẹ́ àjùmọ̀ṣe lẹ́nu iṣẹ́ àti oríṣìíríṣìí ayẹyẹ nílùú pẹ̀lú. “Àjèjé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dóri” àjùmọ̀ṣè wọn yìí mú ìlọsíwájú wá fún ìlú náà lọ́pọ̀lọ́pọ̀ “Abiyamọ kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kò má tatí were” ni ti àwọn ọmọ Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà sí ohunkóhun tí wọ́n bá gbọ́ nípa ìlú wọn. Bí ọ̀rọ̀ kan bá délẹ̀ nípa iṣẹ́ ìlú, wọn máa ń rúnpá-rúnsẹ̀ sí i, wọ́n á sì mú sòkòtò wọn wọ̀ láti yanjú irú ọ̀rọ̀ náà. Ọmọ ọkọ ni àwọn ọmọ ìlú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ní tòótọ̀.

Síwájú sí i, oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó bá òde òní mu ni wọ́n ti là sí àárín ilú láìní ọwọ́ ìjọba kankan nínú fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ Ilé - Ẹ̀kọ́ gíga (Grammar Schoo) méji tí ó wà ní ilú náà, òógùn ojú wọn ni wọ́n fi kọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Modern School wọn. Ọjà ilú, ilé-ìfìwé rànṣẹ́ àti gbàngàn ìlú ti o nà wọn tó àádọ́ta àbọ̀ ọ̀kẹ́ naira: Àwọn ọ̀nà títí tí wọ́n bójú mu tí wọ́n sì bá ti òde òní mu náà ni wọ́n ti fi òógùn ojú wọn là láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba kankan.




#Article 30: Ẹfọ̀n-Alààyè (1752 words)


 
Nínú àwọn ìwé ti mo yẹ̀ wò. kò sí èyí tó sọ pàtó ìgbà tàbí àkókò tí a dá ìlú Ẹ̀fọ̀m-Aláayè sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àbúdá ìtàn ìwáṣẹ̀. púpọ̀ nínú ìtàn yìí ló máa ń rújú pàápàá tó bá jẹ́ ìtàn ìtẹ̀lúdó ni ìlẹ Yorùbá. (Akínyẹmí 1991:121) Ìlànà ìtàn àròsọ ìwásẹ̀ ní a gbé ìtàn wọ̀nyí lé. Ní ìgbà ìwáṣè kò sí pé a ń kọ nǹkan sílẹ̀. Nítorí àìkọ sílẹ̀ ìtàn yìí, kò jẹ́ kì a rí àkọsílẹ̀ gidi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ibi tí ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ti jé ọ̀kan nínú awọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ìtàn ti a rí jójọ kò kọjá ìtàn atẹnúdẹnu. ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayé kò yàtọ̀ sí èyí. Oríṣìí òpìtàn ni a rí, ìtàn wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn, bí kò ní àfikún yóò ni àyọkúro ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí àwọn òpìtàn ti ṣiṣẹ́ lé lórí nípa ìtàn ilẹ̀ Aáfíríkà ni ìyànjú wọn lati wo ìtàn ìwáṣẹ̀, kí wọ́n tó lè fa òótọ́ yọ jáde. Ṣàṣà ni onímọ̀ kan tó ṣiṣẹ́ lórí ìtàn ìlú kan tàbí àdúgbò kan tí kò mú ìlànà ìtàn ìwáṣẹ̀ ló láti ṣàlàyé to bojumu nípa orírun ìlú kan (Johnson 1921;3).

Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ilẹ̀ Yorùbá, àwọ òpìtàn ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayè gbà pé ọ̀dọ̀ odùduwà ni wọ́n tí ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn òpìtàn yìí tilẹ̀ lérò pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó rọ̀ lati ojú ọ̀run sílé ayé. Ìlú tó sọ̀kalẹ̀ sí ní Ilé-Ifẹ̀ tó jẹ́ orírun àwọn Yorùbá. Ìtàn yìí ṣòro láti gbàgbọ́, nítorí kò ri ìdí múlẹ̀. Kò tí ì sí ẹni tí a rí tó wọ̀ láti ojú ọ̀run rí. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀, òrìṣà àti odù mẹ́rìndínlógún ni a gbọ́ pé wọ́n rọ̀ láti ìsálọ̀run wá sí ìsálayé (Abimbọla, W. 1968:15). Awọn òpìtàn yìí lè rò pé bóyá nítorí tí a ti ń pe àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni ìgbákejì òrìṣà ni àwọn náà ṣe rò pé Aláayè àkọ́kọ́ rọ̀ sílẹ́ ayé lati ọ̀run.

Ọmọ òkìrìkìsì

Ọmọ ọ̀ tójú ọ̀run á yé’

Nínu ìtàn ìwáṣẹ̀ mìíràn, a gbọ́ pé Ọbàlùfọ̀n Aláyémore ni ọba àkọ́kọ́ ti o tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó. Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ yìí jẹ́ ọmọ Ọbàlùfọ̀n Ogbógbódirin tí í ṣe àkọ́bí Odùduwà tí ó jẹ́ Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ ni àkókó ìgbà kan. Lẹ́yìn Ikú rẹ̀, Ọ̀rànmíyàn lò yẹ kí ó jẹ ọba ní Ilé-Ifẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti lọ sílùú àwọn ọmọ rẹ̀, Eweka ni Eìní ati Aláàfin ni Ọ̀yọ́. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ti jẹ oyè Ọọ̀ni kí Ọ̀rànmíyàn tó dé.

Nígbà tí Ọ̀rànmíyàn dé, Aláyẹ́mọrẹ sá kúrò lórí oyè nítorí pé ní ayé àtijọ́ wọn kì í fi ẹni ìṣááju sílẹ̀ láti fi àbúrò joyè. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ rìn títí ó fi dé orí òkè kan. Wọn pe ibẹ̀ ni Ọba-òkè. Èyí ni ọba tó tẹ̀dó sorí òkè ṣùgbọ́n lónìí ọ̀bàkè ni wọn ń pe ibẹ̀.

Ni orí òkè yìí, Ọbàlùfọ̀n ṣe àkíyèsí pé ẹranko búburú pọ̀ ní agbègbè tó tẹ̀dó sí, èyí tó pọ̀jù ni ẹfọ̀n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹfọ̀n yìí ni àparun. Awọn ẹfọ̀n kékeré níbẹ̀ ni wọn kójọ sínu ọgbà, ti wọn so wọn mọ́lẹ̀ títí wọ́n fi kú. Ọmọdé tó bá lọ sì igbó ibi tí wọ́n kó ẹfọ̀n kékeré sí, ni awọn òbí wọn a ké pé: ‘Kọ́ ọ̀ yàá ṣe lúgbó ẹfọ̀n alaayè’

Nibi yìí ni Ẹ̀fọ̀n ti kún orúkọ Ọbalufọn Aláyémọrẹ. Lára Aláyémọrẹ ni wọn tí yọ Aláayè to fid i: Ẹ̀fọ̀n-Aláayè títí dí òní. Nígbà tí ó ṣe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ránṣẹ́ sí Ọ̀rànmíyàn kí o fi nǹkan ìtẹ̀lúdó ṣọwọ́ sí òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ; kò pẹ́ ti Ọ̀rànmíyàn kú. Àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ wá ránṣẹ́ si Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ láti wá jọba lẹ́ẹ̀kejì. Kí o tó lọ, ó fí ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. Ìyàwó mẹ́ta ni Aláyémọrẹ ni kí ó tó kúrò ní Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Àwọn ni Adúdú Ọ̀ránkú tí ì ṣe ìran àwọn Obólógun; Aparapára ọ̀run ìran awọn Aṣemọjọ, ẹ̀ẹ̀kẹta ni Èsùmòrè-gbé-ojú-ọ̀run-sàgá-ìjà. Ìtàn sọ pé lásìkò tí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ padà sí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni, bọ́ sí àkókò ti Ọba Dàda Aláàfin Ọ̀yọ́ wá lórí oyè ni nǹkan bí 1200-1300AD.

Bí ìtàn ìwáṣẹ̀ yìí ìbá ṣe rọrún tó láti gbàgbọ́ awọn àskìyèsí kan ní a rí tọ́ka sí tí ó jẹ́ kí ìtàn náà rú ènìyàn lójú. Nínú ìtàn yìí, wọn sọ pé Ọbàlùfọ̀n Ògbógbódirin ni àkọ́bí Odùduwa, èyí tó tako ìtàn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa Odùduwa. Ọ̀kànbí ni àkọ́bí Odùduwa. Bó bá tilẹ̀ ṣe orúkọ ló yípadà, àwọn ọmọ Ọkànbí ni ọba méje pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí Ọbàlùfọ̀n nínú wọn. Ohun tí òpìtàn ìbá sọ fun wa nip é ìran Odùduwà ni Ọbàlùfọ̀n jẹ́.

Àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ rú ni lójú púpọ̀. Nínú ìtàn yìí a ri i pe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ mọ àsìkò ti Ọ̀rànmíyàn wà láyé. A rí i pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni wọn. Kó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó jẹ ọmọ àti bàbá. Lóòótọ́ ni Ọ̀rànmíyàn jẹ ọba ni Òkò, tó tún wá sí Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ará Ọ̀y;ọ ló fi Àjàká jẹ ọba sí Òkò. Aláàfin Dada tí òpìtàn fẹnu bà pé ó jẹ ọba ní Ọ̀yọ́ da ìtàn rú. Johnson (1921:144) gbà pé Àjàká ló wá lórí oyè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn kú. Tó bá jẹ́ òtítọ́ ní Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ tún wa jọba lẹ́ẹ̀kejì ní Ilé-Ifẹ̀ a jẹ́ pé àsìkò Aláàfin Àjàkáló jẹ ọba.

Awọn òtìtọ́ kọ̀ọ̀kan farahàn nínú ìtàn yìí. Lóòótọ́ ni Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ kan wá ni Ilé-Ifẹ̀. Títí dí oní ọ̀gbọ́n Ọbàlùfọ̀n wa ní Ilé-Ifẹ̀. Àdúgbò Aláayè si wa ní Ilé-Ifẹ̀ títí dí òní. Kò sí irọ́ níbẹ̀ pé Ẹ̀fọ̀n Aláayè bá Ilé-Ifẹ̀ tan. Nínú ìtàn mìíràn, a gbọ pé àwọn oríṣìí ènìyàn bí i mẹ́fà ni wọ́n tẹ̀dó lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Nínú ìtàn yìí, a gbọ́ pé Èkúwì ló kọ́kọ́ dé sílùú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, igbó-àbá ni Èkúwì tẹ̀dó sí. Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oríkin náà tẹ̀dó sí Igbó àayè. Lọ́jọ́ kan, lásìkò tí oríkin tẹ̀dó, ó rí iná tó ń rú ni Igbó-Àbá. Ó ṣe ọ̀dẹ lọ sí igbó yìí. Oríkin rọ àwọn tó wa ni Igbó àbá kí wọn jọ má gbé ní Igbó-Àayè. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Lásìkò tí wọn jọ ń gbé ni wọn fí Ọbàlùfọ̀n jẹ ọba. Igbákejì Ọbàlùfọ̀n tí wọ́n jọ wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní wọn fi jẹ igbákejì ọba tí a mọ̀ sí Ọbańlá. Bàbá Igbó Àbá ọjọ́sí ni wọn fi jẹ baba ọlọ́jà tí a mọ sí Ọbalọ́jà. Ọbàlùfọ̀n àti Ọbalọ́jà jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà náà. Bí ọba ṣe ń pàṣẹ fún àayè ní Ọbalọ́jà ṣe n pàṣẹ ní Ọ̀bàlú láyé ìgbà náà. Lónìí, Ọbalọ́jà jẹ Olóyè pàtàkì ní ìlú Ẹ̀fọ̀n. Ọbalọ́jù ní olórí àwọn Ọ̀bàlú. Àjọṣe wá láàrìn Ọba àti Ọbalọ́jà. Bí ọba kan bá wàjà ní ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, iwájú ilé ọba-ọlọ́ja ni wọn yóò kó ọjà lọ.

Nínú ìtàn mìíran a gbọ́ pé ààfin Odùduwà ni wọ́n bí Aláayè sí. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọba obinrin ló bii. O jẹ́ arẹwà okùnrin ti ènìyàn púpọ̀ fẹ́ràn rẹ̀ pàápàá àwọn babaláwo tó ń wá sí ààfin. Ìtàn yìí tẹ̀síwájú pé ọkùnrin yìí ní aáwọ̀ ni ààfin, èyí ló mú kí Odùduwà ṣe fún Aláayè ní ilẹ̀ sí ìráyè tí a mọ̀ sì Modákẹ́kẹ́ lónìí. Odùduwà fún un ni adé tó sì n jẹ́ Ọba Láayè. Nínú ìtẹ̀sìwájú, Ìtàn mìíràn tó fara jọ ìtàn òkè yìí, a gbọ́ pé àwọn ọmọọba méjì ló fẹ́ lọ tẹ ìlú dó. Bó ba rí bẹ́ẹ̀ á jẹ́ pé ìlú Ẹ̀fọ̀n tí wá kí Modákẹ́kẹ́ tó dáyé. Àtàdá ati Johnson tilẹ̀ maa ń to Aré àti Ẹ̀fọ̀n tẹ̀lé ara wọn.

Ni pàtàkì, ogun kò ṣẹgún Ẹ̀fọ̀ Aláayè rí àyàfi Ogun Ọdẹ́rinlọ (1852-54). Ọdẹ́rìnlọ jẹ ọmọ Ìrágberí, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ni ìrágberí ti kúrò. A le sọ pe ọmọ bíbi Ẹ̀fọ̀n ló kó Ẹ̀fọ̀n-Aláayè kì í ṣe ọ̀tá nítorí òkè to yí wọ́n ká jẹ ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ fún ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, ó sì jẹ wàhálà fun ọ̀tá. Àwọn ọ̀tá to fẹ jà wọn lógun nígbó Òòyè, wọn ṣe lásán ni. Ogun yìí fà á ti Aláayè kì í fi jẹ osun ògògó titi dòní. Ohun àrífàyọ nínú ìtàn yìí nip é ọdẹ ló tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n dó gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú mìíran ni ilẹ̀ Yorùbá. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn mìíràn ń tẹ̀lé e wá sí ibi ìtẹ̀dó. Ó ṣe é ṣe bẹ́ẹ̀ nitori ibi ti ọdẹ máa ń tẹ̀dó sí kò ní jìnnà sí omit i ń sàn; àtipé yóò ti kó àwọn ẹran rẹ̀ jọ sí ojú ibi ìdáná. Ọja ló ṣéyọ láti ibẹ̀. A tún rí i pé ẹni tó jẹ ọba Ẹ̀fọ̀n gbé adé rẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀; ṣùgbọ́n àsìkò tó dé sí ibùdó yìí ni a kò mọ̀. Lóòótọ́, ẹni tó bá jẹ́ alágbára láyé àtijọ, tó sì ní àmúyẹ ni wọn fi i jọba, lẹ́yìn ti Ifá bá ti fọre. Kò yá wá lẹ́nu pé wọ́n fi ẹni tí adé ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ jẹ ọba nítorí àwọn ohun àmúyẹ ọba wà ni sàkání rẹ̀.

Ní ìparí, Finnegan (1970:368) sọ nínú ọrọ rẹ pé: 

Èyí ni pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti pẹ́, ó ń sọ nípa ènìyàn akọni àti awọn nǹkan to yi i ka bí ìrìnàjò láti ibi kan sí èkejì, ogun jíjà ati bí wọn ṣe tẹ ìlú dó. Encyclopaedia Britanica (1960:54) ṣàlàyé pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ìtàn nípa àṣà tí ó ń ṣàlàyé nípa ènìyàn, ẹranko, òrìṣà àti ẹ̀mí àìrí. Irú ìtàn yìí kì í sọ àkókò gan-an tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn jẹ́ kí ìtàn ní kókó àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lò rí nínú ìtàn lásán. Ìtàn ìwáṣẹ̀ máa ń jẹ ọ̀nà kan pàtàkì láti ṣàlàyé ìgbé ayé tó ti kọjá. Ò máa ń sọ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe dé sí ilẹ̀ kan ati ìdí tí àwọn kan fi jẹ gàba lórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Volume Library (267) tilẹ̀ sọ pé o yẹ kí ìgbàgbọ́ wa rọ̀ mọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ nítorí ó jẹ́ mọ́ àṣà bí o tilẹ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ti a mọ̀ nip é ìtàn ìwáṣẹ̀ ti wáyé lásìkò tó ti pẹ́.

A kò lè fọ́wọ́ rọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlí Ẹ̀fọ̀n-Alàayè ṣẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn ìtàn tí àwọn òpìtàn sọ fún wa, ìdáṣọró okùn-ìtàn wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n nǹkan tó ṣe pàtàkì ní pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n Alàayè dó wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní àsìkò ìgbà kan tí a kò mọ̀. Ìlú ibi ti wọ́n tẹ̀dó sí tù wọn lára, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dí òní.

Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè I.A. Ologunleko.




#Article 31: Ponna (310 words)


J.A. Ogunwale

Itumo ponna

J.A Ògúnwálé (1992), ‘Àyẹ̀wò Àwọn Afọ̀ Onítumọ̀ Pọ́n-na nínú Àwọn Ìwé kan nínú Èdè Yorùbá.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyé Ẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria. 

AṢÀMỌ̀
	
Pọ́n-na inú àwọn àṣàyàn ìwé Yorùbá kan ni kókó ohun tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí. Iṣẹ́ yìí tún ṣe àlàyé lórí àjọṣepọ̀ ààrin Ṣàkání-Ìtumọ̀, afọ̀ àti ìtumọ̀ nítorí pé bí atọ́nà ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Bákan náà ni a pín àwọn Pọ́n-na tí a rí nínú àwọn ìwé Yorùbá díẹ̀ sí ìsọ̀rí. Ẹ̀yìn èyí ni a wá ṣe àfiwé pọ́n-na pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ìtumọ̀ mìíràn tó ń bá a ṣé orogún. 
	
A fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ Yorùbá tó ń lo èdè náà lẹ́nu wò kí ìtumọ̀ tí a ń fún afọ̀ tí àwa kà sí pọ́n-na má baà dà bí àtorírò tiwa lásán. A wo àwọn ìwé tí ó jẹ mọ́ ewì, ọ̀rọ̀ geere àti eré onítàn kí a lè baà kó gbogbo ẹ̀yà ìwé Yorùbá já. Orí òṣùwọ̀n àjùmọ̀ṣe Kress àti Odell lórí ìṣẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀ ni a gbé iṣẹ́ yìí kà. 
	
A kíyèsí I wí pé àwọn àkíyèsí tí ó jẹ mọ́ ti gírámà àti sẹ̀máńtììkì máa ń pa ìtumọ̀ afọ̀ kan dà. A sì tún kíyèsí i wí pé ìlò àfikún ẹ̀yán wà lára aáyan elédè láti pèsè ṣàkání-ìtumọ̀. Iṣẹ́ yìí tún pín pọ́n-na sí ìsọ̀rí. Òṣùwọ̀n tí a lò ni àyè tí a bá àwọn ibùba pọ́n-na, Ìrísí Ṣàkání-ìtumọ̀, Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ àti àbùdá odo ìtumọ̀ onípọ́n-na. a rí i wí pé àbùdá pọ́n-na kì í ṣe ohun tó yé tawo-tọ̀gbẹ̀rì, a wá fi wé àwọn oríṣìí ẹ̀yà-ìtumọ̀ mìíràn bíi gbólóhùn aláìlárògún, ẹ̀dà òye-ọ̀rọ̀, ààrọ̀ àti gbólóhùn aláìnítumọ̀-pàtó. Iṣẹ́ yìí rí i wí pé ara àbùdá èdè ni àwọn pọ́n-na kan jẹ́, ó lè má jẹ́ àmì àìgbédè-tó olùsọ̀rọ̀. Èyí mú kí a tọ́ka àkọtọ́ tó péye, Ìṣẹ̀dà òyè ọ̀rọ̀ àti ìlò ṣàkání-ìtumọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ìyọní-pọ́n-na. 
	




#Article 32: Ifẹ̀wàrà (526 words)


Ìfẹ̀wàrà jẹ́ ìlú kékeré kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni Nàìjíríà
Gẹ́gẹ́ bí a sọ ṣaájú, ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí dé Ìjọba Ìbílẹ̀ Àtàkúmọ̀sà tí ó ní ibùjókòó rẹ̀ ní Òṣú. Ní ìjọba ìbìlẹ̀ yìí, gbogbo àwọn ìlú àti abúlèko tí ó wà ní ibẹ̀ ló jẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà. Ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀ṣà ni wọ́n sì ń sọ àfi Ifẹ̀wàrà tí ó jẹ́ ẹ̀yà ẹ̀kà-èdè Ifẹ̀ ni wọ́n ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tí gbọ́, Ifẹ̀ ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà ti ṣí lọ sí ìlú náà láti agboolé Arùbíìdì ní òkè Mọ̀rìṣà ní Ilé-Ifẹ̀1 . Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ oyè ló dá ìjà sílẹ̀ ní ààrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò. Ẹ̀gbọ́n fẹ́ jẹ oyè, àbúrò náà sì ń fẹ́ jẹ oyè náà. Ọ̀rọ̀ yìí dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ ní ààrin wọn. Lórí ìjà oyè yìí ni wọ́n w`atí ẹ̀gbọ́n fi lọ sí oko. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀gbọ́n tó ti oko dé, ipè láti jẹ oyè dún. Àbúrò tí ó wà ní ilé ní àsìkò náà ló jẹ́ 

Ipé náà. Ipè ti sé ẹ̀gbọ́n mọ́ oko. Èyí bí ẹ̀gbọ́n nínú nígbà tí ó gbọ́ pé àbúrò òun ti jẹ òyé, ó sì kọ̀ láti padà wá sí ilé nítorí pé kò lè fi orí balẹ̀ fún àbúrò rẹ̀ tí ó ti jẹ oyè. Ọ̀rọ̀ yìí di ohun tí wọn ń gbé ogun ja ara wọn sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n yìí wá ń gbé ogun ja àbúrò rẹ̀ ní Ifẹ̀ lemọ́lemọ́, ni àwọn Ifẹ̀ bá fi ẹ̀pà ṣe oògùn sí ẹnu odi ìlú ní Ìlódè. Wọ́n sì fi màrìwò ṣe àmì sì ọ̀gangan ibi tí wọ́n ṣe oògùn náà sí. Láti ìgbà yìí ni ogun ẹ̀gbọ́n kò ti lè wọ Ifẹ̀ mọ. Àwọn Ìjẹ̀ṣà ní ó ni kí ẹ̀gbọ́n tí ó ń bínú yìí lọ tẹ̀dó sí Ìwàrà. Nígbà tí wọ́n dé Ìwàrà, wọ́n fi mọ̀rìwò ọ̀pẹ gún ilẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́ mọ̀rìwò kọ̀ọ̀kan ti di igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan.Ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀lẹ̀, wọ́n sì pinnu pé àwọn kò níí lè bá àwọn àlejò náà gbé nítorí pé olóògùn ni wọn. Èyí ló mú kí àwọn ara Ìwàrà lé àwọn àlejò náà sí iwájú. Ibi tí àwọn àlejò náà tẹ̀dó sí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Ìwàrà ni a mọ̀ sí Ifẹ̀wàrà lónìí. Lóòótọ́ orí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ifẹ̀wàrà wà ṣùgbọ́n kò sí àjọṣepọ̀ kan dàbí alárà láàrin Ifẹ̀wàrà, Iléṣà àti Ìwàrà títí di òní pàápàá nípa ẹ̀ka-èdè tí wọn ń sọ. 
	
Àkíyèsí fi hàn pé gbogbo orúkọ àdúgbò tí ó wà ní Ifẹ̀ náà ni ó wà ní Ifẹ̀wàrà. A rí agboolé bí Arùbíìdì, Mọ̀ọ̀rẹ̀, Òkèrèwè, Lókòrẹ́ àti Èyindi ní Ifẹ̀wàrà. 
	
Bákan náà ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nì wọ́n ń sọ ní Ifẹ̀wàrà. Àsìkò tí wọ́n bá sì ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ ní Ifẹ̀ náà ni àwọn ará Ifẹ̀wàrà máa ń ṣe tiwọn. 
	
Ìwádìí nípa ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ìlú tí iṣẹ́ yìí dé fi hàn gbangba pé mọ̀lẹ́bí ni Ifẹ̀, Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó pẹ̀lú Òkè-Igbo, àti Ifẹ̀wàrà. Wọ́n jọra nínú ìṣesí wọn. Ẹ̀ka-èdè wọn dọ́gba, orúkọ àdúgbò wọn tún bára mu, bákan náà ni ẹ̀sìn wọn tún dọ́gba. Àkókó tí wọ́n ń ṣe ọdún ìbílẹ̀ kò yàtọ̀ sí ara wọn. Bí ẹrú bá sì jọra, ó dájú pé ilé kan náà ni wọ́n ti jáde. 
	




#Article 33: Ife (348 words)


C.O. Odejobi

Ifẹ̀  láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí, DALL, OAU, IFẸ̀ Nigeria. 
	
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣiwájú nínú ìmọ̀ ni wọ́n ti sọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ifẹ̀. Bákan náà Johnson1, Gugler, àti Flanagan2  tó fi mọ́ Fáṣọgbọ́n3 sọ ìtàn Ifẹ̀ nínú iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, ọ̀nà méjì ni ìtàn Ifẹ̀ pín sí. Èkíní jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nípa pé láti ìpilẹ̀sẹ̀ ni Ifẹ̀ ti wà. Ìtàn kejì ni èyí tí ó sun jáde láti ara Odùduwà1. Ìtàn àkọ́kọ́ ni ti Ifẹ̀ Oòdáyé2 Ìtàn ìwásẹ̀ náà sọ pé Olódùmarè pe àwọn Òrìṣà láti lọ wo ilé ayé wá nígbà ti ó fẹ́ dá ayé. Ó fún wọn ní èèpẹ̀ tí ó wà nínú ìkarahun ìgbín, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún, àti ọ̀ga. Nígbà tí wọ́n dé ilé ayé, wọ́n rí i pé omi ní ó kún gbogbo rẹ̀, àwọn òrìṣà da eèpẹ̀ tí Ooódùmarè fún wọn sí orí omi náà, adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún sì tàn án. Bí adìẹ ẹlẹ́sẹ̀ márùn-ún ṣe ń tan ilẹ̀ yìí bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ń fẹ̀ sí i èyí náà ló bí orúkọ Ifẹ̀. 
	
Ìtàn kejì ni pé láti ìlú mẹ́kà ni Lámurúdu tí ó jẹ́ baba Odùduwà ti wá sí Ifẹ̀. Ogun Mohammed tí ó jà láàrin kèfèrí àti mùsùlùmí ìgbà náà ló ká Lámúrúdu mọ́. Èyí ti Lámurúdu ìbá fi gbà, ó fi ìlú Mẹ́kà sílẹ̀, ó sì tẹ Ifẹ̀ dó.3 Lẹ́yìn ikú Lámurúdu ni Odùduwà gba Ipò. Ilé Ọ̀rúntọ́ ti wà ní Ifẹ̀ kí Lámurúdu tó dé. àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ ni ó gba Lámurúdu àti Odùduwà ní àlejò4. Àwọn ará ilé Ọ̀rúntọ́ gbà fún Odùduwà láti jẹ́ olórì wọn nítorì pé alágbára ni. 

Ìtàn ti akọkọ yìí ló sọ bí Olódùmarè ṣe ran àwọn oriṣa láti wá dá ayé. Lẹ́yìn tí àwọn oriṣa dá ayé tan, ti wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ ni Odùduwà tó wá sí Ile-Ifẹ̀ láti ìlú Mẹka. Abẹ́nà ìmọ̀ itan kejì yìí tilẹ̀ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Lámurúdu àti Odùduwà bá àwọn kan ni Ilé-Ifẹ̀ nígbà ti wọ́n dé Ifẹ̀. Ohun tí èyí èyí ń fi yé wa nip é nibi tí ìtàn akọkọ parí si ni ìtàn kejì ti bẹrẹ. 




#Article 34: Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó (554 words)


C.O. Odejobi

Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó àti Òkè-Igbó Láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria.
	
Dérìn Ọlọ́gbẹ́ńlá nì orúkọ ẹnì tí ó tẹ Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó dó1. Ọmọ ìlú Ifẹ̀ nì Ọlọ́gbẹ́ńlá, ó sì jẹ́ akíkanjú àti alágbára ènìyàn. Ìwádìí fi hàn pe, ọba Òṣemọ̀wé Oǹdó ló ránṣẹ́ sí Ọọ̀nì Abewéelá pé, kí ó rán àwọn ọmọ-ogun wá, kí wọ́n lè ran òun lọ́wọ́ latí ṣẹ́gun àwọn tí ó ń bá òun jà. Ọdún 1845 ni ọba Abewéelá rán Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ jẹ́ ìpè ọba Òṣemọ̀wé ti Oǹdó2 

Wọ́n sì tẹ̀dó sí Òkè-Igbó. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ní ọdún 1845 yìí kan náà, Ọlọ́gbẹ́ńlá kò padà sí Ifẹ̀ mọ́, ó kúkú fi Òkè-Igbó ṣe ibùjókòó rẹ̀. Gbogbo aáyan àwọn Ifẹ̀ láti mú kí Ọlọ́gbẹ́ńlá padà sí Ifẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ́gun ní Oǹdó ló já sí pàbó. Ní ọdún 1880 ní wọn fi jẹ Ọba èyí ni Ọọ̀ni ti Ifẹ̀, ṣùgbọ́n kò wá sí Ifẹ̀ wá ṣe àwọn ètùtù tí ó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ ìgbádé ọba, Òkè-Igbó ni ó jókòó sí1 Òkè-Igbó yìí ní ó wà tí ọlọ́jọ́ fi dé bá a ní ọdún 18922.
	
Ní ọdún 1982 ni àwọn ara Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó kan fi ibinu ya kúrò lára Òkè-Igbó3, nítorí ọ̀rọ̀ ìlẹ̀. Oko-àrojẹ àwọn Òǹdó ni Òkè-Igbó kí ó tó dip é Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó wọn4. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé lórí ilẹ̀ Òǹdó ni Òkè-igbó wà ṣùgbọ́n àwọn Ifẹ̀ ni ó ń gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn Òyìnbó ń pín ilẹ̀ Yorùbá sí ẹlẹ́kùnjẹkùn, wọ́n pín Òkè-Igbó mọ́ Òǹdó. Ohun tí ó ṣẹ́lẹ̀ lẹ̀yín náà nip è àwọn Òǹdó ń fẹ kí àwọn tí ó wà lórì ilẹ̀ àwọn ní Òkè-Igbó máa san owó-orì wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Oǹdó. Bákan náà ni àwọn Ifẹ̀ ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà ní Òkè-Igbó san owó-orí wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ̀ nítorí pé Ifẹ̀ ni wọ́n1. Yàtọ̀ sí àríyànjiyàn tí ó wà lórí ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn Òkè-Igbó san owó-orí sí, àwọn akọ̀wé agbowó-orí tún máa ń ṣe màgòmágó sí iye owó-orí tí àwọn èniyàn bá san2. Èyí ni pé ọ̀tọ̀ ni iye owó tí ó máa wà ní ojú rìsíìtì tí àwọn akọ̀wé agbowó-orí ń fún àwọn tí ó san owó-orí, ọ̀tọ̀ ni iye tí wọ́n máa kó jíṣẹ́. Gbogbo èyí ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Òkè-Igbó ní àkókò náà. Ọba Ọọ̀ni Adérẹ̀mí ni ó pa iná ìjà náà nígbà tí ó pàṣẹ ni oḍún 1932 pé kí ẹni tí ó bá mọ̀ pé Ifẹ̀ ni òun, kúrò ní Òkè-Igbó, kí ó fo odò Ọọ̀ni padà sẹ́yìn kí ó tó dúró. Àwọn tí ó padà sí òdìkejì odò Ọọ̀ni ní oḍún 1928 ati ọdún 1932 ni a mọ̀ sí Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó lónìí. 
	
Ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, àwọn àdúgbò wọ̀nyí ló wà níbẹ̀: Ilé Badà, Oríyangí, Kúwólé, Aṣípa-Afolúmọdi, Mọ̀ọrẹ̀, balágbè, Fáró, Ìta-Akíndé, Odò-Odi, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, Òkèèsodà, Olú-Òjá àti Ọdọ́. Díẹ̀ lára àwọn àdúgbò wọ̀nyí wà ní Ifẹ̀, fún àpẹrẹ, Oríyangí, Mòọ̀rẹ̀, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, àti Òkèèsodà. Bákan náà ló jẹ́ pé gbobgo ọdún ìbílẹ̀ tí  wọ́n ń ṣe ní Ifẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. Bí a bá tún wo ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni. Nítorí náà a gba orin èébú ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. 




#Article 35: Ìgbómìnà (238 words)


Igbomina Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà jẹ́ ẹ̀yà èdè Yorùbá tí àwọn Ìgbómìnà ń sọ. Ní ilẹ̀ Yorùbá lóde òní, àwọn Ìgbómìnà wà ní ìpìnlẹ̀ Ọṣun àti Kwara. Àwọn ìlú tí wọn tí ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣùn ní ìlá Ọ̀ràngún Òkè-Ìlá àti Ọ̀rà. Ní ìpínlẹ̀ Kwara, àwọn ìlú yìí pọ̀ jut i Ọ̀ṣun lọ. Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn ti ń sọ Ìgbominà. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ìfẹlodun, Ìrẹ́pọdun, Òkè-Ẹ̀rọ́ àti Isis. Ìlú tí wọ́n ti n sọ èka-èdè Igbómìnà ni ìjọba Ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódun ni Ìgbàjà, Òkèyá, Òkè-Ọdẹ, Babáńlá, Ṣàárẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní Ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọ̀dun, lára àwọn Ìlú tí wọ́n ti ń sọ ẹ̀kà-èdè Igbómìnà ni Àjàṣẹ́, Òró, Òmù-Àrán,  Àrán-Ọ̀rin. Ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkè-Ẹ̀rọ̀ ẹ̀wẹ̀, wọn a máa sọ Ìgbómìnà ni Ìdọ̀fin. Ní ti ìjọba Ìbílẹ̀ Isis, a rí ìlú bíì Òkè-Onigbin-in, Òwù-Isis, Èdìdi, Ìjárá, Ọwá kájọlà, Ìsánlú-Isis, Ọ̀là àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 
	
Olúmuyiwa (1994:2) wòye pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ka-èdè ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n ní ẹ̀yà. Èyí náà rí bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà. Lóòótọ́, àwọn ìlú tí a dárúkọ bí ìlú tí a ti ń sọ ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà máa ń gbọ́ ara wọn ni àgbọ́yé bí wọ́n ba ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀ oríṣiríṣI ni ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ láti ìlú kan sí èkejì. Ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà Òrò sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ìgbómìnà tí wọn ń sọ ni ẹkùn Òrò. 

Àkíyèsí:  A yọ iṣẹ́ yìí láti inú Àpilẹ̀kọ Ẹ́meè A. F. Bámidélé.




#Article 36: Fíìmù (378 words)


Fíìmu

Ìwà Ọ̀daràn

C.O. Odéjobí

C. O. Ọdẹjọbi (2004), ‘Àyẹ̀wò Ìgbékalẹ̀ Ìwà Ọ̀daràn nínú fíìmù Àgbéléwò Yorùbá’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.

ÀṢAMỌ̀
	
Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹwò sí bí isẹlẹ inú àwùjo se jé òpákùtèlè ìwà òdaràn nínú ìsòwó àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan, b.a. ‘Ogun Àjàyè’, ‘Owọ́ Blow’, ‘Aṣéwó Kánò’, ‘Agbo Ọ̀dájú’, ‘Ṣaworoidẹ’, ‘Ìdè’, abbl. Àlàyé wáyé lórí ọ̀nà ìgbékalè ọ̀ràn nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá, bákan náa ni a sì tún se àyèwò ipa tí fíìmù àgbéléwò ajemọ́ ọ̀ràn dídá ń ní lórí àwọn òǹwòran, òsèré lọ́kùnrin-lóbìnrin àti àwùjo lápapọ̀. Iṣẹ́ yìí ṣe àyèwò ohun tó ń mú kí àwọn asefíìmù ó máa ṣe àgbéjáde fíìmù Yorùbá ajemó òràn dídá tó lu ìgboro pa báyìí, a sì tún wo orísirísi ìjìyà tí àwọn ọ̀daràn máa ń gbà. 
	
Tíọ́rì ìmò ìfojú ìbára-eni-gbépò ni a lò kí a lè fi òràn dídá inú fíìmù wé tí ojú ayé. Ìfọ̀rọ̀ wá àwọn aṣefíìmù lénu wò wáyé láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń gbé fíìmù ajẹmó òràn dídá jáde. A tún fi ọ̀rọ̀ wá àṣàyàn àwọn òṣèré lókùnrin àti lóbìnrin àti ònwòran lénu wò láti mo ìhà tí wón ko sí fíìmù ajemó òràn dídá àti ipa tí wíwo irúfé fíìmù béè lè ní lórí àwọn ènìyàn nínú àwùjo. 
	Àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó jẹ mọ́ iṣẹ́ yìí ni a wò tí a sì tú palè. Ní àfikún. Olùwádìí tún lọ sí ilé ìkàwé láti ka ọ̀pọ̀ ìwé bíi jọ́nà, átíkù, ìwé iṣé àbò-ìwádìí láti lè mo àwọn isé tó ti wà nílè. 
	
Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé ìyàgàn àti àìní tó je mó owó, ipò, obìnrin àti àwọn nǹkan mìíràn tí ẹ̀dà lépa ló ń ti àwon ènìyàn sínú ìwà ọ̀daràn. Iṣẹ́ yìí se àkíyèsí pé lára àwọn tó ń lówó nínú ìwà ọ̀daràn ni a ti rí òré, ebí àti àwọn agbófinró. Bákan náà ni isẹ́ yìí tún se àfihàn onírúurú ọ̀nà tí àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ń gbà dá ọ̀ràn. 
	
Ní ìparí. iṣé yìí gbà pé àwọn ìwà ọ̀daràn tó ń ṣelè ni a lè kà sí ọ̀kan lára ohun tí ìsẹ̀lẹ̀ àwùjọ bí àti pé ìjìyà ti a ń fún ọ̀daràn máa ń ní ipa nínú ẹbí wọn nígbà mìíràn. 

Alábòójútó Kìíní: 		Ọ̀jọ́gbọ́n T.M. Ilésanmí 

Alábòójútó Kejì:		Ọ̀jọ̀gbọ́n B. Àjùwọ̀n 

Ojú Ìwé:			249




#Article 37: Ìlú Ìrèlè (1254 words)


Ilu Irele Akinyomade (2002), ‘Ìlú Ìrèlè’,  láti inú ‘Ipa Obìnrin nínú Ọdún Èje ní Ìlú Ìrèlè.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwe 3-12.

Ìlú Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì àti èyí tí ó tóbi jù nínú Ìkálẹ̀ Mẹ̀sàn-án (Ìrèlè, Àjàgbà, Ọ̀mi, Ìdèpé-Òkìtipupa, Aye, Ìkọ̀yà, Ìlú tuntun, Ijudò àti Ijùkè, Erínjẹ, Gbodìgò-Ìgbòdan Líṣà). Ìlú yìí wà ní ìlà-oòrùn gúṣù Yorùbá (SEY) gẹ́gẹ́ bí ìpínsí-ìsọ̀rí Oyelaran (1967), Ó sì jẹ ibìjókòó ìjọba ìbílẹ̀ Ìrèlè. Ìlú yìí jẹ́ ọkan lára àwọn ìlú tí ó ti wà ní ìgbà láéláé, àwọn olùgbé ìlú yìí yòó máa súnmọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbàá. Ní apá ìlà-oòrun, wọ́n bá ilú Sàbọmì àti Igbotu pààlà, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú Ọ̀rẹ̀ àti Odìgbó pààlà, ní àriwá tí wọ́n sì ba ìlú Okìtìpupa-Ìdèpé àti Ìgbòbíní pààlà nígbà tí gusu wọ́n bá ìlú Ọ̀mì pààlà. Ìrèlè jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sórí yanrìn, tí òjò sì máa ń rọ̀ ní àkókò rẹ̀ dáradára. Eléyìí ni ó jẹ́ kì àwọn olùgbé inú ìlú yìí yan iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa ní àyò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n ṣé wọ́n ní oko lèrè àgbẹ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń gbìn ni ọ̀pẹ, obì tí ó lè máa mú owó wọlé fún wọn. Wọ́n tún máa ń gbin iṣu, ẹ̀gẹ́ kókò, kúkúǹdùkú àti ewébẹ̀ sínú oko àrojẹ wọn. Nígbà tí ó dip é ilẹ̀ wọn kò tó, tí ó sì tún ń ṣá, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i, àwọn mìíràn fi ìlú sílẹ̀ láti lọ mú oko ní ìlú mìíràn. Ìdí èyí ló fi jẹ́ pé àwọn ará ìlú yìí fi fi oko ṣe ilé ju ìlú wọn lọ. Lára oko wọn yìí ni a ti ri Kìdímọ̀, Lítòtó, Líkànran, Òfò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀làjú dé, àwọn ará ìlú yìí kò fi iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹja pípa nìkan ṣe iṣẹ́ mọ́, àwọn náà ti ń ṣe iṣẹ́ ayàwòrán, télọ̀, bíríkìlà, awakọ̀, wọ́n sì ń dá iṣẹ́ sílẹ̀. Wọ́n ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kónyè tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kóyè tí wọn máa ń ná ní ọrọọrín sira wọn. Àwọn olùsìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ pọ̀ ni Ìrèlè. Wọ́n máa ń bọ odò, Ayélála, Arẹdẹ-lẹ́rọ̀n bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún egúngún, Ṣàngó, Ògún, Ọrẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀sìn àjòjì dé wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ń yi padà lati inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ́n sí ẹ̀sìn mùsùmùmí àti ẹ̀sìn kirisitẹni. 
Bí ojú ṣe ń là si náà ni ìdàgbàsókè ń bá ìlú yìí. Oríṣìíríṣìí ohun amúlúdùn ni ó wà ní ìlú Ìrèlè, bíi iná mọ̀nà-mọ́ná, omi-ẹ̀rọ, ọ̀dà oju popo, ile ìfowópamọ́, ilé ìfiwé-ránṣẹ́, ilé-ìwé gígá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ilẹ̀ Yorùbá tí m bẹ ni ìha “Òǹdó Province” ó sì tún jẹ́ ọ̀kan kókó nínú àwọn ilẹ̀ mẹ́ta pàtàkì tí ń bẹ ni “Ọ̀kìtìpupa Division” tàbí tí a tún ń pè ní ìdàkeji gẹ́gẹ́ Ẹsẹ̀ Odò tí ọwọ́ òwúrò ilẹ̀ Yorùbá. Ìwádìí fí yé wa wí pé ọmọ ọba Benin tó jọba sí ìlú Ugbò1 tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Olúgbò-amẹ̀tọ́2 bí Gbáǹgbá àti Àjànà. Gbáǹgbá jẹ́ àbúrò Àjànà ṣùgbọ́n nígbà tí Olúgbò-amẹ̀tọ́ wàjà, àwọn afọbajẹ gbìmọ̀pọ̀ lati fi Gbáǹgbà jẹ ọba èyí mú kí Àjànà bínú kuro ní ìlú, ó sì lọ tẹ ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́3 pẹ̀lú Gbógùnrọ́n arakunrin rẹ̀. Láti ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ ní Àjànà tí lọ sí ìlú Benin, ò sí rojọ́ fún Ọba Uforami4 bí wọ́n ṣe fí àbúrò oùn jọba, àti pé bí oùn náà ṣe tẹ ibikan dó. Oùn yóò sì jẹ Ọba “Olú Orófun”5 sí ìbẹ. Ọba Uforami sì fún Àjànà ní adé, Àjànà padà sí Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ó bí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Ògèyìnbó, ọkùnrin sì ni àwọn mejeeji. Kò pẹ́, kò sí jìnà, Àjànà wàjà. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji lọ si Benin lati jọba. Ògèyìnbó lọ sí Benin lati jọba. Ó dúró sí ọ̀dọ̀ Oba Benin pé baba òun tí wàjà, òun yóò sí jọba. Ọ̀rúnbẹ̀mékún náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ìyá Ọba Benin pé òun náà fẹ jọba nígbà tí baba òun ti kú. Ọba Benin ń ṣe orò ọba fún Ògèyìnbó nígba tí Ìyá ọba ń ṣe orò fún Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún. Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún mu Olóbímítán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí akọ́dà Ọba Benin tí yóò wà gbé oúnjẹ fún Ìyá Ọba, rí í wí pé ọrọ̀ tí ọba ń ṣe fún alejo ọdọ̀ rẹ̀ náà ní Ìyá ọba ń ṣe fún ẹni yìí. Èyí mú kí akọ́dá ọba fi ọ̀rọ̀ náà tó kabiyesi létí. Ní ọba ni ọmọ kì í bí ṣáájú iyaa rẹ, ó pe Ògèyìnbò kó wá máa lọ. Nígbà tí àwọn méjèéjì fí lọ sí Benin, Gbógùnrọ̀n tí gbe “Àgbá Malokun”6 pamọ́ nítorí ó tí fura pé wọn kò ní ba inú dídùn wá.  Ògèyìnbó dé Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, kò rí Àgbá Malòkun mọ́, ó wa gbé Ùfùrà, ó wọ inú ọkọ ojú omi, o sí tẹ isalẹ̀ omi lọ, oùn ní ó tẹ ìlú Erínjẹ dó. Ní àkókò tí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún fí wà ní ìlú Benin, Òlóbímitán, ọmọ rẹ̀ máa lọ wẹ̀ lódò Ìpòba7 àwọn ẹrú ọba sí màa ń ja lati fẹ èyí ló fá ìpèdè yìí “Olóbímitán máa lọ wẹ̀ lódì kí ẹru ọba meji máa ba jìjà ku tori ẹ”. Èyí ní wọ́n fi ń ṣe ọdún Ìjègbé ní ìlú Benin. Ní ìgbà tí ó ṣe Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Olóbímitán padà sí ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ṣùgbọ́n Gbógùnrọ̀n sọ fún wí pe àbúrò rẹ̀ (Ògèyìnbó) i ba ibi jẹ́ kò sì dára fún wọn lati gbé, wọ́n kọja sí òkè omi wọn fi de Ọ̀tún Ugbotu8, wọn sọkalẹ, Olóbímitán ní òun…àbàtà wọ́n wá tẹ́ igi tẹ́ẹ́rẹ́ lorí rẹ̀ fún, èyí ní wọn fí ń kí oríkì wọn báyìí: “Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún a hénà gòkè” .
Àgbá Malòkun tí gbógùnrọ̀n gbé pa mọ́ kò le wọ inú ọkọ́ ojú omi, wọn sọ ọ́ sínú omi, títí dì òní yìí tí wọ́n bá ti ń sọdún Malòkun ní ìlú Ìrèlè, a máa ń gbọ́ ìró ìlù náà ní ọ̀gangan ibi wọ́n gbé sọ ọ́ somi. Wọ́n tẹ̀dó sí odó Ohúmọ. Oríṣìíríṣìí ogun ló jà wọ́n ní odí Ohúmọ, lára wọn ní Ogun Osòkòlò10, Ogun Ùjọ́11, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olumisokun ọmọ ọba Benin, ìyàwò rẹ̀ kò bímọ nígbà tó dé Ìrèlè ó pa àgọ́ sí ibikan, ibẹ̀ ní wọn tí ń bọ Malokun ni ìlú Ìrèlè. Lúmúrè wá dò ní ìlú Ìrèlè, ó fẹ Olóbímitán ṣùgbọ́n Olóbímitán kò bímọ fún un èyí mú kí ó pàdà wa si ọdọ baba rẹ̀, Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún, olúmísokùn wá fẹ Olóbímitán ní odó Ohúmọ. Wọ́n bí Jagbójú àti Oyènúsì, ogun tó jà wọn ní ní odó Ohúmọ pa Oyènúsì èyí mú kí Jagbójú sọ pé “oun relé baba mi”. Mo relé. Bí orúkọ àwọn to kọ́kọ́ jọba ni ìlú Ìrèlè ṣe tẹ̀lé ara wọn nì yìí: 

Ègùntán á ṣẹ 

Ọ̀bàrà á ṣẹ 

A díá fún Ìyá túrèké 

Wọ́n ni kó lọ ra ewurẹ́ wá lọ́jà 

Owó ẹyọ kan ní wọn fún 

Ègùntán ní ìyá òun yóò ra ewúrẹ́ méjì 

Ọ̀bàrà ni ìyà òun yóò ra ewúrẹ́ kan 

Túrèké ra ewúrẹ́ kan 

Ṣùgbọ́n ó lóyún 

Kí ó tó délé ewúrẹ́ bí mọ . 

Ibi owó ń gbé so, 

Tí a rí nǹkan fi kan 

Ìrèlè ẹgùn,

Ó gbẹ́ja ńlá bọfá, 

Èṣù gbagada ojú ọ̀run 

Ó jókòó ṣòwò ọlà 

Malòkun ò gbólú 

Ọba-mi-jọ̀ba òkè. 

Àtètè-Olókun 

Iwá òkun, òkun ni 

Ẹ̀yìn òkun, òkun ni 

A kì í rídìí òkun 

A kìí rídìí Ọlọ́sà 

Ọmọ Ìrèlè kò ní opin 

Ìdí ìgbálẹ̀ kì í ṣẹ́

Aṣọ funfun tí Malòkun 

Ọpẹ ni ti Malòkun .




#Article 38: Bámijí Òjó (1355 words)


Bamiji Ojo (20 October, 1939) je olukowe omo ile Naijiria.

	
A bí Bámijì Òjó ní ogúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939 ní ìlú ìlọ́ràá, ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijió ní ìpínlẹ̀ Ọ̀jọ́. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Jacob Òjó àti Abímbọ́lá Àjọkẹ́ Òjó. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe. 
	
Ojú ti ń là díẹ̀ nígbà náà, ẹni tí ó bá mú ọmọ lọ sí ilé-ìwé ní ìgbà náà, bí ìgbà tí ó fi ọmọ sọ̀fà tí ó mú ọmọ lọ fún òyìnbó ni. Ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ pa ìmọ̀ pọ̀ wọ́n fi sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìjọ onítẹ̀bọmi ti First Baptist Day School ìlú Ìlọràá ni ọdún 1946. O ṣe àṣeyẹrí nínú ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́fà, tí ó kà jáde ni ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Nígbà náà wọ́n ti ń dá ilé ẹ̀kọ́ gíga Mọ́dà (Modern School) sílẹ̀. Bámijí Òjó ṣe ìdánwò bọ́ sí ilé-ìwé Local Authority Modern School ní ìlú Fìdítì, ó wà ní ibẹ̀ fún ọdún mẹ́ta (1956-1959). 
	
Lẹ́yìn èyí nínú ọdún 1960, Bámijí Òjó ṣe iṣẹ́ díẹ̀ láti fi kówó jọ. Nítorí pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ láti tọ́ ọ kọjá ìwé mẹ́jọ. Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ tí ó sì kówó jọ fún ọdún kan pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí “Modern School”, ó tún tíraka láti tẹ̀síwájú lẹ́nu ìwé rẹ̀. Ó lọ sí ilé-ìwé ti àwọn olùkọ́ni ti “Local Authority Teacher Training College” ní ìlú Ọ̀yọ́ láti inú ọdún 1961 di ọdún 1962. 
	
Ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ tí ó wù ú lọ́kàn gan-an láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni iṣẹ́ tíṣà. Ó ṣe iṣẹ́ tíṣà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bí i Ṣakí, Edé, Ahá. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìròyìn ni ó múmú ní ọkàn rẹ̀. 
	
Bámijí Òjó wà lára àwọn méjìlá àkókó tí wọ́n gbà ní ọdún 1969 láti kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì Èkó. Nígbà náà ojú ọ̀lẹ ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tí ó bá lọ kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì. 
	
Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n gba Bámijí Òjó sí ilé iṣẹ́ ìròyìn ní ọdún 1970, Àlhàájì Lateef Jákàńdè ni ó gbà á sí iṣẹ́ ìròyìn ní ilé-iṣẹ́ “Tribune”ní ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí igbá kejì olóòtú Ìròyìn Yorùbá. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó tin í ìyàwó nílé nígbà náà wọ́n gbé e padà sí Ìbàdàn. Ilé-iṣẹ́ wọn wà ní Adẹ́ọ̀yọ́. Ní àsìkò yìí kan náà ni Bámijí Òjó ronú pé iṣẹ́ ìròyìn ti orí Rédíò Sáá ní ó wu òun. Ó wá ń bá wọn ṣiṣẹ́ aáyan ògbufọ̀ ni ilé-iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Èyí ni ó ń ṣe tí ó fi ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ “Tribune” àti nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. 
	
Ní ọdún 1971 ni wọ́n gba Bámijí Òjó gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Ìròyìn ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Àwọn tí wọ́n jìjọ ṣiṣẹ́ ìròyìn nígbà náà ni Alàgbà Ọláòlú Olúmìídé tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Olóògbé Àlhàájì Sàká Ṣíkágbọ́ àti Olóògbé Akíntúndé Ògúnṣínà àti bàbá Omídèyí. 
	
Nítorí ìtara ọkàn tí Bámijí Òjó ní láti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Tẹlifíṣàn ó kúrò ní “Radio Nigeria”, ó lọ sí “Western Nigerian Broadcastint Service” àti “Western Nigerian Televeision Station” WNBS/WNTV tó wà ní Agodi Ìbàdàn, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1973. Ni ibẹ̀ ni ọkà rẹ̀ ti balẹ̀ tí àyè sì ti gbà á láti lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti gbé èdè, àṣà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lárugẹ. Ìràwọ̀ rẹ̀ si bẹ̀rẹ̀ sí í tàn gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn. Nígbà ti Bámijí Òjó wà ní “Radio Nigeria” kí ó tó lọ sí “Western Nigerian Television Station (WNTV)” ni wọ́n ti kọ́kọ́ ran àwọn oníṣẹ́ ibẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Rédíò. Ilé iṣẹ́ Rédíò ní Ìkòyí ni wọn ti gba idánilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ìdí nip é tí ènìyàn bá máa sọ̀rọ̀ nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”nígbà náà ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́. Lára àwọn ètò tó máa ń ṣe lórí ẹ̀rọ Tẹlifísàn ni “Káàárọ̀-oò-jíire” àti “Tiwa-n-tiwa” túbọ̀sún Ọládàpọ̀, Láoyè Bégúnjọbí àti àwọn mìíràn ni wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ nígbà náà. Gbogbo akitiyan yìí mú kí ìrírí Bámijí gbòòrò si nípa iṣẹ́ ìròyìn àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn inú rẹ̀. 
	
Ní ọdún 1976 ni Bámijí Òjó lọ fún ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ ní Òkè Òkun, ní orílẹ̀ èdè kenyà níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí “Certificate Course In Mass Communication” (Ìlànà Ìgbétèkalẹ̀ lórí afẹ́fẹ́). 
	
Nígbà tí ó di oṣù kẹwàá ọdún 1976, ni wọ́n dá àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta sílẹ̀, Ọ̀yọ́, Òndó àti Ògùn, Bámijí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kúrò ni ilé iṣẹ́ “Western Nigerian Broadcasting Services” àti “Western Nigerian Television Station (WNBS/WNTV) tí ó lọ dá Rédíò Ọ̀yọ́ sílẹ̀. Engineer Olúwọlé Dáre ni ó kó wọn lọ nígbà náà, Kúnlé Adélékè, Adébáyọ̀ ni wọ́n jìjọ dá ilé iṣẹ́ Rédíò sí lẹ̀ ni October 1976, wọ́n kó ilé iṣẹ́ wọn lọ sí Oríta Baṣọ̀run Ìbàdàn. 
	
Nínú ọdún 1981 ni Bámijì Òjó tún pa iṣẹ́ tì, tí ó tún lọ fún ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ Rédíò ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó jẹ́ gbajúgbajà ní àgbáyé tí wọn ń pè ní “British Broadcasting Co-operation (BBC) London fún Certificate Course. 
	
Ní ọdún 1983 ni ó lọ sí orílẹ̀ èdè Germany fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Olóṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí à ń pè ni “Voice of Germany”. Níbẹ̀ ló ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ Rédíò àti Móhùnmáwòrán. Ìgbà tí Bámijì Òjó dé ni ó jókòó ti iṣẹ́ tí ó yìn láàyò. Èyí ni ó ń ṣe títí tí wọ́n tún fi pín Ọ̀yọ́ sí méjì tí àwọn Ọ̀ṣun lọ, èyí mú kí àǹfààní wà láti tẹ̀ síwájú. Oríṣìíríṣìí ìgbéga ni ó wáyé nígbà náà ṣùgbọ́n ìgbéga tí ó gbẹ̀yìn nínú iṣẹ́ oníròyìn ni “Director of Programmes’ tí wọ́n fún Bámijí Òjó nínú oṣù kẹsàn-án, ọdún 1991, Ó sì wà lẹ́nu iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ títí di ọdún 1994. Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1994 ni ó fẹ̀yìn tì. 
	
Ní ọdún tí ó tẹ̀lé, nínú oṣù kìíní ọdún 1995 ni Bámijì Òjó dá ilé iṣẹ́ tirẹ̀ náà sílẹ̀. Èyí tí ó pa orúkọ rẹ̀ ní ‘Bámijí Òjó Communicatio Center’. 
	
Bámijì Òjó tin í iyàwó bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run sì ti fi ọmọ márùn-ún dá a lọ́lá. 
	
Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn móríyá àti ìkansáárásí ni Bámijí Òjó gbà nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ijọba. Fún orí pí pé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ tí ó fi hàn ní ilẹ̀ Germany. Ó gba onírúurú ẹ̀bùn fún àṣeyọrí àti àṣeyege ní òpin ẹ̀kọ́ náà. Pẹ̀lú ìrírí àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ‘London’ àti ‘Germany’ó di ọmọ ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí ‘Overseas Broadcasters’ Association’. 
	
Ní ọdún 1990 ni ọ̀gágun Abudul Kareem Àdìsá fún Bámijí Òjó ní ẹ̀bùn ìkansáárá sí, èyí ni ‘Ọ̀yọ́ State Merit Award for the best producer or the year’. Fún ìmọ rírì ètò tí ó ń ṣe ní orí ‘Television Broadcasting Co-operation Ọ̀yọ́ State (BCOS)’ Ṣó Dáa Bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń jé àǹfààní rẹ̀, Aláyélúwà Ọba Emmanuel Adégbóyèga Adéyẹmọ Ọ̀pẹ́rìndé 1. ni ó fi oyè Májẹ̀óbà jẹ́ ti ilú Ìbàdàn dá a lọ́lá, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1994. 

	
Ìwé kíkọ jẹ ohun ti Bámijì Òjó nífẹ̀ẹ́ sí. Ọba Adìkúta jẹ́ ọ̀ken lára ìwé méjì sí mẹ́ta tí ó ti kọ jáde.
	
Ìwé àkọ́kọ́ tí Bámijì Òjó kọ jáde ni Mẹ́numọ́.  Ìwé yìí jáde ni ọdún 1989. 
	
Lẹ́yìn èyí ni Bámijì Òjó kọ ìwé rẹ̀ kejì.  Ọba Adìkúta  tí ó jáde nínú oṣù kẹta ọdún 1995. 
	
Nígbà tí Bámijì Òjó wà ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria” ni ó ti kọ́kọ́ kọ ìwé kan tí ó pè ní Àṣà Àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìwé yìí wà lọ́dọ̀ àwọn atẹ̀wétà tí ó gbàgbé sí wọn lọ́dọ̀ tí kò sì jáde di òní olónìí. 
	
Bámijì Òjó gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí ó ní ìtara ọkàn. ó tún ní àwọn ìwé méjì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò jáde ní àìpẹ́. Àkọ́kọ́ ni Ṣódaa Bẹ́ẹ̀. Ìwé yìí jẹ́ àbájáde ètò kan tí ó ṣe pàtàkì lórí Rédíò. 
	
Òmíràn ni ètò Èyí Àrà.  Bámijí Òjó ni ó dá ètò náà sílẹ̀¸ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 1984. Ní ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jù lọ “South  West”, òun ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kò sí ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó síwájú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí “Phone In” Èyí Àrà.




#Article 39: Ògbàgì (1233 words)


L.A. Adúlójú (1981), ‘Ìlú Ògbàgì’, láti inú ‘Ọdún Òrìṣà Òkè Ògbàgì ní Ìlú Ọ̀gbàgì Àkókó’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, Dall  OUA, Ife, Ojú-ìwé 1-5.
		
ÀPÈJÚWE ÌLÚ ÒGBÀGÌ 
	
Ìlú Ògbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú pàtàkì tó wà ní agbègbè àríwá Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìlú yìí wà láàárín Ìkàrẹ́ àti Ìrùn tó jẹ́ ààlà àríwá Àkókó àti Èkìtì. Ìlú Ọ̀gbàgì wà ní ojú ọ̀nà tó wá láti Adó-Èkìtì sí Ikàrẹ́, ó sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rìnláá sí ìlú Ìkàrẹ́. Láti Ìkàrẹ́, ìlú Ọ̀gbàgì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn tí ó sì jẹ́ pé títì tí a yọ́ ọ̀dà sí ló so ó pọ̀ mọ́ ìlú Ìkàrẹ́ tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkókó. 
	
Ìlú Ọ̀gbàgì kò jìnnà sí àwọn ìlú ńlá mìíràn ní agbègbè rẹ̀. Ní ìlà oòrùn Ọ̀gbàgì, a lè rí ìlú bí i Ìkàrẹ́ àti Arigidi àti ní ìwọ̀ oòrùn ìlú yìí ni ìlú Ìrùn wà ní ọ̀nà tó lọ sí Adó-Èkìtì. 
	
Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú mẹ́fà tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè àríwá Àkókó nírorí ìwádìí sọ fún wa pé gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn, ti ọdún `963, àwọn ènìyàn ìlú yìí ju Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ nígbà náà ṣùgbọ́n èyí yóò tit ó ìlọ́po méjì rẹ̀ lóde òní. Ìlú yìí jẹ́ ìlú ti a tẹ̀dó sí ibi tí ó tẹ́jú ṣùgbọ́n tí òkè yí i po, lára àwọn òkè wọ̀nyí sì ni a ti rí òkè Oròkè tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ojýbọ Òrìṣà Òkè Ọ̀gbàgì. `
	
Ojú ọ̀nà wọ ìlú yìí láti àwọn ìlú tó yí i pot í ó sì jẹ́ pé èyí mú ìrìnnjò láti Ọ̀gbàgì sí ìlúkílùú ní Ìpinlẹ̀ Oǹdó rọrùn. Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí mú un rọrùn láti máa kó àwọn irè oko wọ̀lú láti gbogbo ìgbèríko tó yí ìlú Ọ̀gbàgì ká. 
	
Gẹ́gẹ́ bi ó ti jẹ́ pé oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ àti lóde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè rí i ní ìlú Ọ̀gbàgì níbi tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá ni wọn ń ṣe. Iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ pàtàkì iṣẹ́ àwọn Yorùbá ló rí àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ mìíràn. Iṣẹ́ àwọn ọkùnrin ni ẹmu-dídá tó tún ṣe pàtàkì tẹ̀lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Òwò ṣíṣe, oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bí i agbọ̀n híhun, irun gígẹ̀, iṣẹ́ alágbẹ̀dẹ, ilé mímọ àti iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Iṣẹ́ àwọn obìrin sì ni aṣọ híhun, irun dídì, òwò ṣíṣe àti àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìjọba ti ọkùnrin àti obìnrin ń ṣe. 
	
Nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọn ń ṣe, púpọ̀ nínú oúnjẹ wọn ló wá láti ìlú yìí tí ó sì jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ni oúnjẹ tí a ń kó wọ̀lú. Iṣẹ́ ẹmu-dídá pàápàá ti fẹ́ ẹ̀ borí iṣẹ́ mìíràn gbogbo nítorí èrè púpọ̀ ni àwọn tó ń dá a ń rí lórí rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé àwọn àgbẹ̀ oníkòkó kò lè fọwọ́ rọ́ àwọn adẹ́mu sẹ́hìn nítorí ẹmu-dídá kò ní àsìkò kan pàtó, yípo ọdún ni wọ́n ń dá a. 
	
Iṣẹ́ ẹmu-dídá yìí ṣe pàtàkì nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ògùrọ̀ ni a lè rí ní ìlú yìí àti ní gbogbo oko wọn. Àwọn adẹ́mu wọ̀nyí máa ń gbin igi ògùrọ̀ sí àwọn bèbè odò bí àwọn àgbẹ̀ oníkòkó ṣe máa ń gbin kòkó wọn. Èyí ló sì mú kí àwọn tó ń ta ẹmu ní Ìkàrẹ́, Arigidi, Ugbẹ̀, Ìrùn àti Ìkáràm máa wá sí ìlú Ọ̀gbàgì wá ra ẹmu ní ojoojúmọ́. 
	
Bí a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọna ti iṣẹ́ ń gbé wá sí ìlú Ọ̀gbàgì náà ni a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ọ̀gbàgì tí iṣẹ́ ìjọba gbé lọ sí ibòmíràn, nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ìbá wà láàárín ìlú yìí ni wọ́n wà lẹ́hìn odi. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí a lè rí ní àárín ìlú náà ni àwọn olùkọ́ àwọn ọlọ́pàá, ọ̀sìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́, òṣìṣẹ́ ilé ìfìwéránṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀. 
	
Idí tí a fir í àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọ̀nyí ni àwọn àǹfààní tí ìjọba mú dé ìlú yìí bí i kíkọ́ ilé ìgbẹ̀bí àti ìgboògùn, ilé ìdájọ́ ìbílẹ̀, ilé ìfìwéránṣẹ́, ilé ìfowópamọ́, ọjà kíkọ́, ilé ọlọ́pàá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti ilé-ẹ̀kọ́ kéékèèkéé. 
	
Nípa ti ẹ̀sìn, àwọn oríṣìí ẹ̀sìn mẹ́ta pàtàkì tí a lè rí lóde òní ní ilẹ̀ Yorùbá náà ló wà ní Ọ̀gbàgì. Fún àpẹẹrẹ, a lè rí ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé tó jẹ́ ẹ̀sìn kirisitẹẹni àti ẹ̀sìn mùsùlùmí. Nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a ti rí oríṣìíríṣìí àwọn òrìṣà tí wọn ń sìn, èyí tí òrìṣà òkè Ọ̀gbàgì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tó wà fún gbogbo ìlú Ọ̀gbàgì. Bí a ti rí àwọn tó jẹ́ pé wọn kò ní ẹ̀sìn méjì ju ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ni a rí àwọn mìíràn tó wà nínú àwọn ẹ̀sìn ìgbàlódé wọ̀nyí síbẹ̀ tí wọn tún ń nípa nínú bíbọ àwọn òrìṣà inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Eléyìí lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn ìdílé tàbí àwọn àwòrò òrìṣà tó jẹ́ dandan fún wọn láti jẹ oyè àwòrò bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn mìíràn ni wọ́n nítorí ìdílé wọn ló ń jẹ oyè náà. Ẹ̀sìn ìbílẹ̀ kò jẹ́ alátakò fún ẹ̀sìnkẹsìn ni wọ̀ngbà tí ẹ̀sìn náà bá lé mú ire bá àwọn olùsìn. 
	
Àpèjúwe mi yìí kò ní kún tó tí mo bá fẹnu ba gbogbo nǹkan láìsọ ẹ̀yà èdè tí ìlú Ọ̀gbàgì ń sọ. Ní agbègbè Àkókó, oríṣìíríṣìí èdè àdùgbò tó jẹ́ ara ẹ̀yà èdè Yorùbá ni a lè rí, nítorí ìdí èyí, ó ṣe é ṣe kí ọmọ ìlú kan máà gbọ́ èdè ìlú kejì tí kò ju kìlómítà méjì sí ara wọn. Nítorí náà, ó dàbí ẹni pé iye ìlú tí a lẹ̀ rí ní agbègbè àríwá Àkókó tàbí ní Àkókó ní àpapọ̀ ní iye ẹ̀yà èdè tí a lè rí. Ṣùgbọ́n a rí àwọn ìlú díẹ̀ tí wọn gbọ́ èdè ara wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà díẹ̀díẹ̀ nínú wọn. Ó ṣe é ṣe kí irú ìyàtọ̀-sára èdè yìí ṣẹlẹ̀ nípa oríṣìíríṣìí ogun abẹ́lé tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá láyé àtijọ́ nítorí èyí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tẹ̀dó sí agbègbè yìí tí ó sì fa sísọ oníruurú èdè tó yàtọ̀ sí ara wọn nítorí agbègbè yìí jẹ́ ààlà láàárín Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Kwara àti Bendel lóde òní.
	
Nítorí ìdí èyí, èdè Ọ̀gbàgì jẹ́ àdàpọ̀ èdè Èkìtì àti ti Àkókó ṣùgbọ́n èdè Èkìtì ló fara mọ́ jùlọ nítorí ìwọ̀nba ni àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú èdè Ọ̀gbàgì àti ti Èkìtì gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú àwọn orin àti ewì tí mo gbà sílẹ̀. Fún ìdí èyí, kò ní ṣòro rárá fún ẹni tó wá láti Èkìtì láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ èdè Ọ̀gbàgì ṣùgbọ́n ìṣòro ni fún ẹni tó wá láti ìlú mìíràn ní Àkókó láti gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì tàbí láti sọ ọ́ yàtọ̀ sí àwọn ìlú díẹ̀ ní àkókó tí wọn tún ń sọ ẹ̀yà èdè Èkìtì bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ìlú Ìrùn, Àfìn, Eṣé àti Ìrọ̀ ti wọn wà ní agbègbè kan náà pẹ̀lú Ọ̀gbàgì lè sọ tàbí gbọ́ èdè Ọ̀gbàgì pẹ̀lú ìrọ̀rùn. 
	
Bí ó ti wù kí ìṣòro gbígbọ́ èdè yìí pọ̀ tó, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun fún àǹfààní tí mo ní láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn ará ìlú yìí fún ọdún márùn ún tí ó mú kí ń lè gbọ́ díẹ̀ nínú èdè Ọ̀gbàgì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè sọ ọ́ ṣùgbọ́n mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Olóyè Odù tó jẹ́ olùtọ́nisọ́nà àti olùrànlọ́wọ́ mi tó jẹ́ ọmọ Ọ̀gbàgì tó sì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá láti ṣe àlàyé lórí àwọn nǹkan tó ta kókó èyí tí ó sì mú kí iṣẹ́ ìwádìí yìí rọrùn láti ṣe.




#Article 40: Ìrè-Èkìtì (614 words)


Ire-Ekiti

F.I. Ibitoye

F.I. Ibitoye (1981), ‘Ìlú Ìrè-Èkìtì’, láti inú ‘Òrìṣà Ògún ní ìlú Ìrè-Èkìtì.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwé 1-3.
	
Ìrè-Èkìtì jẹ́ ìlú kan ní agbègbè àríwá Èkìtì ní ìpínlẹ̀ Oǹdó; èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ bíbí inú ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn àtijọ́. Tí ènìyàn bá gba ojú títì ọlọ́dà wọ ìlú Ìrè, ó rí bi  kìlómítà márùndínlógójì sí Ìkọ̀lé-Èkìtì tí í ṣe olú ìlú fún gbogbo agbègbè àríwá Èkìtì. Ṣùgbọ́n ó fi díẹ̀ lé ni ogóje kìlómítà láti Ilé-Ifẹ̀. Èyiini tí a bá gba ọ̀nà Adó-Èkìtì. Nígbà tí a bá gba ọ̀nà yìí, lẹ́hìn tí a dé Ìlúpéjú-Èkìtì ni a óò wá yà kúrò ní títí ọlọ́dà sí apá ọ̀tún. Ọ̀nà apá ọ̀tún yẹn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ni a óò wá tọ̀ dé Ìrè-Èkìtì, kìlómítà márùn-ún ibi tí a ti máa yà jẹ́ sí ìlú Ìrè-Èkìtì. 
	
Ara ẹ̀yà ilẹ̀ Yorùbá náà ní ilú Ìrè-Èkìtì wà. Àwọn gan-an pàápàá sì tilẹ̀ fi ọwọ́ sọ àyà pé láti Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ti wá. Wọ́n tún tẹnu mọ́ ọ dáradára pé ibẹ̀ ni àwọn ti gbé adé ọba wọn wa. Nítorí náà, títí di òní olónìí, Onírè ti Ìlù Ìre-Èkìtì jẹ́ ògbóǹtagi kan nínú àwọn ọba Aládé tí ó wà ní Èkìtì. 
	
Gẹ́gẹ́ bí n óò ti ṣe àlàyẹ́ ní orí kejì ìwé àpilẹ̀kọ yìí, “Oní-èrè” ni ìtàn sọ fún wa pé wọ́n gé kúrú sí “Onírè” ti ìsìnyìí. Alàyẹ́ Samuel Johnson nínú The History of  The Yoruba. sì ti fi yé wa pé nítorí oríṣìíríṣìí òkè tí ó yi gbogbo ẹ̀yà Yorùbá tí à ń pe ní Èkìtì ká, ni a ṣe ń pè wọ́n bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, orúkọ àjùmọ jẹ́ ní “Èkìtì”. Ìtàn sí tún fi yé mi pé ìlú kékeré kan tí ó ń jẹ́ “Igbó Ìrùn” ni àwọn ará Ìrè-Èkìtì ti ṣí wá sí ibi tí wọ́n wà báyìí; àìsàn kan ló sì lé wọn kúrò níbẹ̀. “Igbó Ìrùn” ti di igbó ní ìsinyìí, ṣùgbọn apá àríwá Ìrè-Èkìtì ló wà. Mo fi èyí hàn nínú àwòrán ìlú náà. 
	
Ìṣesí àwọn ará Ìrè-Èkìtì kò yàtọ̀ sí tí àwọn ìlú Yorùbá yòókù, yálà nípa aṣọ wíwọ̀ tàbí àṣà mìíràn. Àrùn tí í sìí ṣe Àbọ́yadé, gbogbo Ọya níí ṣe. Àwọn náà kò kẹ̀rẹ̀ nípa gbígba ẹ̀sìn Òkèèrè mọ́ra nígbà tí gbogbo ilẹ̀ Yorùbá mìíràn ń ṣe èyí. Ẹsìn Ìjọ Páàdi àti ti Lárúbáwá ni a gbọ́ pé wọ́n gbárùkù mọ́ jù. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ráyẹ̀ gbọ́ ti ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá, bí ọ́ tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ó ní àwọn àdúgbò tí èyí múmú láyà wọn jù. Fún àpẹrẹ, mo tọka sí àwọn àdúgbò tí wọn ti mọ̀ nípa Òrìṣà Ògún dáadáa nínú àwòrán. 
	
Èdè Èkìtì nì òdè Àdúgbọ̀ wọn. Nítorí náà, ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin èdè Èkìtì àti ti Yorùbá káríayé náà ló wà ní tiwọn. Fún àpẹẹrẹ wọn a máa pa àwọn kóńsónàntì kan bíi ‘w’ jẹ. Wọn a pe “owó,” ‘Òwírọ̀’ “Àwòrò” ni “eó”, “ọ̀úrọ̀”, “Àòrò”. Wọ́n tún lè pa ‘h’ gan-an jẹ; kí wọ́n pe “Ahéré”ní “Aéré. Nítorí náà “Aéré eó” yóò dípò “Ahéré owó”
	
Nígbà mìíràn pàápàá, wọn a fi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan dípò òmíràn, fún àpẹẹrẹ: 
		
ira yóò dípò ará 
		
erú yóò dípò erú
		
èyé  yóò dípò ìyá. 
		
àbá yóò dípò bàbá 
		
ijọ́ yóò dípò ọjọ́ 

	
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ, àwọn náà tún máa ń fi fáwẹ́lì ‘u’ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ: 
		
Ulé dípò Ilé 
		
Ùrè dípò Ìrè 
		
Ufẹ̀ dípò Ifẹ̀ 
		
Ukú dípò Ikú 

		
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni èdè yìí fi yàtọ̀ si ti Yorùbá káríayé. Nítorí náà, mo kàn ṣì ń ṣe àlàyé rẹ̀ léréfèé ni, n óò tún máa mẹ́nu bá wọ́n nígbà tí a bá ń ṣe àtúpayá èdè orin Ògún. Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀ ni.




#Article 41: Ọ̀ra Ìgbómínà (1945 words)


Ọ̀ra Ìgbómínà

Agbègbè Ìlá-Ọ̀ràngún ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà wà. Ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà ló dúró bí afárá tí a lè gùn kọjá sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ípínlẹ̀ Ondó, àti ìpínlẹ́ Kwara. Ìkóríta ìpínlẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni Ọ̀ra-ìgbómìnà wà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní wọ́ ṣírò rẹ̀ mọ́. Kilómítà mẹ́tàlá ni Ọ̀ra-Ìgbómìnà sí Ìlá-Ọ̀ràngún tó wá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Kílómítà mẹ́ta péré ni Ọ̀ra sí Àránọ̀rin tó wà ní ìpínlẹ́ Kwara, ó sì jẹ́ Kìlómítà kan péré sí Ọ̀sàn Èkìtì tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.
	
Ilé-Ifẹ̀ ni àwọm Ọ̀ra ti wá ní òórọ̀ ọjọ́. Ìtàn àtẹnudẹ́nu fi yẹ́ ni pé kì í ṣe Ọ̀ra àkọ́kọ́ ni wọ́n wà báyìí. Ní ǹkan bí ọ̀rìnlé-lẹ́ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́hìn ni wọ́n tẹ ibi tí wọ́n wà báyìí dó. Ọra-Ìgbómìnà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ogun dààmú-púpọ̀ ní ayé àtijọ́. Nínú àwọn ogun tí ìtàn sọ fún ni pọ́ dààmú Ọ̀ra ni – ogun Ìyápọ̀ (ìyàápọ̀), ogun Jálumi, Èkìtì Parapọ̀, àti ògun Ògbórí-ẹfọ̀n. Ní àkókò náà, àwọn akọni pọ́ ní Ọ̀ra lábẹ́ àkóso Akẹsin ọba wọn. Àwọn ògbógi olórí ogun nígbà náà ni ‘Eésinkin Ajagunmọ́rùkú àti Eníkọ̀tún Lámọdi ti Òkè-Ópó àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun mìíràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fí ìbẹ̀rù-bójo sá kúrò ní ìlú ní àkókò ogun. Nígbà tí ogun rọlẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nínú àwọn to ti ságun ló pádá wá sí Ọ̀ra ṣùgbọ́n àwọn mìíràn kò padà mọ́ títí di òní olónìí. Àwọn Òkèèwù tó jẹ́ aládùúgbò Ọra náà ṣí kúrò ní Kèságbé ìlú wọn, wọ́n sì wá sí Ọ̀ra. Nínú àwọn tí kò pádà sí Ọ̀ra mọ́, a rí àwọ́n tọ́ wá ní Rorẹ́, Òmù-àrán, Ìlọfà àti Ibàdàn. Àwọn ìran wọn wà níbẹ́ títí dì òní olónìí. Ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí, ìlú méjì ló papọ̀ tí a ń pè ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà - Ọ̀ra àti Òkèèwù, ìlú ọlọ́ba sin i méjèèjì. 

B. ÌṢẸ̀DÁ ÌLÚ Ọ̀RA-ÌGBÓMÌNÀ 
	
Nítorí pẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀  ìtàn ìṣẹ̀dá àwọn ìlú Yorùbá jẹ́ àtẹnudẹ́nu, ó máa ń sòro láti sọ ní pàtó pé báyìí-báyìí ni ìlú kan ṣe ṣẹ̀. Nígbà míràn a lè gbọ́ tọ́ bí ìtàn méjì, mẹ́ta, tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ nípa bí ìlú kan ṣe ṣẹ́. Báyìí gan-an nit i ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà rí. Ohun tí a gbọ́ ni a kọ sílẹ̀ ní éréfẹ̀ẹ́ nítorí kì í kúkú ṣe orí ìtàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà gan-an ni mo ń kọ ìwé lé, ṣùgbọ́n bí òǹkàwé bá mọ díẹ̀  nínú ìtàn tó jẹ mọ́ ìṣẹ̀dá ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà, yóò lè gbádùn gbogbo ohún tí a bá sọ nípa Ọdún Òrìṣà Ẹlẹ́fọ̀n ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà tí mo ń kọ Ìwé nípa rẹ̀. 
	
Ìtàn kan sọ pé àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra Ìgbómìnà kì í ṣe ọ̀kan náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá. Irú wá, ògìrì wá ni ọ̀rọ̀ ìlú Ọ̀ra. Àwọn ọmọ alápà wá láti Ilé-Ifẹ̀. Àwọn Ìjásíọ̀ wá látio Ifọ́n. Awọn Òkè-Òpó àti Okè kanga wá láti Ọ̀yọ́ Ilé, àwọn mìíràn sí wá láti Ẹpẹ̀ àti ilẹ̀ Tápà. Kò sí ẹni tó lè sọ pé àwọn ilé báyìí-báyìí ló kọ́kọ́ dé ṣùgbọ́n gbogbo àwọn agbolé náà parapọ̀ sábẹ́ àkóso Akẹsìn tó jẹ́ ọmọ Alápà-merì láti Ilé Ọ̀rámifẹ̀ ní Ilé-Ifẹ̀. Orúkọ ibi tí àwọn ọmọ Alápà ti ṣí wá sí Ọ̀ra-Ìgbómìnà náà ni wọ́n fi sọ ìlú Ọ̀ra títí di Òní-Ọ̀ra Oríjà ni wọ́n ti ṣí wá, wọ́n sì sọ íbi tí wọn dó sí ní Ọ̀ra. (Èdè Ìgbómìnà tí wọ́n ń sọ ni wọ́n ṣe ń pe ìlú wọn ní Ọra-Ìgbómìnà). 
	
Àkókò ogun jíjà ni àkókò náà, gbogbo wọn sì máa ń pa ra pọ̀ jagún ni Àwọn-jagunjagun pọ̀ nínú wọn. Jagúnjagun gan-an sì ni Akẹsin tó jẹ́ olórí wọn. Àwọn méjì nínú àwọn olórí ogun wọn ni Eésinkin Ajagun-má-rùkú àti Eníkọ̀tún tí wọ́n pe àpèjà rẹ̀ ní Lámọdi. Eésinkin Ajagun-má-rùkú ló wa yàrà yí gbogbo ìlú Ọ̀ra po. Eníkọ̀tún Lámọdi ló lé ogun Èkìtì-Parapọ̀ títí dé òdò kan tí wọn ń pè ní Àrìgbárá. Àwọn tí ọwọ rẹ̀ sì tẹ̀, wọ́n mọ wọ́n mọ́ odi láàyè ni ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ki àwọn ọmọ Òkè-Òpó ní oríkì- 
		

		
Ọmọ Lámọdi 
		
Ọmọ Àyánwọ́nyanwọ̀n
		

		
Ọmọ Àràpo ni ti 
		
ìbẹ̀tẹ́ 
		
Ọ́mọ́ Álẹ́kàn d’Arìghárá
		
Ọmọ Alégun dé Sanmọr 
		
Baba yín ló pè èjì 
		
Ẹ̀kàn Lọ́jọ́ Ọjọ́ra Kọ́la.” 
	
Lẹ́hìn ogun ìyápọ̀ àti ogun ògbórí-ẹfọ̀n, àwọn aládùúgbò wọn kan  tó ti wà ní Kèságbé lábẹ́ àkóso ọba wọn Aṣáọ̀ni bá Akẹsìn sọ ọ́ kí ó lè fún òun nílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (Akẹsìn) kí wọn lè jọ máa parapọ̀ jagun bí ogun bá tún dé. Akẹsìn bá àwọn ìjòyè rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì gbà. Wọ́n fún Aṣáọ̀ni àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ilẹ̀ ní Ọ̀ra. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà tí lọ, obìnrin kan tó ṣe àtakò pé kí wọn má fún àwọn ọmọ Aṣáọ̀ni tí wọ́n ń pe ní Òkèèwù láàyè, wọ́n dá a dọ̀ọ̀bálẹ̀ wọ́n sì tẹ́ ẹ́ pa lẹ́ẹ̀kẹsẹ̀. Báyìí ni ọba ṣe di méjì ní ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà. Ṣùgbọ́n wọ́n jọ ní àdéhùn, wọ́n sì gbà pé Akẹsìn ló nilẹ̀. Ìyáàfin Bojúwoyè (Òkè-Òpó) ẹni àádọ́rin ọdún àti ìyáàgba Dégbénlé (Ìjásíọ̀) ẹni àádọ́rùnún ọdún ó lé mẹ́fà tí wọ́n sọ itàn yìí fún mi kò ta ko ara wọn rárá, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àkókò kan náà ni mo ṣe ìwádìí ìtàn lẹ́nu àwọn méjèèjì. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Ìran Lámọdi ọmọ Òpómúléró tó wá láti ilé Alápínni ní Ọ̀yọ́ ilé ni ìyáàfin Bojúwoye ìran Enífọ́n sì ni ìyáàgbà Dégbénlé. Àwọn méjèèjì ló wà láyé ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. 
	
Ìtàn kejì tí mo gbà sílẹ̀ lẹnu ìyá àgbà Adégbénlé (Iyá-Ìlá) ti ìjásíọ̀ sọ fún wa pé ìlú méjì ló parapọ̀ di Ọ̀ra bí a ti mọ̀ ọ́n lónìí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, ìlú Ọ̀ra ti wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ogun ‘iyápọ̀’ ati ogun ‘Èkìtìparapọ̀’ tó dé. Ìlú kan sí wà létí Ọ̀ra tó ń jẹ́ Òkèwù. Àwọn ìlú méjèèjì yí pààlà ni. Igi ìrókò méjì ló dúró bí ààlà ìlú méjèèjì. Igi ìrokò kan ń bẹ ní ìgberí Ọ̀ra, ìyẹn ni wọ́n ń pè ní ìrókò  Agóló, ọ̀kan sì ń bẹ ní ìgberí Òkẹ̀wù, ìyẹn ni wọn ń pè ní irókò Mọ́jápa (Èmi pàápàá gbọ́njú mọ igi ìrókò mejèèjì;  ìrókò mọ́jápa nìkan ni wọ́n ti gé ní àkókò tí mo ń kọ̀wé yìí;  ìrókò Agólò sì wà níbẹ̀) Nítorí àwọn igi ìrókò méjèèjì tó1 Ọ́ra àti òkèwù láàárín yìí, àwọn òkèwù tí ìlú tiwọn ń jẹ́ Kò-sá-gbé’ máa ń ki ara wọn ní oríkì-orílẹ̀ báyìí:
		

		Ọmọ ìrókò kan gàǹgà tí ń bẹ nígberí Òkèwù

		Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣè ‘ọn Ọ̀ra 

		Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Òkèwù 

		Wọn è ẹ́ jóhun ún ṣe ‘ọn Àtẹ́-ńlẹ́-ọdẹ́ 

		Ọmọ Ọ́dẹ́-mojì, ma a sin’mọ gágá relé  ọkọ 

		Àpè-joògùn má bì l’Okèwù”. 

	
Ìtàn kẹta jẹ́ èyí tí baba mí gan-an sọ fún mi kí títán tó dé sí i ní dún 1966. Ẹni ọgọ́fa ọdún ni baba mi Olóyè Fabiyi Àyàndá Òpó, mọjàlekan, Aláànì Akẹsìn, nígbà tó tẹ́rí gbaṣọ. Bába mi fi yé mi pé àwọn ojúlé tí wa ní Ọ̀ra nígbà òun gbọ́njú ni Ìperin, Ìjásíọ̀, Òkè-Òpọ́, Òkèágbalá, ilé atè, Odò àbàtà, Òkè-akànangi, Okèkàngá, Òkèọ́jà, odìda, odòò mìjá, Òkèwugbó, Ilé Ásánlú, ilé Akòoyi, ilé sansanran, odònóíṣà ilé ọba-jòkò, ilé Eésinkin-Ọ̀ra ilé ìyá Ọ̀ra, ilẹ́ ọ̀dogun, ilé ọ̀gbara, ilé Olúpo, kereèjà, àti ilé Jégbádò . Gbogbo  àwọn ojúlé wọ̀nyí ló wà lábẹ́ àkóso ọba Akẹsìn ṣùgbọ́n àwọn ìwàrẹ̀fà àti àwọn Ẹtalà2 ló ń pàṣẹ ìlú. Ìdí  nìyẹn tí wọn ṣe máa ń we pé –
		

Akẹsìn kàn jẹ́ ọba Ọ̀ra ni ohun tí àwọn ògbóni tó wà nínú ìgbìmọ̀ - Ìwàrẹ̀fa àti Ẹ̀tàlá bá fi ọ́wọ́ sí ni òun  náà yóò fi ọwọ́ sí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, àwọn ojúlé wọ̀nyí ni àwọn tí kò parun bí ogun ti dààmú ìlú Ọ̀ra tó. Baba mi tún sọ síwájú sí i pé Òrùlé tó ń bẹ ní Ọ̀ra nígba tí òun gbonjú kò ju ọgbọ̀n lọ, àti pé ṣe ni wọn fa àgbàlá láti Òkè-Òpó dé Òkèkàngá. Bí eégún bá sì jáde ní Òkèòpó, títí yóò fi dé Òkèkàngá ẹnì kan kan lè má rí i bí kò bá fẹ́ kí ènìyàn rí òun. Baba mi wá ṣàlayé pé Aláfà baba ti òun pa á nítàn pé àwọn Okèwù tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ Ọ̀ra, Ọ̀ra sì fún wọn láàyè lórí ìlẹ̀ àwọn ìjásíọ̀ àti Òkè Akànangi. Nígbà tí ibi tí a fún wọ́n kò gba wọ́n, wọ́n tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí Aláfa ní Òkè-Òpó. 
	
Nígbà tí awọ́n Òkèwú wá jòkó pẹ̀sẹ̀ tán, àwọn ọmọ íyá wọn tó wà ní Òró àti Agbọnda wá ṣí bá wọ́n. Oníṣòwò ni àwọn tó wá láti Òró wọ̀nyí. Iṣu ànamọ́ li wọn máa ń rù wá sí Ọ̀ra fún tità. Ọ̀nà Àránọ̀rin ni wọ́n máa ń gbà wọ ìlú. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, obìnrin kan tí ara rẹ̀ kò dá máa ń jòkó ní abẹ́ igi kan ní ẹ̀bá ọ̀nà. Ibi tí igi náà wà nígbà náà ni a ń pè ní Arárọ̀mí lónìí. Baba mi so pàtó pé òun mọ obìnrin tí a ń wí yìí àti pé Àdidì ni wọ́n ń pè é. Ìgbà-kìgbà tí àwọn oníṣòwò wọ̀nyí bá ti ń ru iṣu ànàmọ́ ti Ọ̀ró bọ̀, tí wọn bá sì ti dé ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn a sọ ẹrù wọn kalẹ̀, wọn sì sinmi tẹ́rùn. Kí wọn tó kúrò ní ọ̀dọ̀ Àdìdì, wọn á ju iṣu ànàmọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Báyìí ni àwọn Òkèwù bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i ní Ọ̀ra-Ìgbómínà. Nígbà tó yá, Arójọ̀yójè tó jẹ Aṣáọ̀ni (Ọba ti àwọn okèwú) nígbà náà tọrọ ilẹ̀ díẹ̀ sí i lọ́wọ́ Aláfà òkè-òkó (baba mi àgbà) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́, Aláfà fún un ní ilẹ̀ nítorí àwọn Òke-òpó ní ilẹ̀ ilé púpọ̀. Ilẹ̀ oko nikan ni wọn kò ní ní ọ̀nà. 
	
Ní ibi tí Aláfà yọ̀ọ̀da fún Arójòjoyè yìí, akọ-iṣu àtí tábà ni àwọn Òkè-òpó ti máa ń gbìn síbẹ̀ rí. Ibẹ̀ náà ni olọ́ọ̀gbẹ́ Ìgè kọ́ ilẹ́ rẹ̀ sí. Ilẹ́ náà wà níbẹ̀ ní àkókò tí mo ń kọ ìwé yìí. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Òkèwù tó rí ààyè kólé sí ṣe ń ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ìyá wọn tó wà ní ẹkùn Òrò àti Agbọndà nìyẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló tún wá láti Èsìẹ́, Ílúdùn, Ìpetu (Kwara), Rorẹ́ àti Òmu-àrán. 
	
Báyìí, àwọn ìtàn mìíràn tí àwọn baba ńlá wa kò pa rí ti ń dìde. Nígba tí ọ̀rọ̀ adé gbé ìjà sílẹ̀ ní Ọ̀ra-Ìgbómìnà láìpẹ́ yìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wádìí ìtàn Ọ̀ra. Àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ náa wà nínú ìwé ìkéde Gómìná ìpinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olóyè Bọ́lá Ìge tí ní orí ẹrọ asọ̀rọ mágbesí nínú oṣu kẹwàá ọdún 1980 a tún gbọ́ nínú ìkẹ́de yẹn ni pé Òkèwù ló tẹ ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà dó àti pé àwọn ló sọ orúkọ ìlú náà ní Ọ̀ra (A ó ra tán) Ohun tó da àwa lójú ni pẹ́ ìlú méjì ló papọ̀ tí wọn so Ọ̀ra-Ìgbómìnà ró báyìí. Ìlú ọba Aládé sì ni ìlú méjèèjì Ọ̀ra àti Òkèwù. 

D. ÀWỌN ÈNÌYÀN ÌLÚ Ọ̀RA, IṢẸ́ OÚNJẸ ÀTI ÈDÈ WỌN 
	
Ẹ̀yà Yorùbá kan náà ni gbogbo àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀ra-Ìgbómìnà àti Òkèwù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀kan náà ni wọ́n ní òórọ̀ ọjọ́ bí a ti sọ ṣáájú. Àwọn ará Ọ̀yọ́ wà ní Ọ̀ra, àwọn árá Ilé-Ifẹ̀ sì wà ní Ọ̀ra pẹ̀lú. Àwọn kan tán sí Èkìtì, àwọn mìíràn si tan sí ìpínlẹ̀ Kwárà. Àwọn tó ti ilẹ̀ Tápà wá ń bẹ ní Ọ̀ra, àwọn tó ti Kàbbà wá sì ń bẹ níbẹ̀ báyìí- àwọn ni ọmọ, Olújùmú. Àwọn Hausá pàápàá wà ní ìlú Ọ̀ra báyìí, ṣùgbọ́n èdè Ìgbómìnà ni èdè tí ó gbégbá oróke láàrin wọn. 
	
Iṣẹ́ àgbẹ̀ aroko-jẹun ni iṣẹ Ọ̀ra láti ilẹ̀ wà. Wọ́n ń gbin iṣu, àgbado, àti ẹ̀gẹ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọ́n fi ń ṣowó ni tábà ọ̀pẹ, áko, erèé òwú, obì àbàtà àti ìgbá tí wọ́n fi ń ṣe ìyere fún irú tí wọ́n fi ń ṣe ọbẹ̀.




#Article 42: Ìjẹ̀bú-Òde (1712 words)


Ijebu-Ode je ilu to gbajumo nile Yoruba ni ipinle Ogun lapa iwo-oorun orile-ede Naijiria.. Oba Awujale ni oruko Oba alade ti won fi n joba ni Ijebu-ode. Oba Sikiru Kayode Adetona ni o wa lori ite lowo ni ilu Ijebu-ode.

Orísìírísìí ni ìtàn tí à ń gbó nípa ìsèdá ìjèbú Òde. Sùgbón èyí tí ó wó pò jù nínú àwon ìtàn náà ni mo ménu bà yìí;

Aládùígbò ni Odùduwà àti Alárè jé ni apá ilè Lárúbáwá. Odùduwà ni a gbó pé ó kókó sí kúrò ní agbègbè náà wá sí Ilé-Ifẹ̀. Léhìn rè ni Alárè kúrò ní ilè Wàdáì; tí ó gba asálè Núbíà dé Ilé-Ifè, tí ó sì se “e-nlé-ń bèun o” fún Odùdùwà. Alárè fi omobìnrin rè kan Gbórowó, fún Odùduwà láti fi se aya. Léhìn èyí, ó gba ònà Ìseri dé Ìbesè, títí ó fi dúró ní Ìjèbú-Òde. Ajèbú àti Olóde jé lára àwon àtèlé Alárè. Fún isé ribiribi won fún ìlú ni a se so Ibùdó náà lórúko won - Ajèbú-Olóde. Àpèjá orúko yìí ni ó di Ìjèbú-Òde lónìí yìí.

Léhìn Alárè ni Lúwà (OLÙ-ÌWÀ) náà dé láti asálè Núbíà. Òun náà gba ònà Ilé-Ifè, ó sì yà kí Odùduwà. Lúwà àti Àlárẹ̀ bí ọmọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Osi ni ọmọ Lúwà; Eginrin sì ni ọmọ Alárẹ̀. Ní àsìkò yìí. Ọṣìn tàbí Ọlọ́jà ni à ń pe Olórí Ìjẹ̀bú-Òde.

Èdè àìyédè bẹ́ sílẹ̀ láàárín Alárẹ̀ àti Lúwà lórí, i ẹni tí yóò jẹ ọlọ́jà. Nígbà tí wọ́n tọ Ìfá lọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó fí yé wọn pé ẹni tí yóò jẹ olórí kòì tíì dè!.

Kò pẹ́ kò jìnnà, lẹ́hìn ikú Alárẹ̀ àti Lúwà, ni àjèjì kan tí o múrá pàpà-rẹrẹ wọ̀lú. Ọ̀nà Oǹdó ni àjèji yíí gbà wọ ìlú. Kò pẹ́, ìròhìn ti tàn ká pé àjìji kán fẹ́ gbọ́gun wọ̀lú. Èyí ni ó mú Apèbí (Olóyè pàtàkì kan ní ibùdó yìí) lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì lọ báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótọ́. Àjèjì yìí kò fèsì ju pé “Ìjà dà?. láti fi hàn pé òun kò bá ogun wá. Àjèjì náà fi yé wọ́n pé Ògbòrògánńdá-Ajogun ni orúkọ òun. Ó jẹ́ ọmọ Gbórówó tí í ṣe ọmọbìnrin Alárẹ̀ tí ó fún Odùduwà fẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀, Ipasẹ̀ àwọn ẹbí ìyáa rẹ̀ ni Ògbòrògánńdà tọ̀ wá, lẹ́hìn ikú bàbá rẹ̀. Títí di òní, àdúgbò tí Apèbí tí pàdé Ògbòrògánńdà ni à ń pè ní ÌJÀDÀ.

Àpàbí lọ fi tó olóyè àgbà Jaginrìn tí ó rán an níṣẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀rọ̀ ni àjèjì náà mú wá. Nígbà tí Jaginrìn bi Apèbí ibi tí àjèjì náà wà, Apèbí dáhùn pé “Ọba-ńníta” (Ọba wà ní ìta) nítorí ipò Ọ́ba ni ó rí i pé ó yẹ ẹni pàtàkì bí i tí Ògbòrògbánnńdà-Ajogun. Láti ìgbà yìí ni a tí mọ Ògbòrògánńdà ní Ọbańníta, tí àjápè rẹ̀ di Ọbańta di òní. Agbègbè tí Ọníṣeémù ti lẹ́ ọ̀sà lọ tí a fún Ògbòrògánńdà láti máa gbé ni ó júwe pé” ó tóó ró”- (Ibí yìí) tó láti dúró sí) ni à ń pè ní Ìtóòró di òní. Àdúgbò yìí ni a ṣe ọ̀wọ́n kan sí ní ìrántí Ọbańta, nítorí a kò mọ bí ó ṣe kú. Inú igbó kan ni tòsí Orù-Àwà ni a gbọ́ pé ó rá sí.

Ògbórògbánńdá Ajogun (Ọbańta) gbé Winniadé, ọmọ Osi níyàwó. Ósi yìí, bí a ti mọ̀ ṣáájú jẹ́ ọmọ Lúwà. Ọbáńta sì jẹ́ ọmọ-ọmọ Alárẹ̀. Wọ́n bí ọmọkùnrin kan tí ó ń jẹ Mọnigbùwà. Síbẹ̀ aáwọ́ tí ó wà láàárín Lúwà àti Alárẹ̀ nípa óyè jíjẹ kò í tán láàárín àwọ́n ẹbí méjèèjì.

Láti fi òpin sí aáwọ̀ yìí, àwọn ará ìlú ní kí Monigbùwà, ọmọ Ọbańta, jáde rẹ̀ ti ṣe ní ọjọ́ kìíní. ‘Mọnigbùwà gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lọ sí ìletò kan tí a mọ̀ sí Òdo, láti ibẹ̀ ní ó sì ti padà wọ ìlú pẹ̀lú ìfọn àti orin. Ọjọ́ yìí ni a gbé adé fún Mọnígbùwà. Oùn ni ó jẹ́ ẹni àkókó ti ó jẹ oyè Awùjalẹ̀ - ‘A-mu-ìjà-ilẹ̀’-èyí ni ẹni tí ó parí ìjá tí ó bá nílẹ̀. Àpápè oyè yìí ni ó di Awùjalẹ̀ dòní yìí. Títí di òní yìí ni ẹnikẹ́ni tí a bá yàn gẹ́gẹ́ bí ọba tuntun gbọ́dọ̀ jáde ní ìlú lọ sí Òdo, kí ó sì wọ ìlú padà gẹ́gẹ́ bí i Mọnigbùwà àti Ọbańta kí ó tó ó gbadé.

Lára àwọn olóyè pàtàkì-pàtàkì ní Ìjẹ̀bú-Òde ni Olísà Ẹgbọ̀, Àgbọ̀n, Kakaǹfò, Jaginrìn àti Lápòẹkùn, tí wọ́n jẹ́ óyè ìdílé. Àwọn oyè bí i Ọ̀gbẹ́ni Ọjà kìí ṣe oyè ìdílé.
Àwùjalẹ̀ kọkànléláàádọ́ta ni a gbọ́ pé ó wà lórí oyè báyìí.

Àwọn Ìjẹ̀bú fẹ́ràn láti máa jẹ kókò àti ọ̀jọ̀jọ̀. Wọ́n tún fẹ́ràn lati máa fi ògìrì sí obẹ̀ àti oúnjẹ wọn mìíràn bíi ikọ́kọrẹ́ láti fún un ní adùn àjẹpọ́nmulá.

Ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ni àwọn ènìyàn Ijẹ̀bú Òde ní ìgbà láíláí. Wọ́n máa ń bọ oríṣìíriṣìí òrìṣà tí a ń bọ ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bí i Ògún, Ifá, Èsù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òrìṣà ìbílẹ̀ bíi Agẹmọ, Òrò, àti Obìnrin-Òjòwú wà pẹ̀lú. Lọ́de oní àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ̀nyí kò ranlẹ̀ bíi ti àtijọ́, síbẹ̀ a ṣì ń bọ wọ́n lójú méjèèjì. Ẹ̀sìn Mùsùlùnì ni ọ̀pọ̀ àwọn ará Ìjẹ̀bú-Òde ń ṣe báyìí. Mọṣáláṣí kan wà ní àdúgbò Òyìngbò tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú mọ́ṣáláṣí tí ó tóbi jù ni apá ìwọ́ oòrùn Afríka.

Àwọn ẹlẹ́sìn àtẹ̀lé Krístì Lóríṣìíríṣìí kò gbẹ́hìn. Àwọn náà pọ̀ ní iba tiwọn. Àwọn ìjọ Àgùdà tilẹ̀ fi Ìjẹ̀bú Òde ṣe ibùjúkóó fún dáyósíìsì ti ẹkùn Ìjẹ̀bú.

	Ìtùmò: 	   Àdúgbò yìí ni àwon ìjòyè Oba ìlú yìí tí a ń pè ni olówá tè dí, ti won si ń se ìjoba lórí àwon ènìyàn tó wà ládùgbó yìí 

	Ìtùmò: 		 Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà alá wà tétètélè, Àwon àwòrò òrìsà yìí ni ó te àdúgbò yìí dó. 

	Ìtùmò: 		Igi obì púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí bá nígbà ti wón fé te ìbè dó.

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà òsù wa. ni tori pe ibí yìí ni wón ti ń bo òrìsà yìí ni wón se ń pe e ni ìta òsù. 

	Ìtùmò: 		Igi òpe púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí ban i ibi yìí nígbà tí wón fé te ibè dó

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni òkan lára àwon akoni ode to máa ń ye ojó ogun ti awon olóde yòókù bá ti dá síwájú tè dó ìdí niyìí tí won fi ń pe àdúgbò yìí ni Ayegun. 

	Ìtùmò: 		Awon ounje orisirisi tí a dì sínú àpò bii àgbàdo, ìyo, ni àwon ara àgbègbè máà ń gbé wá si àdúgbò yìí wá lati tà kí ó tó di àdúgbò. Wón si máà ń na ojà ni àdúgbò yìí títí di òní yìí . 

	Ìtùmò: 		Isé ìkokò mímo ni isé àwon to té àdúgbò yìí dó. Díè lára àwon omo omo won si ń se ìsé yìí 

	Ìtùmò: 		Àdúgbò yìí ni àwon Olósùgbó ti máà ń se ìpàdé. Níbè ni ilé ìpàdé wón wa, kí ó tó di pé won te ibè dó. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni ójúbo osi esi wà télètélè kí o to di pé won te ibè do tí o si dí àdúgbò ojúbo osi yìí si wa níbè títí dònìí. 

	Ìtùmò: 		Àwon Opó ni won máà ń na ojà yìí ni alaalé. Òríta ti wón ń náà yìí ni o di adúgbò, ti wón si ń pe ni ìtà opó. Wón si máà ń ná ojà alé ni àdúgbò yìí títí dònìí 

	Ìtùmò: 		Okunrin kan tó mú opà dání ló te apá ibí yìí dó. Ìtàn so fún wa pé àpá ase Oba ìlú ibòmíìràn ló mu dàni nígbà tí o ń bo, àwon kan tilè so pé Àremo oba ìlú náà ni. Nígbà tí o, fé te àdúgbò náà do ó mú òpá yìí dá ni, Ìdí niyìí tó fi je pé won ń je oba ni àdúgbò náà títí di òní yìí 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé omi nigbogbo àdúgbò yìí teletélè kí ó to dí pe wón te ibè do. Okunrin akoni ti a ń pè ni òró ni o pé ofò tí ó sì le omi náà lo. Ìdí nìyìí ti a fi ń pé àdúgbò náà ni Ìtóòró. 

	Ìtùmò: 		Ibí yìí ni òkan lára àwon akoni tó te ìlú yii dó kokó dúró si kó tó dip é ó wo àárin ìlú lo. Nígbà ti ijà dé láàrin òun àti àwon tí wón fo wo ìlú yìí, o bínú pàdà si ibi yìí o si wolè. Ìdí niyìí tí wón fi ń pe àdúgbò naa ni Olóde. Oórì okùnrin yìí si wà níbè títí dòníì. 

	Ìtùmò: 		Eégún kan ti won ń pè ni obrinrin ojòwú ní o te ibí yìí dó. Èégún Odoodún ni eégún máà ń jáde ni àdúgbò yìí títí donii. Ìdí igi ìrókò ni won fi se ojúbo eégún yìí Igi ìrókò yii wà níbè títí dónì yìí. 

	Ìtùmò:     	Isé epo ni àwon to te àdúgbò yìí yàn láàyò léyìn tí wón ti dó síbè. Bí o tilè jé pé won kò se ise epó níbè mó, won si ń ná ojà epo níbè titi dò níí. 

	Ìtùmò: 		Lára àwon ìjòyè oba Gbélébùwà àkókó tí won kò fara mo on pé kí wón pa Oba náà ni won wa te àdúgbò yìí dó léyìn ti wón kúrò ni ààfún. 

	Ìtùmò: 		Oríta yìí ni àwon ìjoyè Oba Gbétebùwá àkókó péjo sí láti bi ara won ohun ti o ye kí àwon se fún oba náà. 

	Ìtùmò: 		Ìtàn so gún wa pé nígbà tí wín fe te ibí yìí dó, wón bá òrìsà kan níbè tó dé adé sórí tó sì fi èwòn onírin se ileke owó àti tí esè. Ìdí ni yìí ti à fi máà ń yan Oba láti ìdílé enití ó te àdúgbò náà dó. Ìdílè yìí náà tílè ni ààfún tí a ń pè ni ààfin Òba ìdéwon.

	Ìtùmò: 		Ìtàn so fún wa pé bí ó tilè jé pé èrúktí o té àdúgbò yìí do kii se àfín, sùgbón gbogbo àwon omo tí won bi láti ìdílè enití o te àdúgbò náà do je àfín. Nígbà ti won lo bi ifá wo, Ifá ni ki won máà bo Obàtálá ni ìdílé náà, láti ìgbà náà lo ni won ti ń bo Obàtálá ni ìdílè yìí. Ti o bad i àsìkò odún òrìsà yìí, àríyá ni fún gbogbo àwon omo àdúgbò yìí àti fún ìlú pàápàá.




#Article 43: Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): B (6594 words)


baboon: n; (Baboon is an animal.) ìnàkí Eranko ni ìnàkí

baby:n;  (The priest prayed for all babies.) omo owóÀlùfáà gbàdúrà fún gbogbo àwon omo owó

bachelor:n; 	(The bachelor refuses to get married.) àpón okùnrin, Àpónkùnrin náà kọ̀ láti fè ìyàwó 

back:n; (Turn its back to me.) èyìn 	Ko èyìn rè sí mi	 

back:v; (Don’t back mi)  ko èyìn sí; te lé Ma ko èyìn sí mi 

back: adv; (He paid the money back.)
padà o san owó náà padà 

backwards:adv; (They asked the Child to go backwards.) padàséyìn Wón ní kí omo náà pedàséyìn

background:n; (He gave the picture he drew a very good background.)  pile Ó fún àwòran tó yà ní ìpìle tó dára. 

bacon:n; (Bacon is sweet with salt.)
eran èyìn elédè Eran èyin elédè dùn pèlu iyò 

bacteria:n; (Bacteria causes deseases.) kokoro tàbí ògbìn kékere tí a le fi èro wò. Kòkò máa n fa àrùn

bad:adj; (The man is too bad.) burú Okùnrin náa buru jù 

badge: (There is a badge on Tunde’s shirt.) Ami asafihan, ìdánimò	Àmi idánimò wà lára ewù Tuned 

badminton: n; (Ade likes playing badminton.) Ere ìdáraya oní-bóòlù kékere àfigi gbé Ade féràn láti maa gbá bóòlù kékeré àláfígigbá. 

baggage: (Adé took care of his baggage 
when he wanted to travel.) Àpò erù fùn ìrìn-àjò-orisìí erù ni a kó sínú àpò náà. Adé tójú àpò erù rè dáadáa nígbà tí o fé rin ìrìn-àjò 
bait:n;  (The bait fixed into the hook was too small for the fishes to see) ìje Ije enu ìwo náà kéré fún eja láti rí

bake: v; (He baked bread.) yan Ó yan búrédi

baker:n;  (The bake baked many loaves of bread.) olùyan Olùyan náà yan òpòlopo búrédì 

bakery: n; (He has a bread bakery.)
 ilé isé ìyan-nnkan Ó ní ilé ise ìyanbúrèdì

balance:v; (The farmer weighug sale to balance the weigh of his cocoa bags equally.) wòn lógboogba Agbè náà fì ìwon won àwon kòkó rè loogboogba

balance:n;  (They have bought a new 
weighinh scale.) ìwon-èro tí a fi n won nnkan 	Won ti rà ero ìwòn tuntun 

badge:n;  (He sewed the badge with his 
shirt.) àmi O rán ami náàmó èwu re 

balcony:n; (I met him at the balcony.) òdèdè tí ó lókè ni ilé ètéèsì. Ní òdèdè tí ó wà ní òke pètésì ni mo ti bá a .

bald:adj; (The old man is bald headed.) pípárí Okùnrin agbàlagbè náà ti di apárí 

bale:n; (He went to the bank with bales of money.) ìdì O kó awon ìdì owó náà lo sí ilé ìfowó pamosí 

bale:v; (The waste papers are bailed) dì Won dì àwon ìwé tí kò wùlò pò 

ball:n; (He knows how to play footaball.) bóòlù; ohunkóhun tí a sù róbóbó	Ó mò nípa bóòlù aláfesègbá 

ballet:n; (I have never taken part in ballet.) ere-orúse oníyó tí kò lórò síso Nínú N kò bá won kópa nínú eré-onise oníjó tí ko lórò síso nínú rí.

balloon:n; (The Children love to play with balloos.)apo róbà tí a fé atégùn sí Awon omodé náa féràn láti máa fí apo roba tí a fé ategun sínú rè. Sere
ballpoint:n; (The ballpoint has spoilt.)
 kálámù ìkòwé onírin rógódó lénu kálámù ìkòwé onírin rógódó lénu náa ti bàjé

bamboo:n; (The house was built with 
Bamboo). oparun Oparun ni wón fi kó ilé náa 

ban:v;  (We shall ban smoking in the 
school) fi òfin dè A ó fi òfin de sìgá mimu nílé iwé 

ban: n; (There is a ban on fighting in the school.) ìfòfindè Ìfòfindè wà lórí ìjà jíjà nile ìwé

banana:n; (Banana is common in Ile-Ifè) ògèdè 
were Ògèdè were wópò ni Ile-Ifè 
	
band:n; (He uses bands to tie it well.) ìde; ìso Ó fi iso/ide  dì í dáadáa 

bandage:n; (He used bandages to tie up his wound.) ìrèpé aso tí awon orísègun fí n di ojú ogbé máa n di ojú ogbè di egbò rè 

bandage:v; (He bandaged his wound tightly.) dì-di ojú egbò O di ojú ogbé rè dan-in-dan-in

bandit:n; (The man is a complete bandit)  olósà Olóbà gbáà ni okùnrin náà

bang:n;  (He always shuts the door with a bang.) àriwo òjijì N se ni o máa n tilekun pèlú ariwo òjiji. 

bang:v;  (Please don’t bang the door when you go out) ti gbà fi pariwo òjiji Máse fi ilèkùn ijéun pariwo tó o bá jade

bangle: n;  (A goldsmith manufactured this bangle).ègbà owó Alágbède to ro ègbà owó yìí 

banish: v; (The king banished him) lé kírò ní ile, gbè kuro (lókàn) Oba náà lé e kuro ní ìlú O gbé ìwàkuwà oko rè kúrò lókàn rè. 

bank: n;  (She banished herself from her husband's mis-behaviour). (He is the manage of the bank) ilé ìfowópamósí; bèbè odò Oun ni olorí ilé ìfowopamósí náà O dúró sí bèbè odò 

baptise:v;  (He stood at the bank of a river.) (John the Baptist baptized Jesus Christ.) rì bo oni-sàmi sí gégé bí ùàmà kìrìsìteenì. Jòhánù onítèbomi ló se ìrìbomi fún Jésù kirisiti. 

bar:n; (He was called to the bar.)
irin tàbí igi gbooro; iyanrì tí n dí nu odò, ibi tí tóón tí n dúró rojó ní kootu, egbé àwon agbejórò Wón pèé sínú egbé àwon agbejó rò 

bar:v; (Poverty bars the way to progress.) dénà Ìsé ló máa n dínà ìlosíwájú 	

barbed wire: n; (He fenced his house with barbed wire).
 irin tín-ún-tún-ún-rún tí a hun lónà tí nnkan kò lè koja nínú re. O fi ìrìn tín-ún-rún tún-ún-rún tí a hun pò se gbà jí ile rè ká 

barber: n; (The man is a barber.)
 onígbàjámò Onígbàjámo ni okùnrin náà 

bargain: v; (He bargained with girl over the price that he would sell it for.) dúnàá- dúrà; ná- se àdéhùn oje to fé san tabí fé rà á; sàdéhun O sàdéhùn pelu omobìnrin náà; oye tó fé ta á 

bark: v; (He barked like a dog.) gbó O gbó bí ajá 	 

barrack:n; (The government has built many barracks for our soldiers.) ibùgbé awon ológun tàbi àwon agbófuiró.Àwon ìjoba tí ko òpòlopo àwon ibùgbé fún àwon ológun wa 

barrel:n; (The barrel of water is at the back of the house.) agbá Agbá omi náà léhìnkìnlé 

barren: adj;  (The woman was barren for three years.)yàgàn, se aláìléso Obinrin náà yagan fun odún méta	

barrier: n;  (There are barriers on that road.) ìdína; ìdènà Ìdínà wà ní ojú ònà yen

barrow: (He put the loads in the wheel 
barrow.) kèkè erù èwù omo owó; ojú orórì òkú. O kó awon erù náà sínú kèké erù
barter:n;  (Our forefathers used to trade by barter system.)pàsípàro; ìpààrò. Pàsípààrò ni àwon bàbá nla wa máa ni se láyé àtojo 	

barter:v; (He bartered his clothes for shoes.) pààrò, se pàsípààrò. Ó fi aso rè pààrò fún bàta 	
base:n;  (The base of the pit is very dark.) ìsàlé, ìpìlè, ìjokòó Ìpìle kòtò náà sókùnkùn gidi 	 

Basis: n;  (What is the basis for your 
opinion?) pàtó Kí ni pàtó èrò okàn re? 

basket: n; (He filled the basket with fruits). apèrè àgbòn 	Ó fí èso kún inú apèrè náa 

baskeball: n;  (The child is playing basketball.) bóòlu alápèrè Omo náa n gbá bóòlu alápèrè 

bat: n; (He killed two bats yesterday.) (He bough a pair of new bats) àdán, òòbè Ó pa adan méjì lánàá Pákó pèlèbe tí a fi n gbá eyin orí tábílè. Ó ra pákó pèkó pelebe tuntun méjì tí a fi n gbá eyin orí tábieì 

batch: (He has completed the first batch.) owó kan, àpapò nnkan Ó ti pari òwó àkókó

bathe:  (We often bathe in the river on 
hot days.) wè: lúwèé A máa n sábàa wè nínú odò naa nìgbà oru

bathroom: n; (The students built a bathroom in their school.) balùwè; ibi ìwe-ibì ti a n wè sí Awon akekòó náà kó balùwè ní ilé-ìwé won 

battery: n;  (He bought a new battery to his car.) ohun ìjà ogun, àpótí ìnúnáwa. Ó ra apótí ìmúnáwa túntun sí mótò ayókélé rè

battle: n;  (They have stopped the battle). ìjà, ogun Wón ti dá ijà náà dúró 

battle: v;  (He battle with cancer for three years).bá jà; jagun Ó bá aisan jejere jagun fún Odún méta 

be: v;  (You don’t know what you will be tomorrow.) jé; dà’dì O kò mo ohun tí o le jé lóla
beach: n; (I will go to the beach tomorrow.) etí òkun; èbá òkun N ó lo sí etí òkun lóla 

bead: (She has bought new set of  beads.) ìlèkè Ó ti ra àwon ìlèke tuntun 

beak: n;  (He cut away the beak of the bird.) enu eye; agógó eye	Ó gé enu eye náà dànú 	 

bear: n; (Bear is not common in Africa.) bíárì-irufé erànko nlá kan tí ó n gbé ilè ótútù. bíárì ko wópò ní Ile Adúláw’`

bear: v; (Who is bearing John?) (He bears it all)  jé orúk, fara dà Ta lo n jé Jòhánù Ó fara dà a gbogbo rè 

beard: n; (The man shaved his beard.)
 irùngbòn  Okùnrìn náa fá irùngbòn rè 

beast: n; (The beast has devoured my goat.) eranko búburú  Eranko búburú ti pa ewúré mi je

beat: v; (The teacher beat the child.) lù Olùkó lu omo náà

beautiful: adj; (The lady is beautiful) tí o rewa; tí o dara Omobìnrin náà rewà

beauty: n; (She has lost her beauty.) ewà, òsó, dídára Ó ti so ewà rè nù 

beckon: v; (The beckoned to me to come.)   juwó sí; se àpeere sí Wón juwó sí mi kí n wá 

become: (I want to become a lawyer.)dì Mo fé di agbejórò 

because: conj; (I bought the book because of the child.) nítorí; tori tí Mo ra ìwè náà nítori omo náà	

bed: n; ibùsùn (We have many beds in our house.) (The machine rests on a bed of concrete.) A ní ibùsùn púpò nínú ilé wa Odò; isale Èro náà sùn lé ìsàlè kannkéré náà

bed: v; (He bedded the bricks in concrete.) so pò dáindáin; to pò rémúrémú 	ó to àwon bíríkì náà pò rémúrémú pèlú kannkéré 	

beef: n; (He bought beef for me.) eran màálù      Ó ra eran màálù fún mi 

beetle:  (The beetle is dead.)olóbòn-ùn-bon-un Olóbon-ùn-bon-ùn náà ti kú.

before: adv; (I came before him.) saájú Mo dé saájú rè

beg: v; (He begged them.)  sagbe: toro: bèbè Ó bè wón. 	 

begin: v;  (We shall begin the work 
tomorrow.) bèrè A ó bere isé náà ní òla

bahalf: n;  (He collected the money on my behalf.) ìtìléyìn; ojú rere ìdúrónípò; nípò ó gba owo náà nípò mi 

behave: v;  (I want you to behave well.) hùwa, lò Mo fé kí o hùwa dáadáa 	 

behind: prep; (He stood behind the Child.) léyin Ó dúró léyìn omo náà 

belief: n; (It was my belief that she went.) ìgbàgbó Ìgbàgbó mi nip é ó lo  

believe: v ; (I believe in God.) gbàgbó; ní ìdánilójú Mo gbàgbó nínú olórun. 	 

bell: n; (He rang the bell)  agogo tí a n lù Ó lú agogo náà.	 

bellow: v; (The man was bellowing like a cow.) ke bíì máàlu Okùnrin náà n ké b’’I màálù 	 

bellows: n;  (The goldsmith bought a new bellows.) ewìrìAlágbède náa ra ewìrì tuntun 

belly: n; (He stabbed the child in the belly.) ikùn Ó gún omo náà ní obè ní ikùn.	 

belong: v; (These books belong to me.) se tem; jé teni  Tí èmi ni àwon ìwé yìí 

beloved: adj; (I want there with my beloved 
wife.) olùfé; àyànfé.	Mo lo sí ibè pèlú olólùfé ayà mi. 

belt:n; (He has lost his belt.) láwàní; òjá àmùrè; ìgbànú; ìgbàjá. Ó ti so ìgbànú rè nù belt: v; (His dress was betted at the waist.) ìgbàja, so ìgbànú. Ó fi ìgbànú so aso to wò módìí dáadáa 

bench:n; (He sat on a bench.) (The attorney turned to address the bench.)ìjokòó Ó jókòó lórí ìjokòó kan Ìjókòó tàbí egbé àwon adájó ni lé ejó Adájó agbà náà yí padà láti bá ìjokòó /egbé àwon adájó náà sòrò. 

bend: v; (He bent the iron.) wó; tè Ó wó irin náà

bend: n; (He cut the bend from the tree.) ibi tí o wó, ibi tí o tè O gé ibi tí ó te lára igi náà 

beneath: prep; (The river is flowing beneath the Bridge.) nísàlè; lábè Oni náa n sàn lábè afárá	

benefit: n; (I have not seen any benefit in my coming here.) aìfààní; èrè N ko tíì rí àìfààní kankan nínú wìwá sí ibí mí 

beside: prep; (He stood beside me.) ní ègbé Ó dúró ní ègbé mi 

besides: pre/adv; (Basides working as a doctor, he also writes novels.) pèlúpèlú; yàtó fún. Yàtó fún síse isé ìsègun, Ó tún máa n ko ìtàn arobo 	

best: adj;  (This house is the best in our compound.) dara julo	Ile yìí ló dára julo ni adúgbò wa	

betrag: v; (The woman betrayed her husband.) sòfófó, fi han, tú asírí; Sekúpa Obìnrin náà tú asírí oko rè 

better:adj; (This one is better.) sàn; sàn ju; dára ju 	Eyí sàn jú 

between: prep; (There is a strife between them.) (He stood between us.)láàrin; lágbede méjì. Ìja wà láàrin won Ó duro lágbede méjì wa  

beverage:n;  (Give beverages to me.) ohun mí mu Fún mi ni ohun mímù	

beware:v; (Beware of bad friends.) sóra; year; kíyèsára Sóra fún àwon oré burúkú 

beyond: prep; (He stands beyond the house.) níwaju; ní ìkoja Ó dúro ní ìkojá ilé náà 	 

beyond: (He did it beyond my expectation.) kojá: jù Ó se é ju bí mo ti se fé lo	 

bicycle: n; (My mother bought me a bicycle.) kèké Íyá mi ra kèké fún mi lose tó koja last week. 

bible: n; (The child bought a new bible.) Bibeli –ìwe mímó onígbàgbó 	Omo náà ra Bíbélì tuntun 	

bid: v; (He bade me to come near.) (He bade us farewell.) fi àse fún; fi owó lé. So-òrò ìkeyin ó fase fún mi kí n sunmó tòsí Ó sòrò ìkeyin fún wa 

bid: n; (Bids were invited for construction of a new government house.) ìfowóléWón pe àwon ènìyàn fún ìfowóle kíkó ilé ijòba tuntun náà.

big: adj; (The house very big.) tóbi Ilé náà tóbi púpò 

bill: n; (It is a bill that becomes a law.) àbádòfin Àbádòfin ló máa n di ofin 	 

bin: n;  (The man bought a new dust bin.) irufé garawa tabi àpótí Okunrin naa ra garawa ìkólè tuntun kan 

biography: n; (They have read the biography of that man that died yesterday.) Itan ìgbésí ayé èdá Wo ti ka ìtan ìgbésí ayé Okùnrin náà tó ku lánàá .

biology: n; (Akin is a biology teacher.) Ekó ìjìnlè lórí Ohun elemi bí irúgbìn ati eranko Olùkó ekó ìjìnlè lórí ohun elemi bí irúgbìn àti eranko ní Akin.

bird: n; (Birds builds their nest on the 
trees.) eye Awon eye máa n ko ité won sórí Igi.

birth: n; (Birth is a providential grace.) Ìbímo; bíbímo. Oo re-òfé olórun ni ìbímo jé

biscuit: n; (He gave me a biscuit.)
 akara òyìnbó O fún mi ní akara òyìnbó je

bit: adj; (Ade gave me a bit of soup.) síún, tíún, gán-ún Ade fún mi ni obè tíún	

bite: v; (He bit his finger.) bù je; gé je Ó gé ìka rè je.

bitter: adj; (It is as bitter as bitter leaf.) korò Ó korò bí ewúro. 

black;adj; (The black dog is here.) dúdúAjá dúdú náà wà níbí. 	 

black: n; (Black is his best colour.) àwo dídú Àwò dídú lo féràn jù. 	 
blackboard: n; (We have blackboards in our 
classroom.) pátákó ìkòwé A ní pátáko ìkòwé ní yàrá ìkàwé Wa.

blade:n;  (He bought two blades yesterday.) abe; abefélé; Ó ra abefélé méjì lánàá. 

blame: n; (If we don’t complete this job, 
you will take the blame.) Ibáwì; idálébi Tí a kò bá parí sé yìí ìwo ni yóò gba ìdálébi rè.

blame: v; (He blamed the child.) bá wí; dá lébi Ó bá omo náà wí 	 

blanket: n; (He bought a new blanket.) aso ìbora; aso itésùn Ó ra aso ìbora tuntun 

blast: n; (The blast is too much.) Iró kikan; fife èfúùfù; iró ipè. Iró kíkan kíkan náà ti n pò jù.

blast: (He didn’t allow the bomb to blast.) bú gbàmù Ko jé kí àdó olorí naa bú gbamu 	 

blaze: n; (There was a blaze of fire at the company yesterday.) òwó iná Owó iná  sé yo nílé isé náà lánàà 

blaze: v; (The fire blazed out unexpectedly.) sé yo Òwó iná sé yo láìròtélè. 
bleach: v; (He bleached his clothes.) bo: so di funfun 	O bó aso re. 

bleach: n; (He bought new bleach yesterday.) oògùn ibódòtí 	Ó ra oogùn ibódòti tuntun lanáà.

bleak: adj; (The future of a lazy man is bleak.) ti ko sí ìrètí àti dár tí kò dára; tutu; tí kò dájú

bleat: v; (He asked him to bleat like a sheep.) ké bí àgùntàn ó ní kí ó ké bí aùntan

bleat: n;  (The lamb gave a faint bleat.) igbe àgùntàn Òdó àgùntàn náà kò lè ké jákè.

bleed: v; (The child is bleeding through the nose.) sèjè Èjè n jade láto inú omo náà 

blend: v;  (He blended the thour with milk to make it sweet.) dà pò mú dùn Ó da ìyèfun náà pò mó wàrà lati mú un dùn 

blend: n;  (A blend of beverages is very sweet.) adalu ohun mímu máa n dùn

bless: v; (God will bless you.) bù kún Olórun yóò bù kún fun o 	

blew: v; (He blew air at the hot food.) (He blew air with his mouth.) fé atégùn sí Ó fé ategun sí oúnje gbígbóná náa Ó fie mi fé atégùn 

blind: adj; (The man is blind.) foju. Sòkùnkun sí Okùnrin náà fójú. 

blindfold: v;  (Strange love has blindfolded the man.) dí loju; bo loju  sú lójú Ifé àjèjì ti bo okùnrin náà lójú 	

blindness: n; (Blindness is troubling him.) àìrían ìfójú  n dààmú rè.	 

blink: v; (He blinks his eyes.) séjú Ó n se ojú rè	

blister: n; (The accident has cause blister on his body.) ilérórò; oówo, wúwú. Ìjàmbá náà tí jé kí iléròró wàní are rè

block: n; (He removed the block.) ìdínà O mu ìdínà náà kúrò 	 

block: v;  (He blocked the way againt the rat.) sénà; dina Ó sénà mó eku náà 

blonde: adj; (The child has blonde hair.) pupa fúéúé Omo náà ní irun pupa fúéfúé 

blood: n; (The child needs blood.) èjè Omo náà nílò èjè. 

bloom: n; (The tree is in bloom.) ìrúwé; irudi; títanná Ìtaná igi náà famimóira. 

bloom: v; (The tree is blooming.) tanná; rudi; ruwe Igi náà rudí 	

blossom: n; (The trees are all in blossom.)
ìtànná ewèko; ìtànna igi; òdòdó Àwon igi náa wà ni àsìko ìtànná won 

blossom: v; (The tree has stated blossoming since last week.) yo ìtànná; yo yètuyètu Igi náà ti n yo ìtànná láti òse to Koje

blot: n  (There is a blot on the white cloth.) àbàwón Àbàwón wà lára aso funfun náà 

blot: v; (He blotted his book with pen ink.) se àbàwón sí Ó se àbàwón sí wé re pèlú aró kálámù. 

blouse: n; (She bought a new blouse.) èwù awòlékè  obìnrin. Ó ra èwù àwàlékè tuntun. 

blow: v; (He blew whistle.) (He blew air.) fun : fé Ó fun fèrè O fé atégun 

blue: adj; (The cloth is blue.) (He bought a blue cloth.) òfefè Aso náà ní àwò ofefè O ra aso aláwò òfèfé 

blue; n; (Blue is very good.) àwò ojú òrun; àwò ofefè Àwò ojú òrun/ èfefè dárà

blush: v;  (He blushed because of the bad incidents.) bojú jé; pón lójú O bojú jé nítorí ìsèlè náà 	

blush: n; (She cannot hide her blush.) ibojuje; ìlejú koko Ko le fi ibójujé re pamo 		 

boa: n; (The hunter killed a boa.) erè; ejò nlá. Ode pa erè 

boar: n; (The hunter killed a boar yesterday.) ìmàdò; elédé egàn Ode náà pa ìmàdò nlá kan lánàá. 

board: v; (He boarded a bus to his house.) wo; kó símú Ó wo okò lo sí ilé rè 	 

board: n; (He put the poster up on the board.) (The board is/are unhappy about falling sales.) pátákó Ó le àwòrán náà mo ojú pátákó lókè Ìgbìmò Inú ìgbìmò náà kò dùn bí iye ojà tí wón n ní tà tí se n wale 

boast: v;  (Don’t boast fabout what is not yet certain for you.) fón enu. Máse fón enu fún nnkan tí ko ti í da e lójú 

boast: (His boast is too much.) Ìfónu Ifónnu rè ti p`dojù. 

bob: v; (He was bobbing as if he wanted to sleep.) pààrà; rìn kiri. O n paara bí eni pe ó fe jale	

bob: n;  (The bob you have engaged yourself in cannot favour you.) ìpààrà: ìrìnkiri; ìrìnsótè-sódò Ipààrà tí gùnlé yìí kò lè sé o ri àn fààní. 

body: n; (Esau had hair all over his body.) ara Esau ní irun ni gbogbo ara rè

boil: v;  (He boiled the meats they gave him.) bò O bo eran tí won fún-un.

bold: adj; (The man is very bold.) gbóyà; gbójú-gboya Okùnrin náà gbájú-gbóyà

bolt: n; (He bought three small boits.) ìdè O ra awon ìdè kékèéké méta

bómà: n; (He lead the cattle to their bana.) ògbà eran; ibùgbé eran Ó da awon màálù náà wo ibùgbé Won.
bomb: n; (He killed his enemies with a bomb.)
 àdó olóró Ó pa àwon òtá rè pèlú adó olóró

bomb: v; (He bombed the quarters.)
fi adó dóró parun Ó fi adó olora pa agbegbe náà run 

bond: n; (Both of them have entered into a bond.) idè; ìmùle; iwé adéhùn Àwon méjèèjì ti se ìmùlè láàrin ara won.

bone:n;  (The femur is the longest bone in the 
body.) egungun Egungun itan ló gùn jù ninu gbogbo àwon ègungun ara 	

bonfire: n; (The bonfire covers all this compound.) àkàndá má; iná nlá tí a tan síla lákòókò àriyá Akanda me nlá náà mole yìí gbogbo agbègbe yìí 

bonnet:n; (He opened the bonnet of the car.) imú okò ayókélé Ó sí imú oko ayókélé náà sílè  

book: n; (He was reading his book.)
ìwé Ó n ka iwé rè 

boo: v;  (He has booked the 
accommodation for us.) Sètò sílè nípa sísanwo Ó tí seto ele tí a o gbé síle 

bookcase:n; (He bought a new book case.) àpótí ìkówèésí Ó ra àpóti- ìkówèésí tuntun 	 

boot: n; (The soldiers cottected new boots) (He locked the book of the car.) bàtà; èyìn okò-ibi ìkérùsí eéyìn okò. Àwon ome ológun náa gbe bàtá tuntun Ó ti èyìn okò ayokélé náà 

border: n;  (The stood at the border of the 
town.) ìpèkun : ibodè Won duro ni ìpekun ìlú nàá. 

bore: v; (The bore can bore through rock.) (I have heard all his storied before they  bore me/he bores me.) lu; gbé I hunnkan yìí lè lu òkútà kojá Sú; dá lágara Mo ti gbó awon ìtan ìtan re télè wón ti sú mi 

bore: n; (Don’t be such a bore;) (He has a twelve-bore shotgun) ìdámilágara Má saya adámilágara báyen Oníhò; ihò gbígbéjìn Ó ní ìbon olójú/oníhò méjìlá 

born: v; (He was born last year.) bí A bí I lódún tó kojá 

borne: V; (He has borne three Children.) bí Ó bí omo mela

borrow:v; (I borrowed money from him.) yá; Mo yá owo lówó rè	 

boss: n; (The bose was annoyed with his 
secretary.) ogà elèisé Ogá ibi isé náà binú sí akòwé rè	

botany: v; (Our teacher is very verse in botany.) èkó ìjìnlè nípa ohun ógbìn Olukó wa ni ìrò ìhìnlè nínú èjó ìjìnlè nípa ohun ògbìn. 

both: adj; (Both of them are here.) méjèèjì Àwon méjèèjì wà níbí 

bother: v; (Don’t bother yourself.) yo lenu; dààmú. Má yo arà re lému 

bottle: (He put water in all the empty bottles.)
ìgò; sago. Ó ro omi sínu gbogbo kòròfo ìgò náà.

bottom: n; (The bottom of the bottle is dirly.) ìsàle; ìpìlè; ìdí 	Idí ìgò náà dòtí 

bought: v; (He bought a car yesterday.)
rà O ra òkò ayókélé lánàá. 

boulder:n; (The boulder cannot be moved.) òkúta nláribitì Òkúta nlá ribiti náà ko se e si nídìí 

bounce: n; (He allow the baby a bounce 
before the put her on her back.)tito sókè, fifò sókè, Ó fún omo náà laaye itosoke èèkan kí o tó gbé e pòn séyìn 

bounce: v;  (The baby is bouncing on his 
mother’s back.) to; fò sókè omo náà n to sókè eéyìn ìyàá rè	 

boundary: n; (He showed the boundary 
between the two towns.) ààlà; òpin ó fí ààlá ààrin àwon ilú mejèèjì hàn mí. 
bouy: n; (The bouy is no more working Well.) amí lóju omi láti tóka ewu fún oko Àmì lójú omi tí ó n’tóka bí oke se ye kó rìn ko sisé dáadáa 

bow:n; (The bow is no more good.) orun Orun náà ti bàjé	 

bow: (The bowed down for their boss.) (The congregation bowed their heads in prayer.) teríba fún; tè bere Wó tè fún ogá won Ìjo ènìyan te orí won ba fún àdúrà. 

bowl: n; (He bought a new bowl.) Opón; abó kolo Ó ra opón tuntun

box: n; (He packed his clothes in a box.) àpótí Ó pa aso rè mó sínú àpótí 

boy:n; (The boy has left.) odómokùnrin Odómokùnrin náa ti lo 	 

boycott:n; (There was a boycott of election 
by the political parties.) àsepatì Awon ègbé òsèlu náà se àpatì ìdìbò náà. 

boyctt: v; (Don’t boycott my house.) pa ti má se pa ilé mi ti. 	

brace: ìdè; (The brace of my trousers cuit.) ojá ; ohun tí a fi gbá nnkan. Okùn tí mo fi mú sòkòtò mi lókè ti já.

brace: v; (He braced the door with iron rod.) dè; fi gbá ó fi irín gbá ilèkùn náà. 	 

bracelet:n;  (I  bought a golden bracelet 
yesterday.) ègbà owó mo ra ègbà owó olómi góòlù lánàá.	

bracket:n; (He puts the word in a bracket.) àmì àkámó ó fi òró náà sínú àkámó 

bracket: (Make sure you put all the borrwed  words in bracket.) fi sínú àmì àkámó 	Rí ì dajú  pr o fí gbogbo awon òrò ayálò sínú àkámó 	
brag: v; (He likes to brag.) hale, se féfé yangàn ó féràn látì maa hale 	 

braid:v; (He likes to brag.) (The lady braids her hairs.) dì hun; omobínrin náà dì irun rè 

braid:n; (She prefers braid to all other 
styles.) irun dídì; ìhun	ó feran irin dídì ju gbogbo awon àrà yòóku li a lè firun dá 

brain: n; (The Child has a sharp brain.)  opolo, omo náà pè.

brake: n; (The bicycle doesn’t have good 
brake. Ìjámu kèké náà ko ní ìjanu tí o dára

brake: v; (The driver quickly apply brake to 
avoid accident.) lo ìjánu Awakò náà lo ìyánu kí ìjàmbá má bà á selè 

branch: n; (He cut the branches of the tree) èka ó gé àwon èka igi náà 

branch:v; (He branched to the right.) yà; peka o ya sí apá òtún .

brand:n; (The good have the same brand.)
àmì tó wà lára ojà títa àmì ègan. Àwon ojà náà ní àmì kan náà 

brand: (He branded his own products to 
differentiate them from other.) sàmì sí; sàmì ègàn sí láná; kégàn Ó sàmì sí àwon òjà re láti yà wón sótò lára àwon mìíràn 

brittle:adj; (The bone is vey brittle.) rorùn láti Eegun náà ròrun láti fó 	 

broad:adj; (The road is broad.) gbòòròònà nàá gbòòrò. 

broadcast: v; (He broadcast the news on the 
television.) fán káàkiri, tàn káàkiri ó tan ìròyìn náà kaye lórí èro móhùn-máworan 

broadcast: n; (He stood against the broadcast of the program.) ìtànkáàkìrí Ó ta ko ìràn kaakìri ètò náà 	

broken:adj; (He threw away the broken bottle.)  fífó ó da efífó ìgò náà nù 

broken:v; (The bottle has broken.) Ìgò  náà ti fó 	 
bronze: (The wrist watch is made from bronge.) adàlu bàbà àti ide Àdàlù bàbà àti ide ní wón fi se aago owó náa

brooch: n; (The lady always uses broocher.) ìktí òsó tí àwon obìnrin náà máa n lo ikótí osò lati fi so èwu re lórùn nigbà gbogbo. 

brood: v; b (The hen broods its eggs.) sàba; pa eyin Adìe náa pa àwon eyin rè. 	

brood: n; (The two chicken are of the same brood.) om eye tí ìyá won jo pa nígbà kan náà Ìgbà kàn náà ní won pa awon omo ad`ye mejéèji.

brook: n; (We bathe in a brook.) odò ìsàn kékeré	A wè nínú odò ìsàn kékeré	

brook: v; (He brooked the suffering.) fara dà ó farad a ìnira náà

broom: n; (He gave me a broom.) owò; ìgbálè ó fún mi ní igbálè kan 

broomstick:n (Give me a broomstick from the broom.) sasawo; eyo omo owo. fún mini eyo omo owo kan nínú owò yen

brother: n; (Adé is my brother) arákùnrin Arákùnrin mí ni Adé	

brow: n; (The dangling stick hit my brow.) (He stood at the brow of the hill.)  iwájùn orí; sónsó orí òkè Igi tó n jì dirodiro náà gbá mi níwàju orí . Ó dúró ní sónsó orí òkè. 

bruis:v; (He bruised the head of the snake) tè ré; pa lara ó te ejò náà lórí mólè 

bruise: n; (The ara bruises on the body of 
the thief.) ogbé ìtèré, ìpalára  ojú ogbé wà lára olè náà 	

brush: v; (He brushed the dust off is cloth.) gbònnù ó gbon ìdòtí kúrò lara aso rè.	

brush: n; (He bought a new brush.) owò –owò ìgbòn-nnkan –nù	ó ra owò/ ìgbon-nnkan-nù tuntun

brutal: adj; (The man is too brutal.) rorò; níkà okùnrin náà rorò 	 

brutality:  n; (He showed his brutality by 
stabbing the Child.) ìrorò; ìsèka ó fi ìrorò rè han nípe gígún omo náà lobe 

brute: n; (My husband is a brute.) ònrorò; ika 
onroro ni okò mi 	

buck: n;  (Buck goes to drink at the river in 
the evening.) ako àgbònrín ; obúko;	Ako àgbònrin a máa nmimu ni odo ìsàn ní owó àsálé 	
bucket: n; (He bought a new bucket.) garawa ó ra garawa tuntun 

buckle: n; (The shoe has two buckles.) ìdè bàtà náà ní ide méjì 

buckle:v; (He buckle his shoes.) ìdè nnkan 	ó de bata rè

bud: n; (He pruned the new buds from the 
tree.) eélù ó já àwon ìdì tuntun ara igi náà kúrò	

bud; v; (The orange tree has budded.) rudí; rúwè Igí osàn náà ti rudi 	 

budge: v; (He budged the big stone.) mi; sún ó mí òkúta nlá naa

budget: n; (The president of this counting has read the budget.) ìwé ìròyìn owó ; iwe ìròyìn ètó ìsíná. Aare orílè-ede yìí tí ka iwè ètò ìsúná owó.

buffalo :v;  (Buffalo is a wicked animal.) efòn Eranko búburú ni efon 

bug : n;  (Bed buy is among all the bugs 
that bite.) kòkòro; ìda; ìdun	 Idún wà lára àwon kokorò kékèèke tó n jèyan.

build: v; (He built a house.) kó ilé; mo o k\ó ilé
building: n; (The building are very good.) ilé ti a kó Awon ilé tí wón kó náà dára	 

bulge: v; (when my mother came back from the market, her bag was bulging with things.)
wú sóde; wú síta. Àpò ìyá mi wu pèlu orisìí awon nnkan tó rà nìgbà tí o ti  ojà dé

burglear :n; (The police men have arrested the burglars.) afólé; fótéfólé –eni tí o wole onílé láti jí erù kó 

bulgle : (The hunter lost his bugle.) fère ìpè ologun	ode náà so fèrè rè nù 	 

bulk  : (He bought it in bulk.) ìwon nlanlá; tìtobi ó rà a ní nlá 	

bull: n; He slaughter the bull.) ako màákù 	ó pa ako màálù naa  

bulldoze: n;  (The government has bought a 
new bulldozer.) èro ìpalèmó. Ijoba ti ra ero ìpalemó tuntun	

bullet : n; (The bullet wounded him.) ota ìbon; ahaya ota ìbon náa pá eara	 

bullock: n; (He slaughter a bullock.) egboro ako màálù; odá màálu ó pa egboro ato màálù kan 	 
bully:  (The man is a complete bully.) aninilára; ayonilénu Ayonilénu pómbélé ni okùnrin náà

bully:v; (The teacher always bullies on his students.) ipá láyà; kígbe mó olùkó náà máa n pá àwon akékòó rè láyá.

bully  goat: n’ (The man has a bully goat.) obúko tabi ako ewúre òkùnrin náa ni ako ewúré kan 	 
bump: n; (The bump is still there.) wíwú soke wiwu náà sì wa mibe

bump:v; (He bumped against chair.) ko lù ó ko lu àga

bumper: n; (He hit the bumper of the car.) ìdáàbòbò okò ó ko lu ìdáàbòbò okò ayókélé náà.	
bun: n; (He ate bun yesterday.) akara róbóto àláàádùn ó je àkàrà roboto aláàádun lánàná	 

bunch: (He bounght a bunch of plantain.)
siiri; akója nnkan ó ra siiri ògèdè àgbagbà bindle: n;  (The bundles of stick are plenty.) ìdì; erù.  Àwon ìdì igi náà pò 	 

bungalow: n; (He has buit a bungalow.) irúfé ilé ile kan ó ti kó irúfé ilé ilè kan 

bunk: n; (They put two or three bunks on 
top of another to save place.) ibùsin tí se mó ògiri wón to ibùsùn meji tabi meta léra, nitorí ààyè 

burial:n; (His burial will be on Tuesday.) ayeye ìsìnkú ojó ìségun ní ayeye ìsùn kú rè

burn: v; (Fires were burning all over they 
city.) (The house burned to the ground.) jònà; jó Iná n jò ní gbogbo ìlú naa Ile náà jóná pátápátá 

burrow: n; (I saw a burrow yesterday.) ihò ehoro mo rí ihò ehoro kan lanaa	

burrow: v; (The rodent burrowed its way into the sand.) gbého Eku náà gbéhò rè sínú iyanrin 	
burst: v; (The tyre will burst if you blow it 
up any more.) bé; fó; tú jade Táyà náa yóò bé tí o bá tún fé e sí

burst: n;  (There was a burst of laugher 
from the child.) ìsè òjiji Awon omo náà bu sérìn-ín lójiji 	

bury: v; (He was buried in his home town.) (The dog buried the bone it had found.) sin; bò mole: sìnkú. Wón sin in ìlúu rè. Ajá náà bo eegun tó rí mole 

bus : n;  (Shall we walk or go by bus?)
oko se kí a fí ese rin ni àbí kí a wo okò ?

bush : n;  (There  is only one bush between 
my village and the town.) igbó : igbé Igbo kan soso ló wà láàrin abúlé mi ati ilú náà. 

bushfool : n; (He killed one bushfool yesterday.) àparò ó pa àparò kan lánàá 	 
business: n; (My business is selling fruit.) (leave me alone mind your business.) isé; òwò; nnkan tó kan ení. Èso títà ni òwò mi 
Fi mí sílè, gbájú mó ohun tó kàn ọ́. 

busy :v; (I am busy.) sise lówó; mo n sise lówó	
busy: adj; (He is a very busy man.) náà láápon okùnrin náàláápon

but : conj;  (His mother won’t be here, but his father might.) sùgbón ìjá è le má wà níbí sùgbon bàbáa rè le wà níbí. 

butcher: n;  (His father is a butcher.) alápata Alápatà nì bàbáa rè 	

bulter : n;  (Fry the onions in butter.) orí (àmó) Dín àlùbósà náà òrí àmo 

bulter : v; (She buttered four tick slices of bread.) fí orí (amó) sí buredi 	ó fi orí (amo) sí awon ègé buredi kíki merín 

butterfly :n; (She is like a butterfly.) labalábá ó rí bí ì labalaba 

button : (He pressed the button.) ìdè ó te ìdè náà 

button: v; (She hurridly button her blouse.) fi ìdè dè ó yara de ìde èwu  rè	

buy : v; (My father but a new cloth.) rà bàbá mí ra aso tuntun.

buzz : v;  (The insects were buzzing around 
the room.)  kùn bí olóbòn-ùn-bon-ùn. Kòkòrò náà n kùn káàkiri iyèwù

buzz : n; (The buzz of the bees is too much.) kíkùn kíkùn awon oyin náà tip ò ju 	 

by : prep; (A house is by the river.) lébàáIlé kan wà lébàá 

by :and; (He came in by the door.) nípase ó gba ojú ònà wole 

brim : n; (We stood at the brim of the river.) bèbà odò A dúró ní bèbè odò naa 	
brim : v; (His eyes were brimmed with tears.) kún fun; kún ojú rè kún fún omijé 

bring : v;  (He wants to go and bring the money.) mú wá ó fé lo mú owó náà wá 

bring up : v; (He brought up the child.)  tó 	ó tó omo náà dàgbà	

brisk : adj; (The man is very brisk.) já fafa; yára okùnrin náà já fáfá dáadáa 	 

brass : adj;  (He bought a brass plate.) oníde ó ra abó oníde 	

brass: n; (The brass is very good.) ide. Ide náà dára gidigidi 	

brave : v; (The child is very brave.) láyà: gbójú-gbóyà; gbóyà. Omo náà gbóyà dáadáa 

bread : n; (I ate bread yesterday.) àkàrà Mo je àkàrà lánàá 

breadfruit: (He ate breadfruit.) N.b “gbere” (is a borrowed word, it is borrowed from breadfruit. It is short end from “gberebúùtù”
 gbere; -irúfé èso igi kan ó je gbere. 

breadth: n; (He calculated the breadth of the 
House.) ìbú; gbígbòòrò ó won ìbú ilé náà

break: v; (He broke the stick.) fo; sé; dá ó dá opá náà 	

break :n; (They have gone on long break.) ìsimi; dídá Wón ti lo nínú olójó gbooro. 	 

breakfast : n; (I have eaten my breakfast.) oúnje òwúrò mo ti je oúnjè òwúrò 	

breast: n; (Covered her breat with cloth.) oyàn; omu. ó fi aso bo ọyàn rẹ.

breastfeed: v;  (She breastfeeds her baby everyday.) fún omo lóyàn ó máa n fún omo re lóyàn lójoojúmò 

breath: n; (Breath is very important for all living things.) èémí Èémí se pàtàkí fun gbogbo ohun To bá n mí

breathe : (He breathed out.) mí ó mí jade

breed: v; (I breed goats.)  se ìtójú; bí; lóyún tó; sìn mo n se ìtoju/sìn ewúré 

breed: n; (I like this breed of goats.) irufé ohun òsùn; eyà ohun òsìn mo feran eya ewúré yìí 

breeder:n; (My father is a breeder of goats.) olùtójú; olùsìn olutójú ewure ni bàbà mi 

breeze: n; (The breeze is very cool.) atégun tó n fé yéè Atégun náà tutu dáadáa 

brew: v; (He brews all sorts of drinks.) pon otí ó máa n pon orisìírisìí otí mímu. 	

brewry: n; (He sets up a brewry.) ilé ìpon otí ó da ilé ìpon otí sílè 	

bribe: v;  (He bribed his boss.) fún ní rìbá tabi àbètélè o fún ogá rè ní àbètélè 	

bribe: n; (He took bribe from the man.) àbètélè; owó èyìn; rìbá ó gba àbètéle lówó okùnrin náà

brick: n;  (He used many bricks to build the house.) amò tí a gé tí a n fi kólé ó fi òpòlopo amò tí a gé kó ilé náà 

bridal: adj;  (The bridal party is very interesting.) tí ó je mo ti ìyàwó Àsè igbeyìwó náà dùn 

bridegroom: n; (The bridegroom has arrived.) oko ìyàwó, oko ìyàwó ti dé 	

bride: n; (The bride has come.) ìyàwó asesegbé Ìyàwó àsèsègbé náà ti de 	 

bridemaid: n; (The girl is a bridemaid.)  egbé ìyàwó; omoìyàwó ní omobìnrin náà

bridge : n; (The built a bruge over the river.) afárá wón mo afárá sórí odò náà.
bridge: (He bridged the river.) safárá sí; ó safárá sí orí odò náà 

bridle:n; (The bridle of the horse is cut.) ìyánu; 	ìjánu esin náà ti já

brief: adj;  (I want you to be very brief.) sékí; kíún; sókí Sékí ní mo fè kì o sòrò 	 

briefcase:n; (He bought a new briefcase.) 
ohun èlò ìkérùsí ó rí ohun èlò ìkèrùsí tuntun 

briefy: adv;  (The man told us what 
happerened to him briefly.) láìfa òrò gùn ; ní kúkúrú	okùnrin náà so ohun tó sele sí i fún wa ní kúkúrú	

brigade:n;  (All the membery of brigade were there.) egbé omo-ogun elésin tàbí elésè Gbogbo awon omo ogun egbe elésìn ló wà níbè

bright: adj;  (The sun is very bright.) (The Child is very bright.) tí ó tan imólè, tí ó mole, tí o dán, oòrùn náà mole dáadáa. Tí ó gbón; tí ó ní làá làáyè. Omo náà nì làákàyè dáadáa 




#Article 44: Ọba Ìséyìn (742 words)


Oba Iseyin

OBA ADÉYERÍ LÁTI ENU (PA) ÁLÍMÌ AJÉYEMÍ ILÉ
ALUSÈKÈRÈ NÍ ÌLÚ ÒYÓ

Adéyerí omo Alájogun

Adéyerí omo wúràólá

Adéyerí omo wúràólá

Ìyàndá a-báni-sòrò-má-tannìje

Adéyerí omo Alájogun

À n bó’bo, òbó hun

Adéyerí omo alájogun

Òbo kìkì are rè.

A à féná à ní ò jò

A féná tán

Oníkálukú n gbénu ú sá kiri

Àká baba ìrókò

Asawo lode ò febè paní

Adéyení omo Alájogun ònà ìbàdàn la ò gbodò rìn 

O n káà koko

Adéyení omo Alájogun 

Òjò pa kòkò rè gbìn-gbìn-gbìn

Òjò tí ì bá pa tápà

A dòtúbáté 

Adéyení omo Alájogun 

Elébùrú ìké

		Omo Alájogun

		Òbo kìkí are rè. 

		N ó k’aséyìn oba àrànse 

		Oyinbó omo Èjìdé àgbé 

		Gbógun léye 

		Àsoba jagun

Oyinlolá Oláwóore 

Peranborí

Peran bofá

Oláwóore a bèyìn àrò gele-mò-gelé-mò.

Kò se é mú ròdá 

Ò se é mú

Gbógunléye

Àsobajagun

Nlé Oláwóore 

Baba enìkan ò gbin yánrin

Baba enìkan ò gbin gbòrò 

Omo èjìdé Àgbé

Fúnra rè lóhù 

Aséyìn Oba àrànse

Oyinlolá Oláwóore 

A gbó onísé Oba má mà dúró

Omo èjìdé àgbé tí í gbónísé onjò

Tí í tún fìlà se ge-ge-ge

Oyinlolá

Oláwóore 

Àsán-àn-jòmì-eye

Oláwóore 

Ekùn-abi-làà-làà-ìjà-layà

Láwóore ekun-abi-làà-làà ìjà-layà

Agbógbe má gbóyàn

Oba Àyínde 

Oyinlolá

Láwóore Àbe

Afàdàmò-ragun-jànyìn-jànyìn

Oyinlolá omo Èjìde Àgbé

Dákun má gbéná

Oba àrànse

ohinlolá

Láwóore

Nígbà tí ò sí mó 

Aséyìn ò ti è parun

Oyinlolá

Oláwóore 

O kan Adégbìté

Sùkú-séré Adégbìté

Omo alálè-òrun

A-jó-kí-de-ó-ró

Baba ori dagogo

Àrán kún lé

Baba odún sàrìnnàkò ààlà yìgì

Ààlà yìgì baba ò dé títí dodún

Omo afòkú sòwò 

Àrèmú Arówólóyè

Àbíkú oníjànmón

Baba ládépé

N-n-gb ó gbinrin lówó òtún

Sùkú-mì-séré

Mo se bálágbède òrun ní n lurin

A-jó-kí-de-ó-ró

Baba orí dagogo, n-n-gbó gbinrin

Lówó òsì, Adégbìte

Mo se bálágbèdè-òrun ló n lurin.

A-jó-kíde-á-ró baba orí dagogo

Èmi-ò-tetè-mo-pówó-fá-gùn-má-ràjà-gún-gbe

Arówólóyè

Àbíkú oni jànmó

Baba ládépé

O dèèkínní onísé ìbàdàn dé wón lógun jà ni 

Mókín ilé

Arówólóyè Oba èse

Wón ní mo kí séríkí

Mo kí Balógun

Mo kótùn-ún

Mo kósì

O dèèkejì èwèwè

Onísé ará ìbàdàn dé

Wón lógun jà ni mòkín ilé

Arówólóyè

Wón ní wón ó kí séríkí dáadáa

Wón ó kótùn-ún

Wón ó kósì ìbàdàn

O dèèketa èwèwè

Onísé ará ìbàdàn dé

Wón lógun jà ni Mòkín ilé

Arówólóyè

Oba èse

Wón lógun le fún séríkí

Ogún le fún Balógun

Ogun le fótun-ún

Ogun le fósì

Kóso kó kí e má le è kó won

A-jó-kí-dé-ó-ró

Baba orí dagogo

Sèkèrè kó ní e má le è sétè

Tètè kò pé e má le è kójèbú

Arówólóyè

Abíkú onijànmó

Baba ládépé

Járun-járun

Kó máa jáwon lo 

Jósèèké jósèèké

Kó pé e má le è kójèbú 

Arówólóyè 

Abíkú oníjànmó

Baba ládépé

O kan Olúgbilé

Ìgbà tí ò sí mó

Aséyìn ò ti è parun

Olúgbilé

Eléwu oyè

Òmùdún kókò

Oba asàwòlòlò

Oní jànmó alátise

Olúgbilé

Aberan nílé bí ode aperin

Afàlùkò-jèjèè

Jejèé-nílé-oníjànmó

Jejèé-lóde

Olugbile tó tó baba

Láwóore re i  se 

Aborí esin báá-báá lónà komu

Abìrù esin tìkòtìkò

Lónà ababja 

Sèrùbàwón baba Àjíà

Ológòdo ègi

Olúgbilé

Aberun nlé bí ode aperin

Rèwó-rèwó ní e má ti è rèwó mó 

Ológòdo egi

Olúgbilé ni bá a bá lo 

Emi ni í máa se ní wàye

Mo ní jà mo jùlo 

N-n-jù-tòsun-lo

Òmùwè tí n wè lódò òsà

Kó múra kó lè wèé já

Iba mi olúgbilé aláwòye 

Òmùdún kókò oba asàwòlòlò 

Ìfòròwánilénwò lóri àwon òrò tó ta kókó 

Ìbéère: 	kín ni ìtumò gbólóhùn yìí “A à féná, à ní kò jò?

Ìdáhùn:	ìtumò rè ni pé  nígbà ti ìnà kò ì jò ni à n dúró, tí iná bá ràn 
tán ènìyàn ó ho.
		
Ìbéèrè:		kinni ìtúmò omo Alájogun. 
		
Ìdáhùn:	omo jagun jagun
		Ìbéèrè:		kín ló fa ‘ona ìbàdàn la ò gbodò rìn?
		
Ìdáhùn:	Nítorí pé ológun jo ni wón.
		
Ìbéèrè:		Abèyìn àrò gelemò-gelemò nkó?
		
Ìdáhùn:	ó jé eni tí í máa n ni eran nílé ní gbogbo ìgbà tí ó sì máa 
n fi í se àlejò.
		
Ìbéèrè:	kínni ìtumò Ekùn abi làà-làà ìjà layà?

		Ìdáhùn:	Jagun-jagun tí ó le ni à n pè béè.

		Ìbéèrè:	ìdí tí e fi n pè é ni Oba àrànse?

		Ìdáhùn:	Onírànlówó ènìyàn ni ó n jé béè. Ó n ran ènìyàn lówó.

		Ìbéèrè:	Omo aláte-òrun nkó?

		Ìdáhùn:	Eégún baba won ni aláte-òrun tí a fi  n pè é béè.

		Ìbéèrè:	kin ni ìtumò àbíkú oni janmo?

		Ìdáhùn:	E ni tí n dákú.

		Ìbéèrè:	kín ni  ìdí  tí a fi so pé ó se ori esin báá-báá
				Lónà kòmu?

		Ìdáhùn:	ìdí ni pé  kòmu ni oko rè.

		Ìbéèrè: 	òmùdún kókò a sàwòlòlò nkó?




#Article 45: Ọba Ìkòyí (728 words)


Oba Ikoyi

 LÁTI ENU ALÀGBÀ OYEKALE ALADE
OMO ISÉ FÓYÁNMU)

Ùn n lo ilé wa lóhun ò ò ò ò 

	Nílé ìkòyí omo erù ofà

	Olóòótó omo gbáà, omo gbèdu

	Yánbínlólú omo Arágáláká kee fikú pogun

	

	Omo gbélé 

	Omo gbégbèé

	Omo gbé ijù, gbébi 

	Ò-gbódi-gbé-yàrá

	O gbebadan ò kè pé, o gbákínmòórìn, o gbáawé

	Ò-gbé-fìdítì-gbewàré

	O gbákínelé, o gbéléefón run 

	O gbélé kúata, òtè ò tán e e bibì làá dé si 

	Kú fúnwon rérìn-ín Olóyè n ni baba mi 

	Ó níbi táa bá gbé, ibe nilé eni 

	Jagunjagun lèrò ìkòyí jé, omo oba a jò lápó wòròwòrò 

	Ogun ló bámi ni gbo 

	Mo dolú igbó 

	N lé mi lóhùnún ma dòsó esin 

	Bí bá n rogun

	Èrò òdàn bamii lódan mo dèrò òdàn 

	Ogun ló bámi pàlàpálá mee dòpá à bon 

	Àsé Olú nìkòyi jé omo eèru Ofa 

	Témi bá n lo sónà ihè mo mo on lé wa 

	Olúkòyí àfeji, àfeji n lo bí onikoye àfòjò àfòjò

Olúkòyí àfòjò àfòjò, un lo wa bí Olúkòyí èèrùn gan gan gan 

	N ló bí Olúkòyí ìrìwòwò

	Olúkòyí ìrì wòwò, un ló bi Oníkòyí òdá gbágbá 

	Olúkòyí òdá gbá gba, un ló bi Oníkòyí ò koko 

	Un ba won tó pón kángun síkoto níjóhun

	Témi bá n sónà bè mo monú ilé wa,

	Eléyun nì taa lóbí, taa lóbí ?

	Un ló bí òkéré lèrù gan gang an 

	Òkéré-lèrù gan gan gan gàgbon n baba won àgbà took tó kori 
òde ìsálayé 

N  lé ìkòòòyí omo eerù ofà 

Olóòtó omo gbáà omo gbèdu 

Yánbíniólú omo arágálá efikú pogun 

Témi bá n lo sónà be mo molé wa 

Omo Oba ìjí peké-peké

N lé ìkòòyí omo erù ofà

Àwon ni, àwon lomo Oba ìjí pokùn-pokùn 

Ìjí mó pokùn mó 

Igi àtòrì ni ko yá mó on pa 

Ìji mó pagi àtòrì mó 

Igi àtòrì òun nigi àse 

		

	Láwòójì n be nlé owínsí dara 

	Omírìn dara lóri ofa òòò 

	Ota rìn dara lóri omi ò ò ò 

	Làwa n pèkòyì omo eerú ofà 

	Olóòtó ègi yánbinlolu omo arágálá e fikú pogun.

	Àrònì gbonra jìgì dagun erùù oògùn nù 

	N lé ìkòòyí omo eerù ofà 

	Àlà e wà bí, inú ilé gbogbo kààà sí nkan kan nítiwa 

	Omo sírò n togun 

	Omo gbàro n togun

	Omo jìgan n tode

	Omo jìgan-jìgan láà rùkú alaigbodoràn mote serù bòtè 

	Mo letí mo fi n gbóràn láyé òòò

	Enikéni kó mó rúmí gbajú òde baba mi lo olórí ogun 

	Àwa lomo òsèsè ‘kòyí

	Tí mo réèrín gán án ni kú 

	Tú kí n dérin, elégbà ni mo di pèle níjó tí mo fi lo gán án 

ìlànlá omo èrù oofà

Témi bá n  lo sónà bè mo monlé wa 

Ìkòyí omo eerù ooofà

		4	Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu 

	Èyin obìnrin ìkòyí e mó pagbòn lágbòn mó 

	Gbogbo obìnrin ìkòyí tí bá n pagbòn lágbòn wón n rán oko won 
léti ogun ni 		

Lóòotó ni béè ni òdòdò on yùn

Àkà kè wà bí, inú ilé gbogbo káà sí n kan ní tiwa ìlànlá omo 
gbáà 
erù ooofà

Olóòtó omo gbáà omo gbèdu yánbínlólú omo arágálá omo e fi 
kú pogun

Orin: 		Eruwa nil é omo agbòn, ta n níkòyí ò nílé 
		Omo agbon ?

Ègbè:		Eruwa ni lé omo a 

Lílé:		Ta n ni kòyí ò ni lé omo agbòn

Ègbè:		Èrùwà nilé omo agbòn

Lílé:		Ta n níkòyí ò nílé omo agbon?

Ègbè:		Èrùwà nilé omo agbòn on on. 

Ìrìn mi gbèrè ó dilé wa lóhùn ún òòò

Àdesítèé oníkòyí òòò

Ìkòyí omo eerù oofà 

Adésítèé loba tí nbe lé kòyí omo agbàawà 

			

pogun,

Àrònì gbonra jìgì  dabo erù oògùn nù 

Okùnrin gbon gbon gbon bí ojó kanrí 

Adésítèé,

Okùnrin gbòn gbòn gbòn bí eni fìbon tì 

Ìsépo méjì omokùnrin

Adésítèé mo o bá tòde baba a re lo 

Ìkòyí omo gbáà, omo gbedu yánínlólú omo arágálá e fi kú 

Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa 

Orin: 		Tapó tapó ;à á bómo ogun 

		Tapó tapó là  á  bomo ogun 

		Ìgbà ìkòyì ò tó déedé

Ègbè:		Tapó là á bómo ogun 

Lílé:		Èsò kòyí ò rìkú sá

Ègbè: 		Tapó tapó làá bómo ogun 

Lílé:		Àgbà à kòyì ò ríkú sá 

Ègbè:		Tapó tapó làá bómo ogun 

Lílé:		Àgbà kòyí ò ríkú sá 

Ègbè:		Tapó tapó làá bómo ogun 

Lílé:		Àgbàà kòyì ò ríkú sá 

Ègbè:		Taapó taapó làá bómo ogun un. 

ÀWON  ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA  KÓKÓ NÍNÚ OBA  ÌKÒYÍ




#Article 46: Ọba Ògbómọ̀ṣọ́ (2638 words)


Oba Ogbomoso

 LÁTI ENU ALÀGBÀ OYÈKALÈ ÀLÀDÉ
(Omo Isé Fóyámu)

Ògbómòsó òle ò gbé

Ògbómòsó òle ò gbé, eni ó bá lágbárá ni gbébe

		1	Lóótó ni béèni Òdodo ni 

			Ògbómòsó ‘mo ajekà ká tó mùko yangan 

			Ògbómòsó ‘mo a jòrépo-tú-yì

	Àlà e wà bí o ?

	Inú ilé gbogbo kàà sì n kan an ní tíwa.

	Ògúnlola lorúko sòún àkókó je 

	Soun kéìtán iwin lábérinjo 

	Àísá Òkin onígùru-gùrù kéta

	Adàdá mówù moja àpà

	Oba tóbá onígògòngò jagun àlùsì àpà

	Eléyun ni ni oòòò

	Òun loba tó kókó tèlú ògbómòsó òòòòòò

	Un lókó tèlú Ògbómòsó dó 

	Lóòtó ni, béèni òdodo ni kì gbogbo Oba kí won ó tó mó on je 

	N gbà tí ò dè si eléyun nì mó o 

	Ògbómòsá òle ò gbé eni ó lágbára ní gbébe 

	Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilée wa 

	Èyi loríkì ti ògbómòsó ajílété 
	
Béè náà ni Oba ajísegírí niilé wa 

	E dáké Ògbómòsó òle ò gbé 

	Eni ó lagbara ni gbebe.

	Ògbómòsó, Ogbomojúgun
	
Temi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa 

	Báàbá bára wa tan, a fògbó kògbó nnú lé

	Àlà e wà bí ò ò ò 

	kótó wá kàjàyí-Olú-Ògídí oníkànga àjí pon 

	Aíléwólá agidingbi lójú Ogun 

	Àtilé atona ni baba mi Àrèmi fi sá nka ìjà á sí 

	Béènáàni Aíléwólá agidingbi lójú ogun 

	O lájá ti n be nínú ilé méì wulè gboni,

	Ènìyàn Àjàyí té e rí ò gbodò ya só o mó lásán 

	Béè náà ni omo aráyé nì n kóba lóro 

Ìgbà ti ò dè si eléyùn nì mó o 

N ló wa kan Oba Ajagunbádé

Témi bá n lo sónà ibè mo mo on mi ilé wa 

Ìbísùnmí, Lákanngbò, oko aràgan

Ajagungbádé Onídugbe 

Àráráriri, Gbángbóyè ìrèlè baba òkè

Kójú ó torì, kóràn ó dòrìsà

Òrìsà mo kaàbá

Bábà bá yè Ajagungbádé

Jánjanjan ní mo ón dunni 

Ajírèrín Òkeke 

Àdàgbàlagbà Sinyan àgbìgbò nìwòn

Ìbísùnmí ní n tósàgbònìwòn té e dékun èrín rín

Tobá segúnnugún a kowo móri eyin 

Nnkan to sàjààsá té e délé ìbàdàn 

Tóbá solówó erú ni, à bá ti rérú è mó pátápátá 

		3	Atìbàdàn wá joyè bí omo jógíoró 

			Okùnrin pon pon pon bí ìbon ògodo 

			Gbongbòn janran baba mi ìbisùnmí tó wúwo bí àte àdí 

			Aja-n-gba-da-gírì-jagi

			Ò-jebòlò jegi ìdi rè 

			Sara-sara làá kina bolé

			Òjò pàà pàà ti tújà 
			
Abomo on mú sànpònná kàrà-kàrà nìgbà osàn 

			Ó yi éyìn osè, o pomo òsú lékún 

			O sìkà osumí ògódó ó kanga oní kanga

		Báni bù ú wò omo òkèèbàdàn 

		Àlá ó ba bùú, ó ní iyán lémo 

		Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa

		Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mo òòòò

		N ló wá kàlàbí Òyéwùmí

		Oyèwùmí Ládiméjì, Ládèjo

		Afolábí omo Tinúuwin

		Ajíkobi Dèjì omo iwin ìgbàlè

		Dèjì omo Àsààkún eni tó bá wolodumare ní dá lólá

		Òkìkí ò posù, ariwo ò ní pojó

		
	4	òkìkí ò nó somo onílè ni n kankan 

	Ojo ò tòòjó, ojó ò tojò 

	Ojó táwon kenimoni gbórí àbíkú kale lójàajagun 

	Eni tó kúrú n wón n tiro 

	Ènìyàn tó gùn n bèrè

	Àlàbí ò gùn béè ni ò kúrú 

	Ó dúró gbangba, óbálábòsí wijo 

	Níwájú òyìnbó ajélèèèè o jàree abínú eni 

	Orí ewúré sunwòn itú ló bí 

	Tàgùtàn sin àn ó bí yàgbò 

	Ìpàdéolá abesin gbórùlé jìgbàró 

	Orí baba Láléye sin àn tó bárá Ìbàdàn tan 

	A rí bí won tí n sojú oko Olúgbódi 

	Àrán inú àpóti oko Efúntádé

	Àrìnjó káàkótó oko ògboyà

	Méèle nìkàn sùn, méèle nìkàn dájí 

	Nílé làlàbí òkín lóti málàké ròòde

	Témi bá n ko sónà ‘bè mo monú ilé wa 

	Agbe tori omo rè dáró 

	Àlùpò dùdù tori omo rè kosùn

	Lèkélèké gbàràndá ó torí omo rè déwù aso funfun 

	

	Torí Àbáké lo fi lo o kóògùn aremo 

	Àsoba sàrìnjó tí n gbonílù tí fi gbèwù àrán 

	Oyèwùmí Àlàbí n ní gbomo Ológbàó tí fí wé gèlè genga

	Eléyelé ìyàwó, oko jólásún

	Ará ilé Àdùnní, OLókan aya bale ajísomo Dèjì 

	Àlàbí oko látúndùn 

	Oyèwùmí Àlàbí ló fi Ládùnní rópò ara rè tó dip ó térí gbaso 

	Témi bá n lo sónà ibè mo mo on nú ilé waaa

	Òun loládùnnúnní Àkànó Oba tí n be lógbomòsó òòòò

	Oba ògbómòsó tí n be lórí oyè ní ìsinsin in

	Témi bá n lo sónà ibè mo on lé wa 

	Ìbà baba mi Àkànó Oládùnúnní òòò

	Oládùnúnní Oba tó rojó ilè tó jàreee

	Bémi bá n lo sónà ibè mo monú ílé waaa

	O jàre gbogbo àwon ìjòyè tí n be lórí ilè náà

	Àlàa`fíà ke wà bí o

	Témi bá n lo sónà bè mo molé wa

	Eléyelé ìyàwó òko Lárónké òòò

	Ará ilé Àbìó ò ò ò 

	Oyèwùmí Àlààbí

	Olá òkan ò jòkan aya

	Bale ajísomo Dèjì Àlàbí Oko Túndùn

	Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé won 

	*Àwon lomo Ìbàrùbá niwón elégùn esè

	Ìbàrùbá niwon elégùn esè Olàyankú omo ode bárán eti oya 

	Omo Abérisé

	Omo Agbònkájù

	Omo Ajijoperin

	Ìbàrùbá omo olójà n lìkì 

	Ìbàrùbá mojà lójà

	Ilé yìí, ilé àwon baba mi 

	Mo bá e dó kááda oníkáadé

	Oníkáda won ò sì ní gbèsab àwò ò ní tánmo lórùn n lìkì 

	Omo pákí nimi, mé je sìgo 

	Omo nàmù-námú, erú ò joòrì

	Omo kékeré Ìbàrìbá téerì ò gbodo jáwé apá sié lánlán 

	Ìbàrùbá Olákòndórò, Oláyínnkú, omo ode bare eti oya 

	Omo abérinsé, omo agbònkájù, omo ajíjóperin

	Looto ni béèni òdodo ni 

	Ìbàrùbá won èé sunlé àjà 

	Won a ní e bámi wéké yógùn nanana ki ni róhun kólé 

	

	Ìbàrùbá won è é pèkùlù 

	Won a ní e kálo o lé lóhunún ká lo rèé kédò erin

	Ìbàrùbá Olákòndórò Oláyankú 

	Omo amérin wá á mòlú, omo aréfòndiyàyà

	Àrá abowó òjà lálálá

	Baba mi ògìdán tí fowó ìjà ralè

	Óní bí elérèé ò bá réni 

	Tí ìjèsà ò bá tajà láwìn

	A kòí molésà lásán

	Òyíìrí lápó

	Oládòkun èjè ti ti ti lénu esin 

	Tayérunwón, Tègbésòrun

	Agbesin lówó Olúpaje 

	Aare akòta sùsùsù ofà 

	Sòún abiléfà n wájú 
	Kéètán abilé ofà léyìn 

	Dáùsí abilé ofà láàrin

	Baba wa ló soró kan bí agogo 

	A fìbènbé ooró kù bi òjò 

	Eléyun ni nú ò ò ò

	Àwon Oba tó tògbómòsó o 

	Jógioró akandehunso, àpáti Olúmokò tí kogun lójú tòsán tòòru

	

	kò jé ki elénpe bòdé mó 

	o gbesin lówó Olúgbaja, ààre a-ko-ta-sù sù ofà

	témi bá n lo sónà bè mo monú ilé wa 

	Ìgbà ti ò dè sí eléyùn nì mó ò ò ò ti jógioró kú ò 

	Eranko orí ráre tii dún mònnàhun-mònnàhun 

	Témi bá n lo sónà bè mo mole wa 

	N ló wá kan Ik’’umóyèdé Àjàsá alátò oyè lábé 

	Oba lábé bánbóba bánbóba

	Oba tóláya márùn-ún táwon márààrún ti an bímo oyè 

	Wórókòòkan Oba ni wón je 

	Témi bá n ló sónà ibè mo mo on nú ilé wa 

	Eléyun nì óòòò`

	Taa lóbí, taa lóbí òòò?

	Òun ni baba Àjàjí Olú ògidí òòò
	Olúwùsì Àjàyí 

	Lóòtó ni béè ni òdodo ni 
	Olúwùsì Àjàyí

	Onísòro sègì òpónrororo, baba mi akòtòpò iyùn

	Òbá jègbè ìlèkè Àjàyí ebí láàrin lòbá mó on gbé 

	Ailéwólá o yanjú Olá gandangbon

	Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó ò ò ò 

	Taa lóbí, ta a lóbí ò ò ò ? 

	N lókàndòwú bólántà a wùwón 

	

	Àkèyìn sí olá kì í rò 

	Ìdòwú Olóde Àgbánká

	Fárónbi abesi kan kúro lójú ogun 

	Gúdúgúdú abojú légbèé

	Àlùkojú órun àpinti 

	Adáso mó fágírí, oko ògúnyìnmí

	Agbinni mó gbinsè, oko Ajíbólá

	Ògòngò gongo nírìhànló Oko òjíbù ti jájolá

	Ayìndòwú nibon kò kú, a tomo jógíoro lóra o mú gbogbo e je 

	Ògbó dì ofà tii semú wìlìkí 

	O ní kòsí oya òòòò

	Ogun a kólé e rá òòò

	Bí ò sí olùfòn ogun a jà lérìn

	Tí ò bá síi lákidófà Ìdòwú Ogun ni jòsogbo 

	Ó gòkè òrá, o seré nà fún gàmbàrí 

	Ò se rebee níjó dósogbo 

	Ògbèkè n gbekè, rábesè gbékèlé

	Ó fàtògòrò, ó súwon lóòrógàn títí 

	Ó gbójúlé lé jagun níjó ogun níjó ode 

	Èdù òkin ti fóhnn sà

	Témi bá n lo sónà bè molé wa 

	Ìgbà tí ò dè si eléyun nì mó ò ò ò 

Tí jówólè Oòni 

Akíntúndé Apébu

Apéébu wóló, atìdí yògòlò

Amúlé gbolófófó

Àwa la múlé  gbelé aseni 

Ilé aseni won ò jìnnà ó jà 

Àbá molé  olórò ni, a ò sì molé aseni 

Àbá mole aseni, òràn won a tètè tán 

N lèmi pogunlabí 

Òwè ò jejò kínní o feran ejò se lénu 

Yàkàtà yakata kò jé a rí ìdí ìsápá

Ìbíkúnlé ìbàdàn, won ò je á sodún arò ní nkankan 

Ìgbì tí n gbìkúnlé

A jade tòun tòbùrù gege bi elégbára ègbè léyìn gbogbo àgbà Bàdàn. 

Òháhá ilé lógundégèlé ò eruku esin lofi légún Déyemo 

Awon ará Òòyì,  àwon n won ò gbón 

Àwon n won ò mònràn 

Won ò mò pérúukú lòwò o báwí 

	 	

Òlémo gbó Àsàmú baba Àb áàsì

Ìgbà ti ò dè sí eleyun nì ìn mó òòòò`

N mí Oba márun òòòò

Lóòtó ni béè ni òdodo ni in 

Temi bá n lo sónà bè mo monlé wa 

Ó wa kàbàrí Olúòyó, ebìíyà

Àbàrí OlúÒyó, Oyèédòjun, Látiri abólugun-Oba 

Oba táaké ké ti  ò juke

Oba táa gègè tí ò jugè 

Òrìsà tí ò jugè, ojú pópó ní gbé 

Dúdú fílàní n lomo lákan lé fi modi 

Pupa re ní sàatà, ìdùkúrùkú 

Témi bá n lo sónà bè, mo monú ilé won 

Ìgbà tí ò dè sí eléyun nì mó ò 

Témi bá n lo sónà ibè mo mo on lé e wa a 

In ló wá kàlàó, Onísòrosègi 

Àlàó témi bá n lo sona 

Òun ni baba Àtàndá Ògúnwèndé òòò

Àlàó táa wí yìí, òun ni baba Àtàndá Ògúnwèmdé òòò 

Òun ni baba Láoyè tíí jórumogegege 

Ààre asòkò senbe àbàjà

Sòún dáìsí Oláoyè ni baba ònpetu

Bàbá lelébùrú àásáká	 

Oláoyè abìlé gbogbo lóógunlóógun 

Odán nigi àwúre

Òpè nigi ìràdà 

Àgbà ti n féni láfèé lólé

Iwo nlá ni fólúwa re je 

Té lésin, bàà lésin 

Òkètè n ketè, a mò ón gùn jomo àgbè 

Àtùké bóun àsá baba lágbéndé pinpin pin lórí esin 

Òpòló tóo yírò òo se é to 
Oláoyè okólé baba re lóbá kan kórí 

Alùfáà a pàkòi,

Oúnlé orí omo kélebe

Témi bá n lo sónà be momolée wa

Ìgbà ti ò dè si eléyun nì ìn mó o 

N ló wá kàntá Olóndé omo Omídélé òòò

Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa 

Bá à kègbón taní kàbúrò

Mo kókó fe e lo sílé baba itabiyi

Témi bá kó n lo sónà bè mole wa 

Témi ba n lo sónà bè mo monlé wa 

Kékeré àsá omo ajùújù bala 

Àgbàlagbà àsá omo ajùújù bala 

Kékeré làdàbà subu táwon tí n je láàrin òtá 

Olóumí kékée lo ti n soko won nílé 

Kekere lo ti n soko won lóki 

Kékeé lòjó ti n soko won lóna ijù 

Oníyòówón, Inásírù, Ibasòrun Kínyodé

Iba tíí begun wolé e rémo lo 

Iba tí n bá n bò, a kòdi órun 

Òfesè mejeèjì gungi òbobò 

Eléyun nì ní ò ò ò 

Òun ni baba ìtá Olóndé omo Omídélé ò ò ò 

Òré ò sí, Olórun Oba dada 

Ináwolé baba kóta 

Ó ní Ifá firipò nínú igbó 

Òpèlè firipò laàtàn 

Òrìsà ké kè firipò lágbède agodi 

Ináwolé baba kóta 

Tí ún bá n lo sónà tòkun, òkun lolórí omi 

Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó ò ò ò ò 

N lówá koláyodé ò ò ò 

Adékúnkèé, Adégòkè oko pàte 

Oláyodé omo egúngún oko 

Àrà n baba mi Àatàndá

Adégòkè omo iwin ìgàlè 

Lékèélékèé eléwù akese 

Ahan ran mòjàngbòn, eléwù pànpànkusà

Ògbómòsó ní wón gbé, won ó mo lòó sàyonuso, sí 

Láyodé omo egúngún oko 

Ò-déyìn-ìlèkùn-di-baba-àgbàlagbà

Òmìmyín-mìnyín té e rí ò le è meyín erin 

Èfúùfùlèlè n won ò leè mi òkun

Won ò sì leè mi òsà

Ìse tí èfúùfùlèlè táwon n se sókè lorùn 
Àtàndá Òkín Olóun Oba nu ò joke ó wó 

Àsá n ta, kò leè tagba raso 
Àwòdì wón n rà, won ò le e rewin ìgbàlè

Títí tí àwòdì òkè tée gbélé ò ile mò pé ojú eye oko a mó on ri íri-íri

Ìse ègbón, n wón n pe àbúrò 

Àbúrò ìba sègbónm ojú won n pón 

		

won a wò pèrè-pèrè bí èwù àgbàlagbà 

Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o 

Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa 

Ó wa kan Ajíbnólá, Adogun Eléèpo àrán 

Ajíbólá Oba to kobi sóyi 
Témi bá n lo sónà ibè mo monú ilé wa 

Ajíbólá Oba tó kobi sóyi sógun 

Àlà e wà bí, gbénkan dùgbè-dùgbè

Un ní pé Olóun Oba gbàmi 

Oba séríkí, in ní gbani lóhun tótóbi ní nla tóbi

Sòkòtò èfà mi ò òn balè 

Adìgún ni kásá paà lówó lówó 

Táa bá ti lówó lówó gbogbo e níí tóní

Àlà e wà bí ò, inú ilé gbogbo kàà si nkan nítiwa.

Agbà ti ò dè sí eléyun nì mó o 

Ó wa kòkò lánipèkun 

		16	Témi bá n lò sónà an bè, mo mo on nú ilé wa 

			Àlàáfìà ke wà bí o ? 

			Òkè Olánipèkun?

	Òkè kéé kèè ké, mó on jólè rè sánpónná 

	Kóniyangí kó mó on jélégbáa 

	Òkè tó lo sóòwu òbò 

	Eléèé tó lo sóowu ò dé

	Adéowó dáké mo joke kóòwu jojololá omo Bádéjéorúko

	Òkè ni ò ri powó awon èlèdà
	Àlà e wà bi, inú ilé gbogbo kàà si n kan nít iwa 

	Ìgbà ti ò dè si eléyun nì mó o 

	In ló wa kan Olátúnjí Eléèpo àrán 

	Olátúnji omo gbángbéfun 

	Àrágada sí bààmú lójú oko Oyèládùn 

	Kòlù-kòlù mó kolùmi Olátúnji ò ò ò 

	Eni Olátúnjí Àlàó Àlàó bá kolù yó febo jura

	Ìgbà ti ò dè sí eléyun nì mó o 

	N ló wá kolágidé, Olágíde Àjàgbé òkin baba Lúfójè 

	Témi bá n lo sónà bè mo monú ilé waaa

	

Níjó títáláyé ti dáyé ò ò ò 

Béè náà ni, níwájú omo Odérónké ti n wó tuuru 

Níjó tó fòyìnbó párì joyè 

Àlà e wà bí inú gbogbo kàà si n kan ni tiwa a 

Àjàgbé Òkin baba ìlúróyè

Tí ùn n bá tún lo sónà bè mo mo mole wa 

Ìgbà tí ò dè si eléyin ni mó ò 

Ó wá korímádégún àjààgbé Òkin, 

Tí ùn bá n lo sónà an be mo nú ilé wa 

Salami Àjàgbé, omo ìtá Olónjó, omo Omídélé

Òré Òsú, Olóun Oba dàda 

Ináwole baba kóta 

Gbogbo won pata-pátá táa wí yí òòò

Orílè ti wón ti wá 

Gbogbo won lomo ìbààrú onílè lìkì 

Oláyankú omo ode báré  etí oya 

Ìbàrùbá won è é sunlé àlà 

Won a ni e bami wéké yógùn nanana kí n róhun kole adodo 

		18	ìbàrùbá oonílè lìkì 

	Ìbàrùbá niwon eledin ese, omo ode báré eti oya 

	Òun ni baba tó se gbogbo wón lè pátápátá pogodo 

	Nílé è bààrú onílèe lìkì. 

ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ ORÍKÌ OBA ÒGBÓMÒSO

Ògbómosò lónìí yìí. Sòún Ògúnlolá àwon kan pàdé nínú igbo, 
gégé 
bí ìtàn ti so, èéfìn iná ni wón fi mò pé àwon kan tún wà nínú 
igbó nàá.

	Lára àwon kan tún Ògúnlolá bá pàdé ni Aálè èyí tí ó jé bale 
Òkèelérin, òbé ti ó jé bale Ìjérù, ìran Ègbá ni Òbé jé, nígbà tí 
Aálè 
jé ìran Tápà, gbogbo won jo n se ìpàdé ní òdò Sòún Ògúnlola, 
wón sì fi se alága. 	

orúkootí náà ni oti ewe. Ìyàwó Ògúnlolá je bábá ìjèsà kan ní 
Owo, 
nibi ti wón ti jo n sòrò lówó ni Sòún Ògúnlolá wolé, èdè àìyedè 
dé 
láàrin Ògúnlolá àti baba náà, Sòún si lu bàbá náà pa. 
	wón fún Sòún Ògúnlolá ni àrokò pé kí ó lo fun Aláàrin, bí ó ti 
débè, ó so fún Oba pé òun yóò bá won ségun elémòsó ti n pa 
ará 
Òyó. Ògúnlolá bá elémòsó jà ó sì paá ni ó bá gé ori rè, o sì gbe 
fún 
Aláàfin. Ògbórí elémòsó ni o di gbomoso. 
	Akínkanjú ti Ògúnlolá jé yìí ni o jé kí ó jé Olórí fún àwon Oba 
aládé tí ó wà ní agbègbè Ògbómòsó. 

	Lára àwon Oba aládé náà ni Oba Arèsà, Oba Ònpetu abbl. 




#Article 47: Ọba Ònpetu (1591 words)


Oba Onpetu

ÀLÀDÉ(OMO ISÉ FOYÁNMU)

Ó dilé wa lóhùn-ún òòò

Témi bá n lo sónà token òkun lolórí omi, in 

Mo fé lolé Oba bí adé ò mèedi òjé aa dígò sorò 

		

Omo afínjú eye tíí mumi lágbada tòdò tí mo n bà lonà èbì, 
Òró gangan ni wón fomo odó fún odó òòò,

N lé ni lóhùn ú nose okúmorò lónpetu, 

Lóòró gangan gan táwo todò lónpetu 

Ìda kàlà n baba mi àgbà kan ó tó mùko àdò mònyàn 

Ìyá ò dámi ní àgbalè rí, n dúró gangan le fi múmi ní omo

Obí n jesu kò wale írí, 

Mo bá tòde baba mi lo, 

Omo obí tàlùpò lówó won ò wasà,

Obí, obí te túkùú ò gba toríigi keke 

Omo Oba gbélo, gbébò lebì. 

Mo pàdé egún kan lókè lààká o 

Ojó ò t	òòjó, oojó ò tojò, 

Tí mo pàdé egún kan lókè lààká o, 

Mo rò pé were ò tètè dami mo pemi ni in, 

Témi b	á n lo sónà be mo monlé e wa, 

Ó ní banyan ò gòkè, tó dòkè kó mo on rókè, kómó on bo á 
sísàlè èè

		2	Ó ni ò ní bóun dé pálò baba òun 
			
Mo ní n bo ni in?

			Olóun lomo èbì òjé a dígò soorò 

			Mo bèèrè, mo bèèrè lówóo láyèwú n jósí òòò 

	Ólólúefón leni tó kókó joba lójèé 

	O lólú eyìn ló tèle

	Mo níró loo pa 

	Mo ní àwon lomo Oba mínrin, 

	Àwon lomo Oba mìnrin

	Omo Oba òmìnrìn mínrín tolú òmínrín tó kókó tile-ifè wá 

jònpetu, 

	Eléyun nì baba tó bi Obandí, 

	Obándé un ló bí ògánndolè 

	Ògándolè un lóbí Ona dede 

	Obadede un lóbí ifátólú 

	Ifátólú un baba Àsàmú Atóèbí eni tó kókó degbó òòjé  tó ò 

	Àsàmú òhún un ló sore onílè 

	À sore onílé 

	Un ló sore Olóólà 

	Un ló dìyekan won 

	Olóólà ohun nííjé abú-bí ekùn-mo-pani-je 

	Aké kaaka kí olórò ó gbo baba òtún àgòrò

	Òtún àgòrò, kó tó kolúdé, òkìkí amúlè bí ìbon 

	Òkè léyìn pòrò 
	
Akìí kamo fónbí, un ó bi t`mi pòpò Oba mèdì òjé maa dígò sorò 

	Lókùú Olójà lodòjé ilé 
	
Omo afínjú eye tí í mumi lágbada 

	Témi bá n lo sónà bè mo mo on lée waaa 

	Ojó ò tójó 

	Ojo òò tojò 

	Ìyàwó Olúòjé ó lo sí àwon ona èyìnkùlé 

	Ó lo rèé sègbònsè 

	O rógun lókèè odò loogun bá sú dededee

	Un ló bá sáré wolé 

	Ó ni baálé  wa, òlóòdè e wa 

	Ó ni wá wogun lókè odò, ogun sú dededee

	N baálé  re bá kápó, ó kórun 
	
Olúòjé ó kófà 

	N ló bá sòló  

	Ó wàgbo sòló 

	N ló bá lógun lo 

	Ìyàwó lo sí ònà àwon èyìnkùlé n

	N ló bá rógun lókè odò n logun bá su de de de, 
	
Ó ní baálé  wa, olóòdè wa 

	O ní wá wogun lókè odò ogun sú de dè dee, 

	N ní baálé re, n lo ba kápó, 

	N ló bá kórun
	Olúòjé ba wàgbo sàlàà, n lo ba wàgbo sòló, n lóbá lógun lo 

	Lóòtó ní, béè ni, òdodo ni 

	Ìgbà tó di ní sègbè eléèketa yí èwè wèwè 

	Lóòtó ni béèni òdodo ni 

	Baálè, ìyàwó bá lo sónà oja 

	N ló bá rógun lókè odò, 

	N logun bá sú de de de 

	N ló bá sáré wolé wá 

	Ó ni baálé won, òlóòdè wa 

	O ní wáá wogun lékùlé re ogun dé dan dan dan an 

	N ló bá kápó 

	N ló bá kórun 

	N ni ún bá n lógun ún lo 

	Ó lógun ti ti ti 

	Owó re ò bógun 

	O lógun tí tí tí, lówó re ò bógun

	Ìgbà tó lógun tí tí tí ogun jìnnà 

	N logun bá polúòjé ò ò ò 

	Ó polúòjé so sáàrin ììgbé òo 

	Won retí Olúòjé tí tí tí, won ò ri 

	Ìgbà tó dojó èkejì 

	Ni wón bá fín wá Obi á kiri 

	Igbà ti an waja Obi ti an fi woba kiri títí 

	Wón bá koba láàrin ìgbé òo 

	Níbi tógún paá si ò ò ò ò, 

	In wón bá kàn-án níhòhò 

	Kò sáso kankan lára re 

	Wón léèse, 

	Èétirí enìkan kìíri, enìkan kìí rùkú oolójà nihòhò, 

	N wón bá mája Oba

	

	Ni wón bá bó awo re 

	Ni wón bá fi bo Oba 

	Ni wón bá n pé àbáà dáso epínrín lé epínrín, 

	Kòtíì táso òjé mu ròrun aso aláso ni, 

	Èbáà dáso kókò lagbàlá alé 

	Kòtíì táso táwon òjé mú ròrun aso alaso ni, 

	Kée dáso kókò láàrán 

	Kèè táso tólúòjé múròrun aso aláso ni 
	
Awo ajá pélénjá  pèlènjà pélénjá

	N laso òjé é mú pèkun 

	Moparun yékété etí I yemetu

	Ìrà mokò un o sòkùn fún won lónà tèbì 

	Omo gbálújobi, 

	
Sùsú lelénmò bínú, eléruku jámò 

	Akìí bèèrè àgbà nílé Olúòjé mo olórí adé ò ò ò 

	N jé nú lé lóhùn-ún san àbi ò san 

	Bí ò bá san mó, baba anìnùn ló dà hun un

	Témi bá  n lo sónà an bè è, mo mo on le e wa aa 

	Àlàfià ke wàà bí o ? 
	
Àjàmú ní n be lólúòjé níhà hin ò, 

	Àjàmú ní n be lólúòjé mó on gbórò enu mi 

	Tí ùn n bá n lo sónà be mo monlée wa 

	Bóri gbeni gbeni bá gbeni, 

	Àtàrí gbènyàn gbènyàn tí an ba n gbàwon ènìyàn 

	Oò póríi taa ní ó mo gbè è o o o ? 

	Lóòtó ni béè ni òdodo ni, 
	Òri sàlàkó, oníìlí ò fé ó tú  

	Agbara-bi-awú abáni gbélé ní se bée 

	Òjúòjú elérù gbérù 

	Ó tì lójú elégàn mo rèé tamó baárú 

	Sàlàkó, ni kúrú níhìn-ín, lóhùn-ún 

	
Aso pami un kú in ní lu kára bí ajere 

	O láì wíni loran kó sìì di teni 

	Oníkálùkù kó yáa senu ti è láàbò 

	Bóri gbeni gbeni báa’gbeni, 

	Atari gbènyàn, bí won bá gbawon ènìyàn, 

	Oò póríi taa ni ó mo on gbèè ó o ? 

	Àjàmú mó on gbórò enu mi 

	Abídoyè Àjàmú tí n be lólúòjé lòò ni o, 

	Òò pórí taa ní ó mo gbèè o o ?

	Lóòtó ni, béè ni òdodo ni, 

	Oríi Bóládé, bí ó ti mo on gbè ó tòó pin ni 

	Àwon omo Atóbatélè kó tó wáá joba 

	Bémi bá n lo sónà bè mo molé wa aa 

	Àjàa`mú àró afúgò sorò 

	Àjàmú àró okúmorò lónpetu mo aparun jékété etíi yemetu ìlá 
mokò 
un ò sokùn tún won lónà an tèbì 

Témi bá n lo sónà be, mo monú ilé waa 

		

	Orí Adéolé bí ó ti mó on gbèè ó ótóópin in in 

	Ò póri ta ni ó mo gbèè ó o ? 

	Orí òsékùnmólá, bí ó ti mó on gbè e o tóò pin ni, 

	Ò pórí ta ni ó mo gbèè ó o ?

	Orí Atóyèbí bí  ó ti mó on gbè è o tóò pin ni in 

	Ó póri  ta ni ó mo  gbèè ó o ? 

	Orí Atóyèbí atówúrà sabàjà 

	Atóyèbí Alárìnje è baaka, abi kété kété babaáje ní tako 

	Ìbaaka bàbà sojú òtún ní kànnà kànna kànna 

	O ní, kì í se pésin baba enìkan màrà 

	Kìí jé pésin baba enìkan mo òn jó 

	Sùgbón esin Atóyèbí 

	N lo mò ón jó ju taráyòókù lo 

	Abi kété kété baba á jó wariwo ojú ogun 

	Àbénté ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo 

	Àbèntè ta, n lorúko tó bí baba Oba lómo 
káloolé  lónìí mo jákàn mo on jììgan bìbaaka bàbá soojú òtún 
kànnà  	

O pori ta ní ó mo gbè ó ò ò ò ò ?
		

	Eja ló nibú, bí ó ti mó on gbè ó tó ò pin ni 

	O pórí ta ní ó mo gbè o ? 

	Adédoyin, Àgbàkiri Òsùn sí, 

	N wón n yoko Efúndélé lénu 

	O fárí kondoro o fiyawo kan, babaa lúfóyè

	Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóòpin ni in 

	Témi bá n lo sónà bè mo mo on le e waa 
	Ò póríi ta ni ó mo gbèè ó o 

	Témi gbogbo Oba sónà bè mo mo on le wa 

	Bórí gbogbo Oba wònwònyi dááko bórí won ó ti mó on gbèè o 
tóò pin ni 

Témi  bá n lo sónà bè mo mo on le wa aa 

Àlà e wà bi ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ní tiwaaa?

		

	
Ojàre òsà làbábi níyìn yò 

	Àjeku, a jèkàà làbá lókèrè 

	Èmi náà làbá bi lókì orin mi 

	Orin láwèéréke, orin àwérèke

	Orin asínsínndada, asìnsínndada 

	Bàtá ògèdè
	
Saworo Òkótó 

	Atiro ò yàrìnjó 

	Àrìnjó ò yeni ti n tiro

	E kilo fún mo lárìnjó 

           Ki molárìnjó mó on mésè rè le le le 

           Témi bá n lo sónà be mo mo on lé e e wa a a 
           Omo Oba n mínni 

	Omo Oba minni 

	Omo Oba òmìnnì mínní tolú òmínní to kókó tile-Ifè wa 
jònpetuu 
	
Témi bá n lo sónà an bè mo mo on lé e wa aa 

	Bóri won bí ó ti mó on gbèè ó tóò pin ni in 

	Tí un bá n lo sónà bè mo mo on lé e wa aa 

	Inú ilé gbogbo kàà sí nkan kan an ni tiwaa,  

	Èbì òjèé a bidò sorò 

	Lótùnún Olójà lodoje ilé, 

	Omo afinjú eye tíí muni inú agbada 

		Orin: 	Àlùfáà ni ò ya ní wá 

		Ègbè:	Bódún dé aá fòkó sebo 

		Lílé:	Àlùfáà ni ò yà ní wa 

		Ègbè:	Bódún dé aá fòkó sebo 

		Lílé:	Àlùfáà ni ò yà níí wa 

		Ègbè:	Bódún dé áá fòkó sebo 

		Lilé: 	Àlùùfáà ni ò yà nííu wa 

		Ègbè:	Bódún dé aá fòkó sebo o o o . 

ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA  KOKO NÍUN ORÍKÌ OBA ÒNPETU

			     Akin nílé 

			     Akin lógun

			     Òràn ni mo yàn, un ò yankú 

			     Òràn mo yan, un ò yàrùn 

			     Baba ni á yènà àyèbá 




#Article 48: Ọba Ìrágbìjí (535 words)


Oba Iragbiji

Kábíyésí Oba 

Oba tótó Oba ìrágbìjí 

Àbíyèsí Oba 

Oba mo fé pè n kò ní mu emu 

Oba ni mo fé pè n kò mu gòrò 

Àbè togún ràlú onmo ará lósìn

Téní wíjó ará lóbòkun sá loba ìrágbìjí n jé.

Ònkókóló omo oníyán kónkólóyo 

Omo bárígídí níyán ògún 

Omo arílù mó lulu fún ìrà

Àrílá ílànkí mo gbé òkè je nàmùn 

Gbéléwadé mo gbélé se bí Oba 

Omo Òké gbélé wùsì lónà tòrà 

Anal mo kéde jègbe 

Ará mú lege ará òkun esè kè 

Omo òkan ti yí lulè Ó kù okan 

Omo olórò kan òrò kàn 

Èyí tí fáwù lógànjó yányán

Gódógódó Ilé won kò gbodò sowó odó poro 

Béè ni alògì kan won kò gbodò solo ògì sàrà 

Omo kékèké Ilé won o gbodò sunkún omú 

Èyì tí ò bá sunkún mo lórò ni yoo mo gbe lo. 

Omo òkè kékéké ni yíkè yíkè yí láyé.

Àbè togún ràlú omo arà lósìn 

Téní wíjò ìjèsà kò rídìí ìsáná

Ilé loní Owá ti mú iná roko 

Àbè togún ràlú omo arà lósìn.

Mo tún yí yun tì kédéngbé

Ònyín mo tún lo re dé òkè àgbò. 

Oba tótó mo lémi kò perí Oba 

Oba won n perí e ní Sókótó 

Oba ni wón n perí rè ní Sàbàrà 

Oba ni wón n perí rè nílè ìrágbìjí 

Oba olókùn esin 

Ará Ilé mi abi ìrù esin mi tìèmì

A gbún esin ní késé à ló mò jó édòko 

Gbogbo ara esin wón wá koná sasa 

Oba kólérán tí n retí eni tí yoo tè fun.

Oba n náà ní í be lónà ti òkè àgbò.

Àbè togún ràlú omo arà lósìn 

Téni wíjó ará lódó kánkán

Èyin lomo olóyè nílé omo olóyè lóde.

Oyè náà won kò ní pare mó yin lówó.

Orí àpéré yoo gbé yín dòyè baba èyin 

Èyí tó n be níbè won kò ní kú mo yin lówó

Oba tótó àágbìgí mo lémi kò perí oba 

Oba ni n be lónà ti ìjèsà àbè 

Ìjèsà àbè togún ràlú omo arà lósìn 

Téní wíjó ará lódò kánkán. 

Mo onípokítí Ide Ikú kò ni pa Oyàdókùn wa 

Ìjèsà ìsèrè onílè obi 
Omo ojú rábe sá mó gbódó pea be lórúko.

Omo ojú réjò ata wàrà 

Sòbòrò la bí ìgbín kò fi abe kan ara.

Àwon ni omo olóbìkan òbìkàn 

Èyí tí ó kò bá fé won ní wò sílé

Èyí tí ò kò bá fé won a wò síjù 

Eranko igbó á mu soko je 

A kì ki Ìjèsà kí a má je Obi tógbó. 

Tí e kò bá rí obì tógbó

Kí e wá gba Obì lówó mi 

Àwon lomo olódò kan òdò kan 

Tósàn wéréke tó sàn wèrè ke.

Tí ó dé èyìn èkùlé osólò tó di àbàtà 

Èyin lomo tí e bá jáwé kan 

Eègbá kan ni 

Bí e bá já méjì 

Eègbá méjì ni. 

Tí e bá já méta 

Eègbá méta ni 

Ò pé pep e aso won lóde ìgbájo 

Elégbòdò ni aso àwon ìjèsà 

Èyí tí e bá ri lójà ni kí e rà nfún wá 

Kí n ró jó Olóye lo 

Torí a kà jò olóye dun ìran baba yin

Àbè togún ràlú omo arà lósìn 

Mo bá àágbìjí relé

Mo bá àágbìjí relé.




#Article 49: Alókò ti Ìlokò-ìjèsà (872 words)


Omo ògbágbà sami sile 

Àgbágbá Ilé ria se é sun 

Kí an fònìyàn le ki an mérèé dú 

Omo òréré kóni níjanu 

Omo àgbágbá sami sílé

Àgbágbá ilé ria see sun 

Mesi oko ri wa 

A kìí bani jeku kan abàyà suésùé

A kìí báni in sisré òjá finfin nílokò 

Oso ìgbà mo fi gbígbin n sèye òkè ilokò 

Wón nit ó bá gbin níbòmíràn won a ni ogun ló dé 

Ogun ò mò dé Àgùntan ni 

Àgùntàn oke bàbá lashosre ló n joko nígbà náà 

Omo olórò kan òrò kan 

Tí won fi n se lóròlórò ìbà tetè 

Ilórò agba aiku ile wa nílokò 

Èje ló bí fún wa 

Omo òréré ko ni nijami 

Ko dàíjù kó dá ni ní kòró boko 

Omo oréré o pojú wode ìjèsà míbò 

O ni ti won kò bá poju wò ó 

À remo nílé re 

Omo agbagba sami síle lo sélé yà ònà ìlokò 

Àgbágbá Ilé ria se é sun 

Ibi ti won feniyan sile ti won gberee ru 

omo olójà àlténí fún

Àwon to  bójà ni be ki ni won o se 

O ni bi mo boja ki ni màá se nítèmi 

Se ni n bá ro pòsí ide

Ti n bá ròyìyà iyùn

Se ni a ba gbóità kalé ki an to ru ìlokò ka lo gba’run 

Omo ògúnyán baba ba lérí ota kólórun bùje nígbórò 

Éyin lómògbà lómógba rí yèyé ria nígbó òsé 

Se ni méwàá ní fobi aperiri wò mí 

Obì aperiri Ilé gbara oso ùsì ònà Ìlokò 

Obi apèrírí lúpaa ra nólè kale

Omo olóro a fii gbágùnmòkèkè kalè 

Omo olórò an fi í sori èsí wonin nígó òké 

Èsí Ilémi ko bàmí àbàyè ni e rè 

Kó bá ti la ba omo elomirin ke wa je èsí 

Esi pajá je o fegbe laa seun ni mùrè ògègè ria 

Omo olórò un fi i se hóròhórò ìbàtetè 

Iloro a bolórò a remo nílé re 

Iloro agba aiku ria nílokò èje lo bí kò á 

Omo olorere kó ni níjanu ‘

O daiju kí an dá ni ni kòró bo ko 

Iba mi kára oní mure Agege a 

Baba mi kare oní mùrè àgègè o

Ajagun si òtè wonrin wónrin 

Òjagbáríigba òkè Ìlokò 

Omo oboko jà padìye oko je 

I be si ti sájí oko àgbò n ba gbà 

N ba gbagbo tó sàmù rederede 

N ba gbòbídìye bàyà péke

Omo olúygbó aré o 

Asébi gbodidi emi 

Èlúsémusé 

Elufagba sile ka ma ba silé yà o 

Agba gòkè bèrè mole 

Kómo alókò mó baà nà toto lórí omi 

Àgbágba òkè nawó kanlè é mú ohun oni í je 

Oní mùrè àgègè n lé

Bàbá mí káre onimùrè àgègè o 

Me mo roni kebì a pè run òní 

Obi o peru ni para e jólè kíká

Omo asoro de mèkun kèkun 

Omo olórò a fi í  kun olójà lóta e fun 

Omo olórò a fi í  kun hóròhòrò ìbà tetè 

Horo a boyún 

Hóró a remo 

Hórò a gànyìn bì meje lo bi n Ilòkò 

Onìmùrè agegé nlé

Bàbá mi káre  onimùrè àgègè o 

Omo obóko já padiye oko je 

O ni bi ko si ti saji oko agbo n bá gbà 

N bá gbagba kò í bàmú rederede 

N bá gbòbídìye bàyà péke 

Mo ra gbagiri o 

Olugbo are o 

Asebi gbogogo okun 

Asebi gbodidi eni 

Elu fògbàgbà o sami súlé

Ka ma ba sulé ya o 

Onímùrè agege nle 

Bàbá mi káre onímùrè agege o 

Omo oloro a fi pa hórò hórò ìbàtetè 

Hórò á boyún horo á remo 

Horo a gànyìn bí meje lóbí 

Onímùrè àgègè nlé

Bàbá mi káre onimùrè àgègè o

Omo Ajagun sia ko omo ló reni 

Àjàgúnsi lo lereja to fi wa bogun níjèsà obokun 

Owá mò ni n jíle ní ogboní lásòrè 

Baba mi káre oni mure Àgègè o.

Omo okeinísà Ategboro esu 

Ki mo ro poke inias nisu tii ta 

Mé ra méwùrà dé bè. 

Tori kísu mo baà tàtawòde 

Kí mo jògèdè aigbo loko 

Ki me ba ti jalè 

Se ni a jo a jígbo 

Omo Alágádá kilo fólè 

Àgádá farumo 

Ó fa rùmò 

Eni bá ti pé loko nijo náà 

A je wí pé ó ni ohun tí n se 

Alákàtàkì á kilo fólè 

Selége tìrege légbòrò 

Òrò sí bá yèpè 

Ó tun fi báyín erinlá 

Ó wá fi mu okuta látìbà 

Oloro lo làtìbà 

Ogboni oge lo lodò agidi 

Àgbàrá atiba gbómo paroko sórí òsé

Ara ojúgboro ò gbó 

Èrò àtìbà ò mò 

Omo arí herehere enu gbéde yàde 

Oníjukùn so agogo mo ìrókò 

Àgbà iwoye so agogo mó kun 

Eran yòkòkò mù 

Omo ògbùrùkù yàkè 

Ogbùrú yàkè o dabi kò papò somijè 

Oníjùkù àgbé

Omo abìdèdè ònà omi 

Obi ko wò ó séun eni 

Yè é é hò sénu eni 

Kó hò síjù 

Omo eranko á fije 

Omo olobi yèé ó ho 

Kó petu nígbó àgbó 

Tòótó lobi hò 

Tòótó letu kú nílé ni 
Irin kí mía rin 

Kí màa bóba relé ògún àlròtélè 

Oba dirù sílè 

Ojú roni koro koro bi uwo 

Omo bàtá kumirin babe gèru nílé ògbóni oyé 

Loro lo latiba 

Ogboni lo lodo agigi nílé mi 

Omo elékùn ònà kí an kàn fide se nílé ògbòni 

Omo elékùn ìgbòrò àwíhò 

Èkùn ònà kóó fòó san ni bí òyìyè 

Bàbá mi káre onímùrè àgègé o




#Article 50: Àtáọ́ja Òṣogbo (523 words)


osogbo jé oba ìlú ayé àtijó ilè Òsogbo ní ìpínlè Òsun

A kì í joyin ká gbàgbé adùn.

Enu àgò bàbá ìbà o.

Oòmulè o.

Àjàní Òkín. 

Mo juba baba à mi.

Pópóolá omo Adédoyin

Àjàní Òkín.

Mo fé kí oba ìlú òsogbo.

Morónkólá omo òkè bí Oba aláyélúwà.

Àlàmú ÒKín, Làdiméjì Lálékan.

Ìranolá Morónkólá a bi baba joba.

Taani ì bá lóba méjì tí ò fáyé lójú.

Àlàmú Òkín lóba méjì 

O tún n sènìyàn rere.

Morónkólá Oba Olóríire.

A bà gbàlá tó kokò sáré.

Àgbàlá Àlàmú ju Oko baba elòmíràn lo.

Omo ìjèsà tó gun làlú.

Morónkólá Oba Olóríire.

Elégòdòmì aso ìgbájo.

Elégòdòmì aso ìyèlà.

Èyí tó dùn ni e rà fún mi wá.

Kí n ró n jó ló yè ìjèsà 

Ò sere adé eléní ewá.

Béwùúlè o má so bora.

Omo Ajólówu.

E wòó nílé ìré. 

E wòó nílé Olórò níjèsà abé.

A ríléwó ní mòkun.

A bèdè kirimì ní ìjèsà.

Láì jé mo ro Àlàmú. 

Láì ro Morónkólá.

A bi baba je Oba 

A bile gbágà léyìn.

Àlàmú Òkín. 

A bilé gbágà láàrin.

Ojó ojó kan ò dùn.

Ni ojó  a fé yan omo oyè ní Òsogbo.

Gbogbo omo Oba dúró gégé bí Ogun.

Jagun Akínsòwòn di aláfèyìn tì.

Ìyìolá Morónkólá.

A bi baba jóba.

Akogun Òsogbo àgbàlagbà oyè 

Omo Folásodé Lólá.

Salátìléyìn Oba Morónkólá.

A bi baba j’oba.

Òsà Àkàndé lalátìléyìn Oba. 

Morónkólá a bi baba j’Oba 

Ìyálóde Òsogbo .

Omo Adélékè.

N náà ló salátìléyìn Oba.

Morónkólá a bi baba j’Oba.

Àti awo àti Ògbèrì.

Won ò tètè mò pé.

Jagun Akínsòwón sòtító.

Pé Lápàdé lobá kàn.

Omo Aládéyófin.

Àlàmú Òkín j’Oba ìlú tòrò kin kin.

Morónkólá Oba Olóríire.

Àlàmú omo Mátànmí lósogbo.

Mótànmí aní Kanngúndù 

Omo àkógbé alágbàborò.

Mufúolájé baba Mówunní. 

Amúgbùrùwá fúo.

Baba Olúgbèjà.

Láyànféélé baba Oyin dà.

Olá aláyélúwà j’Oba káyé ó leè rójú.

Ò joyè lógun omo Oba.

Ò joyè tán fará è módò.

Ará níu gbe ni.

Egbàá ò gbe ni.

Àtélewó kì í pé Lájobí.

Lójó Mátànmí n fò de sòkan.

Baba béeni àtànpàkò kò yara è lótò o.

Òde gbangba kò sé dààsè sí.

Lásojú ìlú kan diè-lójú òde.

Àwìrì omo selé oko owó e dan.

Àwìrì tanwì oko owo e dan. 

Ò gbó èlùbó Òsèlú orí emo oko Arinkékànbi.

Alátise ò rómo róye.

Ò rómo róye baba Olúgbèjà.

Oba ò rómo ìlekò.

Aláyélúwà baba ‘Lábímtán.

Ò joyè jogún omo Oba.

O joyè tán fará è módò.

Ará ní n gbe ni.

Egbàá ò gbe ni.

B’Oobásùn bóobá jí.

Àlàmú Òkín, Móojúbà baba à re.

Àjànà kan ó mó pefòn léjó mó.

Oláa baba kálukún ni kálukú n je.

Àlàmú n je Oláa Mátànmí láàfin.

Morónkólá abí baba j’Oba.

A bi àgbàlá tó ìkookò sáré.

Àgbàlá Àlàmú ju oko baba elòmíràn lo.

Èmòilègùnlè baba Gbógbéjó.

A dàgbà Ládìgbéjó. 

Baba Ládàpò.

Bàbá à mi Àlàmú.

A à mo ibi tí yó mo ilé yìí dé.

Omo Mopé.

Àlàmú Òkín.

Bó parí òkanmòkan.

Morónkólá abi baba j’Oba .

Kábíyèsaí Oba Òsogbo

Oba  to léducátìon.

Tó lógbón lórí.

Kábíyèsí Oba Òsogbo.

Iyìolá omo Mákànjúolá.

Kábíyèsí Oba Òsogbo.

Oba tó léducátìon.

Tó lógbón lórí.

Kábíyèsí Oba Òsogbo.

Iyìolá omo Ládéjobi.

Kábíyèsí Oba Òsogbo.




#Article 51: Tìmì tí Èdè (567 words)


Timi ti Ede

Timi Ede

A à  ní joyin, ká tún gbàgbé adùn.

Òrúmo gégé láoyè ako ekùn akùnyùngbà.

Gbóyè ólá Àkànjí ì mi Láoyè tó tóyèse. 

Àgbàdá tolómù omo kélébe .

Àre lágbà lóyè bí ògèdè. 

Àkànjí omo Àjénjù 

Àyà mi kò pé méjì, n bá fi òkan fún omo Ojo. 

Àgbàdá ta lómù omo kélébé.

Ò ránmo ní isé fàyàtí. 

Àkànjí ì jí lo .

A ò rí okùnrin Ogun.

Àgbàdá talómù omo kélébé.

Ìgbà tí ò sí láyé mó tó kú.

Fólórunsó, Ajífòní baba

Baba Bólánlé Oláníyì 

Ajítòní Ajàgbé. 

Olá à re ì ‘dèra ni 

Fólórunsó omo lórí demo 

Àjàgbé omo Béllò 

Àjítòní aran ee deyin.

Béèni àgbo o won 

A sì ti àn ti ròrò ti ròrò 

Ajítòní Ajàgbé.

Síyán ti e dé pinnu ara.

Fólórunsó omo lórí demo .

Fólórunsó.

Orí Oba ni ó bi wón. 

Eni tí n bá Obá á je .

Tí n sòrò Oba léyìn .

Ori Oba ni ó bi wón .

Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun. 

Orí Oba ni ó bi wón.

Eni tí n bá Oba á je.

Tí n bá Oba á mú. 

Orí Oba ni ó bi wón .

Ajítòni Fólórunsó.

Àjàgbé mo gbà fún Oládòkun.

Tìmì Oba Ede 

O kú mèye ìbàdàn .

Ajítòní baba wa.

O kú mèye Òsogbo.

Fólórunsó omo Béllò 

Kò sí ibi owó ìjà erin ò mà mà tó. 

Owó tó Sókótó.

Owó tó ìlorin.

Owó tó ìmèsí olójà òkè.

Àjàgbé owó tó ìlú Èbó.

Oláníyì ìwo lomo Eégúnjobí .

A ó lese tàì leè kó .

Bée bá dé ilée wa lóhùú.

A ó le se tàì le kose kó o 

A ó lese 

Fólórunsó lerí yen.

Àlaré aláwàdà.

		Àjàgbé lerí yen.

Àlaré aláwàdà.

		Àjàgbé lerí yen.

		Àwàdà laré yìí.

		Aremo n be lówó o e e e e 

		Aremo n be lówó. 

Àwàdà laré yìí o .

Aremo n be lóó o eeeee

Aremo n be lóla.

Ikúmóruwá Olórun ló lóògùn.

Kò mò sónísègùn tó ju Olórun lo.

Olórun lo lóògùn

Ikúmoruwá, Àjàgbé Oladokun.

Iró, Iró. Iró ni wón n pa.

èké, èké ni won n sa.

Iró enìkan kì í bá Oba á jà, iró. 

È báà pa àgùntàn, àgùntàn 

È báà pa tòló tòló olórí eye.

Omo tí Olórun yó se, ó ti sé.

Àjàgbé Oládòkun.

Ìyá àjé kú è n yò sèsè

Omo tí àjé fi sílè, ó lè pani je.

Àjàgbé Oládòkun.

A wí, wí, wí wón ò fé.

Won ò fé.

 Won ó fé.

A fò fò, fò, won ò gbà.

A bólù sílè a fi enu wí.

Àpótí alákàrà ká bí á wó.

Abánise mó sì bánise mo.

A jìnnà sátákètè kété kété.

Ojú ti babaláwo yín. 

Ibi e gbé ojú lé ònà ò gba ibè lo.

Ojú ti babaláwo yín. 

Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun.

Kùkùté ò mira jìgì.

Kùkùté ò mira jìgì.

Ení mi kùkùté ara è lómì o.

Kùkùté ò mira jìgì, 

Fólórunsó Àjàgbé Oládòkun 

Kùkùté ò mira jìgì.

Kùkùté ò mira jìgi.

Eni ó mi kùkùté ara è lónìmo.

Kùkùté ò mira jìgì.

Fólórunsó Ajàgbé Oládòkun.

Orí Oba ni ó bi yín.

Orí Oba ni ó bi yín.

Eni  tí n bá Oba á je 

Ti n bá Oba léyìn.

Ajitòni.

Orí Oba ni ó bí yín.

Ikúnrúwá, Àjàgbé Oládòkun.

Orí Oba ni ó bi yín.

Eni tí n bá Oba á je.

Ti n bá Oba á mu.

Tí n sòrò Oba léyìn.

Orí Oba ni ó bi yín.




#Article 52: Olókukù ti Òkukù (1222 words)


 –OBA ABÍÓYÈ OLÚRÓNKÉ TI LÁTI OWÓ RÁFÁTÙ OYÈTÓÚN –ILÉ OLÓKUKÙ

Olúrónké Abíóyè sèsó ará ìbá làlúké

Olúrónké omo orunkunkun tí n jé ó sán ngbáa

Mo dàgbà n ò tí fòrò loyè 

Àkànní eníjà mo tòsín mo mú raso 

Mo tà kòrò mo sìn sosìn sòrò loyè 

Èmí wá teléfe rà kókó 

Omo Olúrónké mo teja nlá 

Mo mú rerú were sókun 

Omo Olúrónké Àbìrókò gogongo nínú oko

Babaà mi Abìrókò kò ní yòyòyò 

Elékùlé à á pàdé

Olúrónké abilé kere níwájú ebu 

Ibájáde ò tún nlé 

Abasó gbé kóko hánu 

Abìrìn aso jèntièlè 

Elékùlé ànpàdé omo ‘Mówálé

Abilé kere níwájú ebu 

Ìsájáde ò tán n lé omo Olúrónké 

Abí bó bá máso dúdú a mú pupa 

A fèyí wìnìwìnì bora sùn

Ará odò kòsi 

Ará odò kòbìnìyàn 

Mo tólá bí eni tóyin énu

Eníjá mo tàsín mo mú raso 

Mo tà kòrò mo sín sosìn sorà loyè

Èmí wá telébe rà kókó 

Mo teja n lá mo mú rerú were 

Wón bú mi lárùpè nìjàbé osólú

Éràn oyè mo délé mo su kún sí baba wa 

Ìsèsó ará ìbálà lúké 

Mo wá délé mo súré  telé

N ó rè bá gògo lómo àgògo mi sòsò layè mokò lotìn 

Eni ó kìjàsé tí ò kiwi 

E máa bá mi ségi gangan lóri olúwa re 

Eríja mo tàsín mo mú rase

Mo tà kòrò yofà loyè

Èmi teléèbé ràkókó 

Mo teja nlá mo mú rerú were lóko 

Òtònpòrò mí yodà loyè 

Obukun wá n bá mí relé ìbálàmoko

Omo alárá ti n gesín  mawo 

Eèkí eríjà mo tàsín mo mú raso 

Mo ta kóró mo sìn sosìn sorà loyè 

Èmí wá telébe rà kókó 

Igi mélòó ní sowó níran babà re

Áwé wón n sowó àràbà kàn mà soyùn 

Nípópó oníjàbé mo ró o 

Áwé n sowó o 

Àràbà mà soyùn nípópó oníjàbé mo ró o 

Ìsèsó alárá mi won ò ní jewe 

Mo loòràn  òwè jálè nìlàkùn 

N ò jé polódòó yò símo 

Omi kúnkún tí n yayaba lénu 

Ìsèsó ará odò kòbini 

Ìsèsó ará odò kòbìyàn 

Ìsèsó ará odò Mòtólání 

Njó àwéré wón n sòwón lòwó n nú ilé wa 

Owó wá sun gbeere wa sì tiè lòtìn

Njó àwèrè àwèrè wón pàd;e jà n jàbé osólú 

Eéràn oyè mo teja dúdú mo mú rerú were

Mo tà kòrò mo sìn sosìn sorà loyè 

Èmí wá telébe rà kókó 

Eéràn oyè mo teja nlá mo mu rerú were

Àwé wón sowó o 

Àràbà kán mà soyùn 

Áwé sowó ará ìbálàmoko

Omo alárá ti n gesin mawo 

E bá n kárelé ará ìbálàlúké

E bá n kárélé omo omifunfun tí n yayaba lénu 

Ìsèsú tí mo kówè n ò kójó tí mo wá kójó tán tíjó n yo mí lénu 

Omo Olúrónké omo Òtínkànle 

Omo Mádòlótìn

Ó wá gbòtìn kan kan kan 

Ìsèsú ará odò orò 

Ará odò mòtòlénú bí eni tóyin émi 

Pí tí wón kése sùbú Oba

Babà mi àlà agemo òjó gèlè àsò

Omo bó di gigùn ó gùn

Olúrónké Obá ni bó di gíga ó ga 

Omo kòga ò bèrè lòkùnrìn kún 

Omo arógangan gún kèsewà nìyá tó bí mi lómo 

Ìsèsú ará odò mòtólárí  o 

		Aásìn-n nì won ò gbe nílé Oba gòdògògò won ò dé n 
léràn-án sè

Ebúkú wá n sé síin lénu 

Àbálàlúké omo arunkunkun tí wón n jósán agbáa 

Ìsèsú ará odò orò 

E bá n kárelé ará ìbálàwóko 

Omoalárá tí n gesín mawo 

Omo alias eníwèé òye 

Baba mi oòsà won ò gbohùn odì títí òsà sé pàyá ìkókó 

Mo síbá olá lómo ode a máa súngi so 

Baba mi Àdìsá lásáré mi èkan kìí se lásán

Bí baba ò bá ti lé nìkan 

Nkan ní baba lo 

Ará ibú aró ará àgbón ìgbe 

Ará omi kúnkún tí yayaba lénu 

Ìrókò tété modé ò gbodò sa 

Eníjó orí òrìlé baba Oyéédùn

Kì í logun ó mó mérú wálé

Láganjú à n gbó à n té é n gbopa bí ò lèrin 

E bá n ká relé o 

Ìsèsù bí mo kówè lotìn 

E bá n ká relé o 

Ará ìbálàmóto 

E bá n kárelé ìbálàmóko 

Omo orunkúnkún tí jósán gbáa

Mo dàgbà n è tíì bòrò loyè 

Omo èkè ò jé wí felékèé nòdí 

Babà mi èsìkà won ò pera è níkà 

Sápé lode èké n jó 

Omo won n jó wón n bá ní kòyi 

Èké ò tètè mò pé tòun là n wi 

Baba Lápéri Àrèmú Oyèuemí Babà mi 

Àrèmú enisànpònná se léwà lajàsé

Tálájogún wá n wó bí ení gbón ni 

Ègùn Àjàsé wá n tirí wó tònà

Ó ní bárèmú ò bá kú ló tán 

Baba Lápérí

E bá n kárelé ará odò kòbini 

É bá n kárelé ará odò kòbìyàn

É bá n kárelé ará odò mòtólání

Omo oríaré àdé sùnyàn ni wón máa n poba 

Babà mi àgbàlagbà lajò 

Ònjó àbú bànté

Orí aré arókó po wá bì ságbàdo lára babà mi abàgbàdo sòsò legàn 

Elékùlé ànpàdé

Ó ti took Omówálé se 

Omo ajímá sé n sé sègí babà mi ò jiníkìtùkùtù se hùn 

Ò sùn jáláte sùn mójúmó

Mójúmó sìn bá yowó dúdú á yowó pupa 

Omo òwàrà

Àlàdé tó ti fón sègo dà á gbó 

Ajímosìn-in nítorí aséwé nítorí aségi 

Ó ni nótorí ìlàpá ti won n wògbè sùà sùà

E bá n kárelé o 

Ìsèsún ará odò orò 

E bá n kárelé o 

Lérìn koko babà mi mòrìwò sara Ògún jìè 

Olúrónke abilé kiri mò níbòkun

Babà mi abòlè kiri mò nílè jèsà

Ìbá mómo è rè Jèsà nímòkun nì bá kú sí 

Oko Lálété

Ará ibú aró ará àgbón ìgbe 

Ará omo kúnkún tí yayaba lénu 

Ìsèsó ará odò orò 

Omo p’ptí wón kesè sùsú Oba 

Babà mi àlà agemo òtó gèlè àsà

Omo bó di gúngùn ógùn 

Olúrónké Obá ní bó di giga ó ga 

Omo à pè á joyè ogun ará ibú aró o 

Ará ibú aró ará àgbón ìgbe 

Níbo nilé yín o 

Ìsèsún tí mo kómè n ò kójó tí mo wá kójó tán tójó wá n yomí lénu 

Odò Òtìn le mò 

E ò mo bú aró o 

Ibú aró n be Òkóyè kólé 

Odò Otìn le mò 

E ò ma bú owó o 

Ibú owó n be Òkóyè kólá

Eníkòyí omo agbònyìn

Eníkòyí omo agbòn ti è rikú sá

Yánbídolú omo alérí ikú kangun 

Òsèsèkòyí omo agbonyìn 

Yánbídolú lóòtó ègin 

Omo awí bée bógun lo 

Èsó wón n rode rèé kólé

Nígba tó níkòyí é fid é olè kólé è lo 

Omo akú omo oru

Omo akú bi ó dí

Omo akú bi ti tèntèré eye ò gbodò dé

Omo akú tán gurí è gún sòyìn 

Òsèsèkòyí eníkòyí dìde

Yánbìdolú ogún tó lo 

Òsèsèkòyí wón n rode rèé kólé

Nígbà ti Èníkòyí é ti dé olè kólé è lo 

Yánbídolú omo a kú tapó torun 

Òsèsèkòyí omo agbònyìn 

Eníkòyí o ì dìde 

Omo a wí bée bógun lo 

Òsèsèkòyì omo akúmó yànyìn kórí

Yánbídoyí olóòótó ègímo 

Alérí ikú kangan 

Òsèsèkòyí omo agbònyín

Eníkòyí dìde Yánbídolú ogún wá ti lo 

Òsèsèkòyí  omo agbòntíè ríkú sá 

Eníkòyí dìde ogún tó lo ogún tó lo 

Èsó ò délé pé ogún tó lo 

Èsó ò fara rogi 

Òsèsèkòyí gbapó gbofà tán ogún wá le

Eniíkòyí wo ló ti ì le ogún tó lo 

Ìdí òyélù a ròkún

Ìdi oyélù a ròsà

Ìdí oyélù a rèkòyi ilé

Onikoyi ò í dìde ogun Oba tó lo 

Òsèsèkòyí omo àgbonyìn 

Yánbídoyí olóòótó èyin




#Article 53: Síńtáàsì Yorùbá (4925 words)


SÍNTÁÀSÌ YORÙBÁ

(1)	Kí ni Sińtáàsì?  Síńtáàsì ni èka kan gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa mú enu ba ohun ti a pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ní ìyín ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò so òrò ti ó mógbón lówó.
Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, 
	
(1)	(a) 	Mo lo sí oko 
		
(b)	Sí lo oko mo 

Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nip é ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. 

	O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. 

	(2)	(a)	Àwon  ti ó  lo kò pò 
		
(b)	 Àwon  ti wón lo kò pò 

Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí. 
Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. 

(2)	Òrò àti Àpólà: 	Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). 

	(3)	(a)	Olú gíga  lo 
		
(b)	Olú  lo

Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 

a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye. 

	Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: 
	
(4)	GB		APOR APIS

Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun  tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). 

(5)	GB		APOR AF APIS

Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: 

(6)	AF 			AS, IB, M, IBM

Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS. 
(4)	APOR:  Èyí ni eni ti ó kópa nínú ohun ti òrò-ìse ń so. OR tàbí arópò-orúko (AR) ni ó máa ń jé olórí fún/APOR. Ohun tí a máa ń pè ní olórí fún àpólà kan ni òrò kan soso tí ó bá è dúró fún àpólà yen. Fún àpeere omo  ni olórí fún (7a) àti (7b) àpólà orúko sì ni méjèèjì. Mo ni olórí fún àpólà orúko olùwà ní (7d), arópò-orúko sì ni mo yìí.

(7)	(a) 	Omo pupa 
	
(b)	Omo 

	(d)	Mo lo 

A lè bá àpólà orúko ni ipò olùwà (èyí ni a fa ìlà sí ní ìdí ni (8a), ipò àbò (òun ni a fa ìlà sì ní ìdí ni (8b) àti ní i`po àbò fún atókùn nínú gbólóhùn (wo òrò tí a fa ìlà sí ní ìdi ní (8d)). 

	(8)	(a)	Aso pupa  ti ya 
	
	(b)	O ti ya aso pupa 

		(d)	Ó rí Olú ni ilé	 

òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè tún APOR ko ni: 

	(9)	APOR ---				OR APAJ

Àpólà àpèjúwe ni APAJ dúró fún. Láti fi hàn pé OR ni ó se pàtàkì jù nínú APOR, a lè ko òfin ìhun gbólóhùn wa báyìí. 

	(10)	APOR ---			OR (APAJ)

Àmì yìí “(   )” dúró fún pé ohun tí ó wà nínú rè kò pon dandan. Àkámó ni a ń pe àmì yìí. Níbi tí a kò bá ti lo àmì yìí, gbogbo ìsòrí òrò tí ó tèlé àmì ofà yen ni ó pon dandan nìyàn. A lè fi àwòrán-atóka igi fi èyí hàn báyìí. (11) nìkan ni a lé rì nínú (9); 
Àwòrán-atóka igi (11) ní èka, ti (12) kò ní. Aróp-orúko náà lè dúró gégé bí APOR. Òfin ìhun gbólóhùn (13) fi èyí hàn. 

(13)	APOR --	  AR 

Nìgbàkúùgbà tí a bá tin i a rópò-orúko gégé bi APOR, arópò-orúko náà kì í ní èyán nítorí a kì í fi òrò mìíràn yán arópò-orúko ní èdè Yorùbá béè ni a kì í fi arópò-orúko Yorùbá yán òrò mìíràn. Àwòrán-atóka igi bíi ti (12) náà ni a ó lò fún òfin ìhun gbólóhùn (13). Ìyàtò tí ó kàn níbè kò ju pé dípò OR, a ó lo AR. 

A lè so gbogbo òfin ìhun gbólóhùn APOR ti a ti ń ko láti òni (wo (9), (10) àti (13)) di eyo kan.	     	 

Àkámó onídodo ni a ń pe àmì yìí “     ” . Ohun tí ó ń fi hàn nip é a ó mú òkan nínú AR àti OR (APAJ). A ti so télè pé ohun tí kò pon dandan ni àmì yìí “(    )” ń fi hàn.  
			

 (17)	(a)	Mo  lo 
	(b)	Olú  lo 
	(d)	Omo pupa lo 
	(e)	 Omo pupa tí ó ga  lo 
Òfin ìhun gbólóhùn tí ó gbé (17e) jáde ni (18) tí a lè rí ni (16) 
		
(18)	APOR ---		       OR (APAJ GB)
 

Àfikún ni ohun tí a pè ní AFK nínú àwòrán yìí. Ohun tí ó dúró fún ni àwon òrò bíi tí (Omo ti ó lo), pé (Ó so pé ó lo) abbl tí a ń pè ní atíka gbólóhùn. Ohun tí tirayáńgù tí ó wà ní (19) dúró fún ni pé a kò fé fó ohun tí ó wà ní abé rè sí wéwé nítorí pé kò se pàtàkì fún ohun tí a ń so lówó. Sé e mò pé a tì lè fó GB sí APOR, AF àti APIS, a kò se èyí nítorí pé kò je wá lógún nínú ohun tí a ń so lówó. A lè so APOR mó APOR lábé APOR. Òfin ìhun gbólóhùn tí a fi lè fi èyí hàn ni (20); (21) sì ni àwòrán-atóka igi rè. 

	
(20)	APOR ---		            AS   APOR   

Òrò-àso ni AS dúrú fún 

Òrò-ìse (IS) ni olórí fún àpólà ìse (APIS). APIS ni a máà ni a máa ń pò ní kókó gbólóhùn nínú àwon ìwé tètèdé onígírámà nítorí pé ó ní òrò-ìse nínú. Òrò-ìse ni ó máa ń so ohun tí APOR se nínú gbólóhùn. Gégé bí olórí fún APIS, ó pon dandan kí òrò-ìse wà nínú gbólóhùn yálà pèlú àwon emèwà rè tàbí ní òun nìkan. 

	(22)	APIS  	---	    IS     X

			
(23)	Olú lo kíákíá 
			
(24)	Olú ra aso

	Lóòótó (23) àti (24) ni ó ni àfikún fún òrò-ìse sùgbón sùgbón (24) nìkan ni lè so pé òrò-ise rè gba àbo. Ohun tí ó fá èyí ni wí pé APOR ni àfikún fún òrò-ìse (23) sùgbón àpólà àpónlé (APAP) ni àfikún fún òrò-ìse (24). A lè fi òfin gbé àlàyé àtúnpín sísòrí òrò-ìse tí a sese sàlàyé rè tán jáde báyìí. 

		(25)	(a)	ISagb 		+    	[---APOR] 
			(b)	ISaigb		+   	[ ---0]
A lè pa òfin méjèèjì yìí pò báyìí 
		
(26)	IS  	+	[ ------------ (APOR)]

Yàtò si APOR àti APAP, IS tún  lè rí àwon àfikún mìíràn. Àwon náà ni àpólà atókùn (APAT) àti gbólóhùn onípele (GB). A lè se àtúnpínsòrí IS pelú gbogbo won báyìí, 

(27)	(a)	rí :	IS;	+ [----- APOR] Mo rí Olú 
	
(b)	wá:	IS;	+ [-----APAT ] Mo wá sí ilé 

	(d)	rà 	IS; 	+ [-----APOR (APAT)] Mo ra aso ní ojà 
	(e)	dàbí:	IS; 	+[--------GB] Ó dàbí kí ó má lo 

Ohun tí òfin (27) yìí ń so nip é tí a bá rí òrò-ìse kan, gégé bí elédè, a ó mo sàkáání ibi tí a ti lè bá a. Fún àpeere, (27a) ń so pé rí jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APOR gégé bí àfikún. (27b) náà so pé wá jé òrò-ìse tí ó máa ń gba APAT gégé àfikún. Kìí se pé àwon òrò-ìse wònyí kò lè yan àfikún mìíràn sùgbón àtúnpínsòrí tí a bá fún òrò kan ni a gbódò tèlé bí béè kó, gbólóhùn tí ó ti je yo kò ní í bófin mú. 

	Yàtò sí àtúnpínsísòrí tí a menu bà yìí, a tún lè fi òfin ìhun gbólóhùn sàlàyé APIS. 
(28)	(a) APIS --- 		   IS
		
(b)   APIS ---		   IS APOR

A lè pa méjèèjì pò báyìí: 

(29)	      APIS ---		IS (APOR) 

Lóòótó, o dàbí ìgbà pé àwòrán-atóka igi yé ènìyàn ju àkámó asàmìsí lo sùgbón à kò lè so pé òkan dára ju èkejì lo tí a bá fi ojú tíórì wò ó. E se àkíyèsi pé àayè tí àwòrán-atóka igi gbà jut i àkámó asàmì sí lo. Níwòn ìgbà tí ó jé wí pé àwon méjèèjì ni a ó máa bá pàdé nínú ìwé, ó ye kí á mò wón. 

(5ii)	Òrò-ìse Àsínpò:	Lóòótó àwon tètèdé onígíràmà ti máa ń fún gbólóhùn abódé ní oríkì pé òun ni àkójopò òrò tí ó òrò-ìse kan nínú. Èyí kò wolé mó nítorí a ti rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo. Àpeere irú gbólóhùn abode báyìí ni gbólóhùn alásínpò ìse. Gbólóhùn yìí máa ń ní olùwà kan sùgbón àwon òrò-ìse yìí mó ara won. Òfin ìhun gbólóhùn ti a máa ń lò fún àpólà-ìse inú gbólóhùn alásínpò ise ni. 

	(32)	APIS ---	    APIS   (APISn )
. 

Oun tí “n” yìí ń so nip é APIS yìí lè máà níye. E jé kí á wo gbólóhùn kan tí ó ní irú òrò-ìsè yìí. 

(34)	Adé gbé ògèdè mi fún eran je 
 

(6)  Àfòmó:	

Ní àárín àpólà ìse àti àpólà orúko ni ìsòrí tí a ń pè ní àfòmó wà. Òpòlopò òrò ni ó wà ní abé ìsòrú yìí. Gbogbo won ni ó sì ní àbùdá òrò-ìse. Ìsòrí yìí ni àwon tètèdé onígírámà ń pè ní asèrànwó-ise. Àwon ohun tí a ń bá lábé ìsòrí yìi ni àsìkò, ibá, múùdù àti ìbámu. Ìdí tí a fi ń pe ìsòrí yìí ní àfòmó nip é púpò nínú àwon ohun tí ó máa ń je yo lábé rè, àfòmó ni wón máa ń jé nínú òpòlopò èdè àgbáyé. Gbogbo èdè ni ó ní àfòmó yìí sùgbón ònà tí èdè kòòkan fi máa ń mú un lò yàtò sí ara won. Gbogbo àwon òrò tí ó wà lábé ìsòrí yìí ní èdè Yorùbá ni ó lè dá dúrò, ìyen ni pé won kì í se mófíìmù àfarahe. Fún àpeere, abé ìsòrí yìí ni a ti máa rí àwon òrò bíi gbódò, lè, máa, ta,  ń abll. Pèlú àfòmó tí a ti menu bà yìí, òfin ìhun gbólóhùn tí a ó máa ló ni (35), 936) ni gbólóhùn tí ó lè ti inú rè jáde, 

(35)	   GB	---	APOR   AF APIS 

(36)	                 Olú     gbódò lo

	
(38)	(a) 	Adé lo sí ilé 

		(b)	Mo rí Olú ní ojà 

		(d)	Òjó ti ilé  lo sí oko

	(39)	APAT ---		AT APOR

Òrò àpóné ni a máa ń bá nínú àpólà àpónlé. Òrò àpónlé yìí seé se kí ó ju eyo kan lo ó sì lè jé eyo kan. (41) ni òfin ìhun gbólóhùn àpólà àpónlé Ní (42), a fa igi sí ìdí àpólà àpónlé a sì ya àwòrán-atóka igi fún un ní (43). 

	(41)	APAP	---	AP   APAP   					 		
(42)	Adé     lo     kíákíá rí 		 

		
AF---		AS, IB, M, IBM. 

(8)	Orísìí Gbóóhùn Yorùbá:  Orísìí gbólóhùn méta ni ó wà ni èdè Yorùbá- (i) gbólóhùn abode, (ii) gbólóhùn oníbò àti (iii) gbólóhùn alákànpò. 

(i) Gbólóhùn abode: 	Púpò nínú àwon àpeere tí a ti ń lò láti ìbèrè ìwé ìléwó yìí ni ó jé gbólóhùn abode. Oríkì tí a lè fún gbólóhùn abode ni gbólóhùn tí ó ní kókó gbólóhùn kan. Ohun tí ó jé kí á lo kókó gbólóhún dipò òrò-ìse ni pé a rí gbólóhùn abode tí ó ní ju òrò-ìse kan lo sùgbón tí ó jé pé kókó gbólóhùn kan soso ni ó ní . Àpeere irú ìyí ni gbólóhùn alásínpò ìse tí a ti sòrò nípa rè sáájú. Òfin ìhun gbólóhùn tí a ń lò fún gbólóhùn abode ni (44); (45) ni àpeere gbólóhùn abódé. 

(44)	 GB ---				APOR AF APIS 

(45)	Mo ra isu 

(ii) Gbólóhùn Oníbò:	Gbólóhùn oníbò ni gbólóhùn tí ó ní olórí gbólóhùn àti gbólóhùn àfibò. Olórí gbólóhùn yìí lè dá dúró sùgbón gbólóhùn àfibò kò lè dá dúró.  

                                                                                             

GB ---			ATAF   GB		

Òfin gbólóhùn (52) lè gbà wá láàyè láti sèdá. 

	(53)	(a) 	Olú dé 
		
(b)	Ade ra aso 

		(d)	Omo tí ó lo dé 
Sùgbón a kò lè sèdá òkankan nínú (54) nípa lílo òfin (52). 
	
(54)	(a)	Ǹjé Olú dé? 
		
(b)	Sé Adé ra aso? 
		
(d)	Omo tí ó lo dé bí? 

Síbè a ó se àkíyèsí pé àwon gbólóhùn (53) ní nǹkan se pèlú (54). Gírámà tí a pè ní gírámà ìyídà onídàro yìí ní gbára láti se àlàyé ìbásepò tí ó wà láàrin àwon gbólóhùn wònyí. Sùgbón kí a tó menu ba bí yóò se se àlàyé yìí, e jé kí a wo àwon ohun tí a lè bá pàdé nínú gírámà yìí. 

Ònà méta ni a lè pín gìrámà yìí sí àwon náà ni ìhun ìsàlè, gbé aifa àti ìhun òkè. Àwon èka méjì mìíràn tún wà tí kò ní í je wá lógún púpò nínú ìdánilékòó yìí: àwon náà ni èka fonólójì àti èka ìlárògún (ìní àrògún). A ó wá yè wón won í òkòòkan. 

(i) ìhun Ìsàlè:	Gbogbo gbólóhùn ni ó máa ń ní ìhun ìsàlè. Ó wá seé se kí ìhun ìsàlè gbólóhùn kan bá ti òkè mu; ó sì seé se kí ó máà bá a mu. Àwon ohun tí a máa ń pá pàdé nínú ìhun ìsàlè ni aká òrò, òfin òrò, òfin gbólóhùn, àttúnpínsìsòrí, òfin ìsòrí òrò, ìyanra (ìyan ara).

(ii)	Gbé alfa:	Ìtumò gbé alfa ni pé kí á gbé nǹkan  kan láti ibì kan lo sí ibòmíràn nínú gbólóhùn.

(iii)	Ìhun Òkè: 	Àwon ohun tí a máa ń bá pàdé nínú ìhun òkè ni ìsòrí kòòfo, gbólóhùn tí a ti da ètò rè rú, ìse lámì kanùn (1ise ní àmì kan ùn) asé. 

(iv)	Èka Fonólójì:	Òkan nínú àwon èka méjì tí kò níí je wá lógún púpò tí a máa ń bá nínú gírámà ìyídà onídàro ni èka fonólòjì. Èka yìí nib í a se ń pe òrò jáde lénu je lógún. 

(v)	Èka Ìlárògún: 	Èka yìí náà kò ní í je wá lógún tó béè tàbí jù béè lo nínú ìdánilékòó yìí. Èka yìí ní ó se pèlú àrògún. Òfin síńtáásì lè gba àwon gbólóhùn kan láàyè tí ó jé pé èka yìí ni yóò so pé irú gbólóhùn béè kò ni àrògún. Àwòrán (57) ní ó fi àwon èka wònyí hàn wá dáradára. E jé kí á wá wo bí gírámà yìí se ń sisé. 

(11)	Gbólóhùn Ìbéèrè béè-ni-béè-kó:	Àwon ìbéèrè kan wà tí ó jé pé béè ni tàbí béè kó ni ìdáhùn máa ń jé. Fún àpeere, tí a bá so pé: 

	(55)	Ǹjé Olú lo? 

A lè dáhùn wí pé: 

	(56)	Béè ni, Olú lo tàbí béè kó, Olú kò lo 

	(57)	 Ìhun Ìsàlè/ìpìlè 

aká òrò 

	òfin òrò 

	òfin ìsòrí 

	àtúnpínsìsòrí 

	ìyanra 

	òfin ìhun gbólóhùn
 

	Gbé Alfa 

	Ìhun Òkè

Ìsòrí kòòfo 
	
Gbólóhùn tí a dà ètò rè rú 

	Ìse lámì kan-ùn 
		asé 

Ẹ̀ká Fonọ́lọ́jì 				

Ẹ̀ka àrògún 

Gégé bí a se so télè, o rorùn láti láti lo òfi ìhun gbólóhùn láti sèdá gbólóhùn bíi (58) sùgbón a kò lè lo òfin ìhun gbólóhùn láti sèdá (55). 
	
(58)  Olú lo

Síbè a gbódò lè sàlàyé bí (55) se wáyé. Ohun tí gírámà tí a ń lò nínú ìdánilékòó yìí so ni pé (58) ni ìpìlò (55), ìyen ni pé ní ìhun ìpìlè, (58) nìkan ni a ní. Ìhun òkè ni (55). Ohun tí ó selè nip é léyìn ìgbà tí a ti fi òfin ìhun gbólóhùn sèdá (58) tán ni a wá so atóka ìbéèrè mó on. Bí àwòrán-atóka igi won se rí nìyi.

Àrótì ni AROTI dúró fún. Àwon ìbéèrè mìíràn tí ó bá eléyìí mu tí a sì gbódò sàlàyé won bákan náà ni (61). 

	(61)	(a)	Sé Olú lo? 
		
(b)	Olú lo bí? 

E ó se àkíyèsí wí pé ń se ni àrótì sáájú gbólóhùn nínú Ǹjé Olú lo? Sùgbón nínú Olú lo bí? àrótì yóò tèlé gbólóhùn ni. 

(12)	Ìbéèrè tí kì í ní ìdáhùn béè ni béè kó: 	Àwon ìbéèrè kan wà ti ìdáhùn won kì í se béè ni tàbí béè kó. Àpeere irú ìbéèrè béè ni 

	(63)	(a) 	Ta ni Olú rí? 

		(b)	Kí ni Olú se? 

Ònà tí a ń gbà se àlàyé àwon ìbéèrè eléyìí yàtò sí ti béè ni béè kó. A ó rántí pé àrótì, ìyen àwomó ni a lò láti sàlàyé bí ìbéèrè béè ni béè kó se wáyé. Gbé alfa ni a ó fi sàlàyé eléyìí. Nígbà tí a ń sòrò nípa àtúnpínsísòrí òrò-ìse, a sàlàyé pé àwon òrò-ìse bíi: rí àti se gbódò ní APOR gégé bí àbò nínú gbólóhùn tí a bá ti lò wón. Ìyen ni a fi ń rí. 
		
(64)	(a) 	Olú se isé 

			(b)	Adé rí Òjó

Tí	 (56) 	kò sì bófin mu 

	(65)	(a)	*Adé rí 

		(b)	*Olú se 

Sùgbón tí a bá wo (63), a o rí i wí pé APOR kankan kò tèlé rí àti se gégé bi àbò síbè àwon méjèèjì bá òfin mu. Àlàyé tí a rí se ni pé kì í se pé won kò ní APOR gégé bú àbò, won ní ní ìhun ìpìlè. Ìhun òkè ni ó ti dàbí ìgbà pé won kò ní nítorí pé a ti gbé APOR àbò tí wón ní kúrò láàyè won. E se àkíyèsí pé tí a bá ń se ìbéèrè alápèpadà, a máa ń so (66). 

	(66)	(a)	Olú se kí ni? 

		(b)	Adé rí tan i? 

Nínú gbólóhùn (66), a ò lè so pé se  àti rí kò ní APOR àbò nítorí ta àti kí ni ó jé àbò fún òkòòkan won, òrò-orúko sì ni ta àti kí yìí. Àwon òrò yìí ni a gbé kúrò láàyè tí wón wà ní ìhun ìpìlè lo sí ibòíràn kí wón tó dé ìhun òkè. Èyí ló fi dàbí ìgbà pé won kò ní àbò. Ìgbà tí a gbé àwon òrò wònyí kúrò láàyè tí wón wà ní (66) lo sí iwájú ni a ní (63). 

Kòòfo ni KF dúró fún. Àwon 	 atóka ìbéèrè kan wà tí òrò-ìse kì í se àtúnpínsísòrí fún won. Àpeere irú won ni: 

(68)	(a)	Níbo ni Olú ti ra aso 

	(b)	Báwo ni Dàda se mú Olu 

A ó se àkíyèsi pé àwon òrò-ìse rà àti mú sì ní APOR àbò tí ó ye kí wón ní. Síbè e ó se àkíyèsí pé a lè se àwon ìbéèrè alápèpadà wònyí: 

(69)	(a)	Olú ra aso, níbo? 

	(b)	Dàda mú Olú, báwo? 

Ohun tí eléyìí ń fi hàn ni pé (69) náà ni ìpìlè fún (68) sùgbón nǹkan tí ó selè nip é àbé àpólà-ìse kó ni àwon atóka ìbéèrè báwo àti níbo wà. Abé ìsòrí tí wón wà ni a ń pè ní àrótì. Bí àwóràn-atóka igi ti won se rí nì yí.

Tí a bá lo atóka ìbéèrè tan i tàbí kí ni láti bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko olùwà, ààyè olùwà yìí kò ní í jé kòòfo. A ó fi arópò orúko kan sí ààyè yìí. Béè náà nit í a bá bèèrè ìbéèrè nípa òrò-orúko tí ó ń yán òrò-orúko mìíràn. Àpeere. 

(71)	(a)	Olú gbé ìwé Adé 

	(b)	Ta ni ó gbé ìwé Adé? 

	(d)	Ta ni Olú gbé ìwé rè

Gbólóhùn tí a tún máa ń gbé alfa nínú rè ni awé gbólóhùn asàpèjúwe.
Àbùdá Awé gbólóhùn Asapèjúwe: 

i.	A rí APOR tí awé gbólóhùn oní-tí tèlé

ii.	APOR tí ó saájú awé gbólóhùn oní-tí yìí ni olórí fún gbogbo 
awé gbólóhùn yìí. 

iii.	Àlàfo kan wà nínú gbólóhùn àfibò inú awé gbólóhùn yìí. 

iv.	Kò sí ibi tí a kò ti lè rí àlàfo tí a menu bà ní (iii) yìí. 

AGBA dúró fún awé gbólóhùn asàpèjúwe. 

(vi)	Àlàfo tí a menu ní III gbódò ní àmì kan náà pèlú atíka awé gbólóhùn asàpèjúwe. 

(vii)	Àwon kan wà nínú àwon awé gbólóhùn asàpèjúwe tí kì í ní àlàfo. Àwon yìí ni ìgbà tí a bá se àpèjúwe fún APOR olùwà àti OR tí ó bá yán OR mìíran. 

(viii)	Ó pon dandan kí APOR méjì bá ara mu nínú awé gbólóhùn asàpèjúwe. Àwòrán-atóka igi tí ó sàlàyé awé gbólóhùn yìí nì yí ní sí-sè-n-tèlé 

GB gbódò ní APOR tí ó bá ti iwájú rè dógbà nínú 

Àmì yìí I ń fi hàn pé àwon APOR méjèèjì bá ara mu. A ó so APOR; kejì di ti  a ó gbé e wá sí abé àfikún. 

Omo ni a ó gbé wá sí abé àfikún tí yóò di ti. 

(14)	Òrò-Ìse aláìléni: 

A ó se àkíyèsí pé gbogbo nǹkan tí a ti ń gbé, apá òtún ni a ti ń gbé won wá sí apa òsì. Ìbéèrè wá nip é sé apá òsì nìkan ni a máa ń gbé nǹkan wa. Ìyen ni pé se apá òsì nìkan ni a máa ń gbé ‘alfa’ wa ni? Kì í se apá òsì nìkan. Àpeere tí a ó fún wa báyìí yóò fi èyí hàn. Àpeere náà ni gbólóhùn tí ó bá ní òrò-ìse aláìléni nínú. Irú gbólóhùn béè ni:

(76)	Kí á pa àgó méta dára, 

dára tí ó wà nínú gbólóhùn yìi ni a pè ní òrò-ìse aláìléni. Àwon òrò-ìse mìíràn tí ó tún wà lábé ìsòrí yìí ni burú, dájú, dùn, wù abbl. E ó se àkíyèsi pé ìtumò kan náà ni (76) àti (77) ni. (77) ó dára kí á pa àgó méta.  Níwòn ìgbà tí wón tin í ìtumò kan náà tí òrò inú won sì férè bára mu tán, ó ye kí á lè topa ìpìlè won dé ibì kan náà. (76) ni ó jé ìpìlè fún (77). Ohun tí ó selè ni pé a gbé kú á pa àgó méta lo sí èyìn dára. Nígbà tí a se eléyìí, ààyè ibi tí kí á pa àgó méta wà télè wá sòfo. Ààyè olùwà ni ààyè yìí. Níwòn ìgbà tí ààyè olùwà kò sì gbódò sófo, a wá fi ó tí kò tóka sí enikéni sí ààyè náà. Báyìí ni a se rí (77) láti ara (76). 

Àyè kòòfo (KF) yìí ni a ó wá fi ó  aláìléni sí. Apá òsì ni a ti gbé nǹkan lo sí apá òtún. Àpeere àwon gbólóhùn tí ó se báyìí wáyé ni: 

(80)	(a)	(i)	Kí á jalè kò dára 

		(ii)	Kò dára kí á jalè 

	(b)	(i) 	Pé mo pé dùn mí 

		(ii)	Ó dùn mí pé mo pé 

(15)	Gbólóhùn Àse:  

Kì í se gbogbo ìyídà ni ó máa ń ní gbé ‘alfa’. Ìyen ni pé kì í se gbogbo ìyídà ni a máa ń gbé nǹkan láti ibì kan lo sí ibòmíràn. Àpeere gbólóhùn tí a sèdá láìgbé nǹkan kan lo sí ibòmíràn ni gbólóhùn àse. Àpeere gbólóhùn àse ni: 

(18)	(i)	wá 

	(ii)	jókòó 

	(iii)	Dìde 

Gbólóhùn ni àwon wònyí sùgbón wón jo APIS lásán. Òhun tí ó selè ni pé a ti pa APOR olùwa won je. APOR olùwà ti a sì pa je ni iwo. Ohun tí a fi mò pé ìwo ni a pa je ni pé a máa n lò ó nínú gbólóhùn àkésí. 

(82)	Ìwo, wá 

Àwon èrí mìíràn tí ó fi ìdí rè mule pé enikejì eyo ni a pe je ni ìwònyí. Nínú gbólóhùn alátapadà, eni nínú APOR àbò gbódò bá eni nínú APOR olùwà mu. Ìyen nip é tí APOR olùwá bá jé eni kìíní eyo, béè náà ni APOR àbò gbódò jé. Fún àpeere, ibì tí àwon gbólóhùn alátapadà (b) ti wa ni (a) 

(83)	(a)	*Òjó féràn Òjó 

	(b)	Òjó féràn ara rè

	(a)	*Èmi féràn èmi 

	(b)	Èmi féràn ara mi 

Òjó àti ara rè  jé eni kéta eyo. Èmi àti ara mi  náà sì jé eni kìíní eyo. E jé kí á wá wo gbólóhùn àse.

(84)	Ìhun ìpìlè: 	*Ìwo gbádùn ìwo 

	Alátapada:	Ìwo gbádùn ara re 

	Yíyo Olùwà:	Gbádùn ara re

Bí òfin yìí se sísé ní sísè-n-telé ni eléyìí. Èrí kejì nit i orísìí ìbéèrè kan tí a lè se lórí gbólóhùn àse. Ìbéèrè yìí fi hàn gbangba pé eni kejì eyo ni a pe je. 
(85)	(a)	Mú owó bò lóla / Sé o gbó? 

	(b)	Wá sí ilé wa o / Sé o gbó? 

Ìbéèrè yìí fi hàn pé èni kejì eyò ni a ń tóka sí. 
(16)	Òté tí ó de Gbe ‘alfa’: A ti sàlàyé pé ìtumò gbé ‘alfa’ ni pé ki a gbe nǹkan tí ó bá wù wá láti ibi kan lo sí ibòmíràn. Òté wà tí ó de nǹkan ti a lè gbé.

(1)	A kò lè gbé òrò kankan láti inú gbólóhùn tí ó bá jé pé APOR tí o ní olórí ni ó je gàba lé e lórí. 

Fún àpeere, láti inú àwon àpólà tí a fa ìlà sí ní ìdí yìi, a kò lè gbé òrò kankan. 

(87)	(i)	(a)	Ìròyìn pá Nàìjirià gba góòlù dùn mó mi 

		(b)	*Kí ni ìròyìn pé Nàìjíríà gbà – dùn mó mi? 

	(ii)	(a)	Olú se ìlérí pé òun yóò fún un ní ìwé 

		(b)	*Kí ni Olú se – pé oun yóò fún un ní ìwé? 

	(iii)	Tí olùwà gbólóhùn bá jé gbólóhùn, a kò lè gbé nǹkan kan láti inú rè. 

A kò lè gbé nǹka láti inú gbólóhùn tí a fa igi sí ní ìdí wònyí. 

(89)	(a)	(i)	Síse ìdáwò mérin ni ojó kan  dára 

		(ii)	*Kin i síse ____ ni ojó kan dára? 

	(b)	(i)	Kí á pa àgó méta wù mí 

		(ii)	Kí ni kí a pa ¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬¬___ wù mí? 
	A kò lè gbé nǹkan kan láti inú àpólà tàbí gbólóhùn àso.

A kò lè gbé eyo nǹkan láti inú àpólà ti a fi ìlà sí ní ìdí yìí. 

(91)	(i)	Mo ri Òjó àti Adé 

	(ii)	*Ta ni mo rí Òjó àti Adé 

	(iii)	* Ta ni mo rí _________ àti Adé? 

Tí a bá máa gbé nǹkan kan, méjèèjì ni a ó gbé papò. 

(92)	Ta ni mo rí _____________?





#Article 61: Ṣàngó (258 words)


Ṣàngó Olukoso, Oko Oya.

Ṣàngó Je Okan lara Awon Orisa ti awon yorùbá n bọ̀ wọ́a ni àjànàkú kọjá a morí nǹkan fìrí, bí a bá rí erin, káwípe a rí erin ní òrọ̀ Ṣàngó jẹ́ láàárin àwon òrìsà ileẹ Yorùbá. Ṣàngó jẹ́ òrìsà takuntakun kan gbòógì láàárín àwon òrìsà tókù ní ilèe Yorùbá. Ó jẹ́ orisà tí ìran rẹ̀ kún fún ìbẹ̀rù. Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbẹ̀rù nígbàtí ó wà laaye nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé Ṣàngó jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó di òrìṣà àrá. Ìtàn sọ wí pé ọmọ Ọ̀rányàn ni ṣàngó i ṣe àti pé Ọya, Ọ̀ṣun ati Ọbà jẹ́ ìyàwó rẹ̀. 

Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkọlura pẹ̀lú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutọ́ pọ̀ lọ́wọ́ ṣàngó g̣ẹ́gẹ́ bí Ọba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di ọ̀tẹ́yímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtẹ̀ mọ́ ọ. Wọ́n fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Ọ̀yọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lẹ́bà ọ̀nà nítòsí Ọ̀yọ́ nígbàtí Ọya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò. 

Ọgbọ́n tí àwọn ènìyàn ṣàngó tókù dá láti fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nípa títi iná bọlé wọn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sọ ṣàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bọ títí dòní tí wọ́n sì ńfi ẹnu wọn túúbá wí pé ṣàngó kò so: Ọba koso. 

ÀWỌN ORÚKỌ TÍ ṢÀNGÓ Ń JẸ́ 

Oríṣiríṣi orúkọ ni a mọ ṣàngó sí nínú èyí tí gbogbo wọn sì ní ìtumọ̀ tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n bẹ́ẹ̀. Àwọn orúkọ bíi ìwọ̀nyìí: 




#Article 62: Gírámà Yorùbá (1536 words)


Gírámà èdè Yorùbá

Gírámà ni ￼ìmò nípa bí a ṣe ń lọ àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ètò àti ìlànà ni èdè Yorùbá 

Ìsòrí gírámà ni wọn yìí 

(a) Ọ̀rọ̀ orúkọ 

(b) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ orúkọ 

(d) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ afarajorúkọ 

(e) Ọ̀rọ̀ ìṣe 

(ẹ) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe 

(f) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé 

(g)  Ọ̀rọ̀ atọ́kùn 

(gb) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀.

Girama Yoruba

Kí ni Sińtáàsì?  Síńtáàsì ni èka kan gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa mú enu ba ohun ti a pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ní ìyín ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò so òrò ti ó mógbón lówó.
Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà, 
	
(1)	(a) 	Mo lo sí oko 

		(b)	Sí lo oko mo 

Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nip é ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. 

	O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé. 

	(2)	(a)	Àwon  ti ó  lo kò pò 
		
(b)	 Àwon  ti wón lo kò pò 

Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí. 

Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. 
(2)	Òrò àti Àpólà: 	Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b). 

	(3)	(a)	Olú gíga  lo 
		
(b)	Olú  lo

Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 

	Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere: 
	
(4)	GB ---		APOR APIS

Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun  tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5). 

(5)	GB ---		APOR AF APIS

Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí: 

(6)	AF ---			AS, IB, M, IBM

Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS

Ayọ Bámgbóṣé

Gìrámà

Fonoloji ati Girama Yoruba

Ayọ̀ Bámgbóṣé (1990), fonọ́lọ́jí àti Gírámà Yorùbá. Ìbàdàn, Nigeria: University Press Limited. ISBN 978 249155 1. 239 pp. 

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ 
	
Láti ìgbà tí Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀kọ́ (N.E.R.C.) ti gbé ìlànà ẹ̀kọ́ Yorúbá fún iloé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì jáde ni ó ti di dandan láti wá ìwé tí yó ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ yọ nínú ìlànà ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ìrírí wa nip é àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ni ó máa ń ni ìṣòro lórí iṣẹ́ tí ó bá èdè yàtọ̀ sí lítíréṣọ̀. lọ Ìdí nìyí tí a fi ṣe ìwé yìí lórí èdè, tí a sì lo ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè láti fi ṣàlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ fonọ́lọ́jì àti gíràmà. 
	
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì àti ti olùkọ́ni, láì-mẹ́nu-ba àwọn olùkọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n ti ń lo ìwé Èdè Ìperí Yorùbá tí N.E.R.C. tẹ̀ jáde ní ọdún 1984, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé sì ṣe olótùú rẹ̀. ìwé Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kejì lórí lílo èdè-ìperí Yorùbá nítorí pé a ṣe àlàyé àwọn èdè-ìperí tí ó bá ẹ̀dá-èdè lọ dáadáa; a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìtumọ̀ wọn hàn kedere. Nípa lílo ìwé yìí, èdè-ìperí á kúrò ní àkọ́sórí nìkan: kódà, á á di ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ mọ̀ dénú, tí wọ́n sì lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹlòmíràn. 
	
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi tí mo ṣe Olóòtú ìwé Èdè-Ìperí Yorùbá náà ni mo kọ ìwé tuntun yìí. Mo sì kọ ọ́ ní ọ̀nà tí yó rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ láti kà nítorí pé nípa ìrírí púpọ̀ tí mo tin í nípa kíkọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀dá-èdè Yorùbá, mo mọ ọgbọ́n tí a lè fi ṣe àlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ tí ó díjú lọ́nà tí yó lè fi tètè yé ni. 
	
A dá ìwé yìí sí ọ̀nà mẹ́ta. Apá kìíni ni Fonọ́lọ́jì, Apá kejì ni Gírámà. Apá kẹta sì ni Ìdánwò Èwonìdáhùn. Nínú apé kìíní àti apá kejì, a pín àwọn orí-ọ̀rọ̀ sí abẹ́ orí kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí a ṣe àlàyé àti ìtúpalẹ̀ orí-ọ̀rọ̀, tí a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìdí ìtúpalẹ̀ náà gúnlẹ̀ dàadáa. Lẹ́yìn èyí ni a fi ìdánrawò kádìí orí kọ̀ọ̀kan. Orí mẹ́rìnlá ni ó wà ní abẹ́ Fonọ́lọ́jì, tí méjìdínlógún sì wà lábẹ̀ Gírámà. Ó ṣeé ṣe fún olùkọ́ láti fa ẹ̀kọ́ méjì mẹ́ta yọ láti ara ori kọ̀ọ̀kan. A sì tún lè lo orí kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí a ti ṣe kọjá lorí orí-ọ̀rọ̀. Ní apá kẹta ìwé yìí, a fi ìdánwò èwonìdáhùn mẹ́rin nínú èyí tí ìbéèrè méẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà nínú ìkọ̀ọ̀ken ṣe àpẹẹrẹ irú ibéèrè ti a lè ṣe fún gírámà àti fonọ́lọ́jì Yorùbá. Irú àpẹẹrẹ ìdánwò báyìí yóò wúlò fún àwọn tí ó ń sẹ́ẹ̀tì ìdánwò àti fún àwọn olùkọ́ pẹ̀lú. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pàápàá yó lè lo ìdánwò yìí gẹ́gẹ́ bí àfikún fún ìdánrawò tí ó wà lẹ́yìn orí kọ̀ọ̀kan. 
	
Mo ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀kó Yorùbá. Ọ̀nà tí wọ́n sì lè fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọn lo ìwé tí yó mú kí ẹ̀kọ́ Yorùbá rọrùn fún wọn láti kọ́. Ìwé tí ó lè ṣe èyí ni ìwé tuntun yìí. Ìwé náà sì lè fún wọn ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún ẹ̀kọ́ Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga.




#Article 63: Sádíìkì (107 words)


Chadic (Sádíìkì)

Omo ebi kan ni eleyii je fun ebi ede ile Aafirika kan ti oruko re n je Afro-Asiatic (Afuro-Esiatiiki). Awon ede ti o wa ninu Chadic yii to ogojo (160) awon ti o si n so awon ede wonyi to ogbon milionu. Awon ti o n so o bere lati iha ariwa Ghana (Gana) titi de aarin gbungbun Aafirika. Hausa ni gbajumo ju ninu awon ede ti o wa ni abe ipin Chadic. Oun nikan ni o wa ninu ipin yii ti o ni akosile ti o peye. Lara awon ede miiran ti o wa ni ipin yii a ti ri Anga, Kotoko ati Mubi.




#Article 64: Elédùmàrè (613 words)


Elédùmarè Yorùbá gbàgbọ́ wípé elédùmàrè ni ó dá ayé àti ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn. Yorùbá sì gbàgbọ́ wí pé kò sí ohun tí elédùmarè kò lẹ se, òhun ni wọ́n fí ń ki elédùmarè wí pé
 ọba àìkú,
  Ọba àtíyìn,
  aláyé gbẹlẹgbẹlẹ
  bí ẹni láyin,
  Ọba atẹ́lẹ̀ bi ẹni tẹ́ní,
  Ọba atẹ́ sánmọ bí ẹni tẹ́sọ, 
  àlọrun-làye-alàye-lọrùn, 
  olọwọ́ gbọgbọ ti yọ ọmọ rẹ̀ nínú ọ̀fìn 
  atẹrẹrẹ káríayé.
 Bí a bá ti ojú inú wò ó á ri wí pé àwọn oríkì yìí fib í olódùmarè se jẹ́ hàn láwùjọ Yorùbá. Ohun tí a ń so ni wí pé ọ̀pọ̀ ìtàn iwásẹ̀ ló sọ wípé bi olódùmarè se dá ayé àti ọ̀run. Èrò Yorùbá ni pé kọ̀ síohun ti a lẹ̀ fi wé elédùmarè nitorí àwọn àwòmọ́ tàbí àbùdá rẹ̀ tó tayọ awari ẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, ẹlédàá, àlẹ̀mí, oun ló ni ọsán àti òru, ọlọ́jọ́ òní, òní ọmọ ọlọ́rin ọ̀la ọmọ ọlọ́run ọ̀tunla ọmọ ọlọrin, ìrèmi ọmọ ọlọrin, òrún ni ọmọ ọlọ́rin. 
	Yorùbá máa ń sọ wí pé iṣẹ́ ọlọ́run tóbi tàbí àwámárídì ni iṣẹ́ olódùmarè. ọ̀rúnmìlà lọ́ fẹ̀yìntì, ó wo títítítí ó ní ẹ̀yin èrò òkun, ero ọ̀sà ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ wí pé iṣẹ́ elédùmarè tòbí. 
Olódùmarè gẹ́gẹ́ bí alágbaára láyé àti lọ́run a dùn ń se bí ohun tí elédùmarè lọ́wọ́ sí a sòro se bí ohun tí elédùmarè kò lọ́wọ́ sí, a lèwí lese, asèkanmákù, ohun tí Yorùbá rò nípa elédùmarè ni wí pé kò sí nǹkan tí kò le se àti wí pé ohunkíhun tí ó bá lọ́wọ́ sí ó di dandan kí ó jẹ́ àseyọrí àti àseyege. Ní ọ̀nà míràn Yorùbá tún gbàgbọ́ wí pé ọlọ́run nìkan ni ó gbọ́n, ìdí ni ìyí tí Yorùbá fi máa ń sọ ọmọ wọn ní Ọlọ́rungbọn elédùmarè rí óhun gbogbo, ó sì mọ ohun gbogbo arínúríde, olùmọ̀ràn ọkàn. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ojú ọlọ́run ni sánmọ̀ Yorùbá sọ wí pé amùokùn sìkà bí ọba ayé kòrí o, Ọba ọ̀rùn ń wò ọ́, ki ni ẹ̀ ń se ní kọ̀kọ̀ tí ojú ọba ọ̀run kò tó. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé elédùmarè ni olùdájọ́ ìyẹ ni wí pé elédùmarè ni adájọ́ tó ga jù láyé àtọ̀run, òun ni ọba adákẹ́ dájọ́, àwọn òrìṣà ló, máa ń jẹ àwọn orúfin níyà ṣùgbọ́n ọlọrun ló ń dájọ́. Bí àpẹẹrẹ ní ìgbnà kan láyé ọjọ́un àwọn òrìṣà fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú elédùmarè, lẹ́yìn tí tọ̀tún tòsì wọn rojọ́ tán elédùmarè dá ọ̀runmìlà láre. Odù ifá kan ọ báyìí wí pé Ọ̀kánjúà kìí jẹ́ kí á mọ nǹkanán-pín, adíá rún odù mẹ́rìndínlógún níjọ́ tí wọ́n ń jìjà àgbà lọ ilé elédùmarè, nìgbà tí àwọn ọmọ irúnmọlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ń jìjà tani ẹ̀gbọ́n tan i àbúrò, wọ́n kí ẹjọ́ lọ sí ọ̀dọ̀  elédùmarè, níkẹyìn elédùmarè dájọ̀ wí pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn Odù yókù. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé onídájọ́ ododo ni elédùmarè ìdí nì yí tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé ọlọ́run mún-un tàbí ó wa lábẹ́. Pàsán ẹlẹ́dùmarè 
	Ní ọ̀nà míràn Yorùbá gbàgbọ́ wípé ọta àìkú ni elédùmarẹ̀ Yorùbá máa ń sọ wípé rẹ̀rẹ̀kufẹ̀ a kì í gbọ́ ikú elédùmarè. Ẹsẹ ifá kan ìyẹn ni ogbè ìyẹ̀fún sọ fún wa wí pé: - 

	Rèròfo awo àjà ilẹ̀ 

	Ló dífá fún elédùmarè 

	Tí ó sọ wí pé wọn ò ní gbọ́ ikú rẹ laalaa. 

	Ní àkótán Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ọba tó mọ́ Ọba tí je ni èérí ni elédùmarè ń se. Òun ni àwọn Yorùbá ń pè ní alálàfunfun ọ̀kàn àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé bí àwọn ángẹ́lù ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ọ̀rùn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òrìṣà jẹ́ orùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ayé. Awọn òrìṣà wọ̀nyí sì ni wọ́n jẹ́ alágbàwí fún àwọn ènìyàn lọ́dẹ̀ elédùmarè.




#Article 65: Àwùjọ (627 words)


Ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Kò sí ẹ̀dá alààyè tó dá wà láì ní Olùbátan tàbí alájogbé. Orísirísi ènìyàn ló parapọ̀ di àwùjọ-bàbá, ìyá, ará, ọ̀rẹ́, olùbátan ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ìyá ṣe ń bí ọmọ, tí bàbá ń wo ọmọ àti bí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ ṣe ń báni gbé, bẹ́ẹ̀ ni ìbá gbépọ̀ ẹ̀dá n gbòòrò si. Gbogbo àwọn wọ̀nyí náà ló parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. Àti ẹ̀ni tí a bá tan, àti ẹni tí a kò tan mọ́, gbogbo wa náà la parapọ̀ di àwùjọ-ẹ̀dá. 

Ní ilẹ̀ Yorùbá ati níbi gbogbo ti ẹ̀dá ènìyàn ń gbé, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe pàtàkì púpọ̀. Bí ẹnìkan bá ní òun ò bá ẹnikẹ́ni gbé, tí kò bá gbé nígbó, yóó wábi gbàlọ. Ṣùgbọ́n, àwa ènìyàn lápapọ̀ mọ ìwúlò ìbágbépọ̀. Orísirísi àǹfàní ni ó wà nínú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. 

Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn bá n gbé papọ̀, ó rọrùn lati jọ parapọ̀ dojú kọ ogun tàbí ọ̀tẹ́ tí ó bá fẹ́ wá láti ibikíbi. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àjòjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló ṣe rí fún àwùjọ-ẹ̀dá. Gbígbé papọ̀ yìí máa ń mú ìdádúró láì sí ìbẹ̀rù dání nítorí bí òṣùṣù ọwọ̀ ṣe le láti ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwùjọ tó fohùn ṣọ̀kan. Èyí jẹ́ oun pàtàkì lára ànfàní tó wa nínú ìṣọ̀kan nínú àwùjọ-ẹ̀dá. Nídà kejì, bí ọ̀rọ̀ àwùjọ-ẹ̀dá ba jẹ́ kónkó-jabele, ẹ̀tẹ́ àti wàhálà ni ojú ọmọ ènìyàn yóó máa rí. Nítorí náà, ó dára kí ìṣọ̀kan jọba ni àwujọ-ẹ̀dá. 

Ìdàgbàsókè tí ó máa ń wà nínú àwùjọ kò sẹ̀yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bí àti ránmú un gángan ò ti sẹ̀yìn èékánná. Ó yẹ kí á mò pé nítorí ìdàgbàsókè ni ẹ̀dá fi ń gbé papọ̀. Bí igi kan ò ṣe lè dágbó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkan ò lè dálùúgbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló máa ń dá Ọgbọ́n jọ fún ìdàgbàsókè ìlú. Bí Ọgbọ́n kan kò bá parí iṣẹ́, Ọgbọ́n mìíràn yóó gbè é lẹ́yìn. Níbi tí orísirísi ọgbọ́n bá ti parapọ̀, ìlọsíwájú kò ní jìnnà si irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ànfàní tó wà ní àwùjọ-ẹ̀dá tí kò sì ṣe é fi sílẹ̀ láì mẹ́nu bà. 

Nínú ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá, a tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsòro tó ń kojú ìbágbépọ̀ ẹ̀dá. Kò ṣe é ṣe kó máa sì wàhálà láwùjọ ènìyàn. A kò lè ronú lọ́nà kan ṣoṣo, nítorí náà, ìjà àti asọ̀ máa ń jẹ́ àwọn nǹkan tí a kò lè ṣàì má rì í níbi ti àwọn ènìyàn bá ń gbé. Wàhálà máa ń fa ọ̀tẹ̀, ọ̀tẹ̀ ń di ogun, ogun sì ń fa ikú àti fífi dúkàá sòfò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn ìṣòro tó n kojú àwùjọ-ẹ̀dá. Kò sí bí ìlú tàbí orílè-èdè kan kò se ní ní ọ̀kan nínú àwọn àwọn ìṣòro wọ̀nyí. 

Ṣùgbọ́n, a gbódò mọ̀ wí pé awọn ànfàní àti awọn ìṣòro wọ̀nyí ti wà láti ìgbà pípé wá. Tí a bá wo àwọn ìtàn àtijọ gbogbo, a ó ri pé gbogbo àwọn nǹkan wònyí kò jẹ́ tuntun. Ọgbọ́n ọmọ ènìyàn ni ó fi ṣe ọkọ̀ orí-ìlẹ, ti orí-omi àti ti òfúrifú fún ìrìnkèrindò tí ó rọrùn. Àwùjọ-ẹ̀dá ti ṣe àwọn nǹkan dáradára báyìí náà ni wọ́n ń ṣe àwọn ohun tí ó lè pa ènìyàn lára. Fún àpẹẹrẹ, ìbọn àti àdó-olóró. Àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ni wọ́n lò ní ogun àgbájé kìnní tí o wáyé ní Odun 1914 sí 1918 àti ti èkejì ní odún 1939 sí 1945. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ti wà tí ó sì tún wà síbè di òní. 

Lákòótán, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ-ẹ̀dá jẹ́ ẹ̀kọ́ tó lárinrin. Ohun kan tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nip é, kò ṣe é ṣe kí ẹ̀dá máa gbe ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni pé gbígbé papọ̀ pẹ̀lú ìsọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló lè mú ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbà-sókè wá




#Article 66: Ògbómọ̀ṣọ́ (1264 words)


Ògbómọ̀ṣọ́ jẹ́ ìlú kan tó gbajúmọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́  lórílẹ̀-èdè Naijiria.

Ogunlọlá jẹ ọde, ògbótari, tí ó mọ̀n nípa ọdẹ síse ó féràn láti máa lọ sísẹ́ Ọde nínú igbó ti a máa ni ìlú Ògbómòsọ́ tí à pè ní igbó ìgbàlè, ṣùgbọ́n ọkọ̀rin yii ti o jẹ ogunlọlá ṣe Baale àdúgbọ̀ tí ó Ogunlọlá gbé nígbà nàá. Baale o ríi wí pe Ogunlọlá gbé àdùtú àrokò náà lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin. Aláàfín àti àwọn emẹ̀wà rẹ̀ yìí àrokọ̀ náà títí, wọ́n sì mọ̀ ọ́ tì. Pẹ̀lú líhàhílo, ìfòyà, aibalẹ ọkàn nípa OGUN Ọ̀GBÒRỌ̀ tí ń bẹ ló de Ọ̀yọ́, kò mú wọn ṣe ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ Ogunlọlá, wọ́n si fi í pamọ́ si ilé olósì títí wọn yóò fi ri ìtumọ̀ sí àrokò náà.
Ní ọjọ́ kan, Ogunlọlá ń sẹ ọdẹ nínú igbó ìgbàlè-àdúgbò i bi tí Gbọ̀ngàn ìlú ògbímòṣọ́ wà lonìí. Igbó yìí, igbó kìjikìji ni, ó ṣòro dojúkọ̀ kí jẹ́ pé ọdẹ ní ènìyàn, kó dà títí di ìgbà tí ojú tí là sí i bí ọdun 1935, ẹ̀rù jẹ́jẹ́ l’o tún jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìlú láti wọ̀ ọ́ ńitorí wí pé onírúurú àwọn ẹnranko búburú l’ó kún ibẹ̀. Àní ni ọdún 1959, ikooko já wo Ile Ògúnjẹ́ ńlé ni ìsàlè-Àfọ́n gẹ́gẹ́ bi ìròyìn, ikooko já náà jáde láti inú igbó ìgbàlè yìí ni àwọn ALÁGỌ̀ (àwọn Baálè tí wọ́n ti kú jẹ rí ní ògbómọ̀ṣọ́, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹsin-ìbílẹ̀) máà ń gbé jáde nígbà tí ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ṣe ọdun Ọ̀LẸ̀LẸ̀. Láti pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bi òpẹ títí di òní, nínú Gbọ̀ngàn Ògbómòṣọ́ ní àwọn Alágà náà ń ti jáde níwọ̀n ìfbà tí ó jẹ́ wí pé ara àwọn igbí ìgbàlè náà ní ó jẹ́. Ogunlọlá kó tí í tin jìnnà láti ìdí igi Àjàbon (ó wá di òní)  tí ó fi ń ri èéfín. Èéfín yìí jẹ́ ohun tí ó yá à lẹ́nu nítorí kò mọ̀ wí pé iru nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ní itòsí rẹ̀ Ogunlọlá pinnu láti tọ paṣẹ̀ èéfín náà ká má bá òpò lọ sílé Olórò, àwọn ògbójú ọdẹ náà rí ara wọn, inú swọn sí dùn wí pé àwọn jẹ pàdé. Orukọ àwọn tí wọ́n jẹ pàdé awa wọn náà ní:- AALE, OHUNSILE àti ORISATOLU. Lẹ̀yìn tí wọn ri ara wọn tan, ti wọn si mọ ara wọn; wọ́n gbìdánwò láti mọ ibi tí Olukaluku dó sí ibùdó wọn. 
Nínú gbogbo wọn Ogunlọla níkan l’ó ni ìyàwó. Wọ́n sì fi ìbùdó Ogunlọlá ṣe ibi inaju lẹ́yìn iṣe oojọ wọn. Lọ́rùn-ún-gbẹkun ń ṣe ẹ̀wà tà, ó sí tún ń pọn otí ká pẹ̀lú; ìdí niyìí tí o fi rọrun fún àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ Lọ́rùn-un-gbẹ́kún láti máa taku-rọ̀sọ àti lati máa bá ara wọn dámọ̀ràn. Bayíí, wọ́n fí Ogunlọla pamọ́ sí ọ̀dọ̀ Olósì. Ìtàn fi yé wa wí pé Ọba Aláàfin tí ó wà nígbà náà ni AJÁGBÓ. Rògbò dèyàn àti aápọn sì wà ní àkókò ti Ogunlọlá gbé aro ko náà lọ si Ààfin Ọba; Ogun ni, Ogun t’ó sì gbóná girigiri ni pẹ̀lú-Orúkọ Ogun ni, Ogun náà ni OGUN Ọ̀GBỌ̀RỌ̀. Nínú ilé tí a fi Ogunlọla. sí, ni ó ti ráńṣe sí Aláàfìn wí pé bí wọ́n bá le gba òun láàyè òun ní ìfẹ́ sí bí bá wọn ní pa nínú Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Ẹni tí a fi tì, pàrọwà fún Ogunlọla nítorí wí pé Ogun náà le púpọ̀ àti wí pé kò sí bí ènìyàn tilẹ́ lé è ní agbára tó tí ó le ṣégun ọlọ̀fè náà. Wọn kò lée ṣe àpèjúwe ọ̀lọ̀té náà; wọ́n sá mọ̀ wí pé ó ń pa kúkúrú, ó sí ń pa gigun ni. 
Aláàfin fún Ogunlọlá láṣẹ láti rán rán òun lọ́wọ́ nípa Ogun ọ̀gbọ̀rọ̀ náà. Aláàfín ka Ogunlọlá sí ẹni tí a fẹ́ sun jẹ, tí ó fi epọ ra ara tí o tún sún si ìdìí ààro, ó mú isẹ́ẹ sísun Yá ni. Alaafin súre fún Ogunlọlá. iré yìí ni Ogunlọla bà lé. Ogunlọlá dójú Ogun, ó pitu meje tí ọdẹ pa nínú igbo ó sẹ gudugudu meje Yààyà mẹ́fà. Àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ fi ibi ọta gunwa sí lórí igin han atamatane Ogunlọlá, Ogunlọá sì “gán-án-ní” rẹ̀. Nibi ti ọta Alaafin yìí tí ń gbiyanju láti yọ ojú síta láti ṣe àwọn jagun-jagun lọ́sé sé ọfà tó sì loro ni ọlọ̀tẹ̀ yìí ń ló; mó kẹ̀jẹ̀ ní Olọ̀tẹ̀ kò tí ì mórí bọ́ sínú tí ọrun fi yo lọ́wọ́ Ogunlọlá; lọrun ló sí ti bá Olọ̀tẹ̀; gbirigidi la gbọ to Ọlọ̀tè ré lulẹ lógìdo. Inú gbogbo àwọn jagun-jagun Ọ̀yọ́ sì dún wọ́n yọ sẹ̀sẹ̀ bí ọmọdé tí seé yọ̀ mọ̀ ẹyẹ. Ogunlọlá o gbé e, o di ọ̀dọ̀ Aláàfin; nígbà yìí ni Aláàfin to mo wí pé Ẹlẹ́mọ̀sọ̀  ni ń ṣe alèṣà lẹ́yìn àwọn ènìyàn òun. 
Bayìí ni Ogunlọlá ṣe àseyorí ohun ti ó ti èrù jẹ̀jẹ̀ sí ọkan àyà àwọn ara ilu ọ̀yọ́. Aláàfin gbé Oṣiba fún Ogunlọlá fún iṣé takun-takun tí ó ṣe, o si rọ̀ ó kìí ó dúró nítòsi òun; ṣùgbọ́n Ogunlọlá bẹ̀bẹ̀ kí òun pasà sí ibùdó òun kí ó ó máa rańsẹ sí òun. Báyìí Aláàfin tú Ogunlọlá sílẹ̀ láàfín nínú ìgbèkùn tí a fii sí kò ní jẹ́ àwáwí rárá láti sọ wí pé nínú ìlàkàkà àti láálàà tí Ogunlọlá ṣe ri ẹ̀yín Ẹlẹ́mọsọ ni kò jọ́ sí pàbó tí ó sí mú orukọ ÒGBÓMỌ̀SỌ́ jade. Erédì rẹ nìyìí Gbara tí a tú Ogunlọla sílẹ̀ tán pẹ̀lu asẹ Alaafin tí ó sì padà si ibùdó rẹ̀ nì ìdí igi Àjàgbọn ni bí èrò bá ń lọ́ tí wọn ń bọ́, wọn yóò máa se àpèjuwe ibudo Ogunlọlá gẹ́gẹ́ bíí Bùdó ò-gbé-orí-Ẹlẹmọsọ; nígbà tí ó tún ṣe ó di Ògbórí-Ẹlẹmọ̀ṣọ́ kó tó wà di Ògbẹ́lẹ́mọ̀sọ́; ṣùgbọ́n lónìí pẹ̀lú Ọ̀làjú ó di ÒGBÓMỌ̀SÓ

Baálẹ̀ ni Olórí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Nínú ìlànà ètò ìjọba, agbára rẹ̀ kò jut i ìgbìmọ̀ àwọn ìjòyè ìlú rẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àlàyé wipe irú ètò báyìí wà láti rí pé Baálẹ̀ tàbí Ọba kò tàpá sí àwọn ìgbìmọ̀ ìjòyè kí gbogbo nǹkan lè máa lọ déédéé ni ìlú. Irú ètò yìí yàtọ púpọ̀ sí ìlànà ètò Ìjọba àwọn ìlú aláwọ̀-funfun ninú eyi ti àṣẹ láti ṣe òfin wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin, tí ètò ìdájọ́ wà lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba. Ẹkìínní kò gbọ́dọ yọ ẹnu sí iṣẹ́ èkejì, oníkálukú ló ni àyè tirẹ̀. Ní ti ètò ìjọba Yorùbá, Ọba atì àwọn ìjòyè ńfi àga gbá’ga ni nínú èyí tí ó jọ pé ìjà le ṣẹlẹ̀ láàrin wọn bi ọ̀kan bá tayọ díẹ̀ sí èyí. Ohun tí ó mu un yàtọ̀ ni wípé Ṣọ̀ún, baba ńlá ìdílé àwọn Baálẹ̀, dé sí ibi tí ó di Ògbómọ̀ṣọ́ lónìí lẹ́hìn tí àwọn mẹ́ta ti ṣaájú rẹ̀ dé ibẹ̀. Nipa akíkanjúu rẹ̀ ló fi gba ipò aṣíwájú lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ yókù. Akẹ́hìndé sì di ẹ̀gbọ́n lati igba yi lọ títí di òní, àwọn baálẹ ti a ti jẹ ní Ògbómọ̀ṣọ́ kò jẹ́ kí àwọn ìdílé ẹni mẹ́ta ti o ṣaáju Ṣọ̀ún dé ìlú jẹ oyè pàtàkì kan. Ẹ̀rù mbà wọ́n pé ìkan nínú àwọn ọmọ ẹni mẹ́ta yìí lè sọ wípé òun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe Olórí ìlú. Nitorina ni o fi jẹ́ pé àwọn ìjòyè ìlú tí o mbá Baálẹ̀ dámọ̀ràn láàrin àwọn ẹni tí ó dé sí ìlú lẹ́hìn Ṣọhún ní a ti yan wọ́n. Síbẹ̀ náà, Baálẹ̀ kan kò gbọdọ̀ tàpá si ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè ìlú, pàápàá nínú àwọn ọrọ tí ó jẹ mọ iṣẹ̀dálẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì jù ní nǹkan ọgọ́rùn ọdún sí àkókò ti a ńsọ nípa rẹ̀ yìí. Àwọn ópìtàn ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ sọ pé gbogbo àwọn Baálẹ̀ ti wọn tàpá si ìmọ̀ràn ìjòyè ìlú ni Aláàfin rọ̀ lóyè. Abẹ́ Aláàfin ni Ògbómọ̀ṣọ́ wà ní ìgbà náà....




#Article 67: Òmuò-Òkè-Èkìtì (482 words)


Ìlú Òmùò-Òkè Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní apá Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta. 

Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà.

	
Ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ni àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri. Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní Òmùò-òkè. 
Olúmoyà pinnu láti sá kúró ni Ifẹ̀ nítorí kò faramọ́ ìyà ti wọn fi ń jẹ́ ẹ́ ni Ifẹ̀. Kí ó tó kúró ni Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ni ibi ti ó máa tẹ̀dó sí. Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹ́ta yìí ni kí ó tẹ̀dó síbẹ̀. 
Àwọn àmì àmì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni

Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rìn títítí ni ó wà dé ibi ti ifá ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un. Nígbà ti ó rí odò, ó kígba pé “Omi o” ibi ni orúkọ ìlú náà “Òmùwò” ti jáde. Òmùwò yìí ni ó di Òmùò-òkè títí di òní. 
Olúmoyà rìn síwájú díẹ̀ kúró níbí odó yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó dé ibìkan, ibi yìí ni òun àti àwọn tí ó ń tẹ̀le kọ́ ilé si. Ibi ti ó kọ́ ilé sí yìí ni ó pè ni “Ìlẹ́mọ” Orúkọ ilé yìí “Ìlẹ́mọ” wà ni Òmùò òkè títí di òní.  Olúmoyà gbọ́rọ̀ sí ifá lẹ́nu, ó sọ odò náà ni “Odò-Igbó” àti ibi ti ó ti rí ẹsẹ̀ erin ni “Erínjó”. Akíkanjú àti alágbára ọkùnrin ni Olúmoyà ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ. ó kọ ilẹ òrìṣà kan tí ó pè orúkọ òrìṣà yìí ni “Ipara ẹ̀rà”. Ibi yìí ni wọn ti máa ń jáwé oyè lé ọba ìlú náà. Báyìí ni Olúmoyà di olómùwò àkọ́kọ́ ti ìlú Òmùwò tí a mọ̀ sí Òmùò-òkè ní òní.




#Article 68: Èdè Yorùbá (1128 words)


Èdè Yorùbá Ni èdè tí ó ṣàkójọ pọ̀ gbogbo kú oótu o-ò-jíire bí, níapá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ bi èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn.

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn olùsọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà ni ìpínlẹ̀ Ẹdó, ìpínlẹ̀ Òndó, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìpínlẹ̀ Èkó, àti ìpínlẹ̀ Ògùn. Ẹ̀wẹ̀ a tún rí àwọn orílẹ̀-èdè míràn bí Tógò apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, Ghana, Sierra Leone,United Kingdom àti Trinidad, gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ.

Èdè Yorùbá jẹ́ èdè kan ti ó gbalẹ̀ tí ó sì buyì káàkiri àgbáyé. Ìtàn sọ fún wa pé ní àgbáyé Kwa ní èdè Yorùbá bátan; kwa jẹ́ ẹ̀yà kan ní Niger-Congo. A lè sọ pé àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Yorùbá yàtọ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lé ní Ọgbọ̀n mílíọ̀nùn tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Èdè Yorùbá gbajú-gbájà ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti káàkiri àgbánlá ayé lápapọ̀. Àwọn ǹkan tí ó ń gbé èdè Yorùbá níyì tí ó fi di àrí má leè lọ àti àwòpadà sẹ́yìn nìwọ̀yín:

Òwe: òwe ni ọ̀kan lára àwọn ọnà èdè tí àwọn Yorùbá ma ń gbà láti kó ẹwà bá ohùn ènu wọn. Orísirísi ọ̀nà ni a le gbà pa òwe:
(a) A le pa òwe gẹ́gẹ́ bí àwọn elédè ti ń pa á tàbí bí gbogbo ènìyàn ti ń pá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Àíyá bẹ́ sílẹ̀ ó bé áré, (igi ọ̀ún ni kò ga).

(b) À lè pa òwe dà, bí àpẹẹrẹ: Ojú kìí ti eégún kí ọmọ alágbàá ma kọrí sóko.

(i) Ojú kì í ti eégún nínú aṣọ

(ii) Ohun tí n tán lọdún eégún, ọmọ alágbàá a kọri sóko.

Lára àwọn èròngbà kan gbòógì tí ìlò èdè Yorùbá yíì ni pé mo fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ èdè Yorùbá lo dáradára nítorí náà a wo ìjúba ni awùjọ Yorùbá, a wo ààtò, Ìtúmọ̀, ìlò, àti àgbéyẹ̀wò àwọn òwe, àkànlò èdè àti ọ̀rọ̀ àmúlò mííràn. A wo èdè àmúlò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ àti igba ti a ba kọ èdè Yorùbá silẹ. A wo ẹ̀bùn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. A sí wo ìlànà ati òté tó de sísọ̀rọ̀ ni àwùjọ Yorùbá. A wo ìwúrẹ láwùjọ Yorùbá. A wo aáyan àròkọ kikọ. Lábẹ́ àròkọ, a wo arokọ wọ̀nyí: alapejuwe, ajemọroyin, alalaye, alariiyan, ìsòròǹgbèsì, onisiipaya, ajẹmọ́-ìsonísókí-ìwé ati arokọ onileta. A wo bi a ṣe n se agbekale isẹ to da le girama, iwe atumọ, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ, àbọ̀ ìpàdé, ìjábọ̀ ìwádìí, ìwé ìkéde pélébé àti eyí ti a fi n se ìpolongo ti a máa ń tẹ̀ mọ́ ara ògiri. Èdè Yorùbá ni ibamu pẹlu asa obínibí Yorùbá. Ó yẹ kí a mọ ọ̀rọ̀ í dá sí. Ó yẹ ki a mọ ọ̀rọ̀ sọ, ki á si mọ ọ̀rọ̀ ọ́ kọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ti a bá ka ìwé kékeré yìí.

Kí àwọn òyìnbó tó gòkè odò dé, kò sí ètò kíkọ ati kíka èdè Yorùbá. Gbogbo ọ̀rọ̀ àbáláyé tí ó ti di àko sílẹ̀ lóde òní,nínú ọpọlọ́ àwọn baba ńlá wa ni wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ àbáláyé báyìí a máa súyọ nínú orin, ewì àti ìtàn àwọn baba wa. Nígbà tí a kọ́ ń pe gbogbo àwọn ẹ̀yà tí èdè wọ́n papọ̀ yìí ní Yorùbá tàbí Yóòbá, wọn kò fi tara tara fẹ́ èyí nítorí pé àwọn ẹ̀yà Yorùbá ìyókù gbà pé àwọn Ọ̀yọ́ nìkan ni Yorùbá. Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run aláwọ̀ funfun tó wá wàásù nípa kírísítì ṣe àkiyèṣí pé èdè wọ́n bá ara wọn mu ni wọ́n bá pè wọ́n ní Yorúbà tàbí Yóòba. Àwọn Yorùbá ti a ko l’éní lo si ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí a sì wá dá padà sí sàró lẹ́hìn tí òwò ẹrú tí tán ni àwọn òyìnbó Ìjọ C.M.S. kọ́kọ́ sọ di onígbàgbọ́. ABUDA ÈDÈ YORÙBÁ Àbùdá èdè Yorùbá ni ó máa jẹ́ kí á mọ ohun tí èdè jẹ́ gan-an. Orísirísi ni àwọn àbùdá tí èdè Yorùbá ní. Èdè Yorùbá kógo àbùdá wọ̀nyí já.

(1) Ohun tí a bá pè ní èdè gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fí ìró èdè gbé jáde. Ìró yìí ni a le pè ní ariwo tí a fi ẹnu pa. A ó ṣe àkíyèsí pé èyí yàtọ̀ sí pípòòyì, ijó ọlọ́bọ̀ùnbọ̀un, dídún tàbí fífò tata tàbí jíjuwó alákàn sí ara wọn.

(2) Èdè nílò kíkọ́ ọ fún ìgbà pípẹ́ díẹ̀ kí ènìyàn tó le sọ ọ́. Ó ti di bárakú tàbí àṣà fún wa pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni èdè. Àkiyèsí àti ìwádìí yìí ni àwọn eléde gẹ̀ẹ́sì ń gọ́ka sí nígbà tí àwọ́n ba sọ pé “Language is Culturally transmitted”. Ọmọ tí a bá ṣẹ̀ṣè bí tí a kò kọ́ ní èdè, àti àwùjọ jẹ́ kòríkòsùn.

(3) Ìhun ni èdè ènìyàn gùn lé tàbí dálé. Bí a ṣe hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú gbólóhùn ṣe pàtàkì kíkà iye ìró èdè nínú gbólóhùn kò fi ibi kankan ní ìtúmọ̀.

A lè sọ pé ìyàndá ṣubú

ìyàndá ẹlẹ́mu ṣubú

Ó ṣubú

Ìyàndá tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣubú.

Ìyípadà orírsirísi ló le wáyé sí gbólóhùn wọ̀nyí tí yóò sì da ètò wọn ní, síbẹ̀síbẹ̀, yóò ní ìtumọ̀. Irú àbùdá yìí ni onímọ̀ ẹ̀dá-èdè ń pè ní “Structure dependence”.

(4) Gbogbo èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ìró èdè tirẹ̀ tí a ń pè ní (Fóníìmù {phonemes}). Foniimu yìí sún mọ́ ti àwọn ẹranko ṣùgbọ́n ó sì tún rọ̀ jut i ẹranko lọ. Ó yàtọ̀ láti èdè kan sì òmíràn. Bí a bá mú fóníìmù yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. kì í dá ìtumọ̀ ní kó wúlò ìgbà tí a bá kàn án pọ̀ mọ́ fóníìmù mìíràn gan-an ló máa ṣìṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ:- ìró èdè /a/ /b/ /d/ /e/ /ẹ/ kò dá ìtumọ̀ ní, àfi tí abá kàn wọ́n papọ̀ lọ́nà orísirísi. A lè se àkànpọ̀ kí á ri ọ̀rọ̀ bí : abẹ, baba, adé, alẹ́ abbl. Irúfẹ́ àkiyèsí àti ìwádìí yí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀dà-èdè ń pe gẹ̀ẹ́sì rè ní “duality” tàbí “double articulation” ìwádìí fihàn pé àwọn ẹyẹ àti ẹranko tí wọ́n ní ìró èdè kò pò, iye èdè tí òkọ̀ọ̀kan ní kò pọ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ adìyẹ ní ìró èdè bí ogún, ti mààlúù jẹ́ mẹ́wàá ṣùgbọ́n kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọgbọ̀n.

(5) Èdè jẹ́ ohun ètò tí a máa ń lò láti ṣe àròyinlẹ̀.




#Article 69: Àṣà Yorùbá (1432 words)


Àṣà àti Ìṣe Yorùbá Mo tún ti dé pẹ̀lú ohùn ẹnu mi, mo tún fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá. Nítorí náà ẹ gbé àga, mo ni ẹ jòkó, kí ẹ gbọ́ mi gbóhùn ẹnu mi. Mo ní kí ẹ gbọ́ gbólóhun tí mo fẹ́ bá gbogbo mùtúnmùwà àní ọmo adáríhunrun sọ. Òrò yí jẹ mí lógún, ọ̀rọ̀ àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá. Nítorí àṣà Yorùbá jẹ́ àṣà tí ó gbajúmọ̀ láàrín àwùjọ, àṣà àti ìṣe wa ṣeé mú yangàn nílé àti ní ọkọ. Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá, a ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí a máa sẹ ìhùwàsí àti ìrísí wa láàrín àwùjọ. Ohun méjì ní mo fẹ́ ṣọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ogún-lọ́gọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe tí ó ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá. Ìkíní ni, Àṣà àti ìsẹ Yorùbá lórí Ìkíni. Èkejì ní Àsà àti ìṣe Yorùbá lórí ìsìnkú nílẹ̀ Yorùbá. 

Ẹ jẹ́ kí a jọ gbé e yèwò, kí a jọ yàn-àn-nàá rẹ̀. Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àkọ́kọ́ ni:

Àṣà ìkíni jẹ́ àṣà tí ó gbajúgbujà nílẹ̀ wa, ó sì jẹ mọ́ ìgbà àti àkókò. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ń sẹlẹ̀ ní déédé àsìkò náà. Bí Yorùbá bá jí láàárọ̀, ọmọdé tí ó bá jẹ́ okùnrin, á wà lórí ìdọ̀bálẹ̀, èyí tí ó bá jẹ́ obìnrin, á wà lórí ìkúnlẹ̀, wọn a sì kí àwọn òbí wọn. Wọ́n máa wí pé, 

Àwọn òbí wọn náà á sì dá wọn lóhùn wí pé, 

Bí ó bá jẹ́ ọ̀sán, wọn á ṣe bákannáà, wọn á sọ wí pé, 

Àwọn òbí wọn náà á dá wọn lóhùn wí pé, 

Bí ó bá jẹ́ ìgbà iṣé, 

Bí ó sì jẹ́ àṣálẹ́, 

Nílẹ̀ Yorùbá, gbogbo àsìkò ni ìkíni wà fún, ṣùgbọ́n ọmọdé ni ó kọ́kọ́ máa ń kí àgbà. Èyí tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní wí pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tàbí, wọ́n kọ́ ọ ní'lé, kò gbà ni. 
Bí ó bá jẹ́ ìgbà ayẹ̣yẹ bíi ìsìnkú àgbà, nítorí Yorùbá kì í ṣe òkú ọ̀dọ́, ẹhìnkùnlé ni wọ́n máa ń sin òkú ọ̀dọ́ sí. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, òfò ni ó jẹ́ fún àwọn òbí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wàyí, bí ó bá jẹ́ òkú àgbà, wọn á ní, 

Bí ó bá jẹ́ ayẹyẹ Ìkómojáde/Ìsọmọlórúkọ, wọn á ní, 

Oríṣiríṣì àkókò ni ó wà nínú odún. Àkókó òfìnkìn, Àkókò ọyẹ́ (Harmattan), Àkókò oòrùn (Summer), Àkókò òjò (raining season), gbogbo wọ̀nyí sì ni àwọn Yorùbá ní bí a ṣe ń kí'ni fún. Ẹ jẹ́ kí á gbẹ́ àṣà 'kejì yẹ̀wò. 

Mo ti sọ ṣáájú wí pé ó ní àwọn òkú tí Yorùbá máa ń ṣe ayẹyẹ fún, àwọn bíi òkú àgbà, nítorí wọ́n gbà wí pé, olóògbé lọ sinmi ni, àti wí pé, wọ́n lọ'lé. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọjà ni ayé, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ilé. 

Bí ó bá jẹ́ òkú ọ̀dọ́ tàbí ọmọdé, òkú ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́ ló jẹ́. Wọ́n á gbà wí pé, àsìkò rẹ̀ kò tíì tó. Yorùbá máa ń ná owó àti ara sí ìsìnkú àgbà, pàápàá bí olóògbé bá jẹ́ ẹni tí ó ní ipò àti ọlá nígbà tí ó wà láyé, tí ó sì tún bí ọmọ. Ìsìnkú àwọn wọ̀nyí máa ń lárinrin, ayé á gbọ́, òrun á sì tún mọ̀ pẹ̀lú. 

Ní ayé àtijọ́, bí aláwo bá kú, àwọn àwọn olúwo ní ń sìnkú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Wọn á pa adìyẹ ìrànà, wọn á sì máa tu ìyẹ́ rẹ bí wọ́n ṣe ń gbé òkú rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí wọn bá sin òkú tán, àwọn aláwo náà máa sun adìye náà jẹ. Ìdí rèé tí Yoòbá fi máa ń sọ wí pè, Adìyẹ ìrànà kì í ṣ'ọhun à jẹ gbé. Nítorí pé, kò sí ẹni tí kò ní kú. 

Ọ̀fọ̀ ni ó máa ń jẹ́ tí ìyàwó ilé bá sáájú ọkọ rẹ̀ kú. Yorùbá gbàgbọ́ pé, ọkọ ló máa ń sáájú aya rẹ̀ kú, kí ìyàwó máa bójú tó àwọn ọmọ. Fún ìdí èyí, bí okùnrin bá kú, àwọn ìyàwó irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe opó pẹ̀lú ìlànà àti àṣà Yorùbá. Ogójì ọjọ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń fi ṣe opó. Lẹ́yìn ìsìnkú, àwọn àgbà ilé ni wọ́n máa pín ogún olóògbé fún àwọn ọmọ rẹ̀, bí ó bá jẹ́ òkú olọ́mọ. Àmọ́ tí kò bá bí’mọ, àwọn ẹbí rẹ̀, ní pátàkì jùlọ, àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tí ó jù ú lọ ní wọ́n máa pín ogún náà láàárín ara wọn. Ó tún jẹ́ àṣà Yorùbá òmíì kí wọn máa ṣú opó olóògbé fún àwọn àbúrò rẹ̀, láti fi ṣe aya.

Àṣà ni ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ìgbé ayé àwọn aṣùwàdà ènìyàn kan, ní àdúgbò kan, bẹ̀rẹ̀ lórí èrò, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, ìsẹ̀dá ohun èlò, ìtàn, òfin, ìṣe, ìrísí, ìhùwàsí, iṣẹ́-ọnà, oúnjẹ, ọ̀nà ìṣe nǹkan, yíyí àyíká tàbí àdúgbò kọ̀ọ̀kan padà. Pàtàkì jùlọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, eré ìbílẹ̀, àti iṣẹ́ ìbílẹ̀. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni Wọ́n kó'ra jọ pọ̀ ń jẹ́ àṣà. 

Ohun tí ó jẹ́ orírun àṣà ni ‘àrà’, ó lè dára tàbí kí ó burú. Ìpolówó Èkìtì – iyán rere, ọbẹ̀ rere; Ìpolówó Oǹdó Ẹ̀gi – (dípò Iyán) ẹ̀bà gbọn fẹẹ. Àṣà Oǹdó ni kí wọ́n máa pe iyán ní ẹ̀bà, nítorí pé èèwọ̀ wọn ni, wọn kò gbọdọ̀ polówó iyán ní àárín ìlú. 
Àṣà jẹ mọ́ ìgbàgbọ́, bí àpẹẹrẹ; àbíkú, àkúdàáyà. Àṣà jẹ mọ́ iṣẹ́-ọnà tí a lè fojú rí tàbí fẹnu sọ. A lè pín àṣà sí ìsọ̀rí mẹ́ta, èyí tí ó jẹ mọ́:

(a) Ọgbọ́n ìmọ̀, ète, tàbí ètò tí à ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ilà kíkọ, irun dídì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

(b) Iṣẹ́-ọnà bíi igi gbígbẹ́, igbá fínfín

(d) Bí a ṣe ń darí ìhùwàsí àwọn ẹgbẹ́/ẹ̀yà kan. 

Ara àbùdá àṣà ni pé: 
(a) Kò lè è súyọ láìsí ènìyàn; ẹ̀mí àṣà gùn ju ti ènìyàn lọ; 

(b) Ó jẹ mọ́ ohun tí a lè fojú rí; 

(d) Àṣà kọ̀ọ̀kan ló ní ìdí kan pàtó. 

(a) Àṣà lè jẹyọ nínú oúnjẹ: Òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ wa. Àkókó kúndùn ẹ̀bà, Ìlàje-púpurú, Igbó ọrà-láfún. 

(b) Àṣà lè jẹyọ nínú ìtọ́jú oyún/aláìsàn/òkú; ètò ẹbí/àjọṣepọ̀; ètò ìṣàkóso àdúgbò, abúlé tàbí ara dídá nípa iṣẹ́-ọnà. 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: 

(a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. 

(b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. 

(d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. 

(e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́.

Àwọn ọ̀nà tí àṣà máa ń gbà yípadà n'ìwọ̀nyí: 

(a) Bí àṣà tó wà nílẹ̀ bá lágbára ju èyí tó jẹ́ tuntun lọ, èyí tó wà tẹ́lẹ̀ yóò borí tuntun. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ wíwọ̀.

(b) Àyípadà lè wáyé bí àṣà tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ bá dógba pẹ̀lú àṣà tuntun, wọ́n lè jọ rìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣà ìgbéyàwó. 

(d) Bí àṣà tuntun bá lágbára ju èyí tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, yóò sọ àṣà ti àtẹ̀hìnwá di ohun ìgbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe ń kọ́'lé. 

Tí a bá wá wò ó fínnífínní, à á ri wí pé, àṣà, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà máa ń dá lé: 

(a) Ìmọ̀ ìṣe sáyẹ́ǹsì 

(b) Ìṣe jẹun wa 

(d) Ìsọwọ́ kọ́lé 

(e) Iṣẹ́ ọwọ́ ní síṣe 
		

Èdè àwọn ènìyàn jẹ́ kókó kan pàtàkì nínú àṣà wọn. Kò sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò nínú àṣà àti èdè. Ìbejì ni wọ́n. Ọjọ́ kan náà ni wọ́n délé ayé nítorí pé kò sí ohun tí a fẹ́ sọ nípa àṣà, tí kì í ṣe pé èdè ni a ó fi gbé e kalẹ̀. Láti ara èdè pàápàá ni a ti lè fa àṣà yọ. A lè fi èdè Yorùbá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni, a lè fi kọrin, a lè fi kéwì, a lè fi jọ́sìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láti ara àwọn nǹkan tí à ń sọ jáde lẹ́nu wọ̀nyí ni àṣà wa ti ń jẹyọ. Ara èdè Yorùbá náà ni òwe àti àwọn àkànlò-èdè gbogbo wà. A lè fa púpọ̀ nínú àwọn àṣà wa yọ láti ara òwe àti àkànlò èdè. 

Nítorí náà, èdè ni ó jẹ́ òpómúléró fún àṣà Yorùbá. Àti wí pé, òun ni ó fà á tí ó fi jẹ́ pé, bí àwọn ọmọ Odùduwà ṣe tàn kálẹ̀, orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n, èdè kan náà ni wọ́n ń sọ níbikíbi tí wọ́n lè wà. Ìṣesí, ìhùwàsí, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀. Fún ìdí èyí, láìsí ènìyàn, kò le è sí àṣà rárá.àsà jẹ́ nnkan gbòógì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ṣùgbọ́n àwọn yorùbá mu ní ọ̀kúnkúndùn kí gbogbo wa sì gbe lárugẹ

 

University Press Limited 

University Press Limited. 

of   CSS Limited.




#Article 70: Ìnáwó (1056 words)


Sé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “Se bó o ti mọ ẹlẹ́wàà sàpọ́n. Ìwọ̀n eku nìwọ̀n ìtẹ́.”  Wọn a sì tún máa pa á lówe pé “ìmọ̀ ìwọ̀n ara ẹni ni ìlékè ọgbọ́n nítorí pé ohun ọwọ́ mi ò tó ma fi gọ̀gọ̀ fà á, í í já lu olúwarẹ̀  mọ́lẹ̀ ni” 
áyé òde òní, àwọn ọ̀dọ́ tilẹ̀ máa ń dáṣà báyìí pé “dẹ̀ẹ́dẹ̀ẹ́ rẹ, ìgbéraga ni ìgbérasán lẹ̀.” Wọ́n máa ń sọ èyí fún ẹni tí ó bá ń kọjá ààyè rẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ ọgbọ́n kan se wí pé “ni àtètékọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà,”  bẹ́ẹ̀ náà ni ètò ti wà fún ohun gbogbo láti ìpilẹ̀sẹ̀ wá. Ètò ní í mú kóhun gbogbo rí rẹ́mú. Ọlọrun ọ̀gá ògo to da ayé. Ó fi ẹranko sígbó  {àwọn olóró}. Ó tún fi ẹja síbú. Ó fi àwọn ẹyẹ kan sígbó. Ó fi àwọn mìíràn sílé. Àdìmúlà bàbá tó ju bàbá lọ tún fi ààlà sáààrin ilẹ̀, omi òkun, àti sánmọ̀. Ohun gbogbo ń lọ ní mẹ̀lọ̀-mẹ̀lọ. 
Bàbá dá àwa ọmọnìyàn kò fi ojú wa sí ìpàkọ́. Kò fi ẹsẹ̀ wa sórí kí orí wá wà lẹ́sẹ̀. Elétò lỌlọ́run gan-an.

Kíni ètò? Ètò jẹ̣́ ọ̀nà tí à ń gbà láti sàgbékalẹ̀ ohun kan tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan lójúnà àti mú kí ó se é wò tàbí kó se é rí tàbí kó dùn ún gbọ́ sétí. A sẹ̀dá orúkọ yìí gan-an ni. Ohun tí a tò ní í jẹ́ ètò. 
Ẹ̀wẹ̀, ìnáwó ni ọ̀nà tàbí ìwà wa lórí bí a se ń náwó. Ohun pàtàkì ni láti sètòo bí a óò se máa ná àwọn owó tó bá wọlé fún wa. Ní àkọ́kọ́ ná, èyí yóò jẹ́ kí á mọ ìsirò oye owó tó ń wọlé fún wa yálà lọ́sẹ̀ ni o tàbí lósù, bí ó sì se lọ́dún gan-an ni. 
Bákan náà, yóò tún mú kó rọrùn fún wa láti mọ àwọn ọ̀nà tí owó náà ń bá lọ. Síwájú síi, ètò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti le ní ìkọ́ra-ẹni-níjàánu lórí bí a se ń náwó wa. 
Bí a bá ti mú ìsàkọ̀tún tán, tí a tún mú ìsàkòsì náà, ìsàkusà ni yóò kù nilẹ̀. Tí a bá yọ ti ètò kúrò nínú ojúse ìjọba pàápàá sí ará ìlú, eré ọmọdé ni ìyókù yóò jẹ́. Gbogbo àwọn ẹka ìjọba pátá-porongodo ló máa ń ní àgbẹ́kalẹ̀ ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé lati mọ oye owó ti wọn n reti ati eyi ti wọn óò na bóyá fún odidi ọdún kan ni o tàbí fún osù díẹ̀. Èyí ni wọ́n ǹ pé ní ‘ÈTÒ ÌSÚNÁ’ 
Ìdí nìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo tolórí-tẹlẹ́mù, tòǹga-tòǹbẹ̀rẹ̀ ki kúlukú ní ètò kan gbòógì lọ́nà bí yóò se máa náwó rẹ̀. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, “eku tó bá ti ní òpó nílẹ̀, kì í si aré sá. Bí a bá ti se àlàkalẹ̀ bí a óò se náwo wa yóò dín ìnákùùná kù láwùjọ wa. Ìnáwó àbàadì pàápàá yóò sì máa gbẹ́nú ìgbẹ́ wo wá láwùjọ wa. 
Mo ti sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀kan nípa àwọn ẹka ìjọba mẹ́tẹ̀ẹ̀tà orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n máa ń sètò ìnáwó wọn. Àwọn wo ló tún yẹ kó máa sètò ìnáwó? Àwọn náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn oníṣòwò, àwọn ọmọ ilé-ìwé, níbi àsẹyẹ. 
Àwọn òsìsẹ́ ìjọba gbọdọ̀ sètò ìnáwó wọn kó sì gún régé. Ìdí ni pé, èyí ni yóò jẹ́ kí owó osù wọn tó í ná. Ẹni tó ń gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lósù tí kò sì fi òdiwọ̀n sí ìnáwó rẹ̀ nípa títò wọ́n lésẹẹsẹ le máa rówó sohun tó yẹ láàákò tó yẹ nígbà tí ó bá ti náwó rẹ̀ sí àwọn ohun mìíràn tó seése kó nítumọ̀ ṣùgbọ́n tí kì í se fún àkókò náà. 

Irú wọn á wá má ráhàn owó tósù bá ti dá sí méjì tàbí kí wọ́n jẹ gbèsè de owó osù mìíràn. 
Síwájú sí i, àwọn oníṣòwò gbọ́dọ̀ máa sètò to jíire lórí ìnáwó wọn. Nípa ṣíṣe èyí, wọn óò ni àǹfààní láti mọ̀ bọ́yá Ọláńrewájú ni iṣẹ́ wọn tàbí Ọláńrẹ̀yìn. Níbi tí àtúnṣe bá sì ti pọn dandan, “a kì í fòdù ọ̀yà sùn ká tó í nà án ládàá,” wọn kò nì í bèsù bẹ̀gbà, wọn óò sì se àtúnṣe ní wéréwéré. Àwọn ọmọ ilé-ìwé gan-an gbọdọ̀ mọ̀ pé ká sètò ìnáwó ẹni kì í sohun tó burúkú bí ti í wù kó mọ. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kó gíga, béèyàn bá gbowó fún àwọn orísirísi ìnáwó láti ilé lórí ẹ̀kọ́ ẹni, ó seése kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ná ìná-àpà tó bá dé ààrin àwọn ẹlẹgbẹ́ẹ rẹ̀. Irú wọn ló máa ń pe ọ̀sẹ̀ tí wọ́n bá ti ilé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn dé ní ‘Ọṣẹ ìgbéraga’ Èyí kò yẹ ọmọlúàbí pàápàá. Ó sì ń pè fún àtúnṣe. 
Ṣíṣe ètò tó gúnmọ́ lórí ọ̀nà tí à ń gbà náwó kò pin sí àwọn ọ̀nà tí mo sàlàyé rẹ̀ sókè yìí. Mo fẹ́ kó ye wá pé a le sètò ìnáwó wa níbi àwọn orísisi ayẹyẹ bí ìsọmọlórúkọ [tàbí ìkọ́mọ́jáde], ìgbéyàwó, oyè jíjẹ, ìṣílé, àti ìsìnkú àgbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi bí a se tó hàn wá ká le mọ ohun tí a óò dágbá lé níbi irúfẹ́ àṣeyẹ tí a bá fẹ́ í ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ a ò ní í sí nínú àwọn tó máa ń pa òwe tó máa ń mú kí wọn kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Òwe wọn ni, “rán aṣọ rẹ bí o bá se ga mọ.” Èyí tí wọn ì bá fi wí pé “rán aṣọ rẹ bí o bá se lówóo rẹ̀ sí.” Bí ẹni tó ga bá rán aṣọ rẹ̀ ní ‘bóńfò’  bó se lówó mọ ni, kò sì fẹ́ í sàsejù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ le ti mọ̀ pé alásejù pẹ́rẹ́ ní í tẹ́. 
Bí a bá wá fẹ́ láti sètò ìnáwó wa, ó yẹ ká mọ̀ pé ìtòṣẹ̀ ló lỌ̀yọ̀ọ́, Oníbodè lo làààfin, ẹnìkan kì í fi kẹ̀kẹ́ síwájú ẹsin. Iwájú lojúgun í gbé. Ìnáwó tó bá ṣe kókó jùlọ tó sì ń bèèrè fún ìdásí ní kíákíá ló yẹ ká fi síwájú bí a se ń tò ó ní ẹsẹẹsẹ. Bí a bá wá kíyèsí pé ètò tí a là sílẹ̀ ti ju agbára wa lọ, ẹ jẹ́ ká fura nítorí pé akéwì kan wí pé: 

			“Ẹ fura óò!

			Ẹ fura óò! 

			Páńsá ò fura 

			Páńsá jááná 

			Àjà ò fura 

			Àjá jìn 

			Ońlè tí ò bá fura 

			Olè ní ó ko o…”




#Article 71: Ètò ajé (785 words)


Eto Oro Aje

Oro Aje

Ajibola, Olaniyi Olabode

AJIBOLA OLANIYI OLABODE

ÈTỌ̀     ORO AJÉ

	Yorùbá tọ̀ wọ́n ní kí la ó jẹ làgba kí la ó ṣe, abálájọ tí ètò ajé fi mumú láyà gbobgo orílẹ̀ èdè àgbáyé tóó bẹ̀. 
	Gbàrà tí ọ̀nà káràkátà oní-pà ṣí pààrọ̀ tayé ọjọ́ tun ti dotun ìgbàgbé ni ètò ajé ti dotun tó gbòòrò síwájú sí. 
	Awọn ènìyàn wáá bẹ̀rẹ̀ síí ní lo àwọn ohun èlò bíi wúrà àti jàdákà láti máa fii se pàṣípààrọ̀ àwọn ohun tí wọ́n nílò. 
	Eléyìí mú kí káràkátà láàrín-ín ìlú àti orílẹ̀ èdè tún gbináyá síi nígbà tí àwọn kù dìẹ̀ ku diẹ tí ń fa ìdílọ́wọ́ nínú káràkátà onípàṣípàrọ̀ ti kúrò ní bẹ̀. 
	Tí abá kọ́kọ́ gbé ètò ayé ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú yẹ̀ wò fínní fínní, aórìí pe ohun erè oko ló jẹ́ lájorí ọrọ̀ ajé àwọn ènìyàn yìí. Àwọn erè oko wọ̀nyí ni wọ́n si ń fi ń ṣe pàṣípàrọ̀ láti tán àìní ara wọn ṣááju alábàápàbé wọn pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ funfun. 
	Ṣíṣa lábàápàdé àwọn aláwọ̀ funfun yìí mú kí àwọn aláwọ̀ dúdú ní àǹfàní àti ṣàmúlò àwọn ohun èlò míràn bíi: Jígí ìwojú, Iyọ̀, ọti líle àti àwọn ohun míràn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àti ibí yìí ni wọ́n ti kọ́ àṣà lílo àwọn ohun èlò táati dárúkọ ṣáájú yìí dípò pà sí pààrọ̀ tó mú ọ̀pọ̀ wàhálà lọ́ iwọ́. kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, ìlànà àti máa lo owó wá sí ojútáyé, tí ètò ọrọ̀ ajé sì wá búrẹ́kẹ́. 
	Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìbúrẹ́kẹ́ ọrọ̀ ajé yìí, ìyípadà díẹ̀ ló dé bá ipò ò ṣì tí àwọn aláwò dúdú yìí ti wà tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ́rí. 
	Èyí tó pọ̀jù nínú èrè ọrọ̀ ayé ìgbà ló dé yìó lóńlọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun. 
	Kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí tí ń pọ̀ sin i òṣì túbọ̀ ń bá àwọn aláwọ̀ dúdú fínra sí. 
	Kàyéfì ọ̀rọ̀ yìí ò sẹ̀yìn ìwà imúni sìn adáni lóró tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí fimú àwọn gìrìpá tó yẹ kó fi gbogbo ọpọlọ àti agbára wọn ṣiṣẹ́ láti mú ayé ìrọ̀rùn wáá bá ilẹ̀ wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 
	Nígbà tó yẹ kí àwọn gìrìpá aláwọ̀ dúdú máa ṣiṣẹ́ idàgbàsókè ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìlẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun ni wọ́n wà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn yìí ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. 
	Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ńlo àwọn aláwọ̀ dúdú láti tún orílẹ̀ èdè ti wọn se, àti láti pilẹ̀ ọrọ̀ ajé tó lààmì láka. 
	Gbogbo ìgbà tí ìmúni lẹ́rú  yìí n lọ lọ́wọ́, tí ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ funfun yìí sì ń tẹ̀ síwájú, kò sí ẹyọ iṣẹ́ ìdàgbàsókè kan ní orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú. 
	Ìgbà tí ìmúnilẹ́rú dáwọ́ dúró, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ti gòkè àgbà díẹ̀ ń se ni wọ́n tún yára gba ètò ìṣàkóso ìjọba lọ́wọ́ àwọn àláwọ̀ dúdú, tí wọ́n sì sọ pé, ọ̀làjú ni àwọn fẹ́ẹ́ fi wọ àwọn aláwọ̀ dúdú yìí tí ẹ̀wù ìdí nìyí tí àwọn fi tẹ wọ́n lóríba tí àwọn sì fi pá gba ijọba wọn. 
	Òtítọ́ tó dájú nip é, àwọn aláwọ̀ funfun yìí ríi pé ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú dára fún àwọn iṣé ọ̀gbìn erè oko kan bíi: kòkó rọ́bà, ẹ̀pà, àti kọfí èyí tí ó wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ohun èlò àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti dá sílẹ̀. 
	Wọ́n wá fi tì pá tì kúùkù sọ̀ ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú di oko Ọ̀gbìn àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò tí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ti wọn. 
	Ipò Ìṣẹ́ àti Ìmúni sìn yìí ni àwọn aláwọ̀ dúdú wà tí tí fi di ìgbà tí wọ́n sọ pé àwọn funfun wọn ní òmìnira. 
	Ipò òṣì àti àre tí àwọn aláwọ̀ funfun fi àwọn ènìyàn yìí sí kò jẹ́ kí wọ́n ó lè dá dúró, kí wọ́n sì dáńgbájíá láti máage àwọn ohun ti wọ́n nílò ní ilé iṣẹ́ ìgbàlódé ti wọn fún raa wọn. 
	Àwọn aláwọ̀ funfun yìí ló sì wá ń dá iye owó tí ohun erè oko tó ń wá láti ilè àwọn aláwọ̀ dúdú yíò jẹ́, èyí ti ó ń túmọ̀ sí pé, ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni dídọ lọ́rọ̀ àti òdìkejì àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú wà. 
	Ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun yìí ni ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé wà, tó bá sì ṣe wùn wọ́n ni wọ́n ń lò ó. 
	Abálájọ tó fi jẹ́ owó tí wọ́n ń ná nílùú wọn fińṣe ìdíwọ̀n pàṣípàrọ̀ ọjà ní ọjà àgbàyé. 
	Kódà, àwọn orílẹ̀ èdè kan tó ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ kan tí àwọn aláwọ̀ funfun yìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní, bíi epo rọ̀bì ò he è dá ohun kan ṣe lórí ohun àmúṣọrọ̀wọn yìí láì sí ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun  yìí níbẹ̀. 
	Abálájọ tó fi ṣòro láti rí orílẹ̀ èdè aláwọ̀ dúdú kankan nínú àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà. 




#Article 72: Ìṣèlú (533 words)


Ìṣèlú tabi òṣèlú ni igbese bi awon idipo eniyan kan se n sepinnu. Oro yi je mimulo si iwuwa ninu awon ìjọba abele.

Ní àwùjọ Yorùbá, á ní àwọn ọ̀nà ìsèlú tiwa tí ó dá wa yàtọ̀ sí ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn. Kí àwọn Òyìnbó tó dé ní àwa Yorùbá ti ni ètò ìsèlú tiwa tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. Tí ó sì wà láàárin ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Yàtọ̀ sí tí àwọn ẹ̀yà bí i ti ìgbò tí ó jẹ́ wí pé àjọrò ni wọn n fi ìjọba tiwọn ṣe (acephalous) tàbí ti Hausa níbi tí àsẹ pípa wà lọ́wọ́ ẹnìkan (centralization). 

Ètò òsèlú Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti inú ilé. Eyi si fi ipá tí àwọn òbí ń kò nínú ilé ṣe ìpìlẹ̀ ètò òsèlú wa. Yorùbá bọ̀ wọn ní, “ilé là á tí kó èsọ́ ròdé”. 
Baba tí ó jẹ́ olórí ilé ni ó jẹ́ olùdarí àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèlú wa. Gbogbo ẹ̀kọ́ tó yẹ fún ọmọ láti inú ilé ni yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Bí i àwọn ẹ̀kọ́ ọmọlúàbí. Tí èdèàiyèdè bá sẹlẹ̀ nínú ile, bàbá ni yóò kọ́kọ́ parí rẹ̀. tí kò bá rí i yanjú ni yóò tó gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ mọ́gàjí agbo-ilé. Agbo-ilé ni ìdílé bíi mẹ́rin lọ sókè tó wà papọ̀ ni ojú kan náà. Wọn kó ilé wọn papọ̀ ní ààrin kan náà. Tí mógàjí bá mọ̀ ọ́n tì, ó di ọdọ olóyè àdúgbò. Olóyè yìí ni ó wà lórí àdúgbò. Àdúgbò ni àwọn agbo-ilé oríṣìíríṣìí tí ó wà papọ̀ ní ojúkan. A tún máa ń rí àwọn Baálè ìletò pàápàá tí wọ́n jẹ́ asojú fún ọba ìlú ní agbègbè wọn. Àwọn ni ọ̀pá ìsàkóso abúlé yìí wà ní ọwọ́ wọn. Ẹjọ́ tí wọn kò bá rí ojúùtú sí ni wọ́n máa ń gbé lọ sí ọdọ ọba ìlú. Ọba ni ó lágbára ju nínú àkàsọ̀ ìsàkóso ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá ka àwọn Ọba wọn sí òrìṣa Ìdí nìyí tí wọn fí máa ń sọ pé: 

Ọ̀kan tí ó lé nínú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ òkànlénú tàbí ọ̀kàn-lé-ní-rinwó (401), àwọn ọba ni. Wọn a ní. 

Ọba yìí ní àwọn ìjòyè tí wọn jọ ń ṣèlú. Ẹjọ́ tí ọba bá dá ni òpin. Ààfin ọba ni ilé ẹjọ́ tó ga jù. Ọba a máa dájọ́ ikú. Ọba si le è gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó tàbí ohun ìní ẹlòmíì. Wọ́n a ní: 
Ọba kì í mùjẹ̀
Ìyì ni ọba ń fi orí bíbẹ́ ṣe. 

A rí àwọn olóyè bí ìwàrèfà, ní òyọ́ ni a ti ń pè wọ́n ní Ọ̀yọ́-mèsì. Ìjòyè mẹ́fà tàbí méje ni wọn. Àwọn ni afọbajẹ. A rí àwọn ìjòyè àdúgbò tàbí abúlé pàápàá tí ó máa ń bá ọba ṣe àpérò tàbí láti jábọ̀ ìlọsíwájú agbègbè wọn fún un. 

A tún ń àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń dáàbò bo ọba àti ìlú. Àwọn ni wọn ń kojú ogun. Àwọn ni o n lọ gba isakọlẹ fọ́ba. A tún ní àwọn onífá, Babaláwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Ètò òsèlú wa tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí ni ó mú kí ó sòro fún àwọn òyìnbọ́ láti gàba tààrà lórí wa (Indirect rule). Àwọn ọba àti ìjòyè wa náà ni wọn ń lò láti ṣèjọba lórí wa. Ó pẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó rí wa wọ.




#Article 78: Afghanístàn (214 words)


Afghanístàn (; Pashto/Dari: , Pashto:  , Dari:  ), àlòṣiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira Onímàle ilẹ̀ Afghanístàn, ni is a orílẹ̀-èdè onílẹ̀bodè ní Gúúsù àti Àrin Ásíà. Afghanístàn ní bodè mọ́ Pakistan ní ìlà-òrùn àti ní gúúsù; mọ́ Iran ní ìwọ̀-òrùn; mọ́ Turkmenistan, Uzbekistan, àti Tajikistan ní àríwá; àti mọ́ Ṣáínà ní àríwá-ìlàòrùn. Gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀ fẹ̀ tó , orílẹ̀-èdè olókè ní tó ní ilẹ̀ pẹpẹ ní apá àríwá àti gúúsù-ilàòrùn. Kabul ni olúìlú àti ilú tótóbijùlọ níbẹ̀.  Iye aráàlú ibẹ̀ fẹ́ ẹ̀ pọ̀ tó 32 mílíọ́nù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà àwọn Pashtun, Tajik, Hazara àti Uzbek.

Nínú ètò ìkànìyàn 1995, àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé ó wà ní ìlú yìí lé díẹ̀ ní mílíònù mọ́kànlélógún (21,017.000). 
Èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí tó àádọ́ta ṣùgbọ́n ìlàjì nínú àwọn tí ó wà ní ìlú náà ni ó ń sọ páṣítọ̀ (Pashto) tí òun àti Dárì jọ jẹ èdè ìjọba (official language).
Dárì (Dari) yìí nì orúkọ tí wọ́n ń pe Persian (Pásíà) ní Afuganísítàànù. 
Dárí yìí ṣe pàtàkì gan-an ni gẹ́gẹ́ bí èdè tí ìjọba ń lò (lingua franca). 
Fún ti òwò tí ó jẹ mọ gbogbo àgbáyé, èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i. 
Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n ń sọ ní ìlú yìí ni Tadzhik, Uzbek, Turkmen, baluchi, Brachic àti pashayi




#Article 79: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Áfríkà Amẹ́ríkà (181 words)


Àpèjá AAVE duro fun African-American Vernacular English, ìyẹn ni, ede Geesi tí àwọn ọmọ Afrika Amerika n so ni ile Amerika. 
Ọ̀kan nínú àwọn èdè àdúgbò ni. Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n tún ń pe èdè yìí ni Black English Vernacular (BEV), Afro-American English àti Black English. Àwọn àmì ìdámò èdè yìí ni pé wọn kì í lo ‘s’ tí ó jẹ́ àtọ́ka ẹni kẹ́ta ẹyọ, bí àpẹẹrẹ, She walk , wọn kìí lo be, bí àpẹẹrẹ, They real fine. wọ́n sì máa ń lo be láti tọ́ka ibá atẹ́rẹrẹ bárakú, bí àpẹẹrẹ, Sometime they be walking round here. A kò le so pàtò ibi tí èdè yìí ti sẹ̀. 
Àwọn kan sọ pé láti ara kirio (Creole) ni ṣùgbọ́n àbùdá rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí a ń ṣe àkíyèsí rẹ̀ lára èdè Gẹ̀ẹ́si tí wọn ń sọ ní gusu Àmẹ́ríkà jẹ́ kí àwọn kan gbà pé láti ara èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ó ti wáyé. 
Èdè yìí wá ní àbùdá tirẹ̀ nígbà tí àwọn dúdú kọjá sí àwọn ìlú ńláńlá. wọ́n wá ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí àmì àdámọ̀ fún ara wọn.




#Article 80: Èdè Áfríkáánì (180 words)


	
Èdè ìwọ̀ oòrùn Jámìnì (a West Germany language) tí ó wáyé láti ara Dọ́ọ̀jì (Dutuh) ni eléyìí tí wọ́n ń sọ ní Gúsù Aáfíríkà. 
Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó míhíọ̀nù mẹ́fà. Wọ́n ń sọ ọ́ ní Nàmíbíà, màláwì, Zambia àti Zimbabwe. 
Àwọn kan tí ó sì ti ṣe àtìpó lọ sí ilẹ̀ Australia àti Canada náà ń sọ èdè náà. Wọ́n tún máa ń pa èdè yìí ni kéépú Dọọ̀jì (lapa Dutch). 
Èdè àwọn tí ó wá tẹ ilẹ̀ Gúsù Aáfíríkà dó ní ṣẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún (17th century) ni ṣùgbọ́n ó ti wá yàtọ̀ sí èdè Dọ́ọ̀jì (Dutch) ti ilẹ̀ Úroòpù (Europe) báyìí nítorí èdè àdúgbò kọ̀ọ̀kan ti ń wọ inú rẹ̀. 
Èdè yìí ni èdè tí ó lé ní ìdajì àwọn funfun tí ó dó sí Gúsù Aáfíríkà ń sọ. Ìdá àádọ́sà n-án àwọn tí òbí wọn jẹ́ ẹ̀yà méjì ni ó sì ń sọ èdè yìí pẹ̀lú. 
Láti ọdún 1925 ni wọn ti ń lo èdè yìí pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè ìjọba. Èdè yìí tin í lítírésọ̀. 
Àkọtọ́ Rómáànù ni wọ́n fi ń kọ ọ́.




#Article 81: Albáníà (185 words)


Albáníà ( , , Gheg Albanian: Shqipnia/Shqypnia), lonibise bi Orileominira ile Albáníà (, pipe ; Gheg Albanian: Republika e Shqipnísë), je orile-ede ni Guusuilaorun Europe, ni agbegbe awon Balkani. O ni bode mo Montenegro ni ariwailaorun, Kosovo ni riwailaorun, Orileominira ile Makedonia ni ilaorun ati Girisi ni gusu ati gusuilaorun. O ni eti-omi ni egbe Omi-okun Adriatiki ni iwoorun, ati legbe Omi-okun Ionia ni gusiiworun. O fi iye to din ni  jinna si Italy, nikoja Strait of Otranto to ja Adriatic Sea po mo Ionian Sea.
Albáníà je omo egbe UN, NATO, Agbajo fun Abo ati Ifowosowopo ni Europe, Igbimo ile Europe, Agbajo Owo Agbaye, Agbajo Ipade Onimale be sini omo egbe lati ibere Isokan fun Mediteraneani. Albania ti fe di omo egbe Isokan Europe lati January 2003, be sini o ti toro lati di omo egbe lati 28 April 2009.

Albáníà je oseluarailu onileasofin pelu itokowo toun yipada. Oluilu Albáníà, Tirana, je ile fun awon eniyan bi 600,000 ninu awon eniyan 3,000,000 to wa lorile-ede na. Atunse oja alominira ti si orile-ede sile fun inawo idagbasoke latokere, agaga fun idagbasoke okun ati eto irinna.




#Article 82: Àlgéríà (119 words)


Àlgéríà (Arabiki: , al-Gazā’ir), fun onibise Orílẹ̀-èdè Olómìnira Òṣèlú àwọn Ènìyàn ilẹ̀ Àlgéríà, je orile-ede ni Ariwa Afrika. Ile re ni ti orile-ede ti o tobijulo ni Okun Mediterraneani, ekeji totobijulo ni orile Afrika leyin Sudan, ati ikokanla totobijulo lagbaye.

Àlgéríà i bode ni ariwailaorun mo pelu Tunisia, ni ilaorun pelu Libya, ni iwoorun pelu Moroko, ni guusuiwoorun pelu Apaiwoorun Sahara, Mauritania, ati Mali, ni guusuilaorun pelu Niger, ati ni ariwa pelu Okun Mediterraneani Sea. Titobi re fe je , be si ni iye awon eniyan re je 35,700,000 ni January 2010. The capital of Algeria is Algiers.

Àlgéríà je omo egbe Iparapo awon Orile-ede, Isokan Afrika, ati OPEC. Bakanna o tun kopa ninu dida ikoenu owo Isokan Maghreb.




#Article 83: Àwọn èdè Altaic (149 words)


Awon ede Altaic
Àkójọpọ̀  èdè tí ó tó ọgọ́ta tí nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-dínlọ́gọ́fà ènìyàn ń sọ ni a ń pè ní  ‘Altaic’. Wọ́n ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ní Penisula Balkan (Balkan Penisula) ní ìlà-oòrùn àríwá ilẹ̀ Asia. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹgbẹ́ Turkic, Mongolian àti Manchus-Tungus. Àkọsílẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àkọsílẹ̀ lórí Turkic wà ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹ́jọ (8th Century) ṣùgbọ́n a kọ̀ mọ nǹkan kan nípa Mongolian ṣáájú sẹ́ńtúrì kẹtàlá (13th Century). Ó tó sẹ́ńtúrì kẹtàdúnlógún (17th Century) kí a tó rí  àkọsílẹ̀ kanka nípa Manchu. Ní sẹ́ńtúrì ogún (20th Century), ìgbìyànjú tó ga wáyé láti sọ àwọn èdè yìí di èdè òde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó wuyì ni ó ń jáde tí a fi àwọn èdè àdúgbò kọ, bí àpẹẹrẹ, Uzbek. Wọ́n tún ṣe àtúnse sí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ Turkish




#Article 84: Orúkọ Yorùbá (857 words)


Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń lò jákè-jádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Yorùbá bí Ìbíní,Tógò àti Nàìjíríà.
Nípaṣe ìṣe àwọn baba ńlá baba àwọ́n Yorùbá, eọ́n ń fún ọmọ wọn lórúkọ níbi ayẹyẹ tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ lẹ́yìn ìbímọ.Àwọn orúkọ àwọn ọmọ jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ifá dídá tí ọ̀pọ̀ Babaláwo bá dá, ṣùgbọ́n ní ayé òde-òní, orúkọ ọmọ tún lè wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó bá ní ipò tóga nínú ẹbí pẹ̀lú bàbá,ìyá,òbí àwọn òbí méjéèjì tàbí ẹni tí ó súnmọ́ wọn gbágbá.Ìyá àti bàbá,àti alásùn-ún-mọ́ wọn lè fún ọmọ tàbí àwọn ọmọ ní orúkọ tóbá wù wọ́n.Orúkọ ọmọ sáábà máa ń wá láti ọ̀dọ àwọn òbí méjéèjì ìyá àti bàbá ọmọ àti àwọn obí tó bí òbí méjéèjì yí wọ́n bí ọmọ tí wọ́n fẹ́ sọ lórúkọ.orúkọ ìbílẹ̀ tí a  dífá fún láti ọ̀dọ Babaláwo ń ṣe àfihàn òrìṣà tó ń ṣe atọ́nà ọmọ náà wá sáyé, yálà ọmọ náà jẹ́ àtúnbí oònilẹ̀ àtipé kádàrá ọmọ àti nípa ti ẹ̀mí tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí,tí ó máa ran ọmọ 
náà lọ́wọ́ láti lè jẹ́ kí ó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.Ayẹyẹ ìkọ̀kọ̀ àkọ́kọ́ kan tún wà fún ìyá àti bàbá ọmọ nìkan níbi tí orúkọ àti èèwọ̀ yóò ti máa jẹ́ fífún ọmọ àti òbí rẹ̀,àti àbá lórí ohun tí ọmọ náà máa nílò láti fi ṣe àṣeyọrí.Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìnáwó àwùjọ tí àsè àti àríyá ti wáyé tí ẹbí àti ojúlùmọ̀ sì ti jẹ́ ìpè àwọn obí ọmọ láti wá báwọn ṣàjọyọ̀ ìbí ọmọ náà.

Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun tí ènìyàn máa ń sáábà kíyèsí láàrin ọ̀sẹ̀ sáájú ayẹyẹ ìṣọmọ-lórúkọ gẹ́gẹ́ bí i àbójútó ńlá tí ó wà lórí gbígbé e lórí i yíyan orúkọ kan tí kò ní ìrísí lórí èyíkéyìí ìwà tó lòdì tàbí ìwà búburú láàrín àwùjọ̀,ní ọìgbà mííràn yíyan orúkọ tí ó ti ọ̀daràn kan tẹ́lẹ̀ fún ọmọ Yorùbá kan kìí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí èrò ọlọ́gbọ́n (gẹ́gẹ́ bí i ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èrò Yorùbá)lè mú kí ọmọ náà ó di olè tàbí ọ̀daràn lọ́jọ́ iwájú.

Èyí ni a tún mọ̀ sí orúko àmútọ̀runwá,(orúkọ tí a gbà wí pé àti ọ̀run ni a ti gbé e wá tàbí tí a tí jẹ bọ̀ láti)  àpẹẹrẹ ni Àìná,ìgè,òjó,Yéwándé,Abọ́ṣẹ̀dé,Táíwò,kẹ́hìndé,Ìdòwú,Àlàbá,Babatúndé,Jọ́ọ̀ọ́dá,Ájàyí,Abíọ́nà,Dàda,ìdògbé,Yéwándé.

Èyí ni (orúkọ tí a fún ọmọ ní ọjọ́ tí ań ṣàjọyọ̀ ìbí rẹ̀,yálà látẹnu àwọn òbí rẹ̀ ni tàbí àwọn alásùn-ún-mọ́ fún un)ni a tún ń pè ní orúkọ àbisọ.Èyí sábà má ń jẹ mọ́ ipò tí ẹbí tábí àwọn ọòbí ọmọ náà wà ní àwùjọ. ìwọ̀nyíni:Ọmọtáyọ̀,Ìbílọlá,Adéyínká,Ọláwùmí,Ọládọ̀tun,ìbídàpọ̀,Ọládàpọ̀,ọlárìndé,Adérónkẹ́,Ajíbọ́lá,Ìbíyẹmí,Morẹ́nikẹ́,Mojísọ́lá,Fọláwiyọ́,
Ayọ̀délé,Àríyọ̀,Oyèlẹ́yẹ,Ọmọ́táyọ̀,Fadérera.

Àwọn orúkọ yìí ni: Àyìnlá,Àjíkẹ́,Àlàó,Àdìó,Àkànmí,Àmọ̀ó,Àríkẹ́,Àgbékẹ́,Àjìún,Àlàkẹ̀,Àwẹ̀ró,Àbẹ̀bí,Àrẹ̀mú,Àlàní,Àyìnké.
ORÚKỌ ÀBÍKÚ
Èyí ń ṣàfihàn ìmọ̀sílára àwọn Yorùbá àti ìgbàgvọ́ eọn nípa ẹ̀mí àìrì,ikú àti àkúdàáyà.
Àpẹẹrẹ orúkọ àbíkú ni:Málọmọ́,Kòsọ́kọ́,Dúrósinmí,Ikúkọ̀yí,Bíòbákú,Kòkúmọ́,Ikúdàísí,Ìgbẹ́kọ̀yí,Àńdùú,Kásìmáawòó,Ọmọ́túndé,Dúrójayé,kalẹ̀jayé.

Orúkọ ìnagijẹ ni orúkó tí wọ́n ma ń fúni látàrí ìhùwà sí,ìrísí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ ni Eyínfúnjowó,Eyínafẹ́,Ajíláran,Ajíṣafẹ́,Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́,Arikúyẹrí,Agbọ́tikúyọ̀,Awẹ́lẹ́wà, ìbàdí àrán àti bblọ. éjì nínú orúkọ àmútọ̀run wá Yorùbá tó gbajúmọ̀ jù ni Táíwò(tàbí Táyé) àti Kẹ́hìndé tí wọ́n fún àwọn ìbejì ní pàtàkì. Ó jẹ́  ìgbàgbọ́ pé àkọ́kọ́ nínú ìbejì ni Táíwò(tàbí Táyé)tí ó gbèrò láti kọ́kọ́ jáde wá sáyé láti finmú fínlẹ̀ bóyá agbègbè ibi tí wọ́n fẹ́ wọ̀ dára tàbí kò dára láti wà sínú ẹ̀.Tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn á tẹ́wọ́ gba ìkejí rẹ̀ Kẹ́hìndé(nígbà mííràn á dá kẹ́hìndé padà)kó ní kó má a bọ̀.
Òmíràn pẹ̀lú ẹ̀sìn àbáláyé:àpẹẹrẹ ni Ifáṣọlá-Ifá ṣe àṣeyọrí.ó ṣeéṣe fífún ọmọ tí wọ́n máa kọ́ gẹ́gẹ́ bí i babaláwo àti iṣẹ́ ifá máa jẹ́ kí ó dọlọ́rọ̀ àti aláṣeyọrí.
Àwọn obí onígbàgbọ́ ìgbàlódé fún ìṣe kí wọ́n máa lo orúkọ àbáláyé fún pípáàrọ̀ orúkọ òrìsà fún OLÚ tàbí OLúWA,ìtumọ̀ olúwa tàbí olúwa mi tí ó ń tọ́ka sí èròǹgbà onígbàgbọ́ nípa ỌLỌ́RUN àti Jésù kírísítì.Fún àpẹẹrẹ Olúwatiṣé-olúwa ti ṣé,àwọn òbí gbàdúrà fún ọmọ olúwa náà sì fún wọn níkan.
Àwọn òbí mùsùlùmí máa ń fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn ní orúkọ Lárúbáwá nígbàmííràn pẹ̀lú pípè Yorùbá,Ràfíáh di Ràfíátù. Orúkọ ipaṣẹ̀ tún lè ṣàkàwé ipò tí ìdílé náà wà láwùjọ(àpẹẹrẹ Adéwálé orúkọ ìdílé ọba àtàtà)Ó tún lè ṣàkàwé iṣẹ́ abínibí ìdílé kan(àpẹẹrẹàgbẹ̀dẹ,àwọn Alágbẹ̀dẹ).
Yorùbá tún ní oríkì irú èyí tí àwọn akọ́ríkì máa ń lò láti tẹpẹlẹ mọ́ Àṣeyọrí aṣáájú ti oríṣìíríṣìí ìdílé.Oríkì tún lè jẹ́ ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ bì i Àdúnnítàbí kí ó jẹ́ ẹṣẹ̀ ìwé tàbí jáǹtìrẹrẹ.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kì í ṣe ipa àtàtà ni ó ń kó nínú orúkọ gidi,oríkì máa ń sáábà jẹ́ lílò ní ẹ̀gbẹ́ kan ,ó máa ń sáábà jẹ́ ohun tí gbogbogbò mọ̀ mọ̀ọ̀yàn ní àkókò kan.Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ni àwọn ará ìlú mìíràn lè dámọ̀ kódà ìdílé wọn nípa lílo oríkì okùn ìrandíran won.
Iṣẹ́ kékeré ni Yíyan orúkọ níṣẹ̀yí nítorí kòsí àkójọpọ̀ orúkọ Yorùbá tó pé.
síbẹ̀síbẹ̀ iṣẹ́ àgbéṣe titun Látọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣe gbogbo orúkọ Yorùbá sí kíkọ sílẹ̀ sínú ìwé arídìí ní ti ìlànà onírúurú ọ̀nà ìgbàròyìn.

Oruko Yoruba naa ni iwe yii da le. O soro nipa jije oruko, eto ikomojade, oruko amutorunwa, oruko abiso ati oruko mti won n fun abiku, iyato laarin oruko ati alaje ki o to wa fi orile pari re. Ibeere wa ni opin iwe fun idanrawo. Awon itumo awon oro ti ta koko naa si wa pelu.




#Article 85: Èdè Azerbaijani (111 words)


Èdè Azerbaijani

Ọmọ ẹgbẹ́ ni èdè yìí jẹ́ fún ẹgbẹ́ èdè tí a ń pè ní Turkic. Ẹgbẹ́ èdè Turkic yìí jẹ́ ọmọ ẹbí Altaic. Àwọn tí ó ń sọ Azerbaijani tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ní Azerbaijan ní ibi tí wọ́n ti ń lò ó gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣe ìjọbi. Wọ́n tún ń sọ èdè yìí ní Turkey, Syria àti Afgloanistan. Wọ́n tún máa ń pe èdè yìí ni Azeri. Àkọtọ́  Cyrillic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Azerbaijan ṣùgbọ́n àkọtọ́ Arabic ni wọ́n fi ń kọ ọ́ sílẹ̀ ní Iran.  Wọ́n fi ojú èdá èdè pín wọn sí Swuthern Azerbaijani) àti Northern Azerbaijani tí mílíọ̀nù méje ènìyàn ń sọ.




#Article 86: Australian (198 words)


Austrolian ni a orúkọ fún ẹgbẹ́ àwọn èdè kan tí àwọn aborigine ń sọ. Àwọn èdè yìí fi bí obọ̀n lé ní igba (230) síbè àwọn tí ó ń sọ wọ́n kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n lọ. 
	Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹbí bí ọgbọ̀n ó dún méjì nítorí wí pé wọ́n ní wọ́n bá ara wọn tan. Gbogbo àwọn èdè wọ̀nyí, yàtọ̀ sí ọ̀kan nínú wọn ni ó wà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Australia àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá (Northern Territory) àti Queensland. Gbogbo ilẹ̀ tí  a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò ju ìdá mẹ́jọ ilẹ̀ Austrolia lọ. Ṣùgbọ́n èdè tí a ń pe ẹbí rẹ̀ ní Pama-Nyunga ni ó gba gbogbo ilẹ̀ yòókú ní Austrolia. Àwọn èdè tí ó wà nínú ebí yìí tó àádọ́ta tí àwọn ènìyàn sì ń lò wọ́n dáadáa. 
	Àwọn èdè tí àwọn ènìyàn ń sọ jù ni twi, Wapiri, Aranda, Mabuyng àti Western Desert. Àwọn tí ó ń sọ òkọ̀ọ̀kan wọn lé tàbí kí ó dún díẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún. Láti nǹkan búséńtúrì kejìdúnlógún àwọn èdè tí ó ní àwọn tí ó ń sọ wọ́n ti ń dínkù jọjọ. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó sẹ́kì yìí ti ń parẹ́.




#Article 87: Ìmàle (2536 words)


Ẹ̀sìn Ìmàle tabi Ẹ̀sìn Islàm ( , ) jẹ́ ẹ̀sìn àlááfíà,ìrọ̀rùn àti ìjupá-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run aṣẹ̀dá gbogbo ayé nípa ṣ́iṣe ìfẹ́ àti títèlé àṣẹ rẹ̀ yálà o tẹ́ ọ lọ́rùn tàbí kò tẹ́ ọ lọ́rùn. Ó tún jẹ́ ẹ̀sin tí Ọlọ́run tún  fi ránṣẹ́ sí gbogbo ayé látọwọ́ àwọn òjíṣ̣́e rẹ̀ tó ti rán wá ṣáájú ànọ́bì Muhammad ọmọ Abdullah (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun ó ma bá a). Òun sì ni ẹ̀sìn òtítọ tí ẹ̀sìn mìíràn kò lè jẹ́  ìtẹ́wọ́gb̀a ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun (Allah) yàtò sí òun nìkan. Ọlọ́hun (Allah) sì ti ṣe é ní ẹ̀sìn ìrọ̀rùn tí kò sí ìṣòro kankan tàbí wàhálà níbẹ̀. Kò si ohun tí ó kọjá agbára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìjẹni nípá fún àwọn tí wọ́n gba èsìn náà. Bẹ́è sì tún ni ẹ̀sìn náà kò la ohun tí ó kọjá agbára wọn bọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ìsìlámù ni ẹ̀sìn tí ó ṣe pé ìmọ̀-Ọlọ́hun ni (al- Taoheed) ní ìpìl̀ẹ rè, òdodo ni òpó rẹ̀, ó dá lórí déédé,otito. Òhun sì ni ẹ̀sìn tí ó gbópọn tí ó jẹ́ pé ó ń darí gbogbo ẹ̀dá sí ibi gbogbo ohun tí yó̀o jẹ́ ànfààní fún wọn ní ọ̀run àti ayé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì tún ń kì wọ́n nílọ̀ nípa gbogbo ohun tí yó̀o ṣaburú fún wọn yálà láyé ni tàbí ọ̀run. Ohun ni ẹ̀sìn ti Ọlọhun (Allah) fi se atunse awon adi-okan ati awon iwa. Ohun naa ni O fi se atunse isemi aye ati ti orun. Oun ni Ọlọhun (Allah) fi se ìrẹ́pọ̀ laarin awon ọkàn ti o keyin si ara won ati awon ojúkòkòrò ti o fonka. Nipase eyi ni O fi yọ àwọn ohun ti a ka si iwaju yii ninu òkùnkùn biribiri iro, ti O si se ifinimona rẹ̀ lo si ibi otito, ti O si to si ọ̀nà lọ si ibi ọ̀nà ti o ye kooro.

ISLAM ni esin ti o duro to, eyi ti a gbe kale ni ona ti o dara de opin ninu gbogbo awon iro ti o muwa ati ninu gbogbo awon idajo re pata.Ko si iroyin kankan ninu re ayafi otito ati ododo be e si ni ko si idajo kankan ninu re ayafi rere ati deede. Ninu re ni a o ti ri awon adisokan ti o ni alaafia, awon ise ti o duro to ,awon iwa ti o dara pari pelu awon eko ti o ye kooro..

Ni soki, ise ISLAM wa lati se aseyori awon ohun ti o n bo wonyii:

Ni akotan, a lee rokirika awon ohun ti esin islam pe ni lo si ibe ninu awon koko ti o n bo wonyii:

Eleyin da lori igbagbo pelu awon origun igbagbo mefeefa:

Eyi le e je be e pelu awon nikan ti o n bo wonyii:

Awon molaaika ni awon eru Olohun kan ti won je eni aponle gegebi won ti je eda Olohun (Allah). Bakannaa, won je oluse ibaada (ijosin) fun Olohun de oju ami won si tun je atele ase re ni perepere. Olohun (Allah) fi awon ise (ojuse) orisirisii fun okookan won. Ninu won ni Jibiriilu eni ti a se afiti ise mimo ti o ba n waye lati odo Olohun (Allah) si odo eni ti O ba fe ninu awon anabi Re ati awon ojise Re ti si. Ara won si tun ni Miikailu eni ti o wa fun alaamori riro ojo ati awon koriko ti n hu. Bee naa ni ara won ni Isiraafiilu eni ti o wa fun fifon fere ni asiko ti Olohun (Allah) ba fe ki gbogbo eda o sun oorun asun- fonfon- n-tefon ti yoo kase ile aye nile ati nigba ti o ba tun fe ki won dide (lati jabo nipa igbesi aye won). Ara won si tun ni molaaika iku eni ti ojuse re je gbigba awon emi ni asiko ti Olohun (Allah) ba ti ni asiko re to.

Olohun (Allah), Oba ti o tobi ti o si gbon-un -gbon julo so awon iwe kale fun awon ojise Re eyi ti ona mimo, rere ati daradara wa ninu re. Awon ti gbedeke re waye ninu awon tira yii ni wonyii:

Olohun (Allah) ti ran awon ojise kan si awon eda Re.

Eni akoko ninu awon ojise naa ni anabi Nuhu nigbati anabi Muhmmad (ki ike ati ola Olohun o ma a baa ati gbogbo awon ojise ti o siwaju re)si je olupinnu won. Gbogbo awon ojise Olohun pata -ti o fi mo anabi Isa- je eda abara ti ko si nkankan ninu jije Olohun ni ara won. Awon paapaa je eru Olohun (Allah) gegebi awon eda yoku naa ti je eru Olohun sugbon ti Adeda won se aponle fun won pelu riran won ni ise mimo si awon eda abara yoku. Ni akotan, Olohun (Allah) ti pari gbogbo ise ti o fe ran si aye pelu ise-imona ti o fi ran anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa).O si ti ran an si gbogbo eniyan laiko da enikan si. Nitori naa, ko si anabi kankan mo leyin anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa).

Ojo agbehinde ni ojo ikehin ti ko ni si ojo kankan leyin ojo naa mo. Ojo naa ni Olohun (Allah) yoo gbe gbogbo eniyan dide ni aaye pada lati seku titi ayeraye ninu ile onidera (alujonna)tabi ninu ile iya (ina) atanijoni.

Ninu igbagbo si ojo ikehin jasi nini igbagbo si gbogbo ohun ti yoo sele leyin iku ni eyi ti o ko ibeere (fitino) saaree ati idera pelu ijiya re sinu. Ati ohun ti yoo tun sele leyin eleyii gegebi agbehinde, iseripadabo si odo Olohun ati isiro ise ti eda gbe aye se. Leyinwa-igba-naa, ni imorile ile ibugbe ayeraye eyi ti i se alujonna tabi ina.

Ohun ti oun n je kadara ni nini igbagbo pe Olohun (Allah) ni O pebubu gbogbo ohun ti n be, Ohun ni O si da gbogbo eda ni ona ti mimo Re ti siwaju re ti ariwoye Re si fe bee. Gbogbo awon alaamori ni o ti je mimo ni o si ti wa ni akoole ni odo Re. Olohun (Allah) fe gbogbo ohun ti n sele ni o je ki o maa sele bee, Oun paapaa ni o si daa.

Esin ISLAM je ohun ti a mo lori awon origun marun kan to je pe eniyan ko lee je musulumi tooto ayafi ti o ba ni igbagbo ninu awon origun naa ti o si n se okookan ninu re. Awon origun naa ni wonyi :

Ijeri (igba-tokantokan) pe Olohun (Allah) nikan ni Oba (ti a a josin fun) ati pe ojise Olohun ni anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) i se. Ijeri yii ni kokoro ISLAM ati ipilese re ti gbogbo eka yoku duro le lori.

Itumo a i si oba miran leyin Olohun (Allah) ni pe ko si eni ti o leto pe ki a ma a se ijosin fun ju oun nikan lo.Oun nikan ni apesin tooto. Gbogbo elomiran ti a ba n dari ijosin si odo re yato si Oun je iwa ibaje ti ko si lese nile bi o ti wu ki o mo. Ohun ti o n je Olohun Oba ninu agboye awa musulumi ni eni ti a a josin fun.

Itumo ijeri (ifaramo) pe anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) je ojise Olohun ni gbigba a ni ododo ninu gbogbo ohun ti o fun ni ni labare re, titele e ninu gbogbo oun ti o pa lase ati jijinna si gbogbo ohun ti o ko fun ni lati se ti o si jagbe mo a i fe be e.

Eyi ni awon irun ti a ma a n paara kiki re ni eemarun lojumo. Olohun (Allah) se e ni ofin lati lee je ifun Olohun ni iwo o Re lori awon eru Re, idupe fu Un lori ideraa Re ati okun idapo laarin musulumi ati Olohun Adeda re. Eyi ti yoo ma a ba A ni gbolohun ninu re ti yoo si ma a gbadura si I ninu re. Ti awon irun yii yo o si je akininlo fun un nipa sise ibaje ati sise aburu.

Olohun (Allah) si ti se imudaniloju daradara esin, igunrege igbagbo ati laada aye ati ti orun fun eni ti o ba n ki irun wakati maraarun daadaa. Ni ipase awon irun yii ni ibale-okan ati ibale-ara ti yoo je okunfa orire aye ati ti orun yoo fi sele fun eni ti o ba n kii deede.

Eyi ni ore atinuwa kan ti eni ti o ba ni owo ti o ti wo gbedeke ti ilana ISLAM se afilele re yoo ma a san ni odoodun fun awon eni ti o leto si gbigba re ninu awon alaini ati awon miran. A ni lati mo daju gbangba pe itore aanu yi i ko je dandan fun alaini ti ko si gbedeke owo yii ni owo re. Eni ti o je dandan fun ni awon oloro ti yoo je pipe fun esin won ati ifaramo ISLAM won .Ti yoo si tun mu ilosiwaju ba iwasi won ati ihuwasi won pelu. Eyi si tun je ona kan pataki lati mu iyonusi ati iyojuran aye kuro lara won ati lara dukia won. Ati lati se afomo fun won kuro nibi aburu pelu lati se ikunlowo fun awon talaka ati awon alaini lawujo ati lati se igbeduro ohun ti yoo mu nkan tubatuse fun awon gan an alara paapaa. Paripari gbogbo re, oore aanu yii ko koja ebubu kan kinkinni ninu ohun ti Olohun (Allah) se fun won ninu owo ati ije- imu.

Eleyi yoo ma a je ohun ti yoo ma a sele ninu osu kan soso lodoodun. Osu yen si ni osu Ramadan alaponle, eyi ti se osu kesan an ninu osu odun hijira (odun ti a n fi osupa mu ka). Ninu osu yii ni gbogbo awon musulumi yoo se ara won ni osusu-owo ti won yoo si kora duro nibii kosee-mase-kosee-mato won gegebi i jije, mimu ati wiwole to aya eni ni asiko osan. Iyen ni pe kikoraduro yo o wa lati asiko idaji hai (yiyo alufajari) titi di irole pata (asiko wiwo oorun). Olohun (Allah) yoo wa a fi pipe esin won ati igbagbo ati amojukuro nibi laifi won jiro ikoraduro yii fun won. Bee si ni pipe won yoo si lekun gegebi nkan daradara miran yoo ti je tiwon ninu awon oore lantilanti ti o ti pa lese sile fun eleyii ni ile aye nihaayin ati ni orun.

Ohun naa ni imura giri lo si ile Olohun (Allah) Olowo lati lo josin fun Un ni asiko kan pato gegebi o tise wa ninu ilana Islam. Olohun (Allah) ti see ni oranyan fun eni ti o ba ni ikapa bee ni igba isemi ni eekan soso. Ninu asiko haji yii ni gbogbo musulumi jakejado aye yoo kojo si aaye ti o loore julo lori ile, ti gbogbo won yoo maa se ijosin fun Olohun kan soso nibe ,ti won yoo si gbe ewu orisikan - naa wo. Ko ni i si iyato laarin olori ati ara ilu, olowo aye ati mekunnu pelu funfun ati dudu ninu won. 

Gbogbo won yo o ma a se awon ise ijosin mimo kan ti o ti ni akosile. Eyi ti o se koko julo ninu re je kikaraduro ni aaye ti a mo si Arafa ati rirokirika ile Oluwa (Kaaba) abiyi ti o je adojuko gbogbo Musulumi ni asiko ijosin won pelu ilosoke-losodo laarin oke Safa ati Moriwa. Awon anfaani aye ati orun olokan -o - jokan ti ko se e ka tan ni o wa ninu re.

Eleyi tumo si pe ki Musulumi maa sin Olohun re pelu igbagbo ati esin ododo gegebi eni-wipe o n wo Olohun Adedaa lojukoroju, bi o tile je pe ire kori I dajudaju Oun n ri o. Bakanaa, ki o rii daju wipe oun se ohun kohun ni ibamu pelu ilana (Sunnah) ojise e Re; annabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun ki o baa).

Bakan- naa ni ISLAM tun feto si igbesi aye awon eni ti o gba a lesin yala ni iwasi won ni eyo kookan ni o tabi nigbati won ba wa nijonijo ni ona ti oriire aye ati torun yo o fi je tiwon. Nitori idi eyi ni o fi se fife iyawo ni eto fun awon atele re ti o si se won lojukokoro lo sibe. O si se sina sise ati iwa pansaga ni eewo fun won ati awon isesi-i-laabi miran. Bee ni o si se dida ibi po ati sisaanu awon alaini ati talika ni oranyan pelu amojuto won. Gegebi o ti senilojukokoro lo si ibi gbogbo iwa to dara ti o si se e ni oranyan, bee gege ti o si kininilo nipa gbogbo iwa buruku ti o si se e ni eewo. Siwaju sii, o se kiko oro jo lona mimo gegebii owo sise tabi yiyafunnilo ati ohun ti o fara pe eleyii ni eto. Ni idakeji ewe, o se owo ele (riba) ati gbogbo owokowo ati ohun ti o ba ti ni modaru ati awuruju ninu ni eewo. 

Yato si ohun ti a ka siwaju yii, ISLAM se akiyesi aidogba awon eniyan ninu diduroto si oju ona ilana re ati siso eto awon eniyan miran. Nitori-idi-eyi ni o fi gbe awon ijiya amunisakuro-nibi-ese kale fun awon itayo -aala ti o ba waye ninu awon iwo Olohun (Allah ) Mimo; gegebii kikoomo (pipada sinu keferi leyin igba ti a ti gba ISLAM), sise sina, mimu oti ati bee bee lo.Gege bee naa ni o gbe awon ijiya adanilekun kale fun titase agere lori awon eto awon eniyan gegebii pipaayan, ole jija, piparo agbere mo elomiran, titayo aala nipa lilu elomiran tabi si see ni suta ati bee bee lo. O se pataki lati fi rinle pe awon ijiya kookan ti o fi lele yii se weku irunfin kookan la i si aseju tabi aseeto nibe. ISLAM tun seto, o si tun fi ala si ibasepo ti o wa laarin awon ara ilu ati awon adari won. O si se titele awon adari ni dandan fun awon ara ilu ninu gbogbo ohun ti ko ba si sise Olohun (Allah) ninu re. O si se yiyapa si ase won ati aigbo- aigba fun won ni eewo nitori ohun ti o le tara eyi jade ninu aapon ati rukerudo fun terutomo.

Ni akotan , a le e fowogbaya re pe ISLAM ti kakoja mimo asepo ti o yanran-un-tan ati ise ti o ye kooro laarin eru Olohun (eda) ati Adeda re ni abala kan, ati laarin omo eda eniyan ati awujo ti o n gbe nibe ninu gbogbo alaamori re ni abala miran. Ko si rere kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti se ifinimona awon atele re sibe ti o si se won lojukokoro nipa diduro tii gboin -gboin. Bee si ni ko aburu kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti ki won nilo gidigidi nipa atimasunmo o ti o si ko o fun won. Eyi ni o fi wa n han wa gedegbe pe esin ti ko labujeku kankan ni ISLAM je, esin ti o si dara ni pelu ti a ba gbe yiri wo ni gbogbo ona. 




#Article 88: Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje (341 words)


Irinkerindo ninu Igbo Elegbeje ni oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko.
Ìrìnkèrindò ni ìwé ìtàn-àròsọ yìí dá lé lórí. Ìwé yìí ni D. O. Fagunwa pè ní Apá Kẹ́ta Ògbójú  Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Nínú Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje, a ìbẹ̀rẹ̀ ìrììnàjò sí òkè ìrònú, alábàá pàdé ẹlẹ́gbára, ìtàn òmùgọ́diméjì àti Òmùgọ́dimẹ́ta ìtàn wèrédìran àti ìgbéyàwó Ìrìnkèrindò

Aiyé kún fún ibùgbé ìyanu, ọba bí Ọlọ́rûn kò sí, Olódùmarè ní ńṣe alákǒso ohun gbogbo tí ńbẹ ní òde aiyé àti òde ọ̀run, ìyanu ní aiyé pàápàá jẹ́: aiyé kún fún ènìà ẹlẹ́sẹ̀ méji ati eranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin,ejò afàiyàfà àti ẹja tí ńkákìiri inú omi, ẹiyẹ tí nkọrin bí fèrè àti alágẹmọ tí Olódùmarè wọ̀ ní onírúnrú asọ.Òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, oòrùn àti òsùpá, àwọ̀sánmọ̀ àti erùpẹ̀ ilẹ̀,gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìyanu.Bákannáà ní ọ̀rọ̀ sìsọ lásán yìí jẹ́ ìyanu, èyítí, mo sì gbọ́ ní ìjọ́sí ni mo ní kí nbá yín sọ lónǐ, ẹ̀nyin ọmọ ènìà..

Ní òwúrọ̀ ọjọ keji, ko pẹ púpò ti mò lọ kí àlejò wà yi tán tí nóẉn fi wí fún mi pé onjẹ tí ṣetán, gbogbo wà lọ sí tábílì, a jẹun. Ìyàlẹ́nu l’o jẹ fún mi pe bi o tilẹ̀ ti jẹ́ pé nkò sọ fún púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi nípa okùnrin na tó wọnni, síbẹ̀ ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀nìà l’o ti gbọ́ nípa okùnrin na, kí o sí tó di pe a jẹun àrọ̀ tán lọ́jọ́ na àwọn ẹ̀nìà tí rọ́ de ilé wa. Bí a tí jẹun tán ní mò ko àwọn ohun ìkọ̀wé jáde tí mò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, on na sí bẹ̀rẹ̀sí ọ̀rọ̀ ísọ ní: ...

	

	

	

Ibiti alejo mi sọrọ na fun mi mọ lọjọ ti a tun nkọwe na ni eyi, a ba da ọwọ duro lọjọ na, a ki awọn ti o wa gbọ ọrọ w ape ki noẉn ma lọ sile ki nwọn tun pada lọjọ keji. 
	
Ko pẹ pupọ ti ilẹ ọjọ keji si mọ ti gbogbo enia tun fi nrọ wọ ile mi, igbati awa na si jẹun tan, alejo mi tun bẹrẹ o nba itan na lọ o ni: 
	

	

	

	

	

	




#Article 89: Emere (167 words)


Olatinwo Adeagbo

Ọlátìńwò Adéagbo Fátokí (1991) Emèrè.  Ìbàdán, Nigeria: Heineman Educational Books Nig. PLC. ISBN 978-129-234-2. Ojú-ìwé 53. 

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

	Ohun tó gbé mi dé ìdí à ń kọ ìwé yìí ni ìgbàgbọ́ àti ihà tí àwọn ènìyàn kọ sí àwọn ọmọ tí à ń pè ní Emèrè. 
	Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rí àwọn ọmọ wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí Àbíkú, Ẹlẹ́gbẹ́, Ọ̀gbáńje, Ọmọ Ìyanu, Abáfẹ́fẹ́rìn-ọmọ Ẹlẹ́mìíkẹ́mìí-ọmọ àti Adíwọ̀n-ọmọ. Àwọn orúkọ wọ̀nyìí fi hàn pé ìṣòro ńlá wà láti dá Emèrè mọ̀. Lọ́wọ̀ọ́ ìgbà tó sì jẹ́ pé a ko le fi Ògún rẹ̀ gbárí pé Emèrè nìyìi, mo wá lọ sí Àròjinlẹ̀ ọkàn, mo pe kọ́lọ́fín ọpọlọ jáde, mo wá rí i pé Emèrè jẹ́ Àjíǹde-òkú tó ń pọ́n ọ̀bẹ sùn, tó tún fapò rọrí. Gbogbo ara ni wọ́n fi ṣe agbára. Ẹ̀mí àìrí tó sì ń bá wọn lò jẹ́ èyí tó ṣòro láti ṣàpèjúwe. Ọmọ kàyéfì ni Emèrè. À ní Àdánwò-ọmọ ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dúró fún tibi-tire tó bá bá àwọn lọ́kọláyà tó bá lùgbàdì wọn.




#Article 90: Báháráìnì (110 words)


Bahrain tabi Ile-Oba Bahrain	Ní ọdún 1995, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé orílẹ̀-èdè yìí tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dégbẹ̀ta àti ààbọ̀ (555,000). Èdè Lárúbááwá (Arabic) ni èdè ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè kan tún wà tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Àwọn èdè náà ni fáàsì (farsi) tí àwọn tí ó ń sọ ó ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́ta (48, 000); Úúdù (Urdu) tí àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) àti àwọn èdè fílípíìnì (Phillipine) mìíràn tí àwọn tí ó ń sọ wọ́n tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbayì ní ilẹ̀ yìí sí i gẹ́gẹ́ bí èdè òwò àti èdè ìṣe àbẹ̀wò sí ìlú (tourism).




#Article 91: Àwọn Bàhámà (183 words)


Àwọn Bàhámà () tabi lonibise bi Orílẹ̀-èdè Àjọni ilẹ̀ awọn Bàhámà, je orile-ede elede Geesi to ni awon erekusu 29, 661 cays, ati 2,387 erekusu kekere 2,387 (apata). O budo si inu Okun Atlantiki ni ariwa Kuba ati Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti), ariwaiwoorun awon Erekusu Turks ati Caicos, ati guusuilaorun orile-ede Awon Ipinle Aparapo ile Amerika (nitosi ipinle Florida). Apapo iye aala ile re je 13,939 km2 (5,382 sq. mi.), pelu idiye olugbe to to 330,000. Oluilu re ni Nassau. Bi jeografi, awon Bahama wa ni asopo erekusu kanna bi Kuba, Hispaniola (Dominiki Olominira ati Haiti) ati Awon Erekusu Turks ati Caicos. 

Awon onibudo ibe tele ni awon Taino ti Arawaka, awon Bahama ni ibi ti Columbus koko gunle si ni Ile Aye Tuntun ni 1492. Botilejepe awon ara Spein ko se amunisin awon Bahama, won ko awon Lucaya abinibi ibe (eyi ni oruko ti awon Taino Bahama unpe ara won) lo si oko eru ni Hispaniola. Lati 1513 de 1650 enikankan ko gbe ori awon erekusu yi, ko to di pe awon olumunisin ara Britani lati Bermuda tedo si erekusu Eleuthera.




#Article 92: Bàlúṣì (103 words)


Bàlúṣì tàbí Bàlóṣì

Baluchi or Balochi

	Ọmọ ẹgbẹ́ èdè tí a ń pé ní Iranian ni Bàlúṣì. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tọ́ mílíọ̀nù márùn-ún. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ọ́ yìí ni ó wà ní Pakísítáánì (Pakistan) ní Bàlúṣísítáànì (Baluchistan). Baluclistan yìí ni ìpínlẹ̀ (province) tí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn jùní pakcstan. Àwọn tí ó ń sọ èdè yìí ní Baluchistan tó múlíọ̀nù (Iran), Afuganíísítáànù (Afghanistan) àti In-índíà (India). Àkọtọ́ Lárúbáwá (Arabic) ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àjọ kan wà tí wọ́n ń pè ní Baluchi Academy tí ó ń ń sí pé àkọsílẹ̀ èdè yìí páye. 




#Article 93: Àwọn èdè Balto-Sílàfù (115 words)


Awon ede Balto-Slavic
Ẹgbẹ́ àwọn èdè tí wọ́n ní Baltic ati Slavic ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wá ń pe àwọn méjèèjì papọ̀ ní Balto-Slavic. Ọmọ ẹgbẹ́ ni àwọn èdè wọ̀nyí jẹ́ fún àwọn ẹ̀yà èdè (branch) tí a ń pè ní Indo-European (In-indo-Yùrópíànù). Àwọn tí ó ń sọ Baluto-Sìláfíìkì yìí tí mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn (300 million people). Eléyìí tí ó ju ìlàjì lọ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni ó ń sọ èdè Rọ́síà (Russian) 

Èdè àìyedè díẹ̀ wà lórí pé bíyá ibi kan náà ni gbogbo àwọn èdè yìí ti ṣẹ̀ tàbí pé nítorí pé wọ́n jọ wà pọ̀ tí wọ́n sì jọ ń ṣe pọ̀ ló jẹ́ kí ìjọra wà láàrin wọn.




#Article 94: Èdè Arméníà (198 words)


Èdè Arméníà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà. 

Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù Kírísítì Èdè Grabar yìí ni wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní, 

Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí. 

Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.




#Article 95: Arméníà (283 words)


Arméníà (; , siso Hayastan, ), fún iṣẹ́ọba bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Arméníà (, Hayastani Hanrapetut’yun, ), je orile-ede oke-ile ti ile yika ni agbegbe Kafkasu ni Eurasia. O budo si oritameta Apaiwoorun Asia ati Apailaorun Europe, o ni bode mo Turki ni iwoorun, Georgia ni ariwa, de facto Nagorno-Karabakh Republic alominira ati Azerbaijan ni ilaorun, ati Iran ati ile Azerbaijani Nakhchivan ni guusu.

A former republic of the Soviet Union, Armenia is a unitary, multiparty, democratic nation-state with an ancient and historic cultural heritage. The Kingdom of Armenia became the first state to adopt Christianity as its religion in the early years of the 4th century (the traditional date is 301). The modern Republic of Armenia recognizes the Armenian Apostolic Church as the national church of Armenia, although the republic has separation of church and state.

Armenia is a member of more than 40 international organisations, including the United Nations, the Council of Europe, the Asian Development Bank, the Commonwealth of Independent States, the World Trade Organization, World Customs Organization, the Organization of the Black Sea Economic Cooperation, and La Francophonie. It is a member of the CSTO military alliance, and also participates in NATO's Partnership for Peace (PfP) programme. In 2004 its forces joined KFOR, a NATO-led international force in Kosovo. It is also an observer member of the Eurasian Economic Community and the Non-Aligned Movement. The country is an emerging democracy, and is currently in a negotiation process with the European Union, of which it may become an Associate Member in the near future. The Government of Armenia holds European integration as a key priority in its foreign policy as it is considered a European country by the European Union.




#Article 96: Argẹntínà (149 words)


Argẹntínà	Nínú ètò ìkànìyàn 1995, iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà (Argentiana) lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì àti àti ààbọ̀ (34, 513, 000). Èdè Pànyán-àn ni èdè tí wọ́n fi ń ṣe ìjọba ní ibẹ̀. Àwọn èdè mìíràn tí wọ́n tún ń sọ ní orílè-èdè yìí lé ní ogún. Lára àwọn ogún èdè yìí ni àwọn èdẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Àmẹ́rídíánà (Ameridian Languages) wà. Ara àwọn èdè. 
	Àmérídíánà yìí ni ‘Guarani, Araucanian, Metaco àti Quechua’. 
	Àwọn èdè tí ó tún wà lára ogún yìí ni èdè tí àwọn tí ó wá se àtìpó ń sọ. Lára wọn ni èdè Ítílì (Ìtahàn) àti Jámánì (Herman). Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń gbilẹ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè fún òwò àgbáyé àti èdè àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wò wá sí ibẹ̀ (International trade and tourism). Wọ́n ń lo èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí pẹ̀lú èdè Pànyán-àn.




#Article 97: Èdè Árámáìkì (178 words)


Èdè Árámáìkì je ara èdè Sèmítíìkì (Semitic). Àwon tí ó ń so èdè yìí tó egbèrún lónà igba ní Ìráànù (Iran) àti Ìráàkì (Iraq) pèlú òpòlopò àwon mìíràn tí wón tún ń so ó ní Ààrin gbùngbùn ìlà-òòrùn àgbáyé (Middle tast). Láti séńtúrì kefà ni wón ti ń fi Árámáìkì àtijó (Classical Aramaic) ko nnkan sílè ní Ààrin gbingbein ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East). Hébéérù ni ó wá gba ipò rè gégé bí èdè tí àwon júù ń so.

Èka-èdè ìwò-oòrùn èdè yìí (Western dialect) ni èdè tí Jéésù Kristì àti àwon omo èyìn rè ń so. Èka-èdè kán tí ó wá láti ara èka-èdè yìí ni wón sì ń so ní àwon abúlé kan ní ilè Síríà àti Lébánóònù.

Ní nnkan  bíi séńtúrì kéje ni èdè Lárúbáwá gba ipò èdè Árámáìkì. Èka-èdè apá ìwo-oòrùn èdè yìí tí a ń pè ní Síríàkì (Syricac) ni àwon ìjo Àgùdà ará fíríàkì (Syriac Catholic) ń lò. 

Álúfábéètì méjìlélógún ni èdè yìí ní. Èdè yìí sì se pàtàkì nítorí pé láti ara rè ni Hébéérù, Lárúbáwá àti àwon èdè mìíràn ti dìde.




#Article 98: Èdè Lárúbáwá (354 words)


Ède Lárúbáwá tabi ede Araabu
Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)). Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí. 
	Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí. 
	Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. 
	Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).




#Article 99: Àngólà (150 words)


Àngólà, lóníbiṣẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Àngólà (, ; Kikongo, Kimbundu, Umbundu: Repubilika ya Ngola), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní apágúsù Áfríkà tó ní bodè mọ́ Namibia ní gúsù, Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò ní àríwá, àti Zambia ní ilàòrùn; ìwọ̀òrùn rẹ̀ bọ́ sí etí Òkun Atlántíkì. Luanda ni olúìlú rẹ̀. Ìgbèríko òde Kàbíndà ní bodè mọ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Kóngò àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira Olóṣèlú ilẹ̀ Kóngò.

Àngólà di ileamusin Portugal ni 1884 leyin Ipade Berlin. O gba ilominira ni odun 1975 leyin ogun itusile. Ko pe leyin ilominira ni ogun abele sele lati 1975 de 2002. Àngólà ni opo alumoni ati petroliomu, be sini okowo re ti ungbera soke pelu iwon eyoika meji lati odun 1990, agaga lateyin igba ti ogun abele wa sopin. Sibesibe opagun ijaye si kere gidigidi fun opo alabugbe, be sini ojo ori ati iye ọ̀fọ̀ ọmọwọ́ ni Angola je awon  eyi to buru julo lagbaye. 




#Article 100: Èdè Àmháríkì (144 words)


Amhariki Èdè Sẹ̀mítíìkì (Semitic) kan ni eléyìí tí nǹkan bú mílíọ̀nu márùndínlógún ń sọ gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kọ́ ní Ethopia (ìtópíà). Níbẹ̀, wọ́n ń lò ó gẹ́gẹ́ bí tí ìjọba ń mú lò. Àwọn bú mílíọ̀nù márùn-ún ni ó ń sọ èdè yìí ní agbègbè Ethiopia nígbà tí ̣ àwọn ọ̀pọ̀lọpò mílíọ̀nù mìíràn ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì àkọ́kúntẹnu ní Ethiopia àti Sudan (Sùdáànù). Láti nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹrìnlá (14th Century) ni èdè yìí ti ní àkọsílẹ̀. Àkọtọ́ Amharic ni wọ́n fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àkọtọ́ yìí ní Kóńsónáǹtì mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ẹ̀dà méjeméje. Ẹ̀dà kóńsónáǹtì tí ènìyàn yóò mú lò dúró lóró fáwẹ̀lì tí kóńsónáǹtì náà yóò bá jẹ yọ. Àbá ti ń wáyé nípa pé kí àtúnṣe wà fún àkọtọ́ yìí. Àwọn kan sì ti kóra wọn jọ fún ìpolongo láti sọ èdè yìí di àjùmọ̀lò (Standardisc).




#Article 101: Olódùmarè (1066 words)


Orúko: Ajayi Olufunmilayo Temitope
 

ÈKÓ NÍPA OLÓDÙMARÈ 

Káàkìri àgbáyé ni a ti mò pé olódùmarè wà, eni tí ó dá ayé àti òrùn àti ohun gbogbo ti ń be nínú won òyígíyigí oba àìrí arínú-róde Olùmòràn Òkàn, alèwílèse, alèselèwí, Oba atélè bí eni téní, Oba atésánmo bí eni téso, Oba lónìí, Oba lóla, Oba títí ayé àìnípèkun, Olówó gbogbogbo tí ń yomo rè nínú òfin, Oba Olójú lu kára bí ajere, Oba onínú fúnfún àti béè béè lo. 

Èyí ni pe oríkì Olódùmarè pọ̀ lọ jáǹtìrẹrẹ, bí a bá sì gbọ́ tí àwọn Yorùbá bá sọ pé ‘orí mi o tàbí olọ́jọ́ ọ̀ní o, Olódùmarè ni wọ́n ń pè ní orí, èyí tí ó dúró fún ẹlẹda orí àti ọlọ́jọ́ òní tí ó dúró fún ẹ̀ni tí ó nì ọjọ́ òní. Tàbí nígbà mìíràn tí àwọn Yorùbá bá rí Ohun tí ó ya ni lẹ́nu wọn á ní ‘Bàbá  ò’ èyí tí ó dúró fún Olódùmarè.

Àwọn ọmọ ènìyàn gbà wí pé  ọlọ́run tóbi ju gbogbo ẹ̀dá lọ ó sì jẹ ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ má a bọlá fún, èrò ọkàn àwọn Yorùbá ni pé ọlọ́run tàbí olódùmarè tóbi púpọ̀, ó sì ju ẹnikẹ́ni lọ àti nítorí èyí kò yẹ kí wọ́n máa dárúko mọ́ ọ lórí bí wọ́n ti ń ṣe sí ẹgbẹ́ àti ọ̀gbà wọn, láti bu ọlá fún-un àti láti fi ìtẹríba wọn hàn fún un wọ́n ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ pè é, wọn a ní ẹlẹda, èyí ní ẹni tí ó dá ọ̀run, àti ayé, òyígíyigì, èyí ni ẹni tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ohun tí a lè  fi wé. Ọba àwámárìdí, èyí ni ẹni tí a kò lè rí ìdí iṣẹ́ rẹ̀, Alábàláṣe, èyí ni ẹnì tí ó ni àbá àti àṣẹ, Bàbá, èyí ni baba gbogbo ẹ̀dá inú ayé, Ọ̀gá ògo; èyí ni ẹni tí ó ni ọ̀run èyí tí ó jẹ́ ògo ẹ̀dá tàbí nígbà mìíràn a lè túmọ̀ rẹ̀ sí ẹni tí ògo tàbí ìgbéga ẹ̀dá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, Atẹ́rẹrẹkáríaye, èyí ni ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní gbogbo ayé ní ìkáwọ́ rẹ̀, ẹlẹ́mìí, èyí ni ẹni tí ó ni ẹ̀mí ẹ̀dá. 

Bí a bá tún gbó nígbà mìíràn tí àwọn àgbàlagbà ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Èdùàrè tàbí wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘olú’ olódùmarè kan náà ni wọn ń tọ́ka sí. Àwọn àgbàlagbà a máa sọ pé: 

mo ló dàṣegbé 

Àṣegbé ọmọ Èdùàrè…

Ohun tí àkọlé yìí ń tọ́ka sí ni pé ohun tí ọmọ Èdùàrè, èyí tí ó dúró fún olódùmarè bá ti ṣe àṣegbé ni ìgbà gbogbo là ń gbọ́ tí àwọn àgbàlagbà máa ń sọ pé “ẹni olúwa dá kò ṣe é fara wé”. Ohun tí wọn ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn yìí nip é ẹni tí Olú, èyí tí ó dúró fún olódùmarè “bá ti dá àyànmọ́ kan mọ́ ẹnìkan, a kò lè fara wé irú ẹ̀nìyàn bẹ́ẹ̀. 

Àwọn àkíyèsí tí a lè rí tọ́ka sí ni pé ọ̀pọ̀ ìtàn ìwásẹ̀ ni ó sọ bí Olódùmarè ṣe sẹ̀dá ayé àti ọ̀run, Yorùbá gbàgbọ́ pé ọ̀run ni olódùmarè wà, tí ó ti ń ṣe àkóso ayé àti ọ̀run, èrò Yorùbá ni pé kò sí ohun tí a ‘lè fi wé olódùmarè nítorí àwọn àwẹ̀mọ́ tàbí abuda rẹ tó tayọ àwa ẹ̀dá lọ fún àpẹẹrẹ a lè pe olódùmarè báyìí pé ‘Ẹlẹda, Ẹlẹ́mìí, Ọlọ́run Ọba ní í fọ́n èjí iwọ́rọ́ iwọ́rọ̣́, òun ló ni ọ̀sán àti òru dọ́jọ́ òní, òní ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀la ọmọ Ọlọ́fin, Ọ̀tunla ọmọ Ọlọ́fin, ìrènì ọmọ Ọlọ́fin, ọ̀rúnní ọmọ  Ọlọ́fin, Yorùbá máa ń sọ pé ìṣẹ́ Ọlọ́run tóbi tàbí àwámárìdí ni iṣẹ́ Ọlọ́run, Ọ̀rúnmìlà fẹ̀yìntì ó wò títí o ní “ẹ̀yín èrò okun, ẹ̀yin èrò ọsa, ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ pé iṣẹ́ Olódùmarè tóbi: A tún lè sọ pé Ọba Ọ̀run ọ̀gá Ògo, atẹ́rẹrẹ káyé ẹlẹ́ní àtẹ́ẹ̀ká, Ọba ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í yẹ̀, alábà láṣẹ̀ á tun le pe ni alágbára láyé àti lọ́run. 

Adùn ún ṣe bí ohun tí olódùmarè lọ́wọ́ sí, aṣòro o ṣe bí ohun tí olódùmarè kò lọ́wọ́ sí, Alèwílèṣe, Aṣèkanmákù. Ìgbà mìíràn a tún lè sọ pé ọlọ́run nìkan ló gbọ́n, ó rí ohun gbogbo, ó sì lè ṣe ohun gbogbo, Arínúróde Olùmọ̀ràn ọkan, Yorùbá sọ pé “Amòòkùn ṣolè bí Ọba ayé kò ri, Ọba ọ̀run ń wò ó, èyí túmọ̀ sí wí pé kò sí ohun tí a ṣe ní ìkọ̀kọ̀ tí Olódùmarè kò rí, kedere ni lójú Olódùmarè, àwọn òrìṣà ló máa ń jẹ àwọn arúfin ní ìyà ṣùgbọ́n Olódùmarè ló máa ń dájọ́ fún wọn, fún àpẹẹrẹ ní ìgbà kan gbogbo òrìṣa fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú olódùmarè lẹ́yin tí tọ̀tún tòsì wọ́n rojọ́ olódùmarè dá ọ̀rúnmìlà láre, odù ifá kan jẹri sí eléyìí, odù náà lọ báyìí “Ọ̀káńjùa kì í jẹ́ ka mọ nǹkan pínpín, Adíá fun odù. Mẹ́rìndín lógún níjọ́ ti wọn ń jìjà àgbà relé olódùmarè, nígbà tí àwọn ọmọ ìrúnmọlẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún tán ń jìjà ta ni ẹ̀gbọ́n ta ni àbúrò láàárin ara wọn, wọ́n kẹ́jọ́ lọ sódọ̀ olódùmarè, níkẹyìn, olódùmarè dá ẹjọ́ pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn odù yókù. Yorùbá gbàgbọ pé onídàjọ́ òdodo ni olódumarè, ìdí nìyí tí Yorùbá fi ń sọ pé ọlọ́run mú u tàbí ó wà lábẹ́ pàṣán ‘Olódùmarè. Òyígíyigì ọba Ọta àìkú fẹ̀rẹ̀kufẹ̀, a kì í gbọ́kú Olódùmarè. 
	Tí a bá tún wo Ọ̀kànrànsá (odù ìfa) òun náà tún sọ pe olódùmarè kì í ku, fún àpẹẹrẹ, Odù ọ̀kànrànsá yìí sọ pé: 

Ọ̀dọ́mọdé kì í gbọ́kú asọ 

yẹyẹyẹ laṣọ ogbó 

àgbàlagbà kì í gbọ́kù aṣọ

yẹyẹyẹ laṣọ ogbó 

Olódùmarè náà ni Ọba àìrí, àwámárìdí Yorùbá tún gbà pé ó jẹ Ọba mímọ́ tí kò léèérí, alálà funfun òkè. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí àwọn áńgẹ́lì tí jẹ́ Olùrànláwọ́ fún Olódùmarè lóde ọ̀run ni àwọn òrìṣà náà jẹ́ aṣojú rẹ̀ lóde ìṣálayé, àwọn òrìṣà wọ̀nyí jẹ́ alágbàwí àwọn ènìyàn níwájú olódùmarè. A gbọ́ wí pé ìbáṣepọ̀ wà láàárin àwọn òrìṣà tàbí òòṣà ilẹ̀ Yorùbá àti Olódùmarè, àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pe òòṣà wọ̀nyí nì wọ́n lè rán sí olódùmarè yálà láti tọrọ nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun ribiribi tí ó ṣe fún wọn. Erò yìí hàn nínú òwe Yorùbá kan pé “ẹni mojú ọwá là ń bẹ̀ sọ́wá, olójú ọwá kan kò sí bíkòṣe ayaba”. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ pé bí a bá fẹ́ kí Ọba ṣe ohun kan fún ni a ó bẹ ayaba sí i, ipò alágbàwí láàárin àwọn abòòṣà àti olódùmarè ni àwọn òòṣà wà.




#Article 102: Koisaanu (1463 words)


ỌLỌFNSAO OLUKEMI    M.

ÀWỌN ẸBÍ ÈDÈ KHOISAN

Ìfáàrà 

	Ẹbí èdè Khoisan yìí ni ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹbí èdè gbogbo tí ó wà ní Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí Greenberg (1963a) ti sọ, ó ní àwọn ni wọ́n dúró fún èyí tí ó kéré jù lọ nínú èdè Áfíríkà. 
ÌPÌLẸ̀ ORÚKỌ ÈDÈ YÌÍ  
	A mu orúkọ yìí jáde láti ara orúkọ ẹgbẹ́ Khoi-Khoi ti Gusu ilẹ Afirikà (South Africa) àti ẹgbẹ́ san (Bushmen) ti Namibia. A máa ń lo orúkọ yìí fún Oríṣìíríṣìí àwọn ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ pé àwọn gan-an ni wọ́n kọ́kọ́ jẹ́ olùgbé ilẹ̀ south Africa kí awọn Bantu tó wá, kí àwọn òyìnbó ilẹ̀ Gẹẹsi (Europe) sì tó kó wọn lẹ́rù.
	Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ni wọn ti siṣẹ lórí orúkọ yìí – Khoisan.Tan Gùldemann ati Rainer Vossen ṣàlàyé nínú iṣẹ́ rẹ̀ pé Leonardt Schulze 1928 ni o mu orúkọ yìí jáde láti ara Hottentot’ tí o túmọ̀ sí Khoi ti o sì tún túmọ̀ sí ‘person’ (ènìyàn) àti ‘san’ tí ó túmọ̀ sí ‘forager’. Lẹ́yìn èyí ni onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá àṣà, ìgbàgbọ́ àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn, anthropologist Schapera (1930) tún wá fẹ̀ orúkọ yìí lòjù sẹ́yìn nípasẹ̀ ‘Hottentot’àti ‘Bushman’ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà, (racia) àṣà (cultural) àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè. (Linguistic). 
	Àwọn orúmọ̀ mìíràn tí wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kẹta ti wọ́n tún siṣẹ́ lé orúkọ yìí lórí ni Kolnler (1975, 1981) sands (1998) àti Traill (1980, 1986). Wọn pinnu láti lo orúkọ náà Khoisan gẹ́gẹ́ bí olúborí fún àwọn èdè tí kìí ṣe ti Bantù tí kì í sì í ṣe èdè Cushitic. 
	Àwọn onímọ̀ akíọ́lọ́jì fi han wí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fa ọdún sẹ́yìn ni awọn ènìyàn Khoisan ti fara hàn. Èyí fi han pé lọ́dọ̀ àwọn àgbà láèláè nìkan ni a ti lè máa gbọ́ èdè Khoisan nìkan báyìí. 
	Bí èdè Khoisan tilẹ̀ farajọra nínú ètò ìró, gírámà tirẹ̀ yàtọ̀ gédégbé. Àìsí àkọ́sìlẹ̀ ìtàn àwọn èdè wọ̀nyí mú kí o nira díẹ̀ láti sọ ìfarajọra awọn èdè yìí sí ara àti sí àwọn èdè adúláwọ̀ tí ó kù. 
	Lóde àní, Ilẹ̀ (South Western Africa) gúsu-ìwọ̀ òòrùn Áfíríkà títí dé àginjù kàlàhárì (Kalaharì Desert), láti Angola de South Africa àti ní apákan ilẹ̀ Tanzania nìkan ní wọ́n ti ń sọ èdè Khoisan. Edè Hadza àti Sandawe ní ilẹ̀ Tanzania ni a sáábà máa ń pè ní Khoisan ṣúgbọ̀n wọ́n yàtọ̀ nípa ibùgbé àti ìmọ̀ ẹ̀dá èdè sí ara wọn. A wá lè sọ pé nínú gbogbo èdè àgbáyé, èdè Khoisan wà lára àwọn èdè tí àwọn onímọ́ èdè kò kọbiara sí tí a kò sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. 

ÌPÒ TÍ ÈDÈ YÌÍ WÀ

	Èdè Khoisan yìí gẹ́gẹ́ bí a ti sọ síwájú ń dín kù síi lójoojúmọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwọn tí wọ́n ń sọ àmúlùmálà èdè Khoisan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè mìíràn tí ó gbilẹ̀ ní agbègbè wọn; wọ́n sì dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní èdè abínibí wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ní àkọ́silẹ̀ kankan tí ó sì fíhàn pé sísọnù tí àwọn èdè wọ̀nyí sọnù, kò lè ní àtúnṣe. 
	Ó jẹ́ ohun tí ó nira díẹ̀ láti sọ pé iye àwọn ènìyàn kan pàtó ni wọ́n ń sọ èdè Khoisan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí àwọn Òyìnbó tó gòkè bọ̀, a kò sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn Òyìnbó ń ṣètò ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì tún ni pé ìwọ̀nba la lè sọ mọ nípa ohun ti ó ń ṣẹlẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ fi hàn pé, ní bíì ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, iye nọ́nbà tí wọ́n kọ sílẹ̀ kò ṣeé tẹ̀lé mọ́; àkọsílẹ̀ sọ wí pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà Igba (120,000 – 200,000) ni wọn, ṣùgbọ́n èyí ti di ohun àfìsẹ́yìn bí eégún fí aṣọ. Wọn kò tó bẹ́ẹ̀ mọ́. 
	Díẹ̀ lára àwọn èdè khoisan àti iye àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́. 

	EDE, 		   	IYE ÀWỌN TI Ń SỌ,	ILÚ, 

Sandare, 				40, 000,		Tanzania 

Haillom (San), 			16,000,		Namibia, 

Name (Khoekhoegowab) 	233,701		Namibia, Botswana, 
South Africa 

Suua ,					6,000,			
Botswana 	

Tsoa. 					5,000,			

//Ani ,				1,000,			Botswana

Gana, 				2,000,			Botswana

Kxoe 				10,000,		Namibia, Angola, Botswana South Africa,
Zambia	

//Gwi, 				2,500	,		Botswana

Naro, 				14,000,		Botswana, Namibia 		

Kung-Ekoka,		6,900,			Botswana, Angola, 
South Africa. 

IHUN EDE KHOISAN
	
ÈTÒ ÌRÓ

	Àwọn èdè Khoisan kò ṣàì ní ìfarajọra nínú ètò ìrò. Ó dá yàtọ̀ gédégbè sí àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà yòókù, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí ó nira.

	FAWẸLI 
	
Ọ̀pọ̀ àwọn èdè Khoisan wònyí ni ó ń lo fáwẹ́lì márùn ún - /i/, /e/, /a/, /o/, /u/ tí a  sì lè pè pẹ̀lú àwọn oríṣìí àbùdá wọ̀nyìí bíi, ìránmú, (nasalization) ìfi káà-ọ̀fun-pè (pharyngealization) ati oríṣìí àmúyẹ ohùn bíi mímí ohun (breathy voice) ati dídún ohùn (Creaky voice) tí yóò sì mú bí i oríṣìí ìró fáwẹ́lì bí i ogójì jáde. 

KỌ́ŃSÓNÁǸTÌ:- 

(Clicks) kílíìkì

	Kílíìkì ni a ń pe àwọn kọ́ńsónáǹtì wọn; títí kan àwọn àfeyínpè (dential), àfèrìgìpè, (alveolar), afàjàfèrìgìpè (alveo-palatal), afẹ̀gbẹ́-ẹnu-pè (lateral) àti kílíìkì afètèpè (bilabial Chick). Sandawe àti àwọn Hadza tí ilẹ̀ Tanzania ń lo àfeyínpè (dental ) afèrìgìpè (alveolar) àti kílíìkì afẹ̀gbé-ẹnu-pè (lateral clicks). Pẹ̀lú gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ títí di àkókò yìí orísun kílíìkì èdè Khoisan kò tíì yéni. 

	Àpẹẹrẹ:- 

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kílíìkì wọ̀nyí ló lè ní Kíkùnyùn-ùn, (Voicing) ríránmú (nasality), “aspiration” ati “ejection”. Láti le mú kí á ní àgbéjáde oríṣìíríṣìí kílíìkì. Àwọn orísìíríṣìí kílíìkì wọnyi ló mú kí èdè Khoisan yàtọ̀. Àpẹẹrẹ nínú èdè Nama, Ogún ni kílíìkì tí wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n n lo mẹ́tàlélógọ́rin nínú ède Kxoe tí ó jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khoisan. Ní àfíkún, àádọ́rùn-ún ònírúrú kóńsónáǹtì kílíìkì ni wọ́n n lo ni Gwi tí òhun náà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Khosian wọ̀nyí. Àpẹẹrẹ Kílíìki Nama

SÍLÉBÙ

	Gbogbo àwọn kóńsónáǹtì Kílíìkì àti èyí tí kìí ṣe kílíìkì ló máa ń fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí fáwẹ́lì sì máa ń tẹ̀lé e. Ìwọ̀nba kóńsónáǹtì bí àpẹẹrẹ /b/, /m/, /n/, /r/, àti /l/ ló lè jẹ yọ láàrín fáwẹ́lì, díẹ̀ sì lè farahàn ní ẹ̀yìn ọ̀rọ̀. 

ÌRÓ OHÙN

	Àwọn èdè Khosan máa ń sàfihàn oríṣìíríṣìí ìró ohùn, bí àpẹẹrẹ, Jul’hoan ní ipele ohun àárún oríṣìí mẹ́rùn, ó sì ní ipele ohun òkè kan.

	Ọ̀rọ̀ àti ìhun gbólóhùn àwọn èdè Khoisan yàtọ̀ síra láàrin ara wọn. 

Ọ̀RỌ̀ ORÚKỌ 

	Ìsọ̀rí mẹ́ta ni ọ̀rọ̀ arúkọ Khoisan pín sí; bí a bá wòó, nípasẹ̀ jẹnda, akọ, abo àti àjọni ni ò pín sí. Nínú Kxoe, fún àpẹẹrẹ, jẹ́ńdà nínú ọ̀rọ̀-orúkọ aláìlẹ́mìí tún máa ń ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìríṣí, bi àpẹẹrẹ, akọ ní í ṣe pẹ̀lú gígùn, tí tò si tóbi, nígbà tí abo ní í ṣe pẹ̀lú nǹken kúkúrú, gbígbòòrò tí kó sì tóbi òríṣìíríṣìí mọ́fíímù ni wọ́n fi ń parí òkọ̀ọ̀kan àwọn jẹ́ńdà wọ̀nyí. 

Àpẹẹrẹ láti inú èdè Nama. 

	Khoisan ,		English, 		Yoruba ,

	Khoe-b,		Man ,			Ọkùnrin ,

	Khoe-s,		Woman, 		Obinrin ,

	Oríṣìíríṣìí nọ́mbà mẹ́ta ni wọ́n ní, àwọn ní ẹyọ, oníméjì àti ọ̀pọ̀. 

NỌ́MBÀ
Apẹẹrẹ  lati inu èdè Naro 

		Male (Akọ), 		Female (Abo),  	Common (Ako/Abo)

SG,		ba ,			sa 				_________
Dual ,		tsara ,			sara, 				Khoara 

PL 		llua 			dzi 				na

Ọ̀RỌ̀-ÌṢE 

	Àbùdá gírámà tí ó sáábà máa ń jẹ yọ nínú àwọn èdè Khoisan ni lílo ọ̀rọ̀-iṣe àkànmónúkọ (verb compound) nígbà tí èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lo ọ̀rọ̀ atọ́kùn tàbí ọ̀rọ̀-iṣe kan (single verb) Àpẹẹrẹ 

		English, 					Khoisan, 
		Enter 						go + enter. 

Àsìkò (Tense) 

	Ẹ̀rún ni a máa ń lò láti fi àsìko hàn nínú èdè KhoeKhoe àti nípa lílo àfòrò ẹyin nínú ede Kxoe, Buga ati //Ani Ninú àwọn èdè Kalahari East Kxoe, Àfòmọ́ ẹ̀yìn ló ń fi ìṣẹ̀lẹ̀ ti o ti Koja hàn (Past Tense), ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí ó lòdì ati jẹ̀rọ́ndì hàn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ti ọjọ́ iwájú ń lo Ẹ̀rún. Bẹ́ẹ̀ náà lọmọ́ sorí nínú èdè Naro, G//ana, G/ui àti ‡Haba. 

IBÁ ÌṢẸ̀LẸ̀ 

	Mana  nìkan ni ó ń lo ibá ìṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìṣẹ̀dá (Morphological Category) ó sì ya ibá ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán sọ́tọ̀ sí àìṣetán 

	Ẹ̀rún tàbí àfòmọ́ ẹ̀yìn ni wọn n lo fún ìyísódì (Khoekhoe tam; G//ana   G/ui àti ‡Haba tàmátema) n lò ẹ̀rún fún ìyísódì nígbà tí (kxoe //Am. Buya-bé) n lo afọmọ ẹyin, nígbà mìíràn wọ́n n lo méjèèjì. 
Ètò Ọ̀rọ̀
	Ètò ọ̀rọ̀ tí àwọn èdè Khoisan ti à ń sọ wọ̀nyí máa ń lò ni (Svo-Subject-Verb-Object) Olùwà ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ̀ tàbí (Sov-Suject-Object-verb).  

Ọ̀rọ̀ Èdè (Vocabulary) 

	Àfihàn ìgbésí ayé àwọn olùṣọ èdè Khoisan ni ọ̀rọ̀-èdè (Vocabulary) wọn jẹ́. Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn olùṣọ èdè wọ̀nyí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìírà, èyí mú kí wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀-èdè tí ó súnmọ́ ọdẹ ṣíṣe, ẹranko, Kóríko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

ÀKỌ́SÍLẸ̀
 	
Ọ̀pọ̀ àwọn èdè wọ̀nyí ni kò ni àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n Nama ati Naro ni àkọsílẹ̀ àti ohun èlò ìkọ́ni. Nama  ní pàtàkì ti wà ní àkọsílẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.




#Article 103: Kazimierz Nowak (104 words)


Kazimierzu Nowaki (lati Ọdún 1897 títí di Osu Òwàrà Ọjọ kétàlá Ọdún 1937 je ọmọ Ìuí Polandi ti Ọjẹ arińninajo Oníweroým ati aya woran ti a bi ni ilu Stiryi. 

Lehin Ogun àgbáyé alakọkọ ogbe ni ilu Poznani lati ọdún 1931 títí di ọdún 1936 Orin, ogun kẹkẹ jake jado ilu Aláẁọ dúdú. Orin irinajo ti oto egberun lọ́na ogoji kilomita (40.000 km). Owun ni eni akọkọ ti okọkọ ṣẹ́iru nkan bayi.

O ti kọ iṣẹ yi si inu iwe ti a pe orukọ rẹ ni Rowerem i pieszo przez Czarny Ląd (Kẹkẹ ati ẹsẹ jake jado ilẹ aláẁọ dúdú).
   
Oku si ilu Poznani.
   




#Article 104: Lítíréṣọ̀ (295 words)


Litireso tabi iṣẹ́ọnàmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà

OHUN TÍ LÍTÍRÉṢỌ̀ JẸ́
	
Eléyìí náà kò ṣàì ní orírun tirẹ̀ láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwọn gẹ́ẹ́sì yá wọ inú èdè wọn tí wọ́n ń pè ni lete rature”
Ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ máa ń yípadà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítíréṣọ̀ kò dúró sójú kan.
Babalọlá (1986), ṣàpèjúwe lítíréṣọ̀ pé: 

Tí a bá wo òde òní, ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ tún yàtọ̀, fún àpẹẹrẹ a máa ń ṣàkíyèsí ìlò èdè tí wọ́n fi kọ ìwé kan yàtọ̀ sí èyí, a tún ka lítíréṣọ̀ kùn iṣẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròkọ àti eré oníṣe. A ó sì rí i pe awẹ́ tàbí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a mẹ̀nubà wọ̀nyí kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ẹ̀dá láwújọ (folklore) mọ́ ara, yálà, a kọ, ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré yàtọ̀ fún àwọn àkọọ́ lẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́.
	Lítírésọ̀ tún jẹ́ irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tó ní àbùdá ẹ̀mí gígùn, ó máa ń fi ìṣẹ̀ṣe àti àṣà àgbáríjọ àwọn èèyàn kan hàn.
Àwọn míràn tó tún sọ̀rọ̀ lórí lítíréṣọ̀ ni àwọn ọmọ lẹ́yìn Mark: Àwọn Marxist (1977) yìí gbà pé:

Èyí ni pé:

Kí òǹkọ̀wé kan tó lè se iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeyanjú, irúfẹ́ oǹkọ̀wé náà gbọ́dọ̀ ni àtinúdá àtinúdá yìí pẹ̀lú ohun gan-an tí ó ń ṣelẹ̀ láwùjọ ni yóò wá sọ di ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀.
Lara àwọn tí ó ṣiṣẹ́ lórí ìlànà Marx yìí ni: Trosky ara Russia, Lucas àti Goldmann. 
Daviguand (1960) ni tíọ́rì sọ pé 

Èyí ni pé:

Nípa yíyẹ lítíréṣọ̀ wò, à ní láti wo ẹ̀hun ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí ni wíwo gbogbo nǹkan tí ó wà láwùjọ yẹn olápapọ̀ láì dá ọ̀kan sí.




#Article 105: Ìjẹ̀ṣà (2541 words)


Àwọn Ìjẹ̀ṣà je iran kan nínú àwọn ọmọ Yorùbá. Ipinle Osun ni Nigeria ni won budo si julo.

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ.

Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì.

Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá)

Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ.

Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé  rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle  gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí  Ọwálùsẹ  padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀ òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro.

Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí.

Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ  pé

		“Ọ̀pá Ìpólé ku ogun

		Ọ̀pá ijakuro ku ọgbọ̀n

		Ọ̀pá Ẹ̀fọ̀n-Aláayè wọ́n ku mẹ́ta gege”

Àti ìgbàyí lo ti di òrìsà sí ìlú Ìpólé àti agbègbè Ìjẹ̀sà.

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré.
Àwọn ìlú naa nì wọ̀nyí

(1)	Ìpólé

(2)	Ìrógbó

(3)	Ìwukùn

(4)	Ìbòdì

(5)	Ìtapá

(6)	Òdò

(7)	Olówu

(8)	Ìperindó

(9)	Ìlokò

(10)	Ìwárája

(11)	Ìsè-Ìjẹ̀sà

(12)	Ìlérín

(13)	Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà

(14)	Ìpetu-jẹ̀ṣà

(15)	Èrìn–Ìjèṣà

(16)	Ìdómínàà

(17)	Ìlásè

(18)	Ìlówá

(19)	Ìkíyìnwá

(20)	Ifẹ̀wàrà

(21)	Èsà-òkè

(22)	Èsà-odò

(23)	Ìbòkun

(24)	Òtan-ilé

(25)	Ìmèsí-ilé

(26)	Òsú

(27)	Ìpetu-ilé

(28)	Ìlàrè

(29)	Ìlayè

(30)	Ìtagúnmodu

(31)	Mogbàrà

(32)	Òmò

(33)	Ìgángán

(34)	Iléṣà

Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí.

(1)	Léjòfì

(2)	Àrápaté

(3)	Risawe

(4)	Òdolé

(5)	Lórò

(6)	Ọbańlá

(7)	Léjọ̀kà

(8)	Sàwè

(9)	Bajimọ 

(10)	sàlórò àti

(11)	Yèyé ríse

Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl.

Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀.

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn.

Oúńjẹ jẹ́ ohun tí kò sé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwùjọ, bẹ 
si ni àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní àwọn oúńjẹ tí wọ́n fẹ́ràn. Tí a ba sọ̀rọ̀ nípa oúńjẹ tí Ìjẹ̀sà fẹ́ràn jù tàbí oúńjẹ ti o jẹ́ oúńjẹ pàtàkì a o ni sai lai dárúkọ iyán, nítorí iyán ní oúńjẹ pàtàkì tí Ìjẹ̀sà maa n jẹ, bí o tìlẹ́jẹ́ pé wọn tun ni àwọn oúńjẹ míràn bi àmàlà, Ẹ̀bà, Fùfú, ẹ̀wà, Ìrẹsì abbl. Sùgbọ́n iyán ni ọba oúńjẹ wọn .Ìjẹ̀sà le jẹ iyán ni ẹmẹẹta ni ojúmọ́ tàbí ni gbogbo Ìgbà àti àkókò nítorí náà, iyán jẹ oúńjẹ fún Ìjẹ̀sà.

Nípa ti ijó jíjó kò sí àdúgbò tí kò ní ijó tàbí orin ti wọn, àwọn ondo n ko obitun, Ìlàjẹ àti Ìkálẹ̀ ń kọ bírípo, bẹ́ nì ti àwọn Ìjẹ̀sà pẹlú ilésà ń kọ orin Àdàmọ̀, bẹ́nì wọ́n tun jọ ijó Ìkàngá ati ijó lóye pẹ̀lú Ìlù bẹ̀nbẹ́ àti orin Ìkàngá bákannáà. Onírúrurú orin ni a mọ̀ Ìjẹ̀sà mọ́ sùgbọ́n Ìkàngá àti loye ni o jẹ́ orin Ìpílẹ̀ wọn ti wọn maa ń kọ.

Èyí maa  tú jẹ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a tì lé rì àsà àti èdè Yorùbá bákannáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà kọọkan tún ní àsà ìwọsọ tí wọn. Àwọn obìnrín Ìjẹ̀sà maa nwọ àsọ̀ àfì tó jẹ́ Ìró àti bùbá bẹ́ni àwọn okùnrin wọn máà ń wọ esikí àti sòkòtò ẹlẹ́nu ńlá pẹ̀lú fìlà alabankata.

Èyí jẹ́ àsà tí o sábà maa ń súyọ láàárín àwọn obìnrin pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn obìnrin Ìjẹ̀sà máà n lo lali, tiro, osùn láti fi soge.

Àwọn Ìjẹ̀sà jẹ́ alákíkánjú àti jagunjagun ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ní àwọn Ìjẹ̀sà ni pa nínú rẹ̀, ní àkókò ogun kariaye ilè Yorùbá. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ìjẹ̀sà ja a ni ogun Ìbàdàn, ogun Jalumu àti ogun Kiriji tàbí ogun Ekìtì parapọ̀. Ogun Èkìtì parapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1877, o sì perí ní ọdún 1886. Ẹni tí ó jẹ́ bí asíwájú ogun pàtàkì yìí ni okùnrin alajagun Ìjẹ̀sà kan ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ògèdèngbé .Ogun Èkìtì parapọ̀ yìí ni ó mú orúkọ Ògèdèngbe dúró sinsin nínú ìtàn Yorùbá ogn náà si ja fún ọdún mẹsan gbáko ọdún 1910 ní ògèdèngbé kú.

Ohun kan tí àwọn Ìjẹ̀sà se ni Ìrántí Ògèdèngbé tí ó jẹ́ olórí àwọn Ìjẹ̀sà wà ni eréjà Ilésà ní iwájú ilé Ìfowópamọ́ ti “National Bank of Nigeria Limited”

Gbogbo àwọn ẹ̀yà ìyókù ní ilẹ̀ Yorùbá ní wọ́n mọ àwọn Ìjẹ̀sà sí onísòwò paraku idi ni yi tí wọn fi ń pe àwọn Ìjẹ̀sà ni “Òsómàáló”. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí kà nínú ìwé, a gbọ́ pẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà ni ó dá àsà san an díẹ̀dị́ẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìsòwò. Wọ́n màá n lọ láti ìlú dé ìlú àti ìletò de ìletò láti se isẹ́ ọjà títà wọn, ohun tí wọn si n ta ní pàtàkì ní asọ.
Sùgbọ́n lónìí Ìjẹ̀sà ti kúrò ni a n kiri láti Ìlú de ìlú tàbí Ìletò de Ìletò, wọ́n ti wà nínú ilé ìtajà ní àwọn ìlú ńláńlá bíi, Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, Ògbọ́mọ̀sọ́, Kánò, Kàdùná, òsogbo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́hìn isẹ́ òwò síse ti a mọ si Òsómàló tí wọ́n máa ń kiri, wọ́n tún máa ń se isẹ́ àgbẹ̀ paraku nínú oko wọn, àwọn Ìjẹ̀sà a maa gbin kòkó, obì, isu, àgbàdo, káfé, ìrẹsì, àti orísì́ àwọn ohun jíjẹ míìràn. orísì àwọn isẹ́ míìràn tí àwọn Ìjẹ̀sà n se ni isẹ́ àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀de góòlù, isẹ́ gbénàgbénà, asọ híhun, aró dídá àti orísi isẹ́ míràn.

Àwọn ilé isẹ́ ti a lè rí ní ilésà ní “ International Breweries Limited Nigeria” ni ibití wọ́n ti ń se ọtí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Trophy Larger Beer” àti àwọn ohun amúlúdùn ti a lè rí ni ilésà lónìí ni iná mọ̀nàmọ́ná, pápá ìseré àti ilé ìtura.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, kí àwọn òyìnbó tó kó ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá de orílè-èdè wa, àwọn Yorùbá ti ni ẹ̀́sìn ti wọn. llésà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ilẹ́ Yorùbá maa n sin àwọn òrìsà bii ògún, ọ̀sun, ifá, èsù, ọya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti o wá sí orilè - èdè yìí wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà ni nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́hìn ni a mọ̀ sí  ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó ti àwọn lárúbáwá wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà.

Ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì náà ni a ti rí Ìjọ Àgùdà (Catholic), Ìjọ onítẹ̀bomi (Baptist) Ìjọ Elétò (Methodist) Ajíhìnrere Kírísítì (Christ Apostelic Church) kérúbù àti séráfù (Cherubim and Seraphim) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn Ìjẹ̀sà ní Ìmọ̀ tí ó gbámúsé ní pa ètò ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjẹ̀sà ni o di ipò gíga mú ní ilé isẹ́ ìjọba fún àǹfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. tị́tí di àkòkò yìí ó tó nǹkan bí aadọta ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní igboro ilésà, ilé ẹ̀kọ́ girama méjìdínlógún àti ilé ìwé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ onípòkejì méjì. Ni àfikún, ìjọba tún ti dá ilé- ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkóni, fún ilé ẹ̀kọ́ giga sílẹ ni llésà ni ọdún 1977(Osun State College of Education)
Àwọn òrìsà ilẹ̀ Ìjẹ̀sà
Owari, Owaluse, Oludu, Oluaye, Ajitafa, Ogun, Omi/Osun. Sùgbọ́n àwọn òrìsà kò se bẹ gbilẹ̀ mọ́ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ọ̀kan soso lalè ri níbú wọn ti o dàbí ẹni pé wọn sin se ọdún rẹ.




#Article 106: Iléṣà (2567 words)


Iléṣà je ilu ni ile Naijiria. 

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ.

Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì.
Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá)

Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń ti pín gbogbo ogún fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Ajíbógun bínú gidi, ó wá bèèrè wí pé kí ni ogún ti oun báyìí, bàbá rẹ ni kò sí nkan-kan mọ́ àfi idà Ìsẹ́gun tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nìkan ló kù, inú bí Ajíbógun ó fa idà yọ láti fi ge bàbá rẹ̀, sùgbọ́n idà bá adé ò sí ge jọwọjọwọ ìwájú adé naa, lẹ́yìn èyí ní bàbá rẹ̀ gbé adé naa fún, nítorí pé ó se akin àti akíkanjú ènìyàn, sùgbọ́n bàbá rẹ sọ fun wí pé láti òní lọ kò gbọdọ̀ dé adé tí ó ní jọwọjọẁ létí mọ́, àti ìgbàyí ló ti di èwọ̀ fún gbogbo ọwá tí ó bá jẹ ni ILÉSÀ.

Ìtàn míràn ni pé, lẹ́yìn ìgbàtí Ajíbógun ti parí isẹ́ ti bàbá ran tán ni o kúrò ni ilé-ifẹ̀ láti lọ se ìbẹ̀wò sí ìlú àwọn bàbá rẹ. lára àwọn ìlú tí Àjíbógun gba kọ já ni Osu àti àwọn ìlú míràn, a gbọ́ wí pé, Ọ̀kà-òkìle tí ó jẹ́ dáódù fúnAjíbógun ní ó jẹ Owari si ìlú Ìpólé tì wọn ń sì ń pé ni Owari. Ìtàn sọ fún wa wí pé Ìpólé yìí ní Ọ̀kà-òkìle jẹ Owa ti rẹ si sùgbọ́n oun àti àwọn ará ìlú ko gbọ ara wọn yé  rárá nítorí agbára tí ó ní, sùgbọ́n o selẹ̀ wí pé ọ̀tẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀sì ni pọ̀ si láàrín àwọn ará ìlú pẹ̀lú ọba, ọ̀tẹ̀ yìí ló fa Ìjà tí ó pín ìlú sí méjì. lára àwọn tí ó kọ́ ara jọ ni wọ́n sọ gbólóhùn kan pé “Ìn jẹ́ asá” tí ó túmọ̀ sí pé “ Ẹjẹ́ ká sá “ èyí ní wọ́n yípadà sí Ìjẹ̀sà, àwọn wọ̀nyí ni wọn lo tẹ ìlú Ilésà gan-gan dó. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìlú Ilésà dó ni àwọn olóyè ti wọ́n kúrò ni ìlú Ìpólé pé ara wọn jọ pé ó yẹ kí àwọn ni ọba, wọ́n wa pa ìmọ̀ pọ̀ pé kí wọn lọ mú Ọwalusẹ ti se àbúrò Ọ̀kà-òkìle kí o jẹ́ ọba wọn, wọ́n se bẹ lọ́ọ̀tọ́ Owálusẹ si jẹ ọba àkọ́kọ́ ní ìlú Ilésà. Ìgbàtí tí Ọ̀kà-òkìle  gbọ́ ní Ìpólé o ránsẹ́ sí Owalusẹ pé kí ó wá. Ọwálúsẹ̀ si se bẹ gẹ́gẹ́, ìgbàtí ó dé ọ̀dọ̀ Ọ̀kà-òkìle naa idà si etí Ọwálùsẹ̀, etí kàn si jábọ́, ìgbàtí  Ọwálùsẹ  padà sí Ilésà oun à ti Ọwá (Ọ̀kà-òkìle) kò rí ara wọ́n, àti ìgbàyí nì Oka- okule tí gẹ́gùn pé gbogbo ọdún tí wọ́n bá fẹ se ni ilésà wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ se ti Ìpólé títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn yìí ni Ọ̀kà-òkìle (Owá) pinu láti ba gbogbo ará Ìpólé se ìpàdé pọ̀, ohun tí o sẹ lẹ ni Ìpàdé ni pé Ọ̀kà-òkìle se àlàyé pé oun fẹ́ férakù láàrín wọn (fẹ́ kú) ó fún wọn ni osù mẹ́ta, lẹ́yìn osù kan ará ìlú lọ ba pé sé kò fẹ́ wo ilé mọ ilè mọ ni, sùgbọ́n ojú ti fẹ́ ma ti Owari nítorí òrọ̀ 

òhún ti di yẹ̀yẹ́ láàárín ìgboro.
Ìgbà tí ó di ọjọ́ tí ó fẹ́ wọ ilẹ̀ ó jẹ́ àárín òru bí owari se wọ ilẹ̀ ni gbogbo ìgboro dàrú nítorí gbiri gbiri tí wọn gbọ́ wọ́n sáré kiri, kò pé ní àwọn kan ri tí wọn si fi ariwo bọ ẹnu pé owá ti rì ò, Owá ti rì ò, èyí ní wọn yí padà tí ó di Owárì. Àfin tí o rì ni à ń pè ní Ùpàrà Owárì. Ìdí sì ni yìí tí Ọwá kò gbọ́dọ̀ fi dé ibẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Ìlú mẹ́ta ló kúrò ni Ìpólé, lára wọn ni Ìpólé, Ìjakuro àti Ẹ̀fọ̀n Aláayè. Ìdí nì yí tí wọn má ń sọ  pé

Ọ̀pá ijakuro ku ọgbọ̀n

Ọ̀pá Ẹ̀fọ̀n-Aláayè wọ́n ku mẹ́ta gege”

Àti ìgbàyí lo ti di òrìsà sí ìlú Ìpólé àti agbègbè Ìjẹ̀sà.

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ó wà ní abẹ́ Ìjẹ̀sà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ni a lè rí tọ́kasí lábẹ́ wọn. Lára àwọn ìlú wọ̀nyí ní a tí rí ìlú ńláńlá àti kékeré.
Àwọn ìlú naa nì wọ̀nyí

(1)	Ìpólé

(2)	Ìrógbó

(3)	Ìwukùn

(4)	Ìbòdì

(5)	Ìtapá

(6)	Òdò

(7)	Olówu

(8)	Ìperindó

(9)	Ìlokò

(10)	Ìwáráya

(11)	Ìsè-Ìjẹ̀sà

(12)	Ìlérín

(13)	Ìjẹ̀bú- Jẹ̀sà

(14)	Ìpetu- jẹ̀sà

(15)	Èrìn –Ìjèsà

(16)	Ìdómínàà

(17)	Ìlásè

(18)	Ìlówá

(19)	Ìkíyìnwá

(20)	Ifẹ̀wàrà

(21)	Èsà-òkè

(22)	Èsà-odò

(23)	Ìbòkun

(24)	Òtan-ilé

(25)	Ìmèsí-ilé

(26)	Òsú

(27)	Ìpetu-ilé

(28)	Ìlàrè

(29)	Ìlayè

(30)	Ìtagúnmodu

(31)	Mogbàrà

(32)	Òmò

(33)	Ìgángán

(34)	Ilésà gan-an

(35)    Ẹ̀rìnmọ̀ Ìjẹ̀sà 

Orísìrísì oyè ló wà ní ilé lólọkàn ò jọ kan. Pàápàá ní ìlú Ilésà gangan, bẹ́ pẹ̀lú ní àwọn oyè míràn tún wà ní ààrín àdúgbò. Bákan náà ni wọ́n ń jẹ àwọn oyè bi baálẹ̀, lọ́jà ni àwọn ìlú kékèké abẹ́ wọn. lára àwọn oyè pàtàkì tí ó wà ní ìlú ilésà gangan ní wọ̀nyí.

(1)	Léjòfì

(2)	Àrápaté

(3)	Risawe

(4)	Òdolé

(5)	Lórò

(6)	Ọbańlá

(7)	Léjọ̀kà

(8)	Sàwè

(9)	Bajimọ 

(10)	sàlórò àti

(11)	Yèyé ríse

Tí a bá wo ètò òsèlú tàbí ètò ìse ìjọba ilé ìjẹ̀sà a ó ri wí pé ó jé ètò ìsè ìjọba ti o dára. Nítorí pé, ọba ló jẹ́ olórí fún gbogbo Ìlú ti o maa n pa àsẹ bákan naa ní wọn ní àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìjòyè. Lára àwọn oyè àdúgbò ni tí a rí olórí ọmọ, ọ̀wábùsuwà, lọ́tún, losì, Ìyá-lóbìrin, àti olórí àdúgbò gangan tí wọn maa n fi orúkọ àdúgbò pè bi àpeere:- bàbá lanaye ni àdúgbò Ànáyè, bàbá luroye ni àdúgbò Ìróyè abbl.

Àwọn olórí àdúgbò kọ̀ọ̀kan yi ló jé olórí fún àwọn ará àdúgbò wọn tí yoo si máà se ìsàkóso àdúgbò naa. Àwọn olórí yìí naa tún ni àwọn àsọmọgbè kọọkan pẹ̀lú isé olúkálukú. Ìyálóbìnrin wà fún ọ̀rọ̀ àwọn obinrin ni àdúgbò, bàbá lórí ọmọ wa fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́. Ti ọ̀rọ̀ kan ba selè láàrín àwọn ọ̀dọ̀ tàbí làáárín àgbà tí ó wà ní àdúgbò. Wọn á gbé ejó naa lọ si ilé bàbá lórí ọmọ tí bàbá lórí ọmọ bá parí ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n a tari rẹ̀ si olórí-àdúgbò àti àwọn ìjòye rẹ tí àwọn ìjòyè àti olórí àdúgbò naa kò bá rí ọ̀rọ̀ náà yanjú wọ́n a gbé o di ọ̀dọ̀ ọwá (Ọba wọn) àti àwọn Ìjòyè rẹ fún ejò dídá. Ọ̀dọ̀ Ọwá yìí ni ẹjọ́ gbígbé kiri parí sí. Tí a bá wá ri ẹjọ́ tí Ọwá kò le parí wọn a ní kí oníjà méjì naa lọ búra ní ẹ̀yìnkùlé Ọwá, níbíyi ènìyàn kò le se èké kí o lọ búra ní bẹ̀ nítorí kò sí ohun tí a sọ tí kò ní selẹ̀.

Tí a bá sọ̀rọ̀ nípa àsà ni ilẹ̀ Yorùbá lónìí, a ó ri wí pé kò sí ojùlówó ọmọ Yorùbá tí kò ní àsà, àmọ́ àsà wá le yàtọ̀ láti ibìkan sí ibòmíràn. Lára àwọn ojúlówó ọmọ Yorùbá tí ó ní àsà ni a ti rí àwọn Ìjẹ̀sà. Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa àsà, àsà jẹ́ ohun tí agbègbè kan ń se yálà nínú Ìwà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí nínú Ìsesí wọn.

Lára àwọn ohun tí a ti le kíyèsí àsà dada ni

(1)	oúńjẹ

(2)	oge síse

(3)	ijó 

(4)	orin

(5)	Ìwọsọ

(1)	OÚŃJẸ:-oúńjẹ jẹ́ ohun tí kò sé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní àwùjọ, bẹ 
si ni àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní àwọn oúńjẹ tí wọ́n fẹ́ràn. Tí a ba sọ̀rọ̀ nípa oúńjẹ tí Ìjẹ̀sà fẹ́ràn jù tàbí oúńjẹ ti o jẹ́ oúńjẹ pàtàkì a o ni sai lai dárúkọ iyán, nítorí iyán ní oúńjẹ pàtàkì tí Ìjẹ̀sà maa n jẹ, bí o tìlẹ́jẹ́ pé wọn tun ni àwọn oúńjẹ míràn bi àmàlà, Ẹ̀bà, Fùfú, ẹ̀wà, Ìrẹsì abbl. Sùgbọ́n iyán ni ọba oúńjẹ wọn .Ìjẹ̀sà le jẹ iyán ni ẹmẹẹta ni ojúmọ́ tàbí ni gbogbo Ìgbà àti àkókò nítorí náà, iyán jẹ oúńjẹ fún Ìjẹ̀sà.

(2)	IJÓ :- Nípa ti ijó jíjó kò sí àdúgbò tí kò ní ijó tàbí orin ti wọn, àwọn ondo n ko obitun, Ìlàjẹ àti Ìkálẹ̀ ń kọ bírípo, bẹ́ nì ti àwọn Ìjẹ̀sà pẹlú ilésà ń kọ orin Àdàmọ̀, bẹ́nì wọ́n tun jọ ijó Ìkàngá ati ijó lóye pẹ̀lú Ìlù bẹ̀nbẹ́ àti orin Ìkàngá bákannáà. Onírúrurú orin ni a mọ̀ Ìjẹ̀sà mọ́ sùgbọ́n Ìkàngá àti loye ni o jẹ́ orin Ìpílẹ̀ wọn ti wọn maa ń kọ.

(3)	ÌWỌSỌ:-maa  tú jẹ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a tì lé rì àsà àti èdè Yorùbá bákannáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà kọọkan tún ní àsà ìwọsọ tí wọn. Àwọn obìnrín Ìjẹ̀sà maa nwọ àsọ̀ àfì tó jẹ́ Ìró àti bùbá bẹ́ni àwọn okùnrin wọn máà ń wọ esikí àti sòkòtò ẹlẹ́nu ńlá pẹ̀lú fìlà alabankata.

(4)	OGE SÍSE:-jẹ́ àsà tí o sábà maa ń súyọ láàárín àwọn obìnrin pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́. Àwọn obìnrin Ìjẹ̀sà máà n lo lali, tiro, osùn láti fi soge.

Àwọn Ìjẹ̀sà jẹ́ alákíkánjú àti jagunjagun ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ní àwọn Ìjẹ̀sà ni pa nínú rẹ̀, ní àkókò ogun kariaye ilè Yorùbá. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ìjẹ̀sà ja a ni ogun Ìbàdàn, ogun Jalumu àti ogun Kiriji tàbí ogun Ekìtì parapọ̀. Ogun Èkìtì parapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1877, o sì perí ní ọdún 1886. Ẹni tí ó jẹ́ bí asíwájú ogun pàtàkì yìí ni okùnrin alajagun Ìjẹ̀sà kan ti orúkọ rẹ ń jẹ́ Ògèdèngbé .Ogun Èkìtì parapọ̀ yìí ni ó mú orúkọ Ògèdèngbe dúró sinsin nínú ìtàn Yorùbá ogn náà si ja fún ọdún mẹsan gbáko ọdún 1910 ní ògèdèngbé kú.

Ohun kan tí àwọn Ìjẹ̀sà se ni Ìrántí Ògèdèngbé tí ó jẹ́ olórí àwọn Ìjẹ̀sà wà ni eréjà Ilésà ní iwájú ilé Ìfowópamọ́ ti “National Bank of Nigeria Limited”
lsẹ́ Àwọn Ìjẹ̀sà

Gbogbo àwọn ẹ̀yà ìyókù ní ilẹ̀ Yorùbá ní wọ́n mọ àwọn Ìjẹ̀sà sí onísòwò paraku idi ni yi tí wọn fi ń pe àwọn Ìjẹ̀sà ni “Òsómàáló”. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí kà nínú ìwé, a gbọ́ pẹ́ àwọn Ìjẹ̀sà ni ó dá àsà san an díẹ̀dị́ẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìsòwò. Wọ́n màá n lọ láti ìlú dé ìlú àti ìletò de ìletò láti se isẹ́ ọjà títà wọn, ohun tí wọn si n ta ní pàtàkì ní asọ.
Sùgbọ́n lónìí Ìjẹ̀sà ti kúrò ni a n kiri láti Ìlú de ìlú tàbí Ìletò de Ìletò, wọ́n ti wà nínú ilé ìtajà ní àwọn ìlú ńláńlá bíi, Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, Ògbómọ̀sọ́, Kano, Kaduna, òṣogbo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́hìn isẹ́ òwò síse ti a mọ si Òsómàló tí wọ́n máa ń kiri, wọ́n tún máa ń se isẹ́ àgbẹ̀ paraku nínú oko wọn, àwọn Ìjẹ̀sà a maa gbin kòkó, obì, isu, àgbàdo, káfé, ìrẹsì, àti orísì́ àwọn ohun jíjẹ míìràn. orísì àwọn isẹ́ míìràn tí àwọn Ìjẹ̀sà n se ni isẹ́ àgbẹ̀dẹ dúdú àti àgbẹ̀de góòlù, isẹ́ gbénàgbénà, asọ híhun, aró dídá àti orísi isẹ́ míràn.

Àwọn ilé isẹ́ ti a lè rí ní ilésà ní “ International Breweries Limited Nigeria” ni ibití wọ́n ti ń se ọtí ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Trophy Larger Beer” àti àwọn ohun amúlúdùn ti a lè rí ni ilésà lónìí ni iná mọ̀nàmọ́ná, pápá ìseré àti ilé ìtura.
Ẹ̀sìn Àwọn Ìjẹ̀sà.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, kí àwọn òyìnbó tó kó ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá de orílè-èdè wa, àwọn Yorùbá ti ni ẹ̀́sìn ti wọn. llésà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ilẹ́ Yorùbá maa n sin àwọn òrìsà bii ògún, ọ̀sun, ifá, èsù, ọya àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀sìn àtọ̀húnrìnwá ti o wá sí orilè - èdè yìí wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà ni nǹkan bíi ọdún mélòó sẹ́hìn ni a mọ̀ sí  ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì, ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ó ti àwọn lárúbáwá wọ ilẹ̀ Ìjẹ̀sà.

Ẹ̀sìn Kìrìsìtẹ́nì náà ni a ti rí Ìjọ Àgùdà (Catholic), Ìjọ onítẹ̀bomi (Baptist) Ìjọ Elétò (Methodist) Ajíhìnrere Kírísítì (Christ Apostelic Church) kérúbù àti séráfù (Cherubim and Seraphim) àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ètò Ẹ̀kọ́
Àwọn Ìjẹ̀sà ní Ìmọ̀ tí ó gbámúsé ní pa ètò ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjẹ̀sà ni o di ipò gíga mú ní ilé isẹ́ ìjọba fún àǹfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. tị́tí di àkòkò yìí ó tó nǹkan bí aadọta ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó wà ní igboro ilésà, ilé ẹ̀kọ́ girama méjìdínlógún àti ilé ìwé ẹ̀kọ́sẹ́ olùkọ́ onípòkejì méjì. Ni àfikún, ìjọba tún ti dá ilé- ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ olùkóni, fún ilé ẹ̀kọ́ giga sílẹ ni llésà ni ọdún 1977(Osun State College of Education)
Àwọn òrìsà ilẹ̀ Ìjẹ̀sà
Owari, Owaluse, Oludu, Oluaye, Ajitafa, Ogun, Omi/Osun. Sùgbọ́n àwọn òrìsà kò se bẹ gbilẹ̀ mọ́ ni ilẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ọ̀kan soso lalè ri níbú wọn ti o dàbí ẹni pé wọn sin se ọdún rẹ.




#Article 107: Ẹ̀gbá (2279 words)


Ẹ̀gbá je eya Yoruba ni Naijiria.

Ó se pàtàkì láti mọ díẹ̀ nípa ìtàn ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti irú ènìyàn tí ń gbé ìlú Ẹ̀gbá. Ìdí èyí ni pé yóò jẹ́ ohun ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó yẹ ní mímọ̀ nínú orin ògódò. Fún ìdí pàtàkì yìí, n ó ò pín àkòrí yìí si ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

	
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ló ti sọ nípa bí a ti se tẹ ilẹ̀ Ẹ̀gbá dó, tí wọn sí tì gbé àbọ̀ ìwádìí wọn fún aráyé rí. Ara irú àwọn báyìí ni Samuel Johnson, Sàbúrì Bíòbákú, Ajísafẹ́, Délànà àti àwọn mìíràn tó jẹ́ òpìtàn àtẹnudẹ́nu.

Johnson gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn Ẹ̀gbá ti wá. O ní àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá tòótọ́ lé ti orírun wọn de Ọ̀yọ́. ó tún tẹ̀ síwájú síi pé ọmọ àlè tàbí ẹrú ni Ẹ̀gbá tí kò bá ní orírun láti Ọ̀yọ́. Àwọn olóyè wọn wà lára àwọn Ẹ̀sọ́ Aláàfin láyé àtijọ́, àtipé àwọn olóyè yìí ló sá wá sí Abẹ́òkúta lábẹ́ olórí wọn tó jẹ́ àbúrò ọba Ọ̀yọ́ nígbà náà.

Délànà ní tirẹ̀ ní etí ilé-ifẹ̀ ni àwọn Ẹ̀gbá tó kọ́kọ́ dé tẹ̀ dó sí. Àwọn ni ó pè ní Ẹ̀gbá Gbàgùrà. Wọ́n dúró súú sùù súú káàkiri. Olú ìlú wọn sì ni “ÌDDÓ” tí ó wà níbi tí Ọ̀yọ́ wà báyìí. Àwọn ìsí kejì sun mọ ìsàlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n kọjá odò ọnà. Àwọn ni Ẹ̀gbá òkè-ọnà. Òsilẹ̀ ni ọba wọn. Òkó ni olú ìlú wọn .Ẹ̀gbá Aké ló dé gbẹ̀yìn.

Ajísafẹ́ ní ọ̀tẹ̀ ló lé àwọn Ẹ̀gbá kúrò ni ilé- ifẹ̀ wá Kétu. Láti Kétu ni wọn ti wá sí Igbó- Ẹ̀gbá kí wọn to de Abẹ́òkúta ní 1830. Sàbúrí Bíòbákú náà faramọ́ èyí.
Lọ́rọ̀ kan sá, àwọn Ẹ̀gbá ti ilé- ifẹ̀ wá, wọ́n ni ohun i se pẹ̀lú oko Àdágbá, Kétu, àti igbó-Ẹ̀gbá.
Ìtàn tún fi yé ni síwájú sii pé ìlú Ẹ̀gbá pọ̀ ní orílẹ̀ olúkúlùkù ló sì ń ní ọba tirẹ̀, fífọ́ tí orílẹ́ Ẹ̀gbá fọ́ lò gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìtàn ti sọ, 1821 ni Ìjà tó fọ́ gbogbo Ìlú Ẹ̀gbá ti sẹlẹ̀. Ohun kékeré ló dá Ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn òwu àti àwọn Ìjẹ̀bú ni ọjà Apòmù, Ogun Ọ̀yọ́ àti tí ifẹ̀ dà pọ̀ mọ́ ogun Ìjẹ̀bú láti bá Òwu jà. Àgbáríjọ ogun yìí dé ìlú àwọn Òwu ní tọ̀ọ̀ọ́tọ́ sùgbọ́n àwọn Òwu lé wọn padà títí wọ́n fi dé àárín àwọn Gbágùrá to wa ni Ìbàdàn. Inú àwọn Gbágùrá kò dùn sí è́yí wọ́n ti lérò pé ogun yóò kó àwọn Òwu. Èyí náà ló sì mú àwọn Gbágùrá tún gbárajọ láti pẹ̀lú ogun Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀bú àti ifẹ̀ kí wọn le borí ogun Òwu. Wọ́n sẹ́gun lóòótọ́ sùgbọ́n lánlẹ́yìn, àkàrà Ríyìíkẹ́ ni ọ̀rọ̀ náà dà nígbẹ̀yìn. Òjò ń podídẹrẹ́ ni, àwòko ń yọ̀. Kò pẹ́ ẹ̀ ni ogun Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀sà, Ọ̀yọ́ àti ifẹ̀ rí i mọ́ pé àsé àwọn Ẹ̀gbá kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ǹbẹ̀ lẹ̀kun sí àwọn Ẹ̀gbá. Wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Ìlú wọn tán lọ́kọ̀ọ̀kan. 

Èyí tí ó wá burú jù níbẹ̀ ni ti IKÚ Ẹ́GẸ́ tó jẹ olóyè ifẹ̀ kan. Lámọ́di asíwájú Ẹ̀gbá kan ló páa nígbà tí ǹ dìtẹ̀ mọ ọn. Sùgbọ́n àwọn ọ̀tá kò sàì pa òun náà sán.
Ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun tí wọn ń dí mọ́ àwọn Ẹ̀gbá yìí ló mú wọn pinnu láti kúrò ní ibùjókòó wọ́n.
Àwọn babaláwo wọn gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, wọn rí odù òfúnsàá. Wọ́n kifá lọ wọ́n kifá bọ̀, wọ́n ní wọn yóò dé Abẹ́òkúta, àwọn aláwọ̀ funfun yóò sì wá láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn babaláwo wọn náà ni Tẹ́jú osó láti Ìkìjà Òjo (a ń-là-lejì- ogbè) ara Ìlúgùn àti Awóbíyìí ará irò.

Nígbà tí wọn kọ́kọ́ dé, wọ́n do sí itòsí Olúmọ, olúkúlùkù ìlú sa ara wọn jọ, wọn do kiri Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá òkè-ọnà àti Ẹ̀gbá Gbágùrá ló kọ́kọ́ dé sí Abẹ́òkúta. Ni 1831 ni àwọn Òwu sẹ̀sẹ̀ wá bá wọn tí àwọn Ẹ̀gbá sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn Ẹ̀gbádò tí wọ́n bá ní Ìbarà ló sọ wọ́n ni Ẹ̀gbá, nínú ọ̀rọ̀ “Ẹ̀GBÁLUGBÓ” ni wọ́n sì tí fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Àwọn òpìtàn ní àwọn Ẹ̀gbádò ni ń gbé ìpadò nígbà tí àwọn Ẹ̀gbá ní gbé ni òkè ilẹ̀. Òpìtàn míìràn tún ní ìtumọ̀ Ẹ̀gbá ni “Ẹ GBÀ Á “ lálejò nítorí pé wọ́n gba àwọn Òwu àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá abẹ́ ààbò sá sí mọ́ra.

	
Ẹ̀yà orísìírísìí tó wà nílẹ̀ Ẹ̀gbá ló jẹ́ kí ó di ìlú ń lá, pẹ̀lú ìjọba àkóso tó lágbára ogun ló sọ ọ́ di kékéré bó ti wàyìÍ. Ní apá Àríwá, ó fẹ̀ dé odò ọbà, ní gúúsù ó gba ilẹ̀ dé Èbúté mẹ́ta, lápá Ìlà Ìwọ̀ oòrùn (Ẹ̀gbádò)
Johnson ní ìlú mẹ́tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta (503) ló parapọ̀ dé Abẹ́òkúta lonìí yìí.
Orísìí mẹ́rin ni àwọn Ẹ̀gbá tó wà ní Abẹ́òkúta lónìí. Kò parí síbẹ̀ àwọn miiran tún wà tí wọn ti di Ẹ̀gbá lónìí. Sé tí ewé bá pẹ́ lára ọsẹ, kò ní sàì di ọsẹ. 
Èkíní nínú àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbà yìí ni Ẹ̀gbá Aké. Orísìírísìí ìlú ló tẹ̀ ẹ́ dó, ìdí nìyí tí àwọn Ẹ̀gbá tó kù se ń sọ pé “Ẹ̀GBÁ KẸ́GBÁ PỌ̀ LÁKÉ”. Aké ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá Aké ni Ìjokò, Ìjẹùn, Ọ̀bà, Ìgbẹ̀Ìn, Ìjẹmọ̀, Ìtọ̀kú, imọ̀, Emẹ̀rẹ̀, Kéesì, Kéǹta, Ìrò, Erunwọ̀n, Ìtórí, Ìtẹsi, Ìkọpa, Ìpóró ati Ìjákọ.

Ẹ̀gbá òkè-ọnà ló tẹ lẹ́ Ẹ̀gbá Aláké. Osìlè ni ọba wọn, oun ni igbákejì Aláké. Òkò ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá òkè -ọnà ni Ejígbo, Ìkìjà, Ìjẹjà, odo, Ìkèrèkú, Ẹ̀runbẹ̀, Ìfọ́tẹ̀, Erinjà, ilogbo àti Ìkànna.
Ẹ̀gbá Gbágùrá ni orísìí kẹta. Ìdó ni olórí ìlú wọn. Àgùrá si ni ọba wọn. Àwọn Ìlú to kù ni ọ̀wẹ̀, Ìbàdàn, Ìláwọ̀, Ìwéré, òjé ati àwọn ìlú mọ́kàndínlógoji (39) mìírán.Nígbà tí ogun bẹ sílẹ̀ ni mẹ́sàn-án lara ìlú Gbágùrá sá lọ fi orí balẹ̀ fún Ọlọ́yọ̀ọ́ títí di òní yìí. Àwọn ìlú naa ni Aáwẹ́, Kòjòkú Agéníge, Aràn, Fìdítì, Abẹnà, Akínmọ̀ọ́rìn, Ìlọràá àti Ìròkò.

Ẹ̀gbá Òwu ni orísìí kẹrin, Àgó-Òwu ni olú ìlú wọn, Olówu ni ọba wọn, ìlú tó kù lábẹ́ Òwu ni Erùnmu, Òkòlò, Mowó, Àgọ́ ọbà, àti Apòmù.
Yàtọ̀ sí àwọn tí a sọ̀rọ̀ rẹ lókè yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà míìràn náà ló pọ̀ ní Ẹ̀gbá tí wọ́n ti di ọmọ onílẹ̀ tipẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn báyìí ni a kó lásìkò ogun tàbí kí wọn wá fúnra wọn nígbà tí wọn ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, tí wọn sì ǹ wá ibi isádi. Irú àwọn báyìí ni Ègùn tí wọn wá ni Àgọ́- Ègùn, Ìjàyè- ni Àgọ́- Ìjàyè, àti àwọn Ìbàràpá ni Ìbẹ̀rẹ̀kòdó àti ni Arínlẹ́sẹ̀. Bákannáà ni àwọn Ẹ̀gbádò wà ní Ìbàrà iléwó, onídà àti oníkólóbó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí sáájú Ẹ̀gbá dó síbẹ̀.

	
Láti ìgbà tí àwọn Ẹ̀gbá ti dó sí Abẹ́òkúta ni ètò ìsèlú wọn ti bẹ̀rẹ̀ si yàtọ̀. Ó di pè wọn ń yan ọba kan gẹ́gẹ́ bí olórí gbogbo gbò. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, kọ́lọ́mú dọ́mú Ìyá rẹ gbé ni. Èyí náà ló sì fìyà jẹ wọ́n. ÀÌrìnpọ̀ ejò ló sá ǹ jẹ ejò níyà.Sé bọ́ká bá síwájú, tí pamọ́lẹ̀ tẹ le e, tí baba wọn òjòlá wá ń wọ́ ruru bọ̀ lẹ́yìn, kò sí baba ẹni tó jẹ dúró. Ọ̀rọ̀ “èmi –ò-gbà ìwọ -ò -gbà” yìí ló jẹ́ kí àwọn alábàágbé Ẹ̀gbá maa pòwe mọ́ wọn pe “Ẹ̀gbá kò lólú, gbogbo wọn ló ń se bí ọba” Ọba wá di púpọ̀.

Ìjọba ìlú pín sí ọ̀nà bíi mẹ́rin nígbà tí ọ̀kan wọn balẹ̀ tán ni ibùdó titun yìí. Àkọ́kọ́ nínú wọn ni àwọn Ológbòóni. Ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ẹgbẹ́ yìí fún ra rẹ̀. Lóòtọ́, ọba ló nilẹ̀, òun ló sì ń gbọ́ ẹjọ́ tó bá tóbi jù. Sị́bẹ̀ síbẹ̀, àwọn Ògbóni lágbára ju ọba lọ. Àwọn ni òsèlú gan-an. Àwọn ló ń pàsẹ ìlú. Wọn lágbára láti yọ ọba lóyè. Delanọ ní láti ilé-ifẹ̀ ni Ẹ̀gbá tí mú ètò Ògbóni wá. Wọn tún un se, wọn sì jẹ́ kí o wúlò tóbẹ́ẹ̀ tí ilé-ifẹ̀ pàápàá ń gáárùn wo ògbóni Ẹ̀gbá.

Orò ni wọn ń lò láti da sẹ̀ríà fún arúfin ti ẹ̀sẹ̀ rẹ tòbi. Bí orò bá ti ń ké ní oru yóò máa bọ̀ lákọlákọ. Olúwo ni olórí àwọn ògbóni. Àwọn oyè tó kù tó sì se pàtàkì ní Apèènà, Akẹ́rẹ̀, Baàjíkí, Baàlá, Baàjítò, Ọ̀dọ̀fín àti Lísa{.
Àwọn olórógun tún ní àwọn ẹgbẹ́ kejì tó ń tún ìlú tò. Láti inú ẹgbẹ́ àáró tí ọkùnrin kan ti n jẹ Lísàbí dá sẹ́lẹ̀, ní ẹgbẹ́ olórógun ti yọ jáde. Ọjọ́ kẹtàdínlógún kẹtàdínlógún ni wọ́n ń se àpèjọ wọn. Àwọn náà ló gba Ẹ̀gbá kalẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tí Ọlọ́yọ̀ọ́ àti àwọn Ìlàrí rẹ fi ń jẹ wọn. Ara àwọn oyè tí wọn ń jẹ ni jagùnà (ajagun lójú ọ̀nà) olúkọ̀tún (olú tí Í ko ogun òtún lójú), Akíngbógun, Òsíẹ̀lẹ̀ àti Akílẹ́gun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni wọn si ti sẹ.
Àwọn pàràkòyí náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ọrọ ba di ti ọrọ̀ ajé àti ìsèlú. Àwọn ni n parí ìjà lọ́jà, àwọn ló n gbowó ìsọ ̀. Asíwájú àwọn pàràkòyí ni olórí pàràkòyí.

Àwọn ọdẹ pàápàá tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn atúnlùútò. Wọ́n ń dá ogun jà nígbà mìíràn. Àwọn ni wọn n sọ ọjà àti gbogbo ìlú lóru.
Àwọn olóyè ọdẹ jàǹjàǹkàn naa a maa ba àwọn tó wà ní ìgbìmọ̀ ìlú pésẹ̀ fún àpérò pàtàkì. Díẹ̀ lára oyè tí wọn n jẹ ni Asípa, olúọ́dẹ àti Àró ọdẹ.

Bí ọ̀rọ̀ kan ba n di èyí ti apá lé ko ka, o di ọdọ olórí àdúgbò nì yẹn. Bí kò bá tún ni ojútùú níbẹ̀, a jẹ́ pé ó di tìlùú nì yẹn ọba lo maa n dájọ́ irú èyí nígbà náà.
Tí a bá ka a ni ẹní , èjì ó di ọba mẹsan an to ti jẹ láti ìgbà ti wọn ti de sí Abẹ́òkúta. Àwọn náà nìwọ̀n yii 
 

ORÚKỌ ỌBA ̀ TÍ Ó JẸ . ÀKÓKÒ TÍ Ó KÚ.

ÒKÚNKẸ́NÚ 	28/08/1854 		 31/08/1862

ADÉMỌ́LÁ	 	28/11/1869 	 	 30/12/1877

OYÉKÀN 	18/01/1878 		18/12/1881

OLÚWAÁJÌ 	 09/02/1885 	27/01/1889

SÓKÁLÙ 	18/09/1891 	11/06/1898

GBÁDÉBỌ̀ 	08/08/1898 		28/05/1920

ADÉMỌ́LÁ II 	10/07/1920 		27/12/1962

GBÁDÉBỌII 	12/08/1963 		26/10/1971

LÍPẸ̀Ẹ́DẸ́ I 	10/08 1972 		……………

Yàtọ̀ sí ọba Aláké tí a to orúkọ wọn sókè yìí, ọba mẹ́rin míìrán tún sì wà ní Abẹ́òkúta tí wọn ń se olórí ìlú wọn. Sùgbọ́n, gbogbo wọn tún sì wà lábẹ́ aláké gẹ́gẹ́ bii ọba gbogbo gbò ni. Àwọn ọba náà ni, Àgùrà Olówu, Òsilẹ̀ àti olúbarà. Ọba aládé sì ni gbogbo wọn. Ní ti oyè tó kù nílùú, o ní agbára tí wọn fún ìlú kọ̀ọ̀kan láti fi olóyè sílẹ̀. Ẹ̀gbá òkè- ọnà ló ń yan ọ̀tún ọba. Ẹ̀gbá Gbágùrá lo n fi òsì àti Òdọ̀fin sílẹ̀. Ẹ̀gbá Òwu lo si n yan Ẹ̀kẹrin ìlú.
	Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jàǹkànjàǹkàn tó ti fi ẹ̀mí wọn wu ewu fún Ẹ̀gbá ni wọ́n máa ń ráńtí nínú gbogbo orin wọn. Wọn a sì máa fi orúkọ wọn búra pàápàá. Irú àwọn báyìí ni Sódẹkẹ́, Lísàbí, Ẹfúnróyè, Tinúubú ati Ògúndìpẹ̀ Alátise. Àwọn Ẹ̀gbá kò kó iyán wọn kéré wọn kò sì yé bu ọlá fún wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú.

Orísìí ètò ìjọba mẹ́rin ọtọ̀ọ̀ọ̀tọ̀ ni ó ti kọjá ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá kí á tó bọ sí èyí tí a wà lóde òní. 

Ètò ìbílẹ̀ lábẹ́ àsẹ Ògbóni àti Pàràkòyí 1830-1865

Ẹ̀gbá United Board of Management 1865-1898

Ẹ̀gbá United Government (Ìjọba Ẹ̀gbá) 1898 – 1914

Ẹ̀gbá Native Administration (Ìjọba Ìbílẹ̀) 1914 – 1960

Orísìírìsìí isé ajé ni àwọn Ẹ̀gbá n mú se nínú ìlú. Yàtọ̀ sí isẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ tajá tẹran ló ń seé wọ́n fẹràn láti máa da aró, wọ́n mọ̀ nípa àdìrẹ ẹlẹ́kọ dáadáa. Wọ́n tún nífẹ̀ẹ́ si òwò síse. Àwọn àbọ̀ ilẹ̀ sàró ni ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òwò síse yìí túbọ̀ gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kò sí ìlú kan tí kò ní ọjà tirẹ̀, sùgbọ́n àwọn ọjà ń lá kan wà tó ti di ti gbogbo gbo. Irú àwọn ọjà báyìí ni Ìtọ̀kú, Ìta Ẹlẹ́gà, ọjà ọba àti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó. Paríparí rẹ̀ àwọn Ẹ̀gbá fẹ́ràn láti máa kọrin lásán.yálà kíkọ tà gẹ́gẹ́ bí alágbe tàbí ìfẹ́ láti máa kọrin lásán. Gbogbo ohun tó sì ti sẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wọn ni wọ́n máa ń mú lò nínú orin wọn pàápàá.

A ti sọ pé kálukú ẹ̀yà Ẹ̀gbá ló ń da ọmú ìyá rẹ̀ gbé, sị́bẹ̀, kò sàìsí ìbásepọ̀ díẹ̀ láàárín wọn.
Lọ́nà kìnní, gbogbo Ẹ̀gbá ló gbà Abẹ́òkúta sí ìlú wọn.Wọn ni ilẹ̀ níbẹ̀, sùgbọ́n wọn a máa lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti lọ múlẹ̀ oko. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń wálé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oko ẹ̀yìn odi ìlú báyìí lo ti di ìlú fún wọn. Abúlé ni wọn n pe àwọn ìletò wọ̀nyí. Kò sí ọmọ Ẹ̀gbá kan tí kò ní abúlé . Ètò abúlé wọ́ pọ̀, ó sì gún régé, Baálẹ̀ tàbí olóróko (olórí oko) ni o wà ní ipò ọ̀wọ̀ jùlọ.

Bákan náà ló jẹ́ pé gbogbo wọn lo jọ ń bú ọlá fún àwọn ẹni ńlá wọn. Kò sí pé apá kan kò ka àwọn ẹni àná yìí wọ̀nyìí́ kún.
Orò tún jẹ́ ẹ̀sìn kan tó so wọ́n pọ̀. Nílélóko ni wọn ti ń sọdún orò lọ́dọọdún. Àwọn olórò ìlú kan lè mú orò wọn dé ìlú mìíràn láìsí ìjà láìsí ìta. Lóòótọ́, ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní òrìsà tirẹ̀ tó se pàtàkì, fún àpẹẹrẹ, àwọn Òwu ló ni Òtòǹpòrò àti Ẹlúkú. Àwọn Odò ọnà ló ni Agẹmọ, àwọn ìbarà lo ni Gẹ̀lẹ̀dẹ́. Òrìsà Àdáátán, ọ̀tọ̀ ni. O máa ń sẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé tí ìlú kan bá parí ọdún tiwọn lónìí, tí àdúgbò míìràn le bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ keje ẹ̀. Èyí kò sí yi padà láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

Ọjà kan náà ni wọn jọ́ ń ná, oúnjẹ ti wọn ń jẹ ní Aké ni wọn ń jẹ ní Òkò. Wọn fẹ́ràn àmàlà láfún púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń jẹ Sapala kòkò, ewé, awújẹ àti èsúrú.




#Article 108: Ilẹ̀ Ọba Bakuba (236 words)


Ilẹ̀ọba Bakuba (o tun nje Kuba tabi Bushongo)
								
Ifáárà: Àwọn kúbà náà ló ń jẹ Bushoong.

Ààrin gbungban gusu (Congo Zaire) ni wọ́n wà

Ẹgbẹ̀riún mẹ́tà-dún-lóguń ni wọn  

Ede Bushhoog ló jẹ́ ẹ̀yà Bàǹtú ni wọn ń sọ 

Biombo, lùbà, kasai, lenda, pyaang, àti Ngongo 

Awọn Bushoog ni ẹ̀yà tó pọ jù ni kńbà.Baba-ńlá wọn ló tẹ ibẹ̀ dó. Abẹ́ 
Ìṣèjọba Shyaan kan soso bi gbogbo wọn wà. Òun ló ń darí wọn. Apá ìwọ̀-oòrùn ni wọ́n ti wá sí tí wọ́n etí Máńgò wọn  bá àwọn ìwa àti kété sì parapọ̀ ṣe ìjoba kúbà.  

IṢẸ́ ỌNÀ WỌN	

Àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà tí àwọn adarí ìjọba àti àwọn mẹ̀kúnǹu ń lò bí :-

Awọn Bushoog ló ń darí Kuba. Olú  ìiú wọn ni 
Nsheng. Ó le ní ọgọ́ruǹ-ún aṣojú fún ìgbèríko kọ̀ọ̀kan. Òfin ati ìlànà ọba Nyimu wọn ń tẹ̀̀ lé oba shyaam ni ọba àkọ́kọ́. Àwọn ọba mọ́kaǹlélógún ló sì ti jẹ lẹ́yìn rẹ̀. o ti ló iríniwó ọdún ṣẹ́yìn tie ̀tò ìjọba náà ti bẹ̀rẹ. 

Bumba ni ẹdá àkọ́kọ́ nínú ìtàn ìgbà ìwáṣẹ̀ won. Òun ló fí awọn Bushoong se asíwájú àti olórí -Ẹ̀sin Baba ńlá wọn ni wọn ń sìn. Ẹ̀sín ọ̀ún ti ń ku lọ díẹ̀díẹ̀. Síbẹ̀, Ìfá tabi Adábigbá ń gbé láàrin wọn. Wọn gbà pè òròṣà ló ko oríre bá wọń. Ère ajá ni wọṅ ń sí ojúbọ òrìsà wọṅ . Ère yìí ló dúró bí olúgbàlà wọn.




#Article 109: Kuwere (193 words)


ÀÀYÈ WỌN

 	Wọ́n wà ní apa ìwọ-oòrun ààrin gbuǹgbùn Tanzania.

IYE WỌN 

	Wọn lè ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta eǹìyàn 

ÈDÈ WỌN 

	Èdè kikwer (ti Bàǹtú ni wọ́n ń sọ

ALÁBÀÁGBÉ

	Zaramọ, Doe, Zingna, Luguru àti Swahili.

ÌTAǸ WỌN 

	Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣẹ́yìn ni baba ńlá Kwere de láti Mozanbique.Nínú ìrìn-àjò wọn ni wọ́n ti bá àwọn eǹìyaǹ Swahili tí wọn di mùslùmí pàdé wọn  fìdí tì sí ibẹ̀ pẹ̀lu àwọn alábàágbè wọn bí Zeramo ati Doe 

ÌṢẸ̀LÚ WỌN	

Àwọn Kwere ò ni ìjọba àpapọ̀ Ijọba ìletò,ijọba abúlé àti ìjọba ìlú-síluń ní wọ́n  ní Àgbà àdúgbò ló ń fi olórí jẹ. Olórí ló ní aṣẹ ilè ìran. Òun si ni ètùtù ìlu wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ọkúnrin ni olórí sáábà ń jẹ́. òun ló ń pàrí ìjà láàrin ẹbi. Agbára ńlá, ọwọ́ rẹ̀ ló wà . Òun náà ló ni agbára tí a fi ń bá èmi àìrí sọ̀rọ̀. 

ỌRỌ̀ AJÉ WỌN 

	Àgbẹ̀ paraku ni wọ́n. Wọ́n ń gbinsu, gbìngẹ̀, gbìngbàdo. Wọ́n ń gbin òwú àti tábá. wọ́n ń sin ẹranko àti ẹyẹ wọn a sì tún máa ṣe ọ̀sin eja.  

IṢẸ̀ ỌNA WỌN

 	Awọn KWERE máa ń gbéji rèbété. 

Ẹ̀sìn WỌN 




#Article 110: Kiwahu (152 words)


ÀÁYÈ WỌN 

	Wọ́n wà ní apá Àríwá Ghana

IYE WỌN

	Wọ́n  lé ní ẹgbẹ̀rún márún –lé lọ́gọ́ta. 

ÈDÈ WỌN 

	Ède Akàn ti ẹ̀yà Twini wọn ń fọ̀ 

ALÁBÀÁGBÉ WỌN

 	ANYI, Asante àti Fante

ÍTÀN WỌN 

	Ẹ̀yà Akan tó ń gbé Àríwá Ghana ni Kwahu. Ìjọba ńlá Akàn bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí sẹ́ńtúrì mẹ́tàla] sẹ́yìn. Àsìkò yìí ni ìjọba ńlá Asanti bẹ̀rè òwò góòlù Àwọn ìpi]nlẹ̀ kéékèèke díde láti gba òmìnira lábẹ́ Denkyira lábẹ aláẹẹ Kumasi Àgbáríjọ Akàn sí lágbára ìsèlú àti ọrọ̀ aje.   

ÌṢÈLÚ WỌN

 	Ìdílé kọọ̀kan ló ní ètò ìṣèlú àti òfin wọn. Olórí okó wà, olórí àdúgbò wà, olori agbègbè wà, mọ́gàjí náà sì wà tó fi dorí ńla Asante. Agbàra ńlá jẹ̀ orírun rẹ̀ dà Asante nìkan tó le jẹ olórí agbègbè tábí ìlú. Títí di àsìkò yìí ni àwọn Asante ń kópa nínú etò ìSèlú Ghana 

IṢẸ̀ ỌNÀ WỌN 

	-	Wọ́n máa ń ṣe Bojì lósọ̀ọ́

ẸSIN WỌN 




#Article 111: Laka (220 words)


ÀÀYÈ WỌN 	

Grúsù ìls̀ oòrùn chad ni wọ́n wà 

IYÈ WỌN	

Ẹgbèrún lọ́nà ọgóruǹún 

ÈDÈ WỌN	

Lake àti Mbonu (Niger-Congo) ni wọ́n ń ṣo

ALÁBÀÁGBÉ WỌN 

	Sára, Èèyan Cameroon àti Fúlaní ni múlé tí wọ́n

ITAN WỌN 	

 Àríwá ìlà oòruń oko chad ni wọ́n ti ṣẹ. Ijọba ńlá tí Fúlàní ló wọn dèbi wọ́n wà yìí. Èdè àti aṣa wọn àti ti Cameroon tó jẹ́ bákan náà.

ÈTÒ ÌṢÈLÚ WỌN 

	Eto ìṣè ijọba abúlè wọ́n jẹ́ ti ẹlẹ́bí baba. Olórí febí wọn gbọ́dọ́ le tan orírun wọn sí ọ̀dọ̀ baba ńlá Laka.  Olórí yìí ló sì ń ṣe ìfilọ̀ ètò àgbẹ̀  

ỌRỌ̀ AJÉ 	

Owú ni wọ́n fi ń sọwó sókè òkun. Agbàdo, bàbà àti ohun ẹnu ń jẹ ló pọ̀ lọ́dọ̀ wọn Àsíkò òjọ nikan ni wọn le ṣe ògbìn nǹkan wòńyi. 

IṢẸ́ ỌNÀ WỌN 

	Àwọn ló ń ṣọnà sí ara. Èyí ni wọn ń lò nígbà aápọ̀n tabi obitan 

Ẹ̀SÍN WỌN 	

Ẹbi wọn sì ń pèṣè fún àwon òkú ọ̀run wọn lójoojúmọ́.

	Orúkọ èdè yìí ni a mọ̀ sí Lákà; tí orúkọ rẹ̀ mìíràn a tún máa jẹ́ Kabba Laka. Èdè adugbo wọn ni a mọ̀ sí Bemour Goula, Mang Maingao pai. Aarin gbungbun ilẹ Chad ni wọn ti n sọ o; wọ́n sì jẹ́ ibatan pẹ̀lú Nilo-Saharan. LAP ni ami tí wọn kọ́kọ́ ń lò dípò èdè Ganda. 




#Article 112: Luba (184 words)


ÀÀYÈ WON	

Àríwa iwọ oòrùn Congo (Zaire) 

IYE WỌṄ 	

Mìlíonù kan 

ÈDÈ WỌṄ  	

CILUBE (Ààrin gbùngbùn Bantu) 

ALÁBÀÁGBÉ WỌN	

Chowe, Ndembu, Kaonde, Benba, Tabwa, Songye, Lunda.

ITAN WỌṄ	

Ijọba ńlá Luba ti bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún  kan ààbọ̀ ọdún sẹ́yin 1,500. Ìjọba  yìí ń gbòòrò láti Upemba tí Í ṣe ààrin gbuńgbún Lube. Wọn fẹ̀ dé iòkè Tangayika lábẹ́ llnngh Sungu tí í ṣe olorí wọṅ ní 1760-1840. Ó gbòòrò de apá àríwá àtiu gusu ní 1840 lábẹ́ iiungo kablee. Igbà tí olórí yà papòdà ni awọṅ Láíubáwó amúnilérú àti àwọn òyìbó anúnisìn  sọ ìjọba ńlá wọn di yẹpẹrẹ.   

ÌṢẸ̀LU WỌṄ 	

Ìjọba àpapọ̀ ni wọṅ ń ṣe Aláyèlúwà (Mulopwe) ni olórí wọn. Awọṅ ìlú kèkerè ń wárì fún Mulopwr. Òun ìlú àti olórí ẹgbẹ́ Bambulye

ỌRỌ̀  AJE WỌN  

	Iṣẹ òwò iyò àti iru ni àwọṅ ọlọlá wọn tún ń ṣe àgbe iṣẹ ọdẹ ẹran àti ti ẹja tún wó pọ̀ láàrin wọn.

IṢẸ́ ỌNA WỌṄ 	

Iṣẹ́ agbẹ̀gilére ni iṣẹ] wọn. Ère ló ń ṣègbè fún  abọ ni wọṅ ń gbẹ̀. Wọ́n tún ń gbẹ̀ ère àgba tí a mọ̀ sí (Mboko) 

Ẹ̀SÌN WỌN	




#Article 113: Sadiiki (363 words)


	Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ New man (1992:253) ó ṣọ́ pe o to nǹkan bi ogóje èdè Chadic gẹ́gẹ́ bí maapu ṣeṣe àfihàn ó tanka èka mẹ́fa nínú ajúwe lati adagun odo Chad nibi tí orúkọ ìdílé ti sẹ̀ wa ti a ṣi ń sọ ni apá kan nìjìríà, Chad Cameroon orílẹ̀ èdè Arìngbùngbùn ilẹ́ Áfíríkà olómìnira àti Niger. Èyí tí ó dára ju tí ó si tan káàkiri ti á ń ṣọ ní èdè Chadic tí a mo si Hausa, tí ó jẹ pe ti á ba fi mìlọnu àwọn tí wọn ń ṣọ èdè kejì ti a ba wo ìgbéléwọ̀n náà a ó ri gẹ́gẹ́ bí èyí to tóbi jù nínú àwọn adúláwọ̀ to n ṣọ èdè náà tì ó sì je pé à yọ Arabiki kúrò ninú rè. 
	Àwọn yòókù tí wọn ń sọ èdè Chadic kò jú ẹgbẹ̀rún kan nìgbà tó o jẹ́ pé àwọn yòókù ko ju perete lọ Newman(1977) wọn pin àwọn Chadic si mẹrin 

(1)	Èdè Chadic ní wọn ń sọ ni ìwọ̀ Oorun Níjiria ti o sì pín ṣi ẹka méjì ìkan wa ní ìṣọ̀rí agbo mẹrin àwọn wọ̀nyí ní Hausa (22,000), Bole (100), Angas (100) ati Ron(115) Nígbà ti ọ̀kan wà ní ìṣọ̀rí mẹ́ta tí á ṣi se àfihàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Bade (250) àti Nalzlm (80), lati Ọwọ Warji (70) ati Boghom(50)

(2)	Bio-Manchaca ni èdè tí wọ́n ń ṣọ ni agbègbè Àríwá Cameroon àti Àríwá ìlà Òòrùn Nígiria pẹlu Chad àwọn ẹka mẹta nígbà tí ìkan jẹ mẹjọ, ti a si ṣe àfihàn rẹ lati Ọwọ Tera (50) Bura (250), Kanwe (300), Lamang (40), Mafa 9138), Sukur (15), Daba (36) àti BaChama-Bata 300. Àwọn méjì nínú ẹ̀ka méjì a le ṣe àfihàn wọn láti Ọwọ Buduma (59) ati Musgu (75) Ìpele Kẹta kun fún èdè ẹyọ kan Gudar (66) 

(3)	Èdè Chadic ní wọn ń ṣọ ní Chad Gusu àti diẹ lára Cameroon àti àringbìngbìn ilé Áfíríkà olómìnira. Èdè náà ní ẹ̀ka méjì tí ó kún fún ẹgbẹ́ ìṣọ̀rí mẹta mẹta tí ó ni ẹka a ṣe àfihàn iṣupọ lórísìíríṣí Ọwọ Kera *51) púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí a le ṣe àfihàn rẹ lati Ọwọ Dangaleat (27) ati Mokulu (12), àti lowo Sokoro (5) 




#Article 114: Sẹ̀mítíìkì (753 words)


	Semitic ni àwọn ènìyàn ka ju ti o ṣi ye wọn jù síbẹ̀ àwọn èdè kan wa ti wọn kò mọ rárá nipá ṣiṣe arópò extant ati extinet kan. Semitic ṣe ipatẹ adọọfa lorisiirisi. Nípa ìṣàkóṣo ti ìbílẹ̀ wọn ṣùgbọ́n dọsini kan àbọ̀ lo wà lábẹ́ ìṣàkóṣo àwọn Arabiki, ṣùgbọ́n àwọn kan rò wípé ko ba ojú mu lati ṣe bẹ. 
	Àwọn Oludari kan gba pe Semitic a le ri orukọ wọn ni àríwá ìlà Oòrùn, àríwá Iwọ Òòrun àti Guṣu lábẹ́ ipin ẹka ìdílé kan ṣùgbọ́n aríyanjiyan wa lórí pe bóyá Arabiki wa ni ariwa ìlà Oòrun tàbí pẹ̀lú ẹ̀ka ìdílé Gúṣù. Arákùnrin tí Orúkọ rẹ̀ ń jẹ Hetzron (1972: 15-16)5 ṣe àríyànjiyàn lórí ipò 

(1)	Ẹka ìdílé àríwá ila Òòrun wa láti Akkadian, nítorí èdè to ti paré tó jẹ́ ayé òlàjú tó ti kọjá lọ ti àwọn Assyrians àti Babylonians nígbà to ṣi jẹ pé Akkadian wà ní lílò fún nǹkan bi Ọdún meji miliniọnu títí di àkókò ayé jésù Hetzron pin àríwá ìwọ̀ Oòrùn Semitiki si àringbùngbùn àti Gúṣù àríwá ṣi ẹ̀ka. Ti àwọn Ìsáájú dúró fún Aramaic ní àṣìkò ìgbà ayé àtijọ́ ati tí ode òní orisiirisi Aramaic ni wọ́n ń ṣọ lati nǹkan bí Centiuri mẹwa BC. Ṣẹ́yìn. nǹkan  bì Centiuri mẹ́fà sẹ́yìn àwọn kirisitẹni Aramaic nìkan ní ó jẹ́ èdè to gbalè nígbà náà bi ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èdè tí á ń ṣọ ni ìlètò ti tàn Kariaye ìwọ̀ Òòrùn Aramaic /ma’lula(15) Turoyo (70) èdè tí á ń pe láàrín àwọn Olùṣo èdè ní Assyrian (200). 
	

	Àwọn phonecian, ni tòótó wọn ń sọ̀rọ̀ nipa Lebanon, nígbà to yá o ń tàn ká nípa gbígba Òmìnira, nígbà to ya ó di èdè àwọn keteji (Carthage) níbi tí á tí mọ hàn-án bí puniki. 
	Èdè ìgbàlódé ti àwọn Hébérù ń ṣọ ni Isrealis lo ṣe àtúnṣe rẹ (4, 510). Èdè tí àwọn Ras Shamra àti Uguritic ń sọ kàyéfì lo jẹ́. Èdè to ti pẹ́ tí àwọn Quran ń lò láti Centiuri kẹrin AD, lo wà ṣùgbọ́n nígbà tó yá wọ́n padà ṣí tí Centiuri karun BC; ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n ko ṣọ mọ́. 
	Loni Orísìírìsí ìpínlẹ̀ Arábìkì tí wọ́n ń so ní tí gbogbogbo ní àrín ìlà Òòrùn àti àríwá adúláwọ̀ Afíríkà. Ní Áfíríkà àwọn èdè tó hàn gbegedé wọn ṣi pegedé Egyptian (42,500), hassaniya (2, 230), ti wọn ń ṣọ ní Mauritania àti díẹ̀ lápá Mali Senegal àti Niger, Morocan (19,542); Shua (1,031), wọn ń ṣọ díẹ̀ ní Chad, Cameroon, Nigeria Niger; Sudanese (16,000-19,000) ohun nìkan ni wọ́n ń sọ ní Àríwá Sudan ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn Olùṣọ èdè ni Egypt àti Eritrea; Algerian Colloquial (22,400), tì wọ́n ń sọ Tunisia; àti Sulaimitoan  (4,500) ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣọ èdè yìí díẹ̀ ní Libya àti Egypt. 
	Ó dá hàn yàtọ̀ ṣí ẹ̀dá ọ̀rọ̀ aláwomọ èdè oni ti Arabiki ṣùgbọ́n èdè Arabiki ní a ń lò fún ẹ̀kọ́ Ìṣàkóṣo àti Ìgbòòrò Ìbánisòrọ̀ bakan náà a ń lo gẹ́gẹ́ bi èdè kejì ó si jẹ́ èdè ìpìnlẹ̀ àkọ́kọ fún èdè Arábìkì. 
	Ìyàtọ̀ ẹ̀dá Ìgbẹ́dègbẹ́yọ̀ wúni lórí nítorípé àpèjúwe àkọ́kọ́ Ferguson (1959) Maltese  (330) wọn ń sọ̀rọ̀ nìpa ilè ti omi yíká ti Malta ati níbikíbi ohun ní ìpìlẹ̀ èdá ti Àríwá Afíríkà Arabiki ṣùgbọ́n tí ó tí tàn ka láàrín àwọn Italiàni. 

(3)	Sémítìkì to wa ní Guṣu kún fún àwọn Arabiki Guṣu àti Ethic Semitic Ṣùgbọ́n àwọn ti tẹ́lẹ̀ kún fún Orísìíríṣí bi Hadrami Mineah  Ontabanian ati Sebaean, Òhun nìkan ni a mọ̀ láti ìwọ̀ Òòrùn Guṣu Arábìkì àkọsílè rè tí wà láti Centiuri méjọ BC pẹ̀lú Arábìkì ti Guṣu Soqotri (70), Mehri (77), Jibbali (25) àti Harsusi (700) Ṣùgbọ́n ki i se gbogbo àwọn Òmòwé to gboye nínú koko isẹ kan lo fara mọ̀. 
	Ethic-Semitic kún fún àwọn ará Àríwá Eghiopic àti ẹ̀ka ọ̀rọ̀ aláwòmọ́ àti Liturgical G I’ IZ Ùqre (683) àti Tigrinya (6, 060) àti Ethiopia tí ó wa ní ẹ̀ka Guṣu to wa láàrin ita tì kò sí ní pínpín. 
	Amharic (20, 000) èdè Ethopia jẹ tí gbogbo gbo ó wà lára ti tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Harari (26), O jé ẹni ti ahọ́n rẹ̀ fanimọ́ra tí ó si jẹ tí ìbìlẹ̀ ṣi gbogbo ìlú Harari gbogbo àwọn ẹgbẹ́ atòdefimọ̀ gbárajọ pẹ̀lú àwọn ará Àrìwá tí Gurage l’orisiirisi  gẹ́gẹ́ bí Soddo (104) yàtọ̀ si tí àringbùngbùn tí ìwọ̀ Òòrùn pẹ̀lú Chaha, Masqan, e.t.c. tí wọ́n jẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ (1,856) Orísìírírìsí nǹkan tí Gurage fi kun ni silti (493) a ṣi ṣe àpínsowoó rẹ̀ ṣi ẹgbé èyí ti o wa láàrín. Ó ṣe pàtàkì kí á ka “Gurage” ká á ṣi fi hàn gẹ́gẹ́ bi èdè kan.




#Article 115: Kusitiiki (514 words)


	Kí á to lè ri Chustic gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan ó ní ṣe pé kí á pápọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ìsọ̀rí èdè yòókù, díẹ̀ nínú wọn dá hàn yàtọ̀ láàrín ara wọn; Àwọn kan ṣe àfihàn tí ó dádúró tí ó ṣi yàtò láàrín ẹ̀ka egbẹ́. Ó ṣì ṣúnmọ́ atodefimọ èdè. Díẹ̀ laarin àwọn àgbà ẹgbẹ́ odẹ ni Kenya lo ń ṣọ Yaaku. Àwọn ẹgbẹ́ mééfèfà jo ni nǹkan kan to jọ jẹ àjọni lórí ẹ̀kọ́ nípa ayé to dúró lórí aṣàmì tí ó wa ní ìsàlẹ̀, ìlà Òòrùn Cushitic to wà lórí òkè ati èyí to wa ní ìlà Òòrùn to wa nílẹ̀, Dullay àti Yaakuni nǹkan tí wọn fi se àárin dipo kí a ka lábẹ́ ìlà Òòrùn ẹwọ́n Cushitic. 

(1)	Cushitic to wa ní Àríwá kún fún èdè eyọkan, Badawi/Beja (1,148), tí á ń ṣọ ní agbègbè to farapẹ́ ìpín ti Sudan, Egypt àti Eriterea. 

(2)	Cushitic to wa ní àringbùngbùn jẹ mọ èdè Àgaw, ó jẹ ẹgbẹ́ ti a ṣe atúnmọ̀ rẹ̀ lórísìírìsí ni Àríwá ìlà Òòrùn Ethiopia àti Kwara lápapọ̀ 1,000), Xamtunga (80), Awngi (490), àti díẹ̀ lórìṣìírìsí tó rún 

(3)	Ai ba ìgbà mu fún Burji, Cushitic tó wà ní ìlà òòrùn tún mún ìpàdé ìṣùpọ̀ àhánnupè. Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀sọ̀ ń gbé ní orí òkè tí wọn ń ṣọ Burji wa ní Àríwá Kenya àwọn ẹgbẹ́ náà ní Burji (87) Sidamo (1,500) àti Kambata Halìyya ẹgbẹ̀rún kan. 
Àwọn Cushitic ìlà Òòrùn ní ẹka ẹgbẹ́ mẹta. 

(i) 	Àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ Àríwá wọn dúró fún saho (144) àti Afari (1,200) 

(ii)	Àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ Oromoid kún fún Orísìírìsí Ojúlówó Oromo (13, 960) tí wọ́n tí sọ̀rọ̀ lati Odò Tana ní kenya si ìpààlà sudan àti Tigrai kòkàárí tí Ethiopia àti konsoid, èdè abínibí lo sọ wọn pọ̣̀ ni Gusu ìwọ̀ Òòrùn. Ṣùgbọ́n eyi ti wọn ń ṣọ ni Kanso (200)

(iii)	Àwọn ọmọ Tana wọn jẹ mo ìlà Òòrùn àti ìwọ̀ Òòrùn ti ìpààlà wa láàrìn wọn. Àwọn ará tẹ́lẹ̀ kún fún Àríwá ni Kenyan Rendille (32) Boni(5) Lapapọ iye ti àwọn Somali jẹ (8,335) Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Somalia, Djiboute, Ila Òòrùn Ethiopia, ati Aríwá ìlà Òòrùn Kẹnya. Ti ìwọ̀ Òòrùn pín tó ṣí ní Daasenech (30) Arbore (1,000-500) àti bóyá èdè Elmọlo. 
	Èkọ́ nípa ìmọ̀ ayé tí ó da wà ní Bayso (500) òhun ní wọ́n ń ṣọ ní agbègbè Abàjà adágún nínú Ethopian Rift Valley tí ó pin ẹya kan pẹlu ìlà Òòrùn atí ìwọ̀ Òòrùn. 

(4)	Dually dúró fún gẹ́gẹ́ bi okùn ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ní àgbègbè Wayto Valley ṣí ìwọ̀ òòrùn ti Konsout (of 4(n) soke) èyí to yàtọ̀ l’orisiirisi ni Gusu Tsmay (7) pípàdé ẹgbẹ́ onihun ìsùpọ̀ lójúpọ̀ parapọ̀ ní Ethnologue gẹ́gẹ́ bi Gwwada (65-76).

(5)	Èdè Cushitic ni Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ń sọ ni Tanzania, níbi ti wọn ti dúró fún iraqw gẹ́gẹ́ bí ìsùpọ̀ fún apẹẹrẹ (365), Gorowa (30) Burunge (31) Mbugu/Mana (32) ní wọn ṣábà maa ń lò gẹ́gẹ́ bi ojúlówó àpẹ̀ẹrẹ èdè àmúlùmálà àti alaisi Asax àti fún kw’adza ọmọ ẹgbẹ ti i ki i ṣe ọmọ ìlú Tan zania tó jẹ dahalo (3,000) ó sọ̀rọ̀ ní ìletò to ṣúnmọ́ ẹnu ìlú odò Tana ní Kenya.




#Article 116: Àwọn èdè Niger-Kóngò (2680 words)


	
Àkójọpọ̀ èdè tí a mọ̀ sí Niger-Congo dín mẹ́rin ni òjì-lé-légbéje. Grimes (1996) ríi gẹ́gẹ́ bíi èyí tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé àti wí pé àwọn èèyàn tí ó ń sọ ọ̀kan tàbí èkejì nínú. àwọn èdè yìí fọ́n ká orílẹ̀ ayé ju àwọn ìyókù akẹgbẹ wọn lọ. 
	Ní orílè èdè Afíríkà, àwọn èdè tí ó ní èèyàn tí ó pọ̀ jùlọ ni wọ́n jẹ́ èyí tí a lè rí ní abẹ́ àkójọpọ̀ èdè Niger-Congo. Bí àpẹẹrẹ, èdè tí ó tóbi jùlọ ni Senegal, Wolof jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè Niger-Congo; Fulfude tí ó tàn káàkirí ìwọ̀ oòrùn àti àárín gbùngùn Afíríkà, ọkan níbẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ náà ni èdè Manding tí ó gbajú gbajà ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onikaluku ni ó ní orúkọ tí ó ń pe èdè yìí, oun náà sì ni a mọ̀ ṣí Bambara tí ó jẹ́ èdè orílè èdè àti ìjọba Mali àti Dyala, èdè Okòwò gbalé-gboko. A kò gbọdọ̀ gbàgbé Akan ní orílẹ̀ èdè Ghana. Yorùbá àti Igbo náà kò gbẹ́yìn níbẹ̀, èdè pàtàkì ni méjèèjì yìí ní orílẹ̀ èdè Nàìjiria. Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, èdè Sango ni wọ́n ń sọ. Àwọn èdè Bantu bíi Ganda, Gikuyu, Kongo, Lingala, Luba-Kasari, Luyia, Mbundu (Luanda), Northern Sotho, Sukuma, Swahili, Tsonga, Tswana, Umbundu, Xhosa ati Zulu. 
	Ó tó èèyàn bíi Mílíọ̀nù lọ́nà ọtà-lé-lọ́ọ̀dúnrún sí Mílíònù irínwó tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń sọ èdè Niger Congo ní Áfíríkà, gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe sọ. 

IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ LÓRÍ ÌPÍN ÈDÈ NIGER-CONGO 

	Ọkan gbòógì lára àwọn èdè tí a rí lára ìpín èdè Niger-Congo ni àkójọpọ̀ èdè Bantu jẹ́. Àwọn èdè yìí gbalẹ tààrà ní ilẹ̀ Áfíríkà, wọ́n sì jọra gidi. Ní abẹ́ gírámà rẹ, a ríi wí pé àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ inú àwọn èdè yìí jọra gan-an, èyí ni ó sì mú àwọn onímọ̀ tí ó jẹ́ aláwọ̀ funfun fi ara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwádìí ní orí àwọn èdè wọ̀nyí. Koelle àti Bleek sọ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà èdè tí àwọn ènìyàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ń sọ ni ó ní ọ̀rọ̀ orúkọ tí a sẹ̀dá nípa àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀. Nínú ìwádìí tirẹ̀, Meinhof sa awọn èdè kan jọ tí wọ́n fi ara pẹ́ ara wọn láti ara ọ̀rọ̀ orúkọ wọn ṣùgbọ́n tí gírámà wọn yàtọ̀ díẹ̀. Èyí ni òún pè ní ‘Semi-Bantu’.
	Westerman ṣe iṣẹ́ tí ó jọ mọ́ ti Meinhof díẹ̀. Ní tirẹ̀, ó se ìpìnyà láàrin àwọn èdè tí ó farahàn ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Sudan. Ó ṣe àkíyèsi àwọn èdè kan tí a rí ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sudan; àwọn náà ni ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà: Kwa, Benue-Cross, Togo, Gur, Mandingo, àti ti ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì. 
	Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sílébù nínú àwọn èdè wọ̀nyí ni wọ́n jé ‘CV’.
	Greenberg yapa díẹ̀ nínú èrò ti rẹ̀. Ó ṣe àtúnpín àwọn èdè wọ̀nyí láàrín ọdún 1949 sí 1954. Ní tirẹ̀, ó pín Bàntú àti ìwọ̀ oòrùn Sudan sí ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó pè ní Niger-Congo, ó sì ṣe àdáyanrí ìlà oòrùn Sudan sí ìsọ̀rí mìíràn ọ̀tọ̀, ó pè é ni Nilo-Saharan. Iṣẹ́ rẹ̀ sì fi ara pẹ́ ti Westerman tààrà ní abẹ́ ìsọ̀rí yìí. Àwọn kókó inú iṣẹ́ Greenberg ni ìwọ̀nyí: 

	(a)	Orúkọ Mandigo yí padà sí Mande 

	(b)	Àárín gbùngbùn Togo di ara Kwa 

	(d)	Benue-Cross yí padè di Benue-Congo 

	(e)	Bantu di ìsọ̀rí kan lábẹ́ Benue-Congo 

(ẹ)	Fulfude di ara ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì; Serer àti Wolof sì di ara kan náà pẹ̀lú fulfude. 

(f)	Adamawa kún àkójọpọ̀ èdè yìí

(g)	Ní ọdún 1963, Kordofanian kúrò ní èdè Kòtó-ǹ-kan ó di ọ̀gbà 
kan náà pẹ̀lú Niger-Congo. Orúkọ wá yí padà, ó di Niger-Kordofanian (tàbí Congo-Kordofanian). 
	
Greenberg fura sí ipe èdè àwọn èdè wọ̀nyí, ó sì tọ́ka síi wí pé /ףּ/. Kordofanian ati /m/ Niger-Congo jọ ara wọn. Èyí sì máa ń jẹyọ dáadáa nínú àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ Kòsemánìí kan nínú àwọn èdè yìí. 
	Lẹ́yìn Greenberg ni Mukarovsky ṣe àtúpalẹ̀ àti àtúnpín àwọn èdè yìí, Ó yọ Kordofanian, Mande, Wolof-Serer-Fulfulde, Ijoid àti Adamawa kúrò níbẹ̀; àwọn ìyókù ni ó sì pè ní ‘Western Nigritic’. Ayé sí tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí gan-an ni láàrín àwọn olùwádìí ìjìnlẹ̀. 
	Àtúnṣe gbòógì wáyé láti ọwọ Bennett àti Sterk (1977), Wọ́n fi ojú lámèyítọ́ wo àwọn ọ̀rọ̣̀ orúkọ tí ó fara jọ ara wọn nínú àwọn èdè wọ̀nyí. Ìgbàgbọ́ wọn ni wí pé Kordofanian àti Mande ti yà kúrò lara wọn. Lẹ́yìn èyí ni ìwọ̀ oòrùn Àtìláńtíìkì yà kúrò lára ìsọ̀rí èdè yìí tí a sì fún àwọn tí ó kù ní orúkọ ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Ara àwọn wọ̀nyí ni Ila-oòrùn Adamawa, Gur, Kru àti Ijọ wà. Ọ̀kan gbòógì iṣẹ́ lórí ìwádìí yìí ni The Niger-Cong Languages  (Bender – Samuel 1989) jẹ́. 
	Àgbékalẹ̀ ìsọ̀rí èdè Niger-Congo gẹ́gẹ́ bí a ti mọ lónìí ni a ṣe àtẹ rẹ̀ sí ìṣàlẹ̀ yìí (Boyd 1989) nípa lílò àlàyé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 

	Nínú atẹ yìí a rí, ‘Proto-Niger-Congo’ nínú èyí tó jẹ́ wí pé ‘Kordofanian’ ni ìsọ̀rí àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ yapa. Mande àti iwọ oòrùn Atlantic ni ìsọ̀rí kejì tí ó tún yapa bẹ́ẹ̀, èyí tí wọ́n fi hàn wá lábẹ́ ‘Proto-Mande-Atlantic-Congo’. 
	Àwọn èyí tí ó tún dàbí rẹ̀ ni àwọn tí wọ́n pín sí abẹ́ ìsọ̀rí ààrín gbùngbùn Niger-Congo. Láti ara ‘Proto-Ijo-Congo’ ni ‘Ijoid’ ti yapa, lábẹ́ rẹ̀ ni a tí rí Ijọ ati Defaka. 
	Lábẹ́ ‘Proto-Ijọ-Congo’, a rí ‘Proto-Dogon-Congo’ èyí tí Dogon yapa láti ara rẹ̀. 
	Lábẹ́ ‘Proto-Dogon-Congo’, a rí ‘Proto-Volta-Congo’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn Vota-Congo àti ìlà oòrùn Volta Congo (Proto-Benue-Kwa). 
	Ní a pá ìwọ̀ oòrùn Volta-Congo ni a ti wá rí Kru, Pre, Senufo; ààrin gbùngbùn Gur àti Adawawa (Bikirin, Day, Kam ati Ubangi). A lè pè é ní Gur-Adamawa.
	Ní apá ìlà oòrùn, ni a ti rí ààrín gbùngbùn orílè èdè Nìjíríà tí òhun náà tún yapa, a sì rí Bantoid Cross lábẹ́ Ìlà oòrùn yìí. 
	Lára Bantoid Cross yìí ni Cross River ti yapa, nígbà tí a wa rí Bantoid lábẹ́ Bantoid Cross. 

	
Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. 
	Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian. 	
 
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. 
	Heiban  pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang,  Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba;  Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro). 
	Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang,  Nding, Tegem. 
	Rashad:  lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. 
	Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima). 

	
Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissan, Mauretania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2).
	Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́. 
	 
	Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. 
	Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. 
	Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don).
	Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San(South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga. 

ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ
	
Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí: 
Fig 2.4.	
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. 
	Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba. 

	Apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria ni a ti rí àwọn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Èdè náà ni a mọ̀ sí Defaka àti Ijọ. Jenewari àti Williamson (1989) ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ isálẹ̀ yìí 
Fig 2.5. 
	Nínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto-Ijoid’ tí ó pín sí Defaka ati Ijọ. Ijọ pín Ìlà-oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn. 
	Lábé ìlà-oòrùn ni a ti rí: Nkọrọ, Ibani, Kalabari, Kirike (Okrika), Nembe ati Akaha(Akassa). 
	Lábẹ́ ìwọ̀-oòrùn ni a ti rí : Izon, Biseni, Akita (Okordia), Oruma. 

	Àwọn ènìyàn bíi ìdajì mílíọ̀nù tí a bá pàdé ní ilẹ̀ Mali àti Burkina Faso ni wọ́n n sọ èdè yìí. 
	Bendor-Samuel àti àwọn ìyókù (1989) ni ó gbé àtẹ yìí kalẹ̀. 
Fig 2.6.
	Ínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín ṣi ìsọ̀rí mẹfa. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí 
	(a)	Plain 			- 	Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, 
						Tomo ka 
	(b)	Escarpment 		-	Toro sọọ, Tombaco sọọ, Kamba sọọ 
	(d)	West			-	Dulerí dom, Ẹjẹngẹ dó 
	(e)	North west		-	Bangeri Me 
	(ẹ)	North Platean	-	Bondum dom. Dogul dom 
	(f)	Ìsọ̀rí kẹfà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu. 

ARIWA VOLTA-CONGO
	Kru, Gur àti Adamawa-Ubangi ni àwọn ẹ̀ka èdè tí a lè rí ní abẹ́ ìsọ̀rí ‘ARIWA VOLTA-CONGO’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn èdè yìí ti fọ́nká orílẹ̀ 

	Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’. 
Fig 2.7. 
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí 
(a)	Ìlà-oòrùn 	-	 Godie  àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. 
(b)	Ìwọ̀-oòrùn	 -	Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao 
(d)	Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme. 

	Èdè yìí gbajú gbajà dáadáa àti wí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ń sọ èdè yìí ní orílẹ̀ ayé. A lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè náà ní orílẹ̀ èdè bíi Cote d’Ivoire Ghana, Togo, Benin, Burkina Faso àti Nigeria. Ó tó èèyàn bíi mílíọ̀nù márùn-ún ati àbàbọ̀ tí wọ́n ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí Manessy 91978) ti ṣe ìwádìí rẹ̀.
Fig 2.8. 
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto Gur’. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ó pín sí:- Ààrin gbùngbùn Proto; Kulango  àti Loron (Proto-Gur); Viemo, Tyefo, Wara-Natioro, Baatonum, Win (Toussian). 
	Ààrin gbùngbùn Proto: eléyìí tún wà pín sí ìsọ̀rí meji pere: Àríwá àti Gúúsù. 
	Lábẹ́ àríwá, a rí : Kurumfe, Bwamu Buli-Konni, Ìlà-oòrùn Oti-Volta, Iwọ̀-oòrùn Oti Volta, Gurma, Yom-Nawdm. 
	Lábẹ́ gúúsù, a rí: Lobi àti Dyan, Kirma àti Tyurama, Ìwọ̀-oòrùn Gurunsi, ààrin gbùngbùn Guruusì àti Ìlà-oòrùn Guruusi, Dogose àti Gan. 

ADAMAWA-UBANGI 
	Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ.
Fig 2.9. 
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀. 
		(a)	Adamawa 		(b)	Ubangi 
Adamawa  - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. 
Ubangi   	-   Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande. 

SOUTH VOLTA-CONGO
	Bennett ati Sterk (1977) pe ‘South Volta-Congo ni ààrin gbùngbùn àríwí Niger-Congo. Atọ́tọ́nu wáyé nípa yíyapa tí ó wá yé láàrin Kwa àti Benue Congo nítorí pé wọ́n sún mọ́ ara wọn pékípẹ́kí-Greenberg (1963). Pàápàá jùlọ yíyapa láàrin èdè kwa, Gbe àti Benue –Congo: Bennett àti Sterk (1977) àti síse àtúnṣe. 
	Kranse (1895) ni ó ṣe ìfihàn orúkọ ‘Kwa’ fún ayé. Bíi mílíọ̀nù lọ́nà ogún ni Grimes (1996) fi yé wa wí pé ó ń sọ èdè náà. Greenbery (1963a) pín-in sí ìsọ̀rí mẹ́jọ, ó sì so àwọn èdè ààrin gbùngbùn Togo pọ mọ ìsọ̀rí tirẹ̀. Stewart 1994 ni o ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí. 
Fig 2.10.	
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kwa’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́fà ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí: 
	(a)	Ega, Avikan ati Alladian, Ajukru, Abidji, Abbey, Attie 
	(b)	Potou Tano 
	(d)	Ga ati Dangme (Proto-Kwa)
	(e)	Na – Togo 
	(ẹ)	Ka – Togo 
	(f)	Gbe 

	Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí wọ̀nyí ni o tún jẹ́ àtúnpín sí ìsọ̀rí mìíran bí àpẹẹrẹ :- Potou-Tano, Na-Togo, Ka-Togo, Gbe. 
Potou-Tano: èléyìí pín sí Potou àti Tano. 
 Lábẹ Potou ni a ti rí Ebríe àti Mbatto 
	Tano – eléyìí pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin. 
	(a)	Krobu 
	(b)	Ìwọ̀-oòrùn Tano: Abure, Eotilé 
(d)	Ààrin gbùngbùn Tano: Akan, Bia (Nzema-Ahanta) àti (Anyi, Banle, Anufo). 
(e)	Guan – O tun pín si Gúúsù níbi ti a ti rí Efutu –Awutu ati Larten-Cherepong-Anum. Bákan náà ni Àríwá Guang. 
Na-Togo:- Ó pín sí Lelémi – Lefana, Akapatu-Lolobi, Likpe, Santrokofi; Logba (Na Togo); Basila, Adele. 
Ka-Togo ;- Ìsọ̀rí eléyìí pín sí Avatime, Nyangbo-Tafi; Kposo, Ahlo, Bowiri (Ka-Togo); Kebu, Animere. 
Gbe :-  Lábẹ́ èyí ni a ti rí: Ewe ati Gen/Aja, Fon-Phla-Phera

BENUE CONGO
	Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. 
	Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. 
	Àtẹ náà nìyí. 
Fig 2.11.
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì. 

	(a)	Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo 

	(b)	Ìlà oòrùn Benue Congo 

Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). 
Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó. 

(a)	Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid. 

(b)	Ukaan

(d)	Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River. 

	Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. 
	Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.




#Article 117: Kodofanianu (128 words)


	Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. 
	Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian. 	
 
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. 
	Heiban  pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang,  Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba;  Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro). 
	
Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang,  Nding, Tegem. 
	Rashad:  lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. 
	Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima).




#Article 118: Mande (215 words)


Ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ni àwọn ènìyàn tí ó ń sọ èdè yìí Sodo sí jùlọ. Àwọn ìhú tí a sì ti rí àwọn tí èdè wọn pẹ̀ka láti ara orí èdè yìí ni Mali, Cote d’Ivoire, Sierra Leone, Liberia, Burkina Faso, Senegal, Gambia, Guinea Bissau, Mauritania, Banin, Ghana, Togo ati Nigeria (Dwyer 1989; Kastenholz 1991/2).
	Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí méjìlá tí wọ́n ń sọ ọ́. 
	Ẹ yẹ àtẹ ìsọ̀rí yìí wò. 
 
	Nínú àtẹ yìíu a rí ‘Proto-Mande’ tí ó pín sí ìwọ̀ oòrùn àti ìlà oòrùn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. A wá rí ìwọ̀ oòrùn fúnrarẹ̀ tí ó tún wá pín sí ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti Àríwá ìwọ̀ oòrùn. 
	Láti ara ààrín gbùngbùn tàbí Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí: Mandaing ati Koranko, Vai àti Kono, Jogo (Ligbi, Nnmu, Atumfuor, Wela) àti Jeri, Sooso àti Yalunka, Kpelle, Loomu, Bandi, Mande ati Loko. 
	Láti ara àríwá-ìwọ̀ oòrùn ni a ti rí Sorogama àti Tieyaxo, Tiema Cewe, hainyaxo, Soninke (Azer), Bobo (Sya), Dzuun (Samogo-Guan) àti Sembia, Jo (Samogo-Don).
	Ní ìlà Oòrùn a rí : Mano, Dan (Yakuba, Gio) àti Tura (Wen), Guro (Kweni) àti Yanre, Mwa àti Wan (Nwa), Gban àti Beng (Gan). Bákan náà, ni a rí: Bisa, Sane (Samogo-Tongan, Maya) àti San (South Samo, Maka), Busa (Bisa, Boko), Shanga àti Tyenga




#Article 119: Àtìláńtíìkì (107 words)


ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ

	Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi ara hàn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, ní ẹ̀bá òkun Àtìláńtíìkì ni èdè yìí sodo sí jùlo. Ó fọ́nká láti ẹnu odò Senegal títí dé orílẹ̀ èdè Liberia. Díẹ̀ lára àwọn èdè tí ó pẹ̀ka sí abẹ́ orí èdè yìí ni a ti rí: Fulfulde, Wolof, Diola, Serer àti Remne. Sapir (1971) ni ó ṣe àgbékalẹ̀ àtẹ ìsàlẹ̀ yìí: 
	
	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Atlantic’ tí ó pín sí Àríwá àti Gunsu. 
	Ní àríwá ni a ti rí Fulfulde àti Wolof, Serer, Cangin, Diola ati Pupel, Balanta, Bassari/Bedik ati Konyagi, Biafada/Pajade, Kobiana/Kasanga àti Banyin, Nalu, Bijago(Proto-Atlantic), Sua, Temne, Sherbro àti Gola, Limba




#Article 120: Dogon (126 words)


Àwọn ènìyàn bíi ìdajì mílíọ̀nù tí a bá pàdé ní ilẹ̀ Mali àti Burkina Faso ni wọ́n n sọ èdè yìí. Bendor-Samuel àti àwọn ìyókù (1989) ni ó gbé àtẹ yìí kalẹ̀. 
Ínú àtẹ yìí, a rí ‘Proto Dogon’ ti o pín ṣi ìsọ̀rí mẹfa. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí 

(a)	Plain 			- 	Jamsay tegu, Toro teju, Tene ka, 
						Tomo ka 

(b)	Escarpment 		Toro sọọ, Tombaco sọọ, Kamba sọọ 

(d)	West			-	Dulerí dom, Ẹjẹngẹ dó 

(e)	North west		-	Bangeri Me 

(ẹ)	North Platean	-	Bondum dom. Dogul dom 

(f)	Ìsọ̀rí kẹfà ni Yanda dom, Oru yille àti Naya tegu.

Iye àwọn tí ó ń sọ èdè yìí jẹ 100,000. (Ọ̀kẹ́márùn-ún) Orílẹ̀ èdè tí wọn tí ń sọ èdè yìí ni Mali, ati Burkina Faso




#Article 121: Krumen (104 words)


Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’. 
 
Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí 

(a)	Ìlà-oòrùn 	-	 Godie  àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane. 

(b)	Ìwọ̀-oòrùn	 -	Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao 

(d)	Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme.




#Article 122: Adámáwá-Ubangi I (156 words)


Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ.

	Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀. 
		
(a)	Adamawa 		

(b)	Ubangi 

Adamawa  - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali. 

Ubangi   	-   Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande.




#Article 123: Àwọn èdè Bẹ́núé-Kóngò (349 words)


Ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èdè yìí ni: Ìwọ̀-oòrùn àti Ìlà oòrùn Benue-Congo. Àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀ ni ó ní àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí, ó sì sodo sí apá gúúsù ilẹ̀ Nigeria dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìlú bíi Cameroon, Congo, CAR, DRC, Tonzania, Uganda, Kenya, Mozambique, Angola, Rwanda, Burundi, Namibia, Zambia, Malawi, Zimbabwe, Gabon, Lesotho, Samalia àti àwọn èdè yìí kalẹ̀. 
	Gẹ́gẹ́ bí Grimes (1996) ṣe wádìí rẹ̀, èdè Yorùbá àti Igbo ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka èdè tí a pè ní Benue-Congo, ìsọ̀rí ìwọ̀ oòrùn Benue-Congo ni ó sì pín àwọn èdè wọ̀nyí sí. 
	Àtẹ náà nìyí. 
Fig 2.11. Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Benue-Congo’ ti o pín sí ìsọ̀rí meji pàtàkì. 

	(a)	Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo 

	(b)	Ìlà oòrùn Benue Congo 

Ìwọ̀ oòrùn Benue Congo:- Ó pín sí YEAI (Yoruboid, Edoid, Akokoid, Igboid); Akpes; Ayere-Ahan; NOI (Nupoid, Ọkọ, Idomoid). 
Ìlà oòrùn Benue Congo :- Ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta pàtó. 

(a)	Àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Nàìjíráà:- Ó pín sí: Kainji, Àríwá-Ìwọ̀ Plateane, Beromic, Àárín gbùngbùn Plateane, Ìlà-oòrùn Gúúsù Plateane, Tarok, Jukunoid. 

(b)	Ukaan

(d)	Bantoid-Cross:- Lábẹ́ èyí ni Bantoid ti yapa. Nígbà tí a sì rí Cross River ní abẹ́ Bantoid-Cross. Láti ara Cross River ni Bandi ti wá yapa. Nígbà tí a wá rí Delta-Cross lábẹ́ Cross River. 
	Ní ìparí, ó fihàn gbangba wí pé èdè Niger-Congo tóbi tààrà àti wí pé orílẹ̀ èdè Áfíríkà ni ó pẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èdè yìí ni ó gbalẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n a rí lára wọn tí ìgbà ti fẹ́rẹ̀ tan lórí wọn. Àwọn wọ̀nyí ni èdè mìíràn ti fẹ́ máa gba saa mọ lọwọ Àwọn ìdí bíi, òṣèlú, ogun, òlàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sì ṣe okùnfà èyí. Ní pàtàkì jùlọ, gbogbo èdè yìí náà kọ́ ni àwọn Lámèyítọ́ èdè fi ohùn ṣe ọ̀kan lé lórí lábẹ́ ìsòrí tí wọ́n wa ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ‘ẹbí’ rẹ fi ojú hàn gbangba. 
	Ní ìparí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí rẹ̀ ṣùgbọ́n ààyè sì tún sí sílẹ̀ fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ túlẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwádìí àti lámèyítọ́ lórí ẹ̀kà èdè Niger-Congo.




#Article 124: Murtala Muhammad (747 words)


Murtala Ramat Mohammed (ojo ibi November 8, 1938ndash;February 13, 1976)
je olori ijoba Nigeria gege bi ologun lati odun 1975 si 1976. Igba ti awon ologun egbe re fe gba ijoba ni won pa. Ogagun Obasanjo ti o je igbakeji re ni o bo si ori oye gege olori ijoba lati 1976 si 1979. 

A bí ògágun Murtala Ramat Muhammed ni ojó kéjo, osù kejì odún 1938 (8/2/1938). Olórí ológun ní ó jé. Ó di alákòso ológun orílè èdè Nàígíríà ní 1975 títí di odún Feb 13, 1976 Murtala Mohammed jé elésìn Mùsùlùmí, Hausa ni pèlú láti (òkè oya apá gúúsù. Ó kékò ológun ní British Academy, Sandhurst.

Murtala kò faramó ìjoba ológun Johnson Aguiyi Ironsi tí ó fipá gbà joba ni osù kìíní odún 1966 nínú èyí tí wón pa òpòlopò olórí Nàíjíríà tó jé omo apá gúúsù lónà tó burú jáì! Fún ìdí èyí ó kópà nínú ìfipá - gbà ijòba tó wáyé ni July 21, 1966. Wón fipá gba papakò òfurufú ìkejà; èyí tí wón ti yí orúko rè sí Murtala Mohammed International Airport làti fi yé. Ó kókó fé fi ìfipá gbà ijoba yìí gégé bíi igbésè fún àwon ara gúúsù láti ya kúrò lára Nàíjíríà sùgbón ó da àbá yìí nù nígbèyìn.

Ìfipá gbajoba yìí ló mú ògagún (lieutenant-colonel) Yakubu Gowon jé alákòso orílè èdè Nàígíríà. Ní July/29/1975 àwon ologun tó jé òdò
fi ògágun Murtala je alákoso orílè èdè yìí láti jé kí Nàígíríà padà sí ìjoba alágbádá Democracy. Omo odún méjìdínlógójì ni Murtala Ramat Muhammed nígbà tí àwon ológun fi je alákoso rópò Gowon. Murtala kó pa pàtàkì nínú ogun abélé. Ó jé òkan nínú adarí omo ogun Nàígíríà nígbà tí ogun náà dójú iná tán po. Òun ló fà á tí ikojá òdò oya (River Niger) àwon omo ogun Biyafira Biafra se já sí pàbó. Murtala ò lówó sí bí ìfipá-gbà-joba tó mu gorí oyè.

Lógán tí Murtala gbàjòba, ara ohun tó kókó se ni; ó pa ètò ìkani Census ti odún 1973 re, eléyìí tó jé pé ó fì jù sí òdò àwon gúúsù nípa ti ànfàní. Ó padà sí ti odún 1963 fún lílò nínú isé.

Murtala Mohammed yo òpòlopò àwon ògá ise ijoba tí ó ti wà níbè láti ìgbà ìjoba Gowon. Ó tún mú kí àwon ará ìlú ni ìgbèkèlé nínú ìjòba alápapò. Ó lé ni egbàárùn (10,000) òsísé ìjoba tí Murtala yo lénu isé nítorí àìsòótó lénu isé, àbètélè, jegúdú-jerá, síse ohun ìní ìjoba básubàsu, àìlèsisé-lónà-tó ye tàbí ojó orí láìfún won ní nkankan. Fífòmó Murtala kan gbogbo isé ìjoba pátápátá, bí àwon olópàá, amòfin, ìgbìmò tó n mójútó ètò ìléra, ológun, àti Unifásitì. Àwon olórí isé ìjòba kan ni wón tún fi èsùn jegúdú jerá kàn, tí wón sì báwon dé ilé ejó. Murtala tún fó egbàárùn owo-ogun sí wéwé. Ó fún àwon alágbádá ni méjìlá nínú ipò méèdógbòn ti amojútó ìgbìmò isé ìjoba. Ìjoba àpapò gba àkóso ilé isé ìròyìn méjì tí ó tóbi jù lo lórílè èdé yìí. Ó jé kí gbígbé ìròyìn jade wa làbé ìjoba àpapò nìkan. Murtala mú gbogbo Yunifasiti tó wà lábé ìjoba ìpínlè sí abé àkoso ìjoba àpapò.

Mélòó lafé kà nínú eyín adépèlé ni òrò àwon ohun ribi-ribi tí Murtala gbése nígbà ti re. Ara won tún ni dídá ìpínlè méje mó méjìlá tó wà tèlé láti di mókàndínlógún. Murtala se àtúnyèwò ètò ìdàgbàsókè elekéta orílè èdè. Ó rí ìgbówólórí (inflation) gégé bí ìdàmú nlá tó n se jàmbá fún òrò ajé e wa. Fún ìdí èyí, ó pinnu láti dín owó tó wà lode pàápàá èyí tí wón n ná le isé ìjoba lórí ku. Ó tún gba àwon onísé àdáni níyànjú láti máa sesé tí àwon òsìsé gbogbo-o-gbo ti je gàba lé lórí. Murtala tún se àtúnyèwò òye ise ìtójú ìlú tó ní se pèlú ìlú mìíràn tí àwon egbé ìlú tí ó n sèdá epo ròbì lágbàáyé (OPEC). Ó jé kí Nàíjíríà je ohun kìíní tí ó kà sí nípa ti ànfàní àti iye tí wón dálé epo ròbì.

Láìrò télè, ògágun Murtala dèrò òrun ni ojó ketàlá osù kejì, odún 1976. Wón da lónà nínú mótò rè, nígbà tí òun ti mósálásí bò nínú ìfipá-gbà-joba tí ó jé ìjákulè nígbèyìn. Owó te àwon òlòtè tó pa á, sùgbón kì lé tó pa òsìkà ohun rere á tí bà jé. Murtala Ramat Mohammed ti fayé sílè. Èpa kò bóró mó. Ká tó rérin ó digbó, ká tó rèfon ó dò dàn, ká tó réye bí òkín Murtala Ramat Mohammed ìyén di gbére.




#Article 125: Muhammadu Buhari (367 words)


Muhammadu Buhari (tí wọ́n ní Ọjọ́ ketàdínlógún, Oṣù Kejìlá Odún 1942) jẹ́ Aàrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sípò láti odún 2015. Òun náà ló tún wọlé lẹ́ẹ̀kejì gẹ́gẹ́bí Ààrẹ nínú ìdìbò Ààrẹ tí wọ́n dì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2019.   
Buhari tí fìgbà kan jẹ́ ogágun Méjọ̀ Gẹ́nẹ́rà tí ó ti fèyìntì àti pé ó j̣e olórí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lati 31 Oṣù kejìlá odún 1983 sí Oṣù kẹjó odún 1985, léyìn tí ó fi ọ̀nà èbùrú kúùpù ológun gbàjọre.

Muhammadu Buhari ni a bi si idile Fulani ni ọjọ 17 Kejìlá 1942, ni Daura, Katsina Ipinle, si baba rẹ Hardo Adamu, olori Fulani, ati iya Zulaihat. Oun ni ọmọkunrin mẹtalelogun ti baba rẹ. Buhari a ti dide nipa iya rẹ, lẹhin ti baba rẹ kú, nigbati o wà nipa mẹrin ọdun atijọ.

Ni Oṣu Keje 1966, Lieutenant Muhammadu Buhari jẹ ọkan ninu awọn olukopa ninu July Rematch tabi ti a npe ni Counter-Coup, ti Lt-Col Murtala Muhammed ti ṣaju, ti o kọlu ati pe o ti pa Olukọni akọkọ ti Nigeria ti a ti yàn ni Oludari Ipinle Gbogbogbo Aguiyi Ironsi , ti o ti di alakoso ijọba Naijiria lẹhin igbiyanju igbiyanju kan ti o ti kuna ni 15 January 1966, eyiti o bori ijoba ile-igbimọ asofin ti Naijiria (ti a tun mọ ni ilu-ipilẹ akọkọ). Awọn alabaṣepọ miiran ni igbimọ ni ọjọ 28 Keje 1966 pẹlu 2nd Lieutenant Sani Abacha, Lieutenant Ibrahim Babangida, Major Theophilus Danjuma, Lieutenant Ibrahim Bako laarin awọn miran. Igbese naa jẹ ifarahan si ipo Kínní, nibi ti ẹgbẹ ti ọpọlọpọ awọn oludari Igbo ti Major Major Chukwuma Kaduna Nzeogwu ti kọlu ijọba ti o ti dibo ti ijọba-ara ti Prime Minister Abubakar Tafawa Balewa. Ọpọlọpọ awọn ọmọ-ogun ti Iha ariwa ni ibanujẹ nipasẹ iku ti awọn oselu pataki, Alakoso Minisita Abubakar Tafawa Balewa, aṣalẹ ti agbegbe ariwa, Ahmadu Bello, ati awọn olori agba mẹrin lati Ariwa Nigeria: Brigadier Zakariya Maimalari, Colonel Kur Mohammed, Lt-Cols Abogo Largema ati James Pam. Idaniloju agbọnju naa jẹ igbẹkẹle ẹjẹ ti o yori si iku ọpọlọpọ awọn olori alakoso Igbo. Lara awọn ti o farapa ni akọkọ ologun ti ipinle General Aguiyi Ironsi ati Lt Colonel Adekunle Fajuyi, gomina ologun ti Western Region.




#Article 126: Èdè (714 words)


Oríṣìíríṣìí àwọn Onímọ̀ ní ó ti gbìnyànjú láti fún èdè ní oríkì tàbí òmíràn ṣùgbọ́n kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì wònyìí, èmi pàápàá yóò gbìnyìnjú láti sọ lérèfé ohun tí èdè túmọ̀ sí. 
	Èdè ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń lò ní àwùjọ báyá fún ìpolówó ọjà, ìbáraẹni sọ̀rọ̀ ojoojúmó, ètò ìdílé tàbí mọ̀lẹ́bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 
	Ní báyìí mo fẹ́ ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn onímọ̀ ti fún èdè. Gẹ́gẹ́ bí fatunsi (2001) ṣe sọ, 
	“Language Primarily as a System of Sounds exploited for the purpose of Communication bya group of humans.”
	Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ó ní èdè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìrú kan gbòógì tí àwùjọ àwọn ènìyàn ń lò láti fi bá ara ẹni sọ̀rọ̀. 
	Raji (1993:2) pàápàá ṣe àgbékalẹ̀ oríkì èdè ó ṣàlàyé wípé; 

Wardlaugh sọ nínú Ogusiji et al (2001:10) wí pé, 
	“Language is a System of arbitrary Vocal Symbols use for human Communication.”

Àwọn Oríkì yìí àti ọ̀pọ̀lọpọ oríkì mìíràn ni àwọn Onímọ̀ ti gbìyànju láti fún èdè, kí a tó lè pe nǹkan ní èdè, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn èròja wọ̀nyí: èdè gbọ́dọ̀ jẹ́: 

	Síwájú sí í, a ní àwọn àbùdá ti èdè ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ 

(1)	Ìdóhùa yàtọ̀ sí ìtumọ̀ (Ar’bitransess) 

(2)	Àtagbà Àṣà (Cultural transmission) 

(3)	Agbára Ìbísí (Productivity) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo. Gbogbo Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn yàtọ̀ láàrín èdè ènìyàn àti ti ẹranko kì í ṣe ohun tí ó rorùn rárá. 
	Nǹkan àkọ́kọ́ nip é a gbọ́dọ̀ wá oríkì èdè tó ń ṣiṣé lórí èyí tí a ó gbé ìpìnlè àfiwé wa lè. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí oríkì tí ó dàbí ẹni pé ó ṣàlàyé oríkì èdè tàbí tí ó jẹ́ ìtéwógbà fún gbogbo ènìyàn. Charles hocket ṣe àlàyé nínú Nick Cipollone eds 1994 wípé: 
	Ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè borí ìṣòro yìí nip é, kí a gbìnyànjú láti ṣe ìdámọ̀ ìtúpalẹ̀ àwọn àbùdá èdè ju kí a máa gbìnyànjú láti fún ẹ̀dá rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì ní oríkì. 
	Torí náà, a lè pinu bóyá èdè ẹranko pàápàá ni àwọn abida yìí pẹ̀lú… Ohun tí a mọ̀ nípa èdè ẹranko ni pé, kò só èdè ẹranko kọ̀ọ̀kan tí ó ní àwọn àbùdá èdè ènìyàn tí a ti sọ síwájú. Èyí ni ó mú kí á fẹnukò wípé àwọn èdà tí kìí ṣe àwọn ènìyàn kì í lo èdè. Dípò èdè, wọn a máa bá ara wịn sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ń pè ní ẹ̀nà, 
àpẹẹrẹ ìfiyèsí (Signal Cocle).
	Gbogbo ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn yàtọ̀ sí èyí kì í ṣe èdè. Àwọn ọ̀nà náà ní: 

(1)	Ìfé sísú 

(2)	Ojú ṣíṣẹ́

(3)	Èjìká sísọ 

(4)	Igbe ọmọdé

(5)	Imú yínyín 

(6)	Kíkùn ẹlẹ́dẹ̀ 

(7)	Bíbú ti kìnnìún bú 

(8)	Gbígbó tí ájá ń gbó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

	Gbogbo ariwo ti a kà sílẹ̀ wọ̀nyí kì í ṣe èdè nítorí pé; 

(1)	Wọ́n kò ṣe é fọ́ sí wẹ́wẹ́ 

(2)	Wọn kì í yí padà 

(3)	Wọn kì í sì í ní Ìtumọ̀ 

	Pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti sọ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàrín èdè ènìyàn àti ẹranko, Ó hàn gbangba wípé a kò le è fi èdè ẹranko àti ti ènìyàn wé ara wọn. 
	Yorùbá bì wọ́n ní “igi ímú jìnà sí ojú, bẹ́ẹ̀ a kò leè fi ikú wé oorun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èdè ènìyàn àti ẹranko rí. Nínú èdè ènìyàn lati rí gbólóhùn tí ènìyàn so jáde tí a sì leè fi ìmò ẹ̀dá èdè fó sí wéwé. Àtiwípé àǹfàní káfi èdè lu èdè kò sí ní àwùjọ ẹranko gẹ́gẹ́ bí i ti ènìyàn. Fún bí àpẹẹrẹ. 
Olu ra ìṣu 
Olú nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò Olùwá, rà jẹ́ Ọ̀rọ̀-ìṣe nígbà tí ísu jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ ní ipò ààbọ̀. 
	A kò le rí àpẹẹrẹ yìí nínú gbígbó ajá, kike ẹyẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. 
	Nítorí náà èdè ènìyàn yàtọ̀ sí enà apẹẹrẹ, ìfiyèsí (Siganl Code) àwọn ẹranko. 

	Àwọn ìwé ìtọ́ka sí ni àwọn wọ̀nyìí. 

Fatusin, S.A (2001), An Introduction to the Phonetics and Phonology of English. Green-Field Publishers, Lagos. 

Rájí, S.M (1993), Ìtúpalẹ̀ èdè àṣà lítíréṣọ̀ Yorùbá. Fountan Publications, Ibadan. 

Ogunsiji, A and Akinpẹlu O (2001), Reading in English Languag and Communication Skills. Immaculate-City Publishers, Oyo. 

Nic Cipollone eds (1998), Language files Ohio State University Press, Columbus.




#Article 127: Ìtàn àkọọ́lẹ̀ Yorùbá (487 words)


THOMAS PETER TAIWO  ṣẹ

Ìtàn bi ede Yorùbá ṣe di kíko sí lè (Yorùbá Orthography)
Láti ayébáyé, èdè Yorùbá wa lábé ìpínsí sòrí tí ọ̀gbẹ́nì thamstrong (1964) se fún àwọn èdè gbogbo èdè Yorùbá bọ́ sí abẹ́ ìpín èdè “KWA”. Èyí sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé èdè olóhùn (tonalanguage) ni Yorùbá jẹ́. 
Gẹ́gẹ́ bí a se mọ̀ pé tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ rí, a kì í kọ èdè Yorùbá sí lẹ̀, sí sọ nìkan ni a ń sọ ọ́ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun dé tí òwò ẹrú si bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹ wọ́n bèrè sí ní í kó àwọn ọmọ bíbí ilẹ́ Yorùbá lẹ́rú lọ sí òkè-òkun. Èyí tẹ̀síwájú fún ìgbà pípẹ́ kán-fin-kése títí di àsìkò tí ìjọba àpapọ̀ àgbáyé gbìmọ̀ pọ̀ ti òpin sí òwò ẹrú yìí. 
Fún ìdí eléyìí, ó di òranyàn kí á dá àwọn ẹrú wònyí  padà sí ibi tí wọ́n ti sẹ̀ wá. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹní tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá padà sí ilẹ̀ wọn. ṣùgbọ́n ní ọwọ́ àsìkò ti wọ́n fi wà ní oko ẹrú yíì ni wọ́n ti ń se ẹ̀sìn jíjẹ́-ọmọ-lẹ́yìn-kírísítì (chiristanity) Àwọn òyìnbó amúnsìn yìí sí rí i ní ọ̀ranyàn pẹ̀lú láti se agbára lórí i bí ẹ̀sìn yí yóò se máa tẹ̀síwájú láàrin wọn. 
Ẹ̀yí  gan-an ló mú kí wọn se akitiyan lórí bí wọn yóò se se àyípaà ìwé-mímọ́ nì –Bíbélì sí èdè Yorùbá. Nínú sí se eléyìí ó se pàtàkì láti rí i dájú pé ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá tó sì jẹ́ gbédè-gbijọ̀ èdè náà wà ní bẹ̀ àti kí ó sì kó ipa takuntakun nínú sí se àyẹ̀wò, àfikún, àyokúrò àti afótónu tó yaarantí ló rí iṣẹ́ náà. 
Àwọn ènìyàn bíi Humnah Kilham (1891) John Rahar, Gollmer and Bowdich (1817) àti Àjàyí Growther (1815) ló bẹ̀rẹ̀ isẹ́ lórí kí kó lẹ́tà àti àwọn òǹkà jọ.
Okùnrin kan tí ń jẹ́ Bowdich ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ si ṣẹ́ lórí i àwọn òǹkà Yorùbá bí i, óókan, ééjì, ẹ́ẹ́ta títío do ri i ẹ́ẹ́wà-á ó sì se àwọn isẹ́ yìí í ní odún (1817). 
Hamah Kilhar ní (1828) náà sísẹ́ lórí kíkọ sí lẹ̀ èdè tí à ń mẹ́nu bà yìí. Ó fún wa ní ìlànà méjì tí ó se pàtàkì jù nínú isẹ́ rẹ̀. 

Lẹ́yìn Crowther, a ò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn yeekan-yeekan bi, Henny Venn (ijo CMS), Àlùfáà Charle Andrew Gollmer (German), Alufa Heny. Townsend, Samuel Johnson abbl. Tí wọ́n se akanse iṣẹ takun-takun lórí bí èdè Yorùbá se di kí ko sèle. 
Akiyesi pàtàkì kan ti a lee se nínú gbogbo atotonu lórí bi èdè Yorùbá se di kiko silẹ yin i pe nínú gbogbo àwọn to siṣe yi ti wọn jẹ àwọn oyinbo atohun rinwa alawọ dúdú kan ni a timenu ba, ṣùgbọ́n èyí ko fi bẹ́ẹ ri bẹ. 
Àwọn dúdú ti wọn ko pa nínú iṣe yìí naa po jojo ṣùgbọ́n fún ìdí kan tàbí òmíràn ti a ko ni lee sòro nípa wọn. 




#Article 128: Àyàn (303 words)


Ayan (Drummer)

Iṣẹ́ Àyàn

Iṣẹ́ ìlù lílú ni a n pe ni ìṣẹ́  àyàn, àwọn ti o n sẹ iṣẹ yii ni a n pe ni “Aláyàn tàbí ‘Àyàn’. Iṣe àtìrandíran ni èyi, nitori iṣẹ afilọmọlọwọ ni. Gbogbo ọmọ ti Onílù bá bí sí ìdi Àyàn Agalú ni o ni láti kọ ìlù lílù, paapaa akọbi onílù. Dandan ni ki àkọ́bí onílù kọ iṣẹ ìlù, ko si maa ṣe e nitori àwọn onìlu ko fẹ ki iṣẹ́ náà parun. 

Yàtọ̀ si àwọn ti a bì ni ìdile onìlu tabi awọn o ọmọde ti a mu wọ agbo ifa, Ọbàtálá, Eégún tàbí Ṣàngó ti wọn si n ti pa bẹ́ẹ̀ mọ oriṣiiriṣii ìlù wọn a maa n rì awọn to ti ìdílé miíran wa láti kọ ìlù lìlú lọwọ awọn onìlu. Àwọn Yorùbá bọ wọn ni “àtọmọde dé ibi orò ń wò fínní-fínní, àtàgbà dé ibi orò ń wò ranran” Òwe yìi tọka si i pe ko si ohun ti a fi ọmọdé kọ ti a si dàgbà sínú rẹ̀ ti a ko ni le se dáadáa.

Láti kékeré làwọn Yorùbá ti n kọ orìṣiiriṣi ìlù lìlú. Nígba ti ọmọde ba ti to ọmọ ọdún mẹ́wàá sí méjìlá ni yóò ti máa bá baba rẹ ti o jẹ onílù lọ òde aré. Láti kékeré yìí wá ni yóò ti máa foju àti ọkàn si bi a ti n lu ìlù. Àwọn ọmọdékùnrin tí ń bẹ nínú agbo àwọn tí ń bọ̀ Ọbàtálá yóò máa fojú síi bi a ti ń lu ìgbìn, àwọn tí n bẹ lágbo àwọn onífá yóò máa kọ bi a ti ńlu Ìpèsè. Ọ̀nà kan náà yii làwọn tí ń bẹ lágbo àwọn Eléégún àti onísàngó ń gbà kọ́ bi a ti ńlu Bàtá. 
Àwọn ọmọdé mìíran máa ń gbé tó ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lẹ́nu iṣẹ́ ìlù kíkọ́ yìí.




#Article 129: Ìpèsè (184 words)


Ipese Drum

ÌPÈSÈ:- 

Ìlù tí àwọn babaláwo ńlù lọjọ ọdún ifá ni Ìpèsè. Awọn mìíran npe e ni Ìpẹ̀sì. Yatọ̀ si ọjọ ọdun ifa, a tun nlù Ipese lọjọ̀ ti a ba n ṣe isinku tabi ijade oku ọkan nínú àwọn asaaju nibi Ifa. Mẹrin ni ọ̀wọ́ ìlù ti a papọ se Ìpèsè:- 

(a)	Ìpèsè:- Ìlù yi funra rẹ lo tóbi jù nínú mẹ́rèẹ̣́rin. Igi la fi n gbẹ ẹ. Ó sì gbà tó ẹsẹ bata ti a fi bo o loju mọ ara igi ti a gbẹ ti a si da ìho sinu rẹ. 

(b)	Àféré:- Ìlù yìí lo tobi tẹle Ipese. Igi la fi n gbẹ àféré, ṣùgbọ́n o lẹgbẹ ti o fẹ jù ipese ko ga to ipese, ẹsẹ mẹta ni o fi dúró nilẹ. 

(d)	Àràn: Ìlù yìí kò tobi to Aféré, bẹẹ ni ko ga to o. Òun náà ni ẹsẹ̀ mẹ́ta to fi dúró 

(e)	Agogo:-   Ohun kẹ́rin ti a n lù si Ìpese ni agogo. Irin la fi ńrọ agogo. Abala ìrìn meji ti a papọ, ṣùgbọ́n ti a da ẹnu rẹ si lapa kan ni agogo.




#Article 130: Àgèrè (117 words)


Agere Drum

ÀGẸ̀RẸ̀:- 

A nlù agẹrẹ lọjọ ọdun awọn ọdẹ. Idi niyi ti a fi n pe Agẹrẹ ni ìlù ogun. Bi ọlọ́ọ́dẹ tàbí olórí ọdẹ kan bá ku ni a n lù agẹrẹ. Ọ̀wọ́ ìlù mẹta la papọ̀ se àgẹ̀rẹ̀ ògún. 

(a)	Àgẹ̀rẹ̀:- Eyí ni ìlù to tobi ju pátápátá. Igi la fi ngbẹ agẹrẹ. Oju meji Ọgbọọgba lo sì nì. Ìlù yi dabi ìbẹ̀mbẹ́. Awọ la fin bòó lójú ọ̀nà méjèèjì, okun la si nfi wa awọ ojú rẹ lọ́nà méjèèjì ki o le dún. 

(b)	Fééré:- Ìlù yii kere jù agẹrẹ lọ. Igi naa la fi gbẹ ẹ, ṣùgbọ́n ko fẹ to agẹrẹ. 

(d)	Aféré: Ìlù yii lo kere jù awọn meji ìsáájú lọ.




#Article 131: Gbẹ̀du (171 words)


Pàtàkì ni Gbẹ̀du jẹ̀ nínú àwọn ìlù ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìlù yii kan naa lawọn kan n pen i àgbà. Ìyàńgèdè ni ìlẹ̀ Yorùbá. 
Ìlù mẹta la le tọkasi nínú ọwọ ìlù Gbẹ̀du. 

(a)	Aféré:- Ìlù nla ni afẹrẹ. Ó ga tó iwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin ó sì gùn gbọọgì. Géńdé ti ko ba dara rẹ loju ko le gbe nìlẹ. Oùn rẹ̀ máa n rìnlẹ dòdò. Ìkeke ni a fi maa nlù. 

(b)	Apéré tabi Opéré: Ìlù yii lo tobi tẹle afẹrẹ labẹ ọmọ ìlù ti a n pe ni Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ, ṣùgbọ́n ko ga, ko si fẹ lẹnu to aféré. 

(d)	Ọbadan: Ìlù yii lo kere ju nínú ọ̀wọ́ ìlù Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ bi ti awọn yooku. Ko sit obi to apẹẹrẹ rara. 

Gbẹdu se patakì pupọ nitori pe o jẹ ìlù ọba. A kii dede n lu u. Ìlù yi wa fun ìyẹ̀sì awọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá. Bi ọba ba gbesẹ tabi ijoye nla kan tẹri gbaso wọn n lù Gbẹdu lati fi tufọ.




#Article 132: Ìgbìn (131 words)


Ìlù Ìgbìn
Ìlù oriṣà Ọbàtálá ni ìlù yii ọjọ̀ àjọ̀dún Ọbàtálá ni àwọn olóòṣà yìí ńkó ijó Ìgbìn sóde. 
Oriṣii ìlù mẹ́rin la le tọ́ka sí lábẹ́ ọ̀wọ́ ìgbìn. 

(a)	Ìyá-nlá: Igi la fi n gbẹ́ ìlù yìí. Ihò ìnu ìgi naa si dọ́gba jálẹ̀. Awọ lafi ńbo oju ìgi ìlù yi lójù kan.

(b)	Ìyá-gan:  Ìlù yii lo tẹle iya-nla. Òun ló sì dàbí omele tàbí emele ìyá-ńlá, 

(d)	Keke: 	Ìlù yìi lo tẹle Iya-gan. Ó kó ìpa pàtàkì nínú ìgbin. 

(e)	Aféré: Ìlù yii lo kere jù nínú awọ ìlù mẹrẹẹrin ti a le tọka si nínú ọwọ ìlù igbin. Igi náà ni a fi n gbẹ ẹ bi i ti awọn mẹta yooku. Awọn ti n gbẹ ìlù yii máa n sojú àti ìmú sára ìgi ìlù yii.




#Article 133: Àpíntí (123 words)


Apinti (Drum)

Àpíntí:

Ọkan nínú àwọn ìlù ti a nlu nibi aseyẹ ni apinti. Ẹya ìlù mẹta la papọ ti a n pen i àpíntí. 

(a)	Iya-ìlù:  Igi ti a gbẹ ti a si da iho sìnu rẹ la fi nṣe ìya-ìlù. Oju kan ṣoṣo lo ni. Oju kan ṣoṣo yi la n fi awọ bo. Iho ìnu ìgi yi jade si isalẹ rẹ, ko si ni awọ. Iya-ìlù yi ni okun tẹẹrẹ ti a so mọ ara rẹ. Okun náà la fi ngbe e kọpa. 

(b)	Omele tabi Emele: Igi ni a fi n gbe oun náà, ṣùgbọ́n o kere pupọ̀ ju iya-ìlù lọ. 

(d)	Agogo:  Irìn la fi nṣe agogo ti a n lu si apinti. Awọn alagbẹdẹ lo n see.




#Article 134: Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ (199 words)


Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun èlò amúlùúdùn ní ilẹ̀ Yorùbá. Jákè jádò ìlẹ Yorùbá la ti ń lù sẹ̀kẹ̀rẹ̀, pàá pàá jùlọ  níbí àṣeyẹ oríṣiríṣi.

Orísirísi ònà ni àwon ìlú kankam n pe sèkèrè ìlú Cuba n peé ní chekere wón sì tún pèé ní aggué(abwe). Bákan náà Brazil n pèé níxequerê.

Kósó: Kósó ni ìlù tí a fi igi ṣe. Awọ la fi ń bo orí igi tí a gbẹ́ náà. O gùn gbọọrọ tó ìwọ̀n ẹṣẹ̀ bàtà méjì àbọ̀. Ó sì tóbi lórí níbí tí a fi awọ bò ju ìsàlẹ̀ lọ, ó ní ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ tí a lè fi gbé e kọ́ apá.  

Bẹ́mbẹ́: jẹ́ ìlù tí a fi awọ bo lójú méjèèjì, tí wọ́n sì tún fi awọ tẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí Òkun ṣòkòtò  kọ lójú kí ohùn rẹ̀ ó lè dun yàtọ̀ létí. Awọ tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn ṣòkótò yí náà ni wọ́n fi ma ń fà tí wọ́n sì ń fọwọ́ kan ojú ìlù náà kí olè mú Ohun tí onílù náà bá fẹ́ jáde lásìkò tí ó bá ń lùú.  

Aro:  Ìlù kẹrin tí a ń lù sí sẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ ni aro. Irin la fi ń ṣe aro, àwọn alágbẹ̀dẹ ló sì ń ṣe é.




#Article 135: Àpíìrì (156 words)


Àpíìrì tàbí sẹkẹrẹ:

Aré yi wọ́pọ̀ lágbègbẹ̀ Èkìtì. Ó yàtọ̀ sí ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti a kọ́kọ̣́ sàlàyé rẹ̀ nítorí pé a kìí lu aro, koso, àti bẹ̀mbẹ́ síi. Kìkì ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ là ń lù nìbi ti a ba nsere apíìri. Orìṣii ṣẹ̀kẹ̣̀rẹ̀ mẹ́ta là ń lù si apiiri. 

(a)	Ìya-àjẹ́:  Àgbe to tobi díẹ̀ la fi  n ṣe Iya-aje. E so igi kan bayi la n ṣe sara owu ti a ran. Bi a ba ti seetan, a o fi owu ti a se eso si yi kọ ara agbe náà lọwọọwọ titi de ọrun rẹ̀. Eso ara agbe yi ni n dun lara rẹ nìgba ti a ba n luu. 

(b)	Emele-ajè:  Emele-aje meji la n lu si apiiri. Agbe la fi n ṣe e bi ti iya-aje. Agbe ti a fi n se emele-aje ko tobi to eyi ti a fi n se iya-aje. Ìdi niyi ti didun wọn ko fi fẹ dodo bi ti Ìya-aje.




#Article 136: Bobo Madare (106 words)


Bobo Madare

BOBO MADARE
	
Èdè yìí jẹ mọ́ èyí tí wọ́n máa ń sọ ní ìwọ̀ oòrùn Africa. Orúkọ mìíràn tí a tún mọ èdè yìí sí ní: Balck bobo, Bobo Bobo Bobo fing. Àwọn èdè Adugbo wọn ni Benge Bobo, Dioula Bobo, Jula Sogokire Sya Syabere voré Zara. 
	
Ile Burkina. Faso ni wọ́n ti ń sọ ọ́. Nígbà tí wọn sijẹ̣ ẹ̀yẹ̀ ti Niger-Congo pẹ̀lú àwọn ẹya Bobo. 
	
Àwọn àmì ẹ̀ka wọn ni N.C. B B A B A. A tun rí èdè Bobo mìíràn tó jẹ mo ti Gusu ní: Burkina Faso, Mali. Wọ́n sì tì ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí titi di òní.




#Article 137: Èdè Kóngò (172 words)


Kikongo tabi ede Kongo je ede Bantu ti awon eya Bakongo ati Bandundu n so. 

Èdè tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ ni Kitumba, òun ta ń pè ní Kongó ní n ǹkan ṣe pẹ̀lú àpapọ̀ àwọn èdè Bantu. Àwọn ibi tí ati n sọ èdè yìí ni: Angola, Congo, Crabon ati Zoure. 
	
Ní àarin odún (1960) sí Ọdún (1996) àwọn tí ó n sọ èdè yìí dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù mọ́kànlá. Àkọtọ́ èdè wọn muná dóko; ṣùgbọ́n wọn kìí lo àmì ohùn lórí gbogbo ọ̀rọ̀ wọn. Àkọtọ wọn tó wuyì yìí lo mú kí ohun èdè wọn dín kù ní lílò.

Èdè Kongo

Kongo tàbí Kikongo – ó jẹ́ èdè Bantu, àwọn ènìyàn Bakongo ni wọn ń sọ ọ́. Ààrin ilẹ̀ Afíríkà ni ó wà. Àwọn tí wọ́n ń sọ ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù méje ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n kó ní ẹrú ní ilẹ̀ Afíríkà tí wọ́n sì tà wọ́n fún America ni wọ́n ń sọ èdè yìí. Àwọn bí i mílíọ̀nù ni wọ́n ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè méjì.




#Article 138: Sínńtààsì Èdè Aafíríka (1299 words)


AKANDE TITILAYO C.

Sintaasi ede Aafirika

SYNTAX- JOHN R. WATTERS.

John R. Watters túmọ̀ sínńtààsì sí bí ìró àti ọ̀rọ̀ se ń so papọ̀ di gbólóhùn, àti bí àwọn ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan se hun ara wọn papọ̀ ní ìpele, ìpele di gbólóhùn.
	
Gbogbo èdè ni wọ́n ní ju ọ̀nà kan lọ ti wọn ń gba hun ọ̀rọ̀ wọn. tí a bá ń kọ nípa èdè kan, àfojúsùn wa ni láti se àfìwé ìdí tí ìhun wọn fi pé orísìírísìí. Ní ilẹ̀ Afirika, ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èdè ni wọn ń lo Olùwà, àbò àti ọ̀rọ̀ ìṣe. 
	
A tún máa ń lo “less common word orders” nínú gbogbo èdè,  láti sèdá gbólóhùn àyísódì. 

(SENTENCES WITH SINGLE CLAUSES) GBÓLÓHÙN ALÁWẸ̀ KAN.
	
Ètò ọ̀rọ̀ (Word categories) Àwọn ọ̀rọ̀ tí a máa ń tò pọ̀ di gbólóhùn ni OR, IS, Apọnle, Eyan àti Atókùn. Iwájú ọ̀rọ̀ orúkọ ni atọ́kùn máa ń wà Post Position máa ń wa lẹ́yìn ọ̀rọ̀ orúkọ. 
	
Nínú èdè Afirika, OR ati Is se iyebíye. Àwọn èdè Africa máa ń lo Is dáadáa ju àwọn èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè àwọn European. 
Fún àpẹẹrẹ: 

	Aghem, Bantu, Benu-Congo, Niger-Congo 

 -(i)	fi - baףּà – The bird is red. 

	Ọ̀rọ̀ Ise ni wọ́n lo red fún nínú gbólóhùn yìí. 

Ẹ̀wẹ̀, a lè lo ọrọ ìṣe ní ibi tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì bá ti ń lo àpọ́nlé (e.g. frequently, not yet, still, again) ati ọ̀rọ̀ àsopọ̀ 
(Conjunction) e.g. and, their’ 

(i)	Ó tún ń lọ. He is going again. 

(ii)	à-njánà à-Chòr-á She is still talking

	
Àwọn Èdè Africa kò ní Atókà púpọ̀ bí Europeans. Èdè Afíríka jẹ́ èdè olóhùn, èyí ni a sì fi máa ń dá wọn mọ̀ yàtọ̀. 

	(i)	ףּwá báy làa bàà He was very, very red 

	(ii)	ףּwá nyiףּ máa tátátә  He ran quickly and Continuosly 

Gbólóhùn oní pọ́nónna (Simple Sentence)
	
Àwọn wọ̀nyí: Subject (s) verb (v) obuject (o) ni a máa ń lò láti sàlàyé gbólóhùn 
	
Svo ni o gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Afroasiatic àti ní Niger-Congo yàtọ̀ sí Mande, Senufo àti Ijo, Ní ilè Khoisan – Khoe náà yàtọ̀ fún àpẹẹrẹ: 

		Hausa, Chadic, Afroasiatic 

(i)		S		V		O

		Obdun 	yaa ci	na amaaa

	Swahili, Bantu, Benu – Congo, Niger-Congo 

(ii)		S 	      V        O 

	     Halima    a-na-pika     ugali 

	Halima is cooking porridge 

Nínú àwọn èdè wọ̀nyí: 

(iii)	    S           V            O        Adv 

       teleme        a kop       kene    ‘de’ de 

	‘The monkey Caught the branch quickly 

Ìkejì tí ó tùn gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Afirika ni SOV. A lè rí i ní 
Ethio-Semitic, Cushitic àti Omotic láàrin Afroasiatic ní senufo : Bí 
àpẹẹrẹ: 

(i)	Silt’e, Ethio – Semitic, Afroasiatic 	

	  S                        O                 V    

	isaam       ciitañe      gilgil     Ceeñeet 

 (ii)	Supyire, Senufo, Gur, Niger-Congo 

	       S  	 O                  V 

	     Kile ù     kùni             pwọ 

	      ‘May God sweep the path. 

(iii)	Aiki, Maban, Nilo-Saharan 

	     S                  O          V 

	gòףּ                 yàףּ sám   tare 

Ìkẹta ni VSO, òhun kò gbajúmọ̀ ní ilè Afirika. A máa ń rí i ní Berber Chadic ni Afroasiatic, Nilotic Surmic ní ilẹ̀ Eastern Sudamic. Fún àpẹẹrẹ: 

(i)	Maasai, Eastern Nilotic Eastern Sudamic, àti Nilo-Saharan.

		V  		S		O

	     édól             oltúףּání 	       eףּkolìí

	The person sees a gazelle. 

	
Nínú àwọn èdè tí ń lo V S O àbọ̀ kìíní àti ìkejì máa ń tẹ̀lé Is á wá fùn wa ní VSOO Turkana bí àpẹẹrẹ: 

		V		S 		O 		O 

	    à-in-a-kin-i	ayòףּ		ףּide 	         akimui 

	
Nínú èdè SOV, adjuncts (afikun) maa ń síwájú Is, a wá fún wa ni SXOV tàbí SOXV bí ó se hàn ni – 

(1)	Aiki, Maban, Nilo-Saharan. 

		S         O           LOC               V

	Kàikàì  ti    tiףּíףּ gá    tàk  gán tàndàrkÈ

	The child joined its mother at the pound 

	“X” yìí dùró fún ìkan lára àwọn àfìkún. Àfikún (adujunct) ni 

Location post positional phrase “tak g∂n

Àwọn èdè SOV lè lo SOVX fun afikun (adjuncts) bí a se ríi ní Menade, pẹ̀lú atọ́kún Instrumental prepositional a bó a  ti o túmọ̀ sí with a knife. 

	Mende, Western, Mande, Niger – Congo 

	     S                O        V         INST 

	     è 		wúru        tèe 	à bóa 

       hé 		stick 	        cut 	 with  knife 

	He cut the stick with a knife.

Gbólóhùn Àsẹ àti ìbèèrè (commands and questions) Ohun mẹ́ta ni a máa 
gbé yèwò. Èyí ibeere ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ (i) (Yes or no question) (2) Information word question  (3) Indirect question. 
	
Nínú èdè Africa Yes/no question most commonly involve only a question marker or morpheme at the end or the beginning of the sentences. Nínú èdè Africa ìbéèrè oní bẹẹni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ máa ń ni àmì ìbéèrè ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ìparí  
	
Linda is typical of many Niger-Congo and other langs, that use a question marker at the edge of the sentence. Linden i Ogidi nínú àwọn Niger Congo ti o n lo ìbéèrè alámì ni opìn gbólóhùn. 

	Linda, Banda, Adamawa –Ubangi, Niger-Congo 

	(a)	`ce 			gú 

		he/she 	        arrived     she arrived 

	(b)	cè       	gú       à

		he/she    arrived 	Qm

					Did she arrive? 

	
Nínú èdè bíi silte wọ́n máa ń lo ohùn gbigbe sókè ní ìparí gbólóhùn, á lè lò ó gẹ́gẹ́ bíi yes/no question. Fun àpẹẹrẹ: 

	Silt’e, Ethio – Semitic, Afroasiatic 

	akkum 	    tisiikbińaas  way 
						Qm 

ó  máa ń wáyé nínú èdè Haúsá náà. 
	
Ohùn àwọn èdè wọ́nyí: Wande, Gur àti Kwa máa ń lọ sí ilẹ̀ ni. 
Nínú èdè àwọn konni, Gur ní ilè Ghana, vowel or nasal is lengthened and has a slow fall in pitch. Èyí túmọ̀ sí pé nínú èdè Konni fáwẹ̀lì tàbí aránmúpè wọn máa ń falẹ̀.  

Àpẹẹrẹ	nì díè saabú-u

Are you (pi) eating porridge? 

Yes/no question tún máa ń wáyé nípa lilo negation (Ayisodi) “Didn’t he 

go to Accra? Nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a bá dáhùn bẹ́ẹ̀ni, ohun tí à ń sọ ni pé ò lọ sí Accra. Ìdàkejì rẹ̀ ni ó tọ̀nà ní ilẹ̀ Africa.
Ṣùgbọ́n ní ilẹ̀: Ejagbam, Ekoid Bant 

	Benue – Congo àti Niger-Congo 

(a)	Ó – kà – jí ògàm à (Didn’t you go to the Qm market) 

(b)	nńǹ, (ń-kà-ji) Yes, (I didn’t go) 

ÌYÓSÓDÌ 
Twó different kinds of negation should be distinguishes. Túmọ̀ sí pé orísìí àyísódì méjì ni  a máa gbé yèwò. Àkọ́kọ́, A lè yí gbogbo gbólóhùn sí òdì. Ìkejì, ó sì lè jẹ́ àpólà kan nínú gbólóhùn bí àpólà orukọ ni a máa yí sódì.

	VERBAL AFFIXES 

Ọ̀nà tí ó gbajúmọ̀ tí wọ́n fi máa ń yi gbólóhùn sódì ni síse àtúnrọ àwọn ọ̀rọ̀ ìse. A yi kúrò ni ipò ìṣe lọ sí ìse aláyìísódì. Gbogbo ilẹ Benue-Congo ni wọn tí máa ń lò ó. Fún àpẹẹrẹ. 

	ò bò fí – ghGm  He has hit the mat. 

	ò kà bó gbam-fò  he has not hit the mat 

	Compound and complex sentences (Gbólóhùn ọlọ́pọ̀ awẹ́) 

Compound sentewes-ni síse awẹ́ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀, ó máa ń jẹ́ odidi awẹ́ àti àfarahẹ. 

Emphasis or focus’Àfojúsùn, 

Àfojúsùn jẹ́ ohun pàtàkì tàbí information abẹ́nú nínú gbólóhùn. Ó jẹ́ ohun ti olùsọ gbà pé Oùgbọ́ kò gbọdọ̀ bá òun sọ. Èdè Africa máa ń lo ohùn nígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n ohun ti wọ́n sabàá máa ń lò ni (i) yíyí padà kúrò ni ọ̀rọ̀ ìse tàbí kí wọ́n lo AUX àsèrànwọ́ ìṣe (2) use of special words (particles) (3) use of cleft-types constructions fún àpẹẹrẹ nínú èdè Ejaghan. 

(a)	à – nam 		bì-yù 

	       buy 		    yam 

	“She bought yams”

(b)	à – nàm-é 			jén

	     Focus 			what 

	      What    did  she buy 

(c)	à – nam-é 		bì-yù 

	She bought         yams 

Èdè A ghem ni àfojúsùn tó le (complex focus) In some cases it uses a focus particle ñ

(a)	fù kí mò nyiףּ nõ á kí-bé 

	The rat ran in the compound. 

(b)	Fú kí mọ nyiףּ  no á kí-bé 

The rat ran (did not walk) in the compound 

(c)	Fù kí mọ nyiףּ á kí-bé no 

	The rat ran inside the conpound (not inside the house)

Àwọn èdè mìíràn lè lo àpepọ̀ verb changes and particles, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú èdè Vute. 

	(a)	mvèìn yi Gwáb-na tí ףּgé cene 

		The chief bought him a chicken

	(b)	Mvèìn yi Gwab-na-á ףּgé cene já




#Article 139: Zangbetọ (181 words)


Zangbeto jẹ́ Òrìṣà àwọn ẹ̀yà Ògù ní Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry, tí wọ́n gbàgbọ́ pé ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṢẸ̀ wá láti orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin àti orílẹ̀-èdè Togo. Zángbétọ́ lè jade nígbà kúgbàà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ọdún Òrìsà tàbí aỵẹyẹ ìbílẹ̀. ‘Zangbetọ’ jẹ́ Òrìsà tó mò n pa idán ní ọjọ́ ayẹyẹ láti yẹ́ àwọn ènìyàn sì. ‘Zangbetọ’ sì tún jẹ ààbò fún ìlú kí àwọn ọlọ́sà máa ba wọ̀lú ní òru. Tí ọ̀rọ̀ kan bá sí se pàtàkì, ‘Zangbetọ’ kan náà ni wọn yóò ran láti lọ jẹ́ irú isẹ́ bẹ́è. Tí ẹnìkan bà sì sẹ̀ tàbí lódí sí ofin ìlú, àrokò ‘Zangbetọ’ ni wọn yóò fí síwájú ilé e rẹ̀. Ẹníkẹ́ni tí wọ́n bá sì fi irú àrokò yìí síwájú ilé rẹ̀ yóò ní láti dé aàfin Ọba kí ó sì san ohun kóhun tí wọn bá ni kò san ki ó to lè wo ilé rẹ̀.
Àgbálo gbábọ̀ ọ̀rọ̀ nii ni pé àwọn ẹ̀sìn àtọ̀hunrìnwá wà ṣùgbọ́n ẹ̀sìn àbáláyé kò lè parun, nítorí pe, gbogbo àwọn Òrìsà wọ̀nyí ṣì wà síbẹ̀. 

 




#Article 140: Ìrìnàjò lọ sínú Òṣùpá (1401 words)


ÌDÒWÚ OLUWASEUN  ADẸ́SAYỌ̀

ÌRÌNÀJÒ LỌ SÍNÚ ÒṢÙPÁ

Aye mẹ́jọ míràn bíi’rú ti wa lo n yi po káàkiri òòrùn. Àwa la ṣìkẹta táa jìnà sóòrùn, awọn méjì wà níwájú. Àwọn mẹ́fà wà lẹ́yìn wa. Mo ni òòrùn tí à ń wò lókè taa rò pé ó kéré mo ló tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ju gbogbo ilé ayé lọ báyé yìí ṣẹ́ ń yípo òòrùn, bẹ́ẹ̀ náà lòsùpá ń yípó ayé Mo tún sọ fún wa wípé jínjìn ilé ayé sí òṣùpá tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ọ̀rún mẹta, ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún kìlómítà 320, 000 kin. Bíi kéèyàn ó máa rin Èkó sí Ìbàdàn bíi ọ̀nà ẹgbẹ̀rún méjì bẹ́ẹ̀ náà lòṣùpá ṣe jìn sílé ayé tó téèyàn bá kúrò lórí ilẹ̀ ayé àlàfo tí ń bẹ láàrin Ilé-ayé àti òṣùpá, láàrin ilé ayé àti òòrùn láàrin ilé-ayé àti àwọn ayé mẹ́jọ tó kù lèèyàn ó kàn o, téèyàn  bá ń fò lọ sókè sínú òfurufú àlàfo yìí làwọn olóyìnbó ń pè ní space ṣee mọ̀ pé bí ìgbà téèyàn bá to ǹkan ka lẹ̀ tálàfo wá wà níbẹ̀, bí Olódùmarè ṣe tàlàfo sáàrin ilé ayé àtàwọn ayé tókù, àtòòrìn àtòṣùpá rèé. Àlàfo tí à ń sọ yìí, bíi ojú sánmọ̀, ojú òfurufú ló ṣe rí ṣùgbọ́n ǹkan tí ó fi yàtọ̀ díẹ̀ ni pé kò sí atẹ́gùn nínú àlàfo yìí, kò sí kùrukùru òfuru jágédo lásán ni. 
	
Àjá ni wọ́n kọ́kọ́ rán sínú àlàfo tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lọ́dún 1957 Làíkà lórúkọ tájá yìn ń jẹ́, nigba tájá yi padà tí ò kú ní wọ́n bá rán ẹnìkan ta n pe ni Yuri Gagarin lọ sínu àlàfo yìí, láti orílẹ̀èdè Russia láti mọ̀ bálàfo yì sẹ rí Yuri Gagarin lẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ fò kúrò lórí ilẹ̀-àyé pátápátá lọ sinu àlàfo ta  n pe ni space to wà láàrin Ilé ayé àtòṣùpá.
 	
Lẹ́yìn èyí orílẹ̀ èdè America náà bẹ̀rẹ̀ sí ní rìnrìnàjò yii Ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín orílẹ̀èdè America lọ́ sínú òṣùpá lọ́dún 1969 Neil Armstrong ati Edwin Aldrin si lẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ wọnú ọ̀sùpá. Mo sọ fun wa wipe òǹfà kan nbẹ́ ninú ilé ayé tó má n fa gbobgo ǹkan tó bá ti wà lórí ilé-ayé tàbí súnmọ́ ilé ayé mọ́ra, 

Téèyàn á bá wá kúrò lórí ilẹ̀-ayé pátápátá èàyàn gbọdọ̀ jára rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà yìí, mọ́to téèyàn á bá lọ ó gbọ́dọ́ lágbára gidi kò sì tún lè sáré láti bori agbára ̣ òǹfà yìí, tóò ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ inú òṣùpá, Rọ́kẹ́ẹ̀tì ló ń jẹ́ o, Aeroplane, ò lè rin irú ìrìnàjò yí o, e wòó iṣẹ́ ọpọlọ ni wọ́n fi se rọ́rẹ́ẹ̀tì yìí, Ìpéle mẹ́ta ni wọ́n ṣe éńjínnì mọ́to yí o, Ìpéle kínní, ìpéle kejì, ìpóle kẹta lọ sókè ibi tí àwọn èèyàn dúró sí núnú rẹ̀, ó wà lórí ìpéle kẹta lókè téńté bí wọ́n ṣe to àwọn éńjìnnì yìí bíi àgbá rìbìtì léra wọn rèé tó dúró lóòró tó wá kọjú da sánmọ̀ wọ́n tún wá jẹ́ ki ọkọ yìí ṣẹnu ṣómu ṣómú ko le máa wọnú atẹ́gùn lọ sọ̀ọ̀, Orúkọ tí wọ́n fún rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí ni wọn n pè ni Apollo 11, Apollo 11 yìí ga lọ sókè ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́run mẹ́ta Ààbọ̀ ó lé díẹ̀, bíi ká sọ pé ilé alája ogóji epo tí ọkọ yìí ń jẹ kèrémí kọ́ o. Kò ṣéé fẹnu sọ. 
	
Bíi ìgbà tèèyàn bá yin ọta ìbọn, bi wọ́ń ṣé, má n yìn-ín nuu torí ó gbọdọ̀ le sáré dáadáa kío le jára rẹ̀ gbà kúro lọ́wọ́ ̣ òǹfà tí ń bẹ lórí ilẹ̀ aye, tí wọn á bá si yin mọ́to yìí kìí séèyàn kankan ní sàkání ibẹ̀, torí ooru, èéfín àti iná nló má ń jáde ní ìdí Rọ́kẹ̀ẹ̀tì yìí.
	
Àwọn tó lọ inú òṣùpá, ti wọ́n wà nínú mọ́to yìí. wọ́n dera wọn mọ́ àgá ni Àwọn tó yin rọ́kéẹ̀tí yìí sókè, wọ́n jìnnà pátápátá sí ibi tí Rọ́kẹ̀tì yìí wà, ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà ni wọ́n fí yìn ín bi wọ́n sẹ gbéná lé Rókẹ́ẹ̀tí yìí tí à ń pè ní Apollo 11 ni 1969 dó bá dún gbòà? lọkọ̀ bá ṣí, Ó dòkè lójú sán mọ̀ Eré burúkú kí ọkọ̀ máa sáré ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá kìlómítà láàrín wákàtí kan. 10,000km/hr irú eré tí àwọn móto má ń sá lọ́nà ẹ́spùrẹ̀sì irú eré yìí lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan leré tí rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí bá lọ sínú òfurufú lọhun. Láàrin ìṣẹ́jú méjì ààbọ, éńjìnnì tìpéle àkọ́kọ́ ti gbé ọkọ̀ yìí rin kìlómità ọgọrun mẹ́fà 600km. lọ sínú òfunrufú. 
	
Lẹ́yìn iṣẹ́jú méjì ààbọ̀ éńjìnnì tó wà ní ìpéle àkọ́kọ́ ti jó tán ó jábọ́ kúrò lára ọkọ̀ yìí, éńjìnnì tì péle kejì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ó sì gbé wọn rin ẹgbẹ̀rún méji, ó lé ni ọgọrun mẹta kìlómítà 2,300 kilometres láàrin ìṣẹ́jú mẹ́fà lọ́ sí nú òfururú lọ́ùnlọ́ùn, ẹńjìnnì ìpéle kejì jó tán òhun náà jábọ́, tipéle kẹta bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ẹ́njìnnì tìpéle kẹta ló wá jáwọn gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà tí ń bẹ nínú ayé pátápátá, wọ́n sì bọ́ sínú àlàfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtoṣùpá. Nínú àlàfo yìí, ̣ òǹfà  ayé ò ní pa púpọ̀ mọ́ lórí wọn Wọ́n wá sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ni rìnrìnàjò wọn lọ́ sínú òṣùpá ní ìrowọ́ ìrọsẹ̀. Nínú àlàfo tí a ńpè ní space yìí, béèyàn bá ju ̣ ǹkan ókè kìí padà wá lẹ̀ yíó dúró pa sókè ni, kó dà gan béèyàn gan fò sókè èèyàn ò ní tètè padà wálẹ̀ tórí kò sí ̣ òǹfà kan tí ó fààyàn padà nínú àlàfo yìí ṣùgbọ́n béèyàn bá dẹ́nú òṣùpá, ̣ òǹfà ń bẹ nínú òṣúpá ṣùgbọ́n àmẹ́ kò tó tayé béèyàn bá ju ǹkan sókè nínú òṣùpá naa kìí tètè padà walẹ, ẹ má gbàgbé àti nínú àfìfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtọ̀ṣùpá àti nínú òṣùpa gan-an kò sí atẹ́gùn níbẹ̀ o báwo wá làwọn tí wọ́n ń lọ inú òṣùpá ṣé má ń mí, wọ́n má ń gbé atẹ́gùn pamọ́ sínú àpò kan ni, kí wọn o le rátẹ́gùn fi mí. Tòò wọ́n dénú òṣùpá lógúnjọ́ oṣù kẹfà lọ́dún 1969 lọ́jọ̀ Sunday ọjọ ìsinmi ló bọ́ sí ẹ̀yin tẹ́ẹbá ní kàlẹ́ńdà 1969 lọ́wọ́ ẹ wòó ọjọ́ márùn-ún ni wọ́n fi rin ìrìn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun mẹ́ta , ó lé ní ọgọrun lọ́nà ogún kìlómítà 320,000km lọ sí nú òṣùpá, Neil Armstrong lórukọ fẹẹ̀ ẹní tó kọkọ fi ẹsẹ tẹnú òṣùpá bó sẹ́ ń sòkalẹ̀ láti inú ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ óní bí ó ti lẹ̀ jẹ́pé ìgbéṣẹ̀ ti òhun gbé wọnú òṣùpá ó kéré óní ìgbésẹ̀ ńlá ni fún ìran ọmọ ènìyàn. Edwin Aldrin tí wọ́n dìjọ lọ náà sọ̀kalẹ̀ sínú òṣùpá wọ́n bá ààrẹ oríléèdè Amerika Nígbànáà ààrẹ Richard Nixon sọ̀rọ̀ pé tò àwọn tí dé nú òṣùpá o. Àwọn méjéèjì bẹ̀rẹ̀ ìwádí ti wọ́n bá lọ sínú òṣùpá wọ́n fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé erùpè, òkúta àtàwọn òkè ń bẹ nínú òṣùpá ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀dá alàyè tàbí ohun abẹ̀mí kan níbẹ̀. 
	
Inu òṣùpa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ọjọ́ méjì ti è oṣù kan ti wa ni ọ̀ sẹ̀ méjì gbáko lòòrùn á fi ràn. Tí gbogbo ǹkan á sì gbóná lọ́nà méjì ju omi tó ń hó lọ, ọ̀sẹ̀ méjì ni lẹ̀ tún fí má ń ṣú, gbogbo ǹkan á tún tutu lọ́nà méjì ju ice block yìnyín lọ. 
	
Àsìkò ìgbà tóòrùn ń ràn ni wọ́n dé bẹ̀ àmọ́ aṣọ tiwọ́n wọ̀ dábòbò wọn tóoru ò fi mú wọn pa torí wọ́n dọ́gbọ́n éńjìnnì amára tutu sínú aṣọ yìí, àwọn méjéèjì lo wákàtí méjì àtìṣẹ́jú mẹ́ta dínláàádọ́ta nínú òṣùpá wọ́n ṣàwọn ìwáàdí kéèkèè ké wọ́n ri àsìá orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà síbẹ̀, wọ́n bu yèèpè inú òṣùpá àtòkúta díẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì padà, tòò àti lọ sínú òṣùpá ló le àti kúrò níbẹ̀ ò le, wọn yin ra wọn kúrò níbẹ̀ ni bi wọ́n ṣe yin ra wọn kúrò lórí ìlẹ̀ aye. 
	
Ọjọ́ méjì ààbò ni wọ́n fi rìn padà sórílẹ̀ ayé bi wọ́n tún ṣe súnmọ́ ilé-ayẹ́ lòǹfà inú ayé bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ní fàwọ́n, eré ni awọ́n si n bá bo láti inú òṣùpá tẹ́lè leré yìí bá tún pọ̀ si, báwo lọkọ̀ se fẹ́ bà sórí ilẹ̀ pẹ̀lú eré burúkú yìí íápọọ̀tì òtì wo ló fẹ́ bà sí wọ́n sá ṣètò kí mọ́tò yí balẹ̀ sínú òkun alagbalúgbú omi ṣẹẹ mọ̀ pé okún jìn lọ ìsàlẹ̀, omi inú òkun tún dá mọ́tò yìí dúró bíi búrèkì, tòò bi wọ́n se lọ sínú òṣùpá rèé o. Lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1969 16-7-1969 tí wọ́n sì padà sórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù keje kannáà lọ́dún 1969, 24-7-1969.




#Article 141: Baṣọ̀run Gáà (715 words)


Baṣọ̀run Gáà jẹ́ ìwé ìtàn eré-oníṣe tí gbajúmọ̀ oǹkọ̀wé  nì, Adébáyọ̀ Fàlétí kọ. Ó dá lórí ìtàn olóyè Baṣọ̀run tí ìlú Ọ̀yọ́ tí wọ́n ń pè ní Baṣọ̀run Gáà. Ó jẹ́ afọbajẹ ní ìlú Ọ̀yọ́ láyé àtijó. Kókó inú ìwé ìtàn eré oníṣe yìí ni wípé kí a má ṣe ìkà. Ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ni ònkọ̀wé náà fi kọ ìwé náà, tí ó sì gbé ìtàn rẹ̀ lé orí ìtàn gidi tí ó sì jẹ́ ojúlówó ìtàn ilé Yorùbá.

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan ni BBC, ìtàn 
fi ye wa pe, Basọrun Gaa ni olori igbimọ Ọyọmesi, eyi to dabi Olootu ijọba laye ode oni, lẹyin Alaafin, tii se oriade ilu Ọyọ́, Basọrun Gaa lo tun ku.
Ko si sẹni to le e sọ pe ti Basọrun Gaa ko jẹ eeyan gidi, wọn yoo fi jẹ oye Basọrun, to jẹ olori igbimọ lọbalọba fun Alaafin, tii se Ọyọmesi.
Ni bayii, o wa yẹ ka mọ itan igbe aye akọni yii ati ipa to ko ni ilu rẹ, boya rere ni abi buburu.
Basọrun Gaa ni olori ogun Ọyọ ile ati gbajumọ ilu ni saa onka ẹgbẹrun ọdun kẹtadinlogun si ikejidnlogun, 17th/18th century
Basọrun Gaa se gudugudu meje ati ya a ya mẹfa lati rii daju pe Ọyọ ile akọkọ di ilu nla, o lagbara, to si fẹ de ọpọ ilu ati orilẹ-ede lode oni
Lọdun 1750 ni Alaafin Labisi yan Gaa gẹgẹ bii Basọrun, olootu ijọba ati olori igbimọ lọbalọba ẹlẹni meje fun Alaafin nilu Ọyọ ile, ti agbara si n pa Gaa bi ọti
Ilu Ọyọ ile roju, o tuba, o tusẹ lasiko ti Basọrun Gaa joye, ti Ọyọ si maa n gba isakọlẹ lati ọpọ ilu àmọ́nà to wa labẹ rẹ
Tọmọde-tagba nilu Ọyọ lo n bẹru, ti wọn si n bọwọ fun Basọrun Gaa, tori pe o ni oogun abẹnu gọngọ, ti asẹ rẹ si mulẹ ni aarin ilu ju Alaafin Labisi to yan an sipo lọ
Itan sọ pe Basọrun Gaa ni oogun pupọ, to si maa n parada di ẹranko to ba wu u, to fi mọ Ẹkun, Kiniun, Igala, Ọya ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ni kete ti Gaa di Basọrun ni Ọyọ ile lo pa meji ninu awọn ọrẹ imulẹ Alaafin Labisi, eyi to dun ọba naa de egungun, to si gba ẹmi ara rẹ lọdun 1750 naa
Alaafin Awọnbioju lo jẹ Alaafin lẹyin Labisi, sugbọn niwọn igba toun naa kọ lati gba itọni lọdọ Basọrun Gaa, aadoje ọjọ pere lo lo lori itẹ ti Gaa fi ni ki wọn yẹju rẹ
Alaafin Agboluaje to jẹ lẹyin Awọnbioju tiẹ ri ijọba se n tiẹ, tori o n gbọrọ si Basọrun Gaa lẹnu, sugbọn ọwọ Basọrun Gaa naa ni ẹmi rẹ papa bọ si
Alaafin Majẹogbe tiẹ lo dun kan soso pere lori itẹ, ki Basọrun Gaa to ran sọrun ọsan gangan
Lọdun 1774 ni Alaafin Abiọdun gori itẹ, to si n wọna bi yoo se rẹyin Basọrun Gaa, ko lee roju se aye, sugbọn Gaa pa ọmọbinrin Alaafin Abiọdun, Agbọrin, nigba to nilo ẹranko Agbọnrin, to si ni orukọ wọn jọra
Ọrọ naa dun Abiọdun to bẹẹ, to si beere fun atilẹyin Onikoyi, ati aarẹ Ọna Kakanfo to jẹ nigba naa, Ọyalabi lati ilu Ajasẹ ipo, ki wọn lee tete rẹyin Basọrun Gaa
Alaafin Abọdun kọkọ yọ ibẹru Gaa kuro lọkan awọn araalu, to si jẹ ki ibinu rẹ maa ru jade ni inu wọn, titi ti Basọrun Gaa fi rọ lapa, rọ lẹsẹ
Lọdun 1774, ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan Ọyọ ile ya bo agboole Basọrun Gaa, ti wọn si wọ ọ lọ si ọja Akẹsan, ki wọn to sun un nina gburugburu, bẹẹ ni wọn pa a tọmọtọmọ, wọn jẹ ile Gaa run patapata
Sugbọn ori ko akọbi rẹ, Ojo Aburumaku yọ ninu wahala yii, to si sa lọ si ilẹ Ibariba, eyi to fopin si aye fami lete ki n tutọ ti Basọrun Gaa ati idile rẹ n jẹ
Idi ree ti awọn eeyan se maa n pa asamọ pe ‘Bo laya ko sika, to ba ri iku Gaa, ko sootọ’
Sugbọn iku Basọrun Gaa se akoba nla fun ijọba Ọyọ akọkọ, tori lẹyin iku Gaa ni ẹdinku ba bi awọn ọmọ ogun rẹ ti dangajia si ati agbara ilu naa, tawọn ilu kan si n sa kuro labẹ rẹ, titi ti Ọyọ ile akọkọ fi tu lọdun 1836.




#Article 142: Nàìjíríà (2183 words)


Nàìjíríà () jẹ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà  (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira tí ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì tó fi mọ́ Agbẹ̀gbẹ̀ Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní apá Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Orílẹ̀-èdè yí pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Benin ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ó tún pààlà pẹ́lú orílẹ̀-èdè olómìnira ti Nijẹr ní apá àríwá, Chad àti Kamẹróòn ní apá ìlà Oòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni ó jẹ́ Olú-Ìlú fún orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ní ẹ̀yà púpọ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n hànde tí wọ́n tóbi jùlọ, tí Wọ́n sì pọ̀ jùlo, tí a sì kó àwọn ẹ̀ka ìsọ̀rí ìsọ̀rí èyà tókù sí abẹ́ wọn.  Àwọn wọ̀nyí ni HausaẸ̀yà , Ẹ̀ya Ìgbò ati Yorùbá.  

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ. Agbegbe Benue-Cross River jẹ́ rírò gẹ́gẹ́ bí ile àkókó àwọn Bantu arókèrè ti wón fan ka kiri opo arin àti apágúúsù Áfríkà bí irú omi ní arin ẹgbẹ̀rúndún akoko kJ àti ẹgberundun keji.

Oruko Naijiria wa lati Odò Ọya, to tun je mimo gege bi Odo Naija, eyi to san gba Nigeria koja. Flora Shaw, ti yio je iyawo lojo waju fun Baron Lugard ara Britani to je olumojuto amusin, lo seda oruko yi ni opin orundun 19sa.

Naijiria ni orile-ede to ni onibugbe pupojulo ni Afrika, ikejo ni agbaye, be si ni o je orile-ede to ni awon eniyan alawodudu julo laye. O je kikojo mo ara awon orile-ede ti a n pe Next Eleven ni to ri okowo won, o si tun je ikan ninu Ajoni awon Ibinibi. Okowo ile naijiria je ikan ninu eyi to n dagba kiakiajulo laye, pelu IMF to ngbero idagba 9% fun 2008 ati 8.3% fun 2009. Ni ibere awon odun 2000, ogunlogo awon onibugbe gbe pelu iye to din ju US$ 1.25 (PPP) lojumo. Ere Nok tó wà ní Minneapolis Institute of Arts, júwe ẹni pàtàkì kan  mú Ọ̀pá idaran dání ní owó ọ̀tún àti igi ní owó òsì. Ìwònyì ní àmì-ìdámọ̀ aláse tó jẹ́ bíbásepọ̀ mò àwọn fáráò ilè Egypti ayéijoun àti òrìṣà, Oṣíriṣ, èyí lo n so pé irú àwùjọ, idimule, bóyá àti ẹ̀sìn ilè Egypti ayeijoun wà ní agbẹ̀gbẹ̀ ibi tí Nàìjíríà wà loni ní ìgbà àwọn Fáráò.        

Ní apa àríwá, Kano àti Katsina ní ìtàn Àkọsílè tí ọjọ́ wón dẹ́yìn tó bí ọdún 999 kJ. Àwọn ìlú-ọba Haúsá àti Ilé-ọba Kanem-Bornu gbooro gẹ́gẹ́ bí ibùdó ajẹ́ láàrin Àríwá àti Iwoorun Áfríkà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ orundun 19sa lábé Usman dan Fodio àwọn ará Fúlàní di àwọn olórí Ilé-ọba Fúlàní lójúkan èyí tó dúró bayi títí di 1903 nígbàtí àwọn jẹ́ pínpín láàrin àwọn olumusin ara Europe. Láàrin 1750 àti 1900, ìdá kan sí ìdá méjì nínú meta àwọn oníbùgbẹ́ àwọn ìlù Fúlàní jẹ́ eru nítorí ogun.

Àwọn Yorùbá se ojo ti won ti wà ní agbegbe Nàìjíríà, Benin àti Togo ayéòdeòní sẹ́yìn dé bí ọdún 8500 kJ. Àwọn Ìlú-ọba Ifẹ̀ àti Ọ̀yọ́ ní apá Ìwòòrùn Nàìjíríà gbale ní 700-900 àti 1400 nitelera wón. Síbẹ̀síbẹ̀, ìtàn àríso Yorùbá gbàgbọ́ pé Ilé-Ifẹ̀ ni orísun ẹ̀dá ènìyàn pe be si ni o síwájú àsà-ọ̀làjú míràn. Ife seso ere alamo ati onitanganran, Ìlú-ọba Ọ̀yọ́ si fe de ibi tí Togo wà loni. Ìlú-ọba míràn to tún gbalẹ̀ ní gúúsù apáìwòọ̀rùn Nàìjíríà ní Ìlú-ọba Benin láti orundun 15ru  19sa. Ìjoba won de Ìlú Èkó ki àwọn ara Portugal o to wa so ibẹ̀ di Lagos.

Ní apa gúúsùilàodún Nàìjíríà, Ìlú-ọba Nri ti àwọn Igbo gbooro láàrin odunrun 10wa títí de 1911. Eze Nri ni o joba Ìlú-ọba Nri. Ilu Nri jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́ bí ìpilèsè asa igbo. Nri àti Aguleri, níbi ti ìtàn ariso ida Igbo ti bere, wa ni agbẹ̀gbẹ̀ ìran Umueri, awon ti won so pe iran awon de ile oba Eri fun ra re.

Awon oluwakiri ara Portugal ni awon ara Europe akoko to bere isowo ni Naijiria ti won si so ebute ni Eko di Lagos fun oruko ilu Lagos ni Algarve. Oruko yi le mo ibe bi awon ara Europe miran na se n se owo nibe. Awon ara Europe sowo pelu awon eya abinibi ni eba odo, won si bere owo eru nibe, eyi to pa opo awon eya abinibi Naijiria lara. Leyin ti awon ogun Napoleon bere, awon ara Britani fẹ isowo de inu arin Naijiria.

Ni 1885 igbesele Iwoorun Afrika latowo awon ara Britani gba idamo kariaye, nigba to si di odun to tele ile-ise Royal Niger Company je hihaya labe ayeolori Sir George Taubman Goldie. Ni 1900 awon ile ti ile-ise yi ni di ti ijoba Britani. Ni January 1, 1901 Naijiria di ile alaabo ti Britani, ikan ninu Ile-oba Britani to je alagbara julo nigba na.

Ni 1814, agbegbe na je sisodokan gege bi Imusin ati alaabo ile Naijiria (Colony and Protectorate of Nigeria). Fun amojuto, Naijiria je pinpin si igberiko apaariwa ati apaguusu ati imusin Eko. Eko Iwoorun ati okowo ayeodeoni tesiwaju ni kikankikan ni guusu ju ni ariwa lo, ipa eyi n han ninu aye oloselu Naijiria de oni. Ni odun 1936 ni oko eru sese di fifofin lu. 

Leyin Ogun Agbaye Eleekeji gege bi esi fun idagba isonibinibi Naijiria ati ibere fun ominira, awon ilana-ibagbepo to ropo ara won ti won je sisodofin latowo Ijoba Britani mu Naijiria sunmo ijoba-araeni to duro lori asoju ati apapo. Nigba to fi di arin orundun 20ji iru nla fun ominira ja ka kiri Afrika.

Ni October 1, 1960 Naijiria gba idani lowo orile-ede Sisodokan Ilu-oba. Ile olominira tuntun yi mu opo awon eniyan ti won n fe ki ibinibi ti won o je eyi to lagbara julo. Ijoba aladani Naijiria tuntun je isowopo awon egbe amojeoyipada: Nigerian People's Congress egbe to je didari lowo awon ara Ariwa ati awon elesin musulumi ti Ahmadu Bello ati Abubakar Tafawa Balewa to di Alakoso Agba akoko leyin ominira, je olori, ati eyi ti awon Igbo ati elesin Kristi je didari National Council of Nigeria and the Cameroons (NCNC) ti Nnamdi Azikiwe, to di Gomina-Agba ainibi akoko ni 1960, se olori. Ni ipo alatako ni egbe ilosiwaju Action Group (AG) ti o je didari lowo awon Yoruba ti Obafemi Awolowo se olori. 

Ipinu odun 1961 fun Apaguusu Kameroon lati darapo mo orile-ede Kameroon nigbati Apaariwa Kameroon duro si Naijiria fa aidogba nitori pe apa ariwa wa je titobi ju apaguusu lo gidigidi. Naijiria pinya lodo Britani ni 1963 nipa siso ara re di ile Apapo Olominira, pelu Azikiwe gege bi Aare akoko. Rogbodiyan sele ni Agbegbe Apaiwoorun leyin idiboyan 1965 nigbati Nigerian National Democratic Party gba ijoba ibe lowo AG.

Aidogba yi ati ibaje eto idiboyan ati oloselu fa ni 1966 de awon ifipagbajoba ologun lera lera. Akoko sele ni January ti awon odo oloselu alapaosi labe Major Emmanuel Ifeajuna ati Chukwuma Kaduna Nzeogwu. O ku die ko yori si rere - awon olufipagbajoba pa Alakoso Agba, Sir Abubakar Tafawa Balewa, Asolori Agbegbe Apaariwa Naijiria, Sir Ahmadu Bello, ati Asolori Agbegbe Apaiwoorun ile Naijiria, Sir Ladoke Akintola. Botileje bayi, sibesibe awon olufipagbajoba na ko le gbe ijoba kale nitori isoro bi won yio ti se, nitori eyi  Nwafor Orizu, adelede Aare je mimu dandan lati gbe ijoba fun Ile-ise Ologun Adigun Naijiria labe Apase Ogagun JTY Aguyi-Ironsi.

Sistemu ofin otooto merin lo wa ni Naijiria.

Naijiria ni eka idajo ti Ile-ejo Gigajulo ile Naijiria je eyi to lagbarajulo.

Ojuse awon ise ologun Olominira Apapo ile Naijiria ni lati daabo bo ile Naijiria, igbesoke ijelogun abo Naijiria ati itileyin itiraka igbero alafia agaga ni Iwoorun Afrika.  

Ise ologun Naijiria ni Ile-ise Ologun Akogun, Ile-ise Ologun Ojuomi, ati Ile-ise Ologun Ojuafefe.

Lopolopo igba Ile-ise Ologun Naijiria ti ko ipa ninu igbero alafia ni Afrika. Ile-ise Ologun Naijiria gege bi ikan ninu ECOMOG ti ko ipa gege bi olugbero alafia ni Liberia ni 1990, Sierra Leone ni 1995, Ivory Coast ati Sudan.

Naijiria budo si apaiwoorun Afrika ni Ikun-omi Guinea, o si ni iye apapo ifesi 923,768 km2 (356,669 sq mi) eyi so di orile-ede 32ji titobijulo lagbaye leyin Tanzania. Bode re pelu Benin to 773 km, pelu Niger to 1497 km, pelu Tsad to 87 km ati pelu Kameroon to 1690 km; bakanna ala eti-odo re to 853 km. Ibi gigajulo ni Naijiria ni Chappal Waddi ni 2419 m (7936 ft). Awon odo gbangba ibe ni Odo Oya ati Odo Benue ti won japo ni Lokoja lati ibi ti won ti san lo si nu Okun Atlantiki lati Delta Naija.

Bakanna, Naijiria je gbongan pataki fun orisirisielemin pataki. Agbegbe to ni awon orisirisi labalaba julo laye ni agbegbe Calabar ni Ipinle Cross River. Awon obo agbele wa ni igbe ni Guusuilaorun Naijiria ati Kameroon nikan.

Ojuile Naijiria je orisirisi. Ni Guusu lookan ojuojo je ti ojoinuigbo amuooru nibi ti ojo odoodun to 60-80 inches (1,524 to 2,032 mm) lodun. Ni apa guusuilaorun ni Awon Iwule Obudu wa.

Naijiria je pipin si ipinle 36 ati Agbegbe Oluilu Apapo kan; awon wonyi na je pipin si agbegbe ijoba ibile 774. 

Ilu mefa ni Naijiria ni awon onibugbe to to egbegberun kan tabi pupo julo: Eko, Kano, Ibadan, Kaduna, Port Harcourt ati Ilu Benin.

Naijiria je ikan larin awon oja to n gberasoke nitori awon alumoni pupo to ni, inawo, ibanisoro, ofin ati irinna ati pasiparo ipinwo (Ilepasiparo Ipinwo Naijiria) to je ekeji 
titobijulo ni Afrika. Naijiria ni 2007 je 37je laye ni Gbogbo Ipawo Orile-ede. Gege bi Economic Intelligence Unit ati Ileifowopamo Agbaye se so Gbogbo Ipawo Orile-ede ti Naijiria fun ipin agbara iraja ti je ilopomeji lati $170.7 legegegberunkeji ni 2005 de $292.6 legbegberunkeji ni 2007. Gbogbo Ipawo Orile-ede fun enikookan ti fo lati $692 fun enikookan ni 2006 de $1,754 fun enikookan ni 2007. 

Nigba opo epo awon odun 1970, Nigeria seigbajo gbese okere totobi gidi lati seinawo idimule aje, sugbon leyin ti iye owo epo din ni awon odun 1980, o soro gidi fun Naijiria lati san awon gbese re pada, eyi fa lati fi owo to ya sile laisan ko le ba ko ju si bi yio se san ele lori owo to ya nikan.

Leyin ijiroro ijoba Naijiria, ni October 2005 Naijiria ati awon alawin Paris Club fi enu ko pe Naijiria le ra gbese re pada pelu idinwo to to 60%. Naijiria lo ere to je ninu epo lati san gbese 40% to seku, eyi je ki $1.15 legbegberunkeji o le sile lodun lati se eto idin itosi/aini. Naijiria di orile-ede Afrika akoko ti o san gbogbo gbese (ti idiye re je $30 legbegberunkeji) to je Paris Club pada ni April 2006.  

Naijiria je orile-ede 8jo to n ta petroleomu laye, be sini ohun ni ikewa to ni ipamo petroleomu. Naijiria je omo egbe OPEC. Epo petroleomu ko ipa pataki ninu okowo Naijiria to siro fun 40% Gbogbo Ipawo Orile-ede (GIO) ati 80% iye owo ti ijoba n pa.  

Naijiria ni ikan ninu oja fun ibanisorolookan ton dagbasoke kiakia laye, awon ile-ise ibanisorolookan bi MTN, Etisalat, Zain ati Globacom ni ibujoko totobijulo ati tolerejulo won ni Naijiria.   

Naijiria ni apa okowo isefunni oninawo didagba gidi, pelu adalu awon ile-ifowopamo abele ati kariaye, awon ile-ise imojuto ohun ini, ile-ise adiyelofo, awon ile-ise brokerage, awon ajo aladani equity ati awon ile-ifowopamo inawole.     

Bakanna Naijiria tun ni opolopo alumoni aintimulo bi efuufu aladanida, edu, bauxite, tantalite, wura, tanganran, irin inule, okutadidan, niobiomu, oje, ati sinki. Botilejepe awon alumoni inule wonyi po daada, awon ile-ise akoalumoni ti yio mu won jade ko si.

Ise-agbe je eyi to n mu owo okere wole fun Naijiria teletele. Nigbakan, Naijiria lo n ta epa, koko ati epo ope to pojulo si oke okun ati olupese pataki agbon, eso osan, agbado, oka baba, ege, isu ati ireke. Bi 60% awon ara Naijiria ni won sise ninu ise-agbe, be sini ile to se dako si sugbon ti won ko je be po gidi.  

Naijiria ni awon ile-ise agbese bi awo ati iwun aso ni Kano, Abeokuta, Onitsha ati Eko. Ile-ise ajopo oko bi Peugeot lati Fransi ati Bedford lati Britani to je ikan ninu apa ile-ise oko lati orile-ede Amerika, General Motors nisin, awon ewu t-shirt, ike ati onje alagolo.

Naijiria ni orile-ede ti awon  eniyan posijulo ni Afrika botilejepe iye gangan ko i je mimo. Agbajo Sisokan awon Orile-ede diye pe iye awon eniyan ni 2009 je 154,729,000, ti 51.7% inu won gbe loko ati 48.3% n gbe ni ilu ati iye eniyan 167.5 ni agbegbe ilopomeji kilomita kan.  

Naijiria ni orile-ede kejo ti o ni awon eniyan topojulo laye. Idiye ni 2006 so pe iye eniyan ti ojo-ori won wa larin odun 0-14 je 42.3%, larin omo odun 15-65 je 54.6%. Osuwon ibimo po gidi ju osuwon iku lo, won je 40.4 ati 16.9 ninu 1000 eniyan ni telentele.  
Naijiria ni bi 250 eya eniyan pelu orisirisi ede pelu asa ati ise orisirisi. Awon eya eniyan totobijulo ni Hausa/Fulani, Yoruba ati Igbo ti apapo won je 68% nigbati Edo, Ijaw, Kanuri, Ibibio, Ebira, Nupe ati Tiv je 27%, awon yioku je 7%. Arin ibadi Naijiria je mimo pe o ni opolopo eya eniyan bi Pyem, Goemai, ati Kofyar.




#Article 143: Twa (121 words)


Twa tabi Batwa jé àwon èyà ènìyàn kúkuru (pigmy) tí a le pè ní àràrá. Àwọn  ni Olùgbé tí a ní àkọsílẹ̀ pé ó pẹ́ jù ní àarin gbùngbùn ìlẹ Afíríka nibi tí a ti rí àwọn orílẹ̀-èdè bí Rwanda, burunidi ati Ilẹ̀ olomìnira ti Congo lóde òní. Àwọn ará Hutu tó sẹ̀ wá láti àwọn ara Bantu jọba lé Twa lori nígbà tí wọ́n dé agbègbè náà ṣùgbọ́n nígbà tó di bí ẹgbẹ̀rún  ọdun ìkẹẹ̀dógún (15th century AD) ni Tustsi fó jẹ́ ara ẹ̀yà Bantu dé sí agbègbè náà ti wọ́n sì jẹ ọba lórí Twa àti Hutu ti wọ́n ba lórí ìlẹ náà. Àwọn ènìyàn Twa ń sọ èdè Kwyarwanda èyí ti àwọn ènìyàn Tutsi ati Hutu n sọ.




#Article 144: Èdè Wolof (108 words)


Ede Wolof jẹ èdè tí à ń sọ ni atí bèbè Senegal Mílíọ̀nù méjì-àbọ̀ niye àwọn tó ń sọ. Awọn Olùbágbè wọn ni Mandika ati Fulaní. Awọn isẹ́ ọna wọn màa ń rewà tó sì ma ń ní àmìn àti àwòràn àwọn asáájú nínú ẹ̀sìn musulumi. Ìtan Wolof ti wà láti bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjìlá tàbí métàlá sẹ́yìn. Ìtàn ẹbí alátẹnudẹ́nu wọn sọ pé ọ̀kan lára àwọn tó kọkọ tẹ̀dó síbí yìí jẹ́ awọn to wa láti orífun Fulbe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn Wolof ni a le rí nínú àwọn orin oríkì èyí ti a ma ń gbọ́ láti ẹnu àwọn ‘Griots’ àwọn akéwì. Mùsùlùmí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọnm ará Wolof.




#Article 145: Wum (106 words)


 
Wum je ilu ni Kamẹroon
	
Apa ariwa Cameroon ni ibùgbé àwọn ènìyàn Wum. Wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn níye. Àwọn alábágbé wọn ni Esu, kom àti Bafut. Èdè Wum (macro-Bantu) ni wọ́n n sọ. Nítori ìgbàgbọ̀ wọn nipa orí, kò fẹ̣́si nínú isẹ́ ọnà wọn  tí a kì í rì àwòrán ori. Àgbè ọlọ́gìn àgbàdo, isu, ati ewébe ni àwọn ará Wum. Wọn tún jẹ́ olùsìn adìẹ ati ewúrẹ́ èyí sì kó ìpa tó jọjú nínú àtijẹ wọn lójojúmọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Fulani ló di mùsùlùmí ni òpin ẹgbẹru ọdun méjìdínlógún. Akitiyan wọn nínú ẹ̀sìn yìí láti tàn-án ka ló mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Wum dí ẹlẹ́sìn mùsùlùmí.




#Article 146: Yaka (113 words)


Ní gúsu apa iwo oòrùn Congo ti Zaire àti ní Angola ni àwon ènìyàn Yaka wà. òké méjìdínlógún (300.000) ni wón tó níye. Lára àwon aládúgbò won ni Suku, Teke àti Nkanu.’ 

Itan àtenudénu fìdí rè múlè pé àwon ènìyàn Yaka pèlú Suku jé ara àwon tí ó kógun ja ìlú ńlá Kongo ni egbèrún odún kerìndínlógún. Suku ti je òkan lára kéréjé èyà tó wà lábé Yakà rí./ Nípa síse ode ni ònà tí àwon okùnrin Yaka n gbà sapé won láti gbe ètò orò ajé. ‘Ajá ode sì jé ohun ìní pàtàkì láàrin àwon Yaka. Àgbe ni àwon obìnrin Yaka, wón si ma ń gbìn ègé, ànànmó, èwà àti erèé míràn.




#Article 147: Zulu (132 words)


Àwọn ènìyàn Zulu ni ẹ̀yà tó pọ̀jù ni orílè-èdè Gúúsù Áfríkà. A mọ̀ wọ́n mọ́ ìlẹ̀kẹ̀ alárànbàrà àti agbọ̀n pẹ̀lú àwọn ñǹkan gbígbẹ́. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn jẹ́ ìran tó sẹ̀ lára olóyè kan láti agbègbè Cóńgò, ni ñǹkan ẹgbẹ̀rún ọdùn mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọn tẹ̀síwájú sí Gúsú. Àwọn ènìyàn Zulu gbàgbọ́ nínú òrìṣà tó ń jẹ́ Nkulunkulu gẹ̀gẹ́ bí asẹ̀dá wọn òrishà yìí ko ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìfẹ́ sí ìgbé ayé kọ̀ọ̀kan. Awọn ènìyàn Zulu pin sí méjì! àwọn ìlàjì ni inú ìlù nígbà tí àwọn ìlàjì yókù sì wà ní ìgberíko tí wọ́n ń ṣisẹ́ àgbẹ̀. Mílíònù mẹ́sàn-án ènìyàn ló ń sọ èdè Zulu. Èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ìjọba mọ́kànlá ilẹ̀ South Africa. Àkọtọ Rómàniù ni wọ́n fi ń kọ èdè náà.




#Article 148: Ilẹ̀ Yorùbá (1278 words)


Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè ìgbéró àsà ilẹ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ní Ìwọ̀òrùn Áfríkà. Ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ láti Nàìjíríà, Benin títídé Togo, agbègbè ilẹ̀ Yorùbá fẹ̀ tó 142,114 km2 106,016 km2 inú rẹ̀ (74.6%) bọ́sí Nàìjíríà, 18.9% bósí orílẹ̀-èdè Benin, àti 6.5% yìókù bósí orílẹ̀-èdè Togo. Ilẹ̀ ìgbéró àsà Yorùbá yìí ní iye àwọn ènìyàn bíi mílíọ́nù 55.

 

	
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Àtàndá (1980), bí àwọn Yorùbá ṣe dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àsìkò tí wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀ kíi ṣe ìbéèrè tí ẹnikẹ́ni lè dáhùn ní pàtó nítorí pé àwọn baba nlá wọn kò fi àkọsílẹ̀ ìṣe àti ìtàn wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjogúnbá. 
	
Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí a gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá yàtọ̀ sí ara wọn díẹ̀díẹ̀. Ìtàn kan sọ fún wa pé àwọn Yorùbá ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀ àti láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé. Ìtàn ọ̀rùn pé kí ó wá ṣẹ̀dá ayé àti àwọn ènìyàn inú rẹ̀. Ìtàn náà sọ fún wa pé Odùduwà sọ̀kalẹ̀ sí Ilé-Ifẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Wọ́n sì ṣe iṣẹ́ tí Olódùmarè rán wọn ní àṣepé. Nípasẹ̀ ìtàn yìí, a lè sọ pé Ilé-Ifẹ̀ ní àwọn Yorùbá ti ṣẹ̀, àti pàápàá gbogbo ènìyàn àgbáyé. 
	
Ìtàn mìíràn tí a tún gbọ́ sọ fún wa pé àwọn Yorùbá wá Ilé-Ifẹ̀ láti ilẹ̀ Mẹ́kà lábẹ́ àkóso Odùduwà nígbà tí ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ Arébíà lẹ́yìn tí ẹ̀sìn Islam dé sáàrin àwọn ènìyàn agbègbè náà. Àwọn onímọ̀ kan nípa ìtàn ti yẹ ìtàn yìí wò fínnífínní, wọ́n sì gbà wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe é ṣe kí àwọn Yorùbá ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Mẹ́kà àti agbègbè Arébíà mìíràn kí wọ́n tó ṣí kúrò,  ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá gan-an ni íjíbítì tàbí Núbíà. Àwọn onímọ̀ yìí náà gbà pé Odùduwà ni ó jẹ́ olórí fún àwọn ènìyàn yìí. 
	
Kókó pàtàkì kan tí a rí dìmú ni pé Odùduwà ni olùdarí àwọn ènìyàn tí ó wá láti tẹ̀dó sí Ilé-Ìfẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn méjéèjì tí a gbọ́ ṣe sọ. Tí a bá yẹ ìtàn méjéèjì wò, a ó rí i pé kò ṣe é ṣe kí Odùduwà méjèèjì jẹ́ ẹnìkan náà nítorí pé àsìkò tàbí ọdún tí ó wà láàrin ìṣẹ̀dá ayé àti àsìkò tí ẹ̀sìn Islam dé jìnna púpọ̀ sí ara wọn. Nítorí ìdí èyí a lè gbà pé nínú ìtàn kejì ni Odùduwà ti kópa. Ìdí mìíràn tí a fi lè fara mọ́ ìtàn kèjì ni pé lẹ́yìn àyẹ̀wò sí ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá fínnífínní, ó hàn gbangba pé Odùduwà bá àwọn ẹ̀dá Olọ́run kan ní Ilé-Ifẹ̀ nígbà tí ó dé ibẹ̀. Àwọn ìtàn kan dárúkọ Àgbọnmìrègún tí Odùduwà bá ní Ilé-Ifẹ̀. Èyí fihàn pé kìí ṣe òfìfò ní ó ba Ilé-Ifẹ̀, bí kò ṣe pé àwọn kan wà níbẹ̀  pẹ̀lú Àgbọnmìrègún. Èyí sì tọ́ka sí i pé a ti ṣẹ̀dá àwọ̣n ènìyàn kí ọ̀rọ̀ Odùduwà tó jẹ yọ, nítorí náà, kò lè jẹ́ Odùduwà yìí ni Olódùmarè rán wá láti ṣẹ̀dá ayé gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ọ nínú ìtàn ìṣẹ̀dá. 
	
Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, a rí ẹ̀rí nínú ìtàn pé Odùduwà níláti gbé ìjà ko àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan tí ó bá ní Ilé-Ifẹ̀ láti gba ilẹ̀, àti pàápáà láti jẹ́ olórí níbẹ̀. Ìtàn Mọ́remí àjàṣorò tí ó fi ẹ̀tàn àti ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kan ṣoṣo tí ó bí gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìmúnisìn àwọn ẹ̀yà Ùgbò lè jẹ̀ ẹ̀rí tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odùduwà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun kí wọ́n tó le gba àkóso ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn  kan tí wọ́n bá ní Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àbáláyé ti sọ. 
	
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́. 
	
Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 
	
Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́. 
	
Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀. 
	
Lábẹ́ àwọn olórí ìlú wọ̀nyí ni a tún ti rí àwọn olóyè orísìírísìí tí wọ́n ní isẹ́ tí wọ́n ń se láàrín ìlú, ẹgbẹ́, tàbí ìjọ (ẹ̀ṣìn). Lára irú àwọn oyè bẹ́ẹ̀ ni a ti rí oyè àjẹwọ̀, oyè ogun, oyè àfidánilọ́lá, oyè ẹgbẹ́, oyè ẹ̀ṣìn àti oyè ti agboolé bíi Baálé, Ìyáálé, Akéwejẹ̀, Olórí ọmọ-osú, Ìyá Èwe Améréyá, Mọ́gàjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

	
Ní báyìí, tí a bá wo èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ pín èdè náà sábẹ́ ẹ̀yà Kwa nínú ẹbí èdè Niger-Congo. Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀yà Kwa yìí ló wọ́pọ̀ jùlọ ní sísọ, ní ìwọ̀ oòrùn aláwọ̀ dúdú fún ẹgbẹ̣ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn onímọ̀ èdè kan tilẹ̀ ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé láti orírun kan náà ni àwọn èdè bí Yorùbá, Kru, Banle, Twi, Ga, Ewe, Fon, Edo, Nupe, Igbo, Idoma, Efik àti Ijaw ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa gẹ́gẹ́ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dúró láti bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọ̀dún sẹ́yìn. 
	
Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èdè Yorùbá. Àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè rí àwọn tó n sọ èdè Yorùbá nílẹ̀ Nàìjíríà norílẹ̀ èdè Bìní. Tógò àti apá kan ní Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà bí i Cuba, Brasil, Haiti, àti Trinidad. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, òwò ẹrú ni ó gbé àwọn ẹ̀yà Yorùbá dé ibẹ̀. 

	
Ìràn Yorùbá jẹ́ ìran tó ti ní àṣà kí Òyìnbó tó mú àṣà tiwọn dé. Ètò ìsèlú àti ètò àwùjọ wọn mọ́yán lórí. Wọ́n ní ìgbàtbọ́ nínú Ọlọ́run àti òrìṣà, ètò ọrọ̀ ajé wọn múnádóko. 
	
Yorùbá ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti fi ọmọ fọ́kọ tàbí gbé ìyàwó.  Wọ́n ní ìlànà tó sọ bí a se n sọmọ lórúkọ àti irú orúkọ tí a le sọ ọmọ torí pé ilé là á wò, kí a tó sọmọ lórúkọ. Ìlànà àti ètò wà tí wọ́n ń tẹ̀lé láti sin ara wọn tó papòdà. Oríìsírísìí ni ọ̀nà tí Yorùbá máa ń gbá láti ran wọn lọ́wọ́, èyí sì ni à ń pè àṣà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́. Àáró, ìgbẹ́ ọdún dídẹ, ìsingbà tàbí oko olówó, Gbàmí-o-ràmí àti Èésú tàbí Èsúsú jẹ́ ọ̀nà ìràn-ara-ẹni-lọ́wọ́. 
	
Yorùbá jẹ́ ìran tó kónimọ́ra. Gbogbo nǹkan wọn sì ló létò. Gbogbo ìgbésí ayé wọn ló wà létòlétò, èyí ló mú kí àwùjọ Yorùbá láyé ọjọ́un jẹ́ àwùjọ ìfọ̀kànbalẹ̀, àlàáfíà àti ìtẹ̀síwájú. Àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ètò ìbágbépọ̀ láwùjọ Yorùbá ní ẹ̀kọ́-ilé, ètò-ìdílé, ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tàbí irọ̀sírọ̀. Ẹ̀kọ́ abínimọ́, àwòse, erémọdé, ìsírò, ìkini, ìwà ọmọlúàbí, èèwọ̀, òwe Yorùbá, ìtàn àti àlọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́-ilé. Nínú ètò mọ̀lẹ́bí lati rí Baálé, ìyáálé Ilé, Ọkùnrin Ilé, Obìnrin Ilé, Ọbàkan, Iyèkan, Ẹrúbílé àti Àràbátan. 
	
Oríṣìíríṣìí oúnjẹ tó ń fún ni lókun, èyí tó ń seni lóore àti oúnjẹ amúnidàgbà ni ìràn Odùduwà ní ní ìkáwọ́. Díẹ̀ lára wọn ni iyán, ọkà, ẹ̀kọ, mọ́ínmọ́ín àti gúgúrú. 
 

Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá, Ilé-Ẹ̀kọ́ Gíga ti Àwọn Olùkọ́ni Àgbà tí ó jẹ́ ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Osíẹ̀lẹ̀, Abẹ́òkúta (2005): Ọgbọ́n Ìkọ́ni, Ìwádìí àti Àṣà Yorùbá. 




#Article 149: Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (205 words)


Orílẹ̀-Èdè Yorùbá
	
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ènìyàn Yorùbá wà káàkiri ìpínlẹ̀ bí i mẹ́sàn-án. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Ẹdó, Èkó, Èkìtí, Kogí, Kúwárà, Ògùn, Òndò, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́. 
	
Lóde òní, Yorùbá wà káàkiri ilẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú (Áfíríkà), Amẹ́ríkà àti káàkiri àwọn erékùsù tí ó yí òkun Àtìlántíìkì ká. Ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. A le ríwọn ní Nàìjíríà, Gáná, Orílẹ̀-Olómìnira Bẹ̀nẹ̀, Tógò, Sàró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti àwọn erékùsù káàkiri, a lè rí wọn ní jàmáíkà, Kúbà, Trínídáádì àti Tòbégò pẹ̀lú Bùràsíìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 
	
Yàtọ̀ sí ètò ìjọba olósèlú àwarawa tí ó fi gómìnà jẹ olórí ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a tún ní àwọn ọba aládé káàkiri àwọn ìlú nlánlá tí ó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára wọn ni Ọba ìbíní, Ọba Èkó, Èwí tí Adó-Èkìtì, Òbáró ti Òkéné, Aláké tí Abẹ́òkúta, Dèji ti Àkúrẹ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Àtá-Ója ti Òṣogbo, Sọ̀ún ti Ògbòmọ̀ṣọ́ ati Aláàfin ti Ọ̀yọ́. 
	
Baálẹ̀ ní tirẹ̀ jẹ́ olórí ìlú kékeré tàbí abúlé. Ètò ni ó sọ wọ́n di olórí ìlú kéréje nítorí pé Yorùbá gbàgbọ́ pé ìlú kìí kéré kí wọ́n má nìí àgbà tàbí olórí. Aláàfin ni a kọ́kọ́ gbọ́ pé ó sọ àwọn olórí báyìí di olóyè tí a mọ̀ sí baálẹ̀. 
	




#Article 150: Ìfitónilétí (2593 words)


Informatics (Ifitonileti)

OWOLABANI JAMES AHISU	ati	
AKINDIPE OLUWABUNMI TOPE	

	Ètò Gírámà

	Ìfáàrà

						(Jọ́ọ̀nù 1:1)

Kì í ṣe ohun tó dájú ni pé akẹ́kọ̀ó èdè kọ̀ọ̀kan yóò jiyàn pé ọ̀rọ̀ ni wúnrèn ìpìlẹ̣̀ fún ìtúpalẹ̀ nínú àwọn gírámà. A lè yígbà yígbà kí a wádìí lítítésọ̀ fún àríyànjiyàn lórí mọ́fíìmù, sùgbọ́n léyìn gbogbo atótónu yìí, kí ni a rí? Ṣé ó lẹ́ni tó n sọ mófíìmù tó dáwà tí wọn kìí sìí ṣe ọ̀rò fúnra wọn? kí ni ó wà nínú ọ̀rò–sísọ tó ní ìtumọ̀? Kí ni àwọn ìdánudúró fún gbólóhùn? Ọ̀rọ̀ ni àárín, inú, àti àwọn ìbẹ̀rè ọ̀rọ̣̣̣̀.àjòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀, kódà fóníìmù pẹ̀lú kò lè dá dúró tí kò bá ti lè làdì sí ìtumọ̀ nínú ọ̀rọ̀. Ní àtètèkọ́ṣe ni ọ̀rọ̀ wà. Ó wà níbẹ̀ láti dá ayé ọfọ̀ sílẹ̀, láti mọ àti láti tún ọ̀rò–sísọ mọ, láti fikún, láti yọ kúrò àti láti mú yẹ ní oríṣìíríṣị ọ̀nà.

Ẹ jẹ́ kí á padà kúrò ní àníjẹ́ ìmọ́ wa lọ sí ajúwè nínú gírámà; ètò rẹ̀ ìlànà ìfojú- ààtò-wò àti àlàyé rẹ̀. Fífi ojú gbogbo ayé wo gírámà, a máa ṣe àpèjúwe ètò gírámà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀, ní pàtàkì pèlú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá kí a sì fi àpéjọ àwọn ènìyàn tí n gbọ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ láti dásí ìfihàn nípa títẹríba fún èrò ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún ìtúpalẹ̀ ní èdè tirẹ̣̀, èdè ènìyàn mìíran. Àkíyèsí ni pé tí èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá, àwọn èdè tí kò tàn mọ́ra wọn tó gbilẹ̀, ni a lè tún ṣe àtúnṣe rẹ̀ sí àwọn òfin tí a ti gbìmọ̀ wọn níbí, ó ṣe é ṣe kí àwọn nnkan tí à n rò jẹ́ òtítọ́, kí ó sì sisẹ́ fún èdè mìíràn títí dé àwọn àbùdá àìròtẹ́lẹ̀ àwọn èdè kan. Bí ẹ̀fè yẹn kò bá mú ìbàjẹ́ wá, à á ṣe àtúnwí àbá kan náà pẹ̀lú èyí: àwọn tí wọn kò gba èyí gbọ́dọ̀ mọ̀ nínú wọn pé nígbà tí wón bá n ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn èdè wọn ni àwọn èrò yìí, èrò yìí ni a máa ṣe atótónu wa tí ó kún lórí rẹ̀ fún àpẹẹrẹ èdè Yorùbá, ‘Hausa’, èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè ‘Ibibio’… àwọn èdè tí a kójọ pèlú ìyàtọ̀ ni wọ́n ní ìbáṣepọ̀ kankan nítorí pé wọ́n jẹ́ èdè ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, tí a bá fi ọwọ́ gírámà kan náà mú wọn, à n sọ pé wón ní ìjọra, bí ọkùnrin elédè Gẹ̀ẹ́sì ṣe jọ ọkùnrin elédè Yorùbá kan, tí ìyàtọ̀ wọn sì jẹ́ ti àwọ̀ wọn.
Ìyókù orí yìí yóò mú wa wà ní ìmúra sílẹ̀ láti rí ìdí tí àwọn onímọ̀ èdè fi n kóòdù àwon ìtúpalẹ̀ wọn bí wọ́n bí wọ́n ṣe n ṣe.

Fífún àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lédè Gẹ̀ẹ́sì:

̣Olè, 		ṣíbí, 		tábìlì, 		òṣùká, 	téèpù,

ẹni tó rí sọ Gẹ̀ẹ́sì kò ni ní wàhálà nípa ṣíṣẹ̀dá:

	Àwọn ṣíbí, àwọn tábìlì, àwọn òṣùká, àwọn téèpù.

Ó ti pinu ní ọkàn rẹ̀ láti mọ ìsọdorúkọ àwọn ọ̀rò náà àti àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ (Latin: nomen ‘name’) ̣ni a lè sọ di ọ̀pọ̀ ----- àwọn àpẹẹrẹ pọ̀ nípa àwon nnkan ti a sọ lórúkọ. Nípa ti iye ìtẹ̀sí rẹ̀, a lè fi àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn bí i kan tàbí náà kún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rò náà. Yíyéni láì ṣàlàyé tóbẹ́ ẹ̀ jùbé ẹ̀ lọ gírámà rẹ̀ ni gbìmọ̀ tíórì kan pé kí gbogbo àwọn ọ̀rò orúkọ gba àwọn átíkù kan tàbí náà. Lára àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ni ó jẹ́ pé átíkù wo ni ó síwájú tí ó sì tẹ̀lẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì nínú ìwé tí à n kà lọ́wó láti túmọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó dá yàtọ̀ nípa:

ṣíbí náà ~ ṣíbí kan

Ohùn kan tó tún dìjú ni pé, nígbà tí a bá mú ìkan lára àwọn átíkù wọ̀nyí, ní dandan ọ̀kan lára àwọn tó lè dá dúró tí a pín sí abẹ́ ọ̀rò orúkọ̣ ̣̣̣̣gbọ́dọ̀ tẹ̀le, ṣùgbọ́n kì í ṣe dandan kí sísọ ọ̀rọ̀ jẹ́ òotọ́! Ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀, à n tẹ̀ síwájú láti sọ pé bí a bá ní ọ̀rọ̀ kan, ohun mìíràn, tí ó wá láti ìpín mìíràn, lè tẹ̀le tàbí kí ó máa tẹ̀le, nínú síntáàsì, a máa n lo ọ̀nà mìíràn làti sọ pé:

Ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ X ni a pín g̣ẹ́gẹ́ bí Y àti pé ó lè jẹyọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Z, Z jẹ́ ọ̀rò kan tí ó lè wà tàbí kí ó má wà nílé nígbà náà. Tí a bá n fojú iṣẹ́ ọnà wò ó ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ X ni ìpín onítumọ̀ àdámọ̀ (ìsọ̀rí ọ̀rọ̀) Y ní abgègbè tó saajú òrọ̀mìíràn Z, wíwá níbẹ̀ Z jẹ́ wọ̀fún. Àkọsílẹ̀ afòyemọ̀ tí òkè yìí ni à n pè ní àpíntúnpín sí ìsòrí tó múná dóko ni a jíròrò lè lórí nínú Yusuf (1997).
Tí a bá padà sí àwọn àpẹẹrẹ (1,2) ti òkẹ̀, ẹni tí n sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe lè mọ àwọn tí ó dá dúró yìí to jẹ́ ọ̀rò orukọ tí o lè wà ní ipò tó ṣe kóko; olùwà àti àbọ̀. Lára àwọn ìmọ̀ rẹ̀ nípa àwon òrò wònyí ni pé a lè fún wón ni àwon ipa kan láti kó; tí a bá ní ká wò ó kí ni ìwúlò wọn tí wọn kò bá kó ipa kankan ní àyíká gbólóhùn tàbí ọfọ̀ wọn. Fún àpẹẹrẹ, olè kan jé ̣òṣèré, olùkópa tí ó bá kópa níhìnìn tàbí òhún láti mú àpíyadà wá. Nígbà tí ó bá n ṣerè, a mọ̀ pé ó lè jalè. Kódà kì í ṣe olè tí a kò bá mọ̀ ọ́ sí ẹni tó jí nnkan kan nítorí nínú gbólóhùn bí i.

Ọ̀rò náà tó jẹ́ ‘ole’ sọ ohun tó pọ̀. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó mú náà, tójẹ átíkù, ó lè yàtọ̀ fún oye àwọn olè àti pé ó jẹ ÒṢÈRÉ nínú àyè ọfọ̀ tó lè mú ìyípadà bá ìfarasin kálámù náà.
Rántí pé ọ̀rọ̀ náà ‘kálámù’ wà ní ìsọ̀rí yìí náà pẹ̀lú; ó máa gba átíkù náà/kan tí a lè gbékalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ (àwon kálámù) àti pé a fẹ́ fà á yọ, gẹ́gẹ́ bí àwon ojúgbà rẹ̀, wí pé ó jẹ́ olùkópa ní àyíká gbólóhùn náà sùgbọ́n ní báyìí ó n kó ipa ohun tí wón jí, ipa náà ni a máa pè ni ÀKỌ́SO. Ọpọlọ wa so fún wa pé kálámù kan lè jẹ́ ohun ÈLÒ fún ìbánisọ̀rọ̀. Àwon ipa náà, tí àwon álífábẹ́tì nlá dúró fún ni à n pè ní Àwon ipa aṣekókó, a lè gé e kúrú sí ‘Theta – roles’, tí wón máa n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ‘Ø roles’, bí ìtẹ̀síwájú bá ṣe n bá ìtúpalẹ wa. Ko lè sí ohun ìtọ́kasí tó dúró, àwon olùkópa kan tí a lè tọ̀ka sí, nawọ́ sí, dárúkọ, sọ̀rọ̀ nípa, tí kò ní gba ‘Ø role’ kan. Àwon àjọ̣ni tí a sábà náa n rí ‘Ø roles’ jẹ OLÙṢE, OLÙFARAGBA, (nígbà mìíràn tí a máà n pè ni Àkọ́so), ÒPIN àti ÈLÒ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwon onímọ̀ lìngúísíìkì mọ àwọn mìíràn dájú.

Àwọn àbùbá àdámọ́ ọ̀rò wà tí a lè tọ́ka sí báyìí. Àwọn àbùdá mìíràn máa hàn kedere tí a bá gbé èdè tó yàtọ̀ sí èyí tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ỵẹ̀wò. Nítòótọ́, a máa sọ pé ìwúlò wò ni ó wà nínú kí a máa sọ̀rọ̀ nípa àwon ohun tí a kò rí nínú èdè wa! Ìkìlò: À n sọ̀rò nípa àwọn àbùdá tó wà nínú èdè ènìyàn, kì í kan n se nínú ẹ̀dẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí èdè Yorùbá. Rántí ohun tí a rò nípa Gírámà Àgbáyé, Èdè Gẹ̀ésì, èdè Ìgbò, èdè ‘Eskimo’, èdẹ̀ ‘Japan’…….. jẹ́ díẹ̀ lará èdè ènìyàn tí wón sì ní àwọn ìyàtọ̀ wọn, nínú ohun tó ṣe kókó báyìí, fífún àwọn ọ̀rò aṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ asẹ̀dá bí ị Ọ̀PÒ ‘Ø role’, àwon ipò onítumọ̀ gírámạ̀, abbl.

Ẹ jé ̣kí á fi àbùdá kan kún àwon àpẹẹrẹ wa. Àwon ọ̀rọ̀ náà ni a lè yí padà. Ní bẹ́è à á ní:

b.	Ògbójú olè kan

d.	Igi oaku kan

e.	Téèpù mímọ́gaara kan

ẹ.	Ife kan tó kún fún kọfị́ ̣

f.	Òṣùká kan fún ìbọ̀sẹ̀ aré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá

Àwon wònyí jẹ́ àwọn ẹ̀pọ́n tó jẹ̀ wí pé bí a bá yọ wọ́n kúrò ìtumọ̀ àwon ọ̀rò náa kò ní dínkù (ìsomó)̣. Àwọn àkámọ́ tí a lò nínú àpíntínpín sí ìsọ̀rí tó múná dóko àti àwọn tí a fihàn ní orí kìíní, ni a lè lò báyìí, bí i (T).

b.	téèpù (mímógaara) kan

c.	Ọkùnrin (alágbára) kan.

Àwon ohun tí a fi sínú àkámọ́ ni à n pè ní àwon ìsomọ́, wọn kò ní apíntúnpín sí ìsọ̀rí, wọn kì í ṣe dandan, wọ́n jẹ ẹ̀pọ́n –ọn wọ̀fún. Nígbà tí àwon wònyí tún wúlò níbò mìíràn, a fẹ yán an pé kìí ṣe gbogbo àwọn ẹ̀pọ́n ló jẹ́ wọ̀fún. Kódà nígbà tí wọn kò bá ní ìtumọ̀ àdámò wọ́n wúlò. Fún àpẹẹrẹ, ọba tàbí olorì kò níyì bí ọba tí wọn kò bá ní ìjọba tiwọn. ní bẹ́ẹ̀ a ní:

b.̣ ̣	òbí ti Agbor

d.	Ọba àwon Júù

Kódà Ọba bìnrin ‘Elibabeth’ tí ó tó láti ṣe ìtóka ni a mọ̀ pé ó ní agbára lórí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àkíyèsí pé láti sọ pé Oba bìnrin náà, láà jẹ́ pé ènìyàn n gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí tí iyè rẹ̀ sọ pèlú oríle – èdè náà, máà ṣàì nítumọ̀. Orúkọ àbísọ lè tó láti mọ àwọn orí oyè, ṣùgbọ́n ìjọba wọn tí se pàtàkì jù, ẹ̀pọ́n wọ̀fun. Àwọn ẹ̀pọ́n ni à n pè ní Àwọn Àfikún. Ní kúkúrú, àwọn ẹ̀pọ́n PP ti ọba àti ọba àti ọba jẹ wúnrẹ̀n tí a ní lò.
 

Àwon ọ̀rọ̀, tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí i àwon ọ̀rò orúkọ, gba àwọn nnkan mìíràn mọ́ra dandan, ‘DET’, Àwon ipa aṣekókó, ÌSỌDỌ̀PỌ̀, àwọn kan– npá àti wòfún (ákámọ́), àwon Àfikún àti àwon Ìsomọ́ bákan náà, àti àwon mìíràn tí a kò mẹ́nu bà. Àwon àbùdá àdámọ̀ ti olùsọ èdè rẹ̀ gbọ́dọ̣̀ mọ̀ ni àwon wònyí. Ó jẹ́ dandan pé ó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀, lára èyí tí a máa sọ tó bá yá ní ìfìwàwẹ̀dá. A fẹ́ jẹ kí àwon akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé àwon nnkan wònyí jẹ́ àìkọ́, lára àwon akówọ̀ó rìn UG nínú àká – ọ̀rò náà (atúmò èdè tí iyè náà). A mẹ́nu bà á pé àwon nnkan wònyí kìí hànde bákan náà, sùgbọ́n ó lè gbọ́n fara sin sínú àwon kóòdù mofọ́lójì nínú ọ̀rò náà, ní àwon àyíká tí a kò funra sí.

Àwon àkójọpọ̀ àwon ọ̀rò tó yàtọ̀ sí ti àkọ́kó máa fún wa ni àwon nnkan. Ẹ jẹ kí a mu àwon ọ̀rọ̀ tó n sọ nípa àwon ọ̀rò orúkọ.

fún àwon elédè Gẹ̀ẹ́sì, àwon ọ̀rọ̀ wònyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe (Latin: verbum ‘Word’), won le fi àsìkò ìsẹ̀lẹ̀ hàn nípa gbígba àwon àfòmọ́:

kill: 		kills, 		killed, 			killing.

X		X-s 	X-ed 			X-ing.

Àwon gẹ́gẹ́ bí àwon òrò orúkọ lè gba àwon àbọ̀ àwon kan wòfún ni (àwon ọ̀rò ise agbàbò) nígbà mìíràn ó jé wọ̀fún nígbà tí wọ́n bá jẹ́ aláìgbàbọ̀ ṣùgbọ́n tí won bá gbà àwọn àbọ̀ tan, tàbí kí won máà gba àwon ìsomó kankan.

	3.	eat 	(NP)

		kill 	(NP)

		drink (NP)

			[+ liquid].

Àwon ìsomọ́ máa n borí àwon àpólà (tí ó lè jẹ eyọ ọ̀rò kan ṣoṣ̣o) sí àwon àpólà orúkọ̀. Níbí ni a ṣe àpèjúwe ránpẹ́ nípa àwọn Àfikún ọ̀rọ̀ ìṣe sí.

	4a:	eat		 ([NP an unripe mango])

	b.	destroy 	 [NP the termitarium]

	c.	said 		 [s. that [s the NBA examination is 

	d.	put 		[x [NP salt] [pp in the soap

	e.	saw 		[NP Mọ́remí].

Àwon ọ̀rò ìse aláìgbàbọ̀ ni a máa fihàn nísàlẹ̀, pélù àwon ìsomọ́.

b.	Sùn síjòkó èyìn ọ̀kọ̀

d.	La àlá

e.	Kú.

Nígbà tí àwon yìí kò gba àwon àfikún, wón lè, nípa ìgba àkànṣe gba àwọn àbọ̀ - àwon àbọ̀ àkànse tí a so mọ wọn tàbí tí a sèdá láti ara won. Wón fẹjọ́ Èsù sọ nínú Bíbélì pé ó n gba Éfà níyànjú láti ma bẹ̀rù nípa jíjẹ èso èèwọ̀, tó wí pé, “Èyin kò ní kú kan”. Èṣù kò nílò àti yí ọ̀rọ̀ ìse aláìgbàbò sí agbàbọ̀

Nitóri pé wọ́n n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rò orúkọ wọ́n fi àwọn nnkan pamọ́ lórí àwọn irú ọ̀rọ̀ orúkọ (kódà yíyípadà) ní àwọn èdè kan. Èdè Gẹ̀ẹ́ṣì kìí ṣe àpẹẹrẹ tó dára nípa bí ọ̀rọ̀ ìṣe ṣe lè yí ọ̀rọ̀ roúkọ tí a bá wẹ̀yìn, ipa aṣekókó ÒṢÈRẸ́, ÀKỌ́SO, ÈLÒ, abbl wá tààrà tàbí àìṣetààrà láti ara ọ̀rọ̀ ìṣẹ. Fún àpẹẹrẹ alè máà ri sùgbón a mọ̀ pé N kan náà (nítòótọ́ NP) ni ó n kú nínú:

Olè náà ni olú pa
Àti pé kò sí àníàní, NP kan náà tó fa ikú bó tilẹ̀ jé ̣pé ìtò gẹ́gẹ́ ní àwon olùkópa nínú gbólóhùn méjèèjì wà. Fún bẹ́ẹ̀ Olú ni ÒṢÈRÉ nínú gbólóhùn méjèèjì nígbà tí Olè náà jẹ́ Àkọ́so nínú méjèèjì bákan náà.
A lè sọ̀rò nípa àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rò mìíràn, tó yàtọ̀ sí Àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ àti àwọn ọ̀rò ìse, sùgbón ẹ jẹ́ kí á padá séyìn láti wo àwon ìjíròrò wa fún ìbáramu. À n sọ pé ọ̀rò kòòkan, bó jé ọ̀rò orúkọ tàbí òrọ̀ ìse, máa ṇ̣̣̣ wá pẹ̀lú àwọn nnkan. Nínú ìbásepò wọn, àwon òrò náà n sisẹ́ lórí ara wọn to fi jẹ́ pé àwon ọ̀wò kan a gbà àwọn mìíràn yóò sì fún wọn ní àwọn àbùdá kan. Ọ̀rò orúkọ náà, tó máa n jé olùkópa, kìí ṣe ÒSÈRÉ tàbí ÀKÓSO tí òrò kò bá fún wọn ní irú ipa béè. Nínú ọ̀rò – èdè tí ayé (tí a gbé wọnú gírámà) òrò ìse tó n darí àbọ̀ APOR rẹ̀ fún ìdí èyí, ọ́ n fún ní isẹ́ (ní báyìí, Ø role nìkan, àmó ó lè se àyànse àwon àwòmọ́ mìị́ràn).

Gẹ́gẹ́ bí olùsọ èdè ṣe nu ìmọ̀ nípa àwọn nnkan wònyí láìkọ́ tí ó sì jẹ pé dandan ni ó n tẹ̀lẹ́ àwọn ofin yìí, ṣe a kò lè sọ pé àwon ọgbọ́n ẹ̀tọ̀ yìí jẹ́ abínibí gẹ́gẹ́ bí mímí ṣe jẹ? 

Ìwọ̀n mìíran nì a ti menu bà tẹ́lè, nípa ọ̀rò náà, ohun náà ní pé kìí jẹyọ ní dídáwà. Olè di Olè náà, ògbójú Olè náà, ògbójú alágbára Olè náà pẹ̀lú ìwo, abbl. Àwon àlèpọ̀ òrò náà sí àwọn ọ̀wọ́ tí ó tóbi pẹ̀lú ìrànlówọ́ àwọn ohun tí a pè ní àwon àpólà. Nítorí pé àárín òrò, òrò gangan tí a bá túnṣe nì yóò dúró fún odidi àpólà, a máa n pé irú won ni Ori. Ni a se máa rí i, òrò orúkọ ní ó máa n jé orí fún Apólà orúkọ (APOR), òrò ìse fún Àpólà ìse (APIS), òrò àpèjúwe fún Àpólà àpèjúwe (APAJ)….,X tàbí Y tún àpólà X (XP) àti àpólà Y (YP) bákan náà.
Lẹ́èkan sí, ká wò ó pé olùsọ èka –èdè rè mọ púpò nípa rè. Yorùbá máa mọ̀ mọ̀ pé ọmọ ‘child’ ni a lè tó àwon òrò èpón mọ́ bi i ọmọ kékeré ‘small child’̣, ọmọ baba Ìbàdàn ‘the child of the man from Ìbàdàn’ tàbí ọmọ náà “the child” kò di dandan, àti pé kódà, wọn kò tí ì kọ̀ ní àwon àtòpọ̀ yìí rí. Àti wí pé ọpọlọ tí olùsọ ẹ̀ka–èdè yìí n lo ni a fẹ́ gbéyẹ̀wò nínú gírámà, Akitiyan láti mọ ohun tí ó mọ̀ láì kó. Se kò pani lérìn-ín, olùsọ èka – èdè, tàbí ọmọdé kan n kó àwọn orímò èdá–èdè kò ní ìtumọ̀ sùgbọ́n òótọ́ ni.

A ṣe àfiikún àwọn àpólà tí a kó tí olùsọ èka–èdè lè lò pé kò ní ẹ̀kun ó sì peléke. Àwon iní ìhun béẹ̀ lè kún fún àwon èròjà wọ̀fún tí ó wọnú ara won. Sùgbón èyí kéyií tó bá ṣẹlè, àpólà gbọ́dọ̀ ní orí, títèlé àwon ohun tí òfin níní orí gbà, tí a pè ní ‘endocentricity requiremrnt’. Nítorí bẹ́ẹ̀tí a bá ní òrọ̀ kan W, ó gbọ́dọ̀ di W max tí a túpalẹ̀ ní síntáàsì gẹ́gẹ́ bí i WP (for W-Phrase) tàbí W” (W- double prime (=bar)).̣̣




#Article 151: Ẹ̀kó Ìjìnlẹ̀ nípa Ìfitónilétí (419 words)


OWOLABANI JAMES AHISU

Ẹ̀KÓ ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÌFITÓNILÉTÍ (INFORMATICS)

Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí n kọ́ nípa ètò, ìṣesí àti ìbáṣepọ̀ àwọn ìlànà adánidá àti ìfi-ọgbọ́n-se, tó n pamọ́, tó sì n ṣe ìyípàdà àti ìkójọ ìfitónilétí. Bákan náà, ní ó n sẹ̀dá àwọn ìpìnlẹ̀ ajẹmérò àti tíórì tirẹ. Láti ìgbà tí àwọn ẹ̀ro kọ̀mpútà, àwọn aládáni àti àwọn onílé-iṣé nlánlá tí n ṣe ìyípadà àwọn abala àwùjọ.
Ní ọdún 1957, Karl Steinbush tó jẹ́ orílẹ̀-èdè Germany, tí ó sì tún jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rọ kọ̀mpútà (1917-2005) kọ ìwé kan tí ó pè ní “Informatik: Automatisdie Informationsverarbeitung”) èyí tó túmọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì sí “Informatics: automatic information processing”) ohun ni a túmọ̀ ní èdè Yorùbá bí Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ìlànà ìlò ìfitónilétí tí kò yí padà. Ní òde-òní, “Informatik” ni wọ́n n lò dípo “Computerwissescraft” ni orílẹ̀-èdè Germany èyí tó túmọ̀ sí (Computer Science) ní èdè Gẹ̀ésì, tí ó sì túmọ̀ sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rò kọ̀mpútà ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa èkọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí. 
Bákan náà oríṣìírisìí àwọn onímọ̀ ìjìnlè nípa ẹ̀ro kọ̀mpútà láti àwọn orilẹ̀-èdè àgbáyé ni ó fún Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí ní oríkì tiwọn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ oríkì èyí wá láti orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ̣̣   
Informatics is the discipline of science which investigates the structure and properties (not specific content) of scientific information, as well as the regularities of scientific information activity, its theory, history, methodology and organization.  ̣
Èyí tó túmọ̀ sí:

Ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí jẹ́ ẹ̀ka kan lára ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó n wádìí nípa ètò àti àwon àkòónú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí, pẹ̀lú àwọn ìṣedédé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ọ́rì rẹ̀, ìtàn rẹ̀, ogbọ́n-`ikọ́ni àti ètò rẹ̀ pẹ̀lú.
	
Oríṣìíríṣi ni ó ti bá ìlò rẹ̀, ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ sí. Ìkíní ni pé ìyípadà tó bá ìmò, ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí ni wọ́n ti yọ kúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí ti ẹ̀kọ́ ìyìnlẹ́ nípa ìfitónilétí tó jẹmọ́ ètò ọrọ-ajé àti òfin ikejì ní, nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pò nínú àwọn ìfitónilétí yìí ni wọ́n ti n kó pamọ́ nílànà tòde-òní, ìdíyelé tí wá jẹ pàtàkì sí ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nipa ìfitónilétí Ìkéta jẹ́ ìlò àti ìbánisọ̀rọ̀ nípa ìfitónilétí tí a rò pọ̀ láti lò fún ìwádìí, nígbà tí ó jé pé wọ́n ti gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì sí ohun kóhun tó bá jẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.

Fún ìdí èyí ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ní àgbáyé, wọn kò fọwọ́ yẹpẹre mú ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí àti gbogbo ohun tó so mọ́ ọ  ̣̣




#Article 152: Ìmọ̀ Ẹ̀rọ (730 words)


Sàláwù Ìdáyàt Olúwakẹ́mi

ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ
	
Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ bí akò bá sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, a jẹ́ pé à ń rólé apá kan nìyẹn. Báwo ni a ó ò ṣe pé orí ajá tí a kò níí pe orí ìkòkò tí a fi ṣè é? ìmọ̀ sáyáǹsì ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ.  Sáyáǹsì ni yóò pèsè irinsé tí ìmọ̀ ẹ̀rọ máa lo láti fi se agbára. 
	
Ọ̀nà méjì ló yẹ kí á gbé àlàyé wa kà nígbà tí bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. 

	(1)	Ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé (Anciant technology) 

	(2)	Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé (Modern technology) 

	ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÀBÁLÁYÉ 
	
Ní ìgbà àwọn baba ńlá wa, tí ojú sì wà lórúnkún, ọ̀nà láti wá ojútùú sí ìsòro tó wà láwùjọ bóyá nípa ilẹ́ gbígbé, asọ wíwọ̀ oúnjẹ jíjẹ ló fà á tí àwọn baba ńlá wà fi máa ń lo ìmọ̀ sáyéǹsì tiwańtiwa láti sẹ̀dáa àwọn nǹkan àmúsagbára lásìkò náà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbà náà ló di iṣẹ́ ò òjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ń ṣe lásìkò náà. Ẹ jẹ́ ki á mú lọkọ̀ọ̀kan.

	Oúnjẹ jíjẹ

	Yorùbá bọ̀ wọ́n ní: 

	
Ìṣẹ́ àgbẹ̀ ni isẹ́ ìlè wà. Àwọn baba ńlá wa máa ń lo oríṣìíríṣìí irin ìṣẹ́ láti wá ohun jíjẹ lára wọn ni àdá, ọkọ́, agbọ̀n, akọ́rọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Iṣẹ́ Ọdẹ, 

Iṣẹ́ ọdẹ jẹ́ iṣẹ́ idabọ fún ìran Yorùbá. Ìdí ni péwu ló jẹ́ nígbà náà. Iṣẹ́ àgbẹ̀ gan an ni ojúlówó iṣẹ́ nígbà náà lára àwọn irin-iṣẹ́ tí àwọn ọdẹ máa ń lo ni, ọkọ́, àdá, ìbon, òògùn àti àwọn yòókù. 

	ASỌ WÍWÒ. 
	
Nígbà tí a ba jẹun yó tán, nǹkan tó kù láti ronú nípa rẹ̀ ni bí a oo se bo ìhòhò ara. Èyí ló fà á tí àwọn baba ńlá wa fi dọ́gbọ́n aṣọ híhun. 
	
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, awọ ẹran ni wọ́n ń dà bora lákòókó náà, ṣùgbọ́n wọn ní ọ̀kánjùá ń dàgbà ọgbọ́n ń rewájú ọgbọ́n tó rewájú ló fàá tí àwọn èèyàn fi dọ́gbọ́ aṣọ hihun lára òwú lóko. Láti ara aṣọ òfì, kíjìpá àti sányán ni aṣọ ìgbàlódé ti bẹ̀rẹ̀ ILÉ GBÍGBÉ. 
	
Bí a bá bo àsírí ara tán ó yẹ kí á rántí ibi fẹ̀yìn lélẹ̀ si. Inú ihò (Caves) la gbọ́ pé àwọn ẹni àárọ̀ ń fi orí pamọ́ sí í ṣùgbọ́n bí ìdàgbà sókè ṣe bẹ̀rẹ̀, ni àwọn èèyàn ń dá ọgbọ́n láti ara imọ̀ ọ̀pẹ, koríko àti ewéko láti fi kọ́ ilé. 

IṢẸ ARỌ́ (ALÁGBẸ̀DẸ)
	
Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ Yorùbá bí a kò mẹ́nu bà isẹ́ alágbẹ̀dẹ, a jẹ́ pé àlàyé wa kò kún tó. Iṣẹ́ arọ́ túmọ̀ sí kí a rọ nǹkan tuntun jáde fún ìwúlò ara wa. ọ̀pọ̀ nínú irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tí àwọn àgbẹ̀ ńlò ló jẹ́ pé àwọn alágbẹ̀dẹ́ ló máa ń ṣe e. Irinsẹ́ àwọn ọ̀mọ̀lé, ahunsọ, àwọn alágbẹ̀dẹ ni yóò rọ̀ọ́ jáde. Irinse àwọn ọdẹ, àwọn ọ̀mọ̀lé àwọn alágbẹ̀dẹ ló ń rọ gbogbo rẹ̀. 
	
Ìmọ̀ ẹ̀rọ gan-an lọ́dọ̀ àwọn alágbẹ̀dẹ ló ti bẹ̀rẹ̀. Tí a bá ṣe àtúpalẹ̀ Ẹ̀RỌ̣ yóò fún wa ni 

		ẹ 	-	mofiimu àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ 

		rọ 	-	ọ̀rọ̀-ìṣe adádúró 

		ẹ  	+	rọ ----  ẹrọ. 

	
Rírọ́ nǹkan ntun jáde ni èrọ ìmọ̀ sáyéǹsì gẹ́gẹ́ bí ń ṣe sọ ṣáájú ló bí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó yẹ kí á fi kun un pé, ọpọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ ti sún síwájú báyìí. Ìdí èyí ni pé ìmọ̀ ẹ̀rọ to ti ọ̀dọ̀ àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun wá ti gbalégboko. Àwọn ọ̀nà tí a ń gbà pèsè nǹkan rírọ ti yàtò báyìí. 

ÌMỌ̀ Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ 
	
Lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀làjú wọ agbo ilẹ́ Yorùbá ni ọ̀nà tí a ń gba ṣe nǹkan tó yàtọ̀. Ìmọ̀ ẹrọ àtòhúnrìnwá tí mú àyè rọrùn fún tilétoko. Ṣùgbọn ó yẹ kí á rántí pé ki àgbàdo tóó dáyé ohun kan ni adìyẹ ń jẹ. Àwọn nǹkan tí adìẹ ń jẹ náà lati ṣàlàyé nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àbáláyé. Iṣu ló parade tó diyán, àgbàdo parade ó di ẹ̀kọ. Ìlosíwájú ti dé bá imọ̀ ẹ̀rọ láwùjọ wa. Ẹ jẹ́ kí á wo ìlé kíkọ́ àwọn ohun èlò ìgbàlódé ti wà tí a le fi kọ́ ilé alájàmẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ. 
	
Ìmọ̀ ẹ̀rọ náà ló fáà tí àwọn mọ́tọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fi dáyé. Àwọn nǹkan amáyédẹrun gbogbo ni ó ti wà. Ẹ̀rọ móhùnmáwòrán, asọ̀rọ̀mágbèsì, ẹ̀rọ tí ń fẹ́ atẹgun (Fan), ẹ̀rọ to n fẹ́ tútù fẹ́ gbígbóná (air condition) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, alagbeeka, ẹ̀rọ kòmpútà, ẹ̀rọ alukálélukako (Internet). 
	




#Article 153: Oduduwa (1403 words)


Odùduwà jẹ́ kìí ṣe aláṣeẹ àtolùdarí ìran Yorùbá  òun tún ni gbòngbò kan pàtàkì tí ó  so ilẹ̀ Yorùbá ró láti  ilé Ife,  tí tí dé ibi kíbi tí wọ́n bá ti ń jẹ Ọba káàkàkiri ilẹ̀ Káàrọ̀ -oò -jíire pátá. Lára ìtàn tó fẹsẹ̀ Odùduwà múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá sọ wípé ó jẹ́ ọmọ ọbaáti ilẹ̀ Lárúbáwá tí wọ́n fogun lé kúrò nílùú baba rẹ̀ nílẹ̀ Mẹ́kà tí ó wá di Saudi Arabia lónìí. Látàrí ogun yìí ló jẹ́ kí ó gbéra ọ́un àtàwón ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tíbwọ̀n sìbfi rẹ̀dó sí ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà tí tí dònìí. Títẹ̀dó rẹ̀ náà kìí ṣe pẹ̀lú ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀, bí kọ́ ṣebogun tó gbóná janjan fún bí ọdún oúpọ̀ kí ó tó borí àwọn ẹ̀yà mẹ́tàlá kan tí ó bá ní Ifẹ̀ tí  Ọbàtálá jẹ̀ adarí fún wọn, tí ó sì sọ ìlú náà di Ìlú kan ṣoṣo tí ó wà ní abẹ́  ìṣàkóso Ọba kan ṣoṣo.

Ó gba àwọn ìnagijẹ bí : Ọlòfin  Àdìmúlà, Ọlòfin Ayé àti Olúfẹ̀. Àwọn elédè Yorùbá ma ń pe Orúkọ rẹ̀ báwọ̀nyí:  Odùduwà , tì wọ́n sì tún le dàá pè báyìí: Oòdua tàbì Oòduwà tàbí  Odùduà nígbà míràn ni ó ń tọ́ka sí akọni náà, tí ó sì ń fi pàtàkì àwọn  ilẹ̀ Yorùbá hàn pàá pàà jùlọ àwọn Ọba Aládé  gẹ́gẹ́ bí àrólé àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni iyì àti àpọnlé.

Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Odùduwà ó kúrò láyé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbrẹ̀ ni wọ́n tinfún ká orílẹ̀ kúrò ní Ifẹ̀, tí wọ́n sìbti lààmì -laaka kákiri ìletò tiiwọn nàà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni wọ́n ti dá ìjọba tiwón náà kalẹ̀ nílú tí àwọn náàbtẹ̀dó sí gẹ́gẹ bí Ọba, tí wọ́n sì ń fi yé àwọn ọmọ tiwọn náà wípé  Ile-Ife ni àwọn ti wá

Ọ́rúntó tí ó jẹ́ ọmọ tí ọ̀kan lára àwọn èrú Odùduwà bí fun ni ó jẹ́ ìyá-ńlá àwọn tí wọ́n ń joyè Ọbalúfẹ̀ tí ó jẹ́ oyè igbá-kejì sí oyè Ọọ̀ni ní Ilé-Ifẹ̀ títí dòní 

Ọbalùfọ̀n Aláyémore ni ó wà ní orí ìrẹ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn ti ìrìn-àjò dé, tí ó sì pàṣẹ pé kí Ọbalùfọ̀n ó kúrò lórí àpèrè kí òhn sì bọ́ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọmọ Odùduwà tí ó lẹ̀tọ̀ọ́ sóróyè baba rẹ̀. Lẹ́yìn Làjàmìsà tí ó jé ọmọ Ọ̀rànmíyàn bi ó ni àwọn ọmọ rẹ̀ ń jẹ Ọọ̀ni nílé-Ifẹ̀ títí dòní.

Lápá kan, wọ́n ní ìtàn fiyeni wípé Odùduwà jẹ́ oníṣẹ́ láti ìlú Òkè-Ọrà ìlú tí ó wà ní apá ìlà -Oòrùn é-Ifẹ̀. Wọ́n ní ó rọ̀ láti orí òkè kan pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n, ní èyí tó mú kí wọ́n ma kìí wípé: Oòduà Ayẹ̀wọ̀nrọ̀ tí ó túmọ̀ sí ( 'one who descends on a chain'). Abala ìtàn yí fi yéwa wípé jagun jagun ni Odùduwà jẹ́ pẹ̀lú bí ó ṣe wọ̀ éwù ogun  onírin .Lásìkò tí ó wọ Ilé-Ifẹ̀ wá, àjọṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn wà láàrín àwọn olùgbé ìran mẹ́tàlá(13) Ifẹ̀, tí ìlú kọọ̀kan sì ní Ọba tirẹ̀ bí Ọba Ìjùgbé, Ìwínrín, Ijió, Ìwínrín àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́yìn tí Odùduwà di aláṣẹ́ Ilé-Ifẹ̀ tán, òun àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sapá tí wọ́n sì gba àwọn ìlú àti agbègbè mẹ́tàlá tí a mẹ́nu bà wọ̀nyí, tí wọ́n sì  ṣí Obatala,  nípò gẹ́gẹ́ bí olórí tí wọ́n sì gbé ìjọba titun kalẹ̀ pẹ̀lú ẹtò ìṣèlú tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Látàrí ìdí èyí, ni wọ́n fi ń pèé ní  Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀  àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó mú ètò àti ìlànà ìṣèjọba aládé wọ ilẹ̀Yorùbá

Àkọ́bí Odùduwà tí orúkọ rẹ́ ń jẹ́ Ọ̀kànbí Iyùnadé, ni ó fẹ́ Obatala tí ó sì bí ẹbi tí ó jẹ  Olówu àkọ́kọ́. Ìtàn fiblélẹ̀ wìpé Olówu àkọ́kọ́ yìí ni ó ti gorí ìtẹ́ látìgbà tí ó ti wàní òpóǹló.

Ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Odùduwà tí ó jẹ́ ààyò tí orúkọ rẹ̀ ǹ jẹ́ Ọmọnidẹ, ni ó bí  Sopasan, ẹni tí ó bí ọba Alákétu Sopasan was the first to leave Ile-Ife with his mother and crown. He settled at such temporary sites as Oke-Oyan and Aro. At Aro, Soposan died and was succeeded by Owe. The migrants stayed for a number of generations and broke camp in the reign of the seventh king, Ede, who revived the westward migrations and founded a dynasty at Ketu.

Ajagunlà Fágbàmílà Ọ̀ràngún, tí a lè pè ní ojúlówó ọmó Odùduwà ni ó jẹ́ Ọ̀ràngún ilé Ilé-Ìlála. Odùduwà ni a gbọ́ wípé ó fẹ́ láti bí ọmọ yanturu kí ó lè dẹ́kun àhesọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ifa oracle, he went to a stream, where he found a naked lady by the name of Adetinrin Anasin. She eventually became his wife and the mother of Ifagbamila (which means Ifa saves me)

Ọ̀rànmíyàn ni ó tẹ ìlú  Ọyọ́-Ilé dó. Lẹ́yìn tí lára àwọn ọmọ rẹ̀  Àjàká àti Ṣàngó náà darí ìjọba  Ọ̀yọ́ lẹ́yìn baba wọn.

Ọ̀rànmíyàn tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ Odùduwà ni onírìn-àjò jùlọ láàrí àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ jùlọ. Òni ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ jẹ  He was the first Ọba ilẹ̀ Ìbìní tí ó sì tún jẹ́ ỌbaAláàfin ti Ìlú Ọ̀yọ́, bákan náàni òun ni Ọba  Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ ẹlẹ́kefà nínú ètò.

Lẹ́yìn tí àwọmọ Odùduwà gbogbo ti túká kúrò ní Ifẹ̀ láti lọ dá ìlú àti ìletò tiwọ̀n sílẹ̀, ó ṣòro láti tukọ̀ ìlú náà fún olórí tó wà níbẹ̀ nígbà náà, fúndìí èyí, àwọn ìpèníjà oríṣiríṣi ni ó dojú kọ Ilé-Ifẹ̀ lásìkò yí. Àwọn ẹmẹ̀wà  Ọbàtálá tí ó jẹ́ ẹni tó ti darí Ifẹ̀ ṣáájú Odùduwà ni a gbọ́ wíoé wọ́n sọra wọn di  agbọ́n onígàn oró tí wọ́n sì ń gbẹẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́, léte àti gbẹ̀san gbígba agbára tí Odùduwà gba agbára lọ́wọ́ Obàtálá. Wọn yóò múra gẹ́gẹ́ bí Th àlùjọ̀nú nígbà tí wọn yóò wọ àwọn kiníkan tó dàbí ewé, lọ́nà tí hóò dẹ́rù ba àwọn ènìyàn gidigidi, wọn yóò  ma dáná sunlé tí wọn yóò ja àwọn ọlọ́jà lólẹ láàrín ọjà. Lásìkò yí ni ọmọba bìnrin Mọ́remí Ajasoro, tí ó jẹ́ ọmọba bìnrin ní ìlú Ọ̀fà, tì ó wá láti ìran Ọlálọmí Ọlọ́fà gangan, tí ó jẹ́ ẹni tì ó tẹ Ìlú Ọ̀fà dó tí ó sìbtún jẹ́ adarí pàtàkì fún Ìbọ̀lọ́ ní ìlú Ọ̀yọ́, tí ó sì tún jẹ́ ìbátan Ọ̀rànmíyàn ni a gbọ́ wílé ó dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó sì sapá gidi láti pẹ̀tù sí wàhálà náà níoa ṣíṣe alamí àwọn níṣẹ́ búburú náà.  Ó fara rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ̀ kí wọ́n fipá kó ọòun lẹ́rú. Nínú ìgbèkùn ẹrú rẹ̀ ni Ọba àwọn Ùgbò náà ti fẹ láti fi ṣaya. Ọba náà gbìyànjú láti ba múfẹ̀ẹ́ lẹyìn tí ó fẹ ytan ṣùgbọ́n Mọ́remí kọ̀ jálẹ̀ ní torí ó ti ládé orí tẹ́lẹ̀, àti wípé iṣẹ́ alamí ló wá ṣe kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ló kàn. Ó ní bí Ọba náà bá le dọ ìdí abájọ àwọn amòòkùn-sìkà náà fún òun, kíá ni òun yóò gbà fun lát lájọṣepọ̀. Ọba náà kọọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ẹyí, ṣùgbọ́n ó ṣe ìfẹ́ inú Mọ́remi tí ó sì tú àṣírí náà si lọ́wọ́. Ó sọ fún Mọ́remí wí wípé ohun tí àwọn kórìíra jùlọ nígbà tí àwọn bá ti múra bí àlùjọ̀nnú náà bi iná, nítorí iná nìkan ló lè tú wọ́n láṣìírì, bí wọ́n bá sì ríná, àwọn yóọò sá lọ. Lẹ́yìn tí Mọ́remí ti gnọ́ àṣírí yìí tán ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ń dọ́gbọ́n ọ̀nà tí yóò gbà sákúrò níbẹ̀. OnÓ ní kí wọ́n bá òun wá ọsàn tó pọ́ tí ó sì fi ṣe oògùn orun fún gbogbo àwọn olùgbé Ààfin náà. Lẹ́yìn tí wọ́n jí ni wọ́n ri wípé Mọ́eemí ti na pápà bora tí ó sì ti lọ tú àṣírí àwọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀,. Báyìí ni àwọn Ifẹ̀ ṣe múra sílẹ̀ fún àÙgbọ́ lá ti bá wọn bami ìjà wò. Tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.

Àwọb ìtàn ìbílẹ̀ kam di múlẹ̀ wípé Odùduqà jẹ́ ọkan lára àwọn Orisa tí Elédùmarè dẹẹ́ràn jùlọ nígbà ìwáṣẹ̀. Àwọn ìtàn wọ̀yí fi múlẹ̀ wípé Odùduwà ni Elédùmarè rán wá sáyé láti wádá ayé sorí ẹ̀kún omi. Iṣẹ yìí ni a gbọ́ wípé Ọbàtálá kùnà láti jẹ́ lẹ́ni tí a ti fún ní ìkarahun ìgbín, iyẹ̀pẹ̀, àti igi tíyóò fi tàn án ká fún iṣẹ́ pàtàkì náà. Ìtàn yí ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Yorùbá gbàgbọ́ tí wọ́n sì fi ṣe ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ ì)àgbọ́ wọn nípa ìṣẹ̀dá ayé. Wọ́n ma ń fi igbá àti ṣe àmì Ọbàtálá àti Odùduwà nígbà tí ọnọrí igbá ń rọ́pò Ọbàtálá tí ìyá igbá sì ń dúró fún Odùduwà gẹ́gẹ́ bíese  Ọlọ́fin Ọ̀yẹ́tẹ  tí ó túmọ̀ sí ẹni tí gba igbá ìyè lọ̀dọ̀ Elédùmarè.




#Article 154: Ojú tí Ifá fi n Wọ́ Obìnrin (3195 words)


Ifá jẹ òrìṣà kan pàtàkì láàárín àwọn Yorùbá àwọn Yorúbà gbàgbọ́ wípé Olodumare lo ran ifá wa láti Ode Ọrun láti wa fi Ọgbọ́n rẹ̀ tún ilé ayé se. Ọgbọ́n ìmọ̀ àti Òye tí Olódùmarè fi fún ifá ló fun ifá ní ipò ńlá láàárín àwọn ìbọ ilẹ Yorùbá ….”a kéré-finú-sọgbọ́n”ni oríki ifá. Eleyi lo fi han wa gẹ́gẹ́ bí Abimbọla (1969) ti gbe kala.
	
Nínú isẹ́ àgbékalẹ̀ Ilesanmi ó wa jẹ ki a mọ wípé ifá ni alárínà fún gbogbo ọmọ Oodua oun ni ó dabi agbenuṣọ fún gbogbo àwọn òrìṣà àti Olódùmarè ohùn ṣì la kà ṣí ẹni to ń ṣe àjèwò fún gbogbo mùtúmùwà. Èyí wa fún ni ibò asojú fún gbogbo àwọn Irúnmọlẹ̀ yòókù. Aroko leti ọpọn ifa 1998. 
	
Ifa jẹ ẹwi tí ó máà ń lọ láti ilú kan ṣì èkejì láti dífá. Èyí lo ṣe okùnfa bíbá ọ̀pọ̀ obìnrin pàdé ó ṣI fun ni àǹfáàní láti fẹ ìyàwó púpọ̀ torí irúfẹ́ isé ti ifá ń ṣe. Èyí sí lo fa to fi ṣeṣe fún ifá láti mọ ìwà wọn ó wú oniruuru ìwà yìí jáde torí àjọsepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Obìnrin. Ó maa ń ṣawo kiri ní. Gbogbo ibi tí ifá ba ti dé lo ti ń yan ìyàwó, èyí lo mu ifá rí àríṣá àwọn Obìnrín. 
	
Obìnrín ní a le pè ni ìdàkejì Ọkùnrin tí a ba wo Tíórì Àbùdá onibeji fún àgbéyèwò lítíréṣọ̀ ifá tí Ilésamí pàjúbà rẹ Tíórì yìí nì ó jẹ kí á mọ pé laisi ọ̀tún osi ko le dádúró. 
	
Erongba opilẹkọ yìí ni láti tàn ìmọ́lẹ̀ ṣí ipò tí ifá fi àwọn Obìnrin ṣi Àkíyèsí àwọn ipò wọ̀nyí si han nínú àwọn ẹsẹ ifá. Ojú méjì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ifá fi wo àwọn Obìnrin 

(i)	Ó rí wọn gẹ́gẹ́ bi ẹni réré ti ko ṣe maniyen to lẹ́wà. 

(ii)	Ifá rì àwọn obìnrin ní ìdàkejì gẹ́gẹ́ bi èsù tàbí olubi ẹ̀dá. 

Ṣebí  tibi tirẹ la dálé ayé. Bẹ́ẹ̀ ṣI ni a kìí dára ka ma kù ṣíbì kan. Àwọn òbinrin la ba máà pè ní ejò gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ ifá. Nítorí ìdí èyí ifá rọ àwọn ọkùnrin láti gbọ́n nínú gbọ́n lode tí ọ̀rọ̀ ba ti di ọ̀rọ̀ obìnrin.

OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BÌÍ KÒṢÉÉMÀNÍ TÀBÍ ẸNI RERE
	
Nínú ìpín yìí ifá bẹ̀rẹ̀ ṣí ni ṣe àfihàn wọ́n láti òde pé wọ́n tẹwà ó ṣi rí obìnrin gẹ́gẹ́ bi ẹni rere. Ẹwà wọn ṣI maa ń jẹyọ nínú àwọ̀ tí Olódùmarè fit a wọn lọ́rẹ àto ọmu ti ó fi ṣe àfikún ẹwà wọn. Omú tàbí ọyàn obìnrin ní iyì rẹ̀ ohun ṣi ni onfa to ń fa àwọn ọkùnrin to si ààbí èmú to ń mu wọn mọ́lè lára obìnrin òdí méjì, ìjìnlẹ̀ ohun Eleu ifá Apa kinni pg 54-1-3 fìdí èyí mílẹ̀ pé 

Funfun niyì eyin 

Egun gadaaga niyi orun  

Omu sìkì siki niyi obinrin 

Omu sikisiki niyi obinrin pg 54 1-4

Ohun iyi àti àmúyẹra ní fún ọkọ rẹ bi èyin odi meji Obinrin ba funfun. Bakannaa ni ifá tún fi ye wa pe ki obinrin lómú kọ lopin ẹwa. Ṣùgbọ́n ìmọ́tótó náà tún se pàtàkì láti le e perí ọkùnrin wale ìjìnlẹ̀ ohùn enu ifá láti ọwọ Wade Abimbọla Apa kini pg 51-25-26. 

				Síyínka Súnyinka 

				Baláfúnjú ba ji a sìnyìnká sóko pg. 51 25-26. 

A ko gbọ́dọ̀ gbàgbé wipe ara ẹwà ita ti òrúnmìlà ri lára Àwòrán ní ó fig be e ni ìyàwó. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pe bi àwòrán tí jọju to ko ìwà àrokò ti ifa ń fi èyí pa ní pe ẹwà kii se ogbo nìkan. Bi a ti ń wo ẹwà ifa ni ó yẹ ki a naa wo ti inú. 
	
Ifá wo ẹwà inú àwọn obìnrin ni oríṣìírìṣí ọ̀nà Aabo jẹ ìrànlọ́wọ́ fún òrúnmìlà nigba to lalèjo mẹta Iku, Àrùn àti Èsù. Ààbò lo ko nǹkan ìlò ọkọ rẹ lo ta ni ọjà Ejigbomekan ní owó pọ́ọ́kú ó ra ounjẹ wọn ṣi tójú àwọn àlejò wọn. Ìwa ti Ààbò wù yìí mu kí àwọn àlejò mẹ́ẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí fì ifá sílẹ̀ laipa. Wọn fún Ọ̀rúnmìlà ní ẹ̀bùn ki wọn ó to fí ilé rẹ̀ ṣílẹ̀. Inú Ọ̀rúnmìlà dun nítorí ìwà Ààbò àti ori re tí ó ko ran-an. Èyí ṣi mu kì Òrùnmìlà fẹran Ààbò. 

				Òdá Owo awo kóro 

				Ààbò Obìnrin rẹ̀   - pg 20 1-2 

				Ifá ó ṣI ní Oọkan a a yọ na 

Ní Òrúnmìlà ba pé Ààbò obìnrin rẹ̀ pé kí ó kó àwọn nǹkan ìní òun lọ sọ́jà lọ tà.  Ìjìnlẹ̀ ohun Ẹnu ifa iwe kinni

Ifa fẹ ìwà náà gẹ́gẹ́ bí aya Ọ̀lẹ àti ọ̀bùn ayé ní ìwà jẹ. Èyí mí ki ọ̀rúnmìlà le e lọ ki lọ ṣi nǹkan ò ba gún régé mọ́ àwọn ènìyàn ṣá lọ́dọ̀ rẹ. Àpọ́nlé kò si fún ọ̀rúnmìlà mọ bìí ti tẹ́lẹ̀ ṣebi ko kuku ṣí àpọ́nlé fún ọba tí kò ní olorì. 

			Ká mú rágbá 

			Ká fi ta rágbá 

			Ka mu ràgbà 

			Ka fit a ràgbà 

			Iwa la n wa o, ìwà 

			Alara ó ri ìwà fun mi 

			Ìwà la ń wa o ìwà…

Ìwà ni o jẹ gẹ́gẹ́ bí orison áàsikí fún Ọ̀rùnmìlà ṣùgbọ́n ko mọ iyì  ìwà àfi ìgbà tí ìwà fi ilé Ọ̀rúnmìlà sílẹ̀. 
Ẹ̀mí náà jẹ ọkan lára obìnrin ọ̀rúnmìlà. Ifá fi ẹ̀mí hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀pọ́múléró. Ìdí nìyí tí Ọ̀rúnmìlà fí gbé ẹ̀mí ni ìyàwó ko ba le ṣe rere láyé. Á gbọ́dọ̀ mò wípé ẹmi ní ó gbé ìwá ró. LaiṣI èmí ko si àrà tí ènìyàn le da láyé. Aadogun, aadogbọn, ọwọ́ èmí ni gbogbo rẹ wa. 
Àwọn Yorùbá ṣì gbàgbọ́ wípé ẹ̀mí gígún ni ṣan ìyà Ọ̀rúnmìlà ko le gbàgbé ẹmí nítorí ohun rere ti ẹ̀mí fún Ọ̀rúnmìlà ní ànfààní láti ṣe. Ire gbogbo tí ẹ̀dá ń wa kiri ọwọ́ èmí ní gbogbo rẹ wa. 
Fun àpẹẹrẹ:-	

		A dia fun Ọ̀rúnmìlà 

		Níjọ́ to ń lọ r’ẹmi ọmọ Olódùmarè s’Obinrin 

		Ó ní àṣé bẹmi ò ba bọ́ 

		Owo ń bẹ 

		Hin hin owo ni bẹ 

		Àṣà bemi o ba bọ̣

		Aya ń bẹ 

		Hin hin aya ń bẹ 

		Àsé bẹmi ò bá bọ́ 

		Ọmọ n bẹ 

		Hin hin ọmọ ń bẹ 

		Aṣe bẹmi ò bá bọ̀ 

		Ire gbogbo ń bẹ 

		Hin hin ire gbogbo n bẹ …

Wande Abimbọla Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnu ifá Pg 16 (Eji ogbè). Apa kinni 
	
Odù náà jẹ ọken nínú àwọn ìyàwó ọ̀rúnmìlà tí o ko orire ràn án. Alátìlẹyìn ni odù jẹ fún Ọ̀rúnmìlà. O dìgbà tọmọ èkọ́sẹ́ ifa ba to fojú ba odù ko to dẹni ara rẹ. Èyí túmọ̀ ṣi pé babaláwo tí kò ba fojú bodù kò tii dangajia. 

			Ẹni bá fojú bodù 

			Yoo ṣi dawo 

			A fojú bodù a rire 

OBÌNRIN GẸ́GẸ́ BI OLUBI
	
Àbùdá kejì yìí ní yóò tu tìfun tèdọ̀ ihà kejì tí ifá kọ ṣi àwọn obinrin. Ifá ri àwọn Obinrin gẹ́gẹ́ bi ẹni ibi, alásejù, òjòwú àti àjẹ́. Ó fi ìhà yìí hàn tori pe a kìí dara ka ma kù ṣibi kan.
	
Ifá fi wọn wé aláigbọràn ewúrẹ́ tí wọ́n máà ń ṣe àtojúbọ̀ àwọn ohùn tí ko kàn wọ́n. Bi àpẹẹrẹ Yemòó fẹ mọ ìdí agbára Óòsáála ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú èdó tí ó fi ń pa ẹran ohun tójú tíle-túle alaigbọran ń ri ní ojú rẹ rí lọjọ yìí. Òrúnmìlà ṣọ fún àwọn ìyàwó yòókù láti mase yojú wo ọ̀rọ̀mòdìmọ̀dì obìnrin rẹ̀ tuntun. 
	
Ìyáálé pé àwọn yòókù láti lọ yojú wo ìyàwó tuntun yìí inú bí ìyàwó tuntu, o si jade. Ó sì fi wọn rẹ́ bayí ni Àjàkálẹ̀ àrùn ṣi wọle tọ wọn. A ko le fí gbogbo ara da ìyaálé àti àwọn ìyàwó yòókù lẹ́bi torí Ọ̀rúnmìlà ti yẹ kì ó fi ìyàwó tuntun han àwọn to ba ní ilé ṣùgbọ́n ó kọ̀ ko ṣe èyí nípa ojú tí ọ̀rúnmìlà fí wo Obìnrin tí a le ṣọ pe Ọ̀rúnmìlà lo fí owọ́ ara rẹ da ilé ara rẹ̀ ru. Ẹni ba wa wàhálà dandan ni ki ori i.
	
Ifá tun fí àwọn obinrin hàn gẹ́gẹ́ bí òjòwú, ti wọn kìí fẹ ki ọkọ wọn fẹ ìyàwó mìíràn le wọn àfi àwọn nìkan. 
Fún àpẹẹrẹ: 

				Ọ̀kan ṣoṣo péré lobìnrin 

				Dùn mọ lọ́wọ́ ọkọ 

				Bí wọn ba di méjì wọn a dòjòwú 

				Bí wọn ba di mẹta 

				Wọn a dẹta ń túlé 

				Bí wọn bad è mẹrin 

				Wọn a dí iwọ̀ lo rín mi ni mo rin ọ 

				Bi wọn ba dí marun 

				Wọn a di lágbájá ni ó run ọkọ 

				Wa tan lóhùn ṣuṣuusu 

				Bì wọ́n ba dí mẹ́fà 

				Wọn a dìkà 

				Bi wọ́n ba de meje 

				Wọn a d’àjẹ́ 

				Bí wọ́n ba di mẹjọ 

				Wọ́n a di ìyá alátàrí bàmbà…

			Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá Apá 
Kìínní pg 29-43
						(Òyèkú meji) Wande Abimbọla 
	
Ohun tí o jẹ ìjọjú ní wípé Ifá gan-an mọ pé ó sàn fún ọkùnrin láti fẹ ìyàwó kan. Ẹ̀sẹ̀ amọmọda ni èyí ko yẹ ki Ifá maa fẹ ìyàwó lórí ara wọn. 
	
Eke àti Ọ̀dàlẹ̀ ni Ifá tún pe àwọn obìnrin. Ohùn tí Ifa ń ṣọ níbí ni pe Obìnrin ko ṣe fi inú hàn ṣùgbọ́n ibeere tí a ba bi Ifá ni pe ṣe ọkúnrin ni o se fi inú hàn. Bi o ti wa ni lìkì ni ó wa ni gbanja 

Obinrin leke 

Obinrin lodalẹ 

Keniyan se pẹlẹ 

Ki o ma finu han f’oobinrin
(CL Adeoye pg 243 ẹsẹ ifá kan nínú Obara meji)

Ifá tẹ síwájú nìpa pipe àwọn obìnrin ni dọ́kodọ́kọ àti alágbèrè. Èro ifá ni pé àlè yiyan yìí kii jẹ ki wọn tonu lọpọ igba pe ẹni to ba keré sọkọ ni wọn maa ń ba dálè.

	Àgbìgbọ̀niwọ̀nràn, The unfaithful Ifá priest 

	You have been seeing bad things, 

	Worse things are yet to come; 

	Worse things the father of bad things 

	Ifa divination was performed for Agbigboniworan 

	Who was going to the house of Onkoromebi to perform divination

	Onikoromebi, husband of an adulterous wife 

	It was because of the incessant adultery 

	Of his wife that oniworonebi 

	Performed divination 

	Igba ti o fìyà jẹ obinrin naa tan 

	O gbe ju, agbala 

	O ṣi de e lokun mọ́lẹ̀ 

	Ni àgbàlá ni onikoromebi fi ìyàwó rẹ ṣI 

	Ti o fì lọ bìfa léèrè 

	Àgbìgbò ní ki Onikoromebi o ṣe ṣùúrù 

	O ní ẹni tí o torii rẹ bi ifa léèré 

	Mbẹ loride nínú àgbàlá 

	Igba ti onikoromebi gbọ 

	Oju ti i 

	Ko lee lo tu ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ mọ 

	Ó ní ki Àgbìgbò o lọ ba òun tu u sílẹ̀ 

	Ìgbà tí Agbìgbo débẹ̀ 

	Dípò ki o tu obìnrin náà sílẹ̀ 

	fefẹ ni ń fẹ ẹ….

				(Ifa Divination Poetry pg 87-88)
	
Nígba tí ìyàwó onikoromebi náà yan babalawo ti wọn ni ko ba wọn wo aiṣan agbere lara rẹ. Ṣùgbọ́n ojọ yìí ní ibi wọn wolẹ nítorí bibẹ ní oníkòròmebi bẹ àwọn mejeeji. Babalawo tì wọn ni ko wo aya onikoromebi ko ni ètọ́ lati ṣe èyí. Bí wọ́n ba pe obìnrin ni dokọdọkọ. Obìnrin ko le da ọkọ dó laì ri ọkunrin. 
Fi obìnrin é yálẹ̀ yàlè alainisuru a ri eleyi nínú Sixteen great poems of Ifa Not long again. They sent for Ọ̀rúnmìlà in the abode of Olokun when Ọ̀rúnmìlà was going he did not take Ọ̀rọ̀ his wife along he promised to return on the seventeenth day. He gave sixteen ọ̀ké measures of cowries to ọ̀rọ̀. He also gave her clothes and plenty of food in the third month that Ọ̀rúmìlà had stayed away. 
	For Example: 

			Ọ̀rọ̀ met Ońdàáró 

			They agreed to be Concubines 

			Ondaaro gave her five oke measures 

			Of cowries He cohabited with her, 

			And he became pregnant. 

			Ọ̀rọ̀ met onigoosun 

			After they had talked together 

			Onìgoosun gave her ten Okẹ measures

			Of cowries 

			And cohabited with her 

			And again she became pregnant 

Not long again ọ̀rọ̀ met a man named Olúùkọ́ọlọ́ He gave har 
tiventy okẹ measures of cowries after they hed fun with each other ọ̀rọ̀ became pregnant again. All together the children of Ọ̀rọ̀ thus became six and they were all boys out of the six children three were children of Concubines. 
	
Nínú ẹsẹ̀ Ifá yìí fi hàn wá wípé Owo l’obinrin mọ̀ gbogbo àwọn mẹtẹẹta to ba dálè yìí owó ní wọn fi hàn ọ̀rọ̀. 
	
Aritẹnimọọ wi, a fi apadi fẹnfẹ bo tirẹ̀ mọ́lẹ̀ ni Ifá ibeere ti a ba bi ọ̀rúnmìlà nip e ṣe ko ba obinrin kankan ni àjọsepọ̀ ni ìrìn àjò rẹ. Ko ṣi ẹni to mọ iye ọmọ ti o`hun na bi si àjò. 
			The Sixteen Great Poems of Ifa pg 216-221 Wande Abimbọla  
	
Ifá rí obinrin han gẹ́gẹ́ bi àjẹ́ 

	Fun àpẹẹrẹ: 

Bẹ́ẹ̀ ba gbolagbalagba epo òun ewùso 

Ẹ lo lee ko fún ìyàmi Òsòròngà 

Apa nimawaagun, Olokiki Orù 

Ajẹdọ-tútù-mọ-bi 

Obinrin kukuru regiregi 

	(The 16 Great Poems of Ifa pg 242 Wande Abimbọla) 

	
Àwọn obìnrin náà ni Ifá tún fihàn bí aforesunu se. Wọn fore ṣu Ọ̀rúnmìlà nílé ayé pé àwọn o ni sọ̀kalẹ̀ ní ikùn rẹ mọ́ àfìgbà to ba rúbọ. 

				Wọn ní kí ní ń jẹ sisọ kale 

				Wọn ni a tun ṣòkalẹ̀ mọ́ 
	
Ọ̀rúnmìlà ti mọ Oko ni oko ikun to gbin èpà síbẹ̀. O mọ pé ìhòhò ní àwọn ẹlẹyẹ wa ko to gbà láti ṣe wọn ní àánú. Kìí ṣe Ọ̀rúnmìlà nikan ní àwọn ẹlẹyẹ bẹ. Ọ̀rúnmìlà tí gbàgbé pe bí ojo oore ba pé asiwèrè a gbàgbé àti pé ìwọ̀n ní oore. 
	
Aláwomọ́ àti alakooba ní wọn gẹ́gẹ́ bi ìwà ti ìyá arúgbó tí a fi se àpẹẹrẹ nínú òyèkú méjì wù. Nígbà to fọ̀rọ̀ isú lọ ẹnikan ti ko gba a jẹ o fi ọwọ epo sàmì sìi lára. Ebi kii ṣe ebi ẹni to fi ọwọ́ epo to ọ ni lẹkẹ ẹni to rin ìrìn ìwàsà o di dandan kan fi èkùrọ́ lọ o 
	Fun àpẹẹrẹ: 

				Ó mú ọwọ epo 

				Ó fi to mi lẹ́ẹ̀kẹ́ẹ mi ọ̀tún 
itọrorọ itọrọrọ 

				Ó mú ọwọ epo

				Ó fi to mi leẹkẹ mi òsì itọ̀rọ̀rọ̀ 
itọ̀rọ̀rọ̀ 

		Ìjìnlẹ̀ ohùn ẹnú ifá pg 29-107-110 Òyèkú meji Wande Abimbọla 

Ifá tún jẹ ka mọ pé ìkà àti òfinràn ni wọn. Nínú méjì Yemoo ìyàwó oriṣà ńlá lo ji omi àwọn ẹlẹyẹ pọn to ṣo tun fọ asọ òdé rẹ ṣínú odò náà 

				The witches asked, Did 

				She stab herself and Èlúlù 

				Replied she did not 

				Stab herself, the blood was 

				From her private part 
						(The 16 Great poem ifá) 

The witches therefore swallowed both the husband and the wife. 
Álásejù baba àsetẹ́ tún ní ifá fẹ wọn ohun ti wọn ṣe náà nìyí tí ó je ki nǹkan bọ́tí mọ wọn lọ́wọ́. Wọn kí àsejù bọ ọ̀rọ̀ wọn.
	Fun àpẹẹrẹ :

			Igbó etílé t’oun tẹgbin 

			Adapọ owó toun tiyà 

			Iwo o ju mi 

			Ẹmi  o ju ọ 

			Lara ile ẹni fi ń fojú di ni 
(Oladipọ Yemitan ati Olajide Ogundele Oju Osupa Apa kẹta)
	
Ifá jẹ ka mọ wípé Olódùmarè yan òrìṣà mẹrindinlogun ó fi òbìnrin kan ṣi wípé ki wọ́n maa lọ silẹ́ aye láti maa lọ rúbọ fún àwọn ẹ̀mí airí. Nígbà tí wọn dé ilé ayé ọsun tí ó jẹ obìnrin àárín wọn ní ó maa ń ṣe ìpèsè fún àwọn ẹ̀mí airi yìí. 
	
Ní gbobgo ìgbà tí wọn bat i n lọ gbe ẹbọ yìí lọ fún àwọn ẹmí airi yìí oṣun kìí tẹ̀lẹ́ wọn, ti wọn ba ti de ibẹ̀ gbogbo àwọn òrìṣà wọ̀nyí lo maa ń ko gbogbo ìpèsè yìí jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko mọ wípé Olódùmarè tí fun ọṣun ni agbára láàrín wọn nígbà to yá gbogbo nǹken kò gún régé mọ́ wọn ṣa ògùn títí kò jẹ mọ. Bayi ní wọn ṣe pínú láàrín ara wọ́n láti rán òrìṣà ńlá lọ sọdọ Olódùmarè ṣùgbọ́n òrìṣà ńlá kọ láti lọ. Ní ifá bá ní kí wọ́n ran ohùn lọ sọ́dọ̣̀ Olódùmarè nígbà tí Ifá de ibẹ̀ lo ba ṣọ fún Olódùmarè wípé nǹkan ko 	gún régé mọ̀ o. Olódùmarè ba ni ọṣun ń kọ o ni gbogbo nǹkan te ba ti n ṣe e fi t’obinrin ṣi. 
	
Bayí ní gbogbo àwọn òrìṣà yòókù bu lọ ṣi ọ̀dọ̀ ọṣun láti bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀ṣun ko gba ẹ̀bẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo bẹ̀rẹ̀ ṣi ni mu gbogbo wọn bu lẹyọ kọọkan láti orí Oosala, Ọ̀rúnmìlà Ṣungo, ọya obalùfọ̀n àti bebe lọ ó ní nǹkan tí wọn jọ ràn àwọn ń kọ? lo ba sọ fún wọn wípé ọmọ to wà ní ikùn ohùn tí ohun ba fi bí obinrin Olódùmarè yóò fí àwọn ẹlomíran dipo wọn. Ṣùgbọ́n to ba jẹ pe ọkunrin ní ohun fi bi o ni ohun yoo fi wọn silẹ́ wípé ohùn náà ti ni lara wọn niyẹ̀n ni ọṣun ba fi oyin rẹ bi ọkunrin láti ìgbà yìí tí wọn bat í ń lọ̀ ṣI igbó ẹmí airi láti lọ run wọn maa ń lọ gbé ọmọ ọ̀ṣun láti fi ọwọ́ tirẹ̀ náà ṣI gbogbo nǹkan ti wọn ba ń se tan ba se tan wọn à dá pada fún ìyá rẹ̀. 

Igba yìí lo ti ṣọ pé tó ba jẹ ọkunrin ko ma jẹ Akin osó. 
		Ni ki a 

				Ka kúnlẹ̀ 

				Kí Obìnrin 

				Òbìnrin lo bi wa 

				Ka to di ènìyàn …

	
Ifá jẹ ka mọ̀ wípé alagbará ni àwọn obìnrin Olodumare lọ pin wọn ile agbara yìí. Gbogbo bi àwọn òrìṣà yòókù se ń ko ípèsè yìí jẹ ọ̀ṣun mọ ṣi ṣùgbọ́n ó ṣe bi ènipe ohun ko mọ nǹkan to ń sẹlẹ̀. 
	
Alagbara ní wọn bí wọn se le lo agbara wọn lati fi ṣe daradara ni wọn fi le ṣe búburú. 
				(Olóyè Babalọla Fatoogun (Ifá Priest) Ilobu Oṣogbo.)
	
Ifá tún ṣọ ìtàn nipa àwọn obìnrin ajọ àti ìpàdé to maa ń ṣe o fi hàn bo fe lo agbara àwíṣẹ lati fig be ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ni gbogbo ìgbà tí wọn ba ti fẹ ṣe ìpàdé. 
	
Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà gbogbo agbara àwísẹ to ba sọ labẹ ge. Nitorí ó dúró gẹ́gẹ́ bi agbára ìtúsílẹ̀ àti agbara Hayese. 
	
Bo ṣe dí ojo kan àwọn ọ̀fá wa ọ̀nà láti ji agbara náà gbe wọn ko ri bi wọn ṣe lọ ba ìyàwó ọ̀rúnmìlà pìyí pe to ba juwe ibi ti agbara òhún wa fun àwọn àwọn o fun lówó. 
	
Ìyàwó Ọ̀rúnmìlà gba owo, o ṣi gbe agbára náà o lọ bo mọ inú eérú ojú àrò. Nígba tí Ọ̀rúnmìlà fẹ ṣe ìpàdé a kọkọ gbìyànjú làtí bi ifá léèrè lori bi ìpàdé yoo ṣe ri ni wọn ban i ko lọ bọ ṣango ojú eérú tori ke nǹkan ba le ṣenu ire àti pe kí àsírí to farasin le ba hàn sáyé. 
	
Ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà ti gbe eéru ojú aaro lati bọ Ṣango tan lo ba ri agbara rẹ̀ tí ọ̀tá to ń pè ni ìyàwó bo mọ inú eeru náà. Ìgbà tí ọ̀tá ri pé wọn ko ri Ọ̀rúnmìlà mú náà bá tún lọ ba ìyàwó rẹ láti tún ta ete mìíràn ìyàwó Ọ̀rúnmìlà pẹ̀lú àwọn ọ̀tá náà ba gbìmọ̀ láti lọ ju agbara rẹ sínú odò. 
	
Ìgbà ti ọjọ́ àjò ń pe bọ̀ Ọ̀rúnmìlà lọ bi Ifa léèrè bí ọjọ́ àjọ yoo ṣe rí nítorí ó tí mọ bi obinrin se jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹbọ to jade ṣí nip é ki o lọ ni eja abori ńlá kan, obi àbàtà, àti iyàn ìlèkẹ̀ ko fi bọ ẹlẹda rẹ. Lílà tí Ọ̀rúnmìlà la inú ẹja lo ba agbára rẹ̀ nínú ẹja. Ó gbà pe obinrin ni òdàlẹ̀ ni wọn. 
					(Lati ẹnu Dro Agbájé ti wọn gba lẹnu Babalawo) 
	
Ìtàn kan ti Ifa ṣọ fì Obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bi ọ̀dèlè, afẹnimadenu olubi ènìyàn. Ifá ṣọ ìtàn nípa Ọ̀rúnmìlà 
ENI TÍ MỌ FỌ̀RỌ̀ WÁ LẸ́NU WÒ.

Oloye Babalọla Falogun Ifa Priest Ilobu 
Osogbo.




#Article 155: Ìṣírò (219 words)


Awoyemi, Jolaoluwa

AWÓYẸMÍ JỌLÁOLÚWA

ÌṢIRÒ 

	Àwọn Yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn Yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. Wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi 

		Ení bí ení ni ọmọde ńkawó 

		Èjì bí èjì ni àgbàlà ń tayò

		Ẹ̀ta bi ẹta ẹ jẹ́ ka tárawa lọ́rẹ 

	Ayò tí ta náà tún jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá fi máa ń kọ ìṣirò Yorùbá ni àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣe ìsirò wọn fún àpẹẹrẹ “lé”, “dín”, “àádọ́”, “ẹ̀ẹ́dẹ́”, - jẹ́ àwọn ọ̀nà fún ìfilé àti ìyokúrò ìṣirò wọn. 

	Apẹẹrẹ ìṣirò Yorùbá

	1	-	óókan 

	10	-	ẹ̀wá 

	20	-	ogún 

	21	-	Ọ̀kàn lè lógún (20+1 = ọ̀kan lé ni ogún)

	26	-	ẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n (30-4 = Ọgbọ̀n dín mẹ́rin)

	30	-	Ọgbọ̀n 

	40	-	Ogójì (20x2 = Ogún méjì) 

	60	-	Ọgọ́ta (20x3 ogún mẹ́ta)

	100	-	Ọgọ́rùn-ún (20x5) = Ogún lọ́nà márùn-ún) 

	120	-	Ọgọ́fà (20x6 = Ogún lọ́nà mẹ́fà) 

	50	-	àádọ́ta (20 x3 = 10, ẹ́wàá dín nínú ogún mẹ́ta) 

	200	-	Igba 

	240	-	Òjìlélúgba (40+200; Òjì = 40) 

	300	-	Ọ̀ọ́dúnrún 

	340	-	Ọ̀tàdín nírinwó (400-60 = ọ̀tà = 60 lọ́gbọ́ta)

	800	-	Ẹgbẹ̀rin (igba mẹrin 200x4)

	900	-	Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (1000-100 =  Ọgọ́rùn-ún  dín ni Ẹgbẹ̀rún	




#Article 156: Ìkọ́ni (656 words)


GBADAMOSI TEMITOPE THOMAS

Kíní a mọ̀ sí ìkọ́ni? 
	
Ìkọ́ni túmọ̀ si ìlànà ti àhún gbà láti fii òye hàn láti ìran kan dé òmíràn àti láti ènìyàn sí elòmíràn. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ìkọ́ni lèè túmọ̀ sí ìbáwí tàbí ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ ẹnití ó ju ẹni lọ. Àmọ́ ki a máa fi ọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọọlọ pa ejò, ìkọ́n tòní dá lórí ti Òye, Ìmọ̀ tàbí Èkó. 
	
Tí bá ní kí a woo bi ìtàn ìkọ́ni sé bẹ̀rẹ̀, a máa tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ odún sẹ́yìn. Akòleè sọ pàtó ibi ti ìkóni ti bẹ̀rẹ̀, nítorí pé orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kàn àti àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn níbikíbi lóní ìlànà ti wọ́n ń gbá kọ́ àwọn ènìyàn tiwọn. Ṣùgbọ́n orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ bíi Gíríìsì (Greece) tí ìsirò ti bẹ̀rẹ̀, ilẹ Lárúbáwá (Arabia), ile isrẹẹli ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wa nínú àwọn irú ènìyàn tí ó tayọ nínú ètò ìkọ́ni. Àmọ́ ètò ìkọ́ni bí a sè mọ̀ ti di àtọwọ́dọ́wọ́ débi wípé olúkúlùkù lóti gbàá ti wọ́n sì ti fi tún orílẹ̀ èdè wọn tò. 
	
Bí a ti se ń kọ́ni se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwùjọ, bí ati se lèe kọ́ ọmọdé yàtọ̀ sí bí ati se lèe kọ́ ọ̀dọ́ lángba bẹ́ẹ̀ ni ti ọ̀dọ́ langba náà yàtọ̀ sí ti àgbàlàgbà. Gbogbo wa lamọ̀ wí pé ọmọdé a máa tètè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ibi àwòrán, àwọ̀ àti àfihàn. Nítorí ìdí èyí, àwọn ìwé tí alákọ̀bẹ̀rẹ̀ bíi aláwìíyé dára púpọ̀ fún ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé. 
	
Ẹ̀wẹ̀, tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí bá déé ilé ẹ̀kọ́ girama ìlànà kíkọ́ àti mímọ̀ wọn yóò ti yàtọ̀ díẹ̀ sí ti ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀. Ní pele yìí, a óò tí máa fi yé wọn bá wọ́n se leè fi ọwọ́ ara wọn see àwọn ohun tí wọ́n ń kó wọn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn oo ti máa gbáradì fún ilé ẹ̀kọ́ gíga. Ní ilé ẹ̀kọ́ girama ẹ̀wẹ̀, àwọn ohun ti àwọn akẹ́kọ̀ óò máa há sórí – àkósórí àwọn akẹ́kọ̀ yóò din kù, yàtọ̀ sí tii ilé ẹ̀kọ́ ‘Jéléósimi’. 
	
Ǹjẹ́ tí abá dé ilé ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàtọ̀ ni yóò ti wà nínú bi ase ń kọ́ni. Ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé ọgbọ́n, ilé ẹ̀kọ́ gíga ilé òmìnira. Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga akẹ́kọ̀ ní àǹfààní lati se ohun tówùú nígbà ti ó bá fẹ́ tí kòsì olùkọ́ tí yóò yẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ìkọ́ni nílé ẹ̀kọ̣́ gíga yàtọ̀ gédégédé sí ti ilé ẹ̀kọ́ girama tàbí alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. 
	
Ní ilé ẹ̀kó gíga, akẹ́kọ̀ ló nílò láti se isẹ́ jù, nítorí péé; ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, olùkọ́ yóò kàn wá láti tọ́ akẹ́kọ̀ sọ́nà ni, akẹ́kọ̀ ni yóò se ọ̀pọ̀lọpọ̀ isẹ́ fún ra rẹ̀. 
	
Ìkọ́ni ni orílẹ̀-èdè yi ti dojú kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro tí ósì ti ń se àkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé àti ìdàgbà sókè ilẹ̀ yí. Tí abá ni kí áwòó láti ìgbà ìwásẹ̀ fún àpẹẹrẹ, ètò ìkọ́ni dára ni ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀, èdè Yorùbá ni afi hún kọ́ akẹ́kọ̀ láti ilẹ̀ kí àtó kii èdè òmíràn bọ̀ọ́, àmọ́ ni báyìí èdè gẹ̀ẹ́sì ni afi ń kọ́ akẹ́kọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn si ń sọ èdè Yorùbá nílé. Èyí lómú kí ó jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò leè sọ èdè Yorùbá kó já gaara láì má fii èdè gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan bọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò sì leè sọ èdè gẹ̀ẹ́sì dáradára. Ọ̀rọ̀ wa dàbíi “ẹni tí ófi àdá pa ìkún, ikún sálọ àda tún sọnù”. 
	
Kí ń tó fí gègéèmi sílẹ̀, gbogbo wa lamọ̀ wí pé ni àìsí ìkọ́ni kòleè sí ìmọ̀, ni àìsí ìmọ̀ láti ìran kan dé òmíràn; kò leè sí ìdàgbà sókè, ni àìsí ìdàgbà sókè ẹ̀wẹ̀, kò leè sí ìlosíwájú, ìlú tí kò bá sì ní ìlosíwájú ti setán láti parun ni. Fún ìdí èyí a óò ri péé ìkọ́ni jẹ́ ohun kan gbógì tí a kò leè fi seré ní àwùjọọ wa. 

Ẹ̀kọ́ dára púpọ̀ 

Ẹ̀kọ́ lóni ayé táawà yi sẹ́ 

Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò gíga 

Ẹ̀kọ́ lóhún gbéni dépò ọlá

Ẹ̀kọ́ dára púpọ 

Ẹ̀kọ́ lóni ayé tí awà yí sẹ́.  

ÌTỌ́KASÍ (REFERENCE) 

i.	D.F. Odunjọ		 - 	‘Alawìye Apa keta’ 

ii.	B. Onibonoje 		– 	‘Iwe Ikọni Yorùbá 




#Article 157: Orílẹ̀-èdè Yorùbá (787 words)


ÀKÀNDÉ SAHEED ADÉBÍSÍ

ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ
	
Yorùbá gẹ́gẹ́ bí Orílẹ̀-Èdè jẹ́ àti-ìran-díran Odùduà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọn ń sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti Odùduà ń gbà sìn-ín; ti wọn si bá a jade kúrò ni agbedegbede ìwọ̀ oòrùn nígbà tí ìrúkèrúdò dé nipa ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí. Akikanjú yii pinnu láti lọ tẹ orílẹ̀ èdè miran dó nibi tí wọn yóò gbé ni àǹfàní ati sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti wọn gbà pé ó tọ́ ti ó si yẹ. Bí wọn ti ń rìn káàkiri ni Yorùbá, bí Orìlẹ̀-Èdè n gbòòrò síi, ti ó si fi jẹ́ pé l’onii gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn ń bá ni gbogbo ibi tí wọn ti ń jagun tí ó di ti wọn àti ibi tí wọn gbé ṣe àtìpó, tí wọn si gbé gba àṣà, ati ìṣe wọn, titi ti ọkunrin Akíkanjú, Akọni, Olùfọkànsìn, Olóógun, Àkàndá ẹ̀dá, yii fi fi Ile-Ifẹ ṣe ibùjókòó ati àmù Yorùbá. Ile-Ifẹ yii si ni àwọn Yorùbá ti fọ́nká kiri si ibi ti wọn gbé wà l’onii ti à ń pè ni ‘Ilẹ̀ K’áàrọ̀, O jí i re’. 
	
L’ónìí, kì í ṣe ibi tí a pè ni ‘Ìlẹ̀ k’áàrọ̀, O jí i ré’ yii nìkan ni àwọn Yorùbá wà gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà kan. Wọn fọ́n yíká Ilẹ ènìyàn dudu ni, àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíran l’ábẹ́run ayé. 

	Eyi ni ibi ti àwọn ẹ̀yà ti à ń pè ni Yorùbá wà l’onii: 

	(i)	Ìpínlẹ̀ Kano: Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó wà nibi ni àwọn tí à ń pè ní ‘Báwá Yorúbáwá ati Gogobiri: 

	(ii)	Sokoto: Àwọn ìbátan wọn tí ó wà nibi ni à ń pè ni Beriberi. Gẹ́gẹ́ bi òwe ti ó wí pé ‘Oju ni a ti ń mọ dídùn ọbẹ̀. Ilà oju àwọn ẹ̀yà yii fi ìdí ọrọ yii múlẹ̀. 

	(iii)	Ìpínlẹ̀ Ilẹ̀ Ìbínní dé etí Odò Ọya: Awọn wọnyi ni àwọn ìlú tí ọmọ Eweka gbé ṣe àtìpó ati ibi tí wọn jẹ oyè sí, àwọn bíi Onìṣà Ugbó, Onìṣà Ọlọ́nà àti Onìṣà Gidi (Onitsha), pàápàá jùlọ àwọn tí wọn ń jẹ oyè tí à ń pè ni Òbí. 
Àwọn kan sì tún ni ìran Ègùn bíi: 

Ègùn Ànùmí ni ilẹ Tápà; Ègùn Àwórí ni Ẹ̀gbádò; Ègùn Àgbádárígì ní Ìpínlẹ̀ Èkó. 

	
Awọn ni Ègùn ilẹ Kutonu, Ègùn Ìbàrìbá ilẹ Benin; Aina, Aigbe àti Gaa ni ilẹ Togo ati Gana; àti àwọn Kiriyó (Creoles) ilẹ Sàró (Sierra Leone). 

	
Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà l’áàrin Amẹ́ríkà ti àríwá àti ti gúúsù (Cuba, Trinidad and Tobago, Jamaica and other Caribbean islands); ati àwọn Ìpínlẹ̀ òkè l’ápá ìlà-oòrùn ti Amẹ́ríkà ti Gúúsù: (Brazil, etc). 
	
Bí ó tilẹ jẹ́ pé àwọn ọmọ Odùduà tàn kálẹ̀ bíi èèrùn l’ode oni, ẹ̀rí wa pé orílẹ̀ èdè kan ni wọ́n, ati pé èdè kan náà ni wọn ń sọ nibikibi tí wọn lè wà. Ahọ́n wọn lè lọ́ tàbí kí ó yí pada nínú ìsọ̀rọ̀ síi wọn, ṣùgbọ́n ìṣesí, ìhùwà, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀; gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa sì ti máa ń pa á l’ówe, a mọ̀ a sì gbà pé; Bi ẹrú ba jọ ẹrú, ilé kan náà ni wọn ti wá’. Awọn idi pàtàkì ti ahọ́n àwọn ọmọ Yorùbá fi yí pada díẹ̀ díẹ̀ díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Yorùbá kan náà ni wọn ń sọ niyi: 

	(a)	Bí àwọn akọni ti ń jade kúrò ni Ilé-Ifẹ̀ láì pada bọ̀ wá sile mọ́, ni wọn ń gbàgbé díẹ̀ nínú èdè ìbínibí wọn. 

(b)	Ibikibi ti àwọn akọni yii bá sì ṣe àtìpó sí tàbí tẹ̀dó sí ni wọn ti ń ba ènìyàn. Otitọ ni wọn gba orí l’ọ́wọ́ àwọn ti wọn ń bá ti wọn sì ń di ‘Akẹ́hìndé gba ẹ̀gbọ́n’, ṣugbọ́n bi wọn bá ti ń di onile ni ibi ti wọn tẹ̀dó, tàbí ti wọn ṣe àtìpó si yii, ni wọn mú díẹ̀-díẹ̀ lò nínú èdè, àti àṣà wọn nitori pe bi ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ bi kò tilẹ di ọṣẹ yoo dà bí ọṣẹ; àti pé ti ó bá pẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà bá ti jẹ iyán, kì í mọ òkèlè ẹ̀ bù mọ́; òkèlè ti ó yẹ kí ó máa bù nlanla yoo di ródóródó. Eyí ni ó sì ń fa ìyàtọ̀ díẹ̀-díẹ̀ nínú ìṣesí àwọn Yorùbá nibikibi ti wọn bá wà l’ónìí.

(d)	Bi àwọn ọmọ Yorùbá ti ṣe ń rìn jinna sí, sí Ile-Ifẹ ni ahọ́n àwọn ẹ̀yà náà ṣe ń yàtọ̀. Awọn tó gba ọna òkun lọ ń fọ èdè Yorùbá ti ó lami, ti a sì ń dàpè ni ÀNÀGÓ, àwọn ti wọn sì gba ọna igbó àti ọ̀dàn lọ ń sọ ogidi Yorùbá, irú wọn ni a sì ń pè ni ará òkè. 

Pàtàkì nínú àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó kúrò ni Ile-Ifẹ ti ó sì gba apá òkè lọ nínú igbó ati ọ̀dàn niyi: 




#Article 158: Ogun Àgbáyé Kìíní (1460 words)


ÌJÀ OGUN ÀGBAYÉ KÌÍNÍ Láti ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni àwọn ìwọ̀ búburú bí i: jàgídíjàgan, wàhálà. Rúkèrúdò ti wà nínú ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn. Rògbòdìyàn kò yé sẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ nì làásìgbò kò roko ìgbàgbé. Ìdàrúdàpọ̀ nínú ẹbí, Àríyànjiyàn láàárin ọ̀rẹ́. Gbọ́nmisi, omi ò to kò yé wáyé láàárín ìlú sí ilu, abúléko sí abúléko. Gbogbo àwọn nǹkan ló ń parapọ̀ tí ó sì ń di ogun. 

Tí a bá fi ojú sùnùkùn wo ogun àgbáyé kìíní, a óò rí wí pé gbogbo rògbòdìyàn, àjàkú akátá tó wáyé, kò sẹ̀yìn ìwà ìgbéraga, owú jíjẹ, èmi ni mo jùọ́ lọ, ìwọ lo jùmí lọ láàárín àwọn ọmọ adáríwurun. Àwọn àgbà sì bọ̀ wọ́n ní “àìfàgbà fẹ́nìkan ni kò jẹ́ káyé ó gún”. Nígbà tí ẹnìkan bá rò pé òun ló mọ nǹkan ṣe jú, èrò tòun ló tọ̀nà jù, kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ ta ko ohun tí òun bá sọ. Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó máa ń bí ogun, nígbà tí elòmírà bá ta ko irúfẹ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí ó jẹ gàba lé òun lórí. Bí ogun ṣe máa ń sẹlẹ̀ láàárin ìlú sí ìlú ló máa ń sẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè. 

Ara àwọn nǹkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí. Ogun àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárin orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Austria-Hungary ati Serbia. Ìlú kékeré kan ní awọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ ẹ̀kẹjì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908. Orílẹ̀-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. Sáájú àsìkò yìí, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara wọn. Sáájú ogun àgbàyé kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọ́n orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máà, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira. 

Orílẹ̀-èdè [Belgium] gba òmìnìra ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [Germany] gba tiwọn ní 1871. Ìjà òmìnìra wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lólogbó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe si èyí. Gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ́ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Gbogbo wọn kóra pọ̀. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí sẹlẹ̀, àti àwọ́n ìsòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn òyìnbó sí ilẹ̀ aláwò dúdú [Africa] wà lára àwọn nǹkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. Owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yíò rọrùn fún àwọn láti rí nǹkan àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń fẹ́ tí àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ̀ bèrè sí wáyé láàárin wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn. Nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn, bí wọn ṣe pin kò tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn nígbà náà Àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí furá sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ijà olóró jọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn sọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, awọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. 

Orílẹ̀-èdè [Germany], [Austria-Hungary] ati [Italy] wà ní ẹgbẹ́ kan, nígbà tí orílẹ̀-èdè [Britain], [France] àti [Russia] wà nínú ẹgbẹ́ kejì, Ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹfà ọdún 1914 [18/6/1914] ni okùnrin kan tó ń jẹ́ Gavrilo Princip tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Serbia sekú pa ọmọ Ọba orílẹ̀-èdè Astria-Hungary tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francis Ferdinand ẹni tó yẹ kó di ọba ní orílẹ̀-èdè náà. Èyí kò sẹ̀yìn ìgbìyànjú Serbia láti gba àwọn ẹ̀yà tí Austria-Hungary ti kó sínú ìgbèkùn nínú ogun tí wọ́n ti jà tẹ́lẹ̀. Ikú ọmọ ọba yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé nígbà tí orílẹ̀-èdè Astria-Hungary gbaná jẹ. Wọ́n pinnu láti gbógun ti ilẹ̀ Serbia. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ilẹ̀ Russia tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ilẹ̀ Serbia kéde pé àwọn yíò gbógun tí ilẹ̀ Austria-Hungary. Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbìyànjù láti pẹ̀tù sí wàhálà yìí. Ilẹ̀ 

Austria-Hungary fún ilẹ̀ Serbia ní àwọn nǹkan tó le mu ogun yìí wọlè, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Serbia kò tẹ̀lé àwọn nǹkan wọ̀nyí. Látàrí èyí, ilẹ̀ Austria-Hungary kéde ogun lé Serbia lórí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù kẹjọ ọdún 1914 [28/8/1914]. Bí ilẹ̀ Austria-Hungary ṣe ṣe èyí tan ni orílẹ̀-èdè Russia náà kéde ogun lé ilẹ̀ Austria-Hungary lórí. Bí ilẹ̀ Russia ṣe ṣe èyí tán ni ilè Germany kìtọ̀ fúnwọ̀n pé tí wọ́n bá danwò, àwọn yíò gbógun tìwọ́n. Nígbà tí ilẹ̀ Austria-Hungary ríbi tí ọ̀rọ̀ yìí ń tọ, wọ́n tẹsẹ̀ dúró fún ìjíròrò pẹ̀lú ilẹ̀ Russia. Ilẹ̀ Germany pàsẹ láti tú àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kójọ tẹ́lẹ̀ kọ́ fún ogun yìí ká. Ilẹ Russia kọ etí ikún sí àsẹ tí ilẹ̀ Germany lórí àsẹ yìí. Èyí ló mú kí ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ Russia lórí ní ọjọ́ kìíní osù kejọ ọdún 1914 [1/8/1914]. Ní ọjọ́ kejì sí èyí ni ilẹ̀ ni ilẹ̀ France náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany náà lórí. Ní ọjọ́ kẹta ni ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ France lórí padà. 

Sáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Belgium tí kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù pé tí ogun bá bẹ̀rẹ̀, àwọn kò ní lọ́wọ́ síi. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sì fọwọ́ sí ìwé tí ilẹ̀ Belgium kọ síwọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Germany pinu láti gba ilẹ̀ Belgium kọjá láti kọ lu ilẹ̀ France. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Belgium kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ti pínú pé àwọn kò ní dá sí ìjà. Èyí mú kí ilẹ̀ Germany bínú, wọ́n sì pínú láti gbógun tí ilẹ̀ Belgium. 

Ìpin ìlẹ̀ Germany yìí mú kí ilẹ̀ Britain dá sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n kìlọ̀ fún ilẹ̀ Germany láti ro ìpin àti gbógun ti ilẹ̀ Belgium ní ẹ̀ẹ̀mejì nítorí pé gbogbo àwọn ni àwọn fi ọwọ́ si pé ilẹ̀ Belgium kò ní lọ́wọ́ si ogun yìí nítorí náà, kí wọ́n má ṣe gbógun ti ilẹ̀ Belgium. Ilẹ̀ Germany kọ̀ jálẹ̀ láti gba ọrọ yìí yẹ̀wò, èyí sì mú kí orílẹ̀-èdè Britan kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lóri ní ọjọ́ kẹrin osù kẹjọ ọdún 1914 [4/8/1914]. 

Ilẹ̀ Turkey náà dá sí ogun yìí ní osù kẹwàá ọdún 1914. Nígbà tí ilẹ̀ France náà da si ní osù kọkànlá ọdún 1914. Báyìí ni ogun yìí di ogun àgbéyé, tí ó di ìjà àjàràn. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí awọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí ń ṣe àkóso lé lórí tí wọ́n ń mú sìn pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ [Africa] àti ilẹ̀ Lárúbáwá ni gbogbo wọn náà múra láti gbè sẹ́yìn àwọn ọ̀gá wọn láti bá àwọn orílẹ̀-èdè yòókù jà tí èyí sì di isu atayán-an yàn-an káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé. 

Ní osù kẹrin ọdún 1917 ni ile America náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lórí látàrí bí wọn ṣe kọlu àwọn ara ilẹ̀  America nínú ọkọ̀ ojú-oni ti èyí si tako ìlànà ogun jìjà. Òfin sì wà wí pé tí orílẹ̀-èdè méjì bá ń jà, àwọn ọmọ ogun ara wọn nìkan ní wọ́n dojú ìjà kọ. Orílẹ̀-èdè Germany rú òfin yìí. Èyí sì bí ilẹ̀ America nínú, ìdí nìyí tí wọ́n fi dá’ sí ogun àgbáyé ní ọdún 1917. 

Ogun àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù keje ọdún 1914 [28/7/1914] parí ní ọjọ́ kọkànlá osù kọ́kànlá ọdún 1918[11/11/1918] lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, osù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ogun ti bẹ̀rẹ̀. Owó tí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ná sí ogun yìí tó Ọgórùn-ún méjì Bílóọ̀nù dọ́là [Two Hundred Billons Dollas] owó ilẹ̀ America láyé ìgbà náà tí owó níyì. Bí i ogójì mílíọ̀nù [Fourty Millions] ọmọ ogun orílẹ̀-èdè àgbáyé ló bá ogun yìí lọ kí á ṣẹ̀ṣẹ̀ má sọ ti àwọn ogun ojú-oun bí i mílíọ̀nù mẹ́wàá [Ten millions] tí ó ará ìlú tá kìí ṣe sọ́jà ló sòfò nínú ogun àgbéyé yìí. 

Síbẹ̀síbẹ̀, wàhálà tó sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn rò pé yíò yanju tàbí níyanjú. Wàhálà yìí ló tún sokùnfà ogun àgbáyé kejì àti àwọn ogun tó tún wáyé lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní. 
Ní ìparí, ogun kìí ṣe nǹkan tí ó dára. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ẹni tí ogun ba pa kù ní ń ròyìn ogun. Ogun máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ èmí àti dúkìẹ́ sòfò. Yorùbá tún bọ̀ wọ́n ní ẹni tí sàngó bá tojú rẹ̀ jà rí kò ní báwọn bú olúkòso. Ẹnì tí Ogun bá jà lójú rẹ̀ rí, kò ní bẹ ọlọ́run kí ogun tún wáyé ní ojú òun. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí á ri ogun.




#Article 159: Ìyísódì nínú Ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ (2883 words)


ÌYÍSÓDÌ NÍNÚ Ẹ̀KA-ÈDÈ ÌKÁLẸ̀

Ìfáàrà
	
Gẹ́gẹ́ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu YA, Ìkálẹ̀, tíí ṣe ọ̀kan lára àwọn èka-ède Yorùbá, máa ń ṣe àmúlò oríṣiríṣi wúnrẹ̀n láti fi ìyísódì hàn. Ìyísódì lè jẹ yọ nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, ó sì tún lè jẹ yọ nínu ìhun gbólóhùn kan. Ṣíṣe àfihàn àwọn ọ̀nà lóríṣiríṣi tí ìyísódì máa ń gbà wáyé nínu ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ gan-an ló jẹ wá lógún nínu iṣẹ́ yìí.

Ìyísódì Ẹyọ Ọ̀rọ̀
	
Àkíyèsí fí hàn pé irúfẹ́ ọ̀rọ̀ méjì ló wà: ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ (èyí ti a kò ṣẹ̀dá) àti ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan wà tó jẹ́ wí pé wọ́n ní ìtumọ̀ ìyísódì nínú. Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni rárá. Rárá jẹ́ òdi bẹ́ẹ̀ ni. Ó máa ń dúró gẹ́gẹ́ bíi ìdáhùn gbólóhùn ìbéère

	(b)	(i)	Rárá			(ii)	Rárá

A ó ṣe àkíyèsí wí pé rárá jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tó ń ṣiṣé gbólóhùn òdì.
	
Tí a kò bá fé lo rárá fún ìdáhùn (21a), a lè sọ wí pé:

							
	(c)	(i)	Adé éè wúlí		(ii)	Adé kò wálé.
	
Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ kejì ni ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn yìí ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá tí wọ́n sì ń fún wa ní òye ìyísódì. A pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá, nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ oní-mọ́fíìmù kan. Tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ yìí, a máa ń lo mọ́fíìmù ìsẹ̀dá mọ́ ọ̀rọ̀ ìpìlè, èyí tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀-ìṣe ló máa ń jẹ; àkànpọ̀ àwọn méjéèjì máa ń yọrí sí ọ̀rọ̀-orúkọ. Fún àpẹẹrẹ:
						

   	(b)	(i)	àì- + gbọ́n	 àìgbọ́n	(ii)	àì- + gbọ́n	àìgbọ́n

   	(c)	(i)	àì - + jẹun	 àìjẹun		(ii)	àì - + jẹun	àìjẹun
	
A ṣe àkíyèsí pé mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá àì- náà ni YA máa ń lọ láti fi yi ọ̀rọ̀-ìṣe sódì.

Ìyísódì Fọ́nrán Ìhun Nínu Gbólóhùn Àkíyèsí Alátẹnumọ́

Bí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, fọ́nrán ìhun tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí sí ni a ó gbé sí iwájú gbólóhùn ìpìlẹ̀. Ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé a ó fi ẹ̀rún ní sí èyìn fọ́nrán ìhun náà tí a fẹ́ pe àkíyèsí sí. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè ṣe bẹ́ẹ̀ gbé sí iwájú ni: òlùwà, àbọ̀, kókó gbólóhùn, ẹ̀yán, àpólà-atọ́kùn. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè pe àkíyèsí sí yìí ni a lè yí sódì. A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 

Ìyísódì Olùwà
	
Bí ó ṣe jẹ́ wí pé a lè pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí olùwà nínu gbólóhùn, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè ṣe ìyísódì fún un. Ée ṣe ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò fún ìyísódì Olùwà nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́. Sùgbọ́n nínu YA, ọ̀nà méjì ni a lè gbà ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tí a pẹ àkíyèsí sí. A lè lo atóka ìyísódì kọ́ tàbí kì í se. Fún àpẹẹrẹ:
						

	(b)(i)	Ée ṣe àwa		(ii)	Àwa kọ́ 
   tàbí 
kì í ṣe àwa.

	(b)(i)	Ée ṣe Olú ò ó lọ	(ii)	Olú kọ́ ni ó lọ   
     tàbí 
Kì í ṣe Olú ni ó lọ

(b)(ii)	Ée ṣe ọmọ pupa ò ó hùn (ii) Ọmọ pupa kọ́ ni ó sùn 
	tàbí
						Kì í ṣe ọmọ pupa ni ó sùn

A ṣe àkíyèsí pé rín ni atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ nínu ẸI. Tí a bá sì ti ṣe ìyisódì fọ́nrán ìhun tí a pe àkíyèsí sí, atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ náà kì í jẹ yọ mọ́.

Ìyísódì Àbọ̀
	
Pípe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí àbọ̀ nínu gbólóhùn fara jọ ìgbésẹ̀ ti Olùwà. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbè ni pé tí a bá ti gbé àbọ̀ síwájú, ààye rẹ̀ yóò sófo.
	
Tí a bá fẹ ṣe ìyísódì àbọ̀ inú gbólóhùn, ée ṣe náà ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò. Fún àpẹẹrẹ:
							

	(b)	(i)	Ée ṣe Adé Olú nà	(ii)	Adé kọ́ ni Olú nà
							      tàbí
							kì í ṣe Adé ni Olú nà

(b)	(i)	Ée ṣe ẹran kítà á pa	(ii)	Ẹran kọ̀ ni ajá pa	
     tàbí 
Kì í ṣe ẹran ni ajá pa

Ìyísódì Kókó Gbólóhùn
	
Tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí kókó gbólóhùn, a máa ń ṣe àpètúnpè ẹlẹ́bẹ fún ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí a ṣe ń ṣe èyí ni pé a ó ṣe àpètúnpè kọ́nsónáǹtì àkọ́kọ́ ti ọ̀rọ̀-ìṣe náà kí a tó wá fi fáwẹ̀lì /i/ Olóhùn òkè sí ààrin kọ́ńsónáǹtì méjéèjì. Fún àpẹẹrẹ:
							

	(b)	(i)	Rírà babá ra bàtà rín		(ii)	Rírà ni babá ra bàtà

(b)	(i)	Fífọ̀ Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ múẹ̀n rín 	(ii)	Sísọ ni Ìyábò sọ ọ̀rọ̀ 
mìíràn
Ìyísódì (28) (b) ni (30) nígbà tí ìyísódì (29) (b) ni 31)
						

tàbí
							Kì í ṣe rírà ni bàbá ra bàtà

mìíràn 	
tàbí 
Kì í ṣe sísọ ni Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn.

Ìyísódì Ẹ̀yán
	
Ọ̀nà tí a ń gbà yí èyán sódì nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ yàtọ̀ díẹ̀ sí tí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù. Ìgbésẹ̀ kan wà tí a máa ń ṣe fún èyán tí a pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì rẹ̀. 
	
A lè yíi sódì nínu àpólà-orúkọ tí ó ń yán, a sì tún lè yíi sódì láìbá àpólà-orúkọ tó ń yán rín. Tí èyí bá máa wáyé, a gbọdọ̀ sọ ẹ̀yán náà di awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwe, kí á tó yíi sódì. Yí ni atọ́ka awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwẹ nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìyísódì ẹ̀yán tó dá dúró láìba ọ̀rọ̀-orúkọ tó ń yán rìn ni:
							

tàbí 
Pupa kó ni ọmọ tí mo rí.

							tàbí
							Ègùn kọ́ ni ilè tí lọ

Ìyísódì Àpólà-Àpọ́nlé
	
Gẹ́gẹ́ bí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù ṣe máa di gbígbe síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí wọn, àpólà-àpọ́nlé náà máa ń di gbígbé wá síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí i.
	
Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni àpọ́là-àpọ́nlé máa ń ṣe nínu gbólóhùn: àwọn kan máa ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn náà ti wáyé; àwọn kan sì máa ń sọ ìdí tí ìṣèlẹ̀ náà fi wáyé.
	
Tí a bá fé ṣe ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn ti wáyé, a ó kọ́kọ́ gbé àpólà-àpọ́nlé náà síwáju, a lè ṣe ìpajẹ ọ̀rọ̀-atọ́kùn tó síwáju rẹ̀, a sì lè dáa sí. Tí a bá ṣe yí, a ó wá fi èrún ti kún àpólà-ìṣe náà. Àpẹẹrẹ ni:
							

	(b)	(i)	Ée ṣe Ọ̀rẹ̀ mọ ti jẹun		(ii)	Ọ̀rẹ̀ kọ́ ni mo ti jeun
Àpẹẹrẹ ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ìdí tí ìṣe inú gbólóhùn fi wáyé ni
							

wọ́n ṣe ṣiṣẹ́

Ìyísódì Àsìkò, Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ àti Ojúṣe 
	
Oríṣiríṣi àríyànjiyàn ló wà lóri pé ède Yorùbá ní àsìkò gẹ́gẹ́ bí ìsọ̀rí gírámà tàbí kò ní. Bámgbóṣé (1990:167) ní tirẹ̀ gbà pé àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ wọnú ara wọn Ó ní:
Àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ máa ń fara kọ́ra nínu ède Yorùbá.

Èro Bámgbóṣé yìí ni yóò jẹ́ amọ̀nà fún wa nínu ìsọ̀rí yìí

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àdáwà
	
Àsìkò afànámónìí jẹ mọ́ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ń sẹlẹ̀, yálà ó ti ṣẹlẹ̀ tán tàbí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lásìkò tí à ń sọ̀rọ rẹ̀. Tí a bá lò ó pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, kò sí wúnrẹ̀n tó máa ń tọ́ka rè. Fún àpẹẹrẹ:
						

	Ìyísódì (36) ni:
							

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ
	
Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ máa ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà tí Olùsọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ èyí ni:
							

	
Éé ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ nínu ẸI, ṣùgbọ́n atọ́ka ìyísódì éè ni a fi ń yí i sódì. Àpẹẹrẹ ni:
								
	(b)	(i)	Olú éè rẹ̀n		Oléè rẹ̀n 	(ii)	Olú kò rìn

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú
	
Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán bárakú máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Máa ń àti a máa ló máa ń tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu YA. Ọ̀nà tí ẸI ń gbà tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yàtọ̀ gédéńgbé sí ti YA. Atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI ni éé àti a ka. Ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni:
					

Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ni:
					

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀

Stockwell (1977:39) ṣàlàyé ibá-ìsẹ̀lẹ̀ àṣetán gẹ́gẹ́ bí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí. Bámgbósé (1990:168) ní tirẹ̀ ṣàlàyé wí pé ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìbẹ̀rẹ̀ nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ti parí, ṣùgbọ́n tí ó ṣe é ṣe kí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà má tíì tán. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. A máa ń lò ó papọ̀ pẹ̀lú atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ 
							

Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Fún àpẹẹrẹ:
								

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí
	
Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí pátápátá. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni:
								

	
Éè ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. Nígbà tí a bá yíi padà, ohun ààrin to wà bẹ lóri atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò yí padà sí ohùn ìsàlẹ̀. Àpẹẹrẹ ni:

							

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lè Àdáwà
	
Nígbà tí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú bá ti jẹ yọ pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, (tí kò ní atọ́ka kankan), àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà nínu àsìkò ọjọ́-iwájú. Àwọn àpẹẹrẹ ni:
						

Ìyábọ̀ (51) ni (53), nígbà tí ìyísódì (52) ni (54)
						

lọ́la.

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ
	
Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni:

Ìyísódì rẹ̀ ni:

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú
	
Ìhun kan náà ni èyí ní pẹ̀lú ìhun àsìkò ọjọ́-iwájú àti ibá-ìṣẹ̀lẹ àìṣetán atẹ́rẹrẹ. Àpẹẹrẹ ni:
								

Ìyísódì gbólóhùn yìí ni:

	(b)(i)	Àlàdé éè níí ka jẹja ẹri	(ii)	Àlàdé kò níí máa jẹ ẹja odò

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀
	
Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni:
							

Ìyísódì rẹ̀ ni

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí
	
Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí ti jẹ yọ nínu àsìkò ọjọ́-iwájú ni:
							

	Ìyísódì gbólóhùn yìí ni:

	(b)	(i)	Olú éè tì níí rẹ̀n 	(ii)	Olú kò tíì níí rìn

Ìyísódì Atọ́ka Múùdù (Ojúṣe)

Adéwọlé (1990:73-80) gbà pé múùdù jé ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀ri gírámà Yorùbá. Ó pín wọn sí oríṣìí mẹ́ta nípa wíwo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹ yọ: Ó pe àkọ́kọ́ ni èyí tó ń fi ṣiṣe é ṣe hàn (possibility); ó pe èkejì ní èyí tó ń fi gbígbààyè hàn (permission); ó pe ẹ̀kẹta ni èyí tó pọn dandan. Àwọn múùdù wọ̀nyí ni à ń dá pè ni ojúṣe wọ̀fún, àníyàn àti kànńpá lédè Yorùbá. Fábùnmi (1998:23-24) pè é ní Ojúṣe.

Ìyísódì Ojúṣe Wọ̀fún	
	
Léè ni atóka ojúse wọ̀fún nínu ẸI. Fún àpẹẹrẹ:
							

Tí a bá yi atọ́ka ojúṣe yìí sódì, yóò di leè. Ée ni atọ́ka ìyísódì ojúṣe nínu ẸI.

Ìyísódì Ojúṣe Kànńpá
	
Gbẹẹ̀dọ̀ ni atọ́ka ojúṣe kànńpá nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ni:
						

Ìyísódì rẹ̀ ni:

Ìyísódì Ojúse Ànìyàn
	
Àríyànjiyàn pọ̀ lóri ìsọ̀ri gírámà tí yóò wà nínu YA.Bámgbóṣé (1990) gbà pé atọ́ka àsìkò ọjọ́ iwájú ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ bíi yó, ó, á. Fábùnmi (2001) ní tirè sàlàyé wí pé ojúse ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní Yorùbá tún máa ń lò wón láti fi tọ́ka sí àsìkò ọjọ́-iwájú. Oyèláràn (1982) nínu èro rẹ̀ kò fara mọ́ èro pé yóò jẹ́ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú. Ó ni yóò máa ń ṣiṣẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀, ò sì tún máa ń ṣiṣẹ́ ojúṣe nígbà mìíràn. Sàláwù (2005) ò gba yóò gẹ́gẹ́ bí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú tàbí ojúṣe. Ó ní yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ á, ó àti óó jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àníyàn nínu YA. Adéwọlé (1988) ní tirè ṣe òrínkíniwín àlàyé láti fi ìdi rè múlẹ̀ pé atọ́ka múùdù ni yóò. Nítorí náà, a ó lo wúnrẹ̀n yóò gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àníyàn. Nínu ẸI, a ni atọ́ka ojúṣe àníyàn. Fún àpẹẹrẹ:

					

Ìyísódì rẹ̀ ni:

jẹun lóko

Ìyísódì Odidi Gbòlòhún 
	
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìbẹ̀rẹ iṣẹ́ yìí, a lè ṣe ìyísódì ẹyọ ọ̀rọ̀, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì tún lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn pẹ̀lú. Bámgbóṣé (1990:217) sàlàyé pé ìyísódì odidi gbólóhùn ni èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ mọ wí pe ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nínu gbólóhùn náà kò ṣẹlẹ̀ rárá. Ó ní:
Tí gbólóhùn kò bá ní ju ẹyọ ọ̀rọ̀-ìṣe kan lọ nínu àpólà-ìṣe…, ìyísódì odidi gbólóhùn nìkan ni a lè ṣe fún un. Ṣùgbọ́n, tí ọ̀rọ̀-ìṣe bá ju ọ̀kan, tàbí tí àpólà-ìṣe bá ní fọ́nrán tí ó ju ọ̀kan lọ, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tàbí ti odidi gbólóhùn.

Ìyísódì Gbólóhùn Àlàyé
	
Gbólóhùn àlàyé ni a máa ń lò láti fi sọ bí nǹkan bá ti rí. Bámgbọ́sé (1990:183) sọ wí pé:
Tí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ bá fẹ́ẹ ṣe ìròyìn fún olùgbọ́, gbólóhùn yìí ni yóò lo. Gbólóhùn-kí-gbólóhùn tí kò bá jẹ́ ti ìbéèrè tàbí ti àṣẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ gbólóhùn àlàyé.

Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àlàyé ni:
							

Ìyísódì (67) ni (69), nígbà tí ìyísódì (68) ni (70)

Ìyísódì Gbólóhùn Àṣẹ

Máà ni wúnrẹ̀n tí ẸI ń lò fún ìyísódì gbólóhùn àṣẹ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àṣe ni
								

Ìyísódì (71) yóò fún wa ni (73)

Tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì (72), a ó yọ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ atẹ́rẹrẹ ka kùrò, a ó sì lo atọ́ka ìyísódì máà dípò rẹ̀. Ìyísódì (72) yóò yọrí sí (74)

						

Ìyísódì Gbólóhùn Ìbéèrè

Bámgbóṣé (1990:183-186) ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lóri ọ̀nà tí a máa ń gbà ṣe ìbéèrè nínu ède Yorùbá. Ó ní ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé kí á lo wúnrẹ̀n ìbéèrè nínu gbólóhùn.
	
A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan àti bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ pẹ̀lú wọn.

Gbólóhùn Ìbéèrè tí ó ń lo Atọ́nà Gbólóhùn
	
Ṣé ni ẸI máa ń lò gẹ́gẹ́ bí atọ́nà gbólóhùn láti fì ṣe ìbéèrè bẹ́ẹ̀-ni-bẹ́ẹ̀-kọ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn ìbéèrè oní-atọ́nà gbólóhùn ni:
		ẸI					YA

Éè ni ẸI ń lò láti fi ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè náà. Fún àpẹẹrẹ
							

	A ó ṣe àkíyèsí wí pé atọ́ka ìyísódí yìí máa ń jẹ yọ nípa pé kí á fi sí inú gbólóhùn lẹ́yìn Olúwà.

Gbólóhùn Ìbéèrè to ní Ọ̀rọ̀-orúkọ Aṣèbéèrè
	
Bámgbósé (1990:184) ṣe àlàyé pé nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ ni a ti máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè. Ó ní a lè dá wọn tò gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí kí á fi wọ́n ṣe ẹ̀yán fún ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn.
Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn yìí ni:
						

	(b)	(i)	Kíì yi we fẹ́ o?	(ii)	Èwo lẹ fẹ́ o?

(d)	(i)	Kéèlú àn án gba a?	(ii)	Èló ni wọ́n gbà?
A lè ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè wọ̀nyí. Ìyísódì (79 a-d) ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé ni:
				

(b)	(i)	Kíì yi wéè fẹ́ o?	(ii)	Èwo lẹ ò fẹ́ o?

	(d)	(i)	Kéèlú án àn gba a?	(ii)	Èló ni wọn ò gbà?

Gbólóhùn Ìbéèrè Ọlọ́rọ̀ọ̀ṣe Aṣèbéèrè
	
Han àti kẹ ni ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìlo wọn nínu gbólóhùn ni:
		ẸI					YA

A kò le ṣe ìyísódì gbólóhùn ọlọ́ròòṣe aṣèbéèrè. Fún àpẹẹrẹ:
		ẸI					YA

Ìyísódì Òǹkà Ẹ̀ka-Èdè Ìkálẹ̀
	
Ohun tí a fẹ́ ṣe nínu abala yìí ni ṣíṣe àfihàn ipa ti ìyísódì ní lóri òǹkà ẸI. Ohun tó jẹ wá lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí à ń gbà yí àwọn òǹkà sódì.
	
Ọ̀kan lára àwọn àtúnpín-sí-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ Bámgbóṣé (1990:97) ni ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà. Ó ni ọ̀rọ̀-orúkọ àṣeékà ni èyí tí a lè lò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òǹkà nítorí pe irú ọ̀rọ̀-orúkọ bẹ́ẹ̀ ṣe é kà.
	
Ní ìbamu pẹ̀lú èro Bámgbóṣé yìí, tí a bá lo ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-òǹkà papọ̀, yóò fún wa ní àpólà-orúkọ. Àtúpalẹ̀ irúfé àpólà-orúkọ yìí ni orí (tíí ṣe ọ̀rọ̀-orúkọ) àti ẹ̀yan rẹ̀ (ọ̀rọ̀ òǹkà náà). Irúfẹ́ ẹ̀yán yìí ni Bámgbóṣé pè ní ẹ̀yán aṣòǹkà.
Àpẹẹrẹ irúfẹ́ àpólà-orúkọ yìí ni:
							

	(b)	(i)	Ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún	(ii)	Ilé mẹ́tàdínlógún

	(d)	(i)	Bàtà maàdọ́gbọ̀n 	(ii)	Bàtà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n
	
Ìjẹyọ àwọn àpólà-orúkọ yìí nínu gbólóhùn ni:
							

	(b)	(i)	Mọ kọ́ ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún	(ii)	Mo ko ilé 
mẹ́tàdínlógún.

	(d)	(i)	Mọ ra bàtà maàdọ́gbọ̀n	(ii)	Mo ra bàtà 
mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n
	
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣaájú ní 3.3.4, wí pé tí a bá fẹ́ yí ẹ̀yán sódì, nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, a máa ń sọ ẹ̀yán náà di awẹ́ gbólóhùn asàpèjúwe. Ìgbésè yìí máa ń wáyé nínu ìyísódì òǹkà. Yí ní atọ́ka awẹ́-gbólóhùn-asàpèjúwe nínu ẸI. Ée ṣe ni atọ́ka ìyisódì èyán asòǹka nínu ẸI. Ìyísòdì ẹ̀yán asòǹkà nínu gbólóhùn (86 a-d) yóò fún wa ni (87 a-d)
							

								tàbí 
	Ọmọ tì mo rí, kì í ṣe mẹ́fà

	(b) (i) Ulí yí mọ kọ́, ée ṣe	 	(ii)	Mẹ́tàdínlógún kọ́ ni
		mẹ́ẹ̀tadínógún 				ilé tí mo kọ́
										tàbí 
									Ilé tí mo kọ́ kì í ṣe 
									mẹ́tàdínlógun

(d)	(i)	Bàtà yí mọ rà, ée ṣe 			(ii)	Mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kọ́ ni bàtà tí 
		maàdọ́gbọ̀n					mo rà
	 								tàbí 
								Bàtà tí mo rà kì í ṣe 
								mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n
	
A ó ṣe àkíyèsí wí pé ọ̀nà méjì ni YA lè gbà ṣe ìyísódì ẹ̀yán àsòǹkà, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan ṣoṣo ni ẸI ń gbà ṣe ìyísódì èyí.
	
Bámgbóṣé (1990:129) ṣe àkíyèsí irúfé àpólà-orúkọ kan to pè ní àpólà-orúkọ agérí. Irúfẹ àpólà-orúkọ yìí máa ń sáábà wáyé nínu àpólà-orúkọ tí ọ̀rọ̀ òǹkà jẹ́ ẹ̀yan rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ àpólà-orúkọ yìí ni àbọ̀ àwọn gbólóhùn ìsàlẹ̀ yìí:
						

	
A ó ṣe àkíyèsí pé ẹ̀yán asòǹka nìkan ló dúró gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ gbólóhùn òkè wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n sá, kì í ṣe pé àpólà-orúkọ náà kò ní orí; mọ̀ọ́nú ni orí àpólà náà, ó sì yé àwọn méjéèji tó bá ń tàkurọ̀sọ. Ée ṣe ni a fi máa ń yí irúfẹ́ àpólà-orúkọ agérí wọ̀nyí nínu ẸI. Ìyísódì ọ̀rọ̀ òǹkà nínu gbólóhùn (88) àti (89) ni:
						

tàbí
							Mẹ́wàá kọ́ ni mo jẹ

	tàbí
							Ọgọ́fà kọ́ ni Bọ́lá mu

Ìgúnlẹ̀
	
Nínu orí kẹta yìí, a ti gbìyànjú láti ṣe àgbékalẹ̀ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu ẸI. A ṣe àkíyèsí onírúurú ìhun tí ìyísódì ti ń jẹ yọ nínu ẸI. A jẹ́ kó di mímọ̀ pé a lè ṣe ìyísódì eyọ ọ̀rọ̀; a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn. A tún ṣe àgbéyẹ̀wò ìyísódì àsìkò, ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àti ojúṣe nínu ẸI.
	




#Article 160: Ìmò Ìṣirò (174 words)


Oju Ewe Imo Isiro

Ìmọ̀ Ìsirò jẹ́ èyí t'on jẹ mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgbọ́n ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wíwọ̀n ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). Eyi ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi ootọ́ re mulẹ̀ pelu itumo yekeyeke.

A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Bi a se n lo imo Isiro bo si apa eyi ti a n pe ni Imo Isiro Oníwúlò (Applied Mathematics). Apa keji Imo Isiro ni a mo si Imo Isiro Ogidi. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola.

                                            Awon Orisirisi Nomba ti o wa

                                             Awon Eka Imo Isiro




#Article 161: Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (590 words)


 
Jeremiah Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ (6 oṣù kẹta ọdún 1909 - 9 oṣù karún ọdún 1987), jẹ́ olósèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ̀wọ̀ jẹ́ olórí fún àwon ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú pàtàkì ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

A bí ni ọjọ́ kẹfà osù kẹta ọdún 1909 ni Ìkẹ́nnẹ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun lóòní. Omo àgbẹ̀ tí ó fi iṣẹ́ àti ògùn ìsẹ́ ṣọ ara rẹ̀ di ọ̀mọ̀wé, Awólọ́wọ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ Anglican àti Methodìst ni Ikénne àti ni Baptist Boys' High School ni Abéòkúta. Lèyìn rè ó ló sí Wesley College ni Ibàdàn tí ó fi ìgbà kan jé olùìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. O se olùdarí àti alákóso Egbé Olùtajà Awon Omo Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti àkòwé gbogbogbo Egbé Awon Awako Igb'eru Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union). 

Awólówó tèsíwájú nínú èkó rè, ó sí gbà ìwé erí kékeré ni ọdún 1939, kí ó tó ló láti gbà ìwé erí èkó gíga nínú ìmò owó ni ọdún 1944. Igbà yí nà ló tún jé olóòtú fún ìwé ìròyìn Nigerian Workers (Osisé Omo Ilè Nàìjíríà). Ní ọdún 1940 ó di àkòwé Egbé Odò Awon Omo Ilè Nàìjíríà (Nigerian Youth Movement) èka Ibàdàn, ibi ipò yí ni ó tí s'olori ìtiraka láti se àtúnse Igbìmọ́ Aláse Idámòràn Fún Awon Omo Ibàdàn (Ibàdàn Native Authority Advisory Board) ni ọdún 1942.

Ni ọdún 1944 o lo si ilu Londonu lati ko eko ninu imo ofin be ni o si se idasile Egbe Omo Oduduwa. Leyin igba to pari eko re ni ọdún 1947 o dari pada wale lati wa di agbejoro ati akowe agba fun Omo Egbe Oduduwa. Leyi ọdún meji, Awolowo ati awon asiwaju Yoruba yioku se idasile egbe oselu Action Group eyi ti o bori ninu ibo ọdún 1951 ni Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria. Larin ọdún 1951-54 Awolowo je Alakoso Fun Ise Ijoba ati Ijoba Ibile, o si di Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria ni ọdún 1954 leyin atunko Iwe Igbepapo Ati Ofin (constitution).Gege bi Olori Ijoba Agbegbe Iwo Oorun Ile Naijiria, Awolowo se idasile eko ofe fun gbogbo odo lati ri pe moko moka gba le ka. 

Nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà di olóm̀inira ní ọjọ́ kìnní oṣù kẹ́wàá ọdún 1960, Awólọ́wọ̀ di Olórí ẹgbẹ́ Alátakò (Opposition Leader) sí ìjọba Abubakar Tafawa Balewa àti Ààrẹ Nnamdi Azikiwe ní Ìlú Èkó. Àìṣọ̀kan tó wà láàrín òun àti Samuel Ládòkè Akíntọ́lá tó dipò rẹ̀ gẹ́gẹ́́ bí fìdí hẹẹ́ Olórí Ìjọba ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn mú ni ó dá fàá ká ja tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1962. Ní oṣù kọkànlá ọdún yí, Ìjọba Àpap̀ọ ilẹ̀ Nàìjíríà fi ẹ̀sùn kan Awólọ́wọ̀ wípé ó dìtẹ̀ láti dojú ìjọba bolẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ó tó oṣù mọ́kànlá, ilé-ẹjọ́ dá Awólọ́wọ̀ àti àwọn ọmọ ẹ̀gbẹ́ òṣ̀èlú rẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n (èjìlẹ̀wá sẹ́jọ) lébi èsùn ìdìtẹ̀, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. ọdún mẹ́ta péré ni ó lò ní ẹ̀wọ̀n ní ìlú Calabar tí ìjọba ológun Yakubu Gowon fi da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kẹ́jọ ọdún 1966. Lẹ́yìn èyí Awólọ́wọ̀ di Alákòóso Ìjọba Àpapọ̀ fún Ọrọ Okòwò. Ní ọdún 1979 Awólọ́wọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèlú kan Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀.

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣaláìsí ní ọjọ́ àìkú ọjọ́ kẹsàn oṣù kárùún ọdún 1987 ní ìlú Ìkẹnẹ́. Lẹ́yìn ikú Awólọ́wọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ yí orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ilé-Ifẹ̀ padà sí Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwòrán rẹ̀ wà lórí owó Ọgọ́rùún náị́rà fún ìṣẹ̀yẹ gbogbo ohun tó ṣe fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.




#Article 162: Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): A (1832 words)


Atumo-Ede

a  (1A) kan: I gave him a dog. (Mo fun ní ajá kan).
abandon (v); Kọ̀ sílẹ̀: He abandoned his job. (Ó kọ iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀)

abbreviation  (n);  ìkéúrú: Abbreviation is useful when taking lecture notes. (ìkékúrú wúlò tí a bá ń ṣe àkọsílẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

abdomen (n); ìkùn: The abdomen of the boy protruded because he over ate.  (ikùn ọmọ náà rí róńdó nítorí pé ó jẹun yó jù). 

ability (n); agbára tàbí òye: He has the ability to remember dates. (Ó ní òye ọjọ́ àti àkókò). 

able (adj); lè, lágbár: He is able to do all thing. (Ó lè ṣe ohun gbogbo). 

aboard (adv); nínú okò ojú omi tàbí òfúrufú; The captain welcomes you aboard this plane. (Adarí ọkọ̀ òfúrufú kì i yín káàbọ̀ sínú ọkọ̀. 

abolish  (v); parẹ́: Government has abolished the tax on agricultural products. (Ìjọba ti dá owó orí lori ohun ọ̀gbùn dúró. 

about (adv); yíká, nípasẹ̀: What ara you talking about Kunle? (kí ní ẹ̀ ń sọ nípa Kúnlé?) 

above (adv); lókè: We watched the birds above (À ń wo àwọn ẹyẹ lókè). 

abroad (adv); ẹ̀yìn odi, òkè òkun: My brother is studying abroad. (Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ń kàwé lókè òkun). 

abrupt (adj); lójijì, láìròtẹ́lẹ̀: He shouted abruptly. (Ó kígbe líjijì). 

abscess (n); ìkójọpọ̀ ọyún: The injection Joshua got from the nurse has formed abscess. (Abẹ́rẹ́ tí nọ́ọ̀sì fún Joshua ti di Ọyún). 

absent (adj); kò sí, kò wá; He was absent from work last Tuesday. (Kò wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tó kọ́já).  

absolute (adj); pátápátá; Amina has absolute freedom to choose a husband. (Amina ní òmìnìra pátápátá láti yan ọkọ). 

absorb (v) fàmu: The dry Gari absorbed water easily. (Gaàrí gbígbẹ náà fa omi mu). 

absurd (adj) ṣàìtọ́: He behaved in an absurd way. (Ó hùwà ní ọ̀nà tí kò tọ́). 

abundant (adj); lọ́pọ̀; rẹpẹtẹ: There was an abundant rain last year. (Òjò rò rẹpẹtẹ ní èṣí 

abura (n) ẹ̀yà igi kan: Olu made his furniture with abura (Olú kan àga rẹ̀ pẹ̀lú igi abura). 

abuse (v); èébú: ìlòkílò: The teacher abused his power. (Olùkọ́ náà ṣI agbára lò). 

acacia (n); ẹ̀yà igi kan: The old man rests under acacia tree. (Bàbá arúgbó náà ń gbatẹ́gùn lábẹ́ ogo kaṣíà).

academy (n); Ilé ẹ̀kọ́ gíga: He attends Baptist Academy. (Ó ń lọ sí ilé ìwé gíga ìjọ onítẹ̀bọmi). 

accent (v); àmì ohùn: (Yorùbá is an accent language. (Èdè Yorùbá jẹ́ èdè Olóhùn). 

accept: (v); tẹ́wọ́gbà: I accepted the doctors advice: (Mo gba imọ̀ràn dókítà). 

acceptable (adj);  ìtẹ́wọ́gbà: This work you have done is not acceptable, please do it again. (Iṣẹ́ tí o ṣe kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Jọ̀wọ́, lọ tun ṣe. 

access (n); ọ̀nà, àjè: I have access to the library. (Mo lè wọ ilé ìkàwé). 

accident (n)  èsì, ìjàmbá: There was an accident yesterday. (Ìjàmbá kan sẹlẹ̀ lánàá). 

accommodate (v) fún láàyè: You could accommodate another student in your room (Ó le fún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn láàyè nínú yàrá rẹ). 

accompany (v); Bálọ, Bárìn, Bákẹ́gbẹ́: He accompanied Bọla to Lagos. (Ó bá Bọ́lá lọ sí Èkó). 

accomplish (v) ṣe parí: I accomplished two hours work before dinner. (Mo parí iṣẹ́ wákàtí méjì kí oúnjẹ ọ̀sán tó tó). 

accord (n); ọkàn kan: We are in accord about this matter. (A wà ní ọkàn kan nípa ọ̀rọ̀ yìí). 

account  (n) ìṣirò, ìròyìn: Edwin gave an exciting account of the football match. (Edwin ṣe ìròyìn ìdíje bọ́ọ̀lù orí pápá).

accurate (adj) déédé: My watch is more accurate than yours. (Aago mi ṣe déédé ju tìrẹ). 
accuse (v) fi sùn: The teacher accused Tálá of stealing. (Olùkọ́ náà fi ẹ̀ṣùn kan Tálá pé ó jalè).

accustom (v) mọ́lára, sọdàṣà: She is accustomed to eating beef. (Ó mọlára kí ó máa jẹ ẹran). 

ache  (v) fífọ́, ríro: Her head ached all night (orí fọ́ọ ní gbogbo òru). 

achieve (v) ṣetán, ṣerere: He achieved success in his studies. (Ó ṣe rere lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀). 

acid (n) ohun tó kan tàbí nínú: Some acid dropped onto Maria’s skirt and made a hole in it. 

acknowledge (v) Jẹ́wọ́, gbà: They acknowledged Olu as the cleverest student. (Wọ́n gbà pé Olú ni akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jùlọ). 

acquaintance (n); ojúlùmọ̀: He is an acquaintance of mine (Ojúlùmọ̀ mi ni). 

acquire (v); Jèrè: Ayo acquired his wealth through frand. (Ayò kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ lọ́nà ẹ̀ní). 

acquint (v) dáláre, dásílẹ̀ The suspect was acquitted by the court (Ilé ẹjọ́ dá arúfin náà sílẹ̀). 

acre (n); gburè ilẹ̀: The acre of land belongs to the Chief. (Olóyè ló ni gburè ilẹ̀ náà. 

across (adj); rékọjá: My friend lives in the house across the street. (Ilé tó wà ní ìfòná títì ní ọ̀rẹ́ mi ń gbé). 

act (v) ìṣe, òfin: Killing the lion was an act of bravery. (Iṣé akin ni pípa kìnìún).

active (adj) yára: My little brother is very active, he never sits still. (Àbúrò mi ọkùnrin yára púpọ̀ kì í wò sùù). 

actor (n); Òṣèré ọkùnrin: Hubert Ogunde was a a famous actor. (Gbajúmọ̀ òṣèré ni Ògúndé ń ṣe láyé àtijọ́).

actress (n); òṣẹ̀ré obìnrin: Liz Benson is one of the Contemporary actress. (Ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin ìwòyí ni Liz Benson ń ṣe). 

actual (adj); nítòótọ́, pàápàá, gan-an: He is the actual person that stole the goat. (Òun gan an ló jí ewúrẹ́ náà). 

A.D.  Lẹ́yìn ìkú Olúwa wa: This Church was built in 1950 A.D. (A kọ́ ìlé ìjọsìn yìí ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ó dín díẹ̀ lẹ́yìn ikú Olúwa wa). 

adapt (v); bádọ́gba: mólára, wà fún: It is sometimes difficult to adapt to town life. (Ó máa ń ṣòrọ nígbà míràn kí ìgbé ayé ìgboro tó mómi lára). 

add (v); fikún: There were seven eggs in the basket I added three, so now there are ten. (Ẹyindìyẹ méje ló wà nínú apẹ̀rẹ̀, mo fi mẹ́ta kún un, ní bá yìí ó ti di mẹ́wàá. 
adder (n); paramọ́lẹ̀: Adder is a poisonious snake. (Ejò olóró nì paramọ́lẹ̀). 

address (n); bá sọ̀rọ̀, kọ̀wé sí: Always address elders with respect. (Máa bá àwọn àgbà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀).

adequate  (adj); tó: There is an adequate amount of food for everyone. (Oúnjẹ tó tó wà fún gbogbo ènìyàn). 

adjective (n) Àpèjúwe: She sang a beautiful song. (Ó kọ orin dádùn). 

adjust  (v) tún ṣe, tò léṣẹsẹ: Olù adjusted his trousers. (Olú tún ṣòkòtò rẹ̀ ṣe). 

administer (v); ṣàkóso: The government administers the Country. (Ìjọba ń ṣàkóso orílẹ̀, èdè). 

administrator (n); alákòóso: The Principla is the administrator of the school. (Ọ̀gá ilé ìwé ni alákòóso ìlé ìwé náà). 

admiral (n); Olórí ọkọ̀ ogun: My brother is an admiral. (Olórí ọkọ̀ ogun ojú omi ni ẹ̀gọ́n mi). 

admire (v); jọmi lojú, yìn; wuyì lójú: I admire his Kindness. (Ìwà rere rẹ̀ jọmi  lójú). 

admit (v) gbà sílẹ́, jẹ́wọ́: He admitted his failt. (Ó jẹ́wọ́ àìṣe déédé rẹ̀). 

adolescent (adj) Ọ̀dọ́ rẹ̀. Adolescent life is full of mistakes. (Ìgbà ọ̀dọ́ kún fún àṣìṣe). 

adopt (v) sọdọmọ: The childless couple adopted a child at last. (Tọkọtaya tí wọ́n yàgàn náà ti fi ọmọ kan sọmọ nígbẹ̀yìn).
adore (v); júbà; fẹ́ràn lọ́pọ̀lọpọ̀: The boy adores chocolate. (Ọmọkùnrin náà fẹ́ràn ìpápánu púpọ̀). 

adult (n); àgbà: Olu is now an adult. He can take decisions on his own. (Olú ti dàgbà báyìí. Ó lè dá romú, kí ó sì ṣe ìpinnu lórí ohun tí ó kàn án. 

advance (v); ìlọsíwájú, àgbàsílẹ̀ owó. We are more advanced in techonology. (A ti lọ síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ). 

advantage (n); àǹfààní: There are lots of advantages in doing good. (Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú síṣe rere).

adventure  (n); ìdáwọ́lé: He went into a lot of adventures in order to learn more. (Ó dáwọ́lé oríṣìíríṣìí ń kan kí ó lè ní ìmọ̀ si). 

adverb (n); ọ̀rọ̀ àpọ́nlé: She sang a song beautifully today. (Ó kọrin dáradára ló nìí. 

advertise  (v) kéde, polówó;  The supermarket was advertising salt at a good price. (ilé ìtàjà náà ń polówó iyọ̀ ní owí pọ́ọ́kú). 

advise (v); dárúmọ̀ràn, dámọ̀ràn; ìmọ̀ràn: She advised me to beware of dog. (Ó gbàmí nímọ̀ràn wípé kí n ṣọ́ra fún ajá). 

aerial (n); lójúsánmọ̀, lójúọ̀run: The aerial of my radio is fanlty. (Ọ̀pá redio mi kò dára). 

aeroplane (n); bààbú, ọkọ ofurufu: There was a plane crash at Abuja. (Ìjàmbá ọkọ̀ òfúrufú ṣẹlẹ̀ ní Àbújá). 

affair (n); ìṣe: The party was a very noisy affair. (Ayẹyẹ náà jẹ́ aláriwo). 

affect (v); mú lọ́kàn, kàn: This new rule will not affect me as lam leaving the school. (Òfin tuntun yìí kò kàn ní torí pé mò ń fi ilé ìwé náà sílẹ̀. 

affectionate (adj); nífẹ̀ẹ́: Her mother writes her long, affectionate letters. (Ìyá rẹ̀ kọ lẹ́tà ìfẹ́ gígùn si). 

afford (v); ní agbára láti ṣe ǹkan. My father says he can’t afford a car. (Bàbá mí ní àwọn kò ní agbára láti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́). 

afraid (adj); bẹ̀rù, fòyà, kọmimú: Olu says he’s not afraid of lion. (Olú sọ wí pé òun kò bẹ̀rù kìnìún). 
after (prep); lẹ́yìn, tẹ̀lé: Tomorrow is the day after today. (Ọ̀la ni ó tẹ̀lẹ́ òní). Ọ̀sán (n) afternoon: Come again this afternoon. (Padà wá ní ọ̀sán yìí). 

afterwards (adv); Nígbèyìn: We want to the film and afterwards we walked home together. (A lọ síbi sinimá, nígbẹ̀yìn a jọ rìn lọ sílé). 

again (adv); ẹ̀wẹ̀, lẹ́ẹ̀kejì: I liked the book so much that I read it again. (Mo gbádùn ìwé náà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ tó jẹ́ pé mo tún un kà). 

against (prep); lòdìsí: Our teacher is against bad habits. (Olùkọ́ wa lòdìsí ìwà ìbàjẹ́). 

agbádá (n) agbádá: The agbada he put on made him look twice his age. (Agbádá tí ó wọ̀ mú u dàbí àgbàlagbà). 

age (n); Ọjọ́ orí: Mary’s age is eight. (Ọjọ́ orí Maria ti tó ọdún mẹ́jọ). 

age (v); dàgbà, gbó: He has aged because of hard labour. (Ó ti gbó nítorí ìṣẹ́ agbára). 

agent (n) Aṣojú: My father is a postal agent. (Aṣojú ilé ìṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ni bàbá mi). 

agnostic (n); aláìgbàgbọ́: Olú is an agnostic. (Aláìgbàgbọ́ ni Olú). 

ago (adv); kọjá, sẹ́yìn: We came to live here six years ago. (A dé síbí ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn). 

agony (n); inira, ìrora: The wounded man was in agony. (Inu ìrora ni ọkùnrin tí ó ṣèṣe n nì wà). 

agree (v); sàdéùn, fohùnsọ̀kan: I agree with you. (Mo fohùn sọ̀kan pẹ̀lú rẹ). 

agriculture (n); iṣẹ́ àgbẹ̀: Agriculture is important because we all have to eat. (Iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí wí pé gbogbo wa ni a máa jẹun). 

ahead (adv); ní wájú: We shall have to cross that river ahead of us. (A máa rékojá odò tí ó wà ní wájú wa). 

ahmadiyya(n); Ẹ̀yà èṣìn mùsùlùmí: Alhajì Yusuph is of Ahmadiyya Sect. (Ẹ̀yà Ahmadiyya ni Alhaji Yésúfù). 

aid  (n) ìrànlọ́wọ́: A dictionary is an aid to learning English. (Ìwé asọ̀tumọ̀ jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì). 
aid (v); gbọwọ́, Olùgbọ̀wọ́: He aided the criminal. (Ó ṣe Olùgbọ̀wọ́ ọ̀daràn náà). 

aim (v);  Èrò, fojúsùn: He aimed to be the best football player in the school. (Ó gbèrò láti jẹ́ òṣèré orí pápá tí ó dára jùlọ ní ilé ìwé). 

aim (n); fojúsùn: He aimed at the lion. (Ó fojúsun kìnìún náà). 




#Article 163: Àdúgbò Oyé-Èkìtì (169 words)


ti ẹrin náà ku si iba ni wọn pe ni atẹba ẹni to pa erin náà ni ọlọta aburo ijise ibi ti wọn pa erin náà si ni wọn pe ni ijisẹ. Ijisẹ lo pa àwọn ara Ọyẹ wa lati ile ifẹ pe wọn ti ri ibi tí wọn magbe. Ijisẹ ni orisu ilu Ọyẹ lati ile-ifẹ wa. 

yẹn.

ijisẹ. 

Igbati wọn de ilu Ọyẹ wọn sit un pe wọn ni ijagẹmọ nitorí ija wọn. 

ni ọmọ orin yọyọ ilugbo. 

si ilu Ọyẹ láti ba ọba ji roro, ìdí ti wọn fi pe wọn ni ilupeju. 

àwọn ara Ọyẹ ri pe ọlọrọ ni wọn jẹ ni wọn se pe wọn ni orísunmibare. 

ifẹ.

wọn fi ń pe ni ile-yao. 

ilẹmọ ni yen.

Ijisẹ. 

Ọyẹ. 

Ibẹru:- 	Ọlota ni aburo Ijise lati ile ifẹ wa nígbati wọn de Ọyẹ iberu ati Ijisẹ wa yapa o sit un jẹ àdúgbò ti o bẹru ogun tàbí ija púpọ̀. 

se wa si ilu Ọyẹ ìdí ti wọn fi tẹ̀dó si ìlú Ọyẹ ni èyí.




#Article 164: Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): B (152 words)


ọmọ ọkùnrin). 

sílẹ̀, nítórí pé ó ti wọ́n jù). 

rẹ̀). 

ní òwú dúdú).

ọpọlọ gbá òkúta). 

dára). 

igi, ó sa pamọ́ si ara ẹ̀ka igi). 

ìfowópamọ́ náà pẹ̀ka kaàkiri orílẹ̀ èdè yìí. 

òdùduwà). 

gbóyà lati wo inú ilé tí ó ń jó). 

ńmu omí ìyá rẹ̀). 

náà lọ).

náà bẹ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ki o to gba òògùn rẹ̀). 

produce the teath. (Ìyàwó á bí mẹ́sàn-án, á fi ọ̀kan se ẹ̀nì). 

dé). 

ọmọ ogun ni o da owo ju(. 

náà). 

náà mú wá àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́wàá). 

forí sogi ó rún wómú wómú). 

ìgbìmọ̀ fún káàkiri ti alámọ̀ funfun). 

fífọ́). 

wa).

asọ rẹ̀). 

lẹ́tà dànù ní ọwọ́ mi). 

mọ́ ìyẹ̀pẹ̀). 

àgbọ̀nrín náà ti jẹ ilá tán ni oko.

garawa). 

ọ̀gbìn). 

ìròhùn owó ìlú ni gómìnà kà). 

ìlẹ́ Indíà). 

yẹ lọ). 

ìwọ̀n). 

ìwo). 

mi). 

àpótí). 

kan. 
	

náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri). 

àwọn òbí rẹ̀). 

àpáta). 

igbó)

se òwò ìwé títà). 

tí ó rán). 

káàkírì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà). 




#Article 165: Àdúgbò Àgọ́-Ìwòyè (225 words)


àwọn Àbíkú ọmọ, o máa ń mú wọn dúró láti má lè jẹ́ kí wọ́n kú. Orúkọ Bàbá yì ni wọ́n fi wá ń pé àdúgbó yí ní ìsámùró. 

	

nìyí tí a fi n pè bẹ́ 

àgbolé yì ní òshóòsì 

agbolé yìí ní olóòlù.

ìwòyè, ìdí nì yí tí a fi ń pe agbolé yìí ní Akádì eredò. 	

dirun sórí bí ogbe orí àkùkọ adìẹ. Ìdí nìyí tí a fi ń pe agbolé yì ní Edùwe. 

asiko yi, ìdí niyi ti a fi pe agbole yii ni Batadiran.

fí ń pe agbolé yì ní Agbélékalẹ̀ bí ère. 

sókè de ini tí ó wà lónì yìí. Ìdí nì yí tí a fi ń fi orúkọ rẹ̀ pe Agbolé 
yìí.

fi ń pe ni dosunmu.

pípẹ́ sẹ́yìn, ó sì ti se nkan rere ní ìdí isẹ́ yìí, ìdí nìyí tí a fí ń pé olówó iranrìn.

yí tí a se ń fi orúkọ rẹ̀ pe àdúgbò yí bayi olópò mẹ́rin.

òní olónì, ìdí nìyí tí a fi ń pe àdúgbò yí ní Ìmosù.

yí.

pe agbolé yìí.

odùdányà, oyè yí wá jámọ́.

Orúkọ Baálè yí nì asì fí ń pé agbolé yìí títí di òní olónìí.

opopona ọjà. 

láti inú ìlú Àgó ìwòyè. Ọ̀nà yí ni wọ́n fi pe àdúgbò.

ń pe àdúgbò náà ní ajọbì láre.

nìyí tí a fi ń pé àdúgbò yí ní ìtamẹ́rin.




#Article 166: Nọ́mbà àkọ́kọ́ (206 words)


Ninu Ìmọ̀ Ìṣirò nọ́mbà àkọ́kọ́ (prime numbers) ni a mo si awon nomba adabaye (natural numbers) ti won ni nomba adaba meji pere ti a le fi pin won dogba, eyun ni nomba 1 ati nomba akoko fun ra ara re. Awon nomba akoko po to be to fi je pe won ko lopin gege bi Efklidi se fihan ni odun 300 K.J (kia to bi Jesu, K.J). Nomba odo 0 ati ọ̀kan 1 ki se nomba akoko.

Bi awon nomba akoko se tele ara won ni yi : 2, 3, 5, 7, 11, 13, 17, 19, 23, 29, 31, 37, 41, 43, 47, 53, 59, 61, 67, 71, 73, 79, 83, 89, 97, 101, 103, 107, 109, and 113

Nomba 2 nikan ni o je nọ́mbà tódọ́gba (even number) larin won. Awon to ku je nọ́mbà tóṣẹ́kù (odd numbers).

Ipilese Agbagbo Isesiro la kale pe gbogbo nọ́mbà odidi (integers) apa otun ti won tobi ju 1 lo se ko sile gege bi isodipupo nomba akoko kan tabi jubelo ni ona kan pato. Fun apere a le ko:

Awon nomba akoko ko ni ye. Eyi ti je fifihan lopolopo ona. Eni akoko to koko fi eyi han ni Efklidi. Bi o se fi han ni yi:




#Article 167: Mathimátíkì (130 words)


Mathematiki tabi Ìmọ̀ Ìsirò jẹ́ èyí t'on jẹ mo nipa ọ̀pọ̀iye (quantity), nipa òpó (structure), nipa iyipada (change) ati nipa ààyè (space). Idagbasoke imo Isiro wa nipa lilo àfòyemọ̀ọ́ (abstraction) ati Ọgbọ́n ìrọ̀nú, pelu onka, isesiro, wíwọ̀n ati nipa fi fi eto s'agbeyewo bi awon ohun se ri (shapes) ati bi won se n gbera (motion). E ni awon Onimo Isiro n gbeyewo, ero won ni lati wa aba tuntun, ki won o si fi ootọ́ re mulẹ̀ pelu itumo yekeyeke.

A n lo Imo Isiro ka kiri agbaye ni opolopo ona ninu Imo Sayensi, Imo Ise Ero, Imo Iwosan, ati Imo Oro Okowo. Eyi je mo eko imo isiro to ko ti ni ilo kankan bo tileje pe o se se ki a wa ilo fun ni eyinwa ola.




#Article 168: Nọ́mbà adọ́gba àti aṣẹ́kù (169 words)


Ninu Imo mathematiki, gbogbo nọ́mbà odidi le je nomba adogba (even number) tabi nomba aseku (odd number) lona yi: ti o ba je odidi nomba ni opolopo meji, nomba na je nomba adogba bibeko yio je nomba aseku. Fun apere 4, 0, 8, 16 je nomba adogba bee si ni 1, 3, 7, 9, 11 je nomba aseku.

Akojopo awon nomba adogba se ko bayi:

Akojopo awon nomba toseku se ko bayi:
  

adogba * adogba = adogba

adogba * aseku = adogba

aseku * aseku = aseku 

Ti a ba sepinpin odidi nomba ki se dandan pe yio fun wa ni nomba odidi pada. Fun apere ti a ba sepinpin 1 pelu 4, esi re yio je 1/4 ti ki se nomba adogba tabi nomba aseku nitoripe awon nọ́mbà odidi nikan ni won le je adogba tabi aseku. Sugbon ti ipin ba je odidi nomba, yio je adogba ti afi ti nomba ti a pin (dividend) ni opolopo iye (factor) meji ju nomba ti a fi pin (divisor) lo.




#Article 169: Bọ́lá Ìgè (111 words)


James Ajibọ́lá Adégòkè Ìgè (September 13, 1930 - December 23, 2001) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá ní apá ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. A bi ní ọjọ́ kẹtàlá oṣu kẹsàán ọdún 1930, ó di olóògbé ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣu kejìlá ọdún 2001. ̣̣̣̣̣̣̣̣̣́́́́́́́

A bí ní ìlú Zaria ni ìpínlẹ̀ (Kaduna) bí o tiḷẹ̀ jẹ́ pé (Èsà-òkè) lébàá Iléṣà ni ìlú rẹ̀. Ìgè jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo lati osù kẹwàá ọdún 1979 títí dé osù kẹwàá ọdún 1983. Lẹ́yìn ìgbàtí ìjọ̀ba olósèlú padà dé ní ọdún 1999 Ìgè di Alákòóso ìjọba àpapọ̀ fún ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò-Àgbà ìjọba àpapọ̀̀. O di ọ̀tá pẹ̀lú Oluṣọlá Ọláòṣebìkan fun gbigbemi olóyè Ọbafẹ́mi Awólọ́wọ̀.




#Article 170: Wọlé Sóyinká (118 words)


Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka (ọjọ́ìbí 13 July 1934) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú Ìmọ̀ Lítíréṣọ̀ (literature), alákọsílẹ̀, eré orí ìtàgé (playwright) ati akéwì (poet). Wọlé Sóyinká jẹ́ ògidì ọmọ Yorùbá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gba Ẹ̀bùn Nobel ní ọdún 1986 fún iṣẹ́ owo re lori igbega imo ikowe.. 

Wọ́n bí Wọlé Sóyinká ní ìlú Abẹ́òkúta, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà àti United Kingdom tán, Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Theatre Royal Court ni ìlú Loọ́ńdọ̀nù (London).  Ó tẹ̀ síwájú láti kọ àwọn eré oníṣe lorílẹ̀ èdè méjèèjì ní tíátà àti orí ẹ̀rọ Asọ̀rọ̀-mágbèsì.  Ó kó ipa pàtàkì nínú ètò ìṣèlú àti akitiyan lópọ̀lọpọ̀ nínú ìjàǹgbara òmìnira orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn Great Britain.




#Article 171: Nọ́mbà gidi (1010 words)


Nínú Ìmọ̀ Ìṣirò nọ́mbà gidi (real number) ni a mọ̀ sí àwọn nọ́mbà tí a Ko lè gé, gẹ́gẹ́ bí nọ́mbà oníyemẹ́wàá (decimals) tí kò lópin. Fún àpẹẹrẹ 2.4871773339…. Àwọn nọ́mbà gidi jẹ́ nọ́mbà oníìpín, nọ́mbà bí 42 àti −23/129, àti nọ́mbà aláìníìpín, nọ́mbà gbòngbò alágbára-méjì 2 (square root) tí wọ́n sì ṣeé fihàn gẹ́gẹ́ bí ojúàmì (point) ní orí ìlà nọ́mbà tó gùn ní àìlópin. 

A ń pe àwọn nọ́mbà gidi bẹ́ẹ̀ láti lè ṣèyàtọ̀  sí àwon nọ́mbà tósòro (complex number). Ní ayé àtijọ́ àwọn onímọ̀  ìṣirò mọ nọ́mbà tó rújú gẹ́gẹ́ bí nọ́mbà afòyemọ̀ (imaginary number).

Nọ́mbà gidi lè jẹ́ onípìín tàbí aláìnípìín; Ó lè jẹ́ nọ́mbà Ọ̀jíbírà tàbí nọ́mbà t tí kò ní ònkà (transcendental number); bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n lè jẹ́ nọ́mbà tódájú, ni odi tàbí kí wọ́n jẹ́ òdo.

A n fi nomba gidi se iwon awon opoiye to je wiwapapo (continuous). O se se ka fi won han gege bi nombamewa to ni itelentele (sequence) eyonomba (digit) ti ko lopin lapa otun ojuami nombamewa (decimal point); a le fi won han bayi 324.823211247…. Awon ami bintin meta to wa leyin nomba yi tumosi pe awon eyonomba miran si n bo leyin.

Bakanna, awon nomba gidi tun ni idamo meji ti papa elesese (ordered field) ni, be ni won si ni idamo ti a mo si ipari l'oke tokerejulo (least upper bound). Akoko so fun wa pe awon nomba gidi ni papa kan, pelu aropo, isodipupo ati isepinpin pelu awon nomba ti ki se odo ti won le je elesese lapapo ni ori ila nomba lona to ni ibamu po mo aropo ati isodipupo. Ekeji so fun wa pe ti akojopo nomba gidi ti ki se ofo (empty) ba ni ipari l'oke (upper bound), o gbudo ni ipari l'oke tokerejulo. Awon mejeji yi lapapo ni won se'tumo nomba gidi patapata. Lati inu won ni awon idamo nomba gidi yioku ti jade wa. Fun apere a le fihan pe gbogbo polynomial (alamipupo) alagbara nomba siseku pelu nomba ibamulo (coefficient) gidi yio ni gbongbo gidi; ati pe ti a ba s'aropo gbongbo alagbarameji idin okan (minus one) po mo nomba gidi lati fun wa ni nomba tosoro, esi yi ni a n so pe o je titi ninu aljebra.

A n se iwon ninu Imo Sayensi Alagbamu (physical science) gege bi won ba n sunmo nomba gidi to. Bo tile je pe awon nomba ti a n lo fun eyi je ida nombamewa (decimal fraction) ti won duro fun awon nomba oniipin, nipa kiko won sile gege bi nombamewa fihan pe won n sunmo nomba gidi kan. 

A n so pe nomba gidi se sesiro ti igbese isiro ti a mo si Algorithm ba wa ti yio mu eyonomba re wa. Nitoripe bo tile wu ki awon algorithm re o po to, won niye pato (countable), sugbon awon nomba gidi ko niye (uncountable), nitori eyi opo ninu awon nomba gidi ni won ko se sesiro.

Ero onka Komputa le sunmo nomba gidi nikan. L'apapo won le s'oju fun awon inuakojopo (subset) awon nomba oniipin pato kan, nipa lilo nomba ojuami tonlefo (floating point) tabi nomba ojuami soso (fixed point), be sini awon nomba oniipin yi n je lilo lati sunmo awon iye gidi ti won sunmo won.

Awon onimo isiro n lo ami R (tabi  tabi Unicode ℝ) lati se'duro fun akojopo gbogbo nomba gidi. Ami ikosile Rn n tokasi aaye elegbe-n pelu ipoidojuko (coordinate) gidi won. Fun apere awon iye R3 je nomba gidi meta ti won tokasi ipo kookan ninu aaye elegbe meta (3 dimension) 

A lé mú nomba gidí wa gégé bí àkótán àwon nomba oniìpín ni ònà tó jé pé ìtèntèle nomba kan se fẹsíwájú pèlú nombámèwa tàbí nombáméjì (binary) báyí {3, 3.1, 3.14, 3.141, 3.1415,...} f'enuko sí nomba pàtò gidí kan.

E je ki R ki o duro fun akojopo gbogbo nomba gidi. Nitorie:

Idamo to gbeyin yi lo seyato larin nomba gidi ati nomba oniipin. Fun apere akojopo awon nomba oniipin ti alagbarameji won din si 2 ni nomba oniipin ipari l'oke (apere 1.5) sugbon won ko ni nomba onipin ipari l'oke tokerejulo, nitoripe gbongbo alagbarameji 2 ko se pin

Idi pataki ti a tun se seyato awon nomba gidi ni pe won ni gbogbo opin (limit). A le so pe won tan. Eyi tumosi bawonyi:

Itelentele kan (xn) nomba gidi ni a n pe ni ìtẹ̀léntẹ̀lé Cauchy to je pe fun ε  0, nomba odidi N kan wa to je pe ijinnasi (distance) |xn − xm| kere ju ε eyun to ba je pe n ati m tobi ju N lo. Ni ede mi, itelentele je itelentele Cauchy ti awon afida (element) xn re ba sunmo ara won gbagba.

Itelentele (xn) foriko po si opin x to ba je pe fun ε  0, nomba odidi N kan wa to je pe ijinnasi |xn − x| kere ju ε lo, to ba je pe n tobi ju N lo. Ni ede miran, itelentele kan ni opin x ti awon afida (element) re ba sunmo x gbagbagba.

A ri bayi pe gbogbo itelentele ti o n foriko si oju kanna ni itelentele Cauchy. 

Bayi wipe awon nomba gidi tan.

S'akiyesi pe awon nomba onipin ko lo tan o. Fun apere itelentele 1, 1.4, 1.41, 1.414, 1.4142, 1.41421, …) je ti Cauchy sugbon won ko foriko si nomba oniipin. (Eyi yatosi nomba gidi ti won foriko si gbongbo alagbarameji 2).

Nitoripe awon opin wa fun awon itelentele Cauchy ni isiro Kalkulosi fi se e se, ti o si wulo. Ona kan ti a fi le sewadi boya itelentele kan ni opin ni ki a yewo boya o je itelentele Cauchy, nitoripe a ko le mo opin yi tele.

Fun apere etonomba (series) fun igbega alabase (exponential function)

foriko si nomba gidi kan, nitoripe fun gbogbo x awon aropo

le kere gan ti a ba je ki N o tobi daada. Eyi fihan pe itelentele Cauchy ni o je. A ti mo bayi pe itenlentele ohun foriko si opin kan bi a ko ba ti e le so opin ibi ti o foriko si.




#Article 172: Àwọn Ẹ̀ka-èdè Yorùbá (439 words)


Awon Eka-ede Yoruba

Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá (1994), Àwọn Ẹ̀ka-Èdè Yorùbá 1Akúrẹ́: Ìbàdàn, Montem Paperbacks. ISBN 978-3297-3-3. Ojú-ìwé = 58.

Ọ̀RỌ̀-ÌṢÁÁJÚ
	
Èdè Yorùbá àjùmọ̀lò ni ó pa gbogbo ẹ̀yà Yorùbá pọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀ka-èdè tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ń sọ yàtọ̀ láti ilú kan sí èkeji. Ìyàtọ́ yìí le hàn ketekete tàbí kí ó farasin. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìwádii ni àwọn onímọ̀-èdè ti ṣe lórí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá wọ̀nyí. Púpọ̀ nínú àbájáde ìwádìí wọn ni kò sí ní àrọ́wọ́tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá. Níbi ti irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ bá jàjà bọ́ sí ọwọ́ akẹ́kọ̀ọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọn fi ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yóò mú ìfàsẹ́yìn bá iṣẹ́ wọn nítorí wọ́n ní láti kọ́kọ́ túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Yorùbá kí wọn tó le ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀ka-èdè bẹ́ẹ̀ finnífínní. 
	
Títí di bi mo ṣe ń sọ yìí, kò sí ìwé kankan nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá lórí àtẹ. Ohun àsọmórọ̀ ni àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá jẹ́ nínú àwọn ìwé gírámà Yorùbá tí ó wà lórí àtẹ. Púpọ̀ àbájáde ìwádìí àwọn onímọ̀-èdè tí ó wà ní àrọ́wọ́tó ni ó dálé ìpín-sí-ìsọ̀rí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ohun tí ó jẹ àwọn aṣèwádìí mìíràn lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀ka-èdè ìlú kan tí wọ́n yàn láàyò. Ṣùgbọ́n nínú ìwé yìí mo ṣe àyẹ̀wò púpọ̀ àwọn ẹ̀ka-ède Yorùbá léte àti pe àkíyèsí sí fonẹ́tíìkì àti fonọ́lọ́jì ẹ̀ka-èdè wọ̀nyí. Ìwé yìí yóò wúlò púpọ̀ fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti wọ́n ń kọ́ nípa àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Yóò si ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọnolùkọ̀ọ́ pẹ̀lú. Bákan náà ni ìwé yìío yóò jẹ́ ìpèníjà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀-èdè Yorùbá láti túbọ̀ kọ ibi ara sí àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.
	
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wọ̀nyí tí wọ́n tẹ̀ mí nífá ẹ̀ka-èdè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fojú rí púpọ̀ nínú wọn rí. Àwọn ni Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún, Ọ̀gọ̀gbọ́n Ọládélé Awóbùlúyì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyèlárán, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé, Ọ̀mọ̀wé Adétùgbọ́, Ọ̀mọ̀wé Akínkúgbé àti Ọ̀mọ̀wé Olúrẹ̀mi Bámiṣilẹ̀. 
	
Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀mọ̀wé Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé àti Ọ̀mọ̀wé Jíbọ́lá Abíọ́dún tí wọ́n fu àkókò sílẹ̀ láti bá mi ka ìwé yìí pẹ̀lú àtúnṣe tí ó yẹ nígbà tí mo fí ọwọ́ kọ ọ́ tán. ìmọ̀ràn wọn ni àwọn ohun tí ó dára nínú ìwé yìí, èmi ni mo ni gbogbo àléébù ibẹ́. Mo gbé òṣùbà ọpẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Bísí Ògúnṣíná, Arábìnrin Comfort Ògúnmọ́lá, Arábìnrin Àrìnpé Adéjùmọ̀, Olóyè Olúfẹ́mi Afọlábí, Arábìnrin Ọláyinká Afọlábí, Lékan Agboọlá, Ọjádélé Àjàyí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí mo kọ́ ní àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá láàárín ọdún 1991-1994 àti àwọn aláṣẹ ilé-iṣẹ́ aṣèwétà Montem Paperbacks. Ní ìparí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Arábìnrin Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá, ìyàwó mi àpé àti Mòńjọlá, ọmọ mi, fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn lásìkò ti mo kọ́ ìwé yìí. 
	




#Article 173: Ìsèdálẹ̀ Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà (2318 words)


ÌTÀN ÌSÈDÁLẸ̀ ÌLÚ ÌJẸ̀LÚ-JÈSÀ
	
Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín. 
	
Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé; Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kìíni, Agígírí jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò. Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbón tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọ omún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kì í sìí yara wọn bí ó ti wù kí ó rí. 
	
Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji – Agírírí àti Ajíbógun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọ́n wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà láti dó sí kí wọn lè ni àyè ìjọba tiwọn. Ajíbógun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónií yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírí rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbúrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín.  Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbùrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọ́dọ̀ jìnnà sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé agìnjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pé ibi tí òun ti rìn ti nasẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí. 
	
Kì wọn tó kúrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fùn un ní ọgbọ̀n nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n, òun lè dáàbò bo ara òun ó sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé; 

				“Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n 

				Ìjẹ̀bú ogún 

				É sìí bó ṣe a rí 

				Kógún a parẹ́ 

				mọ́gbọ̀n lára”
	
Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírí àti Ajíbógun ni Ìlé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lé ríran padà. Ó lọ, ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohùn ìní bàbá wọn láìfi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran. 
	
Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. Bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀ bàbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fún un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú ìrin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lóri àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀. 
	
Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyá yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá  Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrè pọ̀. Láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn si wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn. 
	
Itán sọ pé Ìbòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì gba Ilékété lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró. Agóró yìí ló dúro sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan pàtàkì nínú wọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sí iwájú díẹ̀ kí lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ran Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Ìgbà ti Agígírí kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí bóyà ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fún ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti ń wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí. 
	
Ìyàlẹ́nu ńláńlá lọ́ jẹ́ fún Agígírí láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lú àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí tí ibẹ̀ dùn mọ́ ọn fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọḍẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì ó sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n ìsàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkènísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayé”. 
	
Agbo ilée Bajimọn ni Òkè - Ọjà ni Agígírí kọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́hin èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gvà ọ̀tẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè ni Agígírí kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ìlédè náà ní ibi tí ààfin Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí i wọ́n múra láti gbé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Níkẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rè ati àwọn ọmọ - ogun rẹ̀. “Ojù iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu ti ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ̀ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n. 
	
Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbá tí wọ́n dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀sí í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mú ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n. Ìgà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ làti máa tọ́jú egbò náà, wọ́n sì dúró pẹ́ díẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wón fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ibẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilẹ̣́. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn – Agígírí sọ ibẹ̀ ni ÌJẸ̀BÚ nítorí pe ÌJẸ  ni Ìjẹ̀ṣà máa ń pe Ẹ̀JẸ́. Nígbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ́bú tí wọ́n ti ń pè é tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà títí di òní. 
	
Ṣùgbọ́n Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́ tí ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa. 

A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀bù – Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè xxxxxx pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè máa sí láàárin wọn nígbà kan tí rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu ọ̀gbọ́ni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú – Òde lọ. Ibẹ̀ ló ti mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó. 
	
Nínú àwọn ìtán òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ìjẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfé èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mu díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ọ̀gbọ́ni. Ìtán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀. 
	
Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyèwò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ òótọ́ jù lọ nínú wọn.
	
Nípa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ọjọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a tẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì ken náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti a já tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárín wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkan kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn. 
	
Tí Owá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. 
	
Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilèṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Iléṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Iléṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọn ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀.   

	Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé; 

			“ Kàí bi an kọlíjẹ̀bú 	

			Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀ 

			Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú 

			Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀”
	
Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sìń jẹ́ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. A rí Ọ̀gbọ́ni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara ìwàrẹ̀fà mẹfà ni Ọ̀gbọ́ni méjèejì yí wa ni Iléṣà ṣùgbọ́n Ọ̀gbọ́n Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. a rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jèṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà. 
	
Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí tí orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún àpẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní Iléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú méjèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ̀lú. 
	
Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀sà, èdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ. 
	
Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán.
	
Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, óun ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù 
	
Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀ná tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. 
	
Nígbà tí ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́un, àrìmọ-kùnrin ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójú ráyè, kí ó tó tàbà tuṣẹ. 
	
Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Ilẹ́ṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá ati Ọ̀gbọ́ni Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”.




#Article 174: Àgàdá ní Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà (1377 words)


Ìtàn bí Àgàdá ṣendé ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà

Ìtàn méjì ló rọ̀ mọ́ bi Àgàdá ṣe dé Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. 
	

sọ fún wa pé ìlú Ìlayè ni wọ́n tí gbé e wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìlú Ìlayè yí ti wà lásìkò kan ní ayé àtijọ́ ṣùgbọ́n ìwádìí fi hàn wá pé kò sí i mọ́ lóde òní. Ìtàn sọ pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà jẹ́ jagunjagun didi tí ó lágbára púpọ̀. Ó jà títí ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kan dé ìlú Ìlayè, ṣùgọ́n kí ó tó dé ìlú yìí, àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti ránsẹ́ sí àwọn ènìyàn wọn ní ìlú tiwọn pé ki wọn wá pàdé wọn láti fi agbára kún agbára fún wọn nítorí pé ìdè ń ta wọ́n lápá. Báyìí ni àwọn ènìyàn ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbéra láti wà gbèjà Ọba wọn. Ìlù Ìlayè yí ni wọ́n ti pàdé Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà, ogún sì wá gbónà janjan. Nítorí pé agbára ti kún agbára Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà yí, ó wá dàbí ọwọ́ fẹ́ tẹ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun náà bá sá tọ Ọba Ìlú Ìlayè lọ fún ìrànlọ́wọ́. Lọ́gán ni onítọ̀hún náà fún Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ní òrìṣà kan nínú òrìṣà wọn tí ó lágbára gidi láti gbèjà Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ó si sẹ́gun ọ̀tà rẹ̀. Bayìí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ṣe bèèrè fún òrìṣà yí ó sì tọrọ rẹ̀ láti gbé e wá sí ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ó ti ran án lọ́wọ́ lọ́pọ̀: ṣe òrìṣà tí ó bá san ni là ń sìn. Ṣùgbọ́n Ọba yìí kò gbé e fún un, Ìlú rẹ̀ tí ń jẹ́ ÀGÀDÁ ló gbé fún un láti máa gbé lọ ní rántí òrìṣà olùgbèjà yí. Ìgbà tí ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà dé ìlú rẹ̀ ni ó bá kọ́lè kan fún ìránti òrìṣà yí ó sì fi Ọkùnrin kan tì í pé kí ó màa bá òun rántí òrìṣà náà pé òun yóò sì wá máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún fún ìrántí oore tí ó ṣe fún wọn. Báyìí ni ó ṣe di ọdún Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní, ìgbàkugbà tí wọ́n bá sì fẹ́ rántí rẹ̀ tàbí bọ ọ́, ìlú Àgàdá yìí ni wọ́n máa ń lù fún un, ilù ogun sì ni ìlù náà. Láti ọjọ́ náà tí ogun kan bá wọ ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ìlú náà ni wọ́n máa ń lù, tí wọ́n bá sì ti ń lù ú, gbogbo ọmọ -ogun ìlú ni yóò máa fi gbogbo agbára wọn jà nítorí pé orí wọn yóò máa yá, agbára sì túnbọ̀ máa kún agbára fún wọn.

sọ fún wa pé Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ni wọ́n bí i àti pé alágbára gidi ni, ó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kà fim ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ó kú gẹ́gẹ́ bí alágbára, wọ́n sì sin ín gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọkùnrin. Wọ́n sọ ọ́ di òrìṣà kan pàtàkì ní ìlú gẹ́gẹ́ bí àwọn alágbára ayé ọjọ́un tí wọ́n ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà fún àwọn ènìyàn wọn, tí wọ́n kú tán tí wọ́n sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di òriṣà àti ẹn ìbọ lóníì àwọn òrìṣà bí ògún, ọ̀ṣun, ṣàngó, ọbàtálá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí a ń gbọ́ orúkọ wọn jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá lóde òní. 
	
Nígbà tí ó wà láyé, ó fẹ́ràn ìlù Àgàdá púpọ̀. Tí ogun bá sì wà, tí wọ́n bá ti ń lu ìlù náà, kí ó máa jà lọ láìwo ẹ̀nìyàn ni. Kò sì sí ìgbà tí wọ́n bá ń lu ìlù yí tí ogun bá wà tí kò ní ṣẹ́gun. Ìgbà tí ó sí kú, ìlù yí náà ni àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń lú tí ogun bá wà, ó sì di dandan kí àwọn áà borí irú ogun bẹ́ẹ̀.
	
Orúkọ̀ míràn fún Àgàdá tún ni Dígunmọ́dò nítorí pé tí ogún bá ti ń bọ̀ láti wọ̀lú, ibi Ẹrẹ́jà ni ọkùnrin akíkanjú náà yóò ti lọ pàdé rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí ó wọ ìlú dé apá Ọ̀kèniṣà ti a ń pe ní orí ayé tí àwọn ènìyàn wà nígba náà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ní DÍGUNMÓDÒ –DÍ OGUN MỌ́ ODÒ. Títí di oní yìí, Ẹrẹ́jà náà ni wọ́n ti ń bọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ojúbọ rẹ̀. 
	
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní “ẹjọ́ kì í ṣe tara ẹni ká má mọ̀ ọ́n dá” èyí ló jẹ́ kí n ronú dáadáa sí àwọn ìtàn méjì yí láti lè mọ eléyìí tí ó jẹ́ òótọ́ tí a sì lè fara mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtán àtẹnudẹ́nu, àwọn olùsọ̀tàn ìtàn méjèèjì yí ló ń gbìyànjú láti sọ pé epó dun ẹ̀fọ́ wọn nítorí pé oníkálùkù ló ń gbé ìtàn tirẹ̀ lárugẹ. Ṣùgbọ́n ìgbà tí a wo ìsàlẹ̀ láti rí gùdùgbú ìgbá mo gba ìtàn tàkọ́kọ́ tí ó sọ pé ìlú Ilayè ni wọ́n ti mú un wá gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ òótọ́ jù lọ nítorí pé wọ́n máa ń ki òrìṣà náà bayìí pé 

				Jó jẹ̀gi
Ìlayè”

		Nínú orin rẹ̀ náà, ọ̀kan sọ pé:

				Èlè:	Oriṣà Òrìṣà 

				Ègbè:	Jẹ kéèrín peyín ò 

				Èlé:	Bàbá ulé Aláyè 

				Ègbè:	Jẹ́ kéèrín pe yín ò 

				Èlé:	Oriṣà òrìsà 

				Ègbè:	Jẹ́ kéèrín peyín ò 

	
Ṣùgbọ́n kì í ṣe òrìṣà yí nìkan ni ìtàn sọ fún wa pé ó ń 
gbèjà Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lákòókó ogun; ìrókò náà jẹ́ ọ̀kan. Akíkanjú ni òun náà tí kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kó má tatí were” ni tirẹ̀. Nígbà kan rí, a gbọ́ wí pé òrìṣà ìlú Ejíkú3 ni ìrókò jẹ́ ṣùgbọ́n ìgbà gbogbo ni ogún máa ń yọ ìlú yìí lẹ́nu tí wọ́n sí máa ń kó wọn lọ́mọ lọ. Nígẹ̀hìn, wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ò sì ràn wọnm lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí Èkíjú rójú ráyè tán ni wọ́n bá kúkú kó wá sí ilú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà láti sá fún ogun àti pé ẹni tí ó ran ni lọ́wọ́ yìí tó sá tọ̀ ìgbà tí ìlú méjì yí di ọ̀kan ni òrìṣà tí ó ti jẹ́ tí Èjíkú tẹ́lẹ̀ bá di ti Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ìgbà tí Èjíkú ń bọ̀ wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, wọ́n gbé òrìṣà wọn yìí lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tí ogun bá dìde sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni ìrókò yí máa ń dìde láti sa gbogbo ipá ọwọ́ rẹ̀ láti gbèjà ìlú náà. Ológun gidi ni ìtàn sì sọ fún wa pé òun náà jẹ́ látàárọ ọjọ́ wá. Ṣé ẹni tí ó ṣe fún ni là ń ṣe é fún; èyí ni ìrókò náà ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà karí tí nǹkan bá dé sí i láti fi ìwà ìmoore hàn tún ìlú náà. Ìdílé kan pàtàkì ni Èjíkú tí a ń sòrọ̀ rẹ̀ yí jẹ́ nílùú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí, àwọn sì ni ìran tí ń sin tàbí bọ òrìṣà ìrókò yí. Olórí tàbí Ọba Èjíkú sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwàrẹ̀fà mẹfà ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí. 

	
Lẹ́hìn ìgbà tí òrìṣà yí tit i ìlú Ìlayè dé Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí Ọba sì ti gbé e kalẹ̀ sí Ẹrẹ́jà, ló ti fi olùtọ́jù tì í. Ọbalórìṣà ni orúkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ agbátẹrù òrìṣà náà. 
	

	Àwọn tó ń bọ́ ọ́ pín sí mẹ́rin. Olórí àwòrò òrìṣà àgàdá ni Ọbalórìṣà tí ó jẹ́ agbàtẹrù òrìṣà náà. Aṣojú ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló jẹ́ fún òrìṣà náà “Omi ni a sì ń tẹ̀ ká tó tẹ iyanrìn” bí ọbá bá fẹ́ bọ Àgàdá, ọbalórìṣà ni yóò rìí. Bí àwọn ọmọ ìlú ló fẹ́ bọ ọ́, Ọbalòrìṣà náà ni wọn yóò rí pẹ̀lú. 
	
Ìsọ̀ngbè ọbalórìṣà nínú bíbọ Àgàdá ni àwọn olórí ọmọ ìlú. Àwọn olórí-ọmọ yìí ló máa ń kó àwọn ọmọ ìlú lẹ́hìn lákòókó ọdún Àgàdá náà láti jó yí ìlú káákiri àti láti máa ṣàdúrà fún ìlọsíwájú ni gbobgo ìkóríta ìlú. Ọba ìlú náà ní ipa pàtàkì tirẹ̀ làti kó. Òun ló ń pèsè ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lódọọdún láti fí bọ òrìṣà náà èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn rẹ̀ ní ìgbà tó gba òrìṣà náà òun yóò máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún títí dòní ló sì ń ṣe ìràntí ìlérí rẹ̀ ọjọ́ kìíní. 
	
Wàyí o, gbogbo ìlú ni wọ́n ka ọdún díde láti ṣe ọdún náà tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí ó wà ní ìdálẹ̀ ni yóò wálé fún ọdún náà. Gbogbo ìlú ló sì máa ń dùn yùngbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún náà lọ́wọ́.




#Article 175: Samuel Ladoke Akintola (379 words)


Samuel Ladoke Akintola (July 6, 1906 - January 15, 1966) je oloselu omo orile ede Naijiria lati eya Yoruba ni apa ila oorun. A bi ni ojo kefa osu keje odun 1906 ni ilu Ogbomosho.

Wọ́n bí Sámúẹ̀lì sínú ìdílé Akíntọ̀lá ní ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, bàbá rẹ̀ ni Akíntọ̀lá Akínbọ́lá nígba tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Àkànkẹ́ Akíntọ̀lá. Bàbá rẹ̀ jẹ́ oníṣòwò tí ó jáde wá láti inú ẹbí oníṣòwò. Nígbà tí ó kéré jọjọ, àwọn ẹbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Minna tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Naija lónìí. Ó kàwé léréfèé nílé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ́rẹ̀ Church Missionary Society. Ní ọdún 1922, ó padà wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ láti wá bá bàbá bàbá rẹ̀ gbé tí ó tún tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Oníyẹ̀tọmi ṣáájú kí ó tún tó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ Kọlẹ́ẹ̀jì ti onítẹ̀bọmi ní ọdún 1925. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Akádẹmì Onítẹ̀bọmi láàrín ọdún 1930 sí 1942, lẹ́yìn èyí ni ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ àjọ tó mójú tó ìrìnà Rélùwéè ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Lásìkò yí, ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú H.O. Davies, tí ó jẹ́ agbẹjọ́rò àti olóṣèlú, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Nigerian Youth Movement níbi tí ó ti ṣàtìlẹyìn fún Ikoli láti di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú Ìpínlẹ̀ Èkò tako yíyàn tí wọ́n yan Samuel Akisanya, ẹni tí Nnamdi Azikiwe fara mọ́  gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò dépò náà. Akíntọ́lá tún dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn gẹ́gẹ́ bí  òṣìṣẹ́, tí ó sì di olóòtú fún.iwé ìròyìn náà ní ọdún 1953 pẹ̀lú àtìlẹyìn Akinọlá Májà tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olówó ìwé-ìròyìn náà tí ó sì rọ́pò Ernest Ikoli gẹ́gẹ́ olóòtú. Akíntọ̀lá náà sì dá Ìwé-ìròyìn Yorùbá tí wọ́n ń fi èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ ní ojojúmọ́. Ní ọdún 1945, ó tako ìgbésẹ̀ ìdaṣẹ́ sílẹ̀ tí ẹ́gbẹ́ òṣèlú NCNC tí Azikiwe àti Michael Imoudu, fẹ́ gùn lé, èyí sì mu kí ó di ọ̀dàlẹ̀ lójú àwọn olóṣèlú bíi Anthony Enahoro. Ní ọdún 1946, Akíntọ̀lá rí ìrànwọ́ ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ gbà láti kàwé ọ̀fẹ́ ní U.K, níbi tí ó ti parí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ òfin, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò lórí òfin tí ó jẹ mọ́ ìlú. Ní ọdún 1952, òun àti Chris Ògúnbanjọ,olóyè Bọ̀dé Thomas àti Michael Ọdẹ́sànyà kóra jọ pọ̀ di ọ̀kan. 




#Article 176: Nọ́mbà tóṣòro (238 words)


Ninu mathematiki, nọ́mbà aṣòro (complex number) ni awon nomba ti won ri bayi 

to je pe a ati b won je Nọ́mbà Gidi, ti i si je ẹyọ tíkòsí pelu idamo bi i 2 = minus;1. Nọ́mbà gidi a ni a n pè ní apá gidi nọ́mbà tósòro, be sìni nọ́mbà gidi b jẹ́ apá tíkòsi´. A lè sọ pé àwón nọ́mbà gidi je nọ́mbà tósòro pelu apá tíkòsi´ tó jé òdo; eyun pé nọ́mbà gidi a jẹ́ bakanna mọ́ nọ́mbà tósòro a+0i

Fún àpẹrẹ, 3 + 2i jé nọ́mbà tósòro, pẹ̀lú apá gidi to jẹ 3 ati apá tíkòsi´ to jẹ 2. Tí z = a + bi, apá gidi (a) ni a n se àmì rẹ̀ pẹ̀lú Re(z), tàbí real;(z), be sìni apá tíkòsi´ (b) ni a n se àmì rẹ̀ pẹ̀lú Im(z), tàbí image;(z)

Àwon nọ́mbà tósòro se ròpọ̀, yọkúrò, sọdipúpọ̀ tàbi sèpínpiń gẹ́gẹ́ bi a ti n se fun àwon nọ́mbà gidi, be ni wón sì ní ìdámọ̀ tó lẹ́wà mìíràn. Fún àpẹrẹ, nọ́mbà gidi nìkan kò ní ojúùtú fún ìdọ́gba aljebra alápọ̀ọ́nlépúpọ̀ (polynomial) pẹ̀lú nọ́mbà àfise gidi (coefficient), sùgbọ̀n àwọn nọ́mbà tósòro ní. (Eyi ni òpó àgbàrò aljebra) (fundamental theorem of algebra). 

Nínú ìmọ̀ isẹ́-ẹ̀rọ oníná (electrical engineering), níbi ti i ti dúró fún ìwọ́ iná (electric current) àmì tí a n lò fún ẹyọ tíkòsí i ni j, ari bayi pé nigba miran nọ́mbà tósòro se kọ lẹ̀ bayi, a + jb.




#Article 177: Àwùjọ Haúsá (496 words)


Àwùjọ Haúsá

Àwọn òpìtàn bíi Basil (1981), gbìyànjú láti ṣàlàyé bí àwọn Hausa ti sẹ̀. Agbede méjì ni ó ti mú ìtàn sọ. Pàtàkì ohun tí ó sọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ ní ìlú kan tí ń jẹ́ Daura. A gbọ́ pé kanga kan ṣoṣo ló wà nínú ìlú yìí àti pé ejò kan wà ní inú kanga ọ̀hùn ti kì í jẹ́ kí àwọn ará ìlú pọnmi àyàfi tí ó bá jẹ́ ọjọ́ jímọ́ọ̀. Ìtàn ọ̀hún ṣàlàyé pé àjòjì kan tí ń jẹ Bayajidda wọ ìlú wá, ó pa ejò yìí. Ọba ìlú náà tí ó jẹ́ obìnrin sì di ìyàwó àjòjì ọ̀hún. Ṣe ẹní bá ni ẹrú ni ó ni ẹrù, ẹní fẹ́ ọba ti di ọba. Ìtàn sọ pé àwọn ọmọ mejé tí ọkùnrin ọ̀hún bí ni wọ́n dá àwọn ìsọ̀rí méje tí Hausa ní sílẹ̀. Wọ́n ní àwọn ọmọ méje ti àlè rẹ̀ bí ni wọ́n tẹ ìlú méje yòókù dó. Méje tó jẹ́ ojúlówó ni ‘Hausa Bakwai’ nígbà ti méje yòókù jẹ ‘Banza Bakwai’. Awọn Hausa Bakwai ni Biram, Daura, Katsina, Zaria, Kano, Rano ati Gobir. Àwọn méje yòókù ni Zamfara, Kebbi, Gwari, Yauri, Nupe, Yorùbá àti Kwararafa.
	
Ìtàn ti Stride àti Ifeka (1982) sọ ni a fẹ́ mú lò nínú iṣẹ́ yìí. Ìtàn tó wà lókè yìí náà ni wọ́n sọ ṣùgbọ́n wọn ṣe àfikún díẹ̀. Wọn tọ́ka sí àkọsílẹ̀ kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pé jọjọ tí ń jẹ́ “Kano chronicles”. Wọ́n lo àkọsílẹ̀ yìí láti ṣàlàyé pé ọkùnrin kan tí ń jẹ Bàgódà ni ó kọ́kọ́ jọba ní ìlú Kano. Wọn ni nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni ọba ọ̀hún jẹ (A.D. 1000). Wọn ní àkókò yẹn ni ìgbà tí àwọn Hausa bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ sí abẹ́ àkóso ìlú síṣe.
Àtúnsọ ìtàn tí wọ́n sọ gbà pé ọmọ Bayajida ni gbogbo Hausa ka ara wọn kún. Wọ́n ní Abuyazid gan-an ni orúkọ rẹ̀. Wọ́n ní ọmọ ọba ìlú ‘Baghdad’ ni. Wàhálà àna rẹ ló jẹ́ kó sá kúrò ní ìlú. Ó ṣe àtìpó díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìran Kànúrí (ìpínlẹ̀ Borno). Nígbà tí ó dé ibi kan tí ń jẹ́ ‘biram ta gabas’, O fi iyawo re sílẹ̀ nibẹ. Onítọ̀hún sì bí ọmọkùnrin kan síbẹ̀. Ní ìlú Gaya (Ìpínlẹ̀ Kano) ó ṣe alábàábàdé àwọn alágbẹ̀dẹ kan tí wọ́n jáfáfá púpọ̀, wọ́n bá a ṣe ọ̀kọ̀ kan. A gbọ́ pé ọ̀kọ̀ yìí ni ó lò láti fi pa ejò tí ń dààmú àwọn ará ìlú Daura tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ di ọba wọn. Ìtàn yìí sọ fún wa pé Gwari ni orúkọ ẹrúbìnrin tí ó bi àwọn ọmọ méje tí wọ́n wà ní ìsọ̀rí kejì fún un.
Ìtàn yìí tàn ìmọ́lẹ̀ díẹ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Hausa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe iran Hausa ti tan kálẹ̀ kaakiri àgbáyé àwọn Hausa tí wọ́n jẹ́ onílé àti onílẹ̀ ni apá òkè ọya ni orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni a ní lọ́kàn nínú iṣẹ́ yìí. Lára àwọn ìpínlẹ̀ ọ̀hún ni Sokoto, Katsina, Zamfara, Kebbi, Kano, Jigawa, Kaduna, Gombe àti Plateau.




#Article 178: Orlando Owoh (798 words)


Orlando Owoh (oruko abiso: Stephen Oládipúpò Olaore Owomoyela, February 14, 1932 - November 4, 2008) jé olorin omo ile Naijiria. Omo ìlú Ifón lébàá òwò ní Ipinle Ondo ni. Ó lo sí ilé ìwé alákòóbèrè ti Ìjo Elétò ni ìlú Osogbo ní odún 1951 (Decca 1969).
	
Akínmúwàgún (2001:1-3) sàlàyé pé Orlando jáde ní ilé ìwé alákòóbèrè ó sì ń fi ojú sí eré àsíkò àti gbénàgbénà ti bàbá rè ń se. Ó darapò mó egbé omo ogun Nàìjíríà ní odún 1960, sùgbón kò lò ju odún kan péré tó fi kúro tó sì darapò mó egbé orí ìtàgé kan tí a mò sí Ògúnmólá National Concert Party’. Kò pé púpò ti òun pàápàá fi dá eré tirè sílè tí ó sì pé è ni Orlando Owoh And His Omimah Band’. 
	
Odún 1969 ni Orlando gbé ìyàwó. Léyìn ìgbeyàwó àkókó, ó ti fé ìyàwó mérin mìíràn. Orúko àwon ìyàwó rè láti orí ìyàwó àkókó ni Múìbátù Orímipé, Folásadé Àkísan, Mopélólá Ìsòlá, Deborah Akérédolú ati ìyábò Ańjoórìn. Lára awon omo rè ni Káyòdé, Abósèdé, Ségún, Dàpò àti Sèsan. (Akinmuwagun 2001:1-3). Ìwádìí fi hàn pé ó tilè bi òkan nínú àwon omo rè tí ń je Tòkunbò si ìlú Oba, a gbó wí pé isé èsé kíkàn ni òdómokùnrin òhún ń se.
	
Nínú àlàyé Tádé Mákindé (2004:30) ó hàn gbangba pé Tòkunbò omo Orlando jogún èsè kíkàn ni. Ó sàlàyé pé Orlando féràn èsé kíkàn àti pé odidi odún meta ni ó fi je baálè àwon elésèé kíkàn nígbà èwe rè. Ó ní òré ni àbúrò òun àti gbajúgbajà olorin tí ń jé Sunny Ade.
	
Alákíkanjú ni Orlando, nípa akitiyan rè ni a dá Egbé Ìtèsíwájú Ìlú Ifón sílè (Ifón Progressive Union) ní odún 1970. Léyìn to seré ní ìlú Òwò ní odún 1973 ni wón se ètò ífilólè láti kó gbòngàn  (Town Hall). (Àkínmúwàgún 2001:1-3).
	
Nínú ìfòròwánilénuwò tí Tádé Mákindé se, àwon òtító kan jeyo: Ekíní ni pé àìsàn rolápá-rolésè bá a jà, Olórun ló yo ó. Owó òtún re kò sì se é gbé gìtá dáradára mó. Bí ó tilè jé pé ó lè fi owò òtún òhún bo èníyàn lówó tàbí fi gbé omodé, kò se é mú síbí ìjeun dáradára. Gégé bi àlàyé Orlando:
	
Se ni yó máa gbon rìrì tí ó bá ti kù díè kí ó dé enu
Àìsàn yìí kò mu ohùn re lo rárá èyí ni kò sì jé kí akùdé ba eré olósoosù tí ó máa ń se ni ilé ìtura Màjéńtà to wà ní Idimu Egbédá ní Èkó.
	
Nínú ìfòròwánilénuwò yìí, Orlando ní òún ti di omoléyìn kírísítì, ó sì fi gbogbo ògo fún Olórun. Ó ní:
Èmi kì yóò kú bí kò se yíyè láti so nípa dídára Olúwa O mò pé mo sí ni nnkan se ní ilé ayé.

Nígbà tí wón bi í nípa ohun tí àwon olólùfe re ń so kirì pé bí gbajúgbajà olórin àgbàyé – Michael Jackson ba kojú Orlando Owoh nínú eré síse ni Òwò yàtò si ìlú bí i Eko, Abuja tabi Port Harcourt, Orlando ni yóò borí, èsì rè ni pé,
Nítorí èka èdè Òwò enu mi àti síse kòkáárí àsà Òwò ni” (Makinde 2001:30).

Kí ló tún kù o? Orlando fara mó Òwò ati àsà òwò títí ti àwon ènìyàn kan fi yí owó inú Owóméyèlá rè sí Òwò, ó ko ó lórin pé déédéé ara òun ni orúko méjééjì se. Wón fi oyè amúlùúdún dá Orlando lólá ni ìlú Ifón. Nígbà tí ó lo sere ní ìlú Tokyo tó wà ni Ilè Japan ní odún 1986, ìjoba fi Oyè gbédègbéyò (Commander of Language) dá a lólá.
	
Pàtàkì ìsoro tó dojúko yàtò fún ti àìsàn tó ko lú ú ni èwòn tó lo ni odún 1985 látàrí pé ó ń se agbódegbà fún igbó títà.
	
Ní báyìí Orlando ti pé odún mókànlélógóta ó lé díè, ó sì ti se rékóòdù márùn-dín-lógójì.
	
Ìwádìí fi hàn pé Orlando fé ni ibùjókòó ní Ilú òyìnbó àti láti dá Ilé-èkósé eré sílè bí Olórun bá yònda (Akínmúwàgún 2001:1-3). Ó sàlàyé pé òun fé kí àwon orin tí óun ti ko di kíká sórí fóńrán fídíò. Ó ní òun ti parí ètò pèlú Ilé ise `Gazola Nig. Ltd’ láti sètò títa àwon Isé òun sí orí CD pèlú títà rè (Makinde 2004:30).
	
Ní gbogbo ònà, ó hàn gbangba pé Orlando ti di àgbà òjè nínú olórin, kì í se ní àdúgbò ìlú Òwò tàbí ile Yorùbá nikan bí kò se ni gbogbo Nàìjíríà (Uzo 2004:14).
	
Nínú orin tí ó pe àkolé rè ní `Ifón Omimah’, ó sàlàyé pé omo ilu Òwò ni ìyá òun. Nínú orin tí ó ko fún Gbenga Adébóyè, ó jé kí á mò pé òun sì ni ìyá láye nítorí pé ó ni òun ti bá Gbénga Adébóyè sòrò pé yóò bá òun sin ìyá oun lójó tí ó bá relé ogbó.




#Article 179: Lọ́ọ́yà Ọmọ Yorùbá (550 words)


Àtòjọ Àwọn Agbẹjọ́rọ̀ tí wọ́n jẹ́ Ọmọ Yorùbá

Àwọn Lọ́ọ́yà àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Yorùbá. A kọ ọdún tí wọ́n sí òkè orúkọ wọn 

	Christopher Alexander Sapará Williams 
	Òun ni ọmọ Nàìjíríà tí ó kọ́kọ́ di Lọ́ọ́yà 

	Rotimi Olusomoha Aládé 

	John Augustus Otunba Payne 

	E.J. Alexander Taylor 

	John Akinọla Òtúnba Payne 

	Sir Adéyẹmọ Alákijà 

	Ọláyímíká Alákijà 

	Ithiel K Ladipọ Doherty 

	Olaseeni Moore 

	E. A Franklin  

	Alfred Latunde Johnson 

	E.M.E. Àgbètì 

	T.A. Dolierty 

	Adédépò Káyọ̀dé 

	S.H.A. Baptist. 

	Ayọ̀délé Williams 

	Steven Bánkọ́lé Rhodes 

	A.O.D. Dòsùnmú 

	Adébíyí Désàlú 

	C.A. Harrison Ọbáfẹ́mi 

	Muhammed Lawal Basil Agusto 

	A. O. Àbáyọ̀mí 

	I.O. Caxton Martins 

	Rufus Adékúnlé Wright 

	Adégúnlẹ̀ Ṣóẹ̀tán 

	F.O. Lucas

	A. O. Thomas 

	Albert Horatus Akíntúndé Doherty 

	J. Ọmọliyì Coker 

	Isaac Kúshìkà Roberts 

	F. Tátúndé Vincent 

	John Martins

	T. Ẹkúndayọ̀ Kusimo Ṣórìnọ́lá 

	Akínbọ́nà Sólúadé 

	Samuel Ayọ̀délé Thomas 

	Frances Edney Euba 

	Ọmọ́sànyà Adéfólú 

	Richard Adé-Ẹ̀yọ̀ Doherty 

	Hezekiah Ajayi Johnson (Alias Onibuwe) 

	Àlàbá Akéréle 

	Abíọ́lá Akínwùmí 

	Ògúnyẹmí Ẹbíkúnlé Ajọ́ṣẹ̀ 

	Olúwọlé Ayọ̀délé Alákijà 

	Adébíyí Májẹ́kódùnmí 

	Ọlájídé Ọláríbigbé Alákijà 

	Akinọlá Adésọ̀gbìn 

	Adélékè Adédoyin 

	Ladipọ Ọdúnsì 

	Ọladipọ Moore 

	John Idowu Conred Taylor 

	Christian Adéṣẹ́gun Wilson 

			Ọdúnbákú	

	Ọlátúndé Balógun 

					
	Bọ̀dé Thomas

	Àlàbí Taylor

	John Adéjùmọ̀ Kester 

	funsọ Blaize 

	Akíntóyè Tẹ́júosó

	Ọbájẹ́nu Awólọ́wọ̀ 

	H.O. Davies 

	Ọlájídé Ṣómólú 

	S.A. Adéọba 

	Victor Ìlòrí 

	C.O. Awóyẹlé 

	S. Àyìnlá Abina 

	Rẹ̀mí Fàní-Káyọ̀dé

	T.O.S. Benson 

	L.O. Fádípè 

	V.A. Déhìmọ̀ 

	G.B.A. Coker 

	E.A. Caxton-Martins

	M.O. Oyàmádé 

	J.O. Kassim

	O.A. Akántóyè 

	A.O. Lawson 

	Dúró Phillips 

	Àtàndá Fàtáì-Williams 

	O. Akínkúgbé 

	Abíọ́dún Akéréle 

	Ayọ̀ Rósìji 

	M.A. Adésànyà 

	V.O. Ẹ̀san 

	Basheer Agusto 

	C.O. Madarikan 

	A.O. Lápitẹ́ 

	D.O. A. Ògúntóyè 

	G.S. Sówèmímọ̀ 

	J.O. Beckley 

	Adé Mummey 

	S.O. Lámbò 

	Adégbóyèga Adémọ́lá 

	J.A. Adéfarasìn 

	S.L. Akíntọ́lá 

	L.J. Dòsùmú 

	Isin Shotire 

	D.M.O. Akínbíyi 

	C.O. Ògúnbánjọ 

	A. Òkúbádéjọ.

	Ayọ̀ Òkúsàga 

	Oláyínká Ọlámosu 

	O.O. Ọmọlolú 

	H.M. Àllí-Balógun 

	A.M.A. Akinloyè 

	A.G.O. Agbájé 

	Akinọlá Àgùdù 

	J.O. Ajíbọ́lá 

	B. Olówófóyèkù 

	E.B. Craig 

	E.O. Ayọ̀ọlá 

	O. Ajọ́sẹ̀-Adéògún 

	S.A Ògúnkẹ́yẹ 

	D.O. Coker 

	Adéníran Ògúnsànyà 

	S.L. Dúrósarọ́ 

	A.R. Bákàrè

	S.B. Adéwùnmí 

	Adénẹ́kàn Adémọ́lá 

	S.D. Adébíyí 

	Adédàpọ̀ Adérẹ̀mí 

	A. E. Molajo

	O. Ọ̀ráfidíyà 

	Ayọ̀ Richards 

	Àdùkẹ́ Moore 

	E.O. Fákáyòdé 

	G.B.A. Akínyẹdé 

	Andrew Ajíbọ́lá 

	O.B. Akin Olúgbadé 

	A.F.O. Dábírí 

	S.A. Awólèsì 

	A. Adésidà 

	Kẹ́hìndé Ṣófọlá 

	Adédòkun Hastrup 

	J.A. Ọdẹ́kù 

	Búsàrí Òbísẹ̀san 

	O.A. Fájẹ́misìn 

	D.O. Ògúndìran

	Káyọ̀dé Ẹ̀ṣọ́ 

	Y.A. Jìnádù 

	S.O. Abudu 

	B.O. Babalákin 

	Y.O. Àdìó 

	Ọláyínká Ayọ̀ọlá 

	Àbáyọ̀mí Olówòfóyèkù 

Lọ́yà àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà ni Williams 
Alexander Sapara Williams. Ó di agbẹjọ́rò ní odún 1880. Ọmọ Yorùbá 
nì Májísíréètì kìíní ní ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà ni Sir Olumuyiwa Jibalaru. Ọdún 1938 ni ó di Majísíréètì yìí. Òun náà ni ọmọ Nàìjíríà kìíní tí yoo di adájọ́ ilé-ẹjọ́ kóòtù gíga (High Court of Judge). Ọmọ Yorùbá ni Ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí yóò di ‘Chief Justice’ ilẹ̀ Nàìjíríà ni Sir Adétòkunbọ̀ Adémọ́lá. Ọmọ Yorùbá ni Ọmọ-ọba Abẹ́òkúta ni. 
	
Lọ́yà tí ó kọ́kọ́ gba ‘Senior Advocate of Nàìjíríà ‘Chief F.R.A. Williams. Ọmọ Yorùbá ni. 

Lọ́yà obìnbìn àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí yóò di adájọ́ ilé ẹjọ́ àgbà (High Court Judge) ní ilẹ̀ Nàìjíríà ni Mrs Modupẹ Ọmọ-Ẹboh tí ó jẹ́ ọmọ Akingbẹhin. Ọmọ Yorùbá ni.

Òbìnrin  Nàìjíríà tí yóò gba oyè Senior Advocate of Nigeria’ nịmọ ọ tí ó jẹ́kọ́àkó  Yorùbá nị̀mọ. ỌolankẹMrs Folake S 
 ‘Attorney-General’ tị tí yóò jẹkọ́ Nàìjíríà àkọ́mọ‘O  Nàìjíríạ̀ilè ni Dr  di ‘President of̣kọ́ Aáfíríkà tí yóò kọ́ ilẹ̀mọlawale Elias Òun ni ọTeshim O  Yorùbá nịmọthe International Court of Justices’. O 




#Article 180: Atúmọ̀-èdè: Létà A (1833 words)


a  (1A) kan: I gave him a dog. (Mo fun ní ajá kan).
abandon (v); Kọ̀ sílẹ̀: He abandoned his job. (Ó kọ iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀)

abbreviation  (n);  ìkékúrú: Abbreviation is useful when taking lecture notes. (ìkékúrú wúlò tí a bá ń ṣe àkọsílẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

abdomen (n); ìkùn: The abdomen of the boy protruded because he over ate.  (ikùn ọmọ náà rí róńdó nítorí pé ó jẹun yó jù). 

ability (n); agbára tàbí òye: He has the ability to remember dates. (Ó ní òye ọjọ́ àti àkókò). 

able (adj); lè, lágbár: He is able to do all thing. (Ó lè ṣe ohun gbogbo). 

aboard (adv); nínú okò ojú omi tàbí òfúrufú; The captain welcomes you aboard this plane. (Adarí ọkọ̀ òfúrufú kì i yín káàbọ̀ sínú ọkọ̀. 

abolish  (v); parẹ́: Government has abolished the tax on agricultural products. (Ìjọba ti dá owó orí lori ohun ọ̀gbùn dúró. 

about (adv); yíká, nípasẹ̀: What ara you talking about Kunle? (kí ní ẹ̀ ń sọ nípa Kúnlé?) 

above (adv); lókè: We watched the birds above (À ń wo àwọn ẹyẹ lókè). 

abroad (adv); ẹ̀yìn odi, òkè òkun: My brother is studying abroad. (Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ń kàwé lókè òkun). 

abrupt (adj); lójijì, láìròtẹ́lẹ̀: He shouted abruptly. (Ó kígbe lojijì). 

abscess (n); ìkójọpọ̀ ọyún: The injection Joshua got from the nurse has formed abscess. (Abẹ́rẹ́ tí nọ́ọ̀sì fún Joshua ti di Ọyún). 

absent (adj); kò sí, kò wá; He was absent from work last Tuesday. (Kò wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tó kọ́já).  

absolute (adj); pátápátá; Amina has absolute freedom to choose a husband. (Amina ní òmìnìra pátápátá láti yan ọkọ). 

absorb (v) fàmu: The dry Gari absorbed water easily. (Gaàrí gbígbẹ náà fa omi mu). 

absurd (adj) ṣàìtọ́: He behaved in an absurd way. (Ó hùwà ní ọ̀nà tí kò tọ́). 

abundant (adj); lọ́pọ̀; rẹpẹtẹ: There was an abundant rain last year. (Òjò rò rẹpẹtẹ ní èṣí 

abura (n) ẹ̀yà igi kan: Olu made his furniture with abura (Olú kan àga rẹ̀ pẹ̀lú igi abura). 

abuse (v); èébú: ìlòkílò: The teacher abused his power. (Olùkọ́ náà ṣI agbára lò). 

acacia (n); ẹ̀yà igi kan: The old man rests under acacia tree. (Bàbá arúgbó náà ń gbatẹ́gùn lábẹ́ ogo kaṣíà).

academy (n); Ilé ẹ̀kọ́ gíga: He attends Baptist Academy. (Ó ń lọ sí ilé ìwé gíga ìjọ onítẹ̀bọmi). 

accent (v); àmì ohùn: (Yorùbá is an accent language. (Èdè Yorùbá jẹ́ èdè Olóhùn). 

accept: (v); tẹ́wọ́gbà: I accepted the doctors advice: (Mo gba imọ̀ràn dókítà). 

acceptable (adj);  ìtẹ́wọ́gbà: This work you have done is not acceptable, please do it again. (Iṣẹ́ tí o ṣe kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Jọ̀wọ́, lọ tun ṣe. 

access (n); ọ̀nà, àjè: I have access to the library. (Mo lè wọ ilé ìkàwé). 

accident (n)  èsì, ìjàmbá: There was an accident yesterday. (Ìjàmbá kan sẹlẹ̀ lánàá). 

accommodate (v) fún láàyè: You could accommodate another student in your room (Ó le fún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn láàyè nínú yàrá rẹ). 

accompany (v); Bálọ, Bárìn, Bákẹ́gbẹ́: He accompanied Bọla to Lagos. (Ó bá Bọ́lá lọ sí Èkó). 

accomplish (v) ṣe parí: I accomplished two hours work before dinner. (Mo parí iṣẹ́ wákàtí méjì kí oúnjẹ ọ̀sán tó tó). 

accord (n); ọkàn naa; ifowosowopo: We are in accord about this matter. (A wà ní ọkàn naa nípa ọ̀rọ̀ yìí). 

account  (n) ìṣirò, ìròyìn: Edwin gave an exciting account of the football match. (Edwin ṣe ìròyìn ìdíje bọ́ọ̀lù orí pápá).

accurate (adj) déédé: My watch is more accurate than yours. (Aago mi ṣe déédé ju tìrẹ). 
accuse (v) fi sùn: The teacher accused Tálá of stealing. (Olùkọ́ náà fi ẹ̀ṣùn kan Tálá pé ó jalè).

accustom (v) mọ́lára, sọdàṣà: She is accustomed to eating beef. (Ó mọlára kí ó máa jẹ ẹran). 

ache  (v) fífọ́, ríro: Her head ached all night (orí fọ́ọ ní gbogbo òru). 

achieve (v) ṣetán, ṣerere: He achieved success in his studies. (Ó ṣe rere lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀). 

acid (n) ohun tó kan tàbí nínú: Some acid dropped onto Maria’s skirt and made a hole in it. 

acknowledge (v) Jẹ́wọ́, gbà: They acknowledged Olu as the cleverest student. (Wọ́n gbà pé Olú ni akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jùlọ). 

acquaintance (n); ojúlùmọ̀: He is an acquaintance of mine (Ojúlùmọ̀ mi ni). 

acquire (v); Jèrè: Ayo acquired his wealth through frand. (Ayò kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ lọ́nà ẹ̀ní). 

acquit (v) dáláre, dásílẹ̀ The suspect was acquitted by the court (Ilé ẹjọ́ dá arúfin náà sílẹ̀). 

acre (n); gburè ilè, sarẹ: The acre of land belongs to the Chief. (Olóyè ló ni gburè ilẹ̀ náà. 

across (adj); rékọjá: My friend lives in the house across the street. (Ilé tó wà ní ìfòná títì ní ọ̀rẹ́ mi ń gbé). 

act (v) ìṣe, òfin: Killing the lion was an act of bravery. (Iṣé akin ni pípa kìnìún).

active (adj) yára: My little brother is very active, he never sits still. (Àbúrò mi ọkùnrin yára púpọ̀ kì í wò sùù). 

actor (n); Òṣèré ọkùnrin: Hubert Ogunde was a a famous actor. (Gbajúmọ̀ òṣèré ni Ògúndé ń ṣe láyé àtijọ́).

actress (n); òṣẹ̀ré obìnrin: Liz Benson is one of the Contemporary actress. (Ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin ìwòyí ni Liz Benson ń ṣe). 

actual (adj); nítòótọ́, pàápàá, gan-an: He is the actual person that stole the goat. (Òun gan an ló jí ewúrẹ́ náà). 

A.D.  Lẹ́yìn ìkú Olúwa wa: This Church was built in 1950 A.D. (A kọ́ ìlé ìjọsìn yìí ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ó dín díẹ̀ lẹ́yìn ikú Olúwa wa). 

adapt (v); bádọ́gba: mólára, wà fún: It is sometimes difficult to adapt to town life. (Ó máa ń ṣòrọ nígbà míràn kí ìgbé ayé ìgboro tó mómi lára). 

add (v); fikún: There were seven eggs in the basket I added three, so now there are ten. (Ẹyindìyẹ méje ló wà nínú apẹ̀rẹ̀, mo fi mẹ́ta kún un, ní bá yìí ó ti di mẹ́wàá. 
adder (n); paramọ́lẹ̀: Adder is a poisonious snake. (Ejò olóró nì paramọ́lẹ̀). 

address (n); bá sọ̀rọ̀, kọ̀wé sí: Always address elders with respect. (Máa bá àwọn àgbà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀).

adequate  (adj); tó: There is an adequate amount of food for everyone. (Oúnjẹ tó tó wà fún gbogbo ènìyàn). 

adjective (n) Àpèjúwe: She sang a beautiful song. (Ó kọ orin dádùn). 

adjust  (v) tún ṣe, tò léṣẹsẹ: Olù adjusted his trousers. (Olú tún ṣòkòtò rẹ̀ ṣe). 

administer (v); ṣàkóso: The government administers the Country. (Ìjọba ń ṣàkóso orílẹ̀, èdè). 

administrator (n); alákòóso: The Principla is the administrator of the school. (Ọ̀gá ilé ìwé ni alákòóso ìlé ìwé náà). 

admiral (n); Olórí ọkọ̀ ogun: My brother is an admiral. (Olórí ọkọ̀ ogun ojú omi ni ẹ̀gọ́n mi). 

admire (v); jọmi lojú, yìn; wuyì lójú: I admire his Kindness. (Ìwà rere rẹ̀ jọmi  lójú). 

admit (v) gbà sílẹ́, jẹ́wọ́: He admitted his failt. (Ó jẹ́wọ́ àìṣe déédé rẹ̀). 

adolescent (adj) Ọ̀dọ́ rẹ̀. Adolescent life is full of mistakes. (Ìgbà ọ̀dọ́ kún fún àṣìṣe). 

adopt (v) sọdọmọ: The childless couple adopted a child at last. (Tọkọtaya tí wọ́n yàgàn náà ti fi ọmọ kan sọmọ nígbẹ̀yìn).
adore (v); júbà; fẹ́ràn lọ́pọ̀lọpọ̀: The boy adores chocolate. (Ọmọkùnrin náà fẹ́ràn ìpápánu púpọ̀). 

adult (n); àgbà: Olu is now an adult. He can take decisions on his own. (Olú ti dàgbà báyìí. Ó lè dá romú, kí ó sì ṣe ìpinnu lórí ohun tí ó kàn án. 

advance (v); ìlọsíwájú, àgbàsílẹ̀ owó. We are more advanced in techonology. (A ti lọ síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ). 

advantage (n); àǹfààní: There are lots of advantages in doing good. (Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú síṣe rere).

adventure  (n); ìdáwọ́lé: He went into a lot of adventures in order to learn more. (Ó dáwọ́lé oríṣìíríṣìí ń kan kí ó lè ní ìmọ̀ si). 

adverb (n); ọ̀rọ̀ àpọ́nlé: She sang a song beautifully today. (Ó kọrin dáradára ló nìí. 

advertise  (v) kéde, polówó;  The supermarket was advertising salt at a good price. (ilé ìtàjà náà ń polówó iyọ̀ ní owí pọ́ọ́kú). 

advise (v); dárúmọ̀ràn, dámọ̀ràn; ìmọ̀ràn: She advised me to beware of dog. (Ó gbàmí nímọ̀ràn wípé kí n ṣọ́ra fún ajá). 

aerial (n); lójúsánmọ̀, lójúọ̀run: The aerial of my radio is fanlty. (Ọ̀pá redio mi kò dára). 

aeroplane (n); bààbú, ọkọ ofurufu: There was a plane crash at Abuja. (Ìjàmbá ọkọ̀ òfúrufú ṣẹlẹ̀ ní Àbújá). 

affair (n); ìṣe: The party was a very noisy affair. (Ayẹyẹ náà jẹ́ aláriwo). 

affect (v); mú lọ́kàn, kàn: This new rule will not affect me as lam leaving the school. (Òfin tuntun yìí kò kàn ní torí pé mò ń fi ilé ìwé náà sílẹ̀. 

affectionate (adj); nífẹ̀ẹ́: Her mother writes her long, affectionate letters. (Ìyá rẹ̀ kọ lẹ́tà ìfẹ́ gígùn si). 

afford (v); ní agbára láti ṣe ǹkan. My father says he can’t afford a car. (Bàbá mí ní àwọn kò ní agbára láti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́). 

afraid (adj); bẹ̀rù, fòyà, kọmimú: Olu says he’s not afraid of lion. (Olú sọ wí pé òun kò bẹ̀rù kìnìún). 
after (prep); lẹ́yìn, tẹ̀lé: Tomorrow is the day after today. (Ọ̀la ni ó tẹ̀lẹ́ òní). Ọ̀sán (n) afternoon: Come again this afternoon. (Padà wá ní ọ̀sán yìí). 

afterwards (adv); Nígbèyìn: We want to the film and afterwards we walked home together. (A lọ síbi sinimá, nígbẹ̀yìn a jọ rìn lọ sílé). 

again (adv); ẹ̀wẹ̀, lẹ́ẹ̀kejì: I liked the book so much that I read it again. (Mo gbádùn ìwé náà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ tó jẹ́ pé mo tún un kà). 

against (prep); lòdìsí: Our teacher is against bad habits. (Olùkọ́ wa lòdìsí ìwà ìbàjẹ́). 

agbádá (n) agbádá: The agbada he put on made him look twice his age. (Agbádá tí ó wọ̀ mú u dàbí àgbàlagbà). 

age (n); Ọjọ́ orí: Mary’s age is eight. (Ọjọ́ orí Maria ti tó ọdún mẹ́jọ). 

age (v); dàgbà, gbó: He has aged because of hard labour. (Ó ti gbó nítorí ìṣẹ́ agbára). 

agent (n) Aṣojú: My father is a postal agent. (Aṣojú ilé ìṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ni bàbá mi). 

agnostic (n); aláìgbàgbọ́: Olú is an agnostic. (Aláìgbàgbọ́ ni Olú). 

ago (adv); kọjá, sẹ́yìn: We came to live here six years ago. (A dé síbí ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn). 

agony (n); inira, ìrora: The wounded man was in agony. (Inu ìrora ni ọkùnrin tí ó ṣèṣe n nì wà). 

agree (v); sàdéùn, fohùnsọ̀kan: I agree with you. (Mo fohùn sọ̀kan pẹ̀lú rẹ). 

agriculture (n); iṣẹ́ àgbẹ̀: Agriculture is important because we all have to eat. (Iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí wí pé gbogbo wa ni a máa jẹun). 

ahead (adv); ní wájú: We shall have to cross that river ahead of us. (A máa rékojá odò tí ó wà ní wájú wa). 

ahmadiyya(n); Ẹ̀yà èṣìn mùsùlùmí: Alhajì Yusuph is of Ahmadiyya Sect. (Ẹ̀yà Ahmadiyya ni Alhaji Yésúfù). 

aid  (n) ìrànlọ́wọ́: A dictionary is an aid to learning English. (Ìwé asọ̀tumọ̀ jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì). 
aid (v); gbọwọ́, Olùgbọ̀wọ́: He aided the criminal. (Ó ṣe Olùgbọ̀wọ́ ọ̀daràn náà). 

aim (v);  Èrò, fojúsùn: He aimed to be the best football player in the school. (Ó gbèrò láti jẹ́ òṣèré orí pápá tí ó dára jùlọ ní ilé ìwé). 

aim (n); fojúsùn: He aimed at the lion. (Ó fojúsun kìnìún náà). 




#Article 181: Àwọn àdúgbò ìlú Ìkirè (219 words)


gan-gan ni Àjígbọ́ lọ̀sọ́.

wà. Torí pé odo yìí wọn kì í sọ̀rọ̀ tí wọn ń pọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í jẹ́ kí ilẹ̀ mọ́ tí wọn á fi pọn ni wọ́n fí pè é ní “Láì kọ sìn.

fún àwọn tí wọn ń bí abiku, ní ìgbà àtijọ́ kí àwọn àbíkú wọ̀nyí lè maa dúró sayé ni wọn ń pè ní Ọmọ-ró =  Móro.

dúró.

lu ilẹ̀ tó bá ti yọ ènìyàn.

ti máa ń tà á ládúgbò yìí kan náà.

fie tutu lé wọn kuro tó sì di ibi tó ṣe e gbé.

wà ní ibẹ̀ máa ń kún àkún ya wọlé.

ibẹ̀ ṣe olú ilé iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìlú ìkirè ni Ayé dára dé Ayedaade. 

ń dá àwọn ará ìlú lọ́nà. 

Ìpetu-modu tó tẹ ibẹ̀ do. Ibi tí a bá ààkùn.

ará Abẹ́òkuta kan wá ń ta àmàlà níbẹ̀ wọn mọ̀ ọ́ bí ẹni mo owó wọn sì máa n fi júwe pé Ìyànà tí Obìnrin ẹ̀gbá ti ń ta àmàlà.

ma ba à máa la orúkọ mọ́ sàngó lórí wọn ń pe ibẹ̀ ní kòso-Ibi tí sàngó kú sí.

èyí máa ń mú kí ilẹ̀ bẹ̀ rì.

	Ní àkotán, ìwádìí fi yé mi pé kò sí àdúgbò tàbí agbo-ilé tí orúko tó ńjé kò ní ìdí.
(see Yoruba Place names)




#Article 182: Àwọn Àdúgbò Oyé-Èkìtì (174 words)


Adugbo Oye-Ekiti

Oyé-Èkìtì : Àdúgbò

ti ẹrin náà ku si iba ni wọn pe ni atẹba ẹni to pa erin náà ni ọlọta aburo ijise ibi ti wọn pa erin náà si ni wọn pe ni ijisẹ. Ijisẹ lo pa àwọn ara Ọyẹ wa lati ile ifẹ pe wọn ti ri ibi tí wọn magbe. Ijisẹ ni orisu ilu Ọyẹ lati ile-ifẹ wa. 

yẹn.

ijisẹ. 

Igbati wọn de ilu Ọyẹ wọn sit un pe wọn ni ijagẹmọ nitorí ija wọn. 

ni ọmọ orin yọyọ ilugbo. 

si ilu Ọyẹ láti ba ọba ji roro, ìdí ti wọn fi pe wọn ni ilupeju. 

àwọn ara Ọyẹ ri pe ọlọrọ ni wọn jẹ ni wọn se pe wọn ni orísunmibare. 

ifẹ.

wọn fi ń pe ni ile-yao. 

ilẹmọ ni yen.

Ijisẹ. 

Ọyẹ. 

Ibẹru:- 	Ọlota ni aburo Ijise lati ile ifẹ wa nígbati wọn de Ọyẹ iberu ati Ijisẹ wa yapa o sit un jẹ àdúgbò ti o bẹru ogun tàbí ija púpọ̀. 

se wa si ilu Ọyẹ ìdí ti wọn fi tẹ̀dó si ìlú Ọyẹ ni èyí.




#Article 183: Atúmọ̀-èdè: Létà B (154 words)


ATÚMỌ̀-ÈDÈ (YORÙBÁ-ENGLISH):B

ọmọ ọkùnrin). 

sílẹ̀, nítórí pé ó ti wọ́n jù). 

rẹ̀). 

ní òwú dúdú).

ọpọlọ gbá òkúta). 

dára). 

igi, ó sa pamọ́ si ara ẹ̀ka igi). 

ìfowópamọ́ náà pẹ̀ka kaàkiri orílẹ̀ èdè yìí. 

òdùduwà). 

gbóyà lati wo inú ilé tí ó ń jó). 

ńmu omí ìyá rẹ̀). 

náà lọ).

náà bẹ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ki o to gba òògùn rẹ̀). 

produce the teath. (Ìyàwó á bí mẹ́sàn-án, á fi ọ̀kan se ẹ̀nì). 

dé). 

ọmọ ogun ni o da owo ju(. 

náà). 

náà mú wá àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́wàá). 

forí sogi ó rún wómú wómú). 

ìgbìmọ̀ fún káàkiri ti alámọ̀ funfun). 

fífọ́). 

wa).

asọ rẹ̀). 

lẹ́tà dànù ní ọwọ́ mi). 

mọ́ ìyẹ̀pẹ̀). 

àgbọ̀nrín náà ti jẹ ilá tán ni oko.

garawa). 

ọ̀gbìn). 

ìròhùn owó ìlú ni gómìnà kà). 

ìlẹ́ Indíà). 

yẹ lọ). 

ìwọ̀n). 

ìwo). 

mi). 

àpótí). 

kan. 
	

náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri). 

àwọn òbí rẹ̀). 

àpáta). 

igbó)

se òwò ìwé títà). 

tí ó rán). 

káàkírì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà). 




#Article 184: Ìwọ́ ìtanná (264 words)


Ìwọ́ ìtanná tabi ìwọ́ iná ni bi àdìjọ ìtanná se n sàn kiri. Ẹyọ ìwọ̀n SI fun ìwọ́ iná ni ampere (A), to dọ́gba mọ́ sísàn kiri coulomb kan agbára iná ní ìsẹ́jú àáyá.

Iye ìwọ́ iná (ti a wọ̀n ní ampere) ti o n gba òdeojú (surface) kan kọ já ni iye agbára iná (ti a wọ̀n ní coulombs) ti o n sàn kiri l'òdeojú na láàrin àsìkò kan. Tí Q bá jẹ́ iye agbára iná tó kọ já l'òdeojú na láàrin àsìkò T, nípa bayi àriniye (average) ìwọ́ iná I jẹ́:

Tí a bá jẹ́ kí ìwọ̀n àsìkò T kí ó dín títí títí dé òdo, á nìí ìwọ́ iná ẹ̀kanáà (instantaneous) i(t) gẹ́gẹ́ bi:

Nínú àwọn wáyà onípánù (Agbéiná – electrical conductor) tí wón gba agbára iná láàyè, ogunlọ́gọ̀ àwon atanná (electron) ni wọ́n rìn kiri lọ́fẹ̀ẹ́lófòò (atanná ọ̀fẹ́). Àwọn atanná wọ̀nyí kò sopọ̀ mọ́ átọ́mù kankan.

Òfin Ohm n tọ́kasí ìbásepọ̀ tó wà láàrin ìgbanná (Voltage), ìwọ́ iná ati ìdinà iná (electrical resistance):

nígbàtí,

Àpẹrẹ ìwọ́ iná ti a le fojuri ni mọ̀nàmọ́ná (lightning) ati ìjì ojúòòrùn (solar wind). Bakana iwo ina ti a mọ̀ ni sisan atanna ninu okùn onírin, fun apere awon waya opo ina to n gbe ina lati ibikan de ibo miran ati awon waya kekeke ninu awon ero onina (electronics), ati bi atanna se n san koja ninu adena ina (resistor), sisan kiri ioni (ion) ninu bátìrì (battery) ati sisan kiri iho ninu agbeinadie (semiconductor).

Ìwọ́ iná n pese pápá gbéringbérin (magnetic field). A le wo papa gberigberin bii ọ̀pọ̀ ìlà to yi waya po.




#Article 185: Iṣẹ́ẹ̀rọ onítanná (152 words)


Iṣẹ́ẹ̀rọ onítanná (Electrical engineering) ni papa eko iseero to un da lori agbeka ati imulo itanna, isiseonina ati iseonigberingberin onina. Papa eko yi koko di ise sise ni opin orundun okandinlogun leyin isodidunadura  telegrafu itanna ati ipese agbara onitanna. Loni o ti de oro bi agbara, isiseonina, awon sistemu ijannu, igbese alamioro ati awon ibanisoroelero.

Iseero onitanna le tun je mo iseero onina. Iseero onitanna je gbigba pe o da lori awon isoro to je mo awon sistemu onitanna gbangba bi ifiranse agbara itanna ati ikojannu oko, nigbati iseero onina da lori agbeka awon sistemu onina kekere bi komputa ati awon asoyipo olodidi. Tabi, a le so pe awon oniseero onitanna unda ise won lori lilo itanna lati fi safiranse okun onitanna, nigbati awon oniseero onina unda ise won lori lilo itanna lati se igbese aroye. Loni, ko fi be si iyato larin awon mejeji nitori idagbasoke to ti ba isiseonina agbara.




#Article 186: Nọ́mbà (101 words)


Nọ́mbà jẹ́ ohun afòyemò tó dúró fún iye tàbí ìwòn. Àmì-ìsojú fún nọ́mbà ní àn pé nì àmìnọ́mbà (numeral). Nì èdè ojojúmọ́, à n lo àwọn àmìnọ́mbà bí àkólé (fún àpẹrẹ nọ́mbà tẹlífònù, nọ́mbà ilé). Nínú ìmọ̀ ìṣirò ìtumò nọ́mbà tí s'àkomọ̀ àwọn nọ́mbà afóyemọ̀ bí idà (fraction), nọ́mbà apáòsì (negative), tíkòníònkà (transcendental) àti nọ́mbà tósòro (complex).

Àwọn ònà ìṣèṣirò nọ́mbà bí àropò, ìyokúrò, ìsodípúpò, àti ìṣepínpín ní a n sewadi wón nínú ẹ̀ka ìmọ̀ ìṣirò tí a mò sí aljebra afòyemọ̀ (abstract algebra), níbití a tí n sewadi àwọn ònà nọ́mbà afóyemọ̀ bí ẹgbẹ́ (group), òrùka (ring) àti pápá (field).




#Article 187: Áljẹ́brà onígbọrọ (171 words)


Aljebra gbigboro (linear algebra) je eka imo isiro ti o ni se pelu imo nipa awon atokaona (vector), aaye atokaona (vector space), maapu gbigboro (linear map) ati awon ona-eto idogba gbigboro (system of linear equation). Aaye atokaona se pataki ninu imo isiro ayeodeoni, nipa bayi aljebra alatele wulo lopolopo ninu aljebra afoyemo ati agbeyewo alabase (functional analysis). O tun wulo gidigidi ninu awon sayensi aladabaye ati sayensi awujo nigba t'oje pe awon apere alainitele (nonlinear) se mu sunmo eyi to je alatele (linear). 

Itan aljebra ayeodeoni bere ni arin odun 1843 ati 1844. Ni odun 1843, William Rowan Hamilton (eni ti o koko soro nipa atokaona) se awari quaternions. Ni odun 1844, Hermann Grassmann ko iwe ni ede Germani pelu akole Die lineale Ausdehnungslehre. Arthur Cayley mu apotinomba (matrix) wa ni odun 1857. Ilana Cramer to n fihan wa bi a se le s'ojutu awon idogba iseyato abo (partial differential equation) lo so aljebra alatele di eko ti a n ko ni awon ile-eko giga. Fun apere, E.T. Copson ko pe:




#Article 188: Áljẹ́brà (107 words)


Áljẹ́brà ni eka mathimatiki to dori lori igbeka awon ilana ofin awon imuse ati awon ibasepo, ati awon imuwa ati ajotumo to ba je wa ninu won, bi awon oro, awon oniyeoropupo, isedogba ati opo onialjebra. Lapapo mo jeometri, ituwo, topoloji, isopo-noma, ati iro nomba, aljebra je ikan ninu apa mathimatiki. 

Oruko aljebra wa lati inu iwe ti onimo isiro ara ile Persia, Muhammad bin Mūsā al-Khwārizmī ko pelu akole (ni ede arabu كتاب الجبر والمقابلة) Al-Kitab al-Jabr wa-l-Muqabala (to tumosi Iwe ekunrere fun isesiro nipa sisetan ati sisebamu). Eyi fi ona isojutu fun awon idogba alatele ati idogba alagbarameji han.

Aljebra pin si orisirisi eka wonyi:




#Article 189: Òbìrípo (137 words)


Ninu mathimatiki òbìrípo (Circle) pelu arin C ati ilatotan r, je irisi aniwonile to je akojopo awon ojuami ati ijinasi won si arin ti a n pe ni ilatotan (radius).

Iyipo je Ila-alajapo (curve)ti o ti; ti o si pin pepe si apa inu ati ode. Ibu re ni a mo si ayika (circumference). Inu re ni a n pe ni abọ́ (disk). Ọfà (arc) si ni apa iwapapo pato kan lori iyipo na. 

Ti a ba ni ona ipoidojuko x-y, iyipo to ni arin ni (a, b) ati ilatotan r je akojopo gbogbo ojuami (x, y) to fi je pe 

Ti o ba je pe ni ojuibere (0, 0) (origin) ni arin re wa, a le so afise dero bayi, 

Be si ni tangenti yio je

nigbati ,  si je ipoidojuko ojuami kanna won.

(x, y)




#Article 190: M. K. O. Abíọ́lá (354 words)


Moshood Káṣìmawòó Ọláwálé Abíọ́lá (August 24, 1937 - July 7, 1998) tí ó túmọ̀ sí M.K.O Abíọ́lá jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. A bi ní ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.  Ó jẹ́ oníṣòẁò,òǹtẹ̀wé, olóṣèlú àti olóyè ilẹ̀ Yorùbá Ẹ̀gbá pàtàpátá. Ó díje sípò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1993, òun náà sì ni  gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ tí  wọ́n sì fẹnukò sí jákè-jádò orílẹ-èdè Nàìjíríà wípé ó jáwé olúborí nígbà tí olóri ìjọba ológun ìgbà náà Ibrahim Babangida kò kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olúborí ètò ìdìbò náà tí ó sì fi ẹ̀sùn àìṣòtítọ́ àti àìṣòdodo ètò ìdìbò yàn náà. M.K.O kú ní ọdún 1998. 

Moshood Abíọ́lá ni àkọ́bí  bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìkúnlẹ̀ ọmọ kẹtàlélógún, ìdí èyí ní ó fàá tí wọ́n fi dúró títí di ẹ̀yìn ọdún mẹ́ẹ̀dógún (15 years) kí àwọn òbí rẹ̀ tó fún lórúkọ rẹ̀ “Kasimawo” . Moshood fakọyọ nínú ìmọ̀ ìdágbálé (entrepreneur) láti ìgb̀a èwe rẹ̀, ó bẹ̀rè iṣẹ́ igi-ṣíṣẹ́ tà láti ọmọ ọdún mẹ́sàán.  Ó ma ń jí ní ìdájí lọ sóko igi láti wági tí yóò tà ṣáájú kí ó tó lọ sị́ ilé-ìwé kí òun àti bàbá rẹ̀ tó ti rúgbo pẹ̀lú àwọn àbúrò rẹ̀ kó lè rówó ná. Nígb̀a tí ó t́o ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún (15 years), ó dá ẹgbẹ́ eré kan kalẹ̀ tí wọ́n ma ń kọrin kiri láti lè rí óúnjẹ jẹ níbi ìnáwo èyíkéyìí tí wọ́n bá lọ. Láìpẹ́, ó di gbajú-gbajà níbi orin rẹ̀ tó ń kó kiri, ó sì di ẹni tí ó ń bèrè fún owó iṣẹ́ kí wọ́n tó kọrin lóde ìnáwó kòkan. Àwọn owó tí ó ń rí níbi eré rẹ̀ yìí nị́ ó fi ń ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́ tí ó sì ń san owó ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí ìjọ Onítẹ̀bọmi  tí ó wà ní Abéòkúta . Abíọ́́lá jẹ́ Olóòtú ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilé-ìwé wọn tí ó ń jẹ́ The Trumpeter tí Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ sì jẹ́ igbákejì rẹ. Ó dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ National Council of Nigeria and the Cameroons ní ìgbà tí ó di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ètò òṣèlú àwa arawa lábẹ́ àsíá Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group.

 




#Article 191: Átọ̀mù (290 words)


Átọ̀mù je eyo kan ipile èlò ni a mo si ohun to kere julo fun awon apilese (element). Bo tile je pe atomu ni ede Griki tumosi eyi ti ko se fo si wewe, imo atomu nisinyi ni pe awon ohun abeatomu miran tun wa:

Akowa ati alaigbara ni won po ti won kun inu inuikun atomu (atomic nucleus) a si n pe won ni abikun (nucleons). Nigbati atanna si parapo da ìsú atanna to yipo inuikun.

O se se ki atomu o yato nipa iye awon ohun abeatomu ti won ni. Atomu ti won ni apilese kanna ni iye akowa kanna (ti a mo si nomba atomu). Fun apilese kan pato, iye alaigbara yato, eyi si ni n so bi olojukanna (isotope) apilese na yio se ri. Atomu ko ni agbara ina kankan ti iye akowa ati atanna won ba dogba. Atanna ti won jinna julo si inuikun atomu se gbe lo si odo atomu miran to wa ni tosi won tabi ki won o je pin larin awon atomu o hun. Bayi ni awon atomu se n sopo lati di ẹyọ (molecule). Fun apere eyo kan omi je akopapo atomu meji hydrogen ati atomu kan oxygen. Atomu ti atanna won ku die kato tabi to po ju bose ye lo ni an pe ni ioni. Ona miran ti iye akowa ati alaigbara fi le yipada ninu inuikun atomu ni yiyo inuikun (nuclear fussion) tabi fífọ́ inuikun (nuclear fission).

Atomu je ipilese ti ẹ̀kọ́ egbò (chemistry) duro le lori, be ni won si kopamo (conserve) ninu adapo elegbo (chemical reaction).

Fun awon elefufu (gas) ati onisisan (liquid) ati onilile (solid) eleyo (molecular) (fun apere omi ati suga), eyo je ipin to kere julo ohun ti o ni idamo elegbo.  
 




#Total Article count: 190
#Total Word count: 199844